Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Má Ṣe Juwọ́ Sílẹ̀ Nínú Ṣíṣe Ohun Tó Dára

Má Ṣe Juwọ́ Sílẹ̀ Nínú Ṣíṣe Ohun Tó Dára

Má Ṣe Juwọ́ Sílẹ̀ Nínú Ṣíṣe Ohun Tó Dára

ÀPỌ́SÍTÉLÌ Pétérù gba àwọn Kristẹni níyànjú pé kí wọ́n ‘tọ́jú ìwà wọn kí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè.’ (1 Pétérù 2:12) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n túmọ̀ sí “dára lọ́pọ̀lọpọ̀” dúró fún ohun kan tó “lẹ́wà, tó gbayì, to bójú mu, tàbí tó dára gan-an.” Láyé òde òní, ó lè dà bí ẹni pé ńṣe lèèyàn wulẹ̀ ń fàkókò ṣòfò tó bá ń retí pé káwọn èèyàn lápapọ̀ hùwà tó dára. Àmọ́, àwọn èèyàn Jèhófà lápapọ̀ ń fi ọ̀rọ̀ ìyànjú tí Pétérù sọ yẹn sílò lóde òní. Àní, ibi gbogbo làwọn èèyàn ti mọ̀ wọ́n sí ọmọlúwàbí.

Ìwà wọn yìí jọni lójú gan-an tá a bá wo ìnira àti ìṣòro tá à ń dojú kọ ní “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” yìí. (2 Tímótì 3:1) Ojoojúmọ́ là ń rí àdánwò, ibi gbogbo làwọn èèyàn sì ti ń ta ko ìgbésí ayé Kristẹni tá à ń gbé. Yàtọ̀ síyẹn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn àdánwò kan kì í pẹ́ tí wọ́n fi máa ń yanjú, àwọn kan kì í lọ, kódà, wọ́n á tún máa le sí i ni. Àmọ́, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà wá níyànjú pé kí a má ṣe “juwọ́ sílẹ̀ ní ṣíṣe ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀, nítorí ní àsìkò yíyẹ àwa yóò kárúgbìn bí a kò bá ṣàárẹ̀.” (Gálátíà 6:9) Báwo la ṣe lè máa ṣe ohun tó dára ká sì máa ṣe é nìṣó, bí a tiẹ̀ ń rí àdánwò tó ń bani lọ́kàn jẹ́ táwọn èèyàn sì tún ń kórìíra wa?

Àwọn Ohun Tó Lè Ràn Wá Lọ́wọ́ Láti Máa Ṣe Ohun Tó Dára

Irú ẹni téèyàn jẹ́ gan-an àti bí ọkàn rẹ̀ ṣe rí ló máa ń jẹ́ kéèyàn jẹ́ “ẹni iyì, tó ń ṣe ohun tó bójú mu tàbí ohun tó dára gan-an.” Fún ìdí yìí, híhùwà rere nìṣó nígbà tá a bá wà nínú àdánwò tàbí nínú ìnira kì í ṣohun tó máa ń dédé ṣẹlẹ̀ láìsí ìsapá. Fífi àwọn ìlànà Bíbélì ṣèwàhù lójoojúmọ́ ló lè jẹ́ kí èyí ṣeé ṣe. Kí ni díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀? Gbé àwọn kókó tó wà nísàlẹ̀ yìí yẹ̀ wò.

Máa ní irú èrò tí Kristi ní. Èèyàn gbọ́dọ̀ ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ kó tó lè fara da ohun kan tó dà bí ìwà ìrẹ́nijẹ. Kò dájú pé ẹni tó bá ń ka ara rẹ̀ sí pàtàkì á lè ní ìfaradà tí wọ́n bá ṣe àìdáa sí i. Àmọ́ Jésù “rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀, ó sì di onígbọràn títí dé ikú.” (Fílípì 2:5, 8) Bí a bá ń fara wé e, kò ní ‘rẹ̀ wá bẹ́ẹ̀ la ò ní rẹ̀wẹ̀sì’ nínú iṣẹ́ ìsìn mímọ́ wa. (Hébérù 12:2, 3) Ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ kó o sì máa ṣègbọràn nípa fífọwọ́sowọ́pọ̀ tinútinú pẹ̀lú àwọn tó ń mú ipò iwájú nínú ìjọ rẹ. (Hébérù 13:17) Kọ́ bó o ṣe lè máa ka àwọn ẹlòmíràn sẹ́ni tó “lọ́lá jù” ọ́ lọ, kó o jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wọn máa ká ọ lára ju ti ara rẹ lọ.—Fílípì 2:3, 4.

Máa rántí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ rẹ. Ó gbọ́dọ̀ dá wa lójú pé Jèhófà “ń bẹ àti pé òun ni olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá a.” (Hébérù 11:6) Ó bìkítà nípa wa gan-an ó sì fẹ́ ká ní ìyè ayérayé. (1 Tímótì 2:4; 1 Pétérù 5:7) Tá a bá ń rántí pé kò sóhun tó lè mú kí Ọlọ́run má nífẹ̀ẹ́ wa, èyí kò ní jẹ́ ká jáwọ́ nínú ṣíṣe ohun tó dára nígbà tá a bá wà nínú àdánwò.—Róòmù 8:38, 39.

Gbọ́kàn lé Jèhófà pátápátá. Ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà ṣe pàtàkì gan-an, àgàgà tó bá dà bíi pé àdánwò wa kò lópin tàbí tó dà bíi pé ó fẹ́ gbẹ̀mí wa. A gbọ́dọ̀ gbọ́kàn lé Jèhófà pátápátá pé kò ní jẹ́ kí ìdánwò èyíkéyìí le ‘kọjá ohun tá a lè mú mọ́ra,’ àti pé yóò máa ṣe “ọ̀nà àbájáde” fún wa nígbà gbogbo. (1 Kọ́ríńtì 10:13) Bá a bá gbọ́kàn wa lé Jèhófà pátápátá, kódà a lè fìgboyà dojú kọ àwọn tó bá fi ikú halẹ̀ mọ́ wa.—2 Kọ́ríńtì 1:8, 9.

Máa gbàdúrà láìdabọ̀. Àdúrà àtọkànwá ṣe pàtàkì. (Róòmù 12:12) Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tí à ń gbà sún mọ́ Jèhófà jẹ́ nípasẹ̀ àdúrà àtọkànwá. (Jákọ́bù 4:8) Àwọn ohun tójú àwa fúnra wa ti rí ti jẹ́ ká mọ̀ pé “ohun yòówù tí ì báà jẹ́ tí a bá béèrè . . . , ó ń gbọ́ tiwa.” (1 Jòhánù 5:14) Bí Jèhófà bá yọ̀ǹda kí ìṣòro tá a ní máa bá a nìṣó tí èyí sì ń dán ìwà títọ́ wa wò, ńṣe ni ká máa gbàdúrà pé kó ràn wá lọ́wọ́ ká lè fara dà á. (Lúùkù 22:41-43) Ẹ̀kọ́ kan tí àdúrà ń kọ́ wa ni pé, a kò dá nìkan wà, pé níwọ̀n ìgbà tí Jèhófà bá wà pẹ̀lú wa, a óò máa ṣẹ́gun nígbà gbogbo.—Róòmù 8:31, 37.

Iṣẹ́ Àtàtà Ń Mú ‘Ìyìn àti Ọlá’ Wá

“Onírúurú àdánwò” máa ń “kó ẹ̀dùn-ọkàn” bá àwa Kristẹni látìgbàdégbà. Síbẹ̀, a ò gbọ́dọ̀ “juwọ́ sílẹ̀ ní ṣíṣe ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀.” Nígbà tó o bá ń ní ìdààmú ọkàn, jẹ́ kí ìmọ̀ tó o ní pé ìṣòtítọ́ rẹ yóò mú “ìyìn àti ògo àti ọlá” wá níkẹyìn máa fún ọ lágbára. (1 Pétérù 1:6, 7) Máa lo gbogbo àwọn ohun tí Jèhófà pèsè láti fún ìgbàgbọ́ rẹ lókun. Tó o bá nílò ìrànlọ́wọ́, àwọn tó jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn, olùkọ́, àti agbaninímọ̀ràn nínú ìjọ Kristẹni ni kó o tọ̀ lọ. (Ìṣe 20:28) Máa lọ sí gbogbo ìpàdé ìjọ déédéé, èyí tó ń ‘ru wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà.’ (Hébérù 10:24) Kíka Bíbélì lójoojúmọ́ àti dídákẹ́kọ̀ọ́ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti wà lójúfò, á sì jẹ́ kó o lágbára nípa tẹ̀mí, bákan náà ni lílọ́wọ́ nínú ìṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni déédéé yóò tún ràn ọ́ lọ́wọ́.—Sáàmù 1:1-3; Mátíù 24:14.

Bó o bá ṣe túbọ̀ ń rí ọ̀wọ́ ìfẹ́ Jèhófà àti ìtọ́jú rẹ̀ nínú ìgbésí ayé rẹ, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ ọkàn rẹ láti jẹ́ “onítara fún iṣẹ́ àtàtà” yóò máa pọ̀ sí i. (Títù 2:14) Rántí pé “ẹni tí ó bá fara dà á dé òpin ni ẹni tí a ó gbà là.” (Mátíù 24:13) Bẹ́ẹ̀ ni o, àní pinnu pé o ò ní “juwọ́ sílẹ̀ ní ṣíṣe ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀”!

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 29]

A gbọ́dọ̀ gbọ́kàn lé Jèhófà pátápátá pé kò ní jẹ́ kí ìdánwò èyíkéyìí le ‘kọjá ohun tá a lè mú mọ́ra,’ àti pé yóò máa ṣe “ọ̀nà àbájáde” fún wa nígbà gbogbo

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Jíjẹ́ kọ́wọ́ wa dí nínú àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí lè jẹ́ ká wà ní ìmúrasílẹ̀ láti fara da àdánwò