Ẹ̀kọ́ Àjíǹde Kàn Ọ́
Ẹ̀kọ́ Àjíǹde Kàn Ọ́
“Mo sì ní ìrètí sọ́dọ̀ Ọlọ́run . . . pé àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.”—ÌṢE 24:15.
1. Báwo ni ọrọ̀ nípa àjíǹde ṣe dá wàhálà sílẹ̀ láàárín ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn?
JERÚSÁLẸ́MÙ ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù parí ìrìn àjò míṣọ́nnárì rẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kẹta sí ní ọdún 56 Sànmánì Tiwa. Lẹ́yìn táwọn ará Róòmù mú un, wọ́n jẹ́ kó jẹ́jọ́ níwájú ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn ti ilé ẹjọ́ gíga àwọn Júù. (Ìṣe 22:29, 30) Bí Pọ́ọ̀lù ṣe wo àwọn tó wà nínú ìgbìmọ̀ ilé ẹjọ́ náà, ó rí i pé Sadusí ni àwọn kan lára wọn, àwọn yòókù sì jẹ́ Farisí. Àwọn ẹgbẹ́ méjèèjì yìí yàtọ̀ sí ara wọn lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Àwọn Sadusí ò gbà pé àjíǹde wà, àmọ́ àwọn Farisí gbà pé ó wà. Káwọn èèyàn tó wà níbẹ̀ lè mọ̀ pé Pọ́ọ̀lù náà gbà pé àjíǹde wà, ó sọ pé: “Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ̀yin ará, Farisí ni mí, ọmọ àwọn Farisí. Lórí ìrètí àjíǹde àwọn òkú ni a ṣe ń dá mi lẹ́jọ́.” Ohun tó sọ yìí ò jẹ́ kí èrò àwùjọ náà ṣọ̀kan mọ́!—Ìṣe 23:6-9.
2. Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi múra tán láti ṣàlàyé ìgbàgbọ́ tó ní nínú àjíǹde?
2 Ní ọdún bíi mélòó kan ṣáájú àkókò yẹn, nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń lọ sí Damásíkù, ó rí ìran kan, ó sì gbọ́ ohùn Jésù nínú ìran náà. Pọ́ọ̀lù tiẹ̀ bi Jésù pé: “Kí ni kí n ṣe, Olúwa?” Jésù dá a lóhùn pé: “Dìde, bá ọ̀nà rẹ lọ sí Damásíkù, ibẹ̀ sì ni wọn yóò ti sọ fún ọ nípa ohun gbogbo tí a ti yàn kalẹ̀ fún ọ láti ṣe.” Nígbà tí Pọ́ọ̀lù dé Damásíkù, ọmọ ẹ̀yìn Jésù kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ananíà wá a kàn, ó ràn án lọ́wọ́, ó sì ṣàlàyé fún un pé: “Ọlọ́run àwọn baba ńlá wa ti yàn ọ́ láti wá mọ ìfẹ́ rẹ̀ àti láti rí Ẹni olódodo náà [ìyẹn Jésù tó jíǹde] àti láti gbọ́ ohùn ẹnu rẹ̀.” (Ìṣe 22:6-16) Abájọ tí Pọ́ọ̀lù fi múra tán láti ṣàlàyé ìgbàgbọ́ tó ní nínú àjíǹde.—1 Pétérù 3:15.
Pọ́ọ̀lù Polongo Ìrètí Àjíǹde
3, 4. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe fi hàn pé òun ò fọwọ́ kékeré mú ẹ̀kọ́ àjíǹde, kí la sì lè rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ rẹ̀?
3 Ẹ̀yìn ìgbà yẹn ni Pọ́ọ̀lù lọ jẹ́jọ́ níwájú Gómìnà Fẹ́líìsì. Ibi ìgbẹ́jọ́ náà ni Tẹ́túlọ́sì tó jẹ́ “olùbánisọ̀rọ̀ ní gbangba” tó sì ń ṣojú fún àwọn Júù, ti fẹ̀sùn kan Pọ́ọ̀lù pé ó jẹ́ aṣáájú ẹ̀ya ìsìn kan àti pé ó jẹ̀bi ìṣọ̀tẹ̀ síjọba. Pọ́ọ̀lù dá a lóhùn láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ pé: “Mo jẹ́wọ́ èyí fún ọ, pé, ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀nà tí wọ́n ń pè ní ‘ẹ̀ya ìsìn,’ ní ọ̀nà yìí ni mo gbà ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún Ọlọ́run àwọn baba ńlá mi.” Lẹ́yìn náà, ó wá padà sórí kókó pàtàkì tí wọ́n ń sọ bọ̀, ó ní: “Mo . . . ní ìrètí sọ́dọ̀ Ọlọ́run, ìrètí tí àwọn ọkùnrin yìí pẹ̀lú ní, pé àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.”—Ìṣe 23:23, 24; 24:1-8, 14, 15.
4 Nǹkan bí ọdún méjì lẹ́yìn ìyẹn ni Pọ́kíọ́sì Fẹ́sítọ́ọ̀sì tó gbapò lọ́wọ́ Fẹ́líìsì sọ fún Hẹ́rọ́dù Àgírípà Ọba pé kó jẹ́ káwọn jìjọ gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu Pọ́ọ̀lù tó jẹ́ ẹlẹ́wọ̀n nígbà náà. Fẹ́sítọ́ọ̀sì ṣàlàyé pé àwọn tó fẹ̀sùn kan Pọ́ọ̀lù ò gbà pé òótọ́ lóhun tó ń sọ pé “Jésù kan tí ó kú . . . wà láàyè.” Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ tẹnu rẹ̀, ó béèrè pé: “Èé ti rí tí a kà á sí ohun tí kò ṣeé gbà gbọ́ láàárín yín pé Ọlọ́run ń gbé àwọn òkú dìde?” Ó wá sọ pé: “Nítorí pé mo ti rí ìrànlọ́wọ́ tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run gbà, mo ń bá a lọ títí di òní yìí ní jíjẹ́rìí fún àti ẹni kékeré àti ẹni ńlá, ṣùgbọ́n èmi kò sọ nǹkan kan àyàfi àwọn ohun tí àwọn Wòlíì àti Mósè sọ pé yóò ṣẹlẹ̀, pé Kristi yóò jìyà àti pé, gẹ́gẹ́ bí ẹni àkọ́kọ́ tí a óò jí dìde kúrò nínú òkú, òun yóò kéde ìmọ́lẹ̀ fún àwọn ènìyàn yìí àti àwọn orílẹ̀-èdè.” (Ìṣe 24:27; 25:13-22; 26:8, 22, 23) Pọ́ọ̀lù mà kúkú gba ẹ̀kọ́ àjíǹde gbọ́ o, kò fọwọ́ kékeré mú un rárá! Bíi ti Pọ́ọ̀lù ló ṣe yẹ káwa náà máa fi ìdánilójú kéde pé àjíǹde yóò wà. Àmọ́ kí la lè retí látọ̀dọ̀ àwọn èèyàn tá a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àjíǹde? Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé báwọn èèyàn ti ṣe nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń wàásù ni wọ́n máa ṣe.
5, 6. (a) Kí làwọn èèyàn ṣe nígbà táwọn àpọ́sítélì tẹnu mọ́ ọ̀rọ̀ nípa àjíǹde? (b) Kí ló ṣe pàtàkì gan-an fún wa bá a ti ń sọ̀rọ̀ nípa ìrètí àjíǹde fáwọn èèyàn?
5 Gbé ohun tó ṣẹlẹ̀ ṣáájú àkókò yẹn yẹ̀ wò, nígbà tí Pọ́ọ̀lù lọ sí Áténì lákòókò tó wà lẹ́nu ìrìn àjò míṣọ́nnárì ẹlẹ́ẹ̀kejì tó rìn (ní nǹkan bí ọdún 49 sí 52 Sànmánì Tiwa). Ó bá àwọn tó ń bọ onírúurú òrìṣà fèrò wérò, ó sì rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n kíyè sí i pé Ọlọ́run ti pinnu láti ṣèdájọ́ ilẹ̀ ayé ní òdodo nípasẹ̀ ọkùnrin kan tí Òun ti yàn. Èyí kì í sì í ṣe ẹlòmíràn bí kò ṣe Jésù. Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé Ọlọ́run ti fún wa ní ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro nípa èyí ní ti pé ó jí Jésù dìde kúrò nínú ikú. Kí làwọn èèyàn náà ṣe nígbà tí wọ́n gbọ́ bẹ́ẹ̀? Ẹsẹ náà kà pé: “Tóò, nígbà tí wọ́n gbọ́ nípa àjíǹde àwọn òkú, àwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ẹlẹ́yà, nígbà tí àwọn mìíràn wí pé: ‘Dájúdájú, àwa yóò gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ nípa èyí àní ní ìgbà mìíràn.’”—Ìṣe 17:29-32.
6 Bí wọ́n ti ṣe yẹn ò yàtọ̀ sí ohun tójú Pétérù àti Jòhánù rí kété lẹ́yìn Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa. Lákòókò yẹn náà, àwọn Sadusí ló jẹ́ abẹnugan nínú àríyànjiyàn yẹn. Ìwé Ìṣe 4:1-4 sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún wa pé: “Wàyí o, bí àwọn méjèèjì ti ń bá àwọn ènìyàn náà sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, àwọn olórí àlùfáà àti olórí ẹ̀ṣọ́ tẹ́ńpìlì àti àwọn Sadusí dé bá wọn, inú ń bí wọn nítorí pé wọ́n ń kọ́ àwọn ènìyàn náà, tí wọ́n sì ń polongo ní kedere àjíǹde kúrò nínú òkú ní ti ọ̀ràn Jésù.” Àmọ́, àwọn yòókù fi ọkàn tó dára gba ọ̀rọ̀ náà. “Ọ̀pọ̀ lára àwọn tí wọ́n ti fetí sí ọ̀rọ̀ náà gbà gbọ́, iye àwọn ọkùnrin náà sì di nǹkan bí ẹgbẹ̀rún márùn-ún.” Láìsí àní-àní, a ò lè retí pé kí gbogbo èèyàn fara mọ́ ọ̀rọ̀ wa nígbà tá a bá ń sọ pé àwọn òkú yóò jíǹde. Nítorí bẹ́ẹ̀, ó ṣe pàtàkì gan-an ká jẹ́ kí ìgbàgbọ́ tá a ní nínú ẹ̀kọ́ yìí lágbára.
Ìgbàgbọ́ Ṣe Pàtàkì Láti Gbà Pé Àjíǹde Wà
7, 8. (a) Gẹ́gẹ́ bí ohun tó wà nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí ìjọ Kọ́ríńtì ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣe fi hàn, báwo ni ìgbàgbọ́ ẹnì kan ṣe lè jẹ́ asán? (b) Báwo ni òye tó jinlẹ̀ nípa àjíǹde ṣe mú kí ìsìn Kristẹni tòótọ́ yàtọ̀?
7 Kì í ṣe gbogbo àwọn tó di Kristẹni ní ọ̀gọ́rùn-ún ọdún kìíní ló rọrùn fún láti gbà pé àjíǹde yóò wà. Ó ṣòro fáwọn kan nínú ìjọ Kọ́ríńtì láti gba ẹ̀kọ́ yìí. Àwọn ni Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí pé: “Mo fi lé yín lọ́wọ́, lára àwọn ohun àkọ́kọ́, èyíinì tí èmi pẹ̀lú gbà, pé Kristi kú fún ẹ̀ṣẹ̀ wa gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí; àti pé a sin ín, bẹ́ẹ̀ ni, pé a ti gbé e dìde ní ọjọ́ kẹta gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí.” Pọ́ọ̀lù wá fi ẹ̀rí ti òtítọ́ yìí lẹ́yìn, ó sọ pé Kristi tí a jí dìde náà “fara han èyí tí ó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta àwọn ará,” àti pé ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó fara hàn náà ṣì wà láàyè ní àkókò tó ń sọ̀rọ̀ yẹn. (1 Kọ́ríńtì 15:3-8) Ó sì tún sọ fún wọn pé: “Bí a bá ń wàásù Kristi pé a ti gbé e dìde kúrò nínú òkú, èé ti rí tí àwọn kan láàárín yín fi ń sọ pé kò sí àjíǹde àwọn òkú? Ní tòótọ́, bí kò bá sí àjíǹde àwọn òkú, a jẹ́ pé a kò tíì gbé Kristi dìde. Ṣùgbọ́n bí a kò bá tíì gbé Kristi dìde, dájúdájú, asán ni ìwàásù wa, asán sì ni ìgbàgbọ́ wa.”—1 Kọ́ríńtì 15:12-14.
8 Bẹ́ẹ̀ ni o, ẹ̀kọ́ àjíǹde ṣe pàtàkì gan-an débi pé asán ni ìgbàgbọ́ àwa Kristẹni tá ò bá gbà pé lóòótọ́ ni àjíǹde yóò wà. Láìsí àní-àní, òye tó jinlẹ̀ nípa àjíǹde mú káwọn Kristẹni tòótọ́ yàtọ̀ sáwọn èké Kristẹni. (Jẹ́nẹ́sísì 3:4; Ìsíkíẹ́lì ) Abájọ tí Pọ́ọ̀lù fi sọ pé ẹ̀kọ́ àjíǹde wà lára “àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́” ìsìn Kristẹni. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká pinnu pé a ó máa “tẹ̀ síwájú sí ìdàgbàdénú.” Pọ́ọ̀lù sì gbà wá níyànjú pé: “Èyí ni àwa yóò ṣe, bí Ọlọ́run bá yọ̀ǹda ní tòótọ́.”— 18:4Hébérù 6:1-3.
Ìrètí Wà Pé Àwọn Òkú Yóò Jíǹde
9, 10. Kí ni ọ̀rọ̀ náà “àjíǹde” túmọ̀ sí nínú Bíbélì?
9 Kí ìgbàgbọ́ tá a ní pé àjíǹde ń bọ̀ lè túbọ̀ lágbára sí i, ẹ jẹ́ ká gbé àwọn ìbéèrè wọ̀nyí yẹ̀ wò. Ìyẹn àwọn ìbéèrè bíi: Kí ni ọ̀rọ̀ náà “àjíǹde” túmọ̀ sí nínú Bíbélì? Báwo ni ẹ̀kọ́ àjíǹde ṣe fi ìfẹ́ Jèhófà hàn? Ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí yóò mú ká túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run yóò sì tún ràn wá lọ́wọ́ láti fi ẹ̀kọ́ àjíǹde kọ́ àwọn ẹlòmíràn.—2 Tímótì 2:2; Jákọ́bù 4:8.
10 Ọ̀rọ̀ náà “àjíǹde” ni wọ́n fi túmọ̀ ọ̀rọ̀ Gíríìkì kan tó túmọ̀ sí “dídìde dúró lẹ́ẹ̀kan sí i.” Kí ni gbólóhùn yẹn túmọ̀ sí? Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti wí, ìrètí àjíǹde ni pé kí ẹnì kan ni ìdánilójú pé ẹnì tó ti kú yóò tún padà wà láàyè. Bíbélì tún jẹ́ ká mọ̀ pé ẹni náà lè jíǹde pẹ̀lú ara èèyàn tàbí pẹ̀lú ara tó jẹ́ tẹ̀mí. Ó sinmi lórí ìrètí tí onítọ̀hún ní, yálà ìrètí láti gbé lórí ilẹ̀ ayé ni tàbí ìrètí láti lọ sí ọ̀run. Ìyàlẹ́nu ló máa ń jẹ́ fún wa tá a bá ronú nípa bí àgbàyanu ìrètí tá a ní pé àjíǹde ń bọ̀ ṣe fi ìfẹ́, ọgbọ́n, àti agbára Jèhófà hàn.
11. Irú àjíǹde wo làwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run tó jẹ́ ẹni àmì òróró ń retí?
11 Àjíǹde Jésù àti ti àwọn ẹni àmì òróró arákùnrin rẹ̀ yóò jẹ́ kí wọ́n ní ara tẹ̀mí tí yóò mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn lọ́run. (1 Kọ́ríńtì 15:35-38, 42-53) Jésù àtàwọn ẹni àmì òróró wọ̀nyí ni yóò jùmọ̀ jẹ́ alákòóso nínú Ìjọba Mèsáyà náà, èyí tí yóò sọ ilẹ̀ ayé di Párádísè. Àwọn ẹni àmì òróró náà á para pọ̀ di ẹgbẹ́ àlùfáà aládé lábẹ́ Jésù tó jẹ́ Àlùfáà Àgbà. Wọ́n á mú kí ìran ènìyàn jàǹfààní ẹbọ ìràpadà Kristi nínú ayé tuntun tí òdodo yóò wà. (Hébérù 7:25, 26; 9:24; 1 Pétérù 2:9; Ìṣípayá 22:1, 2) Ní báyìí ná, àwọn ẹni àmì òróró tó ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé fẹ́ kínú Ọlọ́run máa dùn sí wọn nígbà gbogbo. Nígbà tí wọ́n bá kú, wọ́n á gba “èrè” wọn nípasẹ̀ àjíǹde sí ọ̀run gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí tí kò lè kú mọ́. (2 Kọ́ríńtì 5:1-3, 6-8, 10; 1 Kọ́ríńtì 15:51, 52; Ìṣípayá 14:13) Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Bí a bá ti di sísopọ̀ ṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀ ní ìfarajọ ikú rẹ̀, dájúdájú, a ó so wá pọ̀ ṣọ̀kan pẹ̀lú rẹ̀ ní ìfarajọ àjíǹde rẹ̀ pẹ̀lú.” (Róòmù 6:5) Àmọ́, àwọn tí àjíǹde tiwọn yóò mú kí wọ́n tún padà wà láàyè lórí ilẹ̀ ayé ńkọ́? Báwo ni ìrètí àjíǹde ṣe lè mú àwọn náà túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run? A lè rí ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ kọ́ látinú àpẹẹrẹ Ábúráhámù.
Àjíǹde Dájú Tá A Bá Jẹ́ Ọ̀rẹ́ Jèhófà
12, 13. Ìdí tó lágbára wo ló mú kí Ábúráhámù gbà pé àjíǹde ń bọ̀?
12 Ábúráhámù tí Bíbélì pè ní “ọ̀rẹ́ Jèhófà” jẹ́ ọkùnrin tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ kò lẹ́gbẹ́. (Jákọ́bù 2:23) Ẹ̀ẹ̀mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Pọ́ọ̀lù mẹ́nu kan ìgbàgbọ́ Ábúráhámù níbi tó ti sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọkùnrin àti obìnrin tó jẹ́ olóòótọ́ nínú orí kọkànlá ìwé Hébérù. (Hébérù 11:8, 9, 17) Nígbà kẹta tí Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ Ábúráhámù, ó gbé e ka bó ṣe múra tán láti fi Ísákì ọmọ rẹ̀ rúbọ. Ó dá Ábúráhámù lójú pé Jèhófà fúnra rẹ̀ ló fọwọ́ sọ̀yà pé, ipasẹ̀ Ísákì ni irú ọmọ tá a ṣèlérí náà yóò ti wá. Ábúráhámù mọ̀ pé bóun tiẹ̀ fi Ísákì rúbọ tí ọmọ náà sì kú pàápàá, “Ọlọ́run lè gbé e dìde, àní kúrò nínú òkú.”
13 Nígbà tí Jèhófà rí bí ìgbàgbọ́ Ábúráhámù ṣe lágbára tó, ó ṣètò pé kó fi ẹran kan rúbọ dípò ọmọ rẹ̀. Síbẹ̀, ńṣe ni ọ̀ràn Ísákì yìí ń ṣàpèjúwe àjíǹde, gẹ́gẹ́ bí àlàyé Pọ́ọ̀lù tó sọ pé: “Láti ibẹ̀, ó [Ábúráhámù] sì tún rí i [Ísákì] gbà lọ́nà àpèjúwe.” (Hébérù 11:19) Ìyẹn nìkan kọ́ o, ìdí tó lágbára kan tún wà tó mú kí Ábúráhámù gbà pé àjíǹde wà. Ṣebí Jèhófà ló sọ agbára Ábúráhámù dọ̀tun tí òun àti Sárà aya rẹ̀ fi lè bí Ísákì ọmọ wọn ní ọjọ́ ogbó wọn, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?—Jẹ́nẹ́sísì 18:10-14; 21:1-3; Róòmù 4:19-21.
14. (a) Ní ìbámu pẹ̀lú Hébérù 11:9, 10, kí ni Ábúráhámù ń dúró dè? (b) Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí Ábúráhámù lọ́jọ́ iwájú kó tó lè rí ìbùkún Ìjọba náà gbà nínú ayé tuntun? (d) Kí ló máa jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti rí ìbùkún Ìjọba náà gbà?
14 Pọ́ọ̀lù fi Ábúráhámù wé àtìpó àti ẹni tó ń gbé inú àgọ́ tó “ń dúró de ìlú ńlá tí ó ní àwọn ìpìlẹ̀ tòótọ́, ìlú ńlá tí olùtẹ̀dó àti olùṣẹ̀dá rẹ̀ jẹ́ Ọlọ́run.” (Hébérù 11:9, 10) Èyí kì í ṣe ìlú ńlá kan tá a lè fojú rí bíi Jerúsálẹ́mù tí tẹ́ńpìlì Ọlọ́run wà o. Àpẹẹrẹ ni wọ́n fi ìlú ńlá náà ṣe. Ìjọba ọ̀run ti Ọlọ́run ni, tí Kristi Jésù àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì máa jùmọ̀ ṣàkóso rẹ̀. Àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì yìí là ń pè ní “ìlú ńlá mímọ́ náà,” “Jerúsálẹ́mù Tuntun” àti “ìyàwó” Kristi, nínú ògo wọn ní ọ̀run. (Ìṣípayá 21:2) Ní ọdún 1914, Jèhófà gbé Jésù gorí ìtẹ́ gẹ́gẹ́ bí Mèsáyà Ọba nínú Ìjọba ti ọ̀run ó sì pàṣẹ fún un pé kó máa ṣàkóso láàárín àwọn ọ̀tá rẹ̀. (Sáàmù 110:1, 2; Ìṣípayá 11:15) Kí Ábúráhámù, “ọ̀rẹ́ Jèhófà” tó lè rí ìbùkún Ìjọba náà gbà, ó ní láti padà wà láàyè. Tí àwa náà bá fẹ́ rí ìbùkún Ìjọba náà gbà, a ní láti wà láàyè nínú ayé tuntun Ọlọ́run, yálà ká wà lára àwọn ogunlọ́gọ̀ ńlá tó máa la Amágẹ́dọ́nì já tàbí ká wà lára àwọn tí a ó jí dìde kúrò nínú ikú. (Ìṣípayá 7:9, 14) Àmọ́, kí ló mú kí Ọlọ́run ṣètò fún àjíǹde?
Ìfẹ́ Ló Mú Kí Ọlọ́run Ṣètò Pé Kí Àjíǹde Àwọn Òkú Wà
15, 16. (a) Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́ pàá nínú Bíbélì ṣe jẹ́ ká nírètí pé àwọn òkú á jíǹde? (b) Báwo ni ìgbàgbọ́ tá a ní pé àjíǹde ń bọ̀ ṣe lè mú wa túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà?
15 Àjọṣe tímọ́tímọ́ tá a ní pẹ̀lú Bàbá wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́, ìgbàgbọ́ wa tó lágbára bíi ti Ábúráhámù, àti ìgbọràn wa sí àṣẹ Ọlọ́run ni yóò jẹ́ kí Jèhófà pè wá ní olódodo tí yóò sì kà wá sí ọ̀rẹ́ rẹ̀. Èyí ni yóò mú kó ṣeé ṣe fún wa láti jàǹfààní látinú ohun tí Ìjọba rẹ̀ yóò ṣe fún aráyé. Ní ti tòótọ́, àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, èyí tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 3:15, fún wa ní ìdí pàtàkì tó fi yẹ ká nírètí pé àjíǹde àwọn òkú ń bọ̀ ká sì bá Ọlọ́run dọ́rẹ̀ẹ́. Kì í ṣe pé ó wulẹ̀ sọ nípa bí a óò ṣe fọ́ Sátánì lórí nìkan, àmọ́ ó tún sọ nípa bí irú ọmọ Sátánì yóò ṣe pa Irú Ọmọ obìnrin Ọlọ́run ní gìgísẹ̀. Ikú Jésù lórí òpó igi ni pípa á ní gìgísẹ̀ yìí túmọ̀ sí. Àjíǹde rẹ̀ ní ọjọ́ kẹta ló wo ọgbẹ́ náà sàn, òun ló sì jẹ́ kó ṣeé ṣe láti ṣe ìdájọ́ tó tọ́ fún “ẹni tí ó ní ọ̀nà àtimú ikú wá,” ìyẹn “Èṣù.”—Hébérù 2:14.
16 Pọ́ọ̀lù rán wa létí pé “Ọlọ́run dámọ̀ràn ìfẹ́ tirẹ̀ fún wa ní ti pé, nígbà tí àwa ṣì jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀, Kristi kú fún wa.” (Róòmù 5:8) Mímọyì inú rere tí a kò lẹ́tọ̀ọ́ sí yìí ń mú ká sún mọ́ Jésù àti Bàbá wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ ní ti tòótọ́.—2 Kọ́ríńtì 5:14, 15.
17. (a) Ìrètí wo ni Jóòbù fi hàn pé òun ní? (b) Kí ni ìwé Jóòbù 14:15 fi hàn nípa Jèhófà, báwo ni ọ̀rọ̀ náà sì ṣe rí lára rẹ?
17 Jóòbù, ọkùnrin olóòótọ́ tó gbé ayé ṣáájú àkókò àwọn Kristẹni náà gbà pé àjíǹde ń bọ̀. Sátánì fojú rẹ̀ rí màbo. Àmọ́, Jóòbù ò dà bí àwọn èké ọ̀rẹ́ rẹ̀, tí wọn ò sọ̀rọ̀ nípa àjíǹde rárá. Ńṣe ni ìrètí pé àwọn òkú á jíǹde tu Jóòbù nínú tó sì béèrè pé: “Bí abarapá ènìyàn bá kú, ó ha tún lè wà láàyè bí?” Jóòbù fúnra rẹ̀ dáhùn ìbéèrè yìí, ó ní: “Gbogbo ọjọ́ òpò tí mo ní láti ṣe lápàpàǹdodo ni èmi yóò fi dúró, títí ìtura mi yóò fi dé.” Ó wá sọ fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ pé: “Ìwọ yóò pè, èmi fúnra mi yóò sì dá ọ lóhùn.” Nígbà tí Jóòbù ń sọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára Ẹlẹ́dàá wa onífẹ̀ẹ́, ó sọ pé: “Ìwọ yóò ṣe àfẹ́rí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.” (Jóòbù 14:14, 15) Dájúdájú, Jèhófà ń wọ̀nà lójú méjèèjì de ìgbà tí àwọn olóòótọ́ yóò tún padà wà láàyè nígbà àjíǹde àwọn òkú. Ẹ ò rí i pé bá a ti ń ṣàṣàrò lórí ìfẹ́ àti inú rere tí a kò lẹ́tọ̀ọ́ sí tí Jèhófà fi hàn sí wa, ńṣe lèyí túbọ̀ ń mú wa sún mọ́ ọn gan-an, bá a tiẹ̀ jẹ́ aláìpé!—Róòmù 5:21; Jákọ́bù 4:8.
18, 19. (a) Kí ló jẹ́ kí Dáníẹ́lì nírètí pé òun yóò tún padà wà láàyè? (b) Kí la ó ṣì gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó ń bọ̀?
18 Wòlíì Dáníẹ́lì tí áńgẹ́lì Ọlọ́run pè ní “ọkùnrin fífani-lọ́kàn-mọ́ra gidigidi,” fi ìṣòtítọ́ sin Ọlọ́run fún ọ̀pọ̀ ọdún. (Dáníẹ́lì 10:11, 19) Ìwà títọ́ rẹ̀ sí Jèhófà kò bà jẹ́ ní gbogbo ìgbà tó fi wà nígbèkùn, láti ọdún 617 ṣáájú Sànmánì Tiwa títí tó fi kú lẹ́yìn tó rí ìran kan ní ọdún 536 ṣáájú Sànmánì Tiwa, ìyẹn lọ́dún kẹta Kírúsì Ọba Páṣíà. (Dáníẹ́lì 1:1; 10:1) Nígbà kan, láàárín ọdún kẹta ìṣàkóso Dáríúsì, Dáníẹ́lì rí ìran kan nípa bí àwọn ìjọba ayé ṣe tò tẹ̀ léra wọn, títí tó fi parí sí ìgbà ìpọ́njú ńlá tó ń bọ̀. (Dáníẹ́lì 11:1–12:13) Nítorí pé Dáníẹ́lì kò lóye ìran náà dáadáa, ó béèrè lọ́wọ́ áńgẹ́lì tó wá jíṣẹ́ náà fún un pé: “Olúwa mi, kí ni yóò jẹ́ apá ìgbẹ̀yìn nǹkan wọ̀nyí?” Nígbà tí áńgẹ́lì náà ń dáhùn ìbéèrè rẹ̀ yìí, ó tọ́ka sí “àkókò òpin,” ní àkókò tí “àwọn tí ó ní ìjìnlẹ̀ òye yóò lóye.” Kí ni ìrètí Dáníẹ́lì ní tiẹ̀? Áńgẹ́lì náà là á mọ́lẹ̀ pé: “Ìwọ yóò sì sinmi, ṣùgbọ́n ìwọ yóò dìde fún ìpín rẹ ní òpin àwọn ọjọ́.” (Dáníẹ́lì 12:8-10, 13) Dáníẹ́lì yóò padà wá nígbà “àjíǹde àwọn olódodo,” lákòókò Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi.—Lúùkù 14:14.
19 Apá ìparí àkókò òpin la wà yìí, a sì ti sún mọ́ ìbẹ̀rẹ̀ Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi ju ti ìgbà tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ di onígbàgbọ́. Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ máa bi ara wa pé, ‘Ǹjẹ́ màá wà nínú ayé tuntun náà kí èmi àti Ábúráhámù, Jóòbù, Dáníẹ́lì, àtàwọn ọkùnrin àti obìnrin yòókù tó jẹ́ olóòótọ́ lè jọ sọ̀rọ̀?’ A óò wà níbẹ̀ tá a bá sún mọ́ Jèhófà tá a sì ṣègbọràn sí àwọn àṣẹ rẹ̀. A óò tún ọ̀rọ̀ nípa ìrètí àjíǹde gbé yẹ̀ wò kúnnákúnná nínú àpilẹ̀kọ wa tó tẹ̀ lé èyí ká lè mọ àwọn tí a óò jíǹde.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Kí làwọn èèyàn ṣe nígbà tí Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa ìrètí tó ní nínú àjíǹde?
• Ọ̀nà wo ni ìrètí àjíǹde fi mú káwọn Kristẹni tòótọ́ yàtọ̀ sáwọn èké Kristẹni?
• Báwo lá ṣe mọ̀ pé Ábúráhámù, Jóòbù, àti Dáníẹ́lì gbà gbọ́ pé àjíǹde àwọn òkú wà?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
Nígbà tí Pọ́ọ̀lù wà níwájú Gómìnà Fẹ́líìsì, ó fi ìdánilójú kéde ìrètí tó ní pé àwọn òkú á jíǹde
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Kí ló mú kí Ábúráhámù gbà gbọ́ pé àjíǹde ń bọ̀?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Ìrètí pé àwọn òkú á jíǹde tu Jóòbù nínú
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Dáníẹ́lì yóò padà wá nígbà àjíǹde àwọn olódodo