Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Mo Gbádùn ‘Ìgbésí Ayé Ìsinsìnyí’ Dé Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́!

Mo Gbádùn ‘Ìgbésí Ayé Ìsinsìnyí’ Dé Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́!

Ìtàn Ìgbésí Ayé

Mo Gbádùn ‘Ìgbésí Ayé Ìsinsìnyí’ Dé Ẹ̀kúnrẹ́rẹ́!

GẸ́GẸ́ BÍ TED BUCKINGHAM ṢE SỌ Ọ́

Ó ṣẹ̀ṣẹ̀ pé ọdún mẹ́fà tí mo di òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ni, kò sì tíì ju oṣù mẹ́fà tí mo ṣègbéyàwó, nígbà tí àrùn rọpárọsẹ̀ ṣàdédé kọ lù mí. Ọdún 1950 lèyí ṣẹlẹ̀, ńṣe ni mo sì ṣẹ̀ṣẹ̀ pé ọmọ ọdún mẹ́rìnlélógún nígbà náà. Oṣù mẹ́sàn-án ni mo fi wà nílé ìwòsàn, èyí sì fún mi láǹfààní láti ronú jinlẹ̀ nípa ìgbésí ayé mi. Ní báyìí ti mo ti wá di aláàbọ̀ ara, báwo lọjọ́ iwájú èmi àti ìyàwó mi, Joyce, ṣe máa rí?

BÀBÁ mi jẹ́ ẹnì kan tí kò nífẹ̀ẹ́ sí ìsìn, àmọ́ ó gba ìwé kan tí wọ́n ń pè ní Government lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí lọ́dún 1938. a Àfàìmọ̀ kó má jẹ́ rògbòdìyàn ọ̀rọ̀ ìṣèlú àti bó ṣe jọ pé ogun fẹ́ bẹ́ sílẹ̀ ló mú un gba ìwé náà. Mo mọ̀ pé kò kà á, àmọ́ màmá mi tí kò fi ọ̀rọ̀ ìsìn ṣeré ka ìwé náà. Kíá ló sì ṣiṣẹ́ lórí ohun tó kà nínú rẹ̀. Màmá mi kúrò nínú ìjọ Áńgílíkà ó sì di Ẹlẹ́rìí olóòótọ́ fún Jèhófà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé bàbá mi ṣàtakò sí i, síbẹ̀ kò fi Jèhófà sílẹ̀ títí tó fi kú lọ́dún 1990.

Gbọ̀ngàn Ìjọba kan wà nílùú Epsom lápá gúúsù ìlú London táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti máa ń ṣèpàdé. Ibẹ̀ sì ni ìpàdé àkọ́kọ́ tí màmá mi mú mi lọ. Inú ibì kan tó jẹ́ ṣọ́ọ̀bù tẹ́lẹ̀ ni ìjọ náà ti ń ṣèpàdé, a sì tẹ́tí sí àsọyé arákùnrin J. F. Rutherford tí wọ́n gbà sílẹ̀. Òun ló ń bójú tó iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn. Àsọyé náà wọ̀ mí lọ́kàn ṣinṣin.

Inú ewu ńlá la wà nítorí pé wọ́n ń rọ̀jò bọ́ǹbù sórí ìlú London lákòókò náà. Nítorí náà, lọ́dún 1940, bàbá mi kó ìdílé wa lọ síbì kan tí ààbò wà díẹ̀, ìyẹn ìlú kékeré kan tó ń jẹ́ Maidenhead tó wà ní nǹkan bíi kìlómítà márùnlélógójì sílùú London. Èyí ṣàǹfààní gan-an, nítorí pé àwọn ọgbọ̀n arákùnrin àti arábìnrin tó wà nínú ìjọ tó wà níbẹ̀ fún wa níṣìírí gan-an. Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Fred Smith, ẹni tó ṣèrìbọmi lọ́dún 1917 tó sì jẹ́ àràbà nípa tẹ̀mí fẹ́ràn mi gan-an, ó sì kọ́ mi láti dẹni tó túbọ̀ jáfáfá nínú iṣẹ́ ìwàásù. Títí dòní ni mo ṣì ń mọrírì àpẹẹrẹ rẹ̀ àti bó ṣe fìfẹ́ ràn mí lọ́wọ́.

Mo Bẹ̀rẹ̀ Iṣẹ́ Ìsìn Alákòókò Kíkún

Lọ́dún 1941, nígbà tí mo jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, mo ṣèrìbọmi nínú odò Thames ní oṣù March lọ́jọ́ kan tí òtútù mú gan-an. Nígbà yẹn, ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin tó ń jẹ́ Jim ti fọwọ́ síwèé láti di oníwàásù alákòókò kíkún. Ìlú Birmingham lòun àti Madge ìyàwó rẹ̀ ń gbé báyìí, lẹ́yìn tí wọ́n ti fi gbogbo ìgbésí ayé wọn ṣiṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Wọ́n ṣe iṣẹ́ alábòójútó àyíká àti agbègbè jákèjádò ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Àbúrò mi obìnrin tó ń jẹ́ Robina àti Frank ọkọ̀ rẹ̀ náà ṣì ń sin Jèhófà tọkàntọkàn títí dòní.

Mo ń ṣiṣẹ́ olùṣirò owó nílé iṣẹ́ kan tí wọ́n ti ń rán aṣọ. Lọ́jọ́ kan, ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ náà pè mí sínú ọ́fíìsì rẹ̀, ló bá sọ fún mi pé kí n lọ máa ra ọjà wá fún ilé iṣẹ́ náà, iṣẹ́ yìí sì jẹ́ iṣẹ́ tí yóò máa mówó wọlé fún mi gan-an. Àmọ́, ṣáájú àkókò yẹn, mo ti ń ronú láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ẹ̀gbọ́n mi, ni mo bá sọ fún ọ̀gá mi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ pé mi ò ní lè ṣe iṣẹ́ náà mo sì sọ ìdí rẹ̀ fún un. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fún mi pé ńṣe ló yìn mí pé mo fẹ́ lọ máa ṣe irú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni tó lérè nínú bẹ́ẹ̀. Nítorí náà, lẹ́yìn ìpàdé àgbègbè kan tá a ṣe nílùú Northampton lọ́dún 1944, mo di ajíhìnrere alákòókò kíkún.

Ìlú Exeter ní ìpínlẹ̀ Devon ni ibi àkọ́kọ́ tí wọ́n yàn fún mi láti lọ máa wàásù. Lákòókò náà, ńṣe ni ìlú yìí ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bọ̀ sípò díẹ̀díẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti rọ̀jò bọ́ǹbù sórí rẹ̀ nígbà ogun. Ilé táwọn aṣáájú ọ̀nà méjì kan, Frank àti Ruth Middleton ń gbé lèmi náà ń gbé, wọ́n sì ṣe dáadáa sí mí gan-an. Ọmọ ọdún méjìdínlógún péré ni mí, mi ò sì fi bẹ́ẹ̀ mọ̀ nípa aṣọ fífọ̀ àti béèyàn ṣe ń se oúnjẹ, àmọ́ ìyàtọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í dé bí mo ṣe ń kọ́ bí wọ́n ṣe ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí.

Victor Gurd tó jẹ́ ẹni àádọ́ta ọdún lẹnì kejì mi tá a jọ ń wàásù. Ọmọ ilẹ̀ Ireland ni, àtọdún 1920 ló sì ti ń wàásù. Ó kọ́ mi bí màá ṣe máa ṣètò àkókò mi lọ́nà tó máa ṣe mí láǹfààní. Ó tún kọ́ mi láti túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì kíkà gan-an, bẹ́ẹ̀ ló sì tún jẹ́ kí n mọ àǹfààní tó wà nínú lílo onírúurú ẹ̀dà Bíbélì. Láwọn ọdún tí mi ò tíì nírìírí wọ̀nyẹn, àpẹẹrẹ jíjẹ́ tí Victor jẹ́ adúróṣinṣin ràn mí lọ́wọ́ gan-an.

Àìlọ́wọ́ sí Ogun Dá Ìṣòro Sílẹ̀

Ogun tó ń jà lọ́wọ́ nígbà yẹn ti ń parí lọ, àmọ́ àwọn aláṣẹ ṣì ń kó àwọn ọ̀dọ́ dà sẹ́nu iṣẹ́ ológun. Mo ti kọ́kọ́ lọ jẹ́jọ́ nílé ẹjọ́ kan nílùú Maidenhead lọ́dún 1943. Níbẹ̀ ni mo ti ṣàlàyé yékéyéké pé kò yẹ kí n lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ológun nítorí òjíṣẹ́ Ìhìnrere ni mi. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò gba ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí mo pè, mo pinnu láti lọ sílùú Exeter kí n lè máa bá iṣẹ́ ìsìn mi lọ níbẹ̀. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé ìlú Exeter yìí ni wọ́n ti wá pàṣẹ fún mi pé kí n lọ fara hàn níwájú ilé ẹjọ́ tó wà níbẹ̀. Lẹ́yìn tí adájọ́ náà ti dá ẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́fà pẹ̀lú iṣẹ́ àṣekára fún mi, ó sọ fún mi pé ó dun òun pé ẹ̀wọ̀n náà kò lè jù bẹ́ẹ̀ lọ. Lẹ́yìn tí mo ṣẹ̀wọ̀n oṣù mẹ́fà yẹn tán, wọ́n tún dá mi padà pé kí n lọ ṣe oṣù mẹ́rin mìíràn sí i.

Nítorí pé èmi nìkan ni Ẹlẹ́rìí tó wà nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n náà, Jèhófà làwọn wọ́dà tó wà níbẹ̀ máa ń pè mí. Kì í rọrùn fún mi láti dáhùn nígbà tí wọ́n bá ń fi orúkọ yẹn pè mí níbi tí wọ́n ti ń pe orúkọ wa. Àmọ́ àǹfààní ńlá ló jẹ́ láti máa gbọ́ bí wọ́n ti ń polongo orúkọ Ọlọ́run lójoojúmọ́! Ó jẹ́ káwọn ẹlẹ́wọ̀n yòókù mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí mo jẹ́ tí ẹ̀rí ọkàn mi ò sì gbà mí láyè láti jagun ló jẹ́ kí n wà láàárín wọn. Nígbà tó wá yá, wọ́n mú arákùnrin Norman Castro wá sí ọ̀gbà ẹ̀wọ̀n yìí wọ́n sì yí orúkọ tí wọ́n ń pè mí yẹn padà. Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí pè wá ní Mósè àti Áárónì.

Wọ́n gbé mi kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n ìlú Exerter lọ sí ti ìlú Bristol, lẹ́yìn náà ni wọ́n tún gbé mi lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n ìlú Winchester. Nǹkan máa ń nira gan-an nígbà míì, àmọ́ jíjẹ́ ẹni tó máa ń ṣàwàdà ràn mí lọ́wọ́. Inú èmi àti Norman dùn pé a lè jọ ṣe Ìrántí Ikú Jésù pa pọ̀ nígbà tá a wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Winchester. Arákùnrin Francis Cooke tó wá bẹ̀ wá wò nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n náà ló sì sọ àsọyé alárinrin lórí Ìrántí Ikú Jésù náà.

Àwọn Ìyípadà tó Ṣẹlẹ̀ Lẹ́yìn Ogun

Ìpàdé àgbègbè kan tá a ṣe nílùú Bristol lọ́dún 1946, níbi tí wọ́n ti mú ìwé “Jẹki Ọlọrun Jẹ Olõtọ” jáde ni mo ti pàdé arẹwà ọmọge kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Joyce Moore, òun náà ń ṣe aṣáájú ọ̀nà ní ìpínlẹ̀ Devon nígbà yẹn. A wá mọ́wọ́ ara wá gan-an, ọdún mẹ́rin lẹ́yìn náà la sì ṣègbéyàwó nílùú Tiverton, níbi tí mo ti ń gbé látọdún 1947. Inú yàrá kan tá a rẹ́ǹtì tá a sì ń san ṣílè mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lọ́sẹ̀ là ń gbé. Ìgbésí ayé wa dùn bí oyin!

Láàárín ọdún àkọ́kọ́ tá a ṣègbéyàwó, a ṣí lọ sápá gúúsù ìlú Brixham tó jẹ́ etíkun ẹlẹ́wà, níbi tí wọ́n ti kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọ̀n fẹ̀rẹ̀gẹ̀dẹ̀ tí wọ́n máa ń so mọ́ ẹ̀yìn ọkọ̀ ojú omi ńlá pẹja. Àmọ́ kò pẹ́ rárá tá a débẹ̀ ni àrùn rọpárọsẹ̀ kọ lù mí nígbà táà ń lọ sí ìpàdé àgbègbè kan nílùú London. Mó dákú lọ gbári. Lẹ́yìn oṣù mẹ́sàn-án ni wọ́n tó dá mi sílẹ̀ nílé ìwòsàn gẹ́gẹ́ bí mo ṣe sọ níbẹ̀rẹ̀. Àrùn náà ṣàkóbá ńlá fún ọwọ́ mi ọ̀tún àti ẹsẹ̀ mi méjèèjì, wọn ò sì padà sí bí wọ́n ṣe wà tẹ́lẹ̀ títí dòní. Igi ni mo fi ń rìn. Aya mi ọ̀wọ́n ló máa ń dá mi lára yá nígbà gbogbo tó sì máa ń fún mi níṣìírí, pàápàá jù lọ bó ṣe ń sapá láti máa bá iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà lọ. Àmọ́ kí la ó wá ṣe báyìí? Kò pẹ́ tí mo fi rí i pé ọwọ́ Jèhófà kò kúrú rárá láti gbani.

Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, a lọ ṣèpàdé àyíká kan ní Wimbledon nílùú London. Lásìkò yẹn, mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í rìn láìlo igi. Ibẹ̀ la ti pàdé arákùnrin Pryce Hughes, tó ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nígbà náà. Bó ṣe rí mi báyìí ló kí mi tó sì sọ pé: “Àwé wá o! A fẹ́ kó o wá lọ máa ṣe iṣẹ́ alábòójútó àyíká!” Mi ò tíì gbọ́ ohun tó fún mi níṣìírí tó bẹ́ẹ̀ rí! Àmọ́ ṣé màá lè ṣe iṣẹ́ náà? Èyí kò dá èmi àti Joyce lójú. Ṣùgbọ́n lẹ́yìn tí wọ́n fún mi ní ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ọ̀sẹ̀ kan tá a sì fi gbogbo ọkàn wa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, bá a ṣe gbéra padà sí gúúsù ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nìyẹn, níbi tí wọ́n yàn mí sí láti lọ máa ṣe iṣẹ́ alábòójútó àyíká. Ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n péré ni mí nígbà náà, àmọ́ mi ò lè gbàgbé bí àwọn Ẹlẹ́rìí wọ̀nyẹn ṣe ràn mí lọ́wọ́ gan-an, tí wọ́n fi inú rere hàn sí mi, tí wọ́n sì fi sùúrù bá mi lò.

Nínú gbogbo onírúurú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún tá a ti ṣe, èmi àti Joyce rí i pé bíbẹ àwọn ìjọ wò mú wa sún mọ́ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa nípa tẹ̀mí gan-an. A ò ní mọ́tò, nítorí náà ọkọ̀ ojú irin tàbí bọ́ọ̀sì la máa ń wọ̀ bá a ti ń ti ìjọ kan dé òmíràn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ṣì ń bá ohun tí àìsàn yẹn sọ mí dà yí, síbẹ̀ a gbádùn àǹfààní tí kò lẹ́gbẹ́ yìí títí di ọdún 1957. Ìgbésí ayé tó lárinrin gbáà ni, àmọ́ láàárín ọdún yìí ni ohun mìíràn tún yọjú.

A Bára Wa Nínú Iṣẹ́ Míṣọ́nnárì

Ìdùnnú ṣubú layọ̀ fún wa nígbà tí wọ́n ké sí wa pé ká wá sí kíláàsì ọgbọ̀n ní ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláàbọ̀ ara ni mí, mo ti lè ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan, nítorí náà tayọ̀tayọ̀ lèmi àti Joyce fi tẹ́wọ́ gba ìpè náà. Látinú àwọn ohun tá a tirí, a mọ̀ pé Jèhófà máa ń fúnni lókun téèyàn bá fẹ́ ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Kíákíá ni oṣù márùn-ún tá a fi kẹ́kọ̀ọ́ kárakára ní Ilé Ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead kọjá lọ, èyí tó wáyé ní South Lansing, nílùú New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Tọkọtaya ni gbogbo àwa akẹ́kọ̀ọ́ náà, alábòójútó arìnrìn-àjò sì ni wá. Nígbà tí wọ́n béèrè lọ́wọ́ àwa ọmọ kíláàsì náà pé àwọn wo ni yóò fẹ́ láti yọ̀ọ̀da ara wọn láti lọ ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì nílẹ̀ òkèèrè, a wà lára àwọn tó yọ̀ọ̀da ara wọn lójú ẹsẹ̀. Ibo la máa lọ? Orílẹ̀-èdè Uganda ni, ní Ìlà Oòrùn Áfíríkà!

Nítorí pé wọ́n fòfin de iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Uganda lákòókò náà, wọ́n ní kí n kàn máa gbé lórílẹ̀-èdè yẹn kí n sì wá iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ kan tí màá máa ṣe. Lẹ́yìn tá a ti rìnrìn àjò ọ̀nà jíjìn gan-an nínú ọkọ̀ ojú irin àti ọkọ̀ ojú omi, a gúnlẹ̀ sílùú Kampala, lórílẹ̀-èdè Uganda. Inú àwọn òṣìṣẹ́ tó ń rí sí ọ̀rọ̀ àwọn tó ń wọ̀lú kò dùn rárá bí wọ́n ṣe rí wa, ìwọ̀nba oṣù díẹ̀ ni wọ́n sì fi jẹ́ ká dúró. Lẹ́yìn náà, wọ́n pàṣẹ fún wa pé ká fi orílẹ̀-èdè náà sílẹ̀. Wọ́n wá sọ fún wa láti orílé iṣẹ́ wa pé ká máa lọ sí Northern Rhodesia, (tó ti di Zambia báyìí), a sì ṣe bẹ́ẹ̀. Inú wa dùn gan-an nígbà tá a débẹ̀ tá a sì rí mẹ́rin lára àwọn tá a jọ lọ sílé ẹ̀kọ́ Gílíádì, ìyẹn tọkọtaya Frank àti Carrie Lewis àti tọkọtaya Hayes àti Harriet Hoskins. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni wọ́n tún ní ká máa lọ sí Southern Rhodesia (tó ti di Zimbabwe báyìí).

Ọkọ̀ ojú irin la wọ̀ débẹ̀. Bá a ti ń kọjá lọ, a rí ọ̀yamùúmùú omi tí wọ́n ń pè ní Victoria Falls tó ń tàkìtì sílẹ̀ látòkè, èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ tá a máa rí i. Ẹ̀yin ìyẹn la wá lọ gúnlẹ̀ sí ìlú Bulawayo. Ọ̀dọ̀ ìdílé Mcluckie la kọ́kọ́ wà fúngbà díẹ̀. Wọ́n wà lára àwọn Ẹlẹ́rìí tó kọ́kọ́ fìdí kalẹ̀ sí orílẹ̀-èdè náà. Inú wa dùn gan-an pé a láǹfààní láti mọ̀ wọ́n, ọdún mẹ́rìndínlógún tá a lò ní ìlú yẹn sì jẹ́ ká túbọ̀ mọ̀ wọ́n dáadáa.

Àwọn Nǹkan Ń Yí Padà

Lẹ́yìn tí mo ti gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún ọ̀sẹ̀ méjì kí n lè mọ̀ nípa bí iṣẹ́ ìwàásù ṣe rí nílẹ̀ Áfíríkà, wọ́n ní kí n lọ máa ṣe iṣẹ́ alábòójútó àgbègbè. Bá a ti ń wàásù nínú igbó ilẹ̀ Áfíríkà yìí, a ní láti máa gbé omi, oúnjẹ, aṣọ tá a máa tẹ́ sórí ibùsùn, àwọn aṣọ wa, ẹ̀rọ agbáwòrányọ, ẹ̀rọ amúnáwá àti aṣọ ńlá táà ń lò fún sinimá dání, àtàwọn nǹkan mìíràn tá a nílò. Inú ọkọ akẹ́rù kan tó lágbára láti rin àwọn ọ̀nà gbágungbàgun tá a máa ń gbà là ń kó gbogbo àwọn ẹrù wọ̀nyí sí.

Mo máa ń bá àwọn alábòójútó àyíká tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà ṣiṣẹ́, tayọ̀tayọ̀ sì ni Joyce fi máa ń ran àwọn ìyàwó àtàwọn ọmọ wọn lọ́wọ́. Ó máa ń rẹ̀ẹ̀yàn gan-an béèyàn ti ń rìn nínú àwọn pápá tó ní àwọn igi káàkiri nílẹ̀ Áfíríkà, àgàgà nígbà tí oòrùn bá mú gan-an lọ́sàn-án. Àmọ́ mo wá rí i pé bójú ọjọ́ ṣe rí lágbègbè yìí jẹ́ kó túbọ̀ rọrùn fún mi láti bá ìṣòro jíjẹ́ tí mo jẹ́ aláàbọ̀ ara yí, mo sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún èyí.

Àwọn èèyàn kò lówó lọ́wọ́ lágbègbè yìí. Ọ̀pọ̀ wọn ló nígbàgbọ́ gan-an nínú àṣà àbáláyé àti oríṣiríṣi èèwọ̀ tí wọ́n sì máa ń ní ju ìyàwó kan lọ, síbẹ̀ wọ́n gbà pé òótọ́ pọ́ńbélé lohun tó wà nínú Bíbélì. Láwọn àgbègbè kan, abẹ́ igi ńlá tó ní ibòji làwọn arákùnrin àti arábìnrin wa ti máa ń ṣèpàdé. Tílẹ̀ bá sì ṣú, àtùpà elépo tí wọ́n gbé kọ́ làwọn èèyàn fi máa ń ríran. Gbogbo ìgbà tá a bá jókòó síta tá à ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tá a sì ń wo àwọn ìràwọ̀ tó wà lójú ọ̀run ni iṣẹ́ ọwọ́ Jèhófà yìí máa ń jọ wá lójú.

Ohun mìíràn tá ò tún lè gbàgbé lohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà tá a bá ń fi àwọn fíìmù Watch Tower Society hàn láwọn eréko ilẹ̀ Áfíríkà. Àwọn tó wà nínú ìjọ kan lè má ju ọgbọ̀n lọ o, àmọ́ láwọn ìgbà tá a bá ń fi fíìmù yìí hàn, a mọ̀ pé a máa rí àwọn èèyàn tó tó ẹgbẹ̀rún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tó máa wá!

Òótọ́ ni pé nílẹ̀ olóoru, kò sọ́gbọ́n kéèyàn má máa ṣàìsàn nígbà kọ̀ọ̀kan. Àmọ́, ó ṣe pàtàkì láti má ṣe jẹ́ kí èyí máa kó ìrònú báni ní gbogbo ìgbà tó bá wáyé. Èmi àti Joyce kọ́ bá a ṣe lè bá àwọn àìsàn tó máa ń ṣe wá yí. Mi ò kì í jẹ́ kí àìsàn ibà tó máa ń ṣe mí lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan dá mi gúnlẹ̀, Joyce náà ò sì jẹ́ kí àìsàn kan tí kòkòrò inú omi máa ń fà ṣèdíwọ́ fún iṣẹ́ ìsìn rẹ̀.

Nígbà tó yá, wọ́n ní ká lọ máa ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa nílùú Salisbury, (tó ti di Harare báyìí). Ibẹ̀ la ti láǹfààní láti bá àwọn mìíràn tí wọ́n jẹ́ ìránṣẹ́ tòótọ́ fún Jèhófà ṣiṣẹ́ pa pọ̀. Lára wọn ni Lester Davey àti tọkọtaya George àti Ruby Bradley. Ìjọba yàn mí láti máa fún àwọn Ẹlẹ́rìí ní ìwé àṣẹ ìgbéyàwó, èyí tó jẹ́ kó ṣeé ṣe fún mi láti máa darí ètò ìgbéyàwó àwọn arákùnrin tí wọ́n jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà, èyí sì mú kí ìdè ìgbéyàwó àwọn Kristẹni túbọ̀ lágbára sí i nínú àwọn ìjọ. Lọ́dún díẹ̀ lẹ́yìn náà, àǹfààní mìíràn tún yọjú fún mi. Wọ́n ní kí n lọ máa bẹ gbogbo ìjọ tí kì í sọ àwọn èdè tí àwọn Bantu ń sọ wò, irú bí àwọn ìjọ tó ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì. Ó lé lọ́dún mẹ́wàá témi àti Joyce fi láǹfààní láti mọ àwọn arákùnrin wa bá a ti ń bá iṣẹ́ arìnrìn-àjò yìí lọ, inú wa sì dùn bá a ti ń rí i tí wọ́n ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Lákòókò yẹn náà, a tún ń bẹ àwọn arákùnrin wa wò lórílẹ̀-èdè Botswana àti Mòsáńbíìkì.

Wọ́n Tún Gbé Wa Lọ Síbòmíràn

Lẹ́yìn tá a ti lo ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọdún lápá gúúsù Áfíríkà, èyí tá a gbádùn gan-an, wọ́n tún gbé wa lọ sí orílẹ̀-èdè Sierra Leone, ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà. Kò pẹ́ kò jìnnà tá a dé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì náà láti bẹ̀rẹ̀ sí í gbádùn ẹ̀ka iṣẹ́ ìsìn wa tuntun ni nǹkan yí padà, tọ́rọ̀ ò rí bá a ṣe rò ó mọ́. Àìsàn ibà ńlá dá mi gúnlẹ̀ mi ò sì lókun nínú mọ́. Mo ní láti lọ sílùú London láti lọ gbàtọ́jú, níbẹ̀ ni wọ́n sì ti sọ fún mi pé kí n má ṣe padà sílẹ̀ Áfíríkà mọ́. Èyí dùn wá gan-an, àmọ́ tayọ̀tayọ̀ ni ìdílé Bẹ́tẹ́lì ní London fi tẹ́wọ́ gba èmi àti Joyce. Ọ̀pọ̀ àwọn arákunrin tí wọ́n jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà nínú àwọn ìjọ tó wà ní London kò jẹ́ ká fi bẹ́ẹ̀ màlá pé a kúrò ní Áfíríkà. Bí ara mi ṣe ń yá sí i, ìgbésí ayé Bẹ́tẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí mọ́ wa lára, Ẹ̀ka Ìrajà ni wọ́n sì ní kí n máa bójú tó. Mo gbádùn iṣẹ́ yìí gan-an, pàápàá pẹ̀lú bá a ṣe ń mú ẹ̀ka náà gbòòrò sí i láwọn ọdún tó tẹ̀ lé e.

Níbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1990, àìsàn líle kan kọ lu Joyce olólùfẹ́ mi ọ̀wọ́n, èyí tí kò jẹ́ kó lè rìn mọ́, ó sì kú lọ́dún 1994. Aya tó ṣeé fọkàn tán, tó nífẹ̀ẹ́, tó sì jẹ́ adúrótini lọ́jọ́ ìṣòro ni. Ó máa ń múra tán láti fara da oríṣiríṣi ipò tá a bára wa. Láti lè kojú àdánù ńlá bí irú èyí, mo ti rí i pé ó ṣe pàtàkì láti máa fojú tẹ̀mí wo àwọn nǹkan kí n sì máa retí àwọn ohun tí Ọlọ́run ń mú bọ̀ lọ́jọ́ iwájú. Bákan náà, gbígbàdúrà sí Jèhófà pé kí n má ṣe jáwọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí, títí kan iṣẹ́ ìwàásù, ń ràn mí lọ́wọ́. Èyí kì í sì í jẹ́ kí n ro ìròkurò.—Òwe 3:5, 6.

Àǹfààní ńlá ló jẹ́ láti sìn ní Bẹ́tẹ́lì, ìgbésí ayé tó dára gan-an sì ni. Ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ la jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀, ọ̀pọ̀ nǹkan ló sì máa ń fún wa láyọ̀. Ọ̀kan lára àwọn ìbùkún tá à ń gbádùn ni ti ọ̀pọ̀ àlejò tá a máa ń gbà ní Bẹ́tẹ́lì ti London níbí. Nígbà míì, mo máa ń rí àwọn ọ̀rẹ́ ọ̀wọ́n tí wọ́n wá láti àwọn ibi tí mo ti sìn nílẹ̀ Áfíríkà. Èyí máa ń jẹ́ kí n rántí àwọn àkókò yẹn ó sì máa ń fún mi láyọ̀. Gbogbo ìwọ̀nyí ló ń jẹ́ kí n lè máa gbádùn ‘ìgbésí ayé ti ìsinsìnyí’ nìṣó, ó sì ń fi mí lọ́kàn balẹ̀ láti máa retí “èyí tí ń bọ̀.”—1 Tímótì 4:8.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ọdún 1928 làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ ìwé yìí jáde, àmọ́ a ò tẹ̀ ẹ́ mọ́ báyìí.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Èmi àti màmá mi nìyí lọ́dún 1946

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Èmi àti Joyce lọ́jọ́ ìgbéyàwó wa lọ́dún 1950

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

A wà ní ìpàdé àgbègbè kan nílùú Bristol lọ́dún 1953

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Òkè: à ń bẹ àwùjọ àdádó kan wò. Apá òsì: à ń bẹ ìjọ kan wò ní Southern Rhodesia tó ti di Zimbabwe báyìí