Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ayé Tẹ́nikẹ́ni Ò Ti Ní Tòṣì Sún Mọ́lé

Ayé Tẹ́nikẹ́ni Ò Ti Ní Tòṣì Sún Mọ́lé

Ayé Tẹ́nikẹ́ni Ò Ti Ní Tòṣì Sún Mọ́lé

INÚ àwọn aláìní máa ń dùn tí wọ́n bá rí àwòrán Párádísè bí irú èyí tó wà lẹ́yìn ìwé ìròyìn yìí. Ádámù àti Éfà, tọkọtaya àkọ́kọ́, wà nínú Párádísè nígbà kan rí. Ọgbà Édẹ́nì nibi tí wọ́n ń gbé nígbà náà. (Jẹ́nẹ́sísì 2:7-23) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n pàdánù Párádísè yẹn, èyí ò ní ká má gbà gbọ́ pé Párádísè kan ń bọ̀ lọ́jọ́ ọ̀la, ìyẹn ayé tuntun kan tẹ́nikẹ́ni kò ti ní tòṣì rárá. Àwọn ìlérí tó wà nínú Bíbélì jẹ́ kó dáni lójú pé Párádísè ń bọ̀.

Ìwọ wo ìlérí kan tí Jésù Kristi ṣe lọ́jọ́ tó lò kẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé. Ọ̀kan lára àwọn aṣebi tí wọ́n pa nígbà kan náà pẹ̀lú Jésù gbà gbọ́ pé Ọlọ́run lè yanjú àwọn ìṣòro aráyé. Ó sọ fún Jésù pé: “Jésù, rántí mi nígbà tí o bá dé inú ìjọba rẹ.” Ọ̀rọ̀ tó sọ yìí fi hàn pé ó gbà gbọ́ pé Jésù yóò jọba àti pé àwọn òkú yóò jíǹde. Jésù wá sọ fún un pé: “Lóòótọ́ ni mo sọ fún ọ lónìí, Ìwọ yóò wà pẹ̀lú mi ní Párádísè.”—Lúùkù 23:42, 43.

Bíbélì sọ irú ìgbésí ayé táwọn tó máa wà nínú Párádísè yóò máa gbé, ó ní: “Dájúdájú wọn yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn; dájúdájú, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì máa jẹ èso wọn.” (Aísáyà 65:21) Láìsí àní-àní, “wọn yóò . . . jókòó ní ti tòótọ́, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, kì yóò sì sí ẹnì kankan tí yóò máa mú wọn wárìrì; nítorí ẹnu Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun ti sọ ọ́.”—Míkà 4:4.

Àmọ́, kí ló fà á táwọn èèyàn fi ń tòṣì láyé yìí? Ìrànlọ́wọ́ wo ni Ọlọ́run ń ṣe fáwọn òtòṣì? Ìgbà wo ni kò ní sí òtòṣì mọ́ láyé?

Kí Ló Fà Á Táwọn Èèyàn Fi Ń Tòṣì Láyé Yìí?

Ọ̀tẹ̀ kan tí áńgẹ́lì burúkú kan tó ń jẹ́ Sátánì Èṣù dá sílẹ̀ ló jẹ́ kí Ádámù àti Éfà pàdánù Párádísè tí Ọlọ́run dá wọn sí. Sátánì gbẹnu ejò bá Éfà sọ̀rọ̀, ó sì fẹ̀tàn mú un láti rú òfin tí Ọlọ́run fún wọn, ìyẹn òfin tó ní wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ èso igi kan. Ẹ̀tàn náà sì mú kí Éfà gbà pé tóun bá lè kúrò lábẹ́ àkóso Ọlọ́run, òun á máa jayé orí òun lọ ni. Nígbà tí Éfà fún Ádámù ní èso yẹn, òun náà bá aya rẹ̀ lẹ̀dí àpò pọ̀, ó jẹ ẹ́, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ kẹ̀yìn sí Ọlọ́run.—Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6; 1 Tímótì 2:14.

Bí Ọlọ́run ṣe lé tọkọtaya ọlọ̀tẹ̀ yìí kúrò nínú Párádísè nìyẹn, tí wọ́n wá ń ráágó kí wọ́n tó rí oúnjẹ jẹ. Jèhófà fi Sátánì sílẹ̀ kó máa ṣàkóso aráyé ẹlẹ́ṣẹ̀ látìgbà náà wá kí aráyé lè rí ohun tí àìgbọràn sí Ọlọ́run máa ń yọrí sí. Ìtàn ìran èèyàn látìgbà náà títí di ìsinsìnyí sì ti jẹ́ kó hàn gbangba pé ọmọ èèyàn ò lè sọ ayé yìí di Párádísè. (Jeremáyà 10:23) Kàkà bẹ́ẹ̀, onírúurú ìṣòro ni mímú tí aráyé mú ara wọn kúrò lábẹ́ àkóso Ọlọ́run fà, títí kan àìríná àìrílò tí ń bẹ nínú ayé lónìí.—Oníwàásù 8:9.

Ṣùgbọ́n o, Ọlọ́run ò dá àwọn aláìní dá ìṣòro wọn nínú ayé tó kún fún ìṣòro yìí. Ó ti pèsè ìtọ́sọ́nà tó jọjú fún wọn nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀.

“Ẹ Má Ṣàníyàn Láé”

Lọ́jọ́ kan, Jésù ń bá àwùjọ ńlá kan sọ̀rọ̀, àwọn aláìní sì wà níbẹ̀. Ó sọ pé: “Ẹ fi tọkàntara ṣàkíyèsí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run, nítorí wọn kì í fún irúgbìn tàbí ká irúgbìn tàbí kó jọ sínú ilé ìtọ́jú nǹkan pa mọ́; síbẹ̀ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run ń bọ́ wọn. Ẹ kò ha níye lórí jù wọ́n lọ bí? . . . Nítorí náà, ẹ má ṣàníyàn láé, kí ẹ sì wí pé, ‘Kí ni a ó jẹ?’ tàbí, ‘Kí ni a ó mu?’ tàbí, ‘Kí ni a ó wọ̀?’ Nítorí gbogbo ìwọ̀nyí ni nǹkan tí àwọn orílẹ̀-èdè ń fi ìháragàgà lépa. Nítorí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run mọ̀ pé ẹ nílò gbogbo nǹkan wọ̀nyí. Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.”—Mátíù 6:26-33.

Pé èèyàn jẹ́ aláìní kò ní kó jalè o. (Òwe 6:30, 31) Tó bá lè fi ti Ọlọ́run ṣáájú nígbèésí ayé, ó dájú pé Ọlọ́run yóò pèsè ohun tó ṣaláìní fún un. Wo àpẹẹrẹ ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Tukiso tó ń gbé ní ilẹ̀ Lesotho níhà gúúsù Áfíríkà. Lọ́dún 1998, àwọn ọmọ ogun orílẹ̀-èdè mìíràn wá sí Lesotho láti wá paná ogun táwọn kan gbé dìde sí ìjọba. Ogun yìí làwọn èèyàn fi bojú tí wọ́n ń fọ́ ṣọ́ọ̀bù, tí wọ́n sì ń kó ọjà ọlọ́jà. Ogun yìí ò sì tún jẹ́ káwọn èèyàn ríṣẹ́ ṣe mọ́, ìyàn sì mú gidigidi.

Ibi táwọn tó tòṣì jù lọ ń gbé ní olú ìlú Lesotho ni Tukiso ń gbé. Ọ̀pọ̀ lára àwọn aládùúgbò rẹ̀ ló lọ báwọn jí ọjà kó kí wọ́n lè rí nǹkan jẹ kí wọ́n sì rí nǹkan lò. Nígbà tí Tukiso máa dénú yàrá kan ṣoṣo tó ń gbé, ó rí i pé Maseiso, obìnrin tóun pẹ̀lú ẹ̀ jọ ń gbé, ti kó àwọn nǹkan tó jí kúnnú ilé kítikìti. Tukiso wá sọ fún un pé: “Kó ẹrù wọ̀nyí jáde síta.” Ó ní òfin Ọlọ́run sọ pé èèyàn ò gbọ́dọ̀ jalè. Ni Maseiso bá kó wọn jáde. Àwọn aládùúgbò wọn wá ń fi wọ́n ṣẹlẹ́yà, wọ́n sì pín ẹrù náà mọ́ra wọn lọ́wọ́.

Ẹ̀kọ́ Bíbélì tí Tukiso kọ́ lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ò jẹ́ kó gba ẹrù olè náà. Ǹjẹ́ ebi ò fẹ́rẹ̀ẹ́ yọjú ẹ̀ bó ṣe pa òfin Ọlọ́run mọ́ yìí? Rárá o. Láìpẹ́, àwọn alàgbà kan nínú ìjọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí Tukiso ń lọ wá a kàn, wọ́n sì kó oúnjẹ fún un. Kódà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè Gúúsù Áfíríkà nítòsí wọn kó àwọn nǹkan bí oúnjẹ, aṣọ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ránṣẹ́ sáwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin wọn ní Lesotho láti fi ràn wọ́n lọ́wọ́. Tá a bá díwọ̀n ohun tí wọ́n kó ránṣẹ́, ó wúwo ju ogójì àpò sìmẹ́ǹtì lọ. Bí Tukiso ṣe pa òfin Ọlọ́run mọ́ àti bí ìjọ ṣe fìfẹ́ ràn wọ́n lọ́wọ́ yìí wú Maseiso lórí gan-an ni. Òun náà wá bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tó yá, àwọn méjèèjì lọ gbàwé ẹ̀rí ìgbéyàwó wọn lọ́dọ̀ ìjọba kí wọ́n lè ṣèrìbọmi, kí wọ́n sì di ọkàn lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Wọ́n ṣì ń sin Ọlọ́run tọkàntọkàn di báyìí.

Jèhófà Ọlọ́run ò gbà gbé àwọn aláìní o. (Wo àpótí tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ “Ojú Wo Ni Ọlọ́run Fi Ń Wo Àwọn Òtòṣì?”) Ó ti fi ìfẹ́ ṣètò báwọn èèyàn bíi Tukiso àti Maseiso ṣe máa lè túbọ̀ mọ̀ nípa òun. Ó sì tún kọ ìtọ́sọ́nà nípa bó ṣe ỵẹ kéèyàn máa gbé ìgbé ayé sínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún wọn.

Ohun Àtàtà Tí Ọlọ́run Pèsè

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń gbìyànjú nígbà gbogbo láti ran àwọn òtòṣì lọ́wọ́ bí Ọlọ́run ṣe máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́. (Gálátíà 2:10) Lọ́pọ̀ ìgbà, tí àjálù bá ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀-èdè kan tó sì kan àwọn Kristẹni tòótọ́, a máa ń ṣètò báwọn ará yẹn á ṣe rí ìrànlọ́wọ́ tó yẹ gbà. Àmọ́ ní pàtàkì jù lọ, ohun tó máa ṣe àwọn èèyàn ní gbogbo gbòò láǹfààní nípa tẹ̀mí, títí kan àwọn aláìní, ló jẹ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lógún jù. (Mátíù 9:36-38) Láti ọgọ́ta ọdún sẹ́yìn ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn òjíṣẹ́ tá a ti dá lẹ́kọ̀ọ́ ti ń yọ̀ǹda ara wọn láti lọ ṣiṣẹ́ Ọlọ́run nílẹ̀ òkèèrè. Bí àpẹẹrẹ, tọkọtaya kan tó jẹ́ míṣọ́nnárì tí wọ́n wá láti orílẹ̀-èdè Finland, tí wọ́n kọ́ èdè Sesotho, ló kọ́ Tukiso àti Maseiso lẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n fi di ọmọlẹ́yìn Jésù. (Mátíù 28:19, 20) Irú iṣẹ́ míṣọ́nnárì bẹ́ẹ̀ sábà máa ń gba pé kéèyàn fi ìgbé ayé ìdẹ̀rùn nílùú tí nǹkan ti rọ̀ṣọ̀mù sílẹ̀ láti wá sórílẹ̀-èdè tí wọn ò ti fi bẹ́ẹ̀ rí jájẹ.

Bó ti wù kí nǹkan nira tó fáwọn Kristẹni tòótọ́, wọn kì í jalè rárá. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n gbà gbọ́ pé Jèhófà Ọlọ́run yóò ṣe ọ̀nà àtijẹ-àtimu fáwọn bópẹ́bóyá. (Hébérù 13:5, 6) Ọ̀nà kan tí Jèhófà máa ń gbà pèsè fáwọn èèyàn rẹ̀ ni pé ó máa ń lo ètò rẹ̀ táwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó ń ran ara wọn lọ́wọ́ jákèjádò ayé wà.

Ọ̀nà mìíràn tí Jèhófà máa ń gbà ran àwọn òtòṣì lọ́wọ́ ni pé ó máa ń fún wọn ní ìtọ́sọ́nà tó wúlò gan-an nípa bó ṣe yẹ kí wọ́n máa gbé ìgbé ayé. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé: “Kí ẹni tí ń jalè má jalè mọ́, ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, kí ó máa ṣe iṣẹ́ àṣekára, kí ó máa fi ọwọ́ rẹ̀ ṣe ohun tí ó jẹ́ iṣẹ́ rere, kí ó lè ní nǹkan láti pín fún ẹni tí ó wà nínú àìní.” (Éfésù 4:28) Ọ̀pọ̀ àwọn tó wáṣẹ́ àmọ́ tí wọn ò rí ti fúnra wọn wá nǹkan ṣe, wọ́n ń ṣe iṣẹ́ àṣekára, irú bíi kí wọ́n máa gbin ewébẹ̀. Bíbélì tún kọ́ àwọn tálákà ní bí wọ́n ṣe lè máa ní tọ́rọ́-kọ́bọ̀ lọ́wọ́ nípa yíyẹra fún ìwàkiwà tó lè jẹ́ kí wọ́n máa ná ìná àpà, irú bí ọtí àmujù.—Éfésù 5:18.

Ìgbà Wo Ni Ayé Téèyàn Ò Ti Ní Tòṣì Yóò Dé?

Bíbélì fi yé wa pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ìṣàkóso Sátánì la wà yìí. (2 Tímótì 3:1) Láìpẹ́, Jèhófà Ọlọ́run yóò rán Jésù Kristi wá ṣèdájọ́ ayé. Kí ló máa wá ṣẹlẹ̀ nígbà náà? Jésù dáhùn ìbéèrè yìí nínú ọ̀kan lára àkàwé rẹ̀. Ó ní: “Nígbà tí Ọmọ ènìyàn bá dé nínú ògo rẹ̀, àti gbogbo àwọn áńgẹ́lì pẹ̀lú rẹ̀, nígbà náà ni yóò jókòó lórí ìtẹ́ ògo rẹ̀. Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ni a ó sì kó jọ níwájú rẹ̀, yóò sì ya àwọn ènìyàn sọ́tọ̀ ọ̀kan kúrò lára èkejì, gan-an gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn kan tí ń ya àwọn àgùntàn sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ewúrẹ́.”—Mátíù 25:31-33.

Àwọn tó gbà kí Jésù ṣàkóso àwọn ni àwọn àgùntàn tí àkàwé yìí ń sọ. Jésù fi wọ́n wé àgùntàn nítorí pé wọ́n ń tẹ̀ lé òun tó jẹ́ Olùṣọ́ Àgùntàn wọn lẹ́yìn. (Jòhánù 10:16) Àwọn ẹni bí àgùntàn wọ̀nyí yóò jogún ìyè lábẹ́ àkóso pípé tí Jésù yóò ṣe. Ayé aláyọ̀ làwọn èèyàn yóò máa gbé nínú ayé tuntun tẹ́nikẹ́ni ò ti ní tòṣì. Jésù yóò sì pa àwọn ẹni bí ewúrẹ́ tó kọ ìṣàkóso rẹ̀ run.—Mátíù 25:46.

Ìjọba Ọlọ́run yóò fòpin sí ìwà ibi. Ẹnikẹ́ni ò ní tòṣì mọ́ láé. Dípò ìyẹn, àwọn tó nífẹ̀ẹ́ ara wọn tí wọ́n sì ń ran ara wọn lọ́wọ́ ni yóò máa gbénú ayé. Bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò ayé ṣe fẹ́ràn ara wọn bí ọmọ ìyá jẹ́ ká mọ̀ pé irú ayé tuntun bẹ́ẹ̀ yóò wà, nítorí Jésù sọ pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.”—Jòhánù 13:35.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6, 7]

OJÚ WO NI ỌLỌ́RUN FI Ń WO ÀWỌN ÒTÒṢÌ?

Bíbélì sọ pé Ẹlẹ́dàá èèyàn jẹ́ “Ẹni tí ń fi oúnjẹ fún àwọn tí ebi ń pa.” (Sáàmù 146:7) Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ẹsẹ Bíbélì ló sì sọ ohun tó fi hàn pé Ọlọ́run ò gbàgbé àwọn òtòṣì.

Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jèhófà fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́ ní Òfin rẹ̀, ó pàṣẹ pé kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ àgbẹ̀ má ṣe kórè eteetí oko wọn pátápátá. Ó ní bí wọ́n bá ti kórè èso ólífì àti ti àjàrà wọn lọ́wọ́ kan kí wọ́n má padà lọ máa wá èyí tó bá ṣẹ́ kù. Tìtorí àwọn àtìpó, àwọn ọmọ aláìlóbìí, àwọn opó àtàwọn mìíràn bẹ́ẹ̀ tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ ni Ọlọ́run ṣe ṣòfin onífẹ̀ẹ́ yìí.—Léfítíkù 19:9, 10; Diutarónómì 24:19-21.

Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Ọlọ́run pàṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣẹ́ opó èyíkéyìí tàbí ọmọdékùnrin aláìníbaba níṣẹ̀ẹ́. Bí o bá ṣẹ́ ẹ níṣẹ̀ẹ́ pẹ́nrẹ́n, tí ó sì ké jáde sí mi pẹ́nrẹ́n, èmi yóò gbọ́ igbe ẹkún rẹ̀ láìkùnà; ìbínú mi yóò sì ru ní ti gidi, èmi yóò sì fi idà pa yín dájúdájú, àwọn aya yín yóò sì di opó, àwọn ọmọkùnrin yín yóò sì di ọmọdékùnrin aláìníbaba.” (Ẹ́kísódù 22:22-24) Ó ṣeni láàánú pé ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ ọlọ́rọ̀ ò pa òfin yìí mọ́. Jèhófà Ọlọ́run wá gbẹnu àwọn wòlíì rẹ̀ kìlọ̀ lónírúurú ọ̀nà fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n ṣíwọ́ ohun tí wọ́n ń ṣe yìí àtàwọn ìwà burúkú mìíràn tí wọ́n ń hù. (Aísáyà 10:1, 2; Jeremáyà 5:28; Ámósì 4:1-3) Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, Ọlọ́run jẹ́ káwọn ará Ásíríà ṣẹ́gun ilẹ̀ Ísírẹ́lì, ó sì tún jẹ́ káwọn ará Bábílónì náà ṣẹ́gun wọn lẹ́yìn náà. Bí wọ́n ṣe pa ọ̀pọ̀ nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nìyẹn, tí wọ́n sì kó àwọn tó kù nígbèkùn lọ sílẹ̀ àjèjì.

Jésù Kristi, ààyò Ọmọ Ọlọ́run, ní irú ẹ̀mí aájò tí Baba rẹ̀ ní fún àwọn òtòṣì. Nígbà tí Jésù ń ṣàlàyé ìdí tóun fi ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ òun, ó ní: “Ẹ̀mí Jèhófà ń bẹ lára mi, nítorí tí ó fòróró yàn mí láti polongo ìhìn rere fún àwọn òtòṣì.” (Lúùkù 4:18) Èyí ò túmọ̀ sí pé àwọn òtòṣì nìkan ni iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù wà fún o. Tìfẹ́tìfẹ́ ló fi ran àwọn ọlọ́rọ̀ náà lọ́wọ́. Àmọ́ bí Jésù bá ń ran àwọn ọlọ́rọ̀ lọ́wọ́, ó máa ń jẹ́ kó hàn pé òun ò gbàgbé àwọn òtòṣì náà. Bí àpẹẹrẹ, ó fún olùṣàkóso kan tó jẹ́ ọlọ́rọ̀ nímọ̀ràn pé: “Ta gbogbo ohun tí o ní, kí o sì pín in fún àwọn òtòṣì, ìwọ yóò sì ní ìṣúra ní ọ̀run; sì wá di ọmọlẹ́yìn mi.”—Lúùkù 14:1, 12-14; 18:18, 22; 19:1-10.

Ọ̀ràn àwọn òtòṣì jẹ Jèhófà Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀ lógún gan-an ni. (Máàkù 12:41-44; Jákọ́bù 2:1-6) Ọ̀ràn wọn jẹ Jèhófà lógún débi pé ó fi ọ̀kẹ́ àìmọye wọn tó ti kú sí ìrántí. Gbogbo irú àwọn bẹ́ẹ̀ ni yóò sì jí dìde sí ayé tuntun kan tẹ́nikẹ́ni ò ti ní tòṣì láéláé.—Ìṣe 24:15.

[Àwọn àwòrán]

Bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò ayé ṣe fẹ́ràn ara wọn bí ọmọ ìyá jẹ́ ká mọ̀ dájú pé ayé tuntun ń bọ̀ lóòótọ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Tukiso àti Maseiso rèé pẹ̀lú míṣọ́nnárì tó kọ́ Tukiso lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Maseiso ló dúró lẹ́nu ọ̀nà ilé rẹ̀ yìí àti míṣọ́nnárì tó kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì