Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Olóòótọ́ Èèyàn Fi Ìyìn fún Jèhófà

Àwọn Olóòótọ́ Èèyàn Fi Ìyìn fún Jèhófà

Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn

Àwọn Olóòótọ́ Èèyàn Fi Ìyìn fún Jèhófà

JÁKÈJÁDÒ ayé làwọn èèyàn ti mọ̀ pé olóòótọ́ èèyàn ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́mọdé lágbà. Gbé àwọn àpẹẹrẹ mẹ́ta wọ̀nyí yẹ̀ wò láti apá ibi mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lágbàáyé.

Ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún ni Olúṣọlá tó ń gbé ní Nàìjíríà. Lọ́jọ́ kan, ọmọbìnrin yìí ń bọ̀ wá sílé láti iléèwé, ló bá rí pọ́ọ̀sì kan nílẹ̀. Ó mú un lọ fún ọ̀gá àgbà ilé ìwé rẹ̀, ọ̀gá àgbà náà ka owó tó wà nínú rẹ̀, ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́fà ó lé igba [₦6,200] Náírà. Ọ̀gá àgbà ilé ẹ̀kọ́ náà dá pọ́ọ̀sì náà padà fún olùkọ́ tó sọ nù lọ́wọ́ rẹ̀. Nítorí pé inú olùkọ́ náà dùn fún ohun tí Olúṣọlá ṣe yìí, ó fún un ní ẹgbẹ̀rún kan [₦1,000] Náírà, ó sì sọ pé kó fi owó náà san owó ilé ìwé rẹ̀. Nígbà táwọn akẹ́kọ̀ọ́ yòókù gbọ́ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí, ńṣe ni wọ́n ń fi Olúṣọlá ṣe yẹ̀yẹ́. Ní ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan lẹ́yìn ìyẹn, akẹ́kọ̀ọ́ kan sọ pé wọ́n jí owó òun. Ni àwọn olùkọ́ bá sọ pé kí wọ́n yẹ ara gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wò. Olùkọ́ náà sọ fún Olúṣọlá pé, “Ìwọ, bọ́ síbí. Mo mọ̀ pé o ò lè jalè nítorí Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ọ́.” Wọ́n rí owó náà lọ́wọ́ méjì lára àwọn ọmọkùnrin tó fi Olúṣọlá ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n sì fìyà tó múná jẹ wọ́n. Olúṣọlá kọ̀wé pé: “Inú mi dùn gan-an pé wọ́n mọ̀ mí ní Ẹlẹ́rìí Jèhófà, pé mi ò lè jalè, èyí sì mú kí n lè fi ògo fún Jèhófà.”

Bí Marcelo, ọmọ ilẹ̀ Ajẹntínà ṣe jáde kúrò nílé lọ́jọ́ kan, ó rí àpò ìfàlọ́wọ́ kan nítòsí ilé rẹ̀. Ó gbé àpò náà lọ sínú ilé, òun àti ìyàwó rẹ̀ sì rọra ṣí i. Ó yà wọ́n lẹ́nu gan-an nígbà tí wọ́n rí owó tó pọ̀ gan-an, káàdì ìrajà, àtàwọn ìwé sọ̀wédowó mélòó kan tí wọ́n ti buwọ́ lù nínú àpò náà. Iye tó wà lórí ọ̀kan lára ìwé sọ̀wédowó náà jẹ́ mílíọ̀nù kan owó pésò. Wọ́n rí nọ́ńbà fóònù kan lórí ìwé ìrajà kan tó wà nínú àpò náà. Ni wọ́n bá fi nọ́ńbà fóònù náà pe ẹni tó ni àpò náà, wọ́n ní kó wá gba àpò rẹ̀ àtàwọn ohun tó wà nínú rẹ̀ níbi tí Marcelo ti ń ṣiṣẹ́. Nígbà tẹ́ni tó ni àpò náà dé, ara rẹ̀ kò balẹ̀. Ẹni tó gba Marcelo síṣẹ́ sì sọ fún ọkùnrin náà pé kó fara balẹ̀ nítorí Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni Marcelo. Ẹni tó ni àpò náà fún Marcelo ní ogún owó pésò péré gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn pé ó bá òun rí àpò òun. Ẹ̀bùn tó kéré yìí bí ẹni tó gba Marcelo síṣẹ́ nínú gan-an nítorí ìwà òótọ́ tí Marcelo hù wú u lórí púpọ̀. Èyí fún Marcelo láǹfààní láti ṣàlàyé pé nítorí pé òun jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, òun fẹ́ láti máa ṣòótọ́ nígbà gbogbo.

Láti orílẹ̀-èdè Kyrgyzstan ni ìròyìn tó kàn yìí ti wá. Ọmọkùnrin kan tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́fà tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Rinat rí pọ́ọ̀sì obìnrin kan tó ń gbé nítòsí ilé wọn. Owó tó wà nínú pọ́ọ̀sì náà jẹ́ ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún [1,100] owó som (nǹkan bí ₦3,325). Nígbà tí Rinat dá pọ́ọ̀sì náà padà fún obìnrin ọ̀hún, ó ka owó inú rẹ̀, ó sì sọ fún màmá Rinat pé igba [200] owó som (nǹkan bí ₦665) ti sọ nù lára owó náà. Rinat sọ pé òun kò mú lára owó náà. Ni gbogbo wọn bá lọ wá owó tó sọ nù náà, wọ́n sì rí i nítòsí ibi tí Rínat ti rí pọ́ọ̀sì náà tẹ́lẹ̀. Ìyàlẹ́nu ńlá ló jẹ́ fún obìnrin náà. Ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Rinat àti ìyá rẹ̀. Ìdí àkọ́kọ́ tó fi dúpẹ́ ni pé wọ́n dá owó tó sọ nù náà padà fún òun, ìdí kejì sì ni pé ìyá Rinat tọ́ ọ láti máa hùwà tó yẹ Kristẹni.