Ohun Ìbànújẹ́ Ṣẹlẹ̀
Ohun Ìbànújẹ́ Ṣẹlẹ̀
ỌMỌ ọdún méjì ààbọ̀ kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Owen ń ṣeré nínú balùwẹ̀ ilé wọn. Ó wá ọ̀nà gòkè dé ibi tí àpótí tí wọ́n ń kó oògùn sí wà nínú ilé ìwẹ̀ náà. Bẹ́ẹ̀, èrò àwọn òbí Owen ni pé kò sí bí ọmọ àwọn ṣe lè gòkè débẹ̀. Ìgò kékeré kan wà nínú àpótí náà, ìgò yìí ló sì wu Owen nínú gbogbo ohun tó wà níbẹ̀. Bó ṣe ṣí ìgò náà nìyẹn tó sì da nǹkan tó wà nínú rẹ̀ mu. Ni wàhálà bá dé.
Ó mà ṣe o, ásíìdì olóró ló wà nínú ìgò náà, bí Owen ṣe kú ikú òjijì nìyẹn. Ọkàn àwọn òbí rẹ̀ gbọgbẹ́. Percy tó jẹ́ bàbá Owen lọ sọ́dọ̀ àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀ kí àlùfáà náà bàa lè tù ú nínú. Ó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Kí nìdí tí èyí fi ṣẹlẹ̀?” Àlùfáà náà sì fèsì pé: “Ńṣe ni Ọlọ́run ń fẹ́ áńgẹ́lì kékeré mìíràn lọ́run.” Ìbànújẹ́ wá túbọ̀ dorí àwọn òbí ọmọ náà kodò, wọ́n wò ó pé ìwà ìkà gbáà nìyẹn. Ṣé pé Ọlọ́run ló jẹ́ kí irú jàǹbá bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀? Ohun tí àlùfáà sọ yìí kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá Percy gan-an débi tó fi sọ pé òun ò ní lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì náà mọ́.
Bí Percy ṣe ń rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọmọ rẹ̀ ló ń ronú pé: ‘Àbí ọmọ mi ṣì ń jẹ̀rora ni? Ǹjẹ́ mo tún máa padà rí i?’
Ìwọ náà ti lè máa ronú nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sẹ́ni tó bá kú, kó o sì tún fẹ́ mọ̀ bóyá á ṣeé ṣe láti padà rí àwọn èèyàn wa tó ti kú. Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí. Àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ sì kún fún àwọn ìdáhùn tó ṣe kedere tó sì jẹ́ ìtùnú fún gbogbo àwọn tí irú ohun ìbànújẹ́ bí èyí ti ṣẹlẹ̀ sí. Ní pàtàkì jù lọ, ó tún jẹ́ ká mọ̀ nípa àjíǹde, ìyẹn ohun àgbàyanu tí Ọlọ́run ṣèlérí.
Jọ̀wọ́ ka àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí láti túbọ̀ mọ̀ nípa ìrètí àgbàyanu yìí.