Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Inú Rere Àìlẹ́tọ̀ọ́sí La Fi Gbà Wọ́n Là, Kì í Ṣe Iṣẹ́ Nìkan

Inú Rere Àìlẹ́tọ̀ọ́sí La Fi Gbà Wọ́n Là, Kì í Ṣe Iṣẹ́ Nìkan

Inú Rere Àìlẹ́tọ̀ọ́sí La Fi Gbà Wọ́n Là, Kì í Ṣe Iṣẹ́ Nìkan

“A ti gbà yín là nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ . . . Kì í ṣe ní tìtorí àwọn iṣẹ́, kí ènìyàn kankan má bàa ní ìdí fun ṣíṣògo.”—ÉFÉSÙ 2:8, 9.

1. Báwo làwọn Kristẹni ṣe yàtọ̀ sáwọn èèyàn lápapọ̀ ní ti ojú tí wọ́n fi ń wo ohun tẹ́nì kọ̀ọ̀kan wọn gbé ṣe, kí sì nìdí?

 ÀWỌN èèyàn ayé òde òní máa ń gbéra ga gan-an nítorí àwọn ohun tí wọ́n gbé ṣe, wọ́n sì tètè máa ń fi irú nǹkan bẹ́ẹ̀ yangàn. Àmọ́ àwọn Kristẹni yàtọ̀. Wọn kì í fi àwọn àṣeyọrí tí wọ́n bá ṣe yangàn, kódà bí àwọn àṣeyọrí náà tiẹ̀ jẹ́ èyí tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn tòótọ́ pàápàá. Lóòótọ́, inú wọn máa ń dùn gan-an sí àṣeyọrí táwọn èèyàn Jèhófà ń ṣe lápapọ̀, àmọ́ wọn kì í sọ ipa tí wọ́n bá kó lẹ́nì kọ̀ọ̀kan fáyé gbọ́. Wọ́n gbà pé ohun tó mú kéèyàn ṣe nǹkan ṣe pàtàkì ju ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan ń gbé ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Kì í ṣe ohun tẹ́nì kan bá gbé ṣe ló máa jẹ́ kó rí ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun gbà níkẹyìn bí kò ṣe ìgbàgbọ́ rẹ̀ àti inú rere Ọlọ́run tí a kò lẹ́tọ̀ọ́ sí.—Lúùkù 17:10; Jòhánù 3:16.

2, 3. Kí ni Pọ́ọ̀lù fi ṣògo, kí sì nìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀?

2 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mọ èyí dáadáa. Lẹ́yìn tó gbàdúrà lẹ́ẹ̀mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ pé kí Ọlọ́run bá òun mú ‘ẹ̀gún kan tó wà nínú ara’ òun kúrò, èsì tí Jèhófà fún un ni pé: “Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí mi ti tó fún ọ; nítorí agbára mi ni a ń sọ di pípé nínú àìlera.” Pọ́ọ̀lù fi ìrẹ̀lẹ̀ gba ohun tí Jèhófà sọ yìí, ó sì sọ pé: “Nítorí náà, ṣe ni èmi yóò kúkú máa fi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ gan-an ṣògo nípa àwọn àìlera mi, kí agbára Kristi lè wà lórí mi bí àgọ́.” Irú ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí Pọ́ọ̀lù ní yìí ló yẹ káwa náà ní.—2 Kọ́ríńtì 12:7-9.

3 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù tayọ nínú iṣẹ́ ìsìn Kristẹni, síbẹ̀ ó mọ̀ pé kì í ṣe pé òun ní agbára àrà ọ̀tọ̀ kan tóun fi ń ṣe àwọn nǹkan tóun ń ṣe. Ìyẹn ló jẹ́ kó fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ sọ pé, ‘Èmi, ẹni tí ó kéré jù lọ nínú gbogbo ẹni mímọ́, ni a fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí yìí fún, pé kí n polongo ìhìn rere nípa àwọn ọrọ̀ tí kò ṣeé díwọ̀n ti Kristi fún àwọn orílẹ̀-èdè.’ (Éfésù 3:8) Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí fi hàn pé kò lẹ́mìí ìgbéraga bẹ́ẹ̀ ni kò jẹ́ olódodo lójú ara rẹ̀. “Ọlọ́run kọ ojú ìjà sí àwọn onírera, ṣùgbọ́n ó fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí fún àwọn onírẹ̀lẹ̀.” (Jákọ́bù 4:6; 1 Pétérù 5:5) Ǹjẹ́ à ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù, ká máa fi ìrẹ̀lẹ̀ ka ara wa sí ẹni tó kéré jù lọ nínú àwọn arákùnrin wa?

“Ẹ Máa Kà Á Sí Pé Àwọn Ẹlòmíràn Lọ́lá Jù Yín Lọ”

4. Kí nìdí tó fi lè má rọrùn nígbà mìíràn láti gbà pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù wá lọ?

4 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni nímọ̀ràn pé: “[Ẹ má ṣe ṣe] ohunkóhun láti inú ẹ̀mí asọ̀ tàbí láti inú ìgbéra-ẹni-lárugẹ, ṣùgbọ́n pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ èrò inú, kí ẹ máa kà á sí pé àwọn ẹlòmíràn lọ́lá jù yín lọ.” (Fílípì 2:3) Èyí lè má rọrùn o, àgàgà tá a bá wà nípò tá a ti ń bójú tó ẹrù iṣẹ́ kan. Ìdí tí kò fi rọrùn lè jẹ́ nítorí pé ẹ̀mí ìdíje tó gbòde kan nínú ayé lónìí ti ràn wá dé àyè kan. Ó lè jẹ́ pé àtikékeré ni wọ́n ti ń kọ́ wa pé ká máa bá àwọn ẹlòmíràn díje, bóyá pẹ̀lú àwọn ẹ̀gbọ́n àti àbúrò wa tàbí pẹ̀lú àwọn ọmọ kíláàsì wa nílé ìwé. Ó lè jẹ́ pé gbogbo ìgbà ni wọ́n máa ń sọ fún wa pé ká sapá láti gba ipò kìíní ní kíláàsì tàbí nínú eré sísá. A mọ̀ pé ohun tó dára gan-an ni kéèyàn fi gbogbo ipá rẹ̀ ṣe ohun tó bójú mu. Àwọn Kristẹni náà máa ń ṣe bẹ́ẹ̀, àmọ́ kì í ṣe tìtorí káwọn èèyàn lè máa kan sáárá sí wọn. Dípò ìyẹn, ńṣe ni wọ́n fẹ́ káwọn fúnra wọn tàbí àwọn ẹlòmíràn jàǹfààní kíkún látinú àwọn ohun tí wọ́n bá ṣé. Àmọ́, ó léwu kéèyàn máa wá ọ̀nà táwọn èèyàn á fi máa kan sáárá sí i pé kò sẹ́lẹ́gbẹ́ẹ rẹ̀. Ọ̀nà wo ló gbà léwu?

5. Téèyàn ò bá ṣọ́ra, kí ni ẹ̀mí ìdíje lè yọrí sí?

5 Téèyàn ò bá ṣọ́ra, ẹ̀mí ìdíje tàbí ẹ̀mí ìgbéra-ẹni-lárugẹ lè sọ ẹnì kan dẹni tí kì í bọ̀wọ̀ fáwọn ẹlòmíràn, tó sì máa ń gbéra ga. Ó lè mú kó bẹ̀rẹ̀ sí í jowú ẹ̀bùn àbínibí àti àǹfààní táwọn ẹlòmíràn ní. Òwe 28:22 sọ pé: “Ènìyàn tí ó ní ojú ìlara ń mú ara rẹ̀ jí gìrì tẹ̀ lé àwọn ohun tí ó níye lórí, ṣùgbọ́n kò mọ̀ pé àìní yóò dé bá òun.” Ó tiẹ̀ lè máa kọjá àyè ẹ̀, kó máa wá bóun ṣe máa dé ipò tí kò lẹ́tọ̀ọ́ sí. Káwọn èèyàn lè rò pé ohun tó ń ṣe dára, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí kùn kó sì máa ṣe àríwísí àwọn ẹlòmíràn, àwa Kristẹni gbọ́dọ̀ yẹra fún irú ìwà yìí. (Jákọ́bù 3:14-16) Bó ti wù kó rí, tí irú ẹni bẹ́ẹ̀ ò bá ṣọ́ra, ó lè dẹni tí ẹ̀mí tèmi-nìkan-ṣáá wọ̀ lẹ́wù.

6. Ìkìlọ̀ wo ni Bíbélì fúnni nípa ẹ̀mí ìdíje?

6 Abájọ tí Bíbélì fi rọ àwa Kristẹni pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a di olùgbéra-ẹni-lárugẹ, ní ríru ìdíje sókè pẹ̀lú ara wa lẹ́nì kìíní-kejì, ní ṣíṣe ìlara ara wa lẹ́nì kìíní-kejì.” (Gálátíà 5:26) Àpọ́sítélì Jòhánù sọ̀rọ̀ nípa Kristẹni kan tó dẹni tó ní irú ẹ̀mí yìí. Jòhánù sọ pé: “Mo kọ̀wé ohun kan sí ìjọ, ṣùgbọ́n Dìótíréfè, ẹni tí ń fẹ́ láti gba ipò àkọ́kọ́ láàárín wọn, kò fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ gba ohunkóhun láti ọ̀dọ̀ wa. Ìdí nìyẹn, bí mo bá dé, tí èmi yóò fi rántí àwọn iṣẹ́ rẹ̀ tí ó ń bá a lọ ní ṣíṣe, tí ó ń fi àwọn ọ̀rọ̀ burúkú wírèégbè nípa wa.” Ẹ ò rí i pé ipò tó burú jáì tí kò yẹ kí Kristẹni kan bá ara rẹ̀ lèyí!—3 Jòhánù 9, 10.

7. Kí ni Kristẹni kan ní láti yẹra fún lóde òní tí ẹ̀mí ìdíje gbòde kan lẹ́nu iṣẹ́?

7 Ká sòótọ́, kò ní bọ́gbọ́n mu ká máa rò pé Kristẹni kan lè yẹra fún gbogbo ohun tó jẹ mọ́ ìdíje. Bí àpẹẹrẹ, iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ ẹnì kan lè jẹ́ èyí tó máa mú kó máa bá àwọn ẹlòmíràn tàbí ilé iṣẹ́ mìíràn díje, yálà àwọn tí wọ́n jọ ń ṣe irú ohun kan náà jáde tàbí àwọn tí wọ́n jọ ń ṣe irú iṣẹ́ kan náà. Kódà nínú irú ipò yẹn, Kristẹni kan ní láti wá bóun ṣe máa ṣe iṣẹ́ òun lọ́nà tó máa fi ẹ̀mí ọ̀wọ̀, ìfẹ́ àti ìgbatẹnirò hàn. Á yẹra pátápátá fún àwọn ohun tó lòdì sófin tàbí àwọn ìwà tí kò yẹ Kristẹni, á sì yẹra fún dídi ẹni táwọn èèyàn mọ̀ sí ẹlẹ́mìí ìdíje tàbí ẹni tó lẹ́mìí bó o ba o pá, bó ò ba o bù ú lẹ́sẹ̀. Kò ní máa ronú pé mímú ipò iwájú nínú gbogbo nǹkan ló ṣe pàtàkì jù lọ láyé. Bí Kristẹni kan bá ní láti yẹra fún irú ẹ̀mí ìdíje bẹ́ẹ̀ nínú iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ rẹ̀, mélòómélòó wá ni nínú ọ̀ràn ìjọsìn!

‘Kì Í Ṣe ní Ìfiwéra Pẹ̀lú Ẹlòmíràn’

8, 9. (a) Èé ṣe tí kò fi sídìí kankan tó fi yẹ káwọn alàgbà máa bára wọn díje? (b) Kí nìdí tó fi jẹ́ pé gbogbo ìránṣẹ́ Ọlọ́run ni ọ̀rọ̀ inú 1 Pétérù 4:10 kàn?

8 Irú ẹ̀mí tó yẹ káwọn Kristẹni ní nínú ìjọsìn wọn la ṣàpèjúwe rẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ onímìísí yìí, tó kà pé: “Kí olúkúlùkù máa wádìí ohun tí iṣẹ́ tirẹ̀ jẹ́, nígbà náà ni yóò ní ìdí fún ayọ̀ ńláǹlà ní ti ara rẹ̀ nìkan, kì í sì í ṣe ní ìfiwéra pẹ̀lú ẹlòmíràn.” (Gálátíà 6:4) Nítorí pé àwọn alàgbà nínú ìjọ mọ̀ pé àwọn ò kì í bá ara wọn díje ni wọ́n ṣe ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láàárín ara wọn tí wọ́n sì jùmọ̀ ń ṣiṣẹ́ pọ̀ bí ìgbìmọ̀ kan. Inú wọn máa ń dùn sí ipa tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọ́n bá kó láti jẹ́ kí gbogbo nǹkan máa lọ déédéé nínú ìjọ. Wọ́n tipa bẹ́ẹ̀ ń yẹra fún ẹ̀mí ìdíje tí kì í jẹ́ kí nǹkan lọ bó ṣe yẹ, wọ́n sì ń fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ kí gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ lè wà níṣọ̀kan.

9 Àwọn alàgbà kan lè jáfáfá tàbí kí wọ́n ní ìjìnlẹ̀ òye ju àwọn mìíràn lọ nítorí ọjọ́ orí wọn, nítorí ohun tójú wọn ti rí tàbí ẹ̀bùn àbínibí wọn. Ìdí nìyẹn táwọn alàgbà fi ní iṣẹ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tẹ́nì kọ̀ọ̀kan wọn ń bójú tó nínú ètò Jèhófà. Dípò kí wọ́n máa fi ẹlòmíràn wé ara wọn, ìmọ̀ràn tí wọ́n máa ń fi sọ́kàn ni pé: “Níwọ̀n yíyẹ gẹ́gẹ́ bí olúkúlùkù ti rí ẹ̀bùn kan gbà, ẹ lò ó fún ṣíṣe ìránṣẹ́ fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì gẹ́gẹ́ bí ìríjú àtàtà fún inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọ́run tí a fi hàn ní onírúurú ọ̀nà.” (1 Pétérù 4:10) Ní ti gidi, gbogbo ìránṣẹ́ Jèhófà ni ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí kàn, nítorí pé gbogbo wọn ló ti gba ẹ̀bùn ìmọ̀ pípéye dé àyè kan, gbogbo wọn ló sì láǹfààní láti kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni.

10. Ọ̀nà wo ni ìṣẹ́ ìsìn mímọ́ wa fi lè jẹ́ èyí tí inú Jèhófà dùn sí?

10 Tá a bá fẹ́ kí iṣẹ́ ìsìn mímọ́ wa múnú Jèhófà dùn, a gbọ́dọ̀ fi ìfẹ́ àti ìfọkànsìn ṣe é, a ò ní máa ṣe é tìtorí ète àtijẹ gàba lórí àwọn tó kù. Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká ní èrò tó dára nípa iṣẹ́ tá à ń ṣe láti ti ìjọsìn tòótọ́ lẹ́yìn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ẹni tó mọ ohun tó wà lọ́kàn ẹnì kejì rẹ̀, síbẹ̀ Jèhófà “ń díwọ̀n àwọn ọkàn-àyà.” (Òwe 24:12; 1 Sámúẹ́lì 16:7) Nípa bẹ́ẹ̀, ì bá dára ká máa bi ara wa nígbà gbogbo pé, ‘Kí nìdí tí mo fi ń kópa nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà?’—Sáàmù 24:3, 4; Mátíù 5:8.

Ojú Tó Yẹ Ká Máa Fi Wo Iṣẹ́ Ìsìn Wa

11. Àwọn ìbéèrè wo ló bọ́gbọ́n mu fún wa láti gbé yẹ̀ wò nípa ìgbòkègbodò wa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?

11 Tó bá jẹ́ pé ohun tó ń mú ká ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ni olórí ohun tá a máa fi rí ojú rere Jèhófà, báwo ló ṣe wá yẹ kí iṣẹ́ ìwàásù ká wa lára tó? Bó bá ṣáà ti jẹ́ èrò tó dáa ló ń mú ká ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà, ǹjẹ́ ó tún pọn dandan fún wa láti ròyìn iṣẹ́ tá a ba ṣe àti iye àkókò tá a fi ṣe é? Àwọn ìbéèrè wọ̀nyí mọ́gbọ́n dání, nítorí pé a ò ní fẹ́ kó jẹ́ pé bí àkókò tá a lò ṣe pọ̀ tó ló máa ká wa lára ju iṣẹ́ ìsìn wa sí Jèhófà tàbí kó jẹ́ pé tìtorí kí ìròyìn iṣẹ́ ìwàásù wa lè jọjú la ṣe ń lọ sóde ẹ̀rí.

12, 13. (a) Kí làwọn ìdí díẹ̀ tá a fi ń kọ ìròyìn iṣẹ́ ìwàásù wa sílẹ̀? (b) Kí làwọn ohun tó máa ń múnú wa dùn nígbà tá a bá ń wo àpapọ̀ ìròyìn iṣẹ́ ìwàásù wa?

12 Kíyè sí ohun tí ìwé A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà sọ, ó ní: “Àwọn tó kọ́kọ́ di ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi máa ń nífẹ̀ẹ́ sí ìròyìn nípa bí iṣẹ́ ìwàásù náà ṣe ń tẹ̀ síwájú. (Máàkù 6:30) Ìwé Ìṣe nínú Bíbélì sọ fún wa pé ó tó ọgọ́fà èèyàn tó kóra jọ nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bà lé àwọn ọmọ ẹ̀yìn nígbà Pẹ́ńtíkọ́sì. Kò pẹ́ sígbà náà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn fi di ẹgbẹ̀rún mẹ́ta, nígbà tó sì tún yá, wọ́n di ẹgbẹ̀rún márùn-ún. . . . (Ìṣe 1:15; 2:5-11, 41, 47; 4:4; 6:7) Ìròyìn pípọ̀ tí wọ́n ń pọ̀ sí i yìí á mà fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn níṣìírí o!” Nítorí ìdí kan náà yìí làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní fi ń sapá láti ṣe àkọsílẹ̀ tó péye nípa iṣẹ́ tí wọ́n ṣe jákèjádò ayé ní ìmúṣẹ ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” (Mátíù 24:14) Irú àwọn ìròyìn bẹ́ẹ̀ ń jẹ́ ká rí i bí iṣẹ́ wa ṣe ń lọ sí jákèjádò ayé. Wọ́n ń jẹ́ ká mọ àwọn àgbègbè tó nílò ìrànlọ́wọ́, wọ́n tún ń jẹ́ ká mọ irú ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tá a nílò láti mú iṣẹ́ ìwàásù náà tẹ̀ síwájú àti bí àwọn ìwé náà á ṣe pọ̀ tó.

13 Nítorí náà, ríròyìn iṣẹ́ ìwàásù wa mú kó ṣeé ṣe fún wa láti túbọ̀ ṣe iṣẹ́ tá a gbé lé wa lọ́wọ́ lọ́nà tó gbéṣẹ́, ìyẹn iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere Ìjọba náà. Yàtọ̀ síyẹn, ǹjẹ́ orí wa kì í wú nígbà tá a bá gbọ́ nípa iṣẹ́ táwọn arákùnrin àti arábìnrin wa ń ṣe láwọn apá ibòmíràn láyé? Ìròyìn nípa bá a ṣe ń pọ̀ sí i àti bí àwọn ilẹ̀ tá a ti ń wàásù ṣe ń gbòòrò sí i máa ń múnú wa dùn gan-an. Ó ń jẹ́ ká túbọ̀ máa kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù náà, ó sì ń mú un dá wa lójú pé ìbùkún Jèhófà wà lórí iṣẹ́ náà. Ẹ sì wo bínú wa ṣe máa ń dùn tó nígbà tá a bá rí i pé iṣẹ́ tí àwa gan-an alára ṣe wà lára ìròyìn jákèjádò ayé yẹn! Ohun tẹ́nì kọ̀ọ̀kan wa ń ṣe kéré gan-an tá a bá fi wéra pẹ̀lú gbogbo ìròyìn náà lápapọ̀, àmọ́ Jèhófà ò fojú kékeré wò ó. (Máàkù 12:42, 43) Rántí pé tí ìròyìn tìẹ ò bá sí níbẹ̀, àpapọ̀ ìròyìn jákèjádò ayé kò ní pé.

14. Yàtọ̀ sí wíwàásù àti kíkọ́ni, nǹkan mìíràn wo la tún máa ń ṣe nínú ìjọsìn wa sí Jèhófà?

14 Ká sòótọ́, èyí tó pọ̀ jù lọ lára iṣẹ́ tí Ẹlẹ́rìí kọ̀ọ̀kan ń ṣe láti mú ojúṣe rẹ̀ ṣẹ gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ tó ti yara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà ni kì í fara hàn nínú ìròyìn rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, a kì í ròyìn ẹ̀kọ́ tẹ́nì kọ̀ọ̀kan wá máa ń dá kọ́ nínú Bíbélì, bẹ́ẹ̀ náà ni a kì í kọ iye ìgbà tá a wá sípàdé àti ipa tá a kó nínú àwọn ìpàdé náà sínú rẹ̀. A kì í ròyìn iṣẹ́ ìjọ tá a bá ṣe àti ìrànlọ́wọ́ tá a bá ṣe fáwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́, kódà a kì í kọ iye owó tá a fi ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ Ìjọba náà kárí ayé àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ sínú ìròyìn wa. Nítorí náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìròyìn iṣẹ́ ìsìn wa ṣe pàtàkì ni tí pé ó ń ràn wá lọ́wọ́ láti máa fi ìtara wàásù nìṣó ká má sì jó àjórẹ̀yìn, síbẹ̀ a ò gbọ́dọ̀ máa rò pé ìròyìn náà ló ṣe pàtàkì jù lọ. Ká má ṣe wò ó gẹ́gẹ́ bí ìwé àṣẹ tó máa jẹ́ ká tóótun láti ní ìyè àìnípẹ̀kun.

“Àwọn Onítara fún Iṣẹ́ Àtàtà”

15. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ nìkan kò lè gbà wá là, síbẹ̀ kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì?

15 Ní kedere, bó tilẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ nìkan ò lè gbà wá là, síbẹ̀ ó ṣe pàtàkì. Ìdí nìyẹn tá a fi pe àwọn Kristẹni ní “àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ tirẹ̀ lákànṣe . . . àwọn onítara fún iṣẹ́ àtàtà.” Ìyẹn náà ló sì mú ká rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n máa ‘gba ti ara wọn rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wọn sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà.’ (Títù 2:14; Hébérù 10:24) Jákọ́bù tóun náà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì kò tiẹ̀ fọ̀rọ̀ náà sábẹ́ ahọ́n sọ rárá, ó là á mọ́lẹ̀ pé: “Gẹ́gẹ́ bí ara láìsí ẹ̀mí ti jẹ́ òkú, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ìgbàgbọ́ láìsí àwọn iṣẹ́ jẹ́ òkú.”—Jákọ́bù 2:26.

16. Kí ló tiẹ̀ tún ṣe pàtàkì ju iṣẹ́ lọ, àmọ́ kí ló yẹ ká ṣọ́ra fún?

16 Bó ti wù kí iṣẹ́ rere ṣe pàtàkì tó, síbẹ̀ ohun tó ń mú ká ṣe é ló ṣe pàtàkì jù. Nítorí náà, ó bọ́gbọ́n mu pé ká máa yẹ ohun tó ń mú ká ṣe iṣẹ́ náà wò látìgbàdégbà. Níwọ̀n bí kò ti sí ẹ̀dá ènìyàn kan tó lè mọ èrò ọkàn ẹlòmíràn, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ká má máa dá àwọn ẹlòmíràn lẹ́jọ́. Pọ́ọ̀lù bi wá pé: “Ta ni ìwọ láti ṣèdájọ́ ìránṣẹ́ ilé ẹlòmíràn?” Ó sì dáhùn ní kedere pé: “Lọ́dọ̀ ọ̀gá òun fúnra rẹ̀ ni ó dúró tàbí ṣubú.” (Róòmù 14:4) Jèhófà tó jẹ́ Ọ̀gá gbogbo wa, àti Onídàájọ́ tó ti yàn, ìyẹn Kristi Jésù ni yóò ṣe ìdájọ́ wa, wọn ò sì ní gbé ìdájọ́ náà karí ìṣẹ́ wa nìkan àmọ́ wọ́n á tún gbé e karí ohun tó sún wa ṣe é, àwọn àǹfààní tá a ní, ìfẹ́ wa, àti ìfọkànsìn wa. Jèhófà àti Kristi Jésù nìkan ló lè sọ bóyá a ti ṣe ohun tá a sọ pé káwa Kristẹni ṣe nínú ọ̀rọ̀ tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Sa gbogbo ipá rẹ láti fi ara rẹ hàn fún Ọlọ́run ní ẹni tí a tẹ́wọ́ gbà, aṣiṣẹ́ tí kò ní ohun kankan láti tì í lójú, tí ń fi ọwọ́ títọ̀nà mú ọ̀rọ̀ òtítọ́.”—2 Tímótì 2:15; 2 Pétérù 1:10; 3:14.

17. Bá a ti ń làkàkà láti sa gbogbo ipá wa, kí nìdí tá a fi ní láti fi ọ̀rọ̀ inú Jákọ́bù 3:17 sọ́kàn?

17 Jèhófà kì í retí pé ká ṣe ju agbára wa lọ. Lára àwọn nǹkan tí Jákọ́bù 3:17 sọ nípa “ọgbọ́n tí ó wá láti òkè” ni pé “ó ń fòye báni lò.” Ǹjẹ́ kò ní jẹ́ ìwà ọgbọ́n àti àṣeyọrí lóòótọ́ tá a bá fara wé Jèhófà nínú èyí? Nítorí náà, kò yẹ ká máa ronú pé a ó sapá láti ṣe ohun tó ju agbára wa lọ tàbí ohun tí ọwọ́ wa kò lè tẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni kò yẹ ká máa retí pé káwọn arákùnrin wa ṣe ju agbára wọn lọ.

18. Kí la lè máa wọ̀nà fún tá a bá ń fi ojú tó tọ́ wo iṣẹ́ wa, tí Jèhófà sì tún ń fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ hàn sí wa?

18 Bá a bá ń fojú tó tọ́ wo iṣẹ́ ìsìn wa, tí Jèhófà sì tún ń fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ hàn sí wa, ó dájú pé a óò ní ayọ̀ tá a fi ń dá àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà mọ̀. (Aísáyà 65:13, 14) Ìbùkún tí Jèhófà ń tú sórí àwọn èèyàn rẹ̀ lápapọ̀ yóò máa múnú wa dùn láìka bí ohun tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ń ṣe níbẹ̀ ti kéré tó sí. Nípasẹ̀ “àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́” nígbà gbogbo, ẹ jẹ́ ká máa bẹ Ọlọ́run pé kó ràn wá lọ́wọ́ láti sa gbogbo ipá wa. Lẹ́yìn ìyẹn, ó dájú hán-ún pé, ‘àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà wa àti agbára èrò orí wa nípasẹ̀ Kristi Jésù.’ (Fílípì 4:4-7) Láìsí àní-àní, a lè rí ìtùnú àti ìṣírí gbà látinú mímọ̀ tá a mọ̀ pé inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà la ó fi gbà wá là, kì í ṣe iṣẹ́ nìkan!

Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?

• Kí nìdí táwọn Kristẹni lẹ́nì kọ̀ọ̀kan kì í fi ohun tí wọ́n gbé ṣe yangàn?

• Kí nìdí táwọn Kristẹni kì í ní ẹ̀mí ìdíje?

• Kí nìdí táwọn Kristẹni fi máa ń ròyìn ohun tí wọ́n bá ṣe nínú iṣẹ́ ìwàásù wọn?

• Kí nìdí táwọn Kristẹni kò fi ń ṣèdájọ́ àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

“Inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí mi ti tó fún ọ”

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]

Inú àwọn alàgbà máa ń dùn sí ipa tí ẹnì kọ̀ọ̀kan bá lè kó láti mú kí ìjọ máa tẹ̀ síwájú

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18 19]

Bí ìròyìn tìẹ kò bá sí níbẹ̀, àpàpọ̀ ìròyìn jákèjádò ayé kò ní pé