Kí Nìdí Táwọn Èèyàn Kì Í Fi Bẹ́ẹ̀ Lo Làákàyè?
Kí Nìdí Táwọn Èèyàn Kì Í Fi Bẹ́ẹ̀ Lo Làákàyè?
NÍGBÀ tẹ́nì kan rí ohun tí ọkùnrin kan ṣe, ó ní: “Kí ló tiẹ̀ ń ṣe ọ̀gbẹ́ni yìí ná? Òun kọ́ ló yẹ kó máa ṣe irú nǹkan yẹn.” Ẹnì kan tó tún rí ohun tó ṣe mirí, nítorí ó yà á lẹ́nu pé ó lè ṣe irú ohun tó ṣe yẹn. Bí ẹni náà ṣe ń rìn lọ ló ń kùn pé: “Ẹni tó bá ní làákàyè ò ní jẹ́ ṣe irú nǹkan tó ṣe yẹn.” Ǹjẹ́ o ti gbọ́ irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ rí? Kí ló túmọ̀ sí tá a bá sọ pé ẹnì kan ní làákàyè?
Onílàákàyè ẹ̀dá jẹ́ ẹnì kan tó lọ́gbọ́n, tó sì lóye. Èyí túmọ̀ sí pé ó lè lo ọgbọ́n orí rẹ̀ láti fi ṣe ìpinnu tó dára tàbí láti fi mọ ohun tó yẹ. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló wà tó jẹ́ pé àwọn ẹlòmíì ló máa ń pinnu ohun tí wọ́n máa ṣe fún wọn. Ohun tí wọ́n ń rí lórí tẹlifíṣọ̀n àtèyí tí wọ́n ń gbọ́ lórí rédíò, tàbí èyí táwọn ojúgbà wọn bá sọ fún wọn, tàbí ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń ṣe ni wọ́n fi ń pinnu ohun tí wọ́n máa ṣe.
Ó dà bíi pé àwọn èèyàn kì í fi bẹ́ẹ̀ lo làákàyè nínú ayé tá a wà yìí, ìyẹn ni ọkùnrin kan rí tó fi sọ pé: ‘Àwọn tó ní làákàyè ò tó nǹkan lóòótọ́.’ Báwo la ṣe lè dẹni tó ní làákàyè? Kí sì ni àǹfààní tó wà nínú kéèyàn jẹ́ onílàákàyè?
Báwo La Ṣe Lè Dẹni Tó Ní Làákàyè?
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kéèyàn tó lè jẹ́ onílàákàyè kì í ṣe ọ̀rọ̀ ọjọ́ kan, ó sì gba pé kéèyàn jẹ́ ẹni tó ń ronú jinlẹ̀ kéèyàn sì máa sapá gidigidi, síbẹ̀ èèyàn ṣì lè jẹ́ onílàákàyè. Ronú nípa àwọn ohun mẹ́ta yìí tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní làákàyè.
Kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kó o sì tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wà nínú rẹ̀. Bíbélì lè ràn wá lọ́wọ́ láti di ọlọgbọ́n àti onílàákàyè nítorí pé ó jẹ́ ìwé kan tí wọ́n kọ lọ́nà tó dára gan-an, ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ sì tètè ń yéni. (Éfésù 1:8) Bí àpẹẹrẹ, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni bíi tirẹ̀ níyànjú pé: “Ohun yòówù tí ó jẹ́ òótọ́, ohun yòówù tí ó jẹ́ ti ìdàníyàn ṣíṣe pàtàkì, ohun yòówù tí ó jẹ́ òdodo, ohun yòówù tí ó jẹ́ mímọ́ níwà, ohun yòówù tí ó dára ní fífẹ́, ohun yòówù tí a ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ dáadáa, ìwà funfun yòówù tí ó bá wà, ohun yòówù tí ó bá sì wà tí ó yẹ fún ìyìn, ẹ máa bá a lọ ní gbígba nǹkan wọ̀nyí rò.” (Fílípì 4:8) Tá a bá ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí nígbà gbogbo, ìwà tó mọ́gbọ́n dání tó fi hàn pé a ní làákàyè la ó máa hù.
Fi ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí ọ kọ́gbọ́n. Akéwì ọmọ ilẹ̀ Switzerland kan sọ bí ọgbọ́n àti ìrírí èèyàn nígbèésí ayé ṣe wọnú ara wọn, ó ní: “Ìrírí àti àròjinlẹ̀ . . . ló máa ń múni gbọ́n.” Ìyẹn ló fi jẹ́ pé “ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ aláìní ìrírí ń ní ìgbàgbọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n afọgbọ́nhùwà máa Òwe 14:15) Àwọn nǹkan tá a rí, ẹ̀kọ́ tá a kọ́, àtohun tó ṣẹlẹ̀ sí wa lè mú ká gbọ́n. Nípa bẹ́ẹ̀, bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ó ṣeé ṣe ká mọ bá a ṣe lè yẹra fáwọn àṣìṣe kan tá a ti ṣe sẹ́yìn. Àmọ́ a gbọ́dọ̀ lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ ká sì níwà tútù ká tó lè gbà pé a ṣàṣìṣe. Bí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe jẹ́ ajọra-ẹni-lójú, onígbèéraga àti olùwarùnkì lákòókò òpin tá à ń gbé yìí kì í ṣe ìwà ẹni tó ní làákàyè rárá.—2 Tímótì 3:1-5.
ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Má ṣe kẹ́gbẹ́kẹ́gbẹ́. Àwọn tá à ń bá kẹ́gbẹ́ lè mú ká dẹni tó ń lo ọgbọ́n àti làákàyè, wọ́n sì lè mú ká hùwà òmùgọ̀. Òwe 13:20 sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.” Kò yẹ ká máa ṣe bíi tàwọn tó ń ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run tí wọn ò sì kọbi ara sí Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Òwe 17:12 sọ pé: “Ó yá kí ènìyàn pàdé béárì tí ó ṣòfò ọmọ rẹ̀ ju kí ó pàdé ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ arìndìn nínú ìwà òmùgọ̀ rẹ̀.”
Àǹfààní Wo Ló Wà Nínú Kéèyàn Jẹ́ Onílàákàyè?
Àǹfààní ńlá ló wà nínú kéèyàn jẹ́ onílàákàyè. Ó ń mú kí ìgbésí ayé túbọ̀ gbádùn mọ́ni, kì í sì í mú kéèyàn fàkókò ṣòfò. Téèyàn bá jẹ́ onílàákàyè, kò ní hùwà aláìlọ́gbọ́n tó máa kábàámọ̀ rẹ̀ nígbà tó bá yá. Ńṣe làwọn tí ò lọ́gbọ́n lórí máa ń kóra wọn sí wàhálà. Bíbélì sọ pé: “Iṣẹ́ àṣekára àwọn arìndìn ń tán wọn lókun.” (Oníwàásù 10:15) Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lè máa ṣiṣẹ́ bí ẹni máa kú, síbẹ̀ wọ́n lè má ṣàṣeyọrí.
Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìmọ̀ràn ni Bíbélì fún wa lórí ọ̀rọ̀ ìmọ́tótó, ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀, bá a ṣe lè jẹ́ òṣìṣẹ́ aláápọn, ohun téèyàn lè ṣe tó bá jẹ́ aláìní, àti lórí àwọn nǹkan mìíràn nígbèésí ayé. Ẹgbàágbèje èèyàn lè jẹ́rìí sí i pé nígbà tí àwọn bá tẹ̀ lé ìlànà Bíbélì tó ń jẹ́ kí wọ́n hùwà ọgbọ́n, nǹkan máa ń dára fáwọn, àmọ́ tí àwọn ò bá tẹ̀ lé àwọn ìlànà wọ̀nyí, nǹkan kì í lọ déédéé fún wọn.
Tá a bá ní làákàyè, a ò kàn ní máa tẹ̀ lé ìtọ́ni àti òfin lásán, ńṣe la ó máa ṣe ojúṣe wa bó ṣe yẹ. Àmọ́ ṣá, kì í ṣe pé téèyàn bá ti jẹ́ onílàákàyè kó wá pa ẹ̀kọ́ kíkọ́ tì o. Òwe 1:5 sọ pé: “Ọlọ́gbọ́n yóò fetí sílẹ̀, yóò sì gba ìtọ́ni púpọ̀ sí i.” A tún gbọ́dọ̀ mọ bá a ṣe lè gbé àwọn ohun tá a bá ń kọ́ yẹ̀ wò, ká sì mọ ohun tó yẹ ká mú lò nínú wọn. Èyí á jẹ́ ká lè máa “fi ọgbọ́n rìn.”—Òwe 28:26.
Ẹni tó bá ní làákàyè kì í kọjá ayé rẹ̀. Ó lè wù wá pé ká máa bójú tó tibí-tọ̀hún, àmọ́ ó yẹ ká lo làákàyè wa, ká má ṣe ju agbára wa lọ. Lóòótọ́, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé ká “ní púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe . . . nínú iṣẹ́ Olúwa.” (1 Kọ́ríńtì 15:58) Síbẹ̀, kò yẹ ká gbàgbé ohun tó wà nínú Oníwàásù 9:4 tó sọ pé: “Ààyè ajá sàn ju òkú kìnnìún lọ.” Tá a bá ń tọ́jú ara wa bó ṣe yẹ bá a ṣe ń ṣiṣẹ́ sin Jèhófà, èyí lè mú kí ẹ̀mí wa gùn sí i ká sì máa bá iṣẹ́ Ọlọ́run nìṣó. Làákàyè lè ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe ṣe kọjá ibi tágbára wa mọ ká má bàa di ẹni tí kò láyọ̀ mọ́. Ẹ lè wá rí i báyìí pé ọ̀pọ̀ àǹfààní ló wà nínú kéèyàn jẹ́ onílàákàyè.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìmọ̀ràn ló wà nínú Bíbélì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Àwọn nǹkan téèyàn rí, ẹ̀kọ́ téèyàn kọ́, àtohun tó ti ṣẹlẹ̀ síni lè múni gbọ́n