Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Tí Èdèkòyédè Bá Wáyé Láàárín Tọkọtaya

Tí Èdèkòyédè Bá Wáyé Láàárín Tọkọtaya

Tí Èdèkòyédè Bá Wáyé Láàárín Tọkọtaya

KÒ SÍ ọkọ tàbí aya kan tí orí ẹ̀ pé tí yóò sọ pé inú òun máa ń dùn kí èdèkòyédè máa wáyé láàárín òun àti ẹnì kejì òun. Àmọ́, irú nǹkan bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ gan-an. Bó ṣe sábà máa ń bẹ̀rẹ̀ ni pé, ọ̀kan nínú wọn á sọ nǹkan kan tó bí èkejì nínú. Wọ́n á wá bẹ̀rẹ̀ sí jágbe mọ́ra wọn, inú wọn á sì máa ru, ni awuyewuye ńlá á wá ṣẹlẹ̀, wọ́n á sì máa sọ ọ̀rọ̀ kòbákùngbé síra wọn. Lẹ́yìn náà, àwọn méjèèjì á wá dákẹ́ lọ gbári, wọn ò ní bára wọn sọ̀rọ̀ mọ́. Tó bá wá yá, ìbínú wọn á rọlẹ̀ àwọn méjèèjì á sì bẹ ara wọn. Àlàáfíà á tún padà dé, títí dìgbà tí aáwọ̀ mìíràn á tún fi wáyé.

Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ẹ̀fẹ̀ àtàwọn ètò tí wọ́n máa ń ṣe lórí tẹlifíṣọ̀n ló ń dá lórí èdèkòyédè tó máa ń wáyé láàárín àwọn tọkọtaya. Àmọ́ ọ̀rọ̀ yìí kì í ṣọ̀rọ̀ àwàdà rárá. Kódà, òwe inú Bíbélì kan sọ pé: “Ẹnì kan wà tí ń sọ̀rọ̀ láìronú bí ẹni pé pẹ̀lú àwọn ìgúnni idà.” (Òwe 12:18) Ká sóòótọ́, ọ̀rọ̀ burúkú lè fa ìbànújẹ́ tí kò ní tán lọ́kàn ẹnì kejì ẹni bọ̀rọ̀, kódà lẹ́yìn tí aáwọ̀ náà bá tiẹ̀ ti parí. Ìyàn jíjà sì lè yọrí sí kí ọkọ àti aya bẹ̀rẹ̀ sí i lu ara wọn.—Ẹ́kísódù 21:18.

Òótọ́ ni pé, nítorí àìpé àwa ẹ̀dá èèyàn, kò sọ́gbọ́n kí ìṣòro má máa wáyé láàárín tọkọtaya lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. (Jẹ́nẹ́sísì 3:16; 1 Kọ́ríńtì 7:28) Àmọ́ tí èdèkòyédè tó lágbára bá ń ṣẹlẹ̀ lemọ́lemọ́, kò yẹ kéèyàn máa wò ó pé kò sóhun tó burú níbẹ̀. Àwọn ọ̀mọ̀ràn nípa ìgbéyàwó ti ṣàkíyèsí pé, bí tọkọtaya kan bá ń fìgbà gbogbo ní aáwọ̀ láàárín ara wọn, àfàìmọ̀ kó má jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n máa kọra wọn sílẹ̀ gbẹ̀yìn. Ìdí nìyẹn tó fi ṣe pàtàkì pé kí ìwọ àti aya tàbí ọkọ rẹ mọ bí ẹ óò ṣe máa yanjú èdèkòyédè àárín yín lọ́nà pẹ̀lẹ́tù.

Fara Balẹ̀ Gbé Ohun Tó Ń Fà Á Yẹ̀ Wò

Bó bá jẹ́ pé ìyàn jíjà ni ṣáá nígbà gbogbo láàárín ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ, gbìyànjú láti mọ ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ tí àríyànjiyàn náà fi máa ń wáyé. Lọ́pọ̀ ìgbà, kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí èrò ìwọ àti ẹnì kejì rẹ ò bá dọ́gba lórí ọ̀ràn kan? Ṣé kíákíá ni ìjíròrò yín máa ń yí padà di iṣu ata yán-an yàn-an, tí ẹ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ kòbákùngbé ọ̀rọ̀ síra yín tí ẹ ó sì máa fẹ̀sùn kan ara yín? Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, kí lo lè ṣe?

Lákọ̀ọ́kọ́ ná, fara balẹ̀ ronú dáadáa lórí bí ìwọ gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan ṣe lè máa dá kún ìṣòro náà. Ṣé inú tètè máa ń bí ọ? Ṣé ẹnì kan tó máa ń jiyàn ni ọ́? Kí lọkọ rẹ tàbí aya rẹ yóò sọ nípa rẹ lórí kókó yìí? Ó ṣe pàtàkì kó o gbé ìbéèrè tó kẹ́yìn yìí yẹ̀ wò dáadáa, nítorí pé èrò ìwọ àti ẹnì kejì rẹ lè má dọ́gba lórí ohun tó ń fi hàn pé ẹnì kan máa ń jiyàn.

Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé ẹnì kejì rẹ jẹ́ ẹnì kan tí kì í fi bẹ́ẹ̀ sọ̀rọ̀, àmọ́ tí ìwọ́ jẹ́ ẹni tí kò mọ bá a ṣe ń ṣẹ́ ọ̀rọ̀ kù, tó o sì máa ń fi ìgbónára sọ̀rọ̀, o lè sọ pé: “Nígbà tí mo wà ní kékeré, bí gbogbo wa ṣe máa ń bára wa sọ̀rọ̀ nílé wa nìyẹn. Kì í ṣe pé mò ń jiyàn!” Lóòótọ́, o lè má kà á sí ìjiyàn. Àmọ́, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé bó o ṣe ń rò pé kò sóhun tó burú nínú kéèyàn máa la ọ̀rọ̀ mọ́lẹ̀ yẹn ni ohun tẹ́nì kejì rẹ kà sí iyàn jíjà tó máa ń dùn ún, tó sì lè yọrí sí ìjà. Fífi í sọ́kàn pé bí ìwọ àti ẹnì kejì rẹ ṣe ń sọ̀rọ̀ yàtọ̀ síra lè ràn yín lọ́wọ́ láti dènà àìgbọ́ra-ẹni-yé.

Tún rántí pé kì í ṣe gbogbo ìgbà téèyàn bá ń jiyàn léèyàn máa ń pariwo. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sáwọn Kristẹni pé: “Kí ẹ mú . . . ìlọgun àti ọ̀rọ̀ èébú kúrò lọ́dọ̀ yín pa pọ̀ pẹ̀lú gbogbo ìwà búburú.” (Éfésù 4:31) “Ìlọgun” ni kéèyàn máa pariwo sọ̀rọ̀, nígbà tí “ọ̀rọ̀ èébú” sì ń tọ́ka sí ohun tó ń tẹnu èèyàn jáde. Tá a bá gba ọ̀nà yìí wò ó, a óò rí i pé ọ̀rọ̀ téèyàn kò sọ sókè pàápàá lè fa àríyànjiyàn bó bá jẹ́ ọ̀rọ̀ tó ń bíni nínú tàbí tó ń búni kù ni.

Pẹ̀lú gbogbo ohun tá a ti sọ yìí, wá padà ronú lórí bó o ṣe máa ń ṣe nígbà tí aáwọ̀ bá wáyé láàárín ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ. Ṣé ẹni tó máa ń jiyàn ni ọ́? Gẹ́gẹ́ bá a ti rí i, ìdáhùn sí ìbéèrè yìí sinmi lórí ohun tí ọkọ rẹ tàbí aya rẹ bá sọ. Dípò tí wàá fi ronú pé ọkọ tàbí aya rẹ kò ní àmúmọ́ra ló jẹ́ kó sọ bẹ́ẹ̀, gbìyànjú láti rí ara rẹ lọ́nà tí ẹnì kejì rẹ gbà rí ọ, kó o sì ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Kí olúkúlùkù má ṣe máa wá àǹfààní ti ara rẹ̀, bí kò ṣe ti ẹnì kejì.”—1 Kọ́ríńtì 10:24.

“Ẹ Máa Fiyè sí Bí Ẹ Ṣe Ń Fetí Sílẹ̀”

Apá mìíràn tó tún yẹ ká kíyè sí tí aáwọ̀ bá ṣẹlẹ̀ la rí nínú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé: “Ẹ máa fiyè sí bí ẹ ṣe ń fetí sílẹ̀.” (Lúùkù 8:18) Òótọ́ ni pé kì í ṣe ọ̀nà tí tọkọtaya yóò máa gbà bá ara wọn sọ̀rọ̀ ni Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Síbẹ̀, a lè lo ìlànà tó wà nínú ọ̀rọ̀ Jésù yìí. Ǹjẹ́ o máa ń tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa nígbà tí ẹnì kejì rẹ bá ń sọ̀rọ̀? Àbí o kì í fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ sétí rárá? Àbí kẹ̀, ṣé ńṣe lo máa ń já lu ọ̀rọ̀ rẹ̀, tí wàá máa sọ ohun tó o rò pé ó lè yanjú ìṣòro tó ò tíì lóye rẹ̀ dáadáa? Bíbélì sọ pé: “Tí ẹnì kan bá ń fèsì ọ̀ràn kí ó tó gbọ́ ọ, èyíinì jẹ́ ìwà òmùgọ̀ níhà ọ̀dọ̀ rẹ̀ àti ìtẹ́lógo.” (Òwe 18:13) Nítorí náà, bí èdèkòyédè bá wáyé, ńṣe ló yẹ kí ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ jọ sọ̀rọ̀ lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ náà kẹ́ ẹ sì jọ tẹ́tí gbọ́ ara yín dáadáa.

Dípò tí wàá fi ka èrò ẹnì kejì rẹ sí ohun tí kò ṣe pàtàkì, gbìyànjú láti fi “ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì” hàn. (1 Pétérù 3:8) Ohun tí ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí ní ìpilẹ̀ṣẹ̀ nínú èdè Gíríìkì ni, bíbá ẹlòmíràn jẹ̀rora. Bí ohun kan bá ń kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹnì kejì rẹ, ó yẹ kí ọ̀rọ̀ náà ká ìwọ náà lára. Gbìyànjú láti rí ìṣòro náà bí ẹnì kejì rẹ ṣe rí i.

Ohun tí Ísáákì tó jẹ́ èèyàn Ọlọ́run ṣe gan-an nìyẹn. Bíbélì sọ fún wa pé ọkàn Rèbékà tó jẹ́ ìyàwó rẹ̀ bà jẹ́ gan-an nítorí ìṣòro kan tó ṣẹlẹ̀ nínú ìdílé wọn èyí tó ní í ṣe pẹ̀lú Jékọ́bù ọmọ rẹ̀. Ó sọ fún Ísáákì pé: “Mo ti wá fi tẹ̀gàntẹ̀gàn kórìíra ìgbésí ayé tèmi yìí nítorí àwọn ọmọbìnrin Hétì. Bí Jékọ́bù bá lọ mú aya nínú àwọn ọmọbìnrin Hétì bí ìwọ̀nyí nínú àwọn ọmọbìnrin ilẹ̀ yìí, ire wo ni ìgbésí ayé jẹ́ fún mi?”—Jẹ́nẹ́sísì 27:46.

Lóòótọ́, nítorí ìdààmú ọkàn tó bá Rèbékà, ó ṣeé ṣe kó ti sọ̀rọ̀ kọjá bó ṣe yẹ. Àbí ṣé lóòótọ́ ló kórìíra ìgbésí ayé rẹ̀ ni? Ṣé yóò wá kú lóòótọ́ bí ọmọ rẹ̀ bá lọ fẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọbìnrin Hétì? Kò dájú. Síbẹ̀, Ísáákì kò fọwọ́ kékeré mú bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára Rèbékà. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ísákì rí i pé ohun tí Rèbékà sọ mọ́gbọ́n dání, ó sì ṣe ohun tó yẹ nípa ọ̀rọ̀ náà. (Jẹ́nẹ́sísì 28:1) Ó yẹ kí ìwọ náà ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà mìíràn tí ohun kan bá ń kó ìdààmú ọkàn bá ọkọ tàbí aya rẹ. Dípò tí wàá fi máa wò ó pé ohun tó ń sọ kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì, tẹ́tí sí i, ka ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí, kó o sì dá a lóhùn lọ́nà tó fi hàn pé o gba tirẹ̀ rò.

Títẹ́tí Sílẹ̀ àti Níní Ìjìnlẹ̀ Òye Ṣe Pàtàkì

Òwe inú Bíbélì kan sọ pé: “Ìjìnlẹ̀ òye tí ènìyàn ní máa ń dẹwọ́ ìbínú rẹ̀ dájúdájú.” (Òwe 19:11) Nígbà tí ohùn ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ bá bẹ̀rẹ̀ sí í le síra yín, ó rọrùn láti bẹ̀rẹ̀ sí yára fèsì padà sí gbogbo ọ̀rọ̀ ìbínú tí ẹnì kejì rẹ bá sọ. Àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà, ńṣe lèyí máa ń mú kí àríyànjiyàn náà túbọ̀ le sí i. Nítorí náà, nígbà tó o bá ń tẹ́tí sí ọkọ tàbí aya rẹ, pinnu pé kì í ṣe ọ̀rọ̀ tó ń sọ nìkan ni wàá máa gbọ́, àmọ́ pé wàá tún máa fọkàn sí ohun tó mú kó máa sọ ọ̀rọ̀ náà. Irú ìjìnlẹ̀ òye bẹ́ẹ̀ kò ní jẹ́ kí ìbínú ru bò ọ́ lójú, á sì jẹ́ kó o lè rí ohun tó fa ìṣòro náà.

Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé ìyàwó rẹ sọ fún ọ pé, “O kì í ráyè fún mi rárá!” Ó lè ṣe ọ́ bíi pé kó o da ọ̀rọ̀ náà síbìínú kó o sì fi ìkanra fèsì pé ohun tó sọ kì í ṣòótọ́. O lè dá a lóhùn pé: “Odindi ọjọ́ kan ni mo fi jókòó tì ẹ́ nílé lóṣù tó kọjá!” Àmọ́ tó o bá fetí sílẹ̀ dáadáa, ó ṣeé ṣe kó o rí i pé kì í ṣe ohun tí ìyàwó rẹ ń sọ ni pé kó o máa jókòó ti òun nígbà gbogbo. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó kàn lè fẹ́ kó o fi òun lọ́kàn balẹ̀ pé o ṣì nífẹ̀ẹ́ òun, kó jẹ́ pé ohun tó ń sọ fún ọ ni pé ńṣe ló dà bíi pé o pa òun tì ó sì jọ pé o ò nífẹ̀ẹ́ òun mọ́.

Ká wá ní ìyàwó ni ọ ńkọ́, tí ọkọ rẹ sì sọ pé ohun kan tó o rà lẹ́nu àìpẹ́ yìí kò dùn mọ́ òun nínú. Ọkọ rẹ lè béèrè tìyanutìyanu pé: “Báwo lo ṣe lè ná iye tó tóyẹn?” Ó lè ṣe ọ́ bíi kó o máa wí àwíjàre pé ṣebí a ra àwọn nǹkan kan sínú ilé tàbí kó o máa sọ pé ṣebí òun náà ra nǹkan kan láìpẹ́ yìí. Àmọ́ ìjìnlẹ̀ òye á jẹ́ kó o rí i pé, ó lè má jẹ́ iye tó o ná gan-an lọkọ rẹ ń sọ̀rọ̀ bá. Ó lè jẹ́ pé ohun tó ń dùn ún ni pé o ò jẹ́ kóun mọ̀ pé o fẹ́ ra nǹkan olówó ńlá bẹ́ẹ̀ yẹn.

Lóòótọ́, bí tọkọtaya kọ̀ọ̀kan ṣe ń bójú tó ọ̀rọ̀ àkókò tí wọ́n fi ń wà pa pọ̀ àti bí wọ́n ṣe máa ń fohùn ṣọ̀kan lórí ohun tí wọ́n fẹ́ rà lè yàtọ̀ síra. Àmọ́ kókó tá a ní láti fi sọ́kàn ni pé, tí ọ̀rọ̀ kan bá ti di ohun tí ẹ̀ ń jiyàn lé, ìjìnlẹ̀ òye kò ní jẹ́ kó o bínú kọjá bó ṣe yẹ á sì jẹ́ kó o lè fara balẹ̀ kíyè sí ohun tó jẹ́ ìṣòro náà gan-an. Dípò tí wàá fi fi ìwàǹwára fèsì padà, tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ ìyànjú tí Jákọ́bù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì sọ pé, ká jẹ́ ẹni tó ń ‘yára nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́, ẹni tó ń lọ́ra nípa ọ̀rọ̀ sísọ, àtẹni tó ń lọ́ra nípa ìrunú.’—Jákọ́bù 1:19.

Nígbà tó o bá sì sọ̀rọ̀, máa rántí pé ọ̀nà tóò ń gbà bá ẹnì kejì rẹ sọ̀rọ̀ ṣe pàtàkì. Bíbélì sọ pé “ahọ́n ọlọ́gbọ́n jẹ́ ìmúniláradá.” (Òwe 12:18) Nígbà tí ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ bá ní èdèkòyédè, ṣé ọ̀rọ̀ tí yóò dùn ún wọra lo máa ń sọ àbí èyí tó máa mára tù ú? Ṣé èyí tí kò ní jẹ́ kí ọ̀rọ̀ náà yanjú ni àbí èyí tó máa jẹ́ kẹ́ ẹ lè parí èdèkòyédè náà? Bá a ti rí i nínú àwọn ohun tá a ti ń sọ bọ̀, ńṣe ni fífi ìbínú dá èsì padà tàbí fífi ìwàǹwára sọ̀rọ̀ wulẹ̀ máa ń dá ìjà sílẹ̀.—Òwe 29:22.

Bí èdèkòyédè bá ṣẹlẹ̀ tó sì di ohun tí ẹ̀ ń sọ̀kò ọ̀rọ̀ síra yín, ńṣe ni kó o túbọ̀ sapá láti pọkàn pọ̀ sórí ohun tó jẹ́ kókó ọ̀rọ̀ náà. Ohun tó fà á gan-an ni kó o gbájú mọ́, kì í ṣe ẹnì kejì rẹ. Ohun tó tọ́ láti ṣe ni kó o jẹ́ kó máa jẹ ọ́ lọ́kàn kì í ṣe kó o máa sọ pé ẹnì kan ló jàre tàbí ẹnì kan ló jẹ̀bi. Rí i pé ọ̀rọ̀ tó ń tẹnu rẹ jáde kò mú kí àríyànjiyàn náà túbọ̀ le sí i. Bíbélì sọ pé: “Ọ̀rọ̀ tí ń fa ìrora máa ń ru ìbínú sókè.” (Òwe 15:1) Kò sírọ́ ńbẹ̀ pé ohun tó o bá sọ àti ọ̀nà tó o gbà sọ̀ ọ́ ló máa mú kí ọkọ rẹ tàbí aya rẹ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú rẹ tàbí kó má ṣe bẹ́ẹ̀.

Bọ́rọ̀ Á Ṣe Yanjú Ni Kó O Máa Wá, Kì Í Ṣe Bí Wàá Ṣe Borí

Nígbà tí èdèkòyédè bá ṣẹlẹ̀, bí yóò ṣe yanjú ló yẹ ká máa wá kì í ṣe bá a ṣe máa borí. Kí lo lè ṣe tí ọ̀ràn náà á fi yanjú? Kò sí ọ̀nà mìíràn tó dára tó kó o wá ìmọ̀ràn Bíbélì lórí ọ̀ràn náà kó o sì fi ìmọ̀ràn náà sílò, àwọn ọkọ ló sì yẹ kó kọ́kọ́ máa ṣe èyí. Dípò kó o ti yára máa sọ pé ohun báyìí lo gbà pé yóò yanjú ìṣòro tàbí ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ náà, o ò ṣe wò ó lọ́nà tí Jèhófà gbà wò ó? Gbàdúrà sí Ọlọ́run, kó o sì wá àlááfíà rẹ̀ tí yóò dáàbò bo ọkàn àti ìrònú rẹ. (Éfésù 6:18; Fílípì 4:6, 7) Sa gbogbo ipá rẹ láti wá bó o ṣe lè ṣe ohun tí yóò dùn mọ́ ẹnì kejì rẹ nínú dípò ohun tó bá ṣáà ti tẹ́ ọ lọ́rùn.—Fílípì 2:4.

Ohun tó sábà máa ń jẹ́ kí ọ̀rọ̀ túbọ̀ nira láti yanjú ni jíjẹ́ kí inú tó ń bí ọ borí ìrònú rẹ kó sì mú ọ yí ìwà rẹ padà, kí ọ̀rọ̀ náà má sì tán lọ́kàn rẹ bọ̀rọ̀. Àmọ́, tó o bá ń jẹ́ kí ìmọ̀ràn tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tún èrò rẹ ṣe, èyí yóò jẹ́ kẹ́ ẹ lè wà ní àlàáfíà àti ìṣọ̀kan, wàá sì tún rí ìbùkún Jèhófà. (2 Kọ́ríńtì 13:11) Nítorí náà, jẹ́ kí “ọgbọ́n tí ó wá láti òkè” máa darí rẹ, kó o máa fi àwọn ànímọ́ Ọlọ́run hàn, kó o sì tipa bẹ́ẹ̀ rí èrè tí “àwọn tí ń wá àlàáfíà” máa ń rí.—Jákọ́bù 3:17, 18.

Láìsí tàbí ṣùgbọ́n, gbogbo wa ló yẹ ká kọ́ bí a óò ṣe máa yanjú èdèkòyédè lọ́nà pẹ̀lẹ́tù, kódà bí èyí bá tiẹ̀ gba pé ká yááfì àwọn ohun tá a fẹ́. (1 Kọ́ríńtì 6:7) Àní sẹ́, ẹ jẹ́ ká máa fi ọ̀rọ̀ ìṣílétí tí Pọ́ọ̀lù sọ sílò pé ẹ mú “ìrunú, ìbínú, ìwà búburú, ọ̀rọ̀ èébú, àti ọ̀rọ̀ rírùn kúrò lẹ́nu yín . . . . Ẹ bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀ pẹ̀lú àwọn àṣà rẹ̀, ẹ sì fi àkópọ̀ ìwà tuntun wọ ara yín láṣọ.”—Kólósè 3:8-10.

Òótọ́ ni pé ìgbà mìíràn wà tí wàá sọ àwọn nǹkan tó o máa wá kábàámọ̀ rẹ̀. (Jákọ́bù 3:8) Bí èyí bá ṣẹlẹ̀, ńṣe ni kó o bẹ ọkọ rẹ tàbí aya rẹ. Máa sapá nìṣó. Bí àkókò ṣe ń lọ, ó ṣeé ṣe kí ìwọ àti ọkọ tàbí aya rẹ rí i pé ìyàtọ̀ ti wà gan-an nínú bí ẹ ṣe ń yanjú èdèkòyédè àárín yín.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

Ọ̀nà Mẹ́ta Láti Yanjú Èdèkòyédè

• Tẹ́tí sílẹ̀ sí ọkọ tàbí aya rẹ. Òwe 10:19

• Ka èrò rẹ̀ sí. Fílípì 2:4

• Dá a lóhùn lọ́nà tó fìfẹ́ hàn. 1 Kọ́ríńtì 13:4-7.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ohun Tó O Lè Ṣe Lọ́wọ́lọ́wọ́ Báyìí

Béèrè àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí lọ́wọ́ ọkọ tàbí aya rẹ kó o sì tẹ́tí sí ìdáhùn rẹ̀ láìdá ọ̀rọ̀ mọ ọ́n lẹ́nu. Lẹ́yìn náà kí òun náà wá béèrè lọ́wọ́ rẹ.

• Ṣé mo máa ń jiyàn?

• Ṣé mo máa ń tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa nígbà tó o bá ń sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ àbí ńṣe ni mo máa ń já lu ọ̀rọ̀ rẹ kó o tó sọ ọ́ délẹ̀?

• Ṣé ọ̀rọ̀ mi máa ń fi hàn pé mi ò bìkítà nípa èrò rẹ àbí ó tiẹ̀ máa ń múnú bí ọ?

• Kí làwa méjèèjì lè ṣe kí ọ̀nà tá à ń gbà bára wa sọ̀rọ̀ lè túbọ̀ dára sí i, pàápàá tí èrò wa kò bá ṣọ̀kan lórí ọ̀ràn kan?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Ṣé o máa ń tẹ́tí sílẹ̀?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

“Ńṣe ló dà bíi pé o pa mí tì, ó sì jọ pé o ò nífẹ̀ẹ́ mi mọ́”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

“O kì í ráyè fún mi rárá!”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

“Odindi ọjọ́ kan ni mo fi jókòó tì ẹ́ nílé lóṣù tó kọjá!”