Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Obìnrin Kan Tó Ṣẹ́gun Lọ́nà Àrà Ọ̀tọ̀

Obìnrin Kan Tó Ṣẹ́gun Lọ́nà Àrà Ọ̀tọ̀

Obìnrin Kan Tó Ṣẹ́gun Lọ́nà Àrà Ọ̀tọ̀

ǸJẸ́ àwọn èèyàn ń ṣàtakò sí ọ nítorí ìgbàgbọ́ rẹ, bóyá ní ibi iṣẹ́, nílé ìwé, nínú ìdílé, tàbí látọ̀dọ̀ ìjọba nítorí òfin kan tí wọ́n ṣe? Jọ̀wọ́ má ṣe jẹ́ kí èyí kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ọ. Ọ̀pọ̀ lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti dojú kọ irú àdánwò bẹ́ẹ̀ wọ́n sì ti ṣẹ́gun. Gbé àpẹẹrẹ Erna Ludolph yẹ̀ wò.

Ìlú Lübeck tó wà lórílẹ̀-èdè Jámánì ni wọ́n ti bí Erna lọ́dún 1908. Òun nìkan ṣoṣo ló ń sìn Jèhófà nínú gbogbo ìdílé rẹ̀. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí àdánwò gan-an nígbà tí ìjọba Hitler bẹ̀rẹ̀ sí i ṣàkóso ní ọdún 1933. Àwọn tí Erna jọ ń ṣiṣẹ́ níbì kan náà kẹ́gàn rẹ̀ nítorí pé kò kókìkí orúkọ Hitler. Nítorí ẹ̀sùn yìí sì ni Ìjọba Násì ṣe mú un. Ó lo ọdún mẹ́jọ gbáko ní onírúurú ọgbà ẹ̀wọ̀n àti láwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ tó wà nílùú Hamburg-Fuhlsbüttel, nílùú Moringen, àti ní Lichtenburg, àti nílùú Ravensbrück. Nígbà tí Erna wà ní Ravensbrück, ohun kan ṣẹlẹ̀ tó mú kó di aṣẹ́gun.

Olùtọ́jú Ilé Tí Kò Lẹ́gbẹ́

Ìlú Berlin ni Ọ̀jọ̀gbọ́n Friedrich Holtz àti Alice, ìyàwó rẹ̀ ń gbé. Wọn kì í ṣe ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú Násì, wọn ò sì fara mọ́ ohun tí ẹgbẹ́ náà ń ṣe. Àmọ́ wọ́n tan mọ́ ẹnì kan tó jẹ́ ọ̀gá lára àwọn ẹ̀ṣọ́ SS tó ń bójú tó àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó wà ní àwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ kan. Nítorí náà, nígbà tí ọ̀jọ̀gbọ́n náà àti ìyàwó rẹ̀ ń wá ẹni tó máa bá wọn tọ́jú ilé, ọ̀gá àwọn ẹ̀ṣọ́ SS yìí sọ pé kí wọ́n wá mú ẹlẹ́wọ̀n obìnrin tó bá wù wọ́n. Èyí ló mú kí Alice wá sí ọgbà ẹ̀wọ̀n Ravensbrück ní oṣù March ọdún 1943 láti mú olùtọ́jú ilé kan níbẹ̀. Ta ló mú? Erna Ludolph ni. Erna kó wá sílé àwọn Holtz, wọ́n sì tọ́jú rẹ̀ dáadáa. Lẹ́yìn tí ogun parí, ó bá ìdílé náà lọ sí ìlú Halle, tó wà nítòsí odò Saale. Erna tún rí àtakò níbẹ̀, lọ́tẹ̀ yìí àwọn aláṣẹ ẹgbẹ́ tó ń bójú tó ètò ọrọ̀ ajé ní Ìlà Oòrùn Jámánì ló ṣàtakò sí i. Wọ́n lé ìdílé Holtz lọ sí Ìwọ Oòrùn Jámánì lọ́dún 1957, Erna sì bá wọn lọ. Erna ṣẹ̀ṣẹ̀ wá lómìnira báyìí láti máa ṣe ìsìn rẹ̀.

Báwo ni Erna ṣe wá ṣẹ́gun lọ́nà àrà ọ̀tọ̀? Nítorí ìwà rere Erna àti bó ṣe ń wàásù ọ̀rọ̀ inú Bíbélì dáadáa, Alice Holtz àtàwọn ọmọ rẹ̀ márààrún di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì ṣèrìbọmi. Ìyẹn nìkan kọ́ o, àwọn mọ́kànlá nínú àwọn ọmọ ọmọ Alice tún di Ẹlẹ́rìí. Méjì lára wọn ń sìn lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí ní ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìlú Selters, nílẹ̀ Jámánì. Susanne tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọbìnrin Alice sọ pé: “Àpẹẹrẹ Erna ni olórí ohun tó jẹ́ kí ìdílé wa wà nínú òtítọ́.” Ìfaradà tí Erna ní yìí mú ìbùkún yàbùgà-yabuga wá. Irú ipò wo nìwọ náà wà? Ìfaradà rẹ nígbà ìṣòro líle lè mú irú ìbùkún yìí kan náà wá. Dájúdájú, híhùwà rere àti wíwàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáadáa lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣẹ́gun lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. a

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Nígbà tí à ń múra àtitẹ ìwé yìí jáde ni Erna Ludolph kú lẹ́ni ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún. Ó ṣolóòótọ́ títí dópin.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Erna Ludolph rèé (lórí ìjókòó) pẹ̀lú ìdílé Holtz