Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Nígbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù gbọ́ pé Pétérù tó ń ṣẹ̀wọ̀n wà lẹ́nu ọ̀nà, kí nìdí tí wọ́n fi sọ pé: “Áńgẹ́lì rẹ̀ ni”?—Ìṣe 12:15.

Ó ṣeé ṣe káwọn ọmọ ẹ̀yìn ti ní èrò tí kò tọ̀nà pé áńgẹ́lì kan tó jẹ́ ońṣẹ́ tó ń ṣojú Pétérù ló dúró sẹ́nu ọ̀nà. Gbé àwọn ọ̀rọ̀ tó yí ẹsẹ yìí ká yẹ̀ wò.

Hẹ́rọ́dù tó pa Jákọ́bù ti mú Pétérù. Nítorí náà, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù gbà gbọ́ pé ó máa pa Pétérù náà ni. Nígbà tí wọ́n sọ Pétérù sẹ́wọ̀n, wọ́n fi ẹ̀wọ̀n dè é, àwọn sójà mẹ́rin mẹ́rin tó ń gbaṣẹ́ lọ́wọ́ ara wọn lẹ́ẹ̀mẹ́rin lóòjọ́ ló sì ń ṣọ́ ọ. Àmọ́ áńgẹ́lì kan wá lálẹ́ ọjọ́ kan, ó sì dá a sílẹ̀ lọ́nà ìyanu, ó mú un kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n náà. Nígbà tí Pétérù wá mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀, ó sọ pé: “Nísinsìnyí, mo mọ̀ ní ti gidi pé Jèhófà rán áńgẹ́lì rẹ̀ jáde, ó sì dá mi nídè kúrò lọ́wọ́ Hẹ́rọ́dù.”—Ìṣe 12:1-11.

Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni Pétérù lọ sí ilé Màríà, ìyá Jòhánù tó ń jẹ́ Máàkù, níbi táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù bíi mélòó kan kóra jọ sí. Nígbà tó kan ilẹ̀kùn ọ̀nà àbáwọlé, ìránṣẹ́bìnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ródà ló lọ́ dá a lóhùn. Nígbà tó sì rí i pé ohùn Pétérù lòun ń gbọ́, ó sáré lọ sọ fún àwọn yòókù láìtiẹ̀ tíì jẹ́ kó wọlé! Nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn kọ́kọ́ gbọ́, wọ́n kò gbà gbọ́ pé Pétérù ló wà lẹ́nu ọ̀nà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n rò pé, “ańgẹ́lì rẹ̀ ni.”—Ìṣe 12:12-15.

Ṣé èrò àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà ni pé wọ́n ti pa Pétérù àti pé ẹ̀mí tó jáde kúrò lára rẹ̀ ló wà lẹ́nu ọ̀nà? Èyí ò lè jẹ́ bẹ́ẹ̀ nítorí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù mọ òtítọ́ tí Ìwé Mímọ́ kọ́ni nípa àwọn òkú pé “wọn kò mọ nǹkan kan rárá.” (Oníwàásù 9:5, 10) Kí wá ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn náà ní lọ́kàn nígbà tí wọ́n sọ pé: “Áńgẹ́lì rẹ̀ ni”?

Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù mọ̀ pé látìgbà tí ẹ̀dá èèyàn ti wà làwọn áńgẹ́lì ti máa ń ran àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, Jékọ́bù sọ̀rọ̀ nípa “áńgẹ́lì tí ó ti ń gbà mí padà lọ́wọ́ gbogbo ìyọnu àjálù.” (Jẹ́nẹ́sísì 48:16) Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa ọmọdé kan tó wà láàárín wọn, ó sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ rí i pé ẹ kò tẹ́ńbẹ́lú ọ̀kan nínú àwọn ẹni kékeré wọ̀nyí; nítorí mo sọ fún yín pé nígbà gbogbo ni àwọn áńgẹ́lì wọn ní ọ̀run ń wo ojú Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run.”—Mátíù 18:10.

Kódà, “ońṣẹ́” ni Bíbélì Young’s Literal Translation of the Holy Bible túmọ̀ ọ̀rọ̀ náà aggelos (“áńgẹ́lì”) sí. Ó jọ pé àwọn Júù kan gbà gbọ́ pé ìránṣẹ́ Ọlọ́run kọ̀ọ̀kan ló ní áńgẹ́lì tirẹ̀, ìyẹn “áńgẹ́lì tó ń ṣọ́ ọ.” Àmọ́ ṣá o, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kò fi èrò yìí kọ́ni ní tààràtà. Síbẹ̀ náà, ó lè jẹ́ pé nígbà táwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù sọ pé, “Áńgẹ́lì rẹ̀ ni,” ńṣe ni wọ́n rò pé áńgẹ́lì kan tó jẹ́ ońṣẹ́ tó ń ṣojú Pétérù ló dúró sẹ́nu ọ̀nà àbáwọlé.