Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jèhófà Ń dáàbò Bo Àwọn Tó Ní Ìrètí Nínú Rẹ̀

Jèhófà Ń dáàbò Bo Àwọn Tó Ní Ìrètí Nínú Rẹ̀

Jèhófà Ń dáàbò Bo Àwọn Tó Ní Ìrètí Nínú Rẹ̀

“Jẹ́ kí inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ àti òótọ́ rẹ máa fi ìṣọ́ ṣọ́ mi nígbà gbogbo.”—SÁÀMÙ 40:11.

1. Kí ni Dáfídì Ọba bẹ̀bẹ̀ pé kí Jèhófà ṣe fóun, ọ̀nà wo sì ni Jèhófà gbà dáhùn ẹ̀bẹ̀ yẹn báyìí?

 ‘TARATARA ni Dáfídì ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì fi ní ìrètí nínú Jèhófà,’ ìyẹn ló mú kó sọ pé Jèhófà “dẹ etí rẹ̀ sí [òun], ó sì gbọ́ igbe [òun] fún ìrànlọ́wọ́.” (Sáàmù 40:1) Ọ̀pọ̀ ìgbà lóun fúnra rẹ̀ rí i bí Jèhófà ṣe dáàbò bo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Rẹ̀. Ìdí nìyẹn tí Dáfídì fi bẹ Jèhófà pé kó máa dáàbò bo òun ní gbogbo ìgbà. (Sáàmù 40:11) Dáfídì wà lára àwọn olóòótọ́ ọkùnrin àti obìnrin tí Ọlọ́run ṣèlérí fún pé wọn yóò ní “àjíǹde tí ó sàn jù.” Lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí, Jèhófà dáàbò bó Dáfídì ní ti pé ó ń rántí rẹ̀ pé yóò gba èrè àjíǹde yẹn. (Hébérù 11:32-35) Ó dájú hán-ún pé yóò padà wà láàyè lọ́jọ́ iwájú. Orúkọ rẹ̀ sì wà nínú “ìwé ìrántí” Jèhófà.—Málákì 3:16.

2. Báwo ni Ìwé Mímọ́ ṣe ràn wá lọ́wọ́ láti lóye ohun tí ààbò Jèhófà túmọ̀ sí?

2 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn olóòótọ́ èèyàn tá a mẹ́nu kàn nínú Hébérù orí kọkànlá yẹn ti gbé ayé ṣáájú àkókò tí Jésù Kristi wá sáyé, síbẹ̀ wọ́n gbé ìgbésí ayé wọn lọ́nà tó bá ohun tí Jésù fi kọ́ni mu nígbà tó sọ pé: “Ẹni tí ó bá ní ìfẹ́ni fún ọkàn rẹ̀ ń pa á run, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá kórìíra ọkàn rẹ̀ nínú ayé yìí, yóò fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ fún ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 12:25) Nítorí náà, pé Jèhófà ń dáàbò boni kò túmọ̀ sí pé èèyàn ò ní rí ìṣòro tàbí inúnibíni. Ohun tó túmọ̀ sí ni pé Jèhófà yóò dáàbò bo onítọ̀hún nípa tẹ̀mí kó lè ṣeé ṣe fún un láti jẹ́ oníwà mímọ́ lójú Ọlọ́run.

3. Ẹ̀rí wo la fi mọ̀ pé Jèhófà dáàbò bo Kristi Jésù, kí sì ni àbájáde rẹ̀?

3 Àwọn èèyàn ṣe inúnibíni tó burú jáì sí Jésù fúnra rẹ̀, wọ́n sì tún pẹ̀gàn rẹ̀. Níkẹyìn, àwọn ọ̀tá rẹ̀ fi ikú oró tó tini lójú jù lọ láyé yìí pa á. Síbẹ̀, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé Ọlọ́run kùnà láti mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ pé òun á dáàbò bo Mèsáyà náà. (Aísáyà 42:1-6) Àjíǹde Jésù ní ọjọ́ kẹta lẹ́yìn ikú ìtìjú tó kú fi hàn pé Jèhófà gbọ́ igbe rẹ̀ pé kí Ọlọ́run ran òun lọ́wọ́, bí Jèhófà ṣe gbọ́ igbe Dáfídì nígbà tó sọ pé kó ran òun lọ́wọ́. Jèhófà sì fún Jésù lókun láti pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́. (Mátíù 26:39) Níwọ̀n bí Jèhófà ti dáàbò bo Jésù lọ́nà yìí, Jésù wá tipa bẹ́ẹ̀ dẹni tí kò ní kú mọ́ lọ́run, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn tó ní ìgbàgbọ́ nínú ìràpadà náà sì ń wọ̀nà fún ìyè àìnípẹ̀kun.

4. Ìdánilójú wo ló wà fún àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn “àgùntàn mìíràn”?

4 A lè ní ìdánilójú pé Jèhófà múra tán láti dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lóde òní, ó sì lágbára láti ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bó ti ṣe nígbà ayé Dáfídì àti ti Jésù. (Jákọ́bù 1:17) Ìwọ̀nba àwọn díẹ̀ tó ṣẹ́ kù sórí ilẹ̀ ayé lára àwọn ẹni àmì òróró arákùnrin Jésù lè gbára lé ìlérí Jèhófà tó sọ pé: “Ogún tí ó jẹ́ aláìlè-díbàjẹ́ àti aláìlẹ́gbin àti aláìlèṣá . . . [ni] a fi . . . pa mọ́ ní ọ̀run de ẹ̀yin, tí agbára Ọlọ́run ń fi ìṣọ́ ṣọ́ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ fún ìgbàlà kan tí a múra tán láti ṣí payá ní sáà àkókò ìkẹyìn.” (1 Pétérù 1:4, 5) Àwọn “àgùntàn mìíràn,” tí wọ́n ní ìrètí àtigbé lórí ilẹ̀ ayé náà lè gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run kí wọ́n sì fọkàn tán ìlérí tó ṣe nípasẹ̀ onísáàmù tó sọ pé: “Ẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀. Jèhófà ń fi ìṣọ́ ṣọ́ àwọn olùṣòtítọ́.”—Jòhánù 10:16; Sáàmù 31:23.

Jèhófà Ń Dáàbò Bò Wá Nípa Tẹ̀mí

5, 6. (a) Ọ̀nà wo ni Ọlọ́run gbà ń dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ lóde òní? (b) Àjọṣe wo ló wà láàárín àwọn ẹni àmì òróró àti Jèhófà, àjọṣe wo ló sì wà láàárín òun àtàwọn tó ń retí àtigbé lórí ilẹ̀ ayé?

5 Lóde òní, Jèhófà ti ṣètò láti dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ nípa tẹ̀mí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò dáàbò bò wọ́n kúrò lọ́wọ́ inúnibíni tàbí kúrò lọ́wọ́ àwọn ìṣòro àtàwọn ọ̀ràn ìbànújẹ́ tó máa ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo èèyàn, síbẹ̀ kò dáwọ́ dúró láti máa pèsè ìrànwọ́ àti ìṣírí tí wọ́n nílò kí àjọṣe tímọ́tímọ́ tó wà láàárín òun àtàwọn má bàa bà jẹ́. Orí ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú ìràpadà tí Ọlọ́run fìfẹ́ pèsè ni àjọṣe yìí dúró lé. Ọlọ́run ti fi ẹ̀mí rẹ̀ yan àwọn kan lára àwọn Kristẹni olóòótọ́ wọ̀nyí láti bá Kristi ṣàkóso ní ọ̀run. A ti polongo wọn ní olódodo, wọ́n jẹ́ ọmọ tẹ̀mí fún Ọlọ́run, àwọn sì ni ọ̀rọ̀ yìí ń tọ́ka sí pé: “Ó dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ọlá àṣẹ òkùnkùn, ó sì ṣí wa nípò lọ sínú ìjọba Ọmọ ìfẹ́ rẹ̀, nípasẹ̀ ẹni tí a gba ìtúsílẹ̀ wa nípa ìràpadà, ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa.”—Kólósè 1:13, 14.

6 Ó dá àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn Kristẹni olóòótọ́ yòókù lójú pé àwọn náà lè jàǹfààní látinú ìràpadà tí Ọlọ́run pèsè yìí. A kà pé: “Ọmọ ènìyàn pàápàá wá, kì í ṣe kí a lè ṣe ìránṣẹ́ fún un, bí kò ṣe kí ó lè ṣe ìránṣẹ́ kí ó sì fi ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Máàkù 10:45) Àwọn Kristẹni wọ̀nyẹn ń retí àtigbádùn “òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run” nígbà tí àkókò bá tó. (Róòmù 8:21) Ní báyìí ná, wọ́n ka àjọṣe àárín àwọn àti Ọlọ́run sí ohun tó ṣe pàtàkì gan-an, wọ́n sì ń sapá láti jẹ́ kí àjọṣe náà túbọ̀ lágbára sí i.

7. Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà ń dáàbò bo ipò tẹ̀mí àwọn èèyàn rẹ̀ lóde òní?

7 Ọ̀nà kan tí Jèhófà gbà ń dáàbò bo ipò tẹ̀mí àwọn èèyàn rẹ̀ ni pé ó ṣètò ẹ̀kọ́ tí kò dáwọ́ dúró fún wọn. Èyí ló jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wọn láti ní ìmọ̀ òtítọ́ tó túbọ̀ péye sí i. Jèhófà tún ń tipasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ètò rẹ̀, àti ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ pèsè ìtọ́sọ́nà nígbà gbogbo. Bí ìdílé kan ṣoṣo ni gbogbo àwọn èèyàn Ọlọ́run jákèjádò ayé rí, tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” sì ń dárí wọn. Ẹgbẹ́ ẹrú yìí máa ń bójú tó ohun táwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tí wọ́n jẹ́ ìdílé kan yìí nílò nípa tẹ̀mí, kódà ó tún máa ń bójú tó ohun tí wọ́n nílò nípa tara nígbà mìíràn. Ẹgbẹ́ ẹrú náà sì ń ṣe èyí láìka ibi táwọn èèyàn náà ti wá tàbí ipò tí wọ́n wà láwùjọ sí.—Mátíù 24:45.

8. Ìgbọ́kànlé wo ni Jèhófà ní nínú àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin sí i, kí nìyẹn sì mú dá wọn lójú?

8 Bí Jèhófà kò ṣe ṣíji bo Jésù nígbà táwọn ọ̀tá rẹ̀ gbógun tì í náà ni kì í ṣeé ṣíji bo àwọn Kristẹni nígbà míì táwọn ọ̀tá bá gbógun tì wọ́n lóde òní. Àmọ́ èyí ò túmọ̀ sí pé inú Ọlọ́run ò dùn sí wọn o! Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló fi hàn pé òun fọkàn tán wọn pé ìhà ọ̀dọ̀ òun ni wọ́n wà nínú ọ̀ràn ńlá kan tó kan gbogbo ayé àtọ̀run. (Jóòbù 1:8-12; Òwe 27:11) Jèhófà kò ní fi àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin sí i sílẹ̀ láé, “nítorí pé olùfẹ́ ìdájọ́ òdodo ni Jèhófà, òun kì yóò sì fi àwọn ẹni ìdúróṣinṣin rẹ̀ sílẹ̀. Fún àkókò tí ó lọ kánrin ni [yóò] máa ṣọ́ wọn dájúdájú.”—Sáàmù 37:28.

Inú Rere àti Òótọ́ Ń Dáàbò Boni

9, 10. (a) Báwo ni òótọ́ Jèhófà ṣe ń dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀? (b) Báwo ni Bíbélì ṣe fi hàn pé Jèhófà ń fi inú rere rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ dáàbò bo àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin sí i?

9 Nínú àdúrà tó wà ní Sáàmù ogójì, Dáfídì bẹ̀bẹ̀ pé kí inú rere onífẹ̀ẹ́ àti òótọ́ Jèhófà dáàbò bo òun. Òótọ́ Jèhófà àti bó ṣe nífẹ̀ẹ́ òdodo ló mú kó sọ àwọn ìlànà rẹ̀ fúnni lọ́nà tó yéni yékéyéké. Àwọn tó ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà yìí sì ń rí ààbò dé ìwọ̀n àyè kan kúrò nínú wàhálà, ìbẹ̀rù, àtàwọn ìṣòro tó ń dé bá àwọn tí kò tẹ̀ lé àwọn ìlànà rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwa àtàwọn ìdílé wa lè bọ́ lọ́wọ́ ọ̀pọ̀ ìṣòro tó ń bani lọ́kàn jẹ́ tá a bá yàgò fún oògùn líle, ọtí àmupara, ìṣekúṣe, àti ìgbésí ayé oníwà ipá. Kódà, àwọn tó kọsẹ̀ ní ọ̀nà òtítọ́ Jèhófà, bí Dáfídì ti ṣe láwọn ìgbà kan, ní ìdánilójú pé Ọlọ́run ṣì jẹ́ “ibi ìlùmọ́” fún àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ronú pìwà dà. Irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lè fi ìdùnnú sọ pé: “Ìwọ yóò fi ìṣọ́ ṣọ́ mi kúrò nínú wàhálà pàápàá.” (Sáàmù 32:7) Èyí mà fi inú rere onífẹ̀ẹ́ tí Ọlọ́run ní fún wa hàn o!

10 Àpẹẹrẹ mìíràn tó tún fi inú rere onífẹ̀ẹ́ tí Ọlọ́run ní hàn ni bó ṣe kìlọ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé kí wọ́n ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé búburú tó máa pa run láìpẹ́ yìí. A kà pé: “Ẹ má ṣe máa nífẹ̀ẹ́ yálà ayé tàbí àwọn ohun tí ń bẹ nínú ayé. Bí ẹnikẹ́ni bá nífẹ̀ẹ́ ayé, ìfẹ́ fún Baba kò sí nínú rẹ̀; nítorí ohun gbogbo tí ń bẹ nínú ayé—ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ojú àti fífi àlùmọ́ọ́nì ìgbésí ayé ẹni hàn sóde lọ́nà ṣekárími—kò pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Baba, ṣùgbọ́n ó pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ ayé.” Tá a bá kọbi ara sí ìkìlọ̀ yìí, tá a sì ṣe ohun tó sọ yìí, Ọlọ́run yóò dáàbò bo ẹ̀mí wa títí ayérayé, nítorí ẹsẹ náà tún sọ pé: “Síwájú sí i, ayé ń kọjá lọ, bẹ́ẹ̀ sì ni ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni yóò dúró títí láé.”—1 Jòhánù 2:15-17.

Agbára Láti Ronú, Ìfòyemọ̀, àti Ọgbọ́n Ń Dáàbò Boni

11, 12. Ṣàlàyé ọ̀nà tí agbára láti ronú, ìfòyemọ̀, àti ọgbọ́n gbà ń dáàbò bò wá.

11 Ọlọ́run mí sí Sólómọ́nì ọmọ Dáfídì láti kọ̀wé sí àwọn tó fẹ́ rí ojú rere Ọlọ́run. Ohun tó kọ ni pé: “Agbára láti ronú yóò máa ṣọ́ ọ, ìfòyemọ̀ yóò máa fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ.” Ó tún rọ̀ wọ́n pé: “Ní ọgbọ́n . . . Má fi í sílẹ̀, yóò sì pa ọ́ mọ́. Nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, yóò sì fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ.”—Òwe 2:11; 4:5, 6.

12 À ń lo agbára láti ronú nígbà tá a bá ṣàṣàrò lórí ohun tá à ń kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ yóò jẹ́ kí ìfòyemọ̀ wa túbọ̀ pọ̀ sí i ká lè gbájú mọ́ àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù. Èyí ṣe pàtàkì gan-an níwọ̀n bí èyí tó pọ̀ jù lọ lára wa ti mọ̀ pé ìgbà táwọn èèyàn bá fi ohun tí kò ṣe pàtàkì ṣáájú nínú ìgbésí ayé wọn ni ìṣòro máa ń dé, yálà wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ tàbí wọn ò mọ̀ọ́mọ̀. Ó tiẹ̀ lè ti ṣẹlẹ̀ sí àwa fúnra wa pàápàá rí. Ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì, òkìkí, àti agbára ni ayé Sátánì máa ń fi fani mọ́ra, nígbà tí Jèhófà ń gbà wá níyànjú láti gbájú mọ́ àwọn nǹkan tẹ̀mí tó ṣe pàtàkì jù lọ. Kíkùnà láti fi ohun tẹ̀mí ṣáájú ohun ti ara lè mú kí ìdílé tú ká, ó lè jẹ́ kí àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn bà jẹ́, ó sì lè máà jẹ́ kí ohun tí à ń lé nípa tẹ̀mí ṣe pàtàkì lójú wa mọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ èèyàn lè wá já sí ohun ìbànújẹ́ tí Jésù mẹ́nu kàn nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, nígbà tó sọ pé: “Àǹfààní wo ni ó jẹ́ fún ènìyàn kan láti jèrè gbogbo ayé, kí ó sì pàdánù ọkàn rẹ̀?” (Máàkù 8:36) Ìwà ọgbọ́n ló jẹ́ tá a bá kọbi ara sí ìmọ̀ràn Jésù tó sọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.”—Mátíù 6:33.

Dídi Onímọtara-Ẹni-Nìkan Léwu

13, 14. Kí ló túmọ̀ sí tá a bá sọ pé ẹnì kan jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan, kí sì nìdí tí kò fi bọ́gbọ́n mu láti di irú èèyàn bẹ́ẹ̀?

13 Gbogbo èèyàn ló fẹ́ kí nǹkan tòun dáa. Àmọ́, nígbà téèyàn ba wá jẹ́ kí ohun tọ́kàn òun fẹ́ àti ohun tó wu òun di nǹkan tó ṣe pàtàkì jù lọ, wàhálà á dé ṣáá ni. Nítorí náà, kí àjọṣe àárín àwa àti Jèhófà má bàa yingin, ó gbà wá nímọ̀ràn pé ká yẹra fún dídi onímọtara-ẹni-nìkan. Tá a bá sì sọ pé ẹnì kan jẹ́ onímọtara-ẹni-nìkan, ó túmọ̀ sí pé onítọ̀hún jẹ́ kí “kìkì ohun tọ́kàn òun fẹ́, ohun tóun nílò, tàbí ohun tóun fẹ́ràn di ohun tó ká òun lára jù lọ láyé.” Ǹjẹ́ kì í ṣe bí ọ̀pọ̀ èèyàn ṣe rí gẹ́lẹ́ lóde òní nìyẹn? Kódà, Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé “ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ètò búburú ti Sátánì yìí, “àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn” tàbí onímọtara-ẹni-nìkan.—2 Tímótì 3:1, 2.

14 Àwọn Kristẹni gbà pé ó mọ́gbọ́n dání láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé kí wọ́n jẹ́ kí ire àwọn ẹlòmíràn máa jẹ wọ́n lọ́kàn, kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn ẹlòmíràn bí wọ́n ṣe nífẹ̀ẹ́ ara wọn. (Lúùkù 10:27; Fílípì 2:4) Àwọn èèyàn ayé lè máa sọ pé èyí ò mọ́gbọ́n dání o, àmọ́ ó ṣe pàtàkì tá a bá fẹ́ kí ìgbéyàwó wa yọrí sí rere, tá a fẹ́ kí ìdílé wa jẹ́ ìdílé aláyọ̀, tá a sì fẹ́ ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì. Nítorí náà, ẹnì kan tó jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà lóòótọ́ kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìfẹ́ tó ní sí ara rẹ̀ gbapò kìíní nínú ìgbésí ayé rẹ̀ kó wá fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ohun tó ṣe pàtàkì jù. Ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ náà sì ni ìfẹ́ tó ní sí ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú ìjọsìn rẹ̀ sí Jèhófà Ọlọ́run.

15, 16. (a) Kí ni ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan lè yọrí sí, àpẹẹrẹ ta ló sì fi èyí hàn? (b) Ní ti tòótọ́, kí ni ẹnì kan ń ṣe tó bá ń yára dá àwọn ẹlòmíràn lẹ́jọ́?

15 Ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan lè sọ ẹnì kan di ẹni tó ń ṣe òdodo àṣelékè, èyí sì lè mú kí onítọ̀hún di ẹni tó jẹ́ pé èrò tirẹ̀ nìkan ló máa ń tọ̀nà lójú rẹ̀, kó sì tún jẹ́ ọ̀yájú pẹ̀lú. Bíbélì sọ ọ́ lọ́nà tó bá a mu pé: “Ìwọ kò ní àwíjàre, ìwọ ènìyàn, ẹnì yòówù kí o jẹ́, bí ìwọ bá ń ṣèdájọ́; nítorí nínú ohun tí ìwọ ń ṣèdájọ́ ẹlòmíràn, ìwọ ń dá ara rẹ lẹ́bi, níwọ̀n bí ìwọ tí ń ṣèdájọ́ ti ń fi ohun kan náà ṣe ìwà hù.” (Róòmù 2:1; 14:4, 10) Òdodo àwọn aṣáájú ìsìn ayé ọjọ́ Jésù dá wọn lójú débi tí wọ́n fi rò pé àwọn tóótun láti máa dá Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lẹ́bi. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n sọ ara wọn di adájọ́. Wọn ò kì í rí àṣìṣe ti ara wọn, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ mú ẹ̀bi wá sórí ara wọn.

16 Júdásì, ọmọlẹ́yìn Jésù tó da ọ̀gá rẹ̀ sọ ara rẹ̀ dẹni tó ń dá àwọn ẹlòmíràn lẹ́jọ́. Lákòókò kan tí wọ́n wà ní Bẹ́tánì níbi tí Màríà tó jẹ́ arábìnrin Lásárù ti da òróró onílọ́fínńdà sórí Jésù, ńṣe ni Júdásì gbéjà kó o. Ó fi ìbínú rẹ̀ hàn nípa sísọ pé: “Èé ṣe tí a kò ta òróró onílọ́fínńdà yìí ní ọ̀ọ́dúnrún owó dínárì, kí a sì fi fún àwọn òtòṣì?” Àmọ́, ìròyìn náà fi hàn síwájú sí i pé: “Ó sọ èyí, kì í ṣe nítorí pé ó ń ṣàníyàn nípa àwọn òtòṣì, bí kò ṣe nítorí pé olè ni, àti pé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni àpótí owó wà, a sì máa kó àwọn owó tí a fi sínú rẹ̀ lọ.” (Jòhánù 12:1-6) Ẹ má ṣe jẹ́ ká dà bíi Júdásì tàbí àwọn aṣáájú ìsìn wọ̀nyẹn láé, ìyẹn àwọn tí wọ́n máa ń yára láti dá àwọn ẹlòmíràn lẹ́jọ́ tí wọ́n sì fa ègún sórí ara wọn.

17. Ṣàlàyé ewu tó wà nínú kéèyàn jọ ara rẹ̀ lójú jù tàbí kó dá ara rẹ̀ lójú ju bó ti yẹ lọ.

17 Ó ṣeni láàánú pé àwọn Kristẹni ìjímìjí kan tí wọn kì í ṣe olè bíi ti Júdásì wá di agbéraga, wọ́n sì dẹni tó jọra wọn lójú. Àwọn ní Jákọ́bù kọ̀wé nípa wọn pé: “Ẹ ń yangàn nínú ìfọ́nnu ìjọra-ẹni-lójú yín.” Ó wá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Irú gbogbo ìyangàn bẹ́ẹ̀ burú.” (Jákọ́bù 4:16) Ńṣe là ń para wa láyò tá a bá ń yangàn nítorí àwọn ohun tá a ti gbé ṣe tàbí àwọn àǹfààní tá a ní nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. (Òwe 14:16) A rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí àpọ́sítélì Pétérù tó dára rẹ̀ lójú ju bó ti yẹ lákòókò kan débi tó fi fọ́nnu pé: “Bí a bá tilẹ̀ mú gbogbo àwọn yòókù kọsẹ̀ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú rẹ, dájúdájú, a kì yóò mú èmi kọsẹ̀ láé! . . . Àní bí mo bá ní láti kú pẹ̀lú rẹ pàápàá, dájúdájú, èmi kì yóò sẹ́ níní ìsopọ̀ pẹ̀lú rẹ lọ́nàkọnà.” Ká sóòótọ́, kò sídìí tó fi yẹ ká máa fi ohunkóhun tá a bá ní yangàn. Inú rere tá ò lẹ́tọ̀ọ́ sí látọ̀dọ̀ Jèhófà ló jẹ́ ká ní gbogbo ohun tá a ní. Tá a bá ń rántí èyí, a ò ní máa jọ ara wa lójú jù.—Mátíù 26:33-35, 69-75.

18. Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo ìgbéraga?

18 Bíbélì sọ fún wa pé: “Ìgbéraga ní í ṣáájú ìfọ́yángá, ẹ̀mí ìrera sì ní í ṣáájú ìkọsẹ̀.” Kí nìdí? Jèhófà sọ pé: “Mo kórìíra ìgbéra-ẹni-ga àti ìyangàn.” (Òwe 8:13; 16:18) Abájọ tí Jèhófà fi bínú gan-an nítorí “àfojúdi ti ọkàn-àyà ọba Ásíríà àti nítorí ìkara-ẹni-sí-pàtàkì ti ìgafíofío ojú rẹ̀”! (Aísáyà 10:12) Jèhófà sì fìyà jẹ ẹ́ nítorí ẹ̀mí ìgbéraga tó ní. Láìpẹ́, Jèhófà yóò fìyà jẹ gbogbo ayé Sátánì pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn aṣáájú rẹ̀ tó jẹ́ agbéraga tí wọ́n sì jọ ara wọn lójú, yálà àwọn tó ṣeé fojú rí àtàwọn tí kò ṣeé fojú rí. Ẹ má ṣe jẹ́ ká fara wé ìwà aṣetinú-ẹni táwọn ọ̀tá Jèhófà ń hù láé!

19. Ọ̀nà wo làwọn èèyàn Ọlọ́run gbà ń yangàn, síbẹ̀ tí wọ́n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀?

19 Ohun àmúyangàn ni jíjẹ́ táwọn Kristẹni tòótọ́ jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà. (Jeremáyà 9:24) Síbẹ̀ ó yẹ kí wọ́n ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé “gbogbo ènìyàn ti ṣẹ̀, wọ́n sì ti kùnà láti kúnjú ìwọ̀n ògo Ọlọ́run.” (Róòmù 3:23) Nítorí náà, tá a bá fẹ́ máa jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà títí lọ, a gbọ́dọ̀ ní irú ẹ̀mí tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní, ó sọ pé: “Kristi Jésù wá sí ayé láti gba àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ là.” Ó wá fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Nínú àwọn wọ̀nyí èmi jẹ́ ẹni àkọ́kọ́.”—1 Tímótì 1:15.

20. Báwo ni Jèhófà ṣe ń dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ nísinsìnyí, báwo ló sì ṣe máa dáàbò bò wọ́n lọ́jọ́ iwájú?

20 Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé tayọ̀tayọ̀ làwọn èèyàn Jèhófà fi máa ń rẹ ara wọn sílẹ̀ kí wọ́n lè fi ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣáájú nínú ìgbésí ayé wọn, a lè ní ìdánilójú pé Jèhófà á máa dáàbò bò wọ́n nípa tẹ̀mí títí lọ. A sì tún ní ìdánilójú pé nígbà tí ìpọ́njú ńlá bá dé, Jèhófà yóò pa àwọn èèyàn rẹ̀ mọ́ nípa tẹ̀mí àti nípa tara. Nígbà tí wọ́n bá sì wọnú ayé tuntun ti Ọlọ́run náà tán, wọ́n á láǹfààní láti fi ohùn rara kígbe pé: “Wò ó! Ọlọ́run wa nìyí. Àwa ti ní ìrètí nínú rẹ̀, òun yóò sì gbà wá là. Jèhófà nìyí. Àwa ti ní ìrètí nínú rẹ̀. Ẹ jẹ́ kí a kún fún ìdùnnú kí a sì máa yọ̀ nínú ìgbàlà láti ọ̀dọ̀ rẹ̀.”—Aísáyà 25:9.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Báwo ni Jèhófà ṣe dáàbò bo Dáfídì Ọba àti Jésù Kristi?

• Báwo ni Jèhófà ṣe ń dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ lónìí?

• Kí nìdí tó fi yẹ ká yẹra fún ẹ̀mí ìjọra-ẹni-lójú?

• Kí nìdí tá a fi lè máa yangàn, síbẹ̀ ká jẹ́ onírẹ̀lẹ̀?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Báwo ni Jèhófà ṣe dáàbò bo Dáfídì àti Jésù?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10, 11]

Àwọn ọ̀nà wo ni Ọlọ́run gbà ń dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ nípa tẹ̀mí lónìí?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun àmúyangàn ni iṣẹ́ ìsìn wa sí Jèhófà, síbẹ̀ á gbọ́dọ̀ ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀