Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

‘Máa Kó Ara Rẹ Níjàánu Lábẹ́ Ibi’

‘Máa Kó Ara Rẹ Níjàánu Lábẹ́ Ibi’

‘Máa Kó Ara Rẹ Níjàánu Lábẹ́ Ibi’

“Kò yẹ kí ẹrú Olúwa máa jà, ṣùgbọ́n ó yẹ kí ó jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ sí gbogbo ènìyàn, . . . [ẹni] tí ń kó ara rẹ̀ ní ìjánu lábẹ́ ibi.”—2 TÍMÓTÌ 2:24.

1. Kí nìdí táwọn kan fi máa ń fìbínú sọ̀rọ̀ sí wá nígbà tá a bá ń ṣiṣẹ́ ìwàásù?

 Kí lo máa ń ṣe tó o bá pàdé àwọn èèyàn kan tí kò fẹ́ rí ọ sójú tàbí àwọn tí kò fẹ́ gbọ́ ohun tó o fẹ́ sọ fún wọn? Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa ohun tí yóò máa ṣẹlẹ̀ láwọn ọjọ́ ìkẹyìn, ó sọ pé àwọn èèyàn yóò jẹ́ “asọ̀rọ̀ òdì, . . . afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò.” (2 Tímótì 3:1-5, 12) Ó ṣeé ṣe ká bá irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ pàdé lóde ẹ̀rí tàbí láwọn ibòmíràn.

2. Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo ló lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa fi ọgbọ́n bá àwọn tó máa ń fi ìkanra sọ̀rọ̀ sí wa lò?

2 Kì í ṣe gbogbo ẹni tó ń sọ̀rọ̀ ṣàkàṣàkà sí èèyàn ni kò fẹ́ ohun tó dára. Ó lè jẹ́ pé ìnira tó pàpọ̀jù tàbí ìjákulẹ̀ ló mú káwọn kan máa fìbínú sọ̀rọ̀ sí ẹnikẹ́ni tó bá wà nítòsí wọn. (Oníwàásù 7:7) Ọ̀rọ̀kọ́rọ̀ tí ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń gbọ́ lójoojúmọ́ níbi tí wọ́n ń gbé àti níbi iṣẹ́ lè jẹ́ káwọn náà máa sọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. Àmọ́ kò yẹ kí àwa Kristẹni máa bá wọn sọ ọ́, nítorí a mọ ìdí táwọn èèyàn fi ń sọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀. Kí ló yẹ ká ṣe táwọn kan bá fi ìkanra sọ̀rọ̀ sí wa? Òwe 19:11 sọ pé: “Ìjìnlẹ̀ òye tí ènìyàn ní máa ń dẹwọ́ ìbínú rẹ̀ dájúdájú.” Róòmù 12:17, 18 sì gbà wá nímọ̀ràn pé: “Ẹ má ṣe fi ibi san ibi fún ẹnì kankan. . . . Bí ó bá ṣeé ṣe, níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.”

3. Báwo ni jíjẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà ṣe kan iṣẹ́ tá à ń jẹ́?

3 Bó bá jẹ́ pé lóòótọ́ la jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà, yóò hàn nínú ìṣesí wa. Yóò hàn nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa, ó tiẹ̀ tún lè hàn lójú wa àti nínú ohùn tá a fi sọ̀rọ̀. (Òwe 17:27) Nígbà tí Jésù ń rán àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ jáde láti lọ wàásù, ó gbà wọ́n nímọ̀ràn pé: “Nígbà tí ẹ bá ń wọ ilé, ẹ kí agbo ilé náà [“ẹ kí wọn pé, ‘Alaafia fún ilé yi,’” Bíbélì Ìròhìn Ayọ̀]; bí ilé náà bá sì yẹ, kí àlàáfíà tí ẹ fẹ́ fún un wá sórí rẹ̀; ṣùgbọ́n bí kò bá yẹ, kí àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ yín padà sọ́dọ̀ yín.” (Mátíù 10:12, 13) Ìhìn rere ni iṣẹ́ tí à ń jẹ́ fáwọn èèyàn. Bíbélì pè é ní “ìhìn rere àlàáfíà,” “ìhìn rere nípa inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run” àti “ìhìn rere ìjọba yìí.” (Éfésù 6:15; Ìṣe 20:24; Mátíù 24:14) Nítorí náà, kì í ṣe torí ká lè lọ ṣe àríwísí ohun táwọn èèyàn gbà gbọ́ tàbí ká lè bá wọn jiyàn lórí èrò tí wọ́n ní la ṣe ń lọ, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe la fẹ́ sọ ìhìn rere tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fún wọn.

4. Kí lo lè sọ tí ẹnì kan bá sọ pé òun ò fẹ́ gbọ́ kó o tiẹ̀ tó dẹ́nu lé ọ̀rọ̀ rẹ?

4 Ẹnì kan tó o fẹ́ wàásù fún lè dá ọ̀rọ̀ mọ́ ọ lẹ́nu bó o ṣe dẹ́nu lé ọ̀rọ̀ rẹ, kó ní: “Mi ò fẹ́ gbọ́.” Tẹ́nì kan bá sọ bẹ́ẹ̀, o lè sọ pé: “Ṣé ẹ lè jẹ́ kí n ka ẹsẹ Bíbélì kan péré fún yín kí n tó máa lọ.” Onítọ̀hún lè gbà ọ́ láyè láti kà á. Àmọ́ láwọn ìgbà mìíràn, o lè sọ pé: “Mo kàn ní kí n sọ fún yín nípa àkókò kan tí kò ní sí ìwà ìrẹ́jẹ mọ́ tí gbogbo èèyàn á sì nífẹ̀ẹ́ ara wọn ni.” Bó o bá rí i pé kò wu onítọ̀hún pé kó o máa bá ọ̀rọ̀ rẹ lọ, o lè sọ pé: “Ṣùgbọ́n mo rí i pé ẹ ò ráyè báyìí, bóyá kí n padà wá nígbà míì.” Kódà bí onítọ̀hún ò bá tiẹ̀ fẹ́ gbọ́, ṣé ó wá yẹ ká gbà pé ẹni náà ‘kò yẹ’? Ohun yòówù káwọn èèyàn ṣe, ó yẹ ká máa rántí ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé ká ‘jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ sí gbogbo ènìyàn, ká sì máa kó ara wa ní ìjánu lábẹ́ ibi.’—2 Tímótì 2:24.

Sọ́ọ̀lù Jẹ́ Aláfojúdi àti Onítara Òdì

5, 6. Irú ìwà wo ni Sọ́ọ̀lù hù sáwọn ọmọlẹ́yìn Jésù, kí ló sì mú kó hu irú ìwà bẹ́ẹ̀?

5 Ní ọ̀rúndún kìíní, ọkùnrin kan wà tó ń jẹ́ Sọ́ọ̀lù. Àwọn èèyàn mọ̀ ọ́n dáadáa nítorí ọ̀rọ̀ burúkú ẹnu rẹ̀ àti ìwà ìkà rẹ̀. Bíbélì sọ pé ó “ń mí èémí ìhalẹ̀mọ́ni àti ìṣìkàpànìyàn sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Olúwa.” (Ìṣe 9:1, 2) Ó fẹnu ara rẹ̀ sọ pé nígbà kan òun jẹ́ “asọ̀rọ̀ òdì àti onínúnibíni àti aláfojúdi.” (1 Tímótì 1:13) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe kí àwọn kan lára mọ̀lẹ́bí rẹ̀ ti di Kristẹni nígbà tá à ń wí yìí, síbẹ̀ ó hùwà òǹrorò sáwọn ọmọlẹ́yìn Kristi, ó sọ pé: “Níwọ̀n bí orí mi sì ti gbóná sí wọn dé góńgó, mo lọ jìnnà dé ṣíṣe inúnibíni sí wọn, kódà ní àwọn ìlú ńlá tí ń bẹ lẹ́yìn òde.” (Ìṣe 23:16; 26:11; Róòmù 16:7, 11) A ò rí i kà níbì kankan pé àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ń bá Sọ́ọ̀lù jiyàn ní gbogbo àsìkò tó ń ṣenúnibíni sáwọn Kristẹni.

6 Kí nìdí tí Sọ́ọ̀lù fi ń hùwà bẹ́ẹ̀? Ohun tó kọ lọ́pọ̀ ọdún lẹ́yìn ìgbà yẹn jẹ́ ká mọ ohun tó fà á, ó ní: “Mo jẹ́ aláìmọ̀kan, tí mo sì gbé ìgbésẹ̀ nínú àìnígbàgbọ́.” (1 Tímótì 1:13) Farisí ni Sọ́ọ̀lù, ó sì ti kẹ́kọ̀ọ́ “ní ìbámu pẹ̀lú àìgbagbẹ̀rẹ́ Òfin àwọn baba ńlá ìgbàanì.” (Ìṣe 22:3) Gàmálíẹ́lì tó jẹ́ olùkọ́ Sọ́ọ̀lù kì í ṣe ẹlẹ́tanú, àmọ́ aláṣejù ni Káyáfà tó jẹ́ àlùfáà àgbà, tí Sọ́ọ̀lù ń tẹ̀ lé. Káyáfà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn baba ìsàlẹ̀ tó di rìkíṣí pé kí wọ́n pa Jésù Kristi. (Mátíù 26:3, 4, 63-66; Ìṣe 5:34-39) Lẹ́yìn èyí, Káyáfà pàṣẹ pé kí wọ́n na àwọn àpọ́sítélì Jésù lẹ́gba, ó sì pàṣẹ fún wọn pé wọn kò gbọ́dọ̀ wàásù lórúkọ Jésù mọ́. Káyáfà ló ṣe alága níbi ìpàdé ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn tí wọ́n ti fi ìkanra ṣèdájọ́ pé kí wọ́n lọ sọ Sítéfánù lókùúta pa. (Ìṣe 5:27, 28, 40; 7:1-60) Sọ́ọ̀lù wà níbẹ̀ nígbà tí wọ́n ń sọ Sítéfánù lókùúta, Káyáfà sì pàṣẹ fún un pé kó lọ kó àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tó wà ní Damásíkù wá láti lè rí i pé wọn ò gbérí mọ́. (Ìṣe 8:1; 9:1, 2) Gbogbo èyí mú kí Sọ́ọ̀lù máa rò pé òun nítara fún Ọlọ́run, àmọ́ Sọ́ọ̀lù ò ní ojúlówó ìgbàgbọ́ rárá. (Ìṣe 22:3-5) Èrò òdì tí Sọ́ọ̀lù ní yìí ni kò jẹ́ kó gbà pé Jésù ni Mèsáyà. Àmọ́, ìgbà tí Jésù bá a sọ̀rọ̀ lọ́nà ìyanu nígbà tó ń lọ sí Damásíkù ló wá mọ̀ pé àṣìṣe ni òun ti ń ṣe látẹ̀yìnwá.—Ìṣe 9:3-6.

7. Kí ló ṣẹlẹ̀ sí Sọ́ọ̀lù nítorí ọ̀rọ̀ tí Jésù bá a sọ lọ́nà Damásíkù?

7 Kété lẹ́yìn èyí ni Jésù rán ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ kan tó ń jẹ́ Ananíà pé kó lọ jẹ́rìí fún Sọ́ọ̀lù. Bó bá jẹ́ pé ìwọ ni Ananíà, ṣé ara á yá ọ láti lọ sọ́dọ̀ Sọ́ọ̀lù? Ọkàn Ananíà ò balẹ̀, àmọ́ ohùn pẹ̀lẹ́ ló fi bá Sọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀. Ìwà Sọ́ọ̀lù ti yí padà nítorí ọ̀nà ìyanu tí Jésù gbà bá a sọ̀rọ̀ lọ́nà Damásíkù. (Ìṣe 9:10-22) Nígbà tó yá, orúkọ rẹ̀ yí padà di àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ó sì di míṣọ́nnárì onítara nínú ìjọ Kristẹni.

Jésù Jẹ́ Onínú Tútù Síbẹ̀ Ó Nígboyà

8. Báwo ni ìwà tí Jésù ń hù sáwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ṣe jọ ti Baba rẹ̀?

8 Jésù máa ń fi ìtara wàásù Ìjọba Ọlọ́run ó sì máa ń fi inú tútù bá àwọn èèyàn lò, síbẹ̀ onígboyà ni. (Mátíù 11:29) Ó fìwà jọ Baba rẹ̀ ọ̀run, ẹni tó rọ àwọn èèyàn búburú pé kí wọ́n fi ọ̀nà búburú wọn sílẹ̀. (Aísáyà 55:6, 7) Nígbà tí Jésù bá wà pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, ó máa ń kíyè sí ìwà wọn bóyá ó ti dára sí i, ó sì máa ń fún wọn níṣìírí. (Lúùkù 7:37-50; 19:2-10) Jésù kì í tìtorí pé àwọn èèyàn jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ kó pa wọ́n tì. Dípò ìyẹn ó máa ń ṣe bíi ti Baba rẹ̀ tó máa ń fi inú rere, ìmúmọ́ra àti ìpamọ́ra bá àwọn èèyàn lò, bóyá wọ́n á lè ronú pìwà dà. (Róòmù 2:4) Jèhófà fẹ́ kí gbogbo onírúurú èèyàn ronú pìwà dà, kí wọ́n sì rí ìgbàlà.—1 Tímótì 2:3, 4.

9. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ tá a bá wo bí ọ̀rọ̀ inú Aísáyà 42:1-4 ṣe ṣẹ sí Jésù lára?

9 Nígbà tí Mátíù òǹkọ̀wé Ìhìn Rere ń sọ̀rọ̀ nípa ojú tí Jèhófà fi wo Jésù Kristi, ó tọ́ka sí ọ̀rọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ yìí, tó sọ pé: “Wò ó! Ìránṣẹ́ mi tí mo yàn, olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n, ẹni tí ọkàn mi tẹ́wọ́ gbà! Dájúdájú, èmi yóò fi ẹ̀mí mi sórí rẹ̀, ohun tí ìdájọ́ òdodo jẹ́ ni yóò sì mú ṣe kedere fún àwọn orílẹ̀-èdè. Kì yóò ṣàríyànjiyàn aláriwo, tàbí kí ó ké sókè, bẹ́ẹ̀ ni ẹnikẹ́ni kì yóò gbọ́ ohùn rẹ̀ ní àwọn ọ̀nà fífẹ̀. Kò sí esùsú kankan tí a ti pa lára tí yóò tẹ̀ fọ́, kò sì sí òwú àtùpà kankan tí a fi ọ̀gbọ̀ ṣe tí ń jó lọ́úlọ́ú tí yóò fẹ́ pa, títí yóò fi rán ìdájọ́ òdodo jáde pẹ̀lú àṣeyọrí sí rere. Ní tòótọ́, nínú orúkọ rẹ̀ ni àwọn orílẹ̀-èdè yóò ní ìrètí.” (Mátíù 12:17-21; Aísáyà 42:1-4) Jésù kò ṣe àríyànjiyàn aláriwo lóòótọ́ gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe sọ. Àní nígbà tí nǹkan ò rọrùn pàápàá, ó sọ òtítọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́nà tó wọ àwọn tó bẹ̀rù Ọlọ́run lọ́kàn.—Jòhánù 7:32, 40, 45, 46.

10, 11. (a) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Farisí wà lára àwọn tó máa ń ṣàtakò sí Jésù jù, kí nìdí tó fi wàásù fún àwọn kan lára wọn? (b) Báwo ni Jésù ṣe máa ń dá àwọn alátakò rẹ̀ lóhùn nígbà míì, àmọ́ kí ni kì í ṣe?

10 Nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, ó bá ọ̀pọ̀ lára àwọn Farisí sọ̀rọ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan lára wọn gbìyànjú láti fi ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ mú un, Jésù ò wò ó pé gbogbo wọn ló ń ro ibi sí òun. Kí Símónì, Farisí kan tó jẹ́ alárìíwísí, lè ráyè mọ irú ẹni tí Jésù jẹ́ dáadáa ló ṣe ní kí Jésù wá bá òun jẹun nílé. Jésù lọ sílé rẹ̀, ó sì wàásù fáwọn tó wà níbẹ̀. (Lúùkù 7:36-50) Lákòókò mìíràn, Nikodémù, Farisí kan táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa, yọ́ lọ sọ́dọ̀ Jésù nígbà tí ilẹ̀ ti ṣú. Àmọ́ Jésù ò bínú sí i torí pé ó wá sọ́dọ̀ rẹ̀ lálẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó wàásù fún Nikodémù nípa ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí aráyé tó mú kó rán Ọmọ rẹ̀ wá kó lè ṣí ọ̀nà ìgbàlà sílẹ̀ fáwọn tó bá gbà á gbọ́. Síwájú sí i, Jésù ṣàlàyé ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kéèyàn tẹ̀ lé ètò tí Ọlọ́run ṣe. (Jòhánù 3:1-21) Nígbà tó yá, Nikodémù gbèjà Jésù nígbà táwọn Farisí yòókù ń ṣáátá Jésù, tí wọ́n fojú kéré ìròyìn rere táwọn kan mú wá nípa rẹ̀.—Jòhánù 7:46-51.

11 Kì í ṣe pé Jésù ò rí ìwà àgàbàgebè àwọn tó ń gbìyànjú láti dẹkùn mú un. Kì í jẹ́ kí àwọn alátakò fa òun wọnú àríyànjiyàn. Àmọ́ o, láwọn ìgbà tí Jésù rí i pé ó yẹ bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ ṣókí tó máa mú wọn ronú jinlẹ̀ ló máa ń fi dá wọn lóhùn, bóyá kó mẹ́nu kan ìlànà kan tàbí kó lo àpèjúwe kan tàbí kó fa ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan yọ. (Mátíù 12:38-42; 15:1-9; 16:1-4) Láwọn ìgbà míì sì rèé, ńṣe ni Jésù kàn máa ń dákẹ́ tó bá rí i pé ọ̀rọ̀ òun ò ní wọ̀ wọ́n létí nírú àsìkò bẹ́ẹ̀.—Máàkù 15:2-5; Lúùkù 22:67-70.

12. Báwo ni Jésù ṣe ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, kódà nígbà tí wọ́n ń pariwo mọ́ ọn?

12 Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àwọn tí ẹ̀mí àìmọ́ ń darí máa ń pariwo mọ́ Jésù. Ńṣe ni Jésù máa ń kó ara rẹ̀ níjàánu nírú àsìkò bẹ́ẹ̀, kódà ó tún máa ń lo agbára tí Ọlọ́run fún un láti fi wò wọ́n sàn. (Máàkù 1:23-28; 5:2-8, 15) Bí inú bá ń bí àwọn èèyàn kan tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí pariwo mọ́ wa nígbà tá a bá ń wàásù, ó yẹ káwa náà kó ara wa níjàánu, ká sì gbìyànjú láti fi inú rere àti ọgbọ́n hùwà nírú àsìkò bẹ́ẹ̀.—Kólósè 4:6.

Ó Yẹ Ká Máa Kó Ara Wa Níjàánu Nínú Ilé

13. Kí nìdí táwọn aráalé fi máa ń ṣàtakò sí ẹnì kan nínú ìdílé wọn tó bá bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

13 Ibi tó tún ti ṣe pàtàkì pé káwọn ọmọlẹ́yìn Jésù máa kó ara wọn níjàánu ni inú ìdílé. Bí ẹ̀kọ́ òtítọ́ Bíbélì bá wọ ẹnì kan lọ́kàn gan-an, ó máa ń wu irú ẹni bẹ́ẹ̀ pé kí ẹ̀kọ́ Bíbélì wọ àwọn tó wà nínú ìdílé òun náà lọ́kàn. Àmọ́, gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe sọ tẹ́lẹ̀, àwọn aráalé wa lè máa ṣàtakò sí wa. (Mátíù 10:32-37; Jòhánù 15:20, 21) Ọ̀pọ̀ nǹkan ló máa ń fa èyí. Bí àpẹẹrẹ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀kọ́ Bíbélì máa ń mú ká jẹ́ olóòótọ́, ẹni tó ṣeé fọkàn tán, àti ẹni tó ń bọ̀wọ̀ fúnni, síbẹ̀ Ìwé Mímọ́ tún kọ́ wa pé ipò yòówù ká wà, ti Ẹlẹ́dàá wa la gbọ́dọ̀ fi ṣáájú. (Oníwàásù 12:1, 13; Ìṣe 5:29) Ẹnì kan nínú ìdílé wa tó ń ronú pé ìjọsìn Jèhófà ni kò jẹ́ ká bọ̀wọ̀ fún òun bó ṣe yẹ lè máa bínú sí wa. Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká fìwà jọ Jésù nírú ipò bẹ́ẹ̀, kí àwa náà máa kó ara wa níjàánu!—1 Pétérù 2:21-23; 3:1, 2.

14-16. Kí ló mú káwọn kan tó ti máa ń ṣàtakò sáwọn aráalé wọn tẹ́lẹ̀ yí ìwà wọn padà?

14 Ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ń sin Jèhófà lónìí ló jẹ́ pé nígbà kan, ọkọ tàbí aya wọn tàbí ẹlòmíràn nínú ìdílé wọn ń ṣàtakò sí wọn nítorí wọn ò bá wọn ṣe àwọn nǹkan kan bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́ nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn alátakò náà lè ti máa gbọ́ ọ̀rọ̀ àìdáa táwọn èèyàn máa ń sọ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, bóyá kí wọ́n wá máa bẹ̀rù pé ẹni tó ń bá àwọn Ẹlẹ́rìí rìn yìí lè kéèràn ran àwọn yòókù nínú agboolé wọn. Kí ló máa ń jẹ́ kí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ yí ìwà wọn padà? Lọ́pọ̀ ìgbà, ìwà tó dára tí onígbàgbọ́ náà ń hù máa ń wú wọn lórí. Nígbà míì, àtakò táwọn aráalé ń ṣe máa ń rọlẹ̀ tí wọ́n bá rí i pé onígbàgbọ́ náà ń tẹ̀ lé ohun tí Bíbélì wí. Bí àpẹẹrẹ, tí onítọ̀hún bá ń lọ sí ìpàdé àti òde ẹ̀rí déédéé, síbẹ̀ tí kì í jẹ́ kí ìwọ̀nyí pa ojúṣe rẹ̀ nínú ìdílé lára, tó tún máa ń kó ara rẹ̀ níjàánu bí wọ́n tilẹ̀ ń bú u, ìwà wọn lè yí padà.—1 Pétérù 2:12.

15 Ẹ̀tanú tàbí ìgbéraga lè máà jẹ́ kí alátakò kan fẹ́ gbọ́ àlàyé èyíkéyìí látinú Bíbélì. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ọkùnrin kan nìyẹn nílẹ̀ Amẹ́ríkà, ẹni tó sọ pé òun fẹ́ràn orílẹ̀-èdè òun gidigidi. Lákòókò kan, nígbà tí ìyàwó rẹ̀ lọ sí àpéjọ àgbègbè, ọkùnrin náà kó gbogbo aṣọ rẹ̀, ó sì fi ilé sílẹ̀. Lákòókò mìíràn, ó mú ìbọn rẹ̀ nígbà tó fẹ́ kúrò nílé, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí halẹ̀ pé òun á pa ara òun. Ó ní bí òun bá gbẹ̀mí ara òun, ìsìn ìyàwó òun ló fà á. Àmọ́, ìyàwó rẹ̀ ò fi ṣe ìbínú rárá, kàkà bẹ́ẹ̀ ó ń gbìyànjú láti fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ọkọ rẹ̀ náà di Ẹlẹ́rìí lẹ́yìn ogún ọdún tí aya rẹ̀ ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lórílẹ̀-èdè Albania, obìnrin kan bínú gan-an torí pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ́ ọmọ rẹ̀ obìnrin lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ṣèrìbọmi. Ìgbà méjìlá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni ìyá yìí ba Bíbélì ọmọ rẹ̀ jẹ́. Ṣùgbọ́n lọ́jọ́ kan, ó ṣí Bíbélì tuntun tí ọmọ rẹ̀ fi sórí tábìlì. Mátíù 10:36 ló ṣí Bíbélì náà sí láìròtẹ́lẹ̀, ó sì wò ó pé òun gan-an ni ibẹ̀ ń bá wí. Nítorí pé ó fẹ́ràn ọmọ rẹ̀ gan-an, ó sìn ín lọ sí ìdí ọkọ̀ ojú omi nígbà tí ọmọ rẹ̀ àtàwọn Ẹlẹ́rìí mìíràn fẹ́ lọ sí àpéjọ àgbègbè lórílẹ̀-èdè Ítálì. Nígbà tí obìnrin náà rí ìfẹ́ tó wà láàárín wọn, tí wọ́n ń yọ̀ mọ́ra, tí wọ́n sì jọ ń rẹ́rìn-ín, èrò tó ti ní tẹ́lẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí yí padà. Kété lẹ́yìn èyí, ó gbà kí wọ́n máa bá òun kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lónìí, òun náà ti ń ran àwọn ẹlòmíràn tí wọ́n jẹ́ alátakò tẹ́lẹ̀ lọ́wọ́.

16 Nígbà kan, ọkùnrin kan mú ọ̀bẹ dání lọ bá ìyàwó rẹ̀ bó ṣe fẹ́ wọnú Gbọ̀ngàn Ìjọba, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀kò èébú sí i. Àmọ́ ohùn pẹ̀lẹ́ ni aya rẹ̀ fi dá a lóhùn, ó ní: “Ẹ ò ṣe wọlé, kẹ́ ẹ lè fojú ara yín rí ohun tá à ń ṣe.” Ọkùnrin náà sì wọlé. Nígbà tó yá ó di alàgbà nínú ìjọ Kristẹni.

17. Bí nǹkan ò bá lọ déédéé nínú agboolé Kristẹni kan, ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ wo ló lè ràn wọ́n lọ́wọ́?

17 Kódà bó bá tiẹ̀ jẹ́ pé Kristẹni ni gbogbo àwọn tó wà nínú ìdílé yín, àwọn ìgbà kan lè wà tí nǹkan lè má lọ déédéé, tí àìpé ẹ̀dá sì lè mú kẹ́ ẹ máa sọ ọ̀rọ̀ líle sí ara yín. Ẹ jẹ́ ká kíyè sí ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni tó wà nílùú Éfésù ìgbàanì, ó ní: “Kí ẹ mú gbogbo ìwà kíkorò onínú burúkú àti ìbínú àti ìrunú àti ìlọgun àti ọ̀rọ̀ èébú kúrò lọ́dọ̀ yín pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo ìwà búburú.” (Éfésù 4:31) Ó hàn gbangba pé àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láyìíká àwọn Kristẹni tó wà nílùú Éfésù, àìpé tiwọn fúnra wọn àti irú ayé táwọn kan lára wọn ti gbé sẹ́yìn ló ń jẹ́ kí wọ́n hu irú àwọn ìwà wọ̀nyẹn. Àmọ́, kí ló máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti yí padà? Wọ́n ní láti “di tuntun nínú ipá tí ń mú èrò inú [wọn] ṣiṣẹ́.” (Éfésù 4:23) Bí wọ́n bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n ń ṣàṣàrò lórí bí wọ́n ṣe lè fi í sílò nígbèésí ayé wọn, tí wọ́n ń bá àwọn Kristẹni bíi tiwọn kẹ́gbẹ́, tí wọ́n sì ń fi taratara gbàdúrà, èso ẹ̀mí Ọlọ́run yóò túbọ̀ máa hàn nígbèésí ayé wọn. Wọ́n á ‘di onínúrere sí ara wọn lẹ́nì kìíní-kejì, ní fífi ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ hàn, wọ́n á máa dárí ji ara wọn fàlàlà gan-an gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run pẹ̀lú ti tipasẹ̀ Kristi dárí jì wọ́n fàlàlà.’ (Éfésù 4:32) Ohun yòówù káwọn ẹlòmíràn ṣe, ńṣe ló yẹ ká máa kó ara wa níjàánu, ká máa fi inú rere àti ìyọ́nú bá gbogbo èèyàn lò, ká sì máa dárí jini. Àní, a kò gbọ́dọ̀ “fi ibi san ibi fún ẹnì kankan.” (Róòmù 12:17, 18) Ní gbogbo ìgbà, ohun tó tọ́ tó sì yẹ ni pé ká máa fi ìfẹ́ àtọkànwá bá àwọn èèyàn lò gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti ń ṣe.—1 Jòhánù 4:8.

Ìmọ̀ràn Tó Kan Gbogbo Kristẹni

18. Kí nìdí tó fi yẹ́ kí ẹni tó bá jẹ́ alàgbà nílùú Éfésù ìgbàanì tẹ̀ lé ìmọ̀ràn inú 2 Tímótì 2:24, báwo sì ni ìmọ̀ràn náà ṣe lè ṣe gbogbo Kristẹni láǹfààní?

18 Ìmọ̀ràn tí Bíbélì fún wa pé ká máa “kó ara [wa] ní ìjánu lábẹ́ ibi” kan gbogbo àwa Kristẹni. (2 Tímótì 2:24) Àmọ́ Tímótì ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ́kọ́ darí ọ̀rọ̀ yìí sí, torí pé ìmọ̀ràn yìí yóò wúlò fún un nígbà tó fi ń ṣe alàgbà nílùú Éfésù. Ẹlẹ́nu-gbọ̀rọ̀ làwọn kan nínú ìjọ tó wà níbẹ̀, wọ́n sì ń kọ́ àwọn èèyàn ní ẹ̀kọ́ èké. Níwọ̀n bí wọn ò ti fi bẹ́ẹ̀ lóye ìdí tí Ọlọ́run fi fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní Òfin Mósè, wọn ò mọ bí ìgbàgbọ́, ìfẹ́ àti ẹ̀rí ọkàn rere ti ṣe pàtàkì tó. Ìgbéraga ń dá wàhálà sílẹ̀ láàárín wọn bí wọ́n ṣe ń bá ara wọn fa ọ̀rọ̀, èyí ò sì jẹ́ kí wọ́n lóye kókó pàtàkì tó wà nínú àwọn ẹ̀kọ́ Kristi, kò sì jẹ́ kí wọ́n mọ bí fífi gbogbo ọkàn sin Ọlọ́run ti ṣe pàtàkì tó. Kí Tímótì lè bójú tó ọ̀ràn yìí, kò gbọ́dọ̀ gba gbẹ̀rẹ́ bó ṣe ń tẹ̀ lé ìlànà Ìwé Mímọ́ síbẹ̀ ẹ̀sọ̀ pẹ̀lẹ́ ló gbọ́dọ̀ máa fi bá àwọn arákùnrin rẹ̀ lò. Bí àwọn alàgbà òde òní ṣe mọ̀ pé agbo Ọlọ́run kì í ṣe tiwọn ni Tímótì náà mọ̀ bẹ́ẹ̀, ó sì mọ̀ pé tí òun bá ń bá àwọn ará lò, ohun tó máa jẹ́ kí ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan gbilẹ̀ nínú ìjọ lòun gbọ́dọ̀ máa ṣe.—Éfésù 4:1-3; 1 Tímótì 1:3-11; 5:1, 2; 6:3-5.

19. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí gbogbo wa máa “wá ọkàn-tútù”?

19 Ọlọ́run rọ àwọn èèyàn rẹ̀ pé kí wọ́n máa “wá ọkàn-tútù.” (Sekaráyà 2:3) Ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń pè ní “ọkàn-tútù” lédè Hébérù túmọ̀ sí fífi sùúrù fara da ìwà àìdáa, láìsí pé èèyàn ń kanra tàbí pé kó gbẹ̀san. Ẹ jẹ́ kí àwa náà máa fi gbogbo ọkàn wa rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà pé kó ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa kó ara wa níjàánu, ká sì lè máa ṣojú fún un bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, kódà nígbà tí nǹkan bá le gan-an pàápàá.

Ẹ̀kọ́ Wo Lo Kọ́?

• Báwọn èèyàn bá ń ṣáátá, ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wo ló lè ràn ọ́ lọwọ́?

• Kí nìdí tí Sọ́ọ̀lù fi ń hùwà àfojúdi?

• Báwo ni àpẹẹrẹ Jésù ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè máa bá gbogbo onírúurú èèyàn lò bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ?

• Àwọn àǹfààní wo ló lè jẹ yọ bá a bá ń kó ara wa níjàánu ká tó sọ̀rọ̀ nínú ilé?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Ananíà mọ irú èèyàn tí Sọ́ọ̀lù jẹ́, síbẹ̀ ó hùwà pẹ̀lẹ́ sí i

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Bí Kristẹni kan bá ń ṣe gbogbo ojúṣe rẹ̀ nínú ilé, èyí lè mú kí àtakò táwọn aráalé rẹ̀ ń ṣe sí i rọlẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Àwọn Kristẹni máa ń mú kí ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan gbilẹ̀