Mari Ìlú Pàtàkì Kan Láyé Àtijọ́ Tó Wà Nínú Aṣálẹ̀
Mari Ìlú Pàtàkì Kan Láyé Àtijọ́ Tó Wà Nínú Aṣálẹ̀
AWALẸ̀PÌTÀN ọmọ ilẹ̀ Faransé kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ André Parrot sọ pé: “Nígbà tí mo padà dénú yàrá mi lálẹ́ láti ibi témi àtàwọn tó ń bá mi ṣiṣẹ́ ti ṣe àjọyọ̀ nítorí ohun tá a ṣàwárí rẹ̀, inú mi dùn gan-an débi pé tí wọ́n bá gẹṣin nínú mi ẹṣin ọ̀hún ò ní kọsẹ̀.” Ó ṣẹlẹ̀ pé ní oṣù January ọdún 1934, Parrot àtàwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ ṣàwárí ère kan nílùú Tell Hariri, nítòsí ìlú kékeré kan tó ń jẹ́ Abu Kemal lẹ́gbẹ̀ẹ́ odò Yúfírétì ní Síríà. Ohun tí wọ́n kọ sára ère náà ni: “Lamgi-Mari, ọba Mari, àlùfáà àgbà Enlil.” Ère tí wọ́n rí yìí múnú wọn dùn gan-an ni.
Bí wọ́n ṣe mọ ọ̀gangan ibi tí ìlú Mari wà nìyẹn o! Àmọ́, àǹfààní wo ni mímọ̀ tí wọ́n mọ ibi tí ìlú Mari wà yìí yóò ṣe fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
Kí Nìdí Táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Fi Nífẹ̀ẹ́ sí Ìtàn Ìlú Mari?
Òótọ́ ni pé àwọn ìwé ayé àtijọ́ jẹ́ ká mọ̀ pé ìlú kan wà tó ń jẹ́ Mari, àmọ́ ọ̀pọ̀ ọdún làwọn èèyàn ò fi mọ ọ̀gangan ibi tí ìlú náà wà. Àwọn akọ̀wé ilẹ̀ Sumer sọ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé abẹ́ ìlú Mari ni gbogbo àgbègbè Mesopotámíà wà láyé ìgbà kan. Ibi tí ìlú Mari wà ò jìnnà rárá sí odò Yúfírétì, ibẹ̀ sì ni gbogbo àwọn oníṣòwò tó bá ń bọ̀ láti orí òkun tó ya wọ ilẹ̀ Páṣíà máa ń gbà tí wọ́n bá ń lọ sí Ásíríà, Mesopotámíà, Anatolia àti Etíkun Mẹditaréníà. Igi, irin àti òkúta wà lára ohun èlò tí wọ́n máa ń kó gba ìlú náà kọjá, àwọn nǹkan wọ̀nyí sì ṣọ̀wọ́n gan-an ní Mesopotámíà láyé ìgbà yẹn. Owó táwọn oníṣòwò ń san lórí àwọn nǹkan wọ̀nyí ní Mari kì í ṣe kékeré, èyí ló mú kó jẹ gàba lórí gbogbo àgbègbè náà.
Àmọ́, ìjẹgàba yìí dópin nígbà tí Sargon tó jẹ́ alákòóso àgbègbè Akkad ṣẹ́gun Síríà.Ní nǹkan bí ọ̀ọ́dúnrún [300] ọdún lẹ́yìn tí Sargon ṣẹ́gun Síríà, àwọn ológun bẹ̀rẹ̀ sí ṣe gómìnà ìlú Mari. Bí ọ̀kan ṣe ń kúrò ni òmíràn ń bọ́ síbẹ̀. Nǹkan rọ̀ṣọ̀mù díẹ̀ lákòókò táwọn ológun fi ń ṣèjọba. Àmọ́, nígbà tó fi máa dìgbà ìjọba Zimri-Lim, ẹni tó ṣàkóso ìlú náà kẹ́yìn, Mari ò gbayì bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́. Zimri-Lim gbìyànjú láti mú kí ìjọba rẹ̀ túbọ̀ fìdí múlẹ̀, ó lọ ń bá àwọn ìlú mìíràn jagun ó sì ń ṣẹ́gun wọn, ó lọ ń ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn aláṣẹ ìlú mìíràn, ó sì ń bá àwọn ọba míì dána. Àmọ́, ní nǹkan bí ọdún 1760 ṣáájú Sànmánì Tiwa, Hammurabi ọba Bábílónì ṣẹ́gun ìlú náà, ó sì pa á run. Bá ò ṣe gbúròó ìlú tí Parrot sọ pé “ó wà lára ìlú tó jẹ́ ọ̀làjú jù lọ láyé àtijọ́” mọ́ nìyẹn.
Ìrànlọ́wọ́ ńláǹlà ni ọ̀nà táwọn ọmọ ogun Hammurabi gbà pa ìlú Mari run ṣe fáwọn awalẹ̀pìtàn àtàwọn òpìtàn òde òní, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò mọ̀ rárá pé ohun tó máa yọrí sí nìyẹn. Àwọn ògiri bàmùbàmù tí wọ́n wó lulẹ̀ láwọn ibì kan bo àwọn ilé tí gíga rẹ̀ tó mítà márùn-ún mọ́lẹ̀, èyí ò sì jẹ́ káwọn ilé náà bà jẹ́. Àwọn awalẹ̀pìtàn lọ wú àwókù àwọn tẹ́ńpìlì àti àwókù àwọn ààfin kan, wọ́n sì rí ọ̀pọ̀ nǹkan ìṣẹ̀ǹbáyé àti ẹgbẹẹgbẹ̀rún àkọsílẹ̀ tó jẹ́ ká mọ irú ayé táwọn èèyàn ayé ìgbàanì gbé.
Kí nìdí tá a fi nífẹ̀ẹ́ sáwọn àwókù ìlú Mari? Ronú nípa àkókò tí Ábúráhámù, baba ńlá náà, gbé ayé. Ọdún 2018 ṣáájú Sànmánì Tiwa ni wọ́n bí Ábúráhámù, ìyẹn ọ̀ọ́dúnrún ó lé méjìléláàádọ́ta [352] ọdún lẹ́yìn Ìkún Omi ńlá náà. Ìran Ábúráhámù jẹ́ ìran kẹwàá sí ti Nóà. Ọlọ́run sọ fún Ábúráhámù pé kó kúrò ní Úrì, ìlú ìbílẹ̀ rẹ̀, kó lọ sí Háránì. Nígbà tó sì di ọdún 1943 ṣáájú Sànmánì Tiwa tí Ábúráhámù pé ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́rin [75], ó ṣí kúrò nílẹ̀ Háránì, ó sì lọ ń gbé nílẹ̀ Kénáánì. Awalẹ̀pìtàn ọmọ ilẹ̀ Ítálì kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Paolo Matthiae sọ pé: “Ìgbà tí Ábúráhámù ṣí kúrò nílùú Úrì lọ sí Jerúsálẹ́mù [ní Kénáánì] jẹ́ àkókò kan náà tí ìlú Mari wà.” Nítorí náà, bí àwọn awalẹ̀pìtàn ṣe mọ ọ̀gangan ibi tí ìlú Mari wà ṣàǹfààní nítorí pé ó máa jẹ́ ká lè fọkàn yàwòrán irú ìgbésí ayé táwọn èèyàn ń gbé nígbà ayé Ábúráhámù, ẹni tó jẹ́ olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run. a—Jẹ́nẹ́sísì 11:10–12:4.
Kí Làwọn Àwókù Náà Jẹ́ Ká Mọ̀?
Ẹ̀sìn pọ̀ gan-an nílùú Mari, bẹ́ẹ̀ náà ló sì rí láwọn ibòmíràn lágbègbè Mesopotámíà. Àwọn tó ń gbébẹ̀ nígbà yẹn gbà pé èèyàn gbọ́dọ̀ ní ọlọ́run kan tó ń sìn. Káwọn èèyàn náà tó ṣe ìpinnu pàtàkì èyíkéyìí, wọ́n á kọ́kọ́ lọ wádìí lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́run wọn. Àwókù tẹ́ńpìlì mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ làwọn awalẹ̀pìtàn ti wà jáde. Lára àwọn àwókù tẹ́ńpìlì tí wọ́n rí ni Tẹ́ńpìlì Àwọn Kìnnìún (ìyẹn tẹ́ńpìlì táwọn kan gbà pé ó jẹ́ tẹ́ńpìlì Dagan, tí Bíbélì pè ní Dágónì), tẹ́ńpìlì òòṣà tó ń jẹ́ Ishtar, abo-ọlọ́run afúnnilọ́mọ, àti tẹ́ńpìlì Shamash, ọlọ́run oòrùn. Òòṣà táwọn èèyàn ń bọ ni wọ́n kó sínú àwọn tẹ́ńpìlì yìí tẹ́lẹ̀. Àwọn tó ń bọ òòṣà wọ̀nyí gbẹ́ ère ara wọn lọ́nà tó fi hàn pé inú wọn dùn bí wọ́n ṣe ń gbàdúrà, wọ́n wá gbé wọn sórí bẹ́ǹṣì nínú tẹ́ńpìlì náà. Èrò wọn ni pé báwọn ò tilẹ̀ sí níbẹ̀, ère àwọn yìí ò ní jẹ́ kí ìjọsìn wọn dáwọ́ dúró. Parrot
sọ pé: “Ère ara wọn táwọn olùjọsìn máa ń gbé sínú tẹ́ńpìlì dà bí àbẹ́là táwọn ọmọ ìjọ Kátólíìkì máa ń tàn ní ṣọ́ọ̀ṣì wọn lóde òní láti fi dúró fún ara wọn tí wọn ò bá sí nínú ṣọ́ọ̀ṣì, àmọ́ tiwọn tiẹ̀ tún ju tàwọn Kátólíìkì lọ.”Ohun tó pabanbarì jù lọ tí wọ́n rí nílùú Tell Hariri ni àwọn àwókù ààfin ńlá kan tí wọ́n fi orúkọ Zimri-Lim, ọba tó jẹ kẹ́yìn pè. Awalẹ̀pìtàn ọmọ ilẹ̀ Faransé kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Louis-Hugues Vincent sọ pé ààfin náà jẹ́ “ibi ẹlẹ́wà tó gbé iṣẹ́ ọnà ilé kíkọ́ àwọn ará Ìlà Oòrùn Ayé nígbà àtijọ́ yọ.” Ibi tí wọ́n kọ́ ààfin náà sí fẹ̀ ju hẹ́kítà méjì ààbọ̀ lọ, ó sì tó nǹkan bí ọ̀ọ́dúnrún [300] yàrá àti àgbàlá tó wà nínú rẹ̀. Kódà láyé ìgbàanì, àwọn èèyàn gbà pé ààfin náà jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ohun àrà tí ń bẹ láyé. Nínú ìwé Ancient Iraq (Ilẹ̀ Iraq Àtijọ́) tí Georges Roux kọ, ó sọ pé: “Ààfin náà gbayì débi pé ọba ìlú Ugarit tó wà ní etíkun Síríà rán ọmọ ẹ̀ ọkùnrin láti nǹkan bí ẹgbẹ̀ta [600] kìlómítà pé kó kàn tiẹ̀ lọ wo bí ‘ilé Zimri-Lim’ ṣe rí.”
Kí àlejò tó wọ inú àgbàlá ńlá kan, á kọ́kọ́ gba ẹnu ọ̀nà tí wọ́n kọ́ ilé ìṣọ́ sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ méjèèjì wọ ààfin olódi náà. Orí ìtẹ́ tó wà lórí pèpéle kan ni Zimri-Lim, ọba tó jẹ kẹ́yìn ní Mari máa ń jókòó sí. Ibẹ̀ ló ti máa ń bójú tó àwọn ọ̀ràn tó jẹ mọ́ iṣẹ́ ológun, ti ìṣòwò àtàwọn ọ̀ràn míì tó jẹ́ ti ìlú. Ibẹ̀ ló ti máa ń ṣèdájọ́, ibẹ̀ ló sì ti máa ń gbàlejò àwọn tó bá wá sílùú náà àtàwọn aṣojú láti ìlú míì. Yàrá wà fáwọn àlejò ọba tó máa ń wá nígbà àsè ńlá, ọba sì máa ń fún wọn lóúnjẹ àti wáìnì lọ́pọ̀ rẹpẹtẹ. Lára àwọn ohun tí wọ́n máa ń jẹ ni àgbàlàǹgbó, ẹja, ẹran màlúù, ẹran àgùntàn, adìyẹ, tòlótòló àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Wọ́n máa ń jẹ wọ́n ní sísè, sísun tàbí yíyan. Ọbẹ̀ tí wọ́n ti fi àlùbọ́sà wẹ́wẹ́ àtàwọn èròjà amóúnjẹ-ta-sánsán sí, tí wọ́n tún se oríṣiríṣi ẹ̀fọ́ àti wàràkàṣì mọ́ sì ni wọ́n
máa ń fi jẹ ẹ́. Wọ́n tún máa ń jẹ àwọn èso tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ká àtèyí tó ti gbẹ àti àkàrà òyìnbó tí wọ́n dárà sí. Bíà àti wáìnì ni wọ́n máa ń fún àwọn àlejò láti fi pòùngbẹ.Wọn ò fi ọ̀rọ̀ ìmọ́tótó ṣeré láàfin yìí o. Àwọn awalẹ̀pìtàn rí àwọn ilé ìwẹ̀ tó ní agbada ìwẹ̀ tí wọ́n fi amọ̀ ṣe àti ilé ìyàgbẹ́ oníhò. Wọ́n kun ilẹ̀ àwọn yàrá tó wà láàfin náà lọ́dà, wọ́n sì tún fi ọ̀dà kun apá ìsàlẹ̀ àwọn ògiri yàrá náà. Inú gọ́tà tí wọ́n fi bíríkì ṣe ni omi ìdọ̀tí máa ń gbà, láti nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [3,500] ọdún tí ìlú náà sì ti pa run, àwọn páìpù alámọ̀ tí wọ́n fi ọ̀dà kun inú rẹ̀ tó wà níbẹ̀ kò tíì bà jẹ́. Nígbà kan tí àìsàn kọ lu àwọn obìnrin mẹ́ta láàfin ọba tí obìnrin púpọ̀ wà, òfin tó le gan-an ló dè wọ́n. Ńṣe ni wọ́n máa ń gbé irú obìnrin aláìsàn bẹ́ẹ̀ lọ sí àdádó kan, nítorí pé kò gbọ́dọ̀ sún mọ́ ibi téèyàn bá wà. “Kò sẹ́ni tó gbọ́dọ̀ fi abọ́ ẹ̀ mumi, bẹ́ẹ̀ ni kò sẹ́ni tó gbọ́dọ̀ jẹun lórí tábìlì rẹ̀ tàbí kó jókòó sórí àga ẹ̀.”
Ẹ̀kọ́ Wo La Lè Rí Kọ́ Nínú Àkọsílẹ̀ Tí Wọ́n Ṣàwárí?
Parrot àtàwọn tó ń bá a ṣiṣẹ́ rí nǹkan bí ọ̀kẹ́ kan [20,000] wàláà tí wọ́n fi èdè Akkad kọ nǹkan sára rẹ̀. Àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ọ̀rọ̀ àbójútó ìlú àti ọrọ̀ ajé, àtàwọn lẹ́tà wà lára àwọn nǹkan tí wọ́n kọ sára àwọn wàláà náà. Ìdámẹ́ta péré lára ohun tí wọ́n kọ sára wàláà yìí ni wọ́n tíì tẹ̀ sínú ìwé. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ìdìpọ̀ méjìdínlọ́gbọ̀n làwọn ìwé náà. Àmọ́, kí ni àǹfààní àwọn àkọsílẹ̀ yìí? Jean-Claude Margueron tó jẹ́ ọ̀gá àgbà Àjọ Tó Ń Bójú Tó Ìwalẹ̀pìtàn ní Mari sọ pé: “Kó tó di pé a rí àwọn wàláà náà wà jáde látinú àwókù ìlú Mari, a ò mọ nǹkan kan nípa ìtàn, ètò ìlú àti bí ìgbésí ayé ṣe rí ní àgbègbè Mesopotámíà àti Síríà níbẹ̀rẹ̀ ẹgbẹ̀rún ọdún kejì ṣáájú Sànmánì Tiwa. Ọpẹ́lọpẹ́ àwọn nǹkan tá a rí yìí, à bá má lè kọ ìtàn nípa àkókò náà.” Gẹ́gẹ́ bí Parrot ṣe wí, àwọn àkọsílẹ̀ tó wà lára wàláà yẹn “jẹ́ ká rí i pé ìjọra tó pọ̀ gan-an wà láàárín àwọn tí wàláà náà sọ̀rọ̀ nípa wọn àtohun tí Májẹ̀mú Láéláé sọ nípa àwọn tó wà láyé nígbà ayé àwọn Baba Ńlá.”
Wàláà tí wọ́n rí nílùú Mari yìí jẹ́ ká túbọ̀ lóye àwọn ìtàn Bíbélì kan dáadáa. Bí àpẹẹrẹ, ohun tí wọ́n kọ sára wàláà náà fi hàn pé sísọ àwọn aya tàbí àwọn wáhàrì ọ̀tá di tẹni jẹ́ “ohun tó wọ́pọ̀ láàárín àwọn ọba láyé ìgbà yẹn.” Nítorí náà, ìmọ̀ràn tí Áhítófẹ́lì ọ̀dàlẹ̀ fún Ábúsálómù, ọmọ Dáfídì Ọba, pé kó ní ìbádàpọ̀ pẹ̀lú àwọn wáhàrì bàbá rẹ̀ kì í ṣe tuntun.—2 Sámúẹ́lì 16:21, 22.
Láti ọdún 1933 títí di ìsinsìnyí, ìgbà mọ́kànlélógójì làwọn awalẹ̀pìtàn ti lọ walẹ̀ nílùú Tell Hariri. Àmọ́, títí di bá a ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí, àyè ibi tí wọ́n ti ń walẹ̀ kò tíì ju hẹ́kítà mẹ́jọ lọ, àádọ́fà [110] hẹ́kítà sì ni gbogbo ilẹ̀ náà. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n ṣì rí àwọn nǹkan fífanimọ́ra míì lọ́jọ́ iwájú ní Mari, ìlú pàtàkì kan láyé àtijọ́ tó wà nínú aṣálẹ̀.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bákan náà, ó ṣeé ṣe káwọn Júù tí wọ́n kó nígbèkùn lọ sí Bábílónì lẹ́yìn ìparun Jerúsálẹ́mù lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Tiwa gba ẹ̀gbẹ́ àwókù ìlú Mari kọjá.
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 10]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Ibi Tí Òkun Ti Ya Wọ Ilẹ̀ Páṣíà
Úrì
MESOPOTÁMÍÀ
Yúfírétì
MARI
ÁSÍRÍÀ
Háránì
ANATOLIA
KÉNÁÁNÌ
Jerúsálẹ́mù
Òkun Mẹditaréníà (Òkun Ńlá)
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Nínú àkọsílẹ̀ yìí, Iahdun-Lim ọba Mari fi àwọn ilé tó kọ́ yangàn
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]
Ère Lamgi-Mari táwọn awalẹ̀pìtàn rí jẹ́ ká mọ ọ̀gangan ibi tí ìlú Mari wà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Pèpéle kan rèé láàfin, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ibẹ̀ ni wọ́n gbé ère abo-ọlọ́run kan sí
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Ère Ebih-Il, alábòójútó ìlú Mari rèé níbi tó ti ń gbàdúrà
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Lára àwókù ilé tó wà ní Mari rèé, bíríkì tí wọ́n ò fi iná sun ni wọ́n fi kọ́ ọ
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Balùwẹ̀ kan tó wà láàfin
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Òkúta tí wọ́n ya bí Naram-Sin ṣe ṣẹ́gun ìlú Mari sí rèé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Nǹkan bí ọ̀kẹ́ kan [20,000] wàláà ni wọ́n rí nínú àwókù ààfin yìí
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 10]
© Mission archéologique française de Tell Hariri - Mari (Syrie)
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 11]
Àkọsílẹ̀: Musée du Louvre, Paris; ère: © Mission archéologique française de Tell Hariri - Mari (Syrie)
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 12]
Ère: Musée du Louvre, Paris; pèpéle àti balùwẹ̀: © Mission archéologique française de Tell Hariri - Mari (Syrie)
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 13]
Òkúta àwòrán ìṣẹ́gun: Musée du Louvre, Paris; àwókù ààfin: © Mission archéologique française de Tell Hariri - Mari (Syrie)