Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Ọmọ Èèyàn Lè Fòpin Sí Ipò Òṣì?

Ǹjẹ́ Ọmọ Èèyàn Lè Fòpin Sí Ipò Òṣì?

Ǹjẹ́ Ọmọ Èèyàn Lè Fòpin Sí Ipò Òṣì?

ÀÌMỌYE èèyàn ni kò mọ ohun tó ń jẹ́ òṣì láyé wọn, tó jẹ́ pé ebi ò pa wọ́n sùn rí, tí wọn ò sì ráre rí. Ọ̀pọ̀ àwọn wọ̀nyí ni wọ́n máa ń ṣàánú àwọn aláìní, tí wọ́n sì máa ń sa gbogbo ipá wọn láti ràn wọ́n lọ́wọ́.

Àmọ́ ogun, omíyalé, ọ̀dá àtàwọn ìṣòro míì bẹ́ẹ̀ ṣì ń sọ àwọn èèyàn di òtòṣì. Àwọn ìṣòro wọ̀nyí ń han àwọn àgbẹ̀ arokojẹ nílẹ̀ Áfíríkà léèmọ̀ gan-an ni. Àwọn nǹkan wọ̀nyí ti lé àwọn àgbẹ̀ kan kúrò ní abúlé lọ sí ìlú ńlá tàbí kó sọ wọ́n dẹni tó ń ráágó lórílẹ̀-èdè mìíràn. Àwọn mìíràn láti àrọko máa ń ṣí lọ sílùú ńlá lérò pé nǹkan á túbọ̀ rọ̀ṣọ̀mù fáwọn níbẹ̀.

Láwọn ìlú ńlá térò máa ń rọ́ sí jù, àtijẹ-àtimu máa ń ṣòro fáwọn èèyàn. Ìdí ni pé ibi gbogbo máa ń há gádígádí, kì í sì í fi bẹ́ẹ̀ sí ilẹ̀ láti fi dáko. Kì í sábà rọrùn láti ríṣẹ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí ìyà ti pá lórí á wá di jàǹdùkú sígboro. Àwọn aráàlú ké gbàjarè títí síjọba nítorí nǹkan wọ̀nyí àmọ́ ọ̀rọ̀ àìríná-àìrílò kì í ṣe ohun tí ìjọba èèyàn lè yanjú, kódà ńṣe ló ń burú sí i. Nígbà tí ìwé ìròyìn The Independent ti ìlú London ń sọ̀rọ̀ nípa ìròyìn kan tí àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè gbé jáde ní oṣù November 2003, ó ní: “Ńṣe làwọn tí ò rí jẹ tí ò rí mu túbọ̀ ń pọ̀ sí i láyé.” Ó tún fi kún un pé: “Nínú ayé lónìí, nǹkan bí ẹgbẹ̀rin ó lé méjìlélógójì mílíọ̀nù èèyàn ni kì í róúnjẹ jẹ kánú, ọdọọdún la sì ń rí mílíọ̀nù márùn-ún èèyàn tébi ń hàn léèmọ̀ yàtọ̀ sáwọn wọ̀nyí.”

Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè Gúúsù Áfíríkà máa ń gba lẹ́tà látọ̀dọ̀ àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́. Bí àpẹẹrẹ, ọkùnrin kan tó ń gbé nílùú Bloemfontein kọ̀wé pé: “Mi ò níṣẹ́ lọ́wọ́, ńṣe ni mo máa ń jalè nígbà míì. Bí mi ò bá jalè, inú ebi la máa wà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ ti òtútù tó máa ń mú wa gan-an lóru. Kò síṣẹ́ láti ṣe rárá ni o. Ńṣe lọ̀pọ̀ èèyàn ń rìn kiri ìgboro bóyá wọ́n á lè ríṣẹ́ tàbí bóyá wọ́n á kàn tiẹ̀ rí nǹkan fi sẹ́nu. Mo mọ àwọn kan tó jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n máa ń ṣa oúnjẹ jẹ káàkiri orí ààtàn. Àwọn mìíràn tiẹ̀ ti fọwọ́ ara wọn para wọn. Ọ̀pọ̀ èèyàn layé ti sú bíi tèmi, tí wọ́n ti gbà pé àwọn ò lè rí bá ti ṣé mọ́ láé. Ó jọ pé ọmọ èèyàn ò lè rọ́nà gbé e gbà mọ́ láé. Ṣé Ọlọ́run tó dá ẹnu fún wa pé ká máa fi jẹun tó sì dá ara tá à ń wọṣọ sí ò rí gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni?”

Ìdáhùn tó ń tuni nínú wà fún ìbéèrè tó ń jẹ ọkùnrin yìí lọ́kàn. Inú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni ìdáhùn náà sì wà gẹ́gẹ́ bí àpilẹ̀kọ tó kàn yóò ṣe jẹ́ ká mọ̀.