Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Kí nìdí tí Ọlọ́run ò fi pa Dáfídì àti Bátí-ṣébà nígbà tí wọ́n ṣe panṣágà, àmọ́ tó jẹ́ kí ọmọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bí kú?
Òfin Mósè sọ pé: “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé a rí ọkùnrin kan tí ó sùn ti obìnrin kan tí ó jẹ́ ti ẹnì kan, nígbà náà kí àwọn méjèèjì kú pa pọ̀, ọkùnrin tí ó sùn ti obìnrin náà àti obìnrin náà. Nípa bẹ́ẹ̀, ìwọ yóò mú ohun tí ó burú kúrò ní Ísírẹ́lì.” (Diutarónómì 22:22) Ká láwọn adájọ́ ilẹ̀ Ísírẹ́lì ni Jèhófà sọ fún pé kó ṣèdájọ́ Dáfídì àti Bátí-ṣébà, tí wọ́n sì lo Òfin Mósè, ńṣe ni wọn ì bá pa àwọn méjèèjì tó ṣe panṣágà yìí. Àwọn adájọ́ wọ̀nyí ò lè mọ ohun tó wà lọ́kàn ẹni tó bá dẹ́ṣẹ̀ nítorí èèyàn ni wọ́n, nítorí náà ohun tí onítọ̀hún bá ṣe àti ẹ̀rí tí wọ́n bá rí ni wọ́n á fi ṣèdájọ́ rẹ̀. Lábẹ́ Òfin Mósè, ikú ni ìyà ẹ̀ṣẹ̀ ẹni tó bá ṣe panṣágà. Ọlọ́run ò sì fún àwọn tó ń dájọ́ nílẹ̀ Ísírẹ́lì láṣẹ láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ panṣágà ji ẹnikẹ́ni.
Àmọ́ o, Ọlọ́run tòótọ́ lágbára láti rí ohun tó wà lọ́kàn èèyàn, ó sì lè dárí jini tó bá rí i pé ó yẹ bẹ́ẹ̀. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Dáfídì, ẹni tí Jèhófà ti bá dá májẹ̀mú Ìjọba ló dẹ́ṣẹ̀, Jèhófà ò jẹ́ káwọn adájọ́ tó jẹ́ èèyàn dá ẹjọ́ yìí, ńṣe ló pinnu láti dá a fúnra rẹ̀. (2 Sámúẹ́lì 7:12-16) Dájúdájú, “Onídàájọ́ gbogbo ilẹ̀ ayé” lẹ́tọ̀ọ́ láti ṣe irú ìpinnu bẹ́ẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 18:25.
Kí ni Jèhófà rí nígbà tó ṣàyẹ̀wò ọkàn Dáfídì? Àkọlé Sáàmù kọkànléláàádọ́ta jẹ́ ká mọ̀ pé sáàmù yìí sọ bí ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí ṣe rí lọ́kàn Dáfídì “nígbà tí Nátánì wòlíì wọlé tọ̀ ọ́ wá lẹ́yìn tí ó ti ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú Bátí-ṣébà.” Sáàmù kọkànléláàádọ́ta ẹsẹ kìíní sí ìkẹrin kà pé: “Fi ojú rere hàn sí mi, Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́. Nu àwọn ìrélànàkọjá mi kúrò gẹ́gẹ́ bí ọ̀pọ̀ yanturu àánú rẹ. Wẹ̀ mí mọ́ tónítóní kúrò nínú ìṣìnà mi, kí o sì wẹ̀ mí mọ́ àní kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ mi. Nítorí èmi fúnra mi mọ àwọn ìrélànàkọjá mi, ẹ̀ṣẹ̀ mi sì ń bẹ ní iwájú mi nígbà gbogbo. Ìwọ, ìwọ nìkan ṣoṣo, ni mo dẹ́ṣẹ̀ sí, mo sì ti ṣe ohun tí ó burú ní ojú rẹ.” Ó dájú pé Jèhófà á ti rí i nínú ọkàn Dáfídì pé ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ yìí jẹ́ ẹ̀rí pé tọkàntọkàn ló fi ronú pìwà dà, nípa bẹ́ẹ̀ Jèhófà pinnu láti fi àánú hàn sáwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ méjèèjì. Yàtọ̀ síyẹn, aláàánú èèyàn ni Dáfídì fúnra rẹ̀, Jèhófà sì máa ń ṣàánú àwọn aláàánú. (1 Sámúẹ́lì 24:4-7; Mátíù 5:7; Jákọ́bù 2:13) Nítorí náà, nígbà tí Dáfídì jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, Nátánì sọ fún un pé: “Jèhófà, ẹ̀wẹ̀, jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ kọjá lọ. Ìwọ kì yóò kú.”—2 Sámúẹ́lì 12:13.
Síbẹ̀síbẹ̀, Dáfídì àti Bátí-ṣébà ò mú ohun tí wọ́n ṣe jẹ. Nátánì sọ fún Dáfídì pé: “Nítorí pé ìwọ hùwà àìlọ́wọ̀ sí Jèhófà láìsí àní-àní, nípa nǹkan yìí, ọmọkùnrin náà gan-an pẹ̀lú, tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí fún ọ, yóò kú dájúdájú.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì gbààwẹ̀ ó sì ṣọ̀fọ̀ fún ọjọ́ méje nígbà tí ọmọ náà ń ṣàìsàn, ọmọ ọwọ́ náà pàpà kú.—2 Sámúẹ́lì 12:14-18.
Àwọn kan ò gbà pé ó yẹ kí ọmọ náà kú nítorí pé Diutarónómì 24:16 sọ pé: “Kí a má [ṣe] fi ikú pa àwọn ọmọ ní tìtorí àwọn baba.” Àmọ́, a ò gbọ́dọ̀ gbàgbé pé ká ni èèyàn ló dá ẹjọ́ náà ni, àtàwọn òbí méjèèjì àti oyún inú ni ì bá kú. Síwájú sí i, kíkú tọ́mọ náà kú lè jẹ́ kí Dáfídì mọ bí ẹ̀ṣẹ̀ tí òun àti Bátí-ṣébà dá ṣe dun Jèhófà tó. Ó dájú pé ìdájọ́ òdodo ni Jèhófà ṣe nígbà tó dá ẹjọ́ yẹn nítorí pé “pípé ni ọ̀nà rẹ̀.”—2 Sámúẹ́lì 22:31.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Dáfídì ronú pìwà dà tọkàntọkàn