Wọ́n Ní Ìgboyà Nígbà Àtakò
Wọ́n Ní Ìgboyà Nígbà Àtakò
ÀWỌN èèyànkéèyàn fipá wọ́ Gáyọ́sì àti Àrísítákọ́sì wọnú gbọ̀ngàn ìwòran tó wà nílùú Éfésù. Àwọn ọkùnrin méjèèjì yìí àti Pọ́ọ̀lù jọ ń wàásù ni. Odindi wákàtí méjì làwọn èèyàn tínú ń bí náà fi ń pariwo pé: “Títóbi ni Átẹ́mísì ti àwọn ará Éfésù!” (Ìṣe 19:28, 29, 34) Ǹjẹ́ àwọn tó ń wàásù pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù yìí sẹ́ ìgbàgbọ́ wọn bí wọ́n ṣe ń ṣe àtakò sí wọn? Kí ló fa wàhálà yìí pàápàá?
Nǹkan bí ọdún mẹ́ta ni Pọ́ọ̀lù ti fi wàásù nílùú Éfésù ti ìwàásù rẹ̀ sì kẹ́sẹ járí. Nítorí èyí, ọ̀pọ̀ àwọn ará Éfésù ti ṣíwọ́ bíbọ òrìṣà. (Ìṣe 19:26; 20:31) Ojúbọ kékeré tí wọ́n fi fàdákà ṣe fún Átẹ́mísì, ìyẹn abo ọlọ́run afúnnilọ́mọ, ni ibi táwọn ará Éfésù tí máa ń bọ̀rìṣà wọn. Tẹ́ńpìlì tí wọ́n kọ́ fún òrìṣà náà ga débi pé, èèyàn lè rí gbogbo ìlú náà láti ibẹ̀. Wọ́n máa ń fi àwọn ère kéékèèké tí wọ́n ṣe ní àwòrán tẹ́ńpìlì yìí sí ara wọn bí oògùn ìṣọ́ra tàbí kí wọ́n gbé wọn kọ́ sára ilé. Ó dájú pé àwọn Kristẹni kì í ra àwọn ère wọ̀nyẹn.—1 Jòhánù 5:21.
Dímẹ́tíríù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn alágbẹ̀dẹ tó ń rọ àwọn ère náà rò pé iṣẹ́ òjíṣẹ́ Pọ́ọ̀lù yóò mú kí iṣẹ́ tó ń mówó ńlá wọlé fáwọn yìí dẹnu kọlẹ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ sí yí irọ́ pọ̀ mọ́ òtítọ́ ó sì ń sọ àsọdùn káwọn alágbẹ̀dẹ yòókù lè gbà pé àwọn èèyàn tó wà ní gbogbo Éṣíà Kékeré kò ní sin òrìṣà Átẹ́mísì mọ́. Bí àwọn alágbẹ̀dẹ tínú ń bí wọ̀nyẹn ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í pariwo tí wọ́n sì ń fi ìyìn fún Átẹ́mísì báyìí làwọn èèyànkéèyàn tú síta, wọ́n sì da gbogbo ìlú náà rú.—Ìṣe 19:24-29.
Ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn kóra jọ sí gbọ̀ngàn náà, èyí tó lè gbà tó ẹgbàá méjìlá ààbọ̀ [25,000] òǹwòran. Pọ́ọ̀lù fẹ́ bá àwọn èèyànkéèyàn wọ̀nyẹn sọ̀rọ̀, àmọ́ àwọn òṣìṣẹ́ gbọ̀ngàn náà tí wọ́n ṣọmọlúwàbí sọ pé kó má ṣe bẹ́ẹ̀. Níkẹyìn, akọ̀wé ìlú náà pẹ̀tù sáwọn èèyàn náà nínú, Gáyọ́sì àti Àrísítákọ́sì sì sá lọ láìfarapa.—Ìṣe 19:35-41.
Lónìí náà, àwọn alátakò tàbí àwọn jàǹdùkú lè máa gbéjà ko àwọn èèyàn Ọlọ́run lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn. Àwọn ìlú tí wọ́n ti máa ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù wọn sábà máa ń jẹ́ ibi tí ìbọ̀rìṣà, ìwà pálapàla àti ìwà ìpátá ti gbòde kan. Síbẹ̀, tìgboyà-tìgboyà ni wọ́n fi ń fara wé àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ẹni tí ‘kò fà sẹ́yìn nínú kíkọ́ àwọn èèyàn ní gbangba àti láti ilé dé ilé’ nílùú Éfésù. (Ìṣe 20:20) Inú tiwọn náà sì dùn nígbà tí wọ́n rí i bí ‘ọ̀rọ̀ Jèhófà ṣe ń gbilẹ̀ tó sì ń borí.’—Ìṣe19:20.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]
Àwọn àwókù gbọ̀ngàn ìwòran ìlú Éfésù