Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Nìdí Tí Ayé Ò Fi Ṣọ̀kan?

Kí Nìdí Tí Ayé Ò Fi Ṣọ̀kan?

Kí Nìdí Tí Ayé Ò Fi Ṣọ̀kan?

“Látìgbà Ogun Àgbáyé Kejì, èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ tí àwọn orílẹ̀-èdè tó wà nínú Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè máa ṣọ̀kan. . . . Nítorí náà, gbogbo ayé lè lo àǹfààní yìí láti mú ìlérí sànmánì tuntun tá a ti ṣe tipẹ́tipẹ́ ṣẹ.”

GBÓLÓHÙN yìí ni ààrẹ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà kan sọ ni àwọn ọdún 1990. Ní àkókò yẹn, ó dà bíi pé àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ kárí ayé fi hàn pé ayé kò ní pẹ́ wà níṣọ̀kan. Àwọn ìjọba bóofẹ́bóokọ̀ ti wó lulẹ̀ lọ́kọ̀ọ̀kan. Odi ìlú Berlin ti wó lulẹ̀, èyí sì jẹ́ àmì ìbẹ̀rẹ̀ sànmánì tuntun fún àwọn ará Yúróòpù. Àwọn orílẹ̀-èdè tó wà lábẹ́ ilẹ̀ Rọ́ṣíà tẹ́lẹ̀ ti dá dúró. Wíwà tí wọ́n wà pa pọ̀ tẹ́lẹ̀ làwọn tó wà nílẹ̀ Yúróòpù àti Amẹ́ríkà sì gbà pé ó ń dá wàhálà ayé sílẹ̀. Àmọ́ nígbà tí wọn ò wà pa pọ̀ mọ́, ó ya aráyé lẹ́nu gan-an ni. Ọ̀tẹ̀ Abẹ́lẹ̀ tó wà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè ti dópin. Àwọn ìjọba sì ń sọ̀rọ̀ nípa bí wọ́n ṣe máa dín àwọn ohun ìjà ogun kù, títí kan ohun ìjà runlérùnnà. Lóòótọ́ logun bẹ́ sílẹ̀ nílẹ̀ Kuwait, àmọ́ ńṣe nìyẹn kàn dà bí ìṣòro onígbà kúkúrú tó máa mú kí ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn túbọ̀ máa wá àlàáfíà ayé.

Kì í ṣe nínú agbo ìṣèlú nìkan làwọn èèyàn ti rí àmì pé nǹkan yóò dára, ó tún hàn nínú àwọn nǹkan mìíràn tó ń ṣẹlẹ̀ láyé. Nǹkan túbọ̀ ń ṣẹnuure fáwọn èèyàn lápá ibi púpọ̀ láyé. Ìtẹ̀síwájú nínú ìmọ̀ ìṣègùn ti mú kó ṣeé ṣe fún àwọn dókítà láti ṣe ohun táwọn èèyàn rò pé kò lè ṣeé ṣe ní àwọn ẹ̀wádún díẹ̀ sẹ́yìn. Ọrọ̀ ajé ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ti dára sí i débi tó fi hàn pé nǹkan máa rọ̀ṣọ̀mù kárí ayé. Ó jọ pé àwọn nǹkan ń lọ dáadáa bí aráyé ṣe fẹ́ kó rí.

Àmọ́ lónìí, tí kò tíì ju ọdún díẹ̀ péré lẹ́yìn gbogbo àwọn ìtẹ̀síwájú wọ̀nyí, ìbéèrè tá a wá ń bi ara wa ni pé: ‘Kí ló ń ṣẹlẹ̀? Ibo ni ìṣọ̀kan ayé tí wọ́n ṣèlérí náà wà?’ Kò sí ìṣọ̀kan o, ńṣe ló dà bíi pé ayé ti dorí kọ ibi tí wọn ò fẹ́. Ohun tá à ń gbọ́ nínú ìròyìn nígbà gbogbo ni pé, bọ́ǹbù gbẹ̀mí àwọn èèyàn, àwọn apániláyà kọlu àwọn èèyàn, àwọn ohun ìjà tó lè pa àìmọye èèyàn lẹ́ẹ̀kan náà ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ la sì tún ń gbọ́ àwọn ìròyìn mìíràn tó ń bani lọ́kàn jẹ́. Ó jọ pé irú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ báwọ̀nyí ni kò jẹ́ kí ayé ṣọ̀kan. Gbajúmọ̀ ọkùnrin kan tó jẹ́ onímọ̀ nípa ìnáwó sọ̀rọ̀ lẹ́nu lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí pé: “Ńṣe laráyé ń tinú ìwà ipá kéékèèké bọ́ sínú ìwà ipá ńláńlá.”

Ṣé Ayé Ń Ṣọ̀kan Ni àbí Ayé Ń Pín Yẹ́lẹyẹ̀lẹ?

Nígbà tí wọ́n dá Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sílẹ̀, ọ̀kan lára ìdí tí wọ́n sọ pé àwọn fi dá a sílẹ̀ ni láti “mú kí àjọṣe ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́ wà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè àti pé ẹ̀tọ́ ọgbọọgba àti òmìnira láti yan ìjọba tó wuni ló sì lè mú èyí ṣeé ṣe.” Ǹjẹ́ ọwọ́ wọn ti tẹ ohun rere tó wù wọ́n yìí lẹ́yìn ọgọ́ta ọdún tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀? Rárá o! Kàkà káwọn èèyàn máa wá “àjọṣe ọlọ́rẹ̀ẹ́sọ́rẹ̀ẹ́,” ohun tí wọ́n ń wá ni “òmìnira láti yan ìjọba tó wù wọ́n.” Àwọn èèyàn àti onírúurú ẹ̀yà ń wá ọ̀nà láti fi hàn pé ẹni pàtàkì làwọn náà, wọ́n sì tún ń wá ọ̀nà láti gbé ìjọba ti ara wọn kalẹ̀. Àwọn nǹkan wọ̀nyí ti pín ayé sí yẹ́lẹyẹ̀lẹ gan-an. Nígbà tí wọ́n dá Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sílẹ̀, orílẹ̀-èdè mọ́kànléláàádọ́ta [51] ló wà nínú ẹgbẹ́ náà. Àmọ́ lónìí, orílẹ̀-èdè igba ó dín mẹ́sàn-án [191] ló wà nínú rẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bí a ti rí i, níparí àwọn ọdún 1990, ìrètí pé ayé á ṣọ̀kan ló gbòde kan. Látìgbà náà wá, ìrètí yẹn ti dòfo bí aráyé ti rí i táwọn èèyàn ayé ń pín sí yẹ́lẹyẹ̀lẹ. Ìwà ipá fọ́ orílẹ̀-èdè Yugoslavia sí wẹ́wẹ́, orílẹ̀-èdè Chechnya àti Rọ́ṣíà forí gbárí, ogun wà ní Iraq, ìpakúpa ò sì dáwọ́ dúró ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé. Gbogbo ìwọ̀nyí jẹ́ ẹ̀rí pé ńṣe layé túbọ̀ ń yapa sí i.

Kò sí àní-àní pé tọkàntọkàn làwọn èèyàn fi ń ṣe ọ̀pọ̀ akitiyan tí wọ́n ń ṣe láti mú àlàáfíà wá. Síbẹ̀, ńṣe ló dà bíi pé ìṣọ̀kan ayé ti di ohun tọ́wọ́ kò lè tẹ̀. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ṣe kàyéfì pé: ‘Kí ló fà á tí ayé kò tíì ṣọ̀kan? Ibo ni ayé yìí ń lọ?’

[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

AP Photo/Lionel Cironneau

Arlo K. Abrahamson/AFP/ Getty Images