Bí Mo Tilẹ̀ Jẹ́ Aláìlera, Mo Di Alágbára
Ìtàn Ìgbésí Ayé
Bí Mo Tilẹ̀ Jẹ́ Aláìlera, Mo Di Alágbára
GẸ́GẸ́ BÍ LEOPOLD ENGLEITNER TI SỌ Ọ́
Ẹ̀ṣọ́ SS náà fa ìbọn ìléwọ́ rẹ̀ yọ, ó gbé e sí mi lágbárí, ó sì béèrè pé: “Ṣé o fẹ́ kú? Màá yin ìbọn yìí sí ọ lágbárí nítorí alágídí èèyàn ni ọ́.” Mo dáhùn láìmikàn pé, “Ó yá.” Mo ṣara gírí, mo dijú, mo sì ń dúró kí n gbọ́ ìró ìbọn náà, àmọ́ mi ò gbọ́ nǹkan kan. Bó ti ń gbé ìbọn yẹn kúrò lágbárí mi, ó pariwo pé, “O ò tiẹ̀ kọ ikú pàápàá!” Báwo ni mo ṣe bá ara mi nínú ipò tó léwu yìí?
ÌLÚ Aigen-Voglhub, táwọn òkè ńláńlá yí ká nílẹ̀ Austria ni wọ́n ti bí mi ní July 23, 1905. Èmi ló dàgbà jù nínú àwọn ọmọ òbí mi. Iṣẹ́ pákó lílà ni bàbá mi ń ṣe, ìyá mi sì jẹ́ ọmọ àgbẹ̀. Àwọn òbí mi kò fi bẹ́ẹ̀ rí já jẹ àmọ́ òṣìṣẹ́ kára ni wọ́n. Ìlú Bad Ischl, nítòsí Salzburg, ni mo dàgbà sí lágbègbè táwọn adágún omi tó lẹ́wà àtàwọn òkè gàgàrà wà.
Nígbà tí mo wà lọ́mọdé mo máa ń ronú nípa báwọn kan ṣe ń gbádùn táwọn kan sì ń jìyà nínú ayé, kì í ṣe nítorí pé ìdílé mi jẹ́ tálákà nìkan, àmọ́ nítorí eegun ẹ̀yìn mi tó tẹ̀ látìgbà tí wọ́n ti bí mi. Ó máa ń mú kí ẹ̀yìn ro mi kì í sì í jẹ́ kí n lè dúró dáadáa. Wọn ò kì í jẹ́ kí n ṣeré ìdárayá nílé ìwé, èyí sì máa ń jẹ́ káwọn ọmọ kíláàsì mi fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ gan-an.
Níparí Ogun Àgbáyé Kìíní, kí n tó pé ọmọ ọdún mẹ́rìnlá, mo pinnu pé ó yẹ kí n wá iṣẹ́ kan ṣe kí n lè bọ́ lọ́wọ́ ìṣẹ́. Ebi àpafẹ́ẹ̀ẹ́kú ló máa ń pa mi nígbà gbogbo, akọ ibà tí àjàkálẹ̀-àrùn gágá fà kì í sì í jẹ́ kí ara mi le rárá, àjàkálẹ̀-àrùn yẹn ti pa ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn nígbà yẹn.
Èsì tí ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn àgbẹ̀ tí mo wáṣẹ́ lọ sọ́dọ̀ wọn máa ń fún mi ni pé, “Irú iṣẹ́ wo ni ìwọ tí ò lágbára yìí lè ṣe?” Síbẹ̀síbẹ̀, àgbẹ̀ onínúure kan fún mi níṣẹ́ ṣe.Mímọ̀ Nípa Ìfẹ́ Ọlọ́run Wú Mi Lórí
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Kátólíìkì gidi ni màmá mi, agbára káká ni mo fi ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì nítorí pé bàbá mi ò ka ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn sí bàbàrà. Ní tèmi, inú mi ò dùn rárá sí báwọn èèyàn ṣe ń lo ère nínú ìjọsìn, èyí sì wọ́pọ̀ gan-an nínú Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì.
Lọ́jọ́ kan lóṣù October 1931, ọ̀rẹ́ mi kan sọ pé kí n bá òun lọ sí ìpàdé ìsìn tí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fẹ́ ṣe. Orúkọ yẹn ni wọ́n fi ń pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn. Inú ìpàdé yìí ni wọ́n ti fi Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè pàtàkì tó ti ń jẹ mí lọ́kàn, irú bíi: Ṣé lílo ère nínú ìjọsìn wu Ọlọ́run? (Ẹ́kísódù 20:4, 5) Ǹjẹ́ iná ọ̀run àpáàdì wà? (Oníwàásù 9:5) Ǹjẹ́ àwọn òkú á jíǹde?—Jòhánù 5:28, 29.
Ohun tó wú mi lórí jù lọ ni pé Ọlọ́run ò lọ́wọ́ sáwọn ogun táwọn èèyàn ti máa ń pààyàn nípakúpa, àní bí wọ́n tilẹ̀ sọ pé tìtorí orúkọ rẹ̀ làwọn ṣe ń jà á. Mo kẹ́kọ̀ọ́ pé “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́” ó sì ní orúkọ kan tó ju gbogbo orúkọ lọ. Jèhófà ni orúkọ náà. (1 Jòhánù 4:8; Sáàmù 83:18) Orí mi wú gan-an nígbà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ pé nípasẹ̀ Ìjọba Jèhófà, á ṣeé ṣe fún èèyàn láti máa gbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé nínú Párádísè tó kún fún ayọ̀. Mo tún kọ́ nípa àgbàyanu àǹfààní tó wà fún àwọn èèyàn aláìpé tí Ọlọ́run ti yàn láti bá Jésù ṣàkóso nínú Ìjọba ọ̀run. Mo ṣe tán láti lo ara mi fún Ìjọba yẹn. Nítorí náà mo ṣèrìbọmi ní May 1932, mo sì di ọkàn lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ohun tí mo ṣe yẹn gba ìgboyà gan-an, nítorí lákòókò yẹn ìsìn Kátólíìkì nìkan ni wọ́n ń ṣe lórílẹ̀-èdè Austria, wọn ò sì fi bẹ́ẹ̀ gba ẹ̀sìn mìíràn láyè.
Wọ́n Pẹ̀gàn Mi, Wọ́n sì Tún Ṣàtakò sí Mi
Inú àwọn òbí mi bàjẹ́ gan-an nígbà tí mo fi ṣọ́ọ̀ṣì sílẹ̀, kíá ni àlùfáà sì sọ ọ̀rọ̀ náà fún àwọn ọmọ ìjọ látorí àga ìwàásù. Àwọn ará àdúgbò á bẹ́ itọ́ sílẹ̀ níwájú mi láti fi pẹ̀gàn mi. Síbẹ̀síbẹ̀, mo pinnu láti di ọ̀kan lára àwọn òjíṣẹ́ tí ń fi àkókò kíkún wàásù mo sì bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà ni January 1934.
Ọ̀ràn òṣèlú túbọ̀ gbóná girigiri nítorí agbára ìjọba Násì tó túbọ̀ ń pọ̀ sí i ní ìpínlẹ̀ wa. Nígbà tí mo ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà ní Àfonífojì Styria ní Enns, àwọn ọlọ́pàá ń wá mi kiri, mo sì ní láti máa ‘ṣọ́ra bí ejò.’ (Mátíù 10:16) Ojoojúmọ́ ni wọ́n ń ṣe inúnibíni sí mi láàárín ọdún 1934 sí 1938. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò níṣẹ́ lọ́wọ́, síbẹ̀ wọ́n kọ̀ láti fún mi ní owó tí wọ́n máa ń fún àwọn tí ò níṣẹ́ lọ́wọ́. Wọ́n tún sọ mí sẹ́wọ̀n ọlọ́jọ́ díẹ̀ nígbà bíi mélòó kan, wọ́n sì tún fi mí sẹ́wọ̀n ọlọ́jọ́ gbọọrọ lẹ́ẹ̀mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nítorí pé mò ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù.
Àwọn Ọmọ Ogun Hitler Gba Austria
Ní oṣù March 1938, àwọn ọmọ ogun Hitler gba Austria. Láàárín ọjọ́ díẹ̀ péré, ó lé ní ọ̀kẹ́ mẹ́rin ààbọ̀ [90,000] èèyàn, ìyẹn ìpín méjì nínú ìpín ọgọ́rùn-ún àwọn àgbàlagbà tí wọ́n kó lọ sáwọn ẹ̀wọ̀n àtàwọn àgọ́ ìṣẹ́níṣẹ̀ẹ́ tí wọ́n sì fẹ̀sùn kàn wọ́n pé wọ́n ń ta ko ìjọba Násì. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti múra sílẹ̀ de ohunkóhun tó lè ṣẹlẹ̀. Nígbà ẹ̀rùn ọdún 1937, àwọn ará ìjọ tí mo kọ́kọ́ ń dara pọ̀ mọ́ fi kẹ̀kẹ́ rin àádọ́ta dín nírinwó [350] kìlómítà lọ ṣe ìpàdé àgbáyé nílùú Prague. Ibẹ̀ ni wọ́n ti gbọ́ nípa ìwà ìkà ti wọ́n ń hù sáwọn tó jẹ́ onígbàgbọ́ bíi tiwa nílẹ̀ Jámánì. Ó wá hàn gbangba pé àwa ló kàn báyìí.
Àwọn ìpàdé àti iṣẹ́ ìwàásù àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà di ohun tá à ń ṣe lábẹ́lẹ̀ látọjọ́ táwọn ọmọ ogun Hitler ti gba Austria. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé à ń kó ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gba ẹnu bodè Switzerland wọlé ní bòókẹ́lẹ́, síbẹ̀ ìwé náà kò kárí wa. Nítorí èyí, àwọn ará wa tó wà ní Vienna máa ń tẹ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní bòókẹ́lẹ́ nílẹ̀ Jámánì. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo sì máa ń kó ìwé lọ fún àwọn Ẹlẹ́rìí.
Wọ́n Fi Mí sí Àgọ́ Ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́
Ní April 4, 1939, àwọn ọlọ́pàá Gestapo mú èmi àtàwọn Kristẹni mẹ́ta mìíràn nígbà tá à ń ṣe Ìrántí Ikú Kristi lọ́wọ́ nílùú Bad Ischl. Wọ́n fi ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ gbé wa lọ sí orílé-iṣẹ́ àwọn ọlọ́pàá nílùú Linz. Ìgbà àkọ́kọ́ tí màá wọ ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ nìyẹn, àmọ́, ìdààmú yẹn ò jẹ́ kí n gbádùn rẹ̀. Nílùú Linz, wọ́n fi ìbéèrè pin mí lẹ́mìí, àmọ́ mi ò sẹ́ ìgbàgbọ́ mi. Oṣù márùn-ún lẹ́yìn náà ni wọ́n gbé mi wá síwájú adájọ́ ní ìpínlẹ̀ Upper Austria. Láìròtẹ́lẹ̀, wọ́n fòpin sí ẹjọ́ ọ̀daràn tí wọ́n ń bá mi ṣe, síbẹ̀ ìyẹn kọ́ ni òpin ìyà mi. Láàárín ìgbà yẹn, wọ́n ti kó àwọn Kristẹni mẹ́ta yòókù lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, wọ́n sì kú síbẹ̀, àmọ́ wọ́n ṣe olóòótọ́ títí dópin.
Wọ́n fi mí sínú àhámọ́, nígbà tó sì di October 5, 1939, wọ́n sọ fún mi pé wọ́n máa mú mi lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ tó wà ní Buchenwald nílẹ̀ Jámánì. Àkànṣe ọkọ̀ ojú irin kan ti ń dúró de àwa ẹlẹ́wọ̀n ní ibùdókọ̀ ojú irin tó wà nílùú Linz. Àwọn ọkọ̀ ojú irin náà ní àwọn yàrá ẹ̀wọ̀n tó wà fún èèyàn méjì méjì. Gómìnà ìpínlẹ̀ Upper Austria tẹ́lẹ̀, Ọ̀mọ̀wé Heinrich Gleissner, lẹni témi pẹ̀lú rẹ̀ jọ wà ní yàrá ẹ̀wọ̀n kan náà.
Èmi àti Ọ̀mọ̀wé Gleissner jọ sọ̀rọ̀ gan-an. Ó fẹ́ mọ ohun tó sọ mí di èrò ẹ̀wọ̀n, ó sì dún ún pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dojú kọ ọ̀pọ̀ ìṣòro lákòókò tóun jẹ́ Gómìnà nítorí àwọ́n èèyàn bá wọ́n ṣẹjọ́ gan-an ní ìpínlẹ̀ tó ti ṣèjọba. Ó wá sọ tẹ̀dùntẹ̀dùn pé: “Ọ̀gbẹ́ni Engleitner, ohun tó ṣẹlẹ̀ ti ṣẹlẹ̀ ná, àmọ́ mo tọrọ àforíjì. Ó jọ pé ìjọba wa ò ṣẹ̀tọ́. Tó o bá ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ èyíkéyìí nígbà míì, mo ṣe tán láti ràn ọ́ lọ́wọ́.” A tún pàdé ara wa lẹ́yìn ogun náà. Ó ràn mí lọ́wọ́ láti gba owó tí ìjọba ń san fún àwọn tí ìjọba Násì fìyà jẹ́.
“Màá Yìnbọn fún Ọ”
Ní October 9, 1939, mo bára mi ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ tó wà ní Buchenwald. Bá a ṣe ń débẹ̀ ni wọ́n sọ fún ẹni tó ń bójú tó ọgbà ẹ̀wọ̀n náà pé Ẹlẹ́rìí kan wà lára àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé, ó sì dájú sọ mí. Ó lù mí bí ẹni máa kú. Nígbà tó wá mọ̀ pé òun ò lè mú mi sẹ́ ìgbàgbọ́ mi, ó sọ pé: “Màá yìnbọn fún ọ, Engleitner. Àmọ́ kí n tó ṣe bẹ́ẹ̀, màá jẹ́ kó o kọ ọ̀rọ̀ ìdágbére sínú káàdì kan fún àwọn òbí rẹ.” Mo ronú nípa ọ̀rọ̀ ìtùnú tí mo lè kọ sáwọn òbí mi, ṣùgbọ́n ìgbàkigbà tí mo bá ti gbé gègé mi báyìí láti kọ̀wé, ńṣe ló máa gbá ìgúnpá mi ọ̀tún, èyí sì ń mú kí nǹkan tí mò ń kọ rí wọ́gọwọ̀gọ. Á wá máa fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ pé: “Òpònú ẹ̀dá! Kò tún lè kọ ìlà méjì kó gún régé. Bíbélì nìkan ló mọ̀ ọ́n kà, àbí mo purọ́?”
Lẹ́yìn náà, ẹni tó ń bójú tó ọgbà ẹ̀wọ̀n yìí fa ìbọn rẹ̀ yọ, ó gbé e sí mi lágbárí, ó sì ṣe bíi pé òun fẹ́ yìn ín, gẹ́gẹ́ bí mo ti sọ níbẹ̀rẹ̀ ìtàn yìí. Lẹ́yìn náà, ó tì mí wọnú yàrá ẹ̀wọ̀n kékeré kan tí èrò kúnnú rẹ̀ fọ́fọ́. Orí ìdúró ni mo wà tílẹ̀ ọjọ́ náà fi mọ́. Ṣùgbọ́n ká tiẹ̀ ní mo ráyè, mi ò
ní lè sùn nítorí pé gbogbo ara ló ń ro mí. Ohun tá a lè pè ní “ọ̀rọ̀ ìtùnú” táwọn tó wà nínú yàrá ẹ̀wọ̀n pẹ̀lú mi sọ fún mi kò ju pé, “Àṣedànù gbáà ni kéèyàn kú nítorí ìsìn ìranù kan!” Ọ̀mọ̀wé Gleissner wà ní yàrá ẹ̀wọ̀n tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ tèmi. Ó gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀ ó sì fi ẹ̀dùn ọkàn sọ pé, “Inúnibíni tí wọ́n ń ṣe sáwọn Kristẹni tún ti bẹ̀rẹ̀!”Nígbà ẹ̀rùn ọdún 1940, wọ́n pàṣẹ fún gbogbo àwa ẹlẹ́wọ̀n pé ká jáde ká wá lọ máa fọ́ òkúta ní ọjọ́ Sunday kan, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kì í ṣiṣẹ́ lọ́jọ́ Sunday. Wọ́n kàn fẹ́ fi èyí gbẹ̀san “ìwà àìdáa” táwọn ẹlẹ́wọ̀n kan hù ni. Wọ́n ní ká máa kó àwọn òkúta ńláńlá láti ibi tá a ti ń fọ́ òkúta lọ sínú ọgbà ẹ̀wọ̀n. Àwọn ẹlẹ́wọ̀n méjì kan gbé òkúta ńlá kan sí mi lẹ́yìn. Òkúta náà sì fẹ́rẹ̀ẹ́ rìn mí mọ́lẹ̀. Àmọ́, Arthur Rödl, (ọ̀gá ọ̀gbà ẹ̀wọ̀n náà) táwọn èèyàn bẹ̀rù rẹ̀ gan-an ṣàdédé wá gbà mí sílẹ̀. Nígbà tó rí i bó ṣe ṣòro fún mi tó láti gbé òkúta náà, ó sọ fún mi pé: “O ò lè gbé òkúta tó wà lẹ́yìn rẹ yẹn dénú ọgbà! Gbé e sílẹ̀ kíákíá!” Àṣẹ́ tó yá mi lára láti pa mọ́ lèyí jẹ́. Rödl wá na ìka sí òkúta tó kéré, ó sì sọ pé: “Gbé ìyẹn kó o sì rù ú wá sínú ọgbà. Ìyẹn ò wúwo rárá!” Lẹ́yìn náà, ó yíjú sí ẹni tó ń kó wa ṣiṣẹ́ ó sì pàṣẹ fún un pé: “Jẹ́ káwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì padà sínú ọgbà wọn. Iṣẹ́ tí wọ́n ṣe ti tó iṣẹ́ ọjọ́ kan!”
Lẹ́yìn iṣẹ́ ọjọ́ kọ̀ọ̀kan, mo máa ń láyọ̀ láti wà pẹ̀lú ìdílé mi nípa tẹ̀mí. A ti ṣètò bí a ó ṣe máa pín oúnjẹ tẹ̀mí. Arákùnrin kan yóò kọ ẹsẹ Bíbélì kan sórí ìwé péńpé kan, á sì máa lọ látọwọ́ ẹnì kan dé ọwọ́ ẹnì kejì. A tún wá ọ̀nà mú odindi Bíbélì kan wọnú ọgbà ẹ̀wọ̀n náà. A pín in sí ìwé kọ̀ọ̀kan tó wà nínú Bíbélì. Oṣù mẹ́ta gbáko ni ìwé Jóòbù fi wà lọ́dọ̀ mi. Mo tọ́jú rẹ̀ sínú ìbọ̀sẹ̀ mi. Ìwé Jóòbù ràn mí lọ́wọ́ láti dúró láìyẹsẹ̀ nínú ìgbàgbọ́.
Níkẹyìn, ní March 7, 1941, mo wà lára àwùjọ ńlá tí wọ́n kó lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ tó wà nílùú Niederhagen. Ara mi ò le mọ́, ojoojúmọ́ ni àìsàn náà sì ń burú sí i. Lọ́jọ́ kan, wọ́n ní kí èmi àtàwọn arákùnrin méjì kan kó irinṣẹ́ sínú àpótí irinṣẹ́. Lẹ́yìn tá a ṣèyẹn tán, àwa àtàwọn ẹlẹ́wọ̀n kan jọ ń padà sínú ọgbà ẹ̀wọ̀n. Ẹ̀ṣọ́ SS kan ṣàkíyèsí pé mi ò lè rìn kánmọ́kánmọ́ mọ́. Inú bí i débi pé ó gbá mi nípàá látẹ̀yìn lójijì, mo sì ṣèṣe gan-an. Ìrora ọ̀hún pàpọ̀jù fún mi, àmọ́ pẹ̀lú gbogbo ìrora yẹn, mo lọ síbi iṣẹ́ lọ́jọ́ kejì.
Wọ́n Dá Mi Sílẹ̀ Láìròtẹ́lẹ̀
Ní oṣù April ọdún 1943, wọ́n kó wa kúrò ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ti Niederhagen. Lẹ́yìn náà ni wọ́n gbé mi lọ sí àgọ́ ikú, ìyẹn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ tó wà ní Ravensbrück. Lẹ́yìn náà ní June 1943, mi ò tíì retí rẹ̀ rárá nígbà tí wọ́n wá sọ fún mi pé wọ́n máa dá mi sílẹ̀ kúrò ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ náà. Lọ́tẹ̀yí, wọn ò sọ pé kí ń sẹ́ ìgbàgbọ́ mi kí wọ́n lè dá mi sílẹ̀. Màá kàn gbà pé màá máa ṣiṣẹ́ àṣekára nínú oko kan ní gbogbo ìyókù ọjọ́
ayé mi. Mo gbà láti ṣe é kí n bàa lè bọ́ lọ́wọ́ ìnira burúkú tó wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n. Mo lọ sọ́dọ̀ dókítà tó wà nínú ọgbà náà fún àyẹ̀wò mi tó kẹ́yìn níbẹ̀. Ó ya dókítà náà lẹ́nu láti rí mi. Ó sọ pé, “Hẹ̀n-ẹ́n, ṣé pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣì ni ọ́!” Mo dáhùn pé “Bẹ́ẹ̀ ni, Dókítà.” Ó sọ pé, “Ó dáa, tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, kò sídìí tó fi yẹ ká dá ọ sílẹ̀. Àmọ́ ṣá o, ńṣe ni wàhálà máa kúrò lọ́rùn wa tá a bá gbé èèyàn hẹ́gẹhẹ̀gẹ bí irú rẹ yìí sọnù.”Ọ̀rọ̀ tó fi ṣàpèjúwe mi yẹn kì í ṣe àsọdùn. Àìsàn tó ń ṣe mí nígbà yẹn le kú. Ìdun ti fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ gbogbo ara mi tán, ìlùkulù tí wọ́n lù mi ti jẹ́ kí etí mi kan di, egbò sì kún gbogbo ara mi. Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta àtoṣù mẹ́wàá tí mo ti ń jìyà, tébi pa mí bí ẹní máa kú, tí mo sì ṣiṣẹ́ àṣefẹ́ẹ̀ẹ́kú, díẹ̀ ni mo fi wọ̀n ju ààbọ̀ àpò sìmẹ́ǹtì lọ [kìlógíráàmù méjìdínlọ́gbọ̀n]. Ipò tí mo wà nìyẹn nígbà tí wọ́n dá mi sílẹ̀ kúrò lágọ̀ọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ Ravensbrück ní July 15, 1943.
Wọ́n dá mi padà sí ìlú mi nínú ọkọ̀ ojú irin láìfi ẹ̀ṣọ́ kankan tì mí, mo sì lọ fara hàn ní orílé-iṣẹ́ àwọn ọlọ́pàá Gestapo tó wà nílùú Linz. Ọlọ́pàá Gestapo kan fún mi ní àwọn ìwé tó fi hàn pé wọ́n ti tú mi sílẹ̀ ó sì kìlọ̀ fún mi pé: “Bó o bá rò pé kó o lè máa bá iṣẹ́ tó ò ń ṣe lábẹ́lẹ̀ lọ la ṣe tú ọ sílẹ̀, o tanra ẹ jẹ ni o! Tọ́wọ́ wa bá tún lè tẹ̀ ọ́ pẹ́nrẹ́n pé ò ń wàásù, Ọlọ́run nìkan ló máa kó ẹ yọ.”
Mo padà dé ilé mi níkẹyìn! Màmá mi ò fọwọ́ kan ohunkóhun nínú yàrá mi látìgbà tí wọ́n ti kọ́kọ́ mú mi ní April 4, 1939. Àní Bíbélì mi wà bí mo ṣe ṣí i sílẹ̀ lórí tábìlì tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ bẹ́ẹ̀dì mi! Mo kúnlẹ̀ mo sì gbàdúrà ọpẹ́ látọkàn mi wá.
Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn tí wọ́n fi sọ pé kí n lọ máa ṣiṣẹ́ nínú oko kan tó wà lórí òkè. Kódà àgbẹ̀ tó ni oko náà, tó jẹ́ ọ̀rẹ́ mi láti kékeré, ń sanwó kékeré fún mi bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò pọn dandan pé kó san owó náà. Kí ogun tó bẹ̀rẹ̀ ni ọ̀rẹ́ mi yìí ti gbà mí láyè pé kí n kó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pamọ́ síbì kan lọ́dọ̀ rẹ̀. Inú mi dùn gan-an pé mo rí àwọn ìwé tí mo ti kó pamọ́ tẹ́lẹ̀ yẹn lò láti tún ní okun tẹ̀mí padà. Gbogbo ohun tí mo nílò ni mo ní, mo sì pinnu pé màá wà lóko náà títí ogun á fi parí.
Mo Fara Pa Mọ́ Sáàárín Àwọn Òkè
Àmọ́ ṣá o, òmìnira tí wọ́n fún mi yẹn kò tọ́jọ́ rárá. Láàárín oṣù August 1943, wọ́n ní kí n lọ bá dókítà ológun fún àyẹ̀wò ara mi. Lákọ̀ọ́kọ́, ó sọ pé mi ò lè ṣe iṣẹ́ agbára nítorí eegun ẹ̀yìn mi kò dáa. Àmọ́ ọ̀sẹ̀ kan lẹ́yìn ìyẹn ni dókítà kan náà yìí tún sọ pé àyẹ̀wò ti tẹ́lẹ̀ yẹn kò rí bẹ́ẹ̀ mọ́. Ohun tó tún wá kọ ni: “Ara rẹ̀ le, ó lè lọ sójú ogun.” Àwọn ológun wá mi fúngbà díẹ̀ àmọ́ wọn ò rí mi, ṣùgbọ́n ní April 17, 1945 nígbà tó kù díẹ̀ kí Ogun Àgbáyé Kejì parí, ọwọ́ wọn tẹ̀ mí. Wọ́n mú mi lọ sójú ogun.
Mo mú oúnjẹ, aṣọ díẹ̀ àti Bíbélì, mo sì lọ forí pa mọ́ sáàárín àwọn òkè tó wà nítòsí. Lákọ̀ọ́kọ́, ìta ni mò ń sùn, àmọ́ nígbà tó yá òtútù bẹ̀rẹ̀ sí mú gan-an, yìnyín tó rọ̀ sórí ilẹ̀ sì ga tó ẹsẹ̀ bàtà méjì. Gbogbo ara mi ló rin gbingbin. Mo gbìyànjú láti rìn dé ibi ilé kan tó wà lórí òkè kan, ibẹ̀ sí ìsàlẹ̀ sì ga tó nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rin [4,000] ẹsẹ̀ bàtà. Nígbà tí mo ń gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ mo dáná, mo sì yáná, mo tún fi iná náà gbẹ aṣọ mi. Nítorí pé ó ti rẹ̀ mí gan-an, mo gbàgbé sùn lọ sórí bẹ́ǹṣì kan tó wà níwájú iná tí mo dá náà. Láìpẹ́, ìrora burúkú jí mi. Iná ti mú aṣọ mi! Mo bẹ̀rẹ̀ sí í yí gbirigbiri nílẹ̀ kí n lè pa iná náà. Gbogbo ẹ̀yìn mi ló bó.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀rù ń bà mí pé wọ́n lè mú mi, mo wá ọ̀nà yọ́ kẹ́lẹ́ padà sínú oko tó wà lórí òkè náà kí ilẹ̀ tó mọ́, ṣùgbọ́n ẹ̀rù ba ìyàwó olóko yẹn tó bẹ́ẹ̀ tó fi lé mi padà, ó sọ fún mi pé àwọn tó fẹ́ mú mi ti ń wá mi kiri. Ni mo bá lọ sọ́dọ̀ àwọn òbí mi. Lákọ̀ọ́kọ́, àwọn òbí mi pàápàá lọ́ tìkọ̀ láti gbà mí sílé, àmọ́ níkẹyìn wọ́n jẹ́ kí n sùn nínú yàrá tí wọ́n kó ègé koríko sí, màmá mi sì bá mi tọ́jú ọgbẹ́ mi. Àmọ́, lẹ́yìn ọjọ́ méjì, ara àwọn òbí mi ò balẹ̀ mọ́, tó mú mi pinnu pé á sàn kí n padà lọ fara pa mọ́ sáàárín àwọn òkè wọ̀nyẹn.
Ní May 5, 1945, ariwo ńlá kan jí mi. Mo rí ọkọ̀ òfuurufú àwọn ọmọ ogun Olùgbèjà tó ń rà bàbà lókè. Ìgbà yẹn ni mo mọ̀ pé wọ́n ti gba ìjọba lọ́wọ́ Hitler! Ẹ̀mí Jèhófà ti ràn mí lọ́wọ́ láti fara da ìṣẹ̀lẹ̀ agbonijìgì yìí. Mo ti rí i bí ọ̀rọ̀ tó wà ní Sáàmù 55:22 ti jóòótọ́ tó, ó sì tù mí nínú gan-an ní ìbẹ̀rẹ̀ àdánwò mi. Mo ‘ju ẹrù ìnira mi sọ́dọ̀ Jèhófà.’ Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo jẹ́ aláìlera, ó dúró tì mí bí mo ṣe ń rìn gba “àfonífojì ibú òjìji.”—Sáàmù 23:4.
Agbára Jèhófà “Di Pípé Nínú Àìlera”
Lẹ́yìn ogun náà, nǹkan tún bẹ̀rẹ̀ sí i padà sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀ díẹ̀díẹ̀. Mo kọ́kọ́ ń ṣe lébìrà lọ́dọ̀ ọ̀rẹ́ mi àgbẹ̀ tí oko rẹ̀ wà lórí òkè. Ẹ̀yìn tí àwọn ọmọ ogun Amẹ́ríkà wá sí orílẹ̀-èdè wa ní April 1946 ni wọ́n tó dá mi sílẹ̀ pé kí n má ṣe iṣẹ́ oko tó gba agbára gan-an náà mọ́, èyí tí ǹ bá fi gbogbo ìyókù ọjọ́ ayé mi ṣe.
Lẹ́yìn ogun náà, àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà nílùú Bad Ischl àti àgbègbè rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ìpàdé déédéé. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí i fi àkọ̀tun okun wàásù. Wọ́n fi iṣẹ́ aṣọ́de lọ̀ mí nílé iṣẹ́ kan, mo sì lè tipa bẹ́ẹ̀ máa bá iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà mi nìṣó. Níkẹyìn mo fi àgbègbè ìlú St. Wolfgang ṣe ibùgbé, mo sì fẹ́ Theresia Kurz lọ́dún 1949. Theresia ti bí ọmọ kan fún ọkọ tó kọ́kọ́ fẹ́. Ọdún méjìlélọ́gbọ̀n la fi wà pa pọ̀ títí ìyàwó mi àtàtà fi kú lọ́dún 1981. Ó lé ní ọdún méje tí mo fi tọ́jú rẹ̀.
Lẹ́yìn tí Theresia kú, mo tún bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà padà, èyí sì ràn mí lọ́wọ́ láti borí ìbànújẹ́ ọkàn ńláǹlà tí ikú rẹ̀ mú bá mi. Mò ń sìn nísinsìnyí gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà àti alàgbà nínú ìjọ mi nílùú Bad Ischl. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé orí kẹ̀kẹ́ àwọn aláàbọ̀ ara ni mo máa ń jókòó sí, mo máa ń fún àwọn èèyàn ní àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo sì máa ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa ìrètí Ìjọba Ọlọ́run ní ibùdókọ̀ ìlú Bad Ischl tàbí nígbà tí mo bá wà níwájú ilé mi. Ọ̀rọ̀ inú Bíbélì tí mo máa ń bá àwọn èèyàn sọ fún mi ní ayọ̀ ńláǹlà.
Nígbà tí mo ronú nípa bí mo ṣe lo ìgbésí ayé mi látẹ̀yìn wá, mo lè fọwọ́ sọ̀yà pé àwọn nǹkan líle koko tí mo ti fara dà kò múnú mi bàjẹ́. Òótọ́ ni pé àwọn ìgbà mìíràn wà tí ọkàn mi máa ń bàjẹ́ nítorí àwọn àdánwò yìí. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àjọṣe rere tó wa láàárín èmi àti Jèhófà Ọlọ́run ti ràn mí lọ́wọ́ láti dúró ṣinṣin ní àkókò ìṣòro náà. Ìmọ̀ràn tí Olúwa gba Pọ́ọ̀lù pé, “Agbára mi ni a ń sọ di pípé nínú àìlera” ti jóòótọ́ nínú ìgbésí ayé tèmi náà. Nísinsìnyí tí mo ti sún mọ́ ẹni ọgọ́rùn-ún ọdún, èmi náà lè sọ ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Mo ní ìdùnnú nínú àwọn àìlera, nínú àwọn ìwọ̀sí, nínú àwọn ọ̀ràn àìní, nínú àwọn inúnibíni àti àwọn ìṣòro, fún Kristi. Nítorí nígbà tí èmi bá jẹ́ aláìlera, nígbà náà ni mo di alágbára.”—2 Kọ́ríńtì 12:9, 10.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Àwọn ọlọ́pàá Gestapo mú mi, April 1939
Ìwé ẹ̀sùn tí àwọn ọlọ́pàá Gestapo fi kàn mí rèé, May 1939
[Credit Line]
Àwọn àwòrán méjèèjì: Privatarchiv; B. Rammerstorfer
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Àwọn òkè tó wà nítòsí jẹ́ kí n ríbi sá sí
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 23]
Foto Hofer, Bad Ischl, Austria