Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ibo Ni Ayé Yìí Ń lọ?

Ibo Ni Ayé Yìí Ń lọ?

Ibo Ni Ayé Yìí Ń lọ?

ÌṢỌ̀KAN AYÉ. Ìyẹn mà dára o. Àbí kì í ṣe gbogbo èèyàn ló ń fẹ́ ẹ? Dájúdájú gbogbo ayé ló ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Lemọ́lemọ́ ni ìpàdé àwọn aṣáájú ayé ń dá lórí ìṣọ̀kan. Ní oṣù August ọdún 2000, ó lé ní ẹgbẹ̀rún àwọn aṣáájú ẹ̀sìn tó foríkorí ní orílé-iṣẹ́ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè nílùú New York fún Àpérò Àlááfíà Kárí Ayé ní Ẹgbẹ̀rúndún Tuntun. Wọ́n sọ̀rọ̀ nípa bí wọ́n ṣe máa yanjú ìforígbárí tó ń bẹ nínú ayé. Àmọ́ ṣá o, ńṣe ni àpérò náà fúnra rẹ̀ túbọ̀ fi awuyewuye tí ń bẹ nínú ayé hàn kedere. Ẹnì kan tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù, tó mọ̀ nípa òfin àwọn Mùsùlùmí kọ̀ láti wá sípàdé náà nítorí rábì ìsìn Júù kan máa wà níbẹ̀. Àwọn mìíràn tí wọ́n wà níbẹ̀ ń bínú nítorí pé wọn kò pe Dalai Lama tó jẹ́ aṣáájú ẹ̀sìn Búdà wá sí àpérò náà ní ọjọ́ méjì àkọ́kọ́. Ìdí táwọn tó ṣètò àpérò náà fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ẹ̀rù ń bà wọ́n pé Dalái Lama yóò máa ta ko orílẹ̀-èdè Ṣáínà.

Ní oṣù October 2003, àwọn orílẹ̀-èdè tó yí Òkun Pàsífíìkì ká jíròrò nípa ààbò ayé níbi Àpérò Àjọ Elétò Ọrọ̀ Ajé Ilẹ̀ Éṣíà òun Pàsífíìkì tó wáyé lórílẹ̀-èdè Thailand. Àwọn orílẹ̀-èdè mọ́kànlélógún tó wá síbẹ̀ ṣèlérí pé àwọn yóò fọ́ ẹgbẹ́ àwọn apániláyà túútúú, wọ́n sì fẹnu kò lórí àwọn ọ̀nà tí wọ́n máa gbà mú ọ̀ràn ààbò ayé yìí sunwọ̀n sí i. Síbẹ̀ náà, nígbà tí àpérò náà ń lọ lọ́wọ́, ńṣe làwọn aṣojú kan ń kùn nípa ọ̀rọ̀ tí olórí ìjọba kan sọ, wọ́n sọ pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ fi hàn pé ó kórìíra àwọn Júù gan-an.

Kí Ló Fà Á Tí Ayé Kò Fi Ṣọ̀kan?

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ ni wọ́n ti sọ nípa mímú ayé ṣọ̀kan, kò sí àṣeyọrí gidi kan. Láìka akitiyan tí ọ̀pọ̀ èèyàn ń fi òótọ́ inú ṣe sí, kí ló fà á tí ìṣọ̀kan ayé fi jẹ́ àléèbá fún aráyé títí di ọ̀rúndún kọkànlélógún yìí?

Apá kan ìdáhùn sí ìbéèrè yìí fara hàn nínú ọ̀rọ̀ ọ̀kan lára àwọn olórí ìjọba tó wá sí Àpérò Àjọ Elétò Ọrọ̀ Ajé Ilẹ̀ Éṣíà òun Pàsífíìkì náà. Ó sọ pé: “Ẹ̀mí orílẹ̀-èdè tèmi lọ̀gá jẹ́ ìṣòro kan.” Bẹ́ẹ̀ ni, ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni ti wọ àwọn èèyàn lẹ́wù. Ìfẹ́ yíyan ìjọba tó wù wọ́n ló gba orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan àti ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan lọ́kàn. Ọ̀nà tí orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan gbà ń ṣàkóso, ẹ̀mí ìdíje àti ojúkòkòrò ti fa yánpọnyánrin. Ohun tó sábà máa ń ṣẹlẹ̀ ni pé, nígbà tí ohun tí ìjọba orílẹ̀-èdè kan fẹ́ bá ta ko ohun tí gbogbo ayé fẹ́, ohun tí ìjọba orílẹ̀-èdè yẹn fẹ́ ló máa ń borí.

Ọ̀rọ̀ onísáàmù ṣàpèjúwe ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni dáadáa, ó pè é ní, “àjàkálẹ̀ àrùn tí ń fa àgbákò.” (Sáàmù 91:3) Ńṣe ló dà bí àjàkálẹ̀ àrùn tó ń bá aráyé fínra, ó sì ti fa ìyà àjẹẹ̀jẹtán. Ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni tó ń mú káwọn èèyàn kórìíra ara wọn ti wà tipẹ́. Lónìí, ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni ń bá a lọ láti máa koná mọ́ ìpínyà, àwọn alákòóso kò sì lè pa iná náà.

Ọ̀pọ̀ àwọn alákòóso ló mọ̀ dáadáa pé ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni àti ìmọtara ẹni nìkan ló wà nídìí ìṣòro ayé. Bí àpẹẹrẹ, Ọ̀gá Àgbà fún Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè tẹ́lẹ̀ rí, U Thant sọ pé: “Ọ̀pọ̀ jù lọ ìṣòro tá a ní lónìí ló jẹ́ nítorí ìwà tí kò bójú mu . . . Lára wọn ni ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni tó máa ń mú káwọn èèyàn sọ pé ‘ti orílẹ̀-èdè mi ni mo máa ṣe, ì báà dára, ì báà máà dára.’” Síbẹ̀ náà, ńṣe ni ìmọtara ẹni nìkan tó ti jọba lọ́kàn àwọn orílẹ̀-èdè lónìí ń mú kí wọ́n máa jà fún bí wọ́n ṣe máa gbé ìṣàkóso ti ara wọn kalẹ̀. Àwọn tí wọ́n lágbára kò fẹ́ káwọn mìíràn ní rárá. Bí àpẹẹrẹ, ìwé ìròyìn International Herald Tribune sọ̀rọ̀ nípa Àwùjọ Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Yúróòpù, ó ní: “Ìbáradíje àti àìfọkàntánni tí wọ́n fi pilẹ̀ ìṣèlú nílẹ̀ Yúróòpù ṣì wà títí di oní olónìí. Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn orílẹ̀-èdè tó wà nínú Àwùjọ Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Yúróòpù, ni kò fara mọ́ kí ojúgbà wọn kan ní agbára tó ju tiwọn lọ tàbí kó ṣe aṣáájú wọn.”

Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣàpèjúwe ohun tí ìṣàkóso èèyàn fà, ó ní: “Ènìyàn ti jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.” (Oníwàásù 8:9) Nípa pínpín ayé sí kélekèle, àwùjọ èèyàn àtàwọn èèyàn lẹ́nìkọ̀ọ̀kan ti rí i pé òótọ́ ni ìlànà Bíbélì yìí tó sọ pé: “Ẹni tí ń ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ yóò máa wá ìyánhànhàn onímọtara-ẹni-nìkan; gbogbo ọgbọ́n gbígbéṣẹ́ ni yóò ta kété sí.”—Òwe 18:1.

Ẹlẹ́dàá wa tó mọ ohun tó dára jù lọ fún wa kò dá àwọn èèyàn láti gbé ìjọba ti ara wọn kalẹ̀ kí wọ́n sì máa ṣàkóso ara wọn. Àmọ́ nítorí pé àwọn èèyàn ń ṣàkóso ara wọn, wọ́n ti tipa bẹ́ẹ̀ pa ìfẹ́ Ọlọ́run tì, wọn ò sì fẹ́ gbà pé ohun gbogbo jẹ́ tirẹ̀. Sáàmù 95:3-5 sọ pé: “Ọlọ́run ńlá ni Jèhófà àti Ọba ńlá lórí gbogbo àwọn ọlọ́run yòókù, ẹni tí àwọn ibi jíjinlẹ̀ jù lọ ní ilẹ̀ ayé wà lọ́wọ́ rẹ̀ àti ẹni tí àwọn téńté òkè ńláńlá jẹ́ tirẹ̀; ẹni tí òkun, tí òun fúnra rẹ̀ ṣe, jẹ́ tirẹ̀ àti ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ ṣẹ̀dá ilẹ̀ gbígbẹ.” Ọlọ́run ni ọba aláṣẹ tó yẹ kí gbogbo èèyàn wà lábẹ́ ìṣàkóso rẹ̀. Báwọn orílẹ̀-èdè ṣe ń gbé ìṣàkóso tara wọn kalẹ̀, ohun tó lòdì sí òfin Ọlọ́run ni wọ́n ń ṣe.—Sáàmù 2:2.

Kí Ló Máa Yanjú Ìṣòro Náà?

Ọ̀nà kan ṣoṣo tí ayé lè gbà ṣọ̀kan ni kí ayé ní alákòóso kan ṣoṣo tó máa ṣiṣẹ́ fún àǹfààní gbogbo èèyàn. Ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń ronú nípa ipò tá a wà yìí mọ̀ pé ohun tá a nílò gan-an nìyẹn. Bó tilẹ̀ jẹ́ bẹ́ẹ̀, ibi tí kò tọ́ làwọn tó mọ ohun tá a nílò yìí sábà máa ń wá a lọ. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ àwọn sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ láwùjọ, títí kan àwọn olórí ẹ̀sìn, ti rọ àwọn èèyàn láti máa wá ìṣọ̀kan ayé nípasẹ̀ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè. Àmọ́, kò sí àjọ kankan táwọn èèyàn dá sílẹ̀ tó tíì lè yanjú ìṣòro èèyàn kárí ayé, bó ti wù kí ohun tí wọ́n fẹ́ ṣe ti dára tó. Dípò kí wọ́n yanjú àwọn ìṣòro ayé, ńṣe ni ìpínyà tó wà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè túbọ̀ máa ń hàn kedere nínú àwọn àjọ wọ̀nyí.

Bíbélì ti kìlọ̀ fún wa pé ká má ṣe gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ẹgbẹ́ téèyàn dá sílẹ̀ pé wọ́n á yanjú àwọn ìṣòro ayé, ó sọ pé: “Ẹ má ṣe gbẹ́kẹ̀ yín lé àwọn ọ̀tọ̀kùlú, tàbí lé ọmọ ará ayé, ẹni tí ìgbàlà kò sí lọ́wọ́ rẹ̀.” (Sáàmù 146:3) Ǹjẹ́ gbogbo èyí wá túmọ̀ sí pé ayé kò lè ṣọ̀kan láé? Rárá o. Ọ̀nà kan wà tó dájú.

Ọ̀pọ̀ èèyàn ni kò mọ̀ pé Ọlọ́run ti gbé ìjọba kan kalẹ̀ tó lè mú gbogbo ayé wà níṣọ̀kan. Bíbélì sọ nípa Jèhófà Ọlọ́run pé: “Èmi, àní èmi, ti fi ọba mi jẹ lórí Síónì, òkè ńlá mímọ́ mi. Béèrè lọ́wọ́ mi, kí èmi lè fi àwọn orílẹ̀-èdè fún ọ gẹ́gẹ́ bí ogún rẹ àti àwọn òpin ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí ohun ìní rẹ.” (Sáàmù 2:6, 8) Kíyè sí i pé Ìwé Mímọ́ sọ pé Jèhófà Ọlọ́run ‘ti fi ọba rẹ̀ jẹ,’ ìyẹn ẹni tó pè ní “ọmọ mi” ní ẹsẹ keje. Ẹni yìí kì í ṣe ẹlòmíràn bí kò ṣe Ọmọ rẹ̀ tẹ̀mí tó gbawájú jù lọ, ìyẹn Jésù Kristi, ẹni tí Ọlọ́run ti fún láṣẹ lórí gbogbo orílẹ̀-èdè.

Bí Ayé Ṣe Máa Ṣọ̀kan

Ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ni kò tẹrí ba fún ìṣàkóso ọ̀run tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀ yìí. Àwọn orílẹ̀-èdè rò pé ẹ̀tọ́ àwọn ni láti máa ṣàkóso, wọn ò sì juwọ́ sílẹ̀. Àmọ́ ṣá o, Ọlọ́run kò ní fàyè gba àwọn tí kò tẹrí ba fún ìṣàkóso rẹ̀ àti ìjọba tó ti gbé kalẹ̀. Sáàmù 2:9 sọ nípa àwọn tí kò fara mọ́ ètò tí Ọlọ́run ṣe yìí pé: “Ìwọ [ìyẹn Jésù Kristi, tó jẹ́ Ọmọ] yóò fi ọ̀pá aládé irin ṣẹ́ wọn, bí ohun èlò amọ̀kòkò ni ìwọ yóò fọ́ wọn túútúú.” Yálà àwọn orílẹ̀-èdè mọ̀ tàbí wọn ò mọ̀, wọ́n ti dáwọ́ lé ohun tó máa mú kí wọ́n forí gbárí pẹ̀lú Ọlọ́run. Ìwé tó kẹ́yìn nínú Bíbélì sọ pé wọ́n ń kó “àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé pátá” jọ “sí ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè.” (Ìṣípayá 16:14) A óò mú àwọn ìjọba ayé àti gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe tó ń fa ìpínyà kúrò pátá. Èyí yóò sì mú kí ìjọba Ọlọ́run ráyè ṣe iṣẹ́ rẹ̀ láìsí ìdíwọ́.

Níwọ̀n bí Jèhófà Ọlọ́run ti jẹ́ Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run, yóò fi ọgbọ́n lo agbára rẹ̀ láti ṣe àwọn ìyípadà tí yóò mú ayé ṣọ̀kan, ìyẹn á sì jẹ́ nípasẹ̀ Ọmọ rẹ̀. Ìjọba Ọlọ́run yóò mú ìṣọ̀kan gidi wá, yóò sì bù kún gbogbo àwọn olùfẹ́ òdodo. O ò ṣe fi bí ìṣẹ́jú mélòó kan ka Sáàmù kejìléláàádọ́rin [72] nínú Bíbélì rẹ? Àpèjúwe kan wà níbẹ̀ tó jẹ́ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ohun tí ìṣàkóso Ọmọ Ọlọ́run yóò ṣe fún aráyé. Níbi gbogbo láyé, àwọn èèyàn yóò wà níṣọ̀kan, gbogbo ìṣòro wọn, ìyẹn ìpọ́njú, ìwà ipá, ìṣẹ́, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ yóò sì di ohun ìgbàgbé.

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló rò pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kò lè ṣeé ṣe nínú ayé òde òní tó ti pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ yìí. Ṣùgbọ́n àṣìṣe ló máa jẹ́ láti ní irú èrò yẹn. Àwọn ìlérí Ọlọ́run kò kùnà rí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò ní kùnà láé. (Aísáyà 55:10, 11) Ǹjẹ́ o fẹ́ láti rí ìyípadà rere tó ń bọ̀ yìí? O lè rí i. Àní sẹ́, àwọn èèyàn kan ti wà nísinsìnyí tí wọ́n ń múra sílẹ̀ de àkókò yẹn. Wọ́n wá látinú orílẹ̀-èdè gbogbo, àmọ́ dípò kí wọ́n máa bára wọn jà, ńṣe ni wọ́n ṣọ̀kan tí wọ́n sì ń tẹrí ba fún ìṣàkóso Ọlọ́run. (Aísáyà 2:2-4) Àwọn wo ni? Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni. O ò ṣe lọ sí ìpàdé wọn? Ó ṣeé ṣe kó o gbádùn kíkẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn èèyàn tó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ yìí kó o lè tẹrí ba fún ìṣàkóso Ọlọ́run kó o sì lè gbádùn ìṣọ̀kan tí kì yóò lópin.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Àwọn èèyàn láti orílẹ̀-èdè gbogbo ń múra sílẹ̀ láti gbe inú ayé tí ó ṣọ̀kan

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 4]

Saeed Khan/AFP/Getty Images

[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 5]

Obìnrin tó ń ṣọ̀fọ̀: Igor Dutina/AFP/Getty Images; àwọn olùwọ́de: Said Khatib/AFP/Getty Images; àwọn ọkọ̀ ogun: Joseph Barrak/AFP/Getty Images