Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Ìwọ àti Ìdílé Rẹ Máa Ń Jùmọ̀ Sọ̀rọ̀?

Ǹjẹ́ Ìwọ àti Ìdílé Rẹ Máa Ń Jùmọ̀ Sọ̀rọ̀?

Ǹjẹ́ Ìwọ àti Ìdílé Rẹ Máa Ń Jùmọ̀ Sọ̀rọ̀?

ÌWÉ ìròyìn kan tó ń jẹ́ Polityka, tó máa ń jáde lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ nílẹ̀ Poland sọ pé: “Àwa àtàwọn ìdílé wa kì í jọ sọ̀rọ̀ tó bó ṣe yẹ mọ́.” Ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà wọ́n fojú bù ú pé ìṣẹ́jú mẹ́fà péré làwọn tọkọtaya ń lò lóòjọ́ láti fi bá ara wọn sọ ọ̀rọ̀ tó mọ́yán lórí. Àwọn ògbógi kan sọ pé ìdajì gbogbo àwọn tọkọtaya tó ti pínyà àtàwọn to ti kọra wọn sílẹ̀ ni ìṣòro wọn dá lórí pé wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ bá ara wọn sọ̀rọ̀.

Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ láàárín àwọn òbí àtàwọn ọmọ ńkọ́? Ìwé ìròyìn yẹn sọ pé, “ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé ohun táwọn èèyàn pè ní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ ti kúrò ní ká fèrò wérò, ó ti di kìkì ìbéèrè lásán, irú bíi: Kí ló ṣẹlẹ̀ nílé ìwé lónìí? Àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ńkọ́?” Ìwé ìròyìn náà wá béèrè pé lójú ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí, “Báwo làwọn ọmọ wa ṣe máa kọ́ béèyàn ṣe ń ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn?”

Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé bíbá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lọ́nà tó dára kì í ṣàdédé ṣẹlẹ̀ láìsí ìsapá kankan, báwo la ṣe lè mú kí ọ̀nà tá a gbà ń bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ sunwọ̀n sí i? Jákọ́bù tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù fún wa ní ìmọ̀ràn pàtàkì kan, ó ní: “Kí olúkúlùkù ènìyàn yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ, lọ́ra nípa ìrunú.” (Jákọ́bù 1:19) Bẹ́ẹ̀ ni, ká tó lè jùmọ̀ sọ̀rọ̀ lọ́nà tó máa gbé àwọn èèyàn ró, a ní láti fetí sílẹ̀ dáadáa, ká má ṣe máa já lu ọ̀rọ̀, bẹ́ẹ̀ sì ni a kò ní máa ṣáájú ẹlẹ́ẹ̀ẹ́dẹ́ pe ẹ̀ẹ́dẹ́. Yẹra fún ṣíṣe àríwísí nítorí pé ó lè má jẹ́ kí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ dán mọ́rán. Ìyẹn nìkan kọ́ o, Jésù kò lo ìbéèrè láti fi mọ àṣírí àwọn èèyàn, kàkà bẹ́ẹ̀, ó lo ìbéèrè lọ́nà ọgbọ́n láti fi mọ ohun tó wà lọ́kàn àwọn olùgbọ́ rẹ̀, ó sì fi mú kí àjọse òun pẹ̀lú wọn sunwọ̀n sí i.—Òwe 20:5; Mátíù 16:13-17; 17:24-27.

Nípa lílo àwọn ìlànà rere tó wà nínú Bíbélì, máa wá ọ̀nà tí wàá gbà máa bá àwọn èèyàn rẹ fèrò wérò, tí wàá sì máa bá wọn jùmọ̀ sọ̀rọ̀. Èyí yóò yọrí sí àjọṣe tó gún régé tí wàá mọyì rẹ̀ fún ọ̀pọ̀ ọdún, àní ní gbogbo ìgbésí ayé rẹ.