Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi kọ̀wé nípa aya tó jẹ́ Kristẹni pé: “A ó pa á mọ́ láìséwu nípasẹ̀ ọmọ bíbí”?—1 Tímótì 2:15.
Kí ni àwọn ọ̀rọ̀ tó yí ẹsẹ yìí ká fi hàn pé Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn? Bí ẹ̀mí mímọ́ ṣe darí rẹ̀, ńṣe ló ń fún àwọn obìnrin tó jẹ́ Kristẹni nímọ̀ràn nípa bó ṣe yẹ kí wọ́n máa ṣe nínu ìjọ. Ó kọ̀wé pé: “Mo ní ìfẹ́-ọkàn pé kí àwọn obìnrin máa fi aṣọ tí ó wà létòletò ṣe ara wọn lọ́ṣọ̀ọ́, pẹ̀lú ìmẹ̀tọ́mọ̀wà àti ìyèkooro èrò inú, kì í ṣe pẹ̀lú àwọn àrà irun dídì àti wúrà tàbí péálì tàbí aṣọ àrà olówó ńlá gan-an, ṣùgbọ́n lọ́nà tí ó yẹ àwọn obìnrin tí ó jẹ́wọ́ gbangba pé wọn ń fi ọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run, èyíinì ni, nípasẹ̀ àwọn iṣẹ́ rere.” (1 Tímótì 2:9, 10) Pọ́ọ̀lù ń rọ àwọn obìnrin tó jẹ́ Kristẹni pé kí wọ́n máa wà níwọ̀ntúnwọ̀nsì, kí wọ́n má ṣe ṣàṣejù nínú ìmúra wọn, kí wọ́n sì máa fi iṣẹ́ rere ṣe ara wọn ‘lọ́ṣọ̀ọ́.’
Lẹ́yìn ìyẹn, Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé nípa ipò orí nínú ìjọ, ó sọ pé: “Èmi kò gba obìnrin láyè láti kọ́ni, tàbí láti lo ọlá àṣẹ lórí ọkùnrin, bí kò ṣe láti wà ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́.” (1 Tímótì 2:12; 1 Kọ́ríńtì 11:3) Ó ṣàlàyé ìdí tí ètò náà fi rí bẹ́ẹ̀, ó ní Sátánì kò tan Ádámù jẹ, àmọ́ ó ‘tan Éfà jẹ pátápátá, ó sì wá wà nínú ìrélànàkọjá.’ Kí ni kò ní jẹ́ kí obìnrin tó jẹ́ Kristẹni dá irú ẹ̀ṣẹ̀ tí Éfà dá? Pọ́ọ̀lù dáhùn pé: “Bí ó ti wu kí ó rí, a ó pa á mọ́ láìséwu nípasẹ̀ ọmọ bíbí, bí ó bá ṣe pé wọn ń bá a lọ nínú ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ àti ìsọdimímọ́ pa pọ̀ pẹ̀lú ìyèkooro èrò inú.” (1 Tímótì 2:14, 15) Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn tó fi sọ ọ̀rọ̀ yìí?
Ó jọ pé ohun táwọn atúmọ̀ èdè kan ń sọ ni pé ó pọn dandan kí obìnrin bímọ kó tó lè rí ìgbàlà. Bí àpẹẹrẹ, Bibeli Mimọ sọ pé: “A o gbà a là nípa ibimọ rẹ.” Àmọ́ ṣá o, ṣíṣàlàyé ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù lọ́nà yẹn kù díẹ̀ káàtó. Ohun tí ọ̀pọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ sọ ni pé kéèyàn tó lè rí ìgbàlà ó ní láti mọ Jèhófà, kó gba Jésù gbọ́, kó ní ìgbàgbọ́, kó sì fi ìgbàgbọ́ náà hàn nípa iṣẹ́. (Jòhánù 17:3; Ìṣe 16:30, 31; Róòmù 10:10; Jákọ́bù 2:26) Àti pé Pọ́ọ̀lù ò sọ pé bí obìnrin kan bá ṣáà ti jẹ́ onígbàgbọ́, á bímọ láìséwu. Ọ̀pọ̀ obìnrin ló ti bímọ láìsí wàhálà kankan yálà wọ́n jẹ́ onígbàgbọ́ tàbí aláìgbàgbọ́. Ó sì ṣeni láàánú pé, àwọn kan ti kú nígbà tí wọ́n ń bímọ lọ́wọ́, yálà wọ́n jẹ́ onígbàgbọ́ tàbí aláìgbàgbọ́.—Jẹ́nẹ́sísì 35:16-18.
Ìmọ̀ràn mìíràn tí Pọ́ọ̀lù tún fún àwọn obìnrin nínú lẹ́tà yẹn kan náà ló jẹ́ ká mọ ohun tó ní lọ́kàn. Ó sọ nípa àwọn opó kan tí wọ́n ṣì kéré lọ́jọ́ orí tí wọ́n jẹ́ “olóòrayè, [tí] wọ́n ń rin ìrìn ìranù kiri lọ sí àwọn ilé; bẹ́ẹ̀ ni, kì í ṣe aláìníṣẹ́ nìkan, ṣùgbọ́n olófòófó pẹ̀lú àti alátojúbọ àlámọ̀rí àwọn ẹlòmíràn, wọ́n ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí kò yẹ kí wọ́n sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.” Ìmọ̀ràn wo ni Pọ́ọ̀lù ń fúnni nínú ọ̀rọ̀ tó sọ yìí? Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Nítorí náà, mo fẹ́ kí àwọn opó tí ó kéré ní ọjọ́ orí ṣe ìgbéyàwó, kí wọ́n bímọ, kí wọ́n mójú tó agbo ilé kan, kí wọ́n má ṣe fún alátakò ní ìsúnniṣe kankan láti kẹ́gàn.”—1 Tímótì 5:13, 14.
Ipa rere tí obìnrin ń kó nínú ètò ìdílé ni Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Nígbà tí obìnrin kan bá ń ṣe àwọn nǹkan bíi, ‘títọ́ ọmọ àti mímójú tó agbo ilé,’ bí ó ti ń tẹ̀ síwájú “nínú ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ àti ìsọdimímọ́ pa pọ̀ pẹ̀lú ìyèkooro èrò inú” kò ní lè lọ́wọ́ nínú ìwà tí kò dára. Ipò tẹ̀mí rẹ̀ kò ní yingin, ìyẹn ni pé a “pa [ipò tẹ̀mí rẹ̀] mọ́ láìséwu.”(1 Tímótì 2:15) Ṣíṣe irú àwọn ohun wọ̀nyẹn yóò ran àwọn obìnrin tí wọn ò tíì dàgbà púpọ̀ lọ́wọ́ láti yàgò fún àwọn páńpẹ́ Sátánì.
Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù kọ sí Tímótì rán gbogbo wa létí, lọ́kùnrin lóbìnrin, pé ó yẹ ká máa lo àkókò wa lọ́nà rere. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gbà gbogbo àwa Kristẹni nímọ̀ràn pé: “Ẹ máa ṣọ́ra lójú méjèèjì pé bí ẹ ṣe ń rìn kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n.”—Éfésù 5:15.