Bá A Ṣe Lè Máa Lo Ọjọ́ Kọ̀ọ̀kan Lọ́nà Rere
Bá A Ṣe Lè Máa Lo Ọjọ́ Kọ̀ọ̀kan Lọ́nà Rere
“FI HÀN wá, àní bí àwa yóò ṣe máa ka àwọn ọjọ́ wa ní irú ọ̀nà tí a ó fi lè jèrè ọkàn-àyà ọgbọ́n.” (Sáàmù 90:12) Èyí ni àdúrà onírẹ̀lẹ̀ tí Mósè tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì gbà. Kí ni ohun náà gan-an tó ń fẹ́ tó fi gbàdúrà yìí? Ǹjẹ́ ó yẹ kí àwa náà máa fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ gbàdúrà fún ohun kan náà?
Ní ẹsẹ kẹwàá, Mósè kédàárò nípa bí ọjọ́ ayé èèyàn ṣe kúrú tó. Nígbà kan, ó kọ ọ̀rọ̀ Jóòbù sílẹ̀, ẹni tó sọ pé: “Ènìyàn, tí obìnrin bí, ọlọ́jọ́ kúkúrú ni, ó sì kún fún ṣìbáṣìbo.” (Jóòbù 14:1) Ó hàn gbangba pé ó dun Mósè gan-an pé ẹ̀mí àwa èèyàn aláìpé kúrú gan-an. Nítorí náà, ó wò ó pé ẹ̀bùn iyebíye ni ọjọ́ kọ̀ọ̀kan jẹ́. Nígbà tí Mósè ń gbàdúrà sí Ọlọ́run, ó sọ pé òun fẹ́ lo ìyókù ọjọ́ ayé òun lọ́nà rere, ìyẹn lọ́nà tí yóò wu Ẹlẹ́dàá rẹ̀. Ǹjẹ́ kò yẹ káwa náà máa wá ọ̀nà láti lo ọjọ́ kọ̀ọ̀kan lọ́nà rere? Ohun tó yẹ ká sapá láti ṣe nìyẹn tá a bá fẹ́ rí ojú rere Ọlọ́run lákòókò tá a wà yìí.
Ohun mìíràn tún wà tó sún Mósè àti Jóòbù láti ṣe ohun tó tọ́, ohun yìí náà ló sì yẹ kó máa sún àwa náà ṣe ohun tó tọ́. Àwọn ọkùnrin méjèèjì tó bẹ̀rù Ọlọ́run yìí ń wọ̀nà fún èrè kan lọ́jọ́ iwájú, ìyẹn wíwà láàyè lórí ilẹ̀ ayé níbi tí gbogbo nǹkan yóò ti dára gan-an. (Jóòbù14:14, 15; Hébérù 11:26) Ní àkókò yẹn, kò sí ẹnì kankan tí ikú yóò fòpin sí iṣẹ́ rere rẹ̀ mọ́. Ẹlẹ́dàá wa ti sọ pé àwọn olóòótọ́ yóò máa gbénú Párádísè orí ilẹ̀ ayé títí láé. (Aísáyà 65:21-24; Ìṣípayá 21:3, 4) Èyí lè jẹ́ ìrètí tìrẹ náà tó o bá ‘ń ka àwọn ọjọ́ rẹ ní irú ọ̀nà tí wàá fi lè jèrè ọkàn ọgbọ́n.’