Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wọ́n Nírètí Bí Nǹkan Ò Tilẹ̀ Rọgbọ Àpéjọ Àkànṣe ní Àgọ́ Àwọn Tí Ogun Lé Kúrò Nílé

Wọ́n Nírètí Bí Nǹkan Ò Tilẹ̀ Rọgbọ Àpéjọ Àkànṣe ní Àgọ́ Àwọn Tí Ogun Lé Kúrò Nílé

Wọ́n Nírètí Bí Nǹkan Ò Tilẹ̀ Rọgbọ Àpéjọ Àkànṣe ní Àgọ́ Àwọn Tí Ogun Lé Kúrò Nílé

ÀGỌ́ Kakuma táwọn tí ogun lé kúrò nílé ń gbé wà ní àríwá ilẹ̀ Kẹ́ńyà nítòsí ibi tí ilẹ̀ Sudan àti Kẹ́ńyà ti pààlà. Àwọn tó ń gbébẹ̀ lé ní ọ̀kẹ́ mẹ́rin ó lé ẹgbàáta [86,000]. Àgbègbè náà gbẹ táútáú, oòrùn sì máa ń mú janjan níbẹ̀ lọ́sàn-án. Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn ẹ̀yà tógun lé wá síbẹ̀ ń bára wọn jà. Ọ̀pọ̀ lára wọn ti ro ara wọn pin. Àmọ́, àwọn kan nínú wọn ò sọ̀rètí nu.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà díẹ̀ wà lára àwọn tó ń gbébẹ̀, wọ́n sì ń fi ìtara kéde ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Ìjọ kékeré kan ní Lodwar ni wọ́n wà, ó sì tó ọgọ́fà kìlómítà síhà gúúsù àgọ́ náà. Téèyàn bá fẹ́ gbé mọ́tò lọ síbi tí ìjọ tó tún sún mọ́ Lodwar wà, ó máa gbà tó wákàtí mẹ́jọ.

Nítorí pé kò ṣeé ṣe fáwọn tó ń gbé àgọ́ náà láti jáde fàlàlà, ọ̀pọ̀ lára wọn kì í lọ sáwọn àpéjọ táwa Ẹlẹ́rìí máa ń ṣe. Ìdí nìyí táwọn Ẹlẹ́rìí kan fi ṣètò láti wá ṣe àpéjọ àkànṣe ní àgọ́ náà.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Kan Lọ sí Àríwá Kẹ́ńyà

Àwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ló lọ sí àgọ́ náà láti lọ bá wọn ṣèpàdé. Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan tó gbé ọkọ̀ rẹ̀ sílẹ̀ kí wọ́n lè fi rìnrìn àjò náà, àti awakọ̀ rẹ̀ náà bá wọn lọ pẹ̀lú. Wọ́n gbéra láti ìlú Eldoret tó wà ní irínwó ó lé ọgọ́rin [480] kìlómítà síhà gúúsù àgọ́ náà, wọ́n sì rìnrìn àjò lọ sí àgbègbè Lodwar tó gbẹ táútáú, níhà àríwá Kẹ́ńyà láti lọ fáwọn arákùnrin wọn níṣìírí.

Àárọ̀ kùtùkùtù ọjọ́ kan tí òtútù mú gan-an ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò wọn níhà ìwọ̀ oòrùn Kẹ́ńyà tó jẹ́ àgbègbè olókè. Wọ́n wakọ̀ gba ọ̀nà orí òkè tó rí gbágungbàgun, tó gba ẹ̀gbẹ́ oko àti igbó jáde sínú aṣálẹ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ tó jẹ́ àgbègbè tó gbóná gan-an. Bí wọ́n ṣe ń lọ, wọ́n ń rí àwọn ewúrẹ́ àti ràkúnmí tó ń jẹko nínú aṣálẹ̀ náà. Wọ́n tún rí àwọn ọmọ onílẹ̀ nínú aṣọ ìbílẹ̀ wọn tí wọ́n ń rìn lọ lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà, tí ọ̀pọ̀ lára wọn mú ọ̀pá, ọrun àti ọfà lọ́wọ́. Lẹ́yìn ìrìn àjò wákàtí mọ́kànlá, wọ́n dé àgbègbè Lodwar eléruku tó ń gbóná. Àwọn tó ń gbébẹ̀ fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọ̀kẹ́ kan [20,000]. Àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n lọ bá kí wọn tọ̀yàyàtọ̀yàyà. Lẹ́yìn èyí, wọ́n lọ sinmi láti múra sílẹ̀ fún ìgbòkègbodò òpin ọ̀sẹ̀ náà.

Láàárọ̀ ọjọ́ kejì, wọ́n lọ wo àwọn ibi pàtàkì-pàtàkì lágbègbè náà. Wọ́n lọ wo Adágún Turkana táwọn èèyàn máa ń fẹ́ láti wò. Adágún yìí ló tóbi jù lọ ní Kẹ́ńyà, ibẹ̀ ni ọ̀nì pọ̀ sí jù lọ láyé, ọ̀dàn tó yí adágún náà ká sì fẹ̀ gan-an. Omi adágún oníyọ̀ náà ni ìwọ̀nba èèyàn tó ń gbé létí rẹ̀ gbára lé fún oúnjẹ òòjọ́. Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn, wọ́n bá àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní ìjọ tí ń bẹ ní Lodwar ṣèpàdé Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run àti Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn. Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn dára gan-an. Ọdún 2003 ni wọ́n kọ́ ọ, ó sì wà lára àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tí wọ́n kọ́ nínú ètò ìkọ́lé táwọn Ẹlẹ́rìí ṣe fún àǹfààní àwọn orílẹ̀-èdè tí kò fi bẹ́ẹ̀ lọ́rọ̀.

Bí Àpéjọ Àkànṣe Náà Ṣe Lọ

Ọjọ́ Sunday ni wọ́n fi àpéjọ náà sí. Aago mẹ́jọ àárọ̀ ni wọ́n sọ pé àwọn tó wà ní ìjọ tí ń bẹ ní Lodwar àtàwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tó rìnrìn àjò náà lè wọnú àgọ́ náà. Èyí ló mú káwọn Ẹlẹ́rìí yìí tètè bẹ̀rẹ̀ ìrìn wọn. Ọ̀nà tó rí kọ́lọkọ̀lọ tó gbanú aṣálẹ̀ jáde sápá ibi tí Sudan àti Kẹ́ńyà ti pààlà ni wọ́n gbà. Àwọn òkè ńlá tó rí págunpàgun wà lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ ọ̀nà. Àmọ́ nígbà tí wọ́n dé abúlé Kakuma, wọn ò rí òkè kankan mọ́, ńṣe ni gbogbo ilẹ̀ tẹ́jú. Òjò ti ń rọ̀ níbẹ̀, omi sì ti bo àwọn apá ibì kan lára ọ̀nà eléruku tó wọ àgọ́ náà. Bíríkì ni ọ̀pọ̀ lára àwọn tó wà níbẹ̀ fi kọ́lé. Àwọn kan fi páànù kan ilé wọn, àwọn míì sì lo tapólì. Àwọn èèyàn ilẹ̀ Etiópíà, Sòmálíà àti Sudan, àtàwọn míì ń gbé níbi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Tẹ̀ríntẹ̀yẹ làwọn tó wà níbẹ̀ fi kí wọn káàbọ̀.

Gbọ̀ngàn kan táwọn èèyàn ti ń kẹ́kọ̀ọ́ ni wọ́n ti ṣèpàdé náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àwòrán ohun tí ń bani lọ́kàn jẹ́ tójú àwọn tó ń gbé àgọ́ náà ń rí wà lára ògiri, ìṣesí àwọn tó wà níbẹ̀ lọ́jọ́ náà fi hàn pé wọ́n ní ìrètí. Èdè Gẹ̀ẹ́sì àti èdè Swahili ni wọ́n fi sọ gbogbo àsọyé tí wọ́n sọ. Kódà, èdè méjèèjì làwọn alásọyé kan tó gbọ́ àwọn èdè náà dáadáa fi sọ àsọyé wọn. Arákùnrin kan tó jẹ́ ọmọ Sudan tó ń gbé àgọ́ náà ló sọ àsọyé àkọ́kọ́ tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Yíyẹ Ọkàn-àyà Ìṣàpẹẹrẹ Wa Wò.” Àwọn alàgbà tó wá sí àgọ́ náà láti ibòmíì ló sọ àwọn àsọyé yòókù.

Ìrìbọmi jẹ́ ohun pàtàkì tó máa ń wáyé ní gbogbo àpéjọ. Nígbà tí àsọyé ìrìbọmi náà fẹ́ parí tẹ́nì kan ṣoṣo tó fẹ́ ṣèrìbọmi dìde dúró, gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ tẹjú mọ́ ọn. Gilbert lórúkọ rẹ̀. Ọdún 1994 lòun àti bàbá ẹ̀ sá kúrò nílẹ̀ baba wọn nígbà tí ẹ̀yà kan ń pa ẹ̀yà míì. Wọ́n kọ́kọ́ forí lé ilẹ̀ Burundi, wọ́n rò pé kò séwu níbẹ̀, àmọ́ kò pẹ́ tí wọ́n fi mọ̀ pé inú ewu làwọn ṣì wà. Gilbert wá sá lọ sílẹ̀ Zaire, lẹ́yìn náà ó gba ilẹ̀ Tanzania lọ kó tó wá lọ sí Kẹ́ńyà. Nígbà míì, inú igbó ló máa ń sá sí. Ńṣe ni omi lé roro lójú ọ̀pọ̀ èèyàn nígbà tẹ́ni tó ń sọ àsọyé ní inú òun dùn láti kí i káàbọ̀ sínú ìjọ Ọlọ́run. Nígbà tí Gilbert máa dáhùn ìbéèrè méjì tí alásọyé bi í, ìdánilójú àti ohùn tó dún ketekete ló fi sọ pé “Ndiyo!”, ìyẹn “Bẹ́ẹ̀ ni!” lédè Swahili. Àwọn márùndínlọ́gọ́rùn-ún ló wà ní àpéjọ náà. Gilbert àtàwọn arákùnrin kan ló gbẹ́hò kékeré tí wọ́n fi ṣèrìbọmi, wọ́n sì tẹ́ tapólì tí Gilbert fi bo ibi tó ń gbé sínú ihò náà. Ó ṣe ohun tó fi hàn pé ara rẹ̀ ti wà lọ́nà láti ṣèrìbọmi, òun nìkan fi korobá pọnmi kúnnú ihò náà láàárọ̀ ọjọ́ náà!

Ọ̀kan lára ohun táwọn tó pé jọ gbádùn nípàdé ọ̀sán ni ìrírí táwọn akéde kan sọ nípa ipò àwọn Ẹlẹ́rìí tó ń gbé àgọ́ náà. Arákùnrin kan sọ bó ṣe jẹ́rìí fún ọkùnrin kan tó ń sinmi lábẹ́ igi.

Ó bi ọkùnrin náà pé: “Ǹjẹ́ o rò pé gbogbo ìgbà lèèyàn lè jókòó lábẹ́ igi tí ọkàn rẹ̀ á sì balẹ̀?”

Ọkùnrin náà dáhùn pé “Bẹ́ẹ̀ ni.” Lẹ́yìn náà ló sọ pé, “Irọ́ o, ọkàn èèyàn ò lè balẹ̀ láti jókòó lábẹ́ igi bí ilẹ̀ bá ṣú.”

Arákùnrin yìí ka Míkà 4:3, 4 fún un, èyí tó ní: ‘Wọn yóò jókòó ní ti tòótọ́, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, kì yóò sì sí ẹnì kankan tí yóò máa mú wọn wárìrì.’ Ó wá sọ pé: “Nínú ayé tuntun tí Ọlọ́run máa ṣàkóso, gbogbo ìgbà lọkàn èèyàn á máa balẹ̀.” Ọkùnrin náà gba ìwé wa kan tí yóò máa fi kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Arábìnrin kan tí kò tíì pẹ́ táwọn èèyàn ẹ̀ mẹ́ta kú wà lára àwọn tó lọ sí Kakuma. Nígbà tí arábìnrin náà ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ará tó wà ní àgọ́ náà, ó ní: “Ìnira ibí yìí kọjá sísọ; síbẹ̀, ìgbàgbọ́ wọn lágbára gan-an. Ibi tí wọ́n ń gbé kì í ṣe ibi ìdùnnú, àmọ́ ìdùnnú ni wọ́n fi ń sin Jèhófà. Àjọṣe tó dán mọ́rán wà láàárín àwọn àti Ọlọ́run. Àpẹẹrẹ wọn fún mi níṣìírí láti mọ́kàn àti láti máa sin Jèhófà nìṣó. Kò yẹ kí n máa ráhùn rárá!”

Láìpẹ́, àpéjọ náà parí. Ẹni tó sọ àsọyé tó gbẹ̀yìn sọ fáwọn tó péjọ pé orílẹ̀-èdè mẹ́jọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn èèyàn ti wá sí àpéjọ náà. Ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí tó ń gbé àgọ́ náà sọ pé àpéjọ yìí fi hàn pé ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan wà láàárín àwa Ẹlẹ́rìí bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ìṣọ̀kan láyé. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ara wọn lóòótọ́.—Jòhánù 13:35.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

ÀWỌN ỌMỌ ILẸ̀ SUDAN TÍ OGUN SỌ DI KÒ-LẸ́BÍ-KÒ-LÁRÁ

Látìgbà tí ogun abẹ́lé ti bẹ̀rẹ̀ ní Sudan lọ́dún 1983, àwọn tó tó mílíọ̀nù márùn-ún ló ti dẹni tí kò nílé lórí. Lára wọn làwọn ọmọdé tí wọ́n tó nǹkan bí ẹgbàá mẹ́tàlá [26,000] tí ogun sọ di kò-lẹ́bí-kò-lárá. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ lára wọn sá lọ sí àgọ́ táwọn tí ogun lé kúrò nílùú ń gbé lórílẹ̀-èdè Etiópíà, ọdún mẹ́ta ni wọ́n sì fi wà níbẹ̀. Nígbà tí wọ́n tún lé wọn kúrò níbẹ̀, wọ́n fẹsẹ̀ rin ìrìn ọdún kan gbáko padà gba inú ilẹ̀ Sudan lọ síhà àríwá Kẹ́ńyà. Bẹ́ẹ̀ làwọn sójà, àwọn èèyànkéèyàn, àrùn oríṣiríṣi àtàwọn ẹranko ẹhànnà ń hàn wọ́n léèmọ̀ bí wọ́n ṣe ń rìnrìn àjò líle ọ̀hún. Ìdajì àwọn ọmọ wọ̀nyí ló kú sọ́nà, nígbà táwọn yòókù dé Kẹ́ńyà. Àwọn wọ̀nyí ló kọ́kọ́ dé àgọ́ Kakuma. Àwọn àjọ tó ń ṣètò ohun ìrànwọ́ máa ń pè wọ́n ní àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Sudan tí ogun sọ di kò-lẹ́bí-kò-lárá.

Ní báyìí, àgọ́ Kakuma ti di ibùgbé fáwọn tí ogun lé kúrò ní Sudan, Sòmálíà, Etiópíà àtàwọn orílẹ̀-èdè mìíràn. Béèyàn bá ṣẹ̀ṣẹ̀ dé àgọ́ náà, wọ́n á fún un láwọn ohun tó lè fi kọ́ ibi tí yóò máa gbé àti tapólì tó máa fi bò ó. Ẹ̀ẹ̀mejì lóṣù ni wọ́n máa ń fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ní kóńgò ìyẹ̀fun mẹ́fà, kóńgò ẹ̀wà kan, òróró díẹ̀ àti iyọ̀ díẹ̀. Ọ̀pọ̀ lára wọn máa ń fi oúnjẹ tí wọ́n bá kó fún wọn pààrọ̀ nǹkan míì lọ́dọ̀ àwọn ẹlòmíràn.

Díẹ̀ lára àwọn ọmọ tí ogún ti sọ di kò-lẹ́bí-kò-lárá wọ̀nyí ti padà sọ́dọ̀ ìdílé wọn, wọ́n sì ti kó àwọn míì lọ sáwọn orílẹ̀-èdè mìíràn. Àmọ́, Ẹ̀ka Tó Ń Mójú Tó Ọ̀ràn Àwọn Tí Ìṣòro Lé Kúrò Nílùú (Office of Refugee Resettlement) sọ pé, “Ẹgbẹẹgbẹ̀rún lára àwọn ọmọ wọ̀nyí ló dúró sí àgọ́ Kakuma, níbi tí eṣinṣin pọ̀ sí gan-an, tó jẹ́ pé agbára káká ni wọ́n fi ń róúnjẹ jẹ, wọ́n sì gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ àṣekára kí wọ́n tó lè rán ara wọn lọ síléèwé.”

[Credit Line]

Courtesy Refugees International

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 23]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

KẸ́ŃYÀ

Àgọ́ Kakuma

Adágún Turkana

Lodwar

Eldoret

Nairobi

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Wọ́n ń pín omi fún àwọn èèyàn ní àgọ́ Kakuma

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Àwọn Ẹlẹ́rìí ará Kẹ́ńyà rìnrìn àjò jíjìn lójú ọ̀nà tí ò dáa lọ sí àríwá orílẹ̀-èdè wọn láti lọ fún àwọn arákùnrin wọn níṣìírí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ìgbésí ayé ò rọrùn fáwọn tó ń gbé ní àgọ́ náà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Míṣọ́nnárì kan ń ṣe ògbufọ̀ fún aṣáájú ọ̀nà àkànṣe kan tó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Ibi tí wọ́n lò fún ìrìbọmi rèé

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 23]

Ibi tí wọ́n ti ń pín omi fún àwọn èèyàn àti Àgọ́ Kakuma: Courtesy Refugees International