Báwo Ni Ìgbàgbọ́ Nínú Àjíǹde Ṣe Jinlẹ̀ Tó Lọ́kàn Rẹ?
Báwo Ni Ìgbàgbọ́ Nínú Àjíǹde Ṣe Jinlẹ̀ Tó Lọ́kàn Rẹ?
“Ìwọ ṣí ọwọ́ rẹ, Ìwọ sì ń tẹ́ ìfẹ́-ọkàn gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.”—SÁÀMÙ 145:16.
1-3. Ìrètí wo làwọn kan ní nípa ọjọ́ iwájú? Mú àpẹẹrẹ wá.
ỌMỌ ọdún mẹ́sàn-án kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Christopher àti ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin jọ lọ wàásù láti ilé dé ilé láàárọ̀ ọjọ́ kan nítòsí ìlú Manchester, nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Àwọn àti àbúrò màmá wọn ọkùnrin pẹ̀lú ìyàwó rẹ̀ àtàwọn ọmọ wọn méjì ni wọ́n jọ lọ. Ìwé ìròyìn wa tó ṣìkejì èyí, ìyẹn Jí!, ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀, ó ní: ‘Nígbà tó di ọ̀sán, gbogbo wọn forí lé àgbègbè kan tó ń jẹ́ Blackpool, ìyẹn etíkun kan tí kò jìnnà sílé wọn. Ibi ìtura ni etíkun yìí, wọ́n fẹ́ lọ fún ojú wọn lóúnjẹ níbẹ̀. Àwọn mẹ́fẹ̀ẹ̀fà wà lára àwọn èèyàn méjìlá tó kú lójú ẹsẹ̀ nínú jàǹbá ọkọ̀ kan táwọn ọlọ́pàá pè ní ‘ìparun yán-ányán-án.’’
2 Ní alẹ́ ọjọ́ tó ṣáájú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, ìdílé náà lọ sípàdé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ, ọ̀rọ̀ ikú sì ni kókó tí wọ́n jíròrò ní ìpàdé náà. Bàbá Christopher sọ pé: ‘Ọmọ kan tó máa ń ronú jinlẹ̀ ni Christopher. Ní alẹ́ ọjọ́ náà, yékéyéké ló ṣàlàyé nípa ayé tuntun àti ìrètí tóun ní lọ́jọ́ iwájú. Lẹ́yìn náà, bí ìjíròrò wa ti ń tẹ̀ síwájú, Christopher ṣàdédé sọ ohun kan, ó ní: ‘Àǹfààní tó wà nínú bá a ṣe jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni pé, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ikú máa ń dunni wọra gan-an, síbẹ̀ a mọ̀ pé a óò tún rí ara wa padà lórí ilẹ̀ ayé lọ́jọ́ kan.’ Kò sí ọ̀kankan ‘lára àwa tá a wà nípàdé lọ́jọ́ náà tó ronú pé gbólóhùn tó sọ yẹn máa wá di ọ̀rọ̀ mánigbàgbé.’’ a
3 Ní ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú ìgbà yẹn, ìyẹn lọ́dún 1940, wọ́n dá ẹjọ́ ikú fún Ẹlẹ́rìí kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Franz tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Austria. Wọ́n ní wọ́n máa bẹ́ orí rẹ̀ nítorí pé ó kọ̀ láti sẹ́ Jèhófà. Franz kọ lẹ́tà kan sí màmá rẹ̀ látinú àtìmọ́lé tó wà nílùú Berlin, lẹ́tà náà kà pé: “Gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀ tí mo ní, ká ní mo gbà láti ṣe iṣẹ́ ológun, ẹṣẹ́ ikú ni mo dá yẹn. Ìyẹn ì bá sì burú gan-an fún mi. Mi ò ní ní àjíǹde. . . . Nítorí náà, ní báyìí, màmá mi ọ̀wọ́n àti gbogbo ẹ̀yin arákùnrin àti arábìnrin mi, wọ́n ti ṣe ìdájọ́ mi lónìí, ẹ má sì jẹ́ kí ẹ̀rù bà yín, ẹjọ́ ikú ni wọ́n dá fún mi, àárọ̀ ọ̀la ni wọ́n yóò sì pa mí. Ọlọ́run ti fún mi lókun, bó ṣe fún gbogbo àwọn Kristẹni tòótọ́ lókun láyé ọjọ́un. . . . Bí ẹ bá ṣe olóòótọ́ títí dójú ikú, a óò tún pàdé nígbà àjíǹde. . . . Ó dìgbà o. Títí a óò tún fi pàdé.” b
4. Báwo lohun tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn tá a sọ̀rọ̀ wọn níbi yìí ṣe rí lára rẹ, kí la ó sì gbé yẹ̀ wò báyìí?
4 Christopher àti Franz nígbàgbọ́ nínú àjíǹde gan-an. Wọn ò ṣiyèméjì nípa rẹ̀ rárá. Ó dájú pé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí wọn yìí ká wa lára gan-an! Kí ìmọrírì tá a ní fún Jèhófà lè pọ̀ sí i, kí ìrètí wa nínú àjíǹde sì lè lágbára sí i, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ìdí tí àjíǹde fi máa wáyé àti bó ṣe yẹ kí ìmọ̀ tá a ní nípa àjíǹde yìí nípa lórí wa.
Ìran Àjíǹde Orí Ilẹ̀ Ayé
5, 6. Kí ni ìran tí àpọ́sítélì Jòhánù ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ nínú Ìṣípayá 20:12, 13 ṣí payá fún wa?
5 Nínú ìran kan tó dá lórí àwọn ohun tó máa ṣẹlẹ̀ nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi Jésù, àpọ́sítélì Jòhánù rí bí àjíǹde orí ilẹ̀ ayé ṣe ń ṣẹlẹ̀. Ó ní: “Mo sì rí àwọn òkú, ẹni ńlá àti ẹni kékeré. . . . Òkun sì jọ̀wọ́ àwọn òkú tí ń bẹ nínú rẹ̀ lọ́wọ́, ikú àti Hédíìsì sì jọ̀wọ́ àwọn òkú tí ń bẹ nínú wọn lọ́wọ́.” (Ìṣípayá 20:12, 13) Gbogbo àwọn tó wà ní Hédíìsì tàbí Ṣìọ́ọ̀lù, ìyẹn ipò òkú, ló máa rí ìtúsílẹ̀, irú ẹni yòówù kí wọ́n jẹ́, yálà “ẹni ńlá” tàbí “ẹni kékeré.” Àwọn tó kú sínú òkun pàápàá yóò tún padà wà láàyè lákòókò yẹn. Ohun àgbàyanu yìí jẹ́ ọ̀kan lára ohun tí Jèhófà fẹ́ ṣe fún aráyé.
6 Bí Kristi bá ṣe ń bẹ̀rẹ̀ ìṣàkóso rẹ̀ ẹlẹ́gbẹ̀rún ọdún báyìí ni yóò de Sátánì tí yóò sì sọ ọ́ sínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀. Kò sí ọ̀kankan lára àwọn tó jíǹde tàbí ẹnikẹ́ni lára àwọn tó la ìpọ́njú ńlá já tí Sátánì yóò ṣì lọ́nà nígbà ìṣàkóso yẹn, nítorí pé kò ní lè ṣe ohunkóhun. (Ìṣípayá 20:1-3) Ẹgbẹ̀rún ọdún lè dà bí àkókò gígùn lójú rẹ, àmọ́ ká sòótọ́, “bí ọjọ́ kan” péré ló rí lójú Jèhófà.—2 Pétérù 3:8.
7. Kí la óò gbé ìdájọ́ kà nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi?
7 Gẹ́gẹ́ bí ìran yẹn ti fi hàn, àkókò ìdájọ́ ni Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi yóò jẹ́. Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Mo sì rí àwọn òkú, ẹni ńlá àti ẹni kékeré, tí wọ́n dúró níwájú ìtẹ́ náà, a sì ṣí àwọn àkájọ ìwé sílẹ̀. Ṣùgbọ́n a ṣí àkájọ ìwé mìíràn sílẹ̀; àkájọ ìwé ìyè ni. A sì ṣèdájọ́ àwọn òkú láti inú nǹkan tí a kọ sínú àwọn àkájọ ìwé náà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ wọn. . . . A sì ṣèdájọ́ wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ní ìbámu pẹ̀lú àwọn iṣẹ́ wọn.” (Ìṣípayá 20:12, 13) Kíyè sí i pé kì í ṣe ohun tí ẹnì kan ṣe tàbí ohun tí kò ṣe kó tó kú la gbé ìdájọ́ yìí kà. (Róòmù 6:7) Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó wà nínú “àwọn àkájọ ìwé” tí a óò ṣí nígbà yẹn la gbé e kà. Ohun tí ẹnì kan bá ṣe lẹ́yìn tó ti mọ àwọn ohun tó wà nínú àwọn àkájọ ìwé náà ló máa sọ bóyá a óò kọ orúkọ rẹ̀ sínú “àkájọ ìwé ìyè.”
Ṣé “Àjíǹde Ìyè” Ni Àbí “Àjíǹde Ìdájọ́”?
8. Oríṣi ìdájọ́ méjì wo ló ṣeé ṣe káwọn tó máa jíǹde gbà?
8 Níbẹ̀rẹ̀ ìran tí Jòhánù rí yẹn, áńgẹ́lì náà sọ pé “kọ́kọ́rọ́ ikú àti ti Hédíìsì” wà lọ́wọ́ Jésù. (Ìṣípayá 1:18) Òun ni “Olórí Aṣojú ìyè” tí Jèhófà yàn, Ọlọ́run sì ti fún un lágbára láti ṣèdájọ́ “àwọn alààyè àti òkú.” (Ìṣe 3:15; 2 Tímótì 4:1) Báwo ni yóò ṣe ṣe èyí? Yóò ṣe bẹ́ẹ̀ nípa jíjí àwọn tó ń sùn nínú oorun ikú dìde. Jésù sọ fún àwọn èrò kan tó wàásù fún pé: “Kí ẹnu má yà yín sí èyí, nítorí pé wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn rẹ̀, wọn yóò sì jáde wá.” Ó tún fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Àwọn tí wọ́n ṣe ohun rere sí àjíǹde ìyè, àwọn tí wọ́n sọ ohun búburú dàṣà sí àjíǹde ìdájọ́.” (Jòhánù 5:28-30) Nítorí náà, kí ló ń dúró de àwọn olóòótọ́ ayé ọjọ́un lọ́kùnrin lóbìnrin lọ́jọ́ iwájú?
9. (a) Nígbà tí ọ̀pọ̀ bá jíǹde, kí ló dájú pé wọn yóò kọ́? (b) Iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wo ni yóò kárí ayé nígbà yẹn?
9 Nígbà táwọn tó jẹ́ olóòótọ́ láyé ọjọ́un wọ̀nyí bá jíǹde, kò ní pẹ́ rárá tí wọ́n á fi rí i pé àwọn ìlérí táwọn gbà gbọ́ ló ń nímùúṣẹ lọ́wọ́lọ́wọ́. Wọ́n ò ní ṣàìfẹ́ mọ ẹni tí Irú Ọmọ obìnrin Ọlọ́run náà jẹ́, èyí tó wà nínú àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́ nínú Bíbélì, ní Jẹ́nẹ́sísì 3:15. Wọ́n á tún láyọ̀ gan-an láti gbọ́ pé Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí náà, Jésù, ṣòtítọ́ títí dójú ikú ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi ìwàláàyè rẹ̀ ṣe ẹbọ ìràpadà! (Mátíù 20:28) Àwọn tó ń kí wọn káàbọ̀ padà sorí ilẹ̀ ayé pàápàá yóò láyọ̀ gan-an bí wọ́n ti ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ̀ pé inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà àti àánú rẹ̀ ló mú kó pèsè ìràpadà yìí. Kò sí àní-àní pé ọ̀rọ̀ ìyìn yóò kún ọkàn àwọn tí a jí dìde náà nígbà tí wọ́n bá rí ohun tí Ìjọba Ọlọ́run ń gbé ṣe, bó ti ń mú ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn fún ilẹ̀ ayé ṣẹ. Wọ́n yóò ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àǹfààní láti fi hàn pé Baba wọn ọ̀run onífẹ̀ẹ́ àti Ọmọ rẹ̀ làwọ́n fara mọ́. Gbogbo àwọn tó ń gbé láyé nígbà náà yóò láyọ̀ láti kópa nínú iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tí yóò kárí ayé nígbà yẹn. Èyí yóò jẹ́ ká lè kọ́ ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn èèyàn tí wọ́n ń jíǹde látinú ibojì lẹ́kọ̀ọ́, táwọn náà yóò nílò láti tẹ́wọ́ gba ìràpadà tí Ọlọ́run pèsè.
10, 11. (a) Àwọn àǹfààní wo ni gbogbo àwọn tó bá wà lórí ilẹ̀ ayé nígbà Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún yóò ní? (b) Kí ló yẹ kí èyí sún wa ṣe?
10 Nígbà tí Ábúráhámù bá jí dìde, ohun ìtùnú gbáà ni yóò jẹ́ fún un láti rí i pé òun ti wà lábẹ́ ìṣàkóso “ìlú ńlá” tó ti ń wọ̀nà fún náà. (Hébérù 11:10) Ayọ̀ Jóòbù ọkùnrin olóòótọ́ ayé ọjọ́un náà pàápàá kò ní ṣeé fẹnu sọ nígbà tó bá gbọ́ pé bí òun ṣe gbé ìgbésí ayé òun fún àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà mìíràn lókun, ìyẹn àwọn tó rí àdánwò nítorí pé wọ́n jẹ́ olóòótọ́! Dáníẹ́lì pàápàá kò ní ṣàìfẹ́ mọ bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Ọlọ́run mí sí i láti kọ ṣe nímùúṣẹ!
11 Ká sòótọ́, gbogbo àwọn tó bá wà láàyè nínú ayé tuntun tí òdodo yóò wà yẹn, yálà nípasẹ̀ àjíǹde tàbí nípa líla ìpọ́njú ńlá já, ni yóò kọ́ ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ nípa ohun tí Jèhófà ní lọ́kàn fún ayé àtàwọn tó ń gbé inú rẹ̀. Ó dájú pé ìrètí wa láti wà láàyè títí láé àti láti máa yin Jèhófà títí ayé yóò mú kí ètò ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Ẹlẹ́gbẹ̀rún ọdún náà gbádùn mọ́ni gan-an. Àmọ́ ṣá o, ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wá bá ṣe bá a ti ń kẹ́kọ̀ọ́ ohun tó wà nínú àwọn àkájọ ìwé náà ló ṣe pàtàkì jù. Ǹjẹ́ a óò fi ohun tí a bá kọ́ sílò? Ṣé a óò ṣàṣàrò lórí ẹ̀kọ́ pàtàkì yìí ká sì fi ẹ̀kọ́ náà sọ́kàn ká bàa lè ní okun tẹ̀mí láti borí ipá tí Sátánì yóò sà kẹ́yìn láti mú wa kúrò nínú òtítọ́?
12. Kí ló máa jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ẹnì kọ̀ọ̀kan láti kópa gan-an nínú iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ náà àti iṣẹ́ sísọ ayé di Párádísè?
12 Ohun kan tí kò tún yẹ ká gbojú fò dá ni àwọn àgbàyanu ìbùkún tí yóò wá látinú ẹbọ ìràpadà Kristi. Àwọn tí yóò jíǹde kò ní ní àwọn àìlera tàbí àbùkù ara irú èyí tá à ń ní báyìí. (Aísáyà 33:24) Ara gbogbo àwọn tó máa gbé inú ayé tuntun náà yóò jí pépé, wọn ò sì ní ṣàìsàn mọ́, nítorí náà wọ́n á lè máa kópa gan-an nínú iṣẹ́ kíkọ́ ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tó máa jíǹde lẹ́kọ̀ọ́ nípa bí wọn yóò ṣe máa rìn ní ọ̀nà ìyè. Wọ́n á tún kópa nínú arabaríbí iṣẹ́ kan tí irú rẹ̀ kò ṣẹlẹ̀ rí lórí ilẹ̀ ayé, ìyẹn iṣẹ́ sísọ gbogbo ilẹ̀ ayé di Párádísè, sí ìyìn Jèhófà.
13, 14. Kí nìdí tá a fi máa tú Sátánì sílẹ̀ nígbà ìdánwò ìkẹyìn, kí ló sì ṣeé ṣe kó jẹ́ àbájáde rẹ̀ fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa?
13 Nígbà tá a bá tú Sátánì sílẹ̀ látinú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ kó lè mú ìdánwò ìkẹyìn wá, yóò tún gbìyànjú láti ṣi ìran ènìyàn lọ́nà. Gẹ́gẹ́ bí Ìṣípayá 20:7-9 ṣe sọ, gbogbo àwọn ‘orílẹ̀ èdè tí Sátánì ṣì lọ́nà,’ ìyẹn àwùjọ àwọn èèyàn tó rí mú nípasẹ̀ agbára búburú rẹ̀ ni yóò gba ìdájọ́ ìparun. ‘Iná yóò sọ̀ kalẹ̀ láti ọ̀run wá, yóò sì jẹ wọ́n run.’ Ní tàwọn kan lára wọn tó jẹ́ pé àárín ìgbà Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún náà ni wọ́n jíǹde, ìparun yìí yóò mú kí àjíǹde wọn jẹ́ àjíǹde ìdájọ́. Àmọ́ ọ̀rọ̀ tàwọn tí wọ́n jíǹde tí wọ́n sì jẹ́ olóòótọ́ délẹ̀délẹ̀ kò ní rí bẹ́ẹ̀. Wọ́n á gba ẹ̀bùn ìwàláàyè ayérayé. Dájúdájú, “àjíǹde ìyè” ni tiwọn yóò jẹ́.—Jòhánù 5:29.
14 Ọ̀nà wo ni ìrètí tá a ní pé àjíǹde ń bọ̀ lè gbà tù wá nínú kódà lákòókò yìí? Àní, kí la gbọ́dọ̀ ṣe láti rí i dájú pé a óò jàǹfààní tí yóò mú wá lọ́jọ́ iwájú?
Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó Yẹ Ká Kọ́ Nísinsìnyí
15. Ọ̀nà wo ni ìgbàgbọ́ nínú àjíǹde lè gbà ràn wá lọ́wọ́ nísinsìnyí?
15 Ó lè jẹ́ pé èèyàn rẹ kan ṣẹ̀ṣẹ̀ kú láìpẹ́ yìí kó o sì máa fàyà rán àwọn ohun tí ikú ẹni náà fà. Ìrètí pé àwọn òkú yóò jíǹde á mú kí ọkàn rẹ pa rọ́rọ́, á sì jẹ́ kó o ní okun tí àwọn mìíràn kò ní nítorí pé wọn kò ní ìmọ̀ òtítọ́. Pọ́ọ̀lù tu àwọn ará Tẹsalóníkà nínú, ó sọ pé: “A kò fẹ́ kí ẹ ṣe aláìmọ̀ nípa àwọn tí ń sùn nínú ikú; kí ẹ má bàa kárísọ gẹ́gẹ́ bí àwọn yòókù tí kò ní ìrètí ti ń ṣe pẹ̀lú.” (1 Tẹsalóníkà 4:13) Ǹjẹ́ ò ń fojú inú rí ara rẹ nínú ayé tuntun, tó ò ń wo bí àjíǹde ti ń ṣẹlẹ̀? Máa ṣàṣàrò lórí ìrètí tó o ní pé wàá tún padà rí àwọn èèyàn rẹ, sì jẹ́ kí èyí máa tù ọ́ nínú.
16. Nígbà tí àjíǹde bá ṣẹlẹ̀, báwo ló ṣe máa rí lára rẹ?
16 Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, o lè ní àìlera ara tó jẹ́ àbájáde ọ̀tẹ̀ Ádámù, èyí sì lè jẹ́ àìsàn kan tó ń pọ́n ọ lojú gan-an. Má ṣe jẹ́ kí ìbànújẹ́ tí àìsàn yìí ń kó bá ọ mú ọ gbàgbé ayọ̀ tó máa jẹ́ tìrẹ lọ́jọ́ iwájú, ìyẹn ayọ̀ pé wàá jíǹde. Wàá tún padà wà láàyè, wàá sì ní ìlera àti okun tó jí pépé nínú ayé tuntun. Nígbà tó o bá lajú lákòókò náà, tó o sì rí àwọn èèyàn aláyọ̀ tí wọ́n ń bá ọ yọ̀ pé o jíǹde, ó dájú pé o kò ní ṣàì dúpẹ́ gidigidi lọ́wọ́ Ọlọ́run fún inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́.
17, 18. Ẹ̀kọ́ pàtàkì méjì wo ló yẹ ká máa fi sọ́kàn?
17 Kó tó dìgbà yẹn, gbé àwọn ẹ̀kọ́ méjì kan tó yẹ ká máa fi sọ́kàn yẹ̀ wò. Àkọ́kọ́ ni pé, ó ṣe pàtàkì ká máa fi gbogbo ọkàn wa sin Jèhófà lákòókò tá a wà yìí. Bíi ti Ọ̀gá wa, Kristi Jésù, ẹ̀mí ìyọ̀ǹda ara ẹni wa ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àtàwọn èèyàn. Bí àtakò tàbí inúnibíni bá mú kí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wa bọ́ lọ́wọ́ wa tàbí tá ò lómìnira mọ́, síbẹ̀, a óò dúró lórí ìpinnu wa láti má ṣe yẹsẹ̀ kúrò nínú ìgbàgbọ́ láìfi àdánwò èyíkéyìí pè. Táwọn alátakò bá sì ń fi ikú halẹ̀ mọ́ wa, ìrètí pé àjíǹde wà yóò tù wá nínú yóò sì fún wa lókun láti má ṣe sẹ́ Jèhófà àti Ìjọba rẹ̀. Àní sẹ́, bá a ṣe ń fi gbogbo ọkàn wa ṣe iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run tá a sì ń sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn, ńṣe lèyí ń mú ká yẹ lẹ́ni tí àwọn ìbùkún ayérayé tọ́ sí, èyí tí Jèhófà fi pa mọ́ de àwọn olódodo.
18 Ẹ̀kọ́ kejì dá lórí báa ṣe ń kojú àwọn ìdẹwò tí ẹran ara wa aláìpé ń fà. Ìmọ̀ tá a ní pé àjíǹde ń bọ̀ àti ìmọrírì wa fún inú rere tá ò lẹ́tọ̀ọ́ sí tí Jèhófà ń fi hàn sí wa ń mú ká túbọ̀ pinnu láti dúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́. Àpọ́sítélì Jòhánù kìlọ̀ fún wa pé: “Ẹ má ṣe máa nífẹ̀ẹ́ yálà ayé tàbí àwọn ohun tí ń bẹ nínú ayé. Bí ẹnikẹ́ni bá nífẹ̀ẹ́ ayé, ìfẹ́ fún Baba kò sí nínú rẹ̀; nítorí ohun gbogbo tí ń bẹ nínú ayé—ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú àti fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími—kò pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Baba, ṣùgbọ́n ó pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ayé. Síwájú sí i, ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.” (1 Jòhánù 2:15-17) Tá a bá ronú nípa “ìyè tòótọ́ tá a máa gbádùn, ọ̀rọ̀ àlùmọ́ọ́nì tó ń fa àwọn èèyàn mọ́ra nínú ayé kò ní jẹ́ nǹkan kan lójú wa rárá.(1 Tímótì 6:17-19) Bí ohun kan bá fẹ́ sún wa ṣèṣekúṣe, a ó ní gbà. A mọ̀ pé tá a bá lọ kú kí Amágẹ́dọ́nì tó dé, tá a sì ń hùwà tí inú Jèhófà kò dùn sí nìṣó, èyí lè mú kó kà wá mọ́ àwọn tí kò ní jíǹde.
19. Àǹfààní tí kò ṣeé díye lé wo la ò gbọ́dọ̀ gbàgbé?
19 Olórí gbogbo rẹ̀ ni pé, a ò gbọ́dọ̀ gbàgbé àǹfààní tí kò ṣeé díye lé tá a ní láti mú inú Jèhófà dùn lákòókò yìí àti títí láé. (Òwe 27:11) Bí a bá ṣe olóòótọ́ títí dójú ikú tàbí tí à ń bá ìwà títọ́ wa nìṣó títí dé òpin ètò àwọn nǹkan búburú yìí, èyí á fi han Jèhófà pé òun la fara mọ́ nínú ọ̀ràn ẹni tó yẹ kó jẹ́ ọba aláṣẹ láyé àtọ̀run. Ẹ sì wá wo bí yóò ṣe jẹ́ ohun ayọ̀ tó láti gbé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé yálà nípa líla ìpọ́njú ńlá já tàbí nípa àjíǹde tó jẹ́ iṣẹ́ ìyanu!
Jèhófà Yóò Ṣe Ohun Tí Ọkàn Wa Fẹ́ fún Wa
20, 21. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti máa jẹ́ olóòótọ́ nìṣó bá a tiẹ̀ ní àwọn ìbéèrè nípa àjíǹde tí kò sì sí ìdáhùn fún wọn báyìí? Ṣàlàyé.
20 Àwọn ìbéèrè kan ṣì wà nílẹ̀ tí ìjíròrò wa yìí nípa àjíǹde kò tíì dáhùn wọn. Báwo ni Jèhófà yóò ṣe bójú tó ọ̀ràn àwọn tó lọ́kọ tàbí aya kí wọ́n tó kú? (Lúùkù 20:34, 35) Ṣé ibi táwọn èèyàn ti kú ni wọ́n máa jí dìde sí? Ṣé tòsí ibi táwọn èèyàn wọn ń gbé làwọn tó kú máa jí dìde sí? Ọ̀pọ̀ àwọn ìbéèrè mìíràn nípa ètò àjíǹde ló ṣì tún wà tí kò tíì ní ìdáhùn. Nítorí náà, ó yẹ ká máa fi ọ̀rọ̀ Jeremáyà sọ́kàn, ó ní: “Jèhófà jẹ́ ẹni rere sí ẹni tí ó ní ìrètí nínú rẹ̀, sí ọkàn tí ń wá a. Ó dára kí ènìyàn dúró, àní ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́, de ìgbàlà Jèhófà.” (Ìdárò 3:25, 26) Nígbà tí àsìkò bá tó lójú Jèhófà, yóò ṣí ohun gbogbo payá fún wa lọ́nà tó máa tẹ́ wa lọ́rùn gan-an. Kí nìdí tá a fi lè gbà bẹ́ẹ̀?
21 Ìwọ ronú dáadáa lórí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà mí sí, tí onísáàmù náà kọ lórin pé: “Ìwọ ṣí ọwọ́ rẹ, Ìwọ sì ń tẹ́ ìfẹ́-ọkàn gbogbo ohun alààyè lọ́rùn.” (Sáàmù 145:16) Bá a ti ń dàgbà lohun tó wù wá máa ń yí padà. Ohun tá a nífẹ̀ẹ́ sí nígbà tá a wà lọ́mọdé kọ́ lohun tó tún ń wù wá lónìí. Àwọn ohun tójú wa ti rí látẹ̀yìnwá àtàwọn nǹkan tọ́kàn wa fẹ́ ló ń pinnu irú ojú tá a fi ń wo nǹkan. Síbẹ̀, ó dájú pé gbogbo ohun rere tí ọkàn wa bá fẹ́ nínú ayé tuntun ni Jèhófà yóò ṣe fún wa pátá.
22. Kí ló mú ká ní ìdí tó ṣe gúnmọ́ láti yin Jèhófà?
22 Ohun tó ṣe pàtàkì fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa báyìí ni pé ká jẹ́ olóòótọ́. “Ohun tí a ń retí nínú àwọn ìríjú ni pé kí a rí ènìyàn ní olùṣòtítọ́.” (1 Kọ́ríńtì 4:2) Ìríjú ìhìn rere ológo ti Ìjọba Ọlọ́run ni wá. Bá a bá ń fi gbogbo ọkàn polongo ìhìn rere náà fún gbogbo ẹni tá a bá rí, èyí ò ní jẹ́ ká kúrò lójú ọ̀nà tó lọ sí ìyè. Má ṣe gbàgbé pé gbogbo wa ni “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀” ń ṣẹlẹ̀ sí. (Oníwàásù 9:11) Kó o lè dín àníyàn tí kò nídìí kù, èyí tó ń wáyé nítorí pé a ò mọ̀la, má ṣe jẹ́ kí ìrètí ológo tó o ní pé àjíǹde ń bọ̀ yingin. Mọ̀ dájú pé, bó bá tiẹ̀ jọ pé wàá kú kí Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi tó bẹ̀rẹ̀, ìdánilójú tó o ní pé ìtura yóò dé yóò máa tù ọ́ nínú. Nígbà tí àkókò bá tó lójú Jèhófà, yóò ṣeé ṣe fún ìwọ náà láti sọ gbólóhùn tí Jóòbù sọ fún Ẹlẹ́dàá pé: “Ìwọ yóò pè, èmi fúnra mi yóò sì dá ọ lóhùn.” Ọpẹ́ mà ni fún Jèhófà o, ẹni tó fẹ́ kí gbogbo àwọn tó wà ní ìrántí rẹ̀ padà wà láàyè!—Jóòbù 14:15.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo Jí! March 8, 1989, ojú ìwé 10. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.
b Ìwé Jehovah’s Witnesses—Proclaimers of God’s Kingdom, ojú ìwé 662. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Nígbà Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún náà, kí la óò gbé ìdájọ́ àwọn èèyàn kà?
• Kí nìdí táwọn kan á fi ní “àjíǹde ìyè” táwọn mìíràn á sì ní “àjíǹde ìdájọ́”?
• Báwo ni ìrètí àjíǹde ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ nísinsìnyí?
• Báwo ni ọ̀rọ̀ inú Sáàmù 145:16 ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe dààmú nípa àwọn ìbéèrè tí kò tíì ṣe dáhùn báyìí nípa àjíǹde?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Báwo ni ìgbàgbọ́ tá a ní pé àjíǹde ń bọ̀ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ nísinsìnyí?