Àjíǹde Jẹ́ Ohun Àgbàyanu Kan Tá À Ń Retí
Àjíǹde Jẹ́ Ohun Àgbàyanu Kan Tá À Ń Retí
IBI gbogbo làwọn èèyàn ti gbà pé àjíǹde ń bọ̀. Odindi orí kan ni Kùránì, tó jẹ́ ìwé mímọ́ àwọn onísìn Ìsìláàmù, fi sọ̀rọ̀ lórí àjíǹde. Apá kan nínú Surah Karùndínlọ́gọ́rin [75] sọ pé: “Mo fi ọjọ́ ajinde bura . . . Njẹ enia ha le mã ro . . . pe A kò ni le ko awọn egun on jọ? . . . Yio ma bere pe: ‘Igbawo ni ọjọ ajinde na?’ Njẹ ẹniti O ṣe eyi kò ha ni agbara (kan náà) lati ji oku bi?”—Surah 75:1-6, 40.
Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica sọ pé: “Àwọn onísìn Zoroaster gbà gbọ́ pé a óò ṣẹ́gun Ibi pátápátá níkẹyìn, pé àjíǹde gbogbo gbòò ń bọ̀ àti pé Ìdájọ́ Ìkẹyìn yóò dé, pé a óò sì mú ayé kan tó mọ́ tónítóní padà wá fún àwọn olódodo.”
Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Judaica sọ pé àjíǹde ni “ìgbàgbọ́ pé àwọn tó ti kú á jí dìde nínú ara, wọ́n á sì tún padà wà láàyè níkẹyìn lórí ilẹ̀ ayé.” Ìwé yẹn kan náà tún sọ pé ohun táwọn ẹlẹ́sìn Júù gbà gbọ́ ni pé ọkàn èèyàn kì í kú, èyí sì ti mú káwọn èèyàn ní iyèméjì. Àmọ́ ó wá sọ pé: “Láìsí àní-àní, àwọn ìgbàgbọ́ méjèèjì yìí, ìyẹn ẹ̀kọ́ àjíǹde àti ẹ̀kọ́ ọkàn-kì-í-kú, ta ko ara wọn.”
Ìsìn Híńdù kọ́ àwọn èèyàn pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n máa ń tún èèyàn bí tàbí pé èèyàn máa ń tún ayé wá. Tó bá jẹ́ pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí, a jẹ́ pé èèyàn ní láti ní ọkàn kan tó máa ń wà láàyè nìṣó lẹ́yìn ikú. Ìwé Mímọ́ ìsìn Híńdù tí wọ́n ń pè ní Bhagavad Gita sọ pé: “Ọkàn tó ń ṣiṣẹ́ ní ibi gbogbo nínú ara yẹn kò ṣeé pa run. Kò sẹ́ni tó lè pa ọkàn tí kò lè kú náà run.”
Ìsìn Búdà yàtọ̀ sí ìsìn Híńdù nítorí pé ìsìn Búdà gbà pé ọkàn máa ń kú. Àmọ́ lóde òní, ọ̀pọ̀ àwọn onísìn Búdà tó wà ní gbogbo orílẹ̀-èdè tó wà ní ìlà oòrùn Éṣíà ló ti wá gbà gbọ́ pé ọkàn kì í kú, pé ńṣe ló máa ń tinú ara kan bọ́ sínú ara mìíràn. a
Ẹ̀kọ́ Nípa Àjíǹde Dàrú Mọ́ Àwọn Èèyàn Lójú
Ètò ìsìnkú táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì máa ń darí sábà máa ń jẹ́ káwọn èèyàn gbà pé ọkàn ń wà láàyè lẹ́yìn ikú àti pé àjíǹde sì tún wà. Bí àpẹẹrẹ, àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì Áńgílíkà sábà máa ń ka àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní àkàtúnkà pé: “Njẹ bi o ti wu Ọlọrun Olodumarè nínú anu rẹ nla lati gba ọkan arakunrin wa tí ó kú yìí, awa fi ara rẹ fun ilẹ, erupẹ fún erupẹ, eru fun eru, ekuru fun ekuru; ni idaniloju ati li aisiyemeji ireti ajinde si iye ti ko nipẹkun nipasẹ Oluwa wa Jesu Kristi.”—Ìwé The Book of Common Prayer.
Ọ̀rọ̀ inú ìwé yìí ò lè jẹ́ kéèyàn mọ̀ bóyá àjíǹde ni Bíbélì fi kọ́ni tàbí ẹ̀kọ́ ọkàn èèyàn kì í kú. Àmọ́ ṣá o, ṣàkíyèsí ohun tí Ọ̀jọ̀gbọ́n nípa Ìsìn,
ọmọ ilẹ̀ Faransé kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Oscar Cullmann sọ. Ohun tó kọ sínú ìwé rẹ̀ tó pè ní Immortality of the Soul or Resurrection of the Dead? [Àìleèkú Ọkàn Tàbí Àjíǹde Àwọn Òkú, Èwo Ni?] ni pé: “Ìyàtọ̀ ńlá ló wà láàárín ìgbàgbọ́ àwọn Kristẹni pé àjíǹde àwọn òkú ń bọ̀ àti ìgbàgbọ́ àwọn Gíríìkì pé ọkàn kì í kú. . . . Àmọ́ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì wá da ìgbàgbọ́ méjèèjì yìí pọ̀ mọ́ra nígbà tó yá, àwọn tó pe ara wọn ní Kristẹni lóde òní ò sì mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ẹ̀kọ́ méjèèjì yìí. Èmi ò rídìí tí màá fi fi ohun tí èmi àti ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ mìíràn gbà pé ó jẹ́ òótọ́ pa mọ́. . . . Ìgbàgbọ́ nínú àjíǹde ni gbogbo ohun tó wà nínú Májẹ̀mú Tuntun dá lé lórí. . . . Ẹni tó kú yẹn gan-an ló máa padà wà láàyè nípasẹ̀ agbára tí Ọlọ́run ní láti tún ènìyàn dá.”Abájọ tí ẹ̀kọ́ nípa ikú àti àjíǹde fi dàrú mọ́ ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn lójú. Tá a bá fẹ́ mú ìdàrúdàpọ̀ yìí kúrò, a ní láti yẹ Bíbélì wò. Inú rẹ̀ la ti máa rí òtítọ́ tí Jèhófà Ọlọ́run, tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá ènìyàn fi kọ́ni. Àkọsílẹ̀ àwọn àjíǹde bíi mélòó kan wà nínú Bíbélì. Ẹ jẹ́ ká yẹ mẹ́rin wò lára àwọn àkọsílẹ̀ yìí, ká sì wo ohun tí wọ́n fi hàn nípa àjíǹde.
“Àwọn Obìnrin Rí Àwọn Òkú Wọn Gbà Nípa Àjíǹde”
Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sáwọn Júù tó di Kristẹni, ó ní àwọn obìnrin tó nígbàgbọ́ “rí àwọn òkú wọn gbà nípa àjíǹde.” (Hébérù 11:35) Ọ̀kan lára àwọn obìnrin wọ̀nyí gbé ní ìlú Sáréfátì, tó jẹ́ ìlú àwọn ará Fòníṣíà nítòsí Sídónì tó wà ní Etíkun Mẹditaréníà. Opó ni obìnrin yìí, òun ló fi ẹ̀mí ọ̀làwọ́ hàn sí Èlíjà tó jẹ́ wòlíì Ọlọ́run, tó gbà á sílé tó sì fún un lóúnjẹ nígbà tí ìyàn mú gan-an. Ó ṣeni láàánú pé ọmọ obìnrin yìí ṣàìsàn, ó sì kú. Kíá ni Èlíjà gbé ọmọ náà gòkè lọ sí ìyẹ̀wù òkè ilé náà níbi tó dé sí, ó sì bẹ Jèhófà pé kó dá ẹ̀mí rẹ̀ padà. Iṣẹ́ ìyanu ṣẹlẹ̀, ọmọ náà “sì wá sí ìyè.” Èlíjà dá ọmọ náà padà fún ìyá rẹ̀, ó sì sọ pé: “Wò ó, ọmọkùnrin rẹ yè.” Kí ni obìnrin náà wá ṣe? Tayọ̀tayọ̀ ló fi sọ pé: “Mo mọ̀ wàyí, ní tòótọ́, pé ìwọ jẹ́ ènìyàn Ọlọ́run àti pé ọ̀rọ̀ Jèhófà ní ẹnu rẹ jẹ́ òótọ́.”—1 Àwọn Ọba 17:22-24.
Nǹkan bí ọgọ́rùn-ún kìlómítà lápá gúúsù Sáréfátì ni tọkọtaya kan tí wọ́n jẹ́ ọ̀làwọ́ ń gbé. Àwọn ló tọ́jú wòlíì Èlíṣà tó rọ́pò wòlíì Èlíjà. Èyí ìyàwó jẹ́ obìnrin kan tó lókìkí gan-an ní Ṣúnẹ́mù ìlú rẹ̀. Òun àti ọkọ rẹ̀ gba Èlíṣà lálejò, wọ́n sì fi wòlíì náà sí ìyẹ̀wù òkè ilé wọn. Ìbànújẹ́ wọn nítorí àìrọ́mọbí wá dayọ̀ nígbà tí obìnrin náà bí ọmọkùnrin kan. Bí ọmọdékùnrin náà ṣe ń dàgbà, ó sábà máa ń tẹ̀ lé àwọn olùkórè lọ bá bàbá rẹ̀ lóko. Àmọ́, lọ́jọ́ kan ohun ìbànújẹ́ ṣẹlẹ̀. Ọmọdékùnrin náà lọgun pé orí ń fọ́ òun. Ìránṣẹ́ kan sì sáré gbé e padà sọ́dọ̀ ìyà rẹ̀ nílé. Ìyá rẹ̀ gbé e sórí itan rẹ̀ ó sì wà á mọ́ra, àmọ́ kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ọmọ náà kú. Ìyà tí ọkàn rẹ̀ dà rú yìí pinnu láti lọ pe Èlíṣà pé kó wá ran òun lọ́wọ́. Bí òun àti ìránṣẹ́ kan ṣe gbéra nìyẹn tí wọ́n forí lé ibi tí Èlíṣà ń gbé lápá àríwá ìwọ̀ oòrùn Òkè Ńlá Kámẹ́lì.
Wòlíì náà wá rán Géhásì tó jẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ síbẹ̀, ìyẹn sì rí i pé lóòótọ́ ni ọmọdékùnrin náà kú. Èlíṣà àti obìnrin náà wá forí lé ibẹ̀, àmọ́ kí ló ṣẹlẹ̀ nígbà tí wọ́n dé Ṣúnẹ́mù? Àkọsílẹ̀ inú 2 Àwọn Ọba 4:32-37 sọ pé: “Níkẹyìn, Èlíṣà wọnú ilé náà, kíyè sí i, ọmọdékùnrin náà ti kú, a tẹ́ ẹ sórí àga ìrọ̀gbọ̀kú rẹ̀. Nígbà náà ni ó wọlé, ó sì ti ilẹ̀kùn mọ́ àwọn méjèèjì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà sí Jèhófà. Níkẹyìn, ó gòkè lọ, ó sì dùbúlẹ̀ lé ọmọ náà, ó sì fi ẹnu tirẹ̀ lé ẹnu rẹ̀ àti ojú tirẹ̀ lé ojú rẹ̀ àti àtẹ́lẹwọ́ tirẹ̀ lé àtẹ́lẹwọ́ rẹ̀, ó sì tẹ̀ ba lé e lórí, kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ara ọmọ náà sì wá móoru. Lẹ́yìn náà, ó tún bẹ̀rẹ̀ sí rìn nínú ilé, lẹ́ẹ̀kan sí ìhà ìhín àti lẹ́ẹ̀kan sí ìhà ọ̀hún, lẹ́yìn èyí tí ó gòkè lọ, tí ó sì tẹ̀ ba lé e lórí. Ọmọdékùnrin náà sì bẹ̀rẹ̀ sí sín ní èyí tí ó tó ìgbà méje, lẹ́yìn èyí tí ọmọdékùnrin náà la ojú rẹ̀. Nígbà náà ni ó pe Géhásì, ó sì sọ pé: ‘Pe obìnrin ará Ṣúnẹ́mù yìí wá.’ Nítorí náà, ó pè é, ó sì wọlé tọ̀ ọ́ wá. Nígbà náà ni ó sọ pé: ‘Gbé ọmọkùnrin rẹ.’ Ó sì wọlé, ó sì wólẹ̀ níbi ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì tẹrí ba mọ́lẹ̀ fún un, lẹ́yìn èyí tí ó gbé ọmọkùnrin rẹ̀, ó sì jáde lọ.”
Bíi ti opó Sáréfátì yẹn ni obìnrin ará Ṣúnẹ́mù yìí náà ṣe mọ̀ pé agbára Ọlọ́run ló jẹ́ kí ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ṣeé ṣe. Inú àwọn obìnrin méjèèjì yìí dùn gan-an pé Ọlọ́run mú kí àwọn ọmọ wọn ọ̀wọ́n padà wà láàyè.
Àwọn Àjíǹde Tó Wáyé Lákòókò Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Jésù
Ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún [900] ọdún lẹ́yìn ìyẹn, àjíǹde kan tún wáyé ní ibì kan tí kò jìnnà sí apá àríwá Ṣúnẹ́mù nítòsí abúlé kan tí wọ́n ń pè ní Náínì. Bí Jésù Kristi àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ṣe ń rìnrìn àjò bọ̀ láti Kápánáúmù, ó kù díẹ̀ kí wọ́n dé ẹnubodè ìlú Náínì ni wọ́n pàdé àwọn èrò tó fẹ́ lọ sin òkú kan. Jésù sì rí opó kan níbẹ̀ tó jẹ́ pé ọmọkùnrin kan ṣoṣo tó bí ló kú yìí. Jésù sọ fún un pé kó má sunkún mọ́. Lúùkù tó jẹ́ oníṣègùn sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn, ó ní: “Pẹ̀lú èyíinì, [Jésù] sún mọ́ ọn, ó sì fọwọ́ kan agà ìgbókùú náà, àwọn tí wọ́n gbé e sì dúró jẹ́ẹ́, ó sì wí pé: ‘Ọ̀dọ́kùnrin, mo wí fún ọ, Dìde!’ Ọkùnrin tí ó ti kú náà sì dìde jókòó, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀, ó sì fi í fún ìyá rẹ̀.” (Lúùkù 7:14, 15) Àwọn tó rí iṣẹ́ ìyanu yìí fi ògo fún Ọlọ́run. Àwọn èèyàn tó wà lápá gúúsù ìlú Jùdíà àtàwọn àgbègbè tó yí i ká sì gbọ́ ìròyìn nípa àjíǹde náà. Kódà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù Olùbatisí náà gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n sì ròyìn iṣẹ́ ìyanu náà fún Jòhánù. Òun náà tún ní kí wọ́n wá Jésù lọ kí wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ bóyá òun ni Mèsáyà táwọn ń retí. Jésù sọ fún wọn pé: “Ẹ máa bá ọ̀nà yín lọ, ẹ ròyìn ohun tí ẹ rí, tí ẹ sì gbọ́ fún Jòhánù: àwọn afọ́jú ń ríran, àwọn arọ ń rìn, a ń wẹ àwọn adẹ́tẹ̀ mọ́, àwọn adití sì ń gbọ́ràn, a ń gbé àwọn òkú dìde, a ń sọ ìhìn rere fún àwọn òtòṣì.”—Lúùkù 7:22.
Èyí tí gbogbo èèyàn mọ̀ bí ẹni mowó lára Jòhánù 11:39) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ara Lásárù ti bà jẹ́, èyí kò dí àjíǹde náà lọ́wọ́. Nígbà tí Jésù pè é, “ọkùnrin tí ó ti kú náà jáde wá pẹ̀lú ẹsẹ̀ àti ọwọ́ rẹ̀ tí a fi àwọn aṣọ ìdìkú dì, ojú rẹ̀ ni a sì fi aṣọ dì yí ká.” Ohun táwọn ọ̀tá Jésù ṣe lẹ́yìn ìyẹn fẹ̀rí hàn kedere pé Lásárù tó kú ló padà wà láàyè.—Jòhánù 11:43, 44; 12:1, 9-11.
àwọn iṣẹ́ ìyanu àjíǹde tí Jésù ṣe ni ti Lásárù ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́. Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé Jésù ò tètè dé ilé Lásárù lẹ́yìn tí Lásárù kú. Ó ti pé ọjọ́ mẹ́rin tí Lásárù ti kú kí Jésù tó dé Bẹ́tánì. Nígbà tí Jésù sọ pé kí wọ́n gbé òkúta tí wọ́n fi bo ẹnu ibojì náà kúrò, Màtá lọ́ tìkọ̀, ó ní: “Olúwa, ní báyìí yóò ti máa rùn, nítorí ó di ọjọ́ mẹ́rin.” (Kí la lóye látinú àkọsílẹ̀ àjíǹde mẹ́rẹ̀ẹ̀rin yìí? Gbogbo àwọn tó jíǹde yìí ló tún rí bí wọ́n ṣe wà tẹ́lẹ̀. Gbogbo wọn làwọn èèyàn dá mọ̀, kódà àwọn mọ̀lẹ́bí wọn mọ̀ pé àwọn ni. Kò sí ọ̀kankan lára àwọn tó jíǹde náà tó sọ pé nǹkan báyìí ló ṣẹlẹ̀ láàárín àkókò kúkúrú tí wọ́n ò fi sí láàyè yẹn. Kò sí èyí tó sọ pé òun rìnrìn àjò lọ sí ayé mìíràn nínú wọn. Ara gbogbo wọn ló yá dáadáa nígbà tí wọ́n jíǹde. Lójú wọn, ńṣe ló dà bíi pé wọ́n sùn fúngbà díẹ̀ tí wọ́n sì jí, gẹ́gẹ́ bí Jésù ti sọ. (Jòhánù 11:11) Síbẹ̀, gbogbo wọn ló tún padà kú lẹ́yìn ìgbà díẹ̀.
Pípadà Rí Àwọn Èèyàn Wa Tó Ti Kú Jẹ́ Ohun Àgbàyanu Tá À Ń Retí
Ní àkókò díẹ̀ lẹ́yìn ikú Owen tó fa ìbànújẹ́ ńláǹlà, èyí tá a mẹ́nu kan nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, bàbá rẹ̀ lọ sílé aládùúgbò rẹ̀ kan. Ibẹ̀ ló ti rí ìwé pélébé kan lórí tábìlì, wọ́n fi ìwé yìí pe àwọn èèyàn wá síbi àsọyé kan táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣètò rẹ̀. Àkòrí àsọyé náà tí wọ́n pè ní, “Ibo ni Àwọn Òkú Wà?” wù ú gan-an. Ìbéèrè tó ti ń jà gùdù lọ́kàn rẹ̀ gan-an nìyẹn. Ó lọ síbi tí wọ́n ti sọ àsọyé náà, ó sì rí ojúlówó ìtùnú gbà látinú Bíbélì. Ó gbọ́ pé àwọn òkú kò jìyà níbì kankan. Wọn ò joró kankan nínú ọ̀run àpáàdì, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe pé Ọlọ́run mú wọn lọ láti di áńgẹ́lì lọ́run. Ńṣe ni gbogbo àwọn tó ti kú, títí kan Owen, ń sùn nínú ibojì tí wọ́n ń dúró dìgbà tí Ọlọ́run máa jí wọn dìde lákòókò àjíǹde àwọn òkú.—Oníwàásù 9:5, 10; Ìsíkíẹ́lì 18:4.
Ǹjẹ́ ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ nínú ìdílé rẹ rí? Bíi ti bàbá Owen, ǹjẹ́ ìwọ náà fẹ́ mọ̀ nípa ibi tí àwọn èèyàn rẹ tó ti kú wà, ṣé o sì tún fẹ́ mọ̀ bóyá ó lè ṣeé ṣe fún ọ láti padà rí wọn? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, a rọ̀ ọ́ láti gbé àwọn ohun mìíràn tí Bíbélì tún fi kọni nípa àjíǹde yẹ̀ wò. Ó ṣeé ṣe kó o máa bi ara rẹ pé: ‘Ìgbà wo ni àjíǹde náà máa wáyé? Àwọn wo gan-an ló máa jàǹfààní rẹ̀?’ Jọ̀wọ́ ka àwọn àpilẹ̀kọ tó kàn láti rí i bá a ṣe jíròrò àwọn ìbéèrè yìí àtàwọn ìbéèrè mìíràn.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo ìwé Mankind’s Search for God, ojú ìwé 150 sí 154. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló tẹ ìwé náà jáde.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Èlíjà bẹ Jèhófà pé kó dá ẹ̀mí ọmọdékùnrin kan padà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Jèhófà lo Èlíṣà láti jí ọmọ ará Ṣúnẹ́mù dìde
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Jésù jí ọmọ opó Náínì dìde
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àjíǹde yóò jẹ́ kí àwọn mọ̀lẹ́bí tún padà rí àwọn èèyàn wọn tó ti kú