Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Èwe Ń yin Jèhófà ní Iléèwé

Àwọn Èwe Ń yin Jèhófà ní Iléèwé

Àwọn Èwe Ń yin Jèhófà ní Iléèwé

JÁKÈJÁDÒ ayé làwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń wọ́nà láti yin Ọlọ́run ní iléèwé. Bí wọ́n ṣe ń lo ọ̀rọ̀ ẹnu náà ni wọ́n tún ń fi ìwà wọn yìn ín. Àwọn ìrírí kan rèé tó jẹ́ ká rí báwọn ọ̀dọ́ ṣe ń fi ìtara yin Ọlọ́run.

Lórílẹ̀-èdè Gíríìsì, wọ́n ní kí ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí kan kọ àròkọ kan nípa báwọn èèyàn ṣe ń ba àyíká jẹ́. Nígbà tó wo ìwé Watch Tower Publications Index, ó rí àwọn kókó tó lè lò láti fi kọ àròkọ náà nínú ìwé ìròyìn Jí! Nígbà tó sì máa parí àròkọ rẹ̀, ó kọ́ ọ síbẹ̀ pé inú ìwé ìròyìn Jí! lòun ti mú gbogbo àlàyé òun jáde. Olùkọ́ rẹ̀ sọ fún un pé àròkọ rẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àròkọ tí òun tíì gbádùn jù lọ. Níbi àpérò kan tí olùkọ́ náà lọ, ó lo kókó inú àròkọ náà, àwọn tó wà níbẹ̀ sì gbádùn rẹ̀ gan-an. Èyí ló mú kí arábìnrin kékeré yìí kúkú fún olùkọ́ rẹ̀ làwọn ìwé ìròyìn Jí!, ọ̀kan lára àwọn tó sì fún un ni èyí tí àkọlé rẹ̀ jẹ́, “Kí La Lè Ṣe Láìsí Àwọn Olùkọ́?” Nígbà tó yá, olùkọ́ náà sọ fáwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ pé Jí! wúlò gan-an, làwọn akẹ́kọ̀ọ́ kan bá sọ pé àwọn náà fẹ́ gba tiwọn. Ọ̀pọ̀ ìwé ìròyìn Jí! ni arábìnrin náà kó lọ sílé ẹ̀kọ́ káwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà lè rí àwọn ẹ̀dà mìíràn kà.

Lórílẹ̀-èdè Benin nílẹ̀ Áfíríkà, ọ̀dọ́bìnrin kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí ní ìṣòro àrà ọ̀tọ̀ kan. Ọ̀pọ̀ òbí máa ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti gba àwọn olùkọ́ tí yóò kọ́ àwọn ọmọ wọn láwọn iṣẹ́ tó le gan-an kí wọ́n lè yege ìdánwò wọn. Àmọ́, òwúrọ̀ ọjọ́ Sátidé làwọn olùkọ́ náà fi ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí sí. Arábìnrin kékeré yìí ò fara mọ́ ọn rárá, ó sọ pé: “Òwúrọ̀ Sátidé ni gbogbo ìjọ wa jọ máa ń lọ wàásù. Ọjọ́ yìí ni mo fẹ́ràn jù lọ ní gbogbo ọ̀sẹ̀, mi ò sì lè jẹ́ kí ohunkóhun gbà á mọ́ mi lọ́wọ́!” Bàbá ọmọbìnrin náà tí òun náà jẹ́ Ẹlẹ́rìí tó sì ń dá nìkan tọ́mọ, gbà pé òótọ́ lọmọ òun sọ, ó sì rọ àwọn òbí kan àtàwọn olùkọ́ kan pé kí wọ́n fi àkókò ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà sígbà mìíràn. Ṣùgbọ́n ńṣe ni gbogbo wọn yarí. Ni ọmọbìnrin yìí bá sọ pé òun ò ṣe ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà mọ́. Dípò ìyẹn, ó ń bá àwọn tó wà ní ìjọ rẹ̀ lọ sóde ẹ̀rí. Àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ wá bẹ̀rẹ̀ sí fi ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n ní kó lọ wá ibì kan sọ àpò ìwàásù rẹ̀ sí, kó má tiẹ̀ sin Ọlọ́run mọ́. Wọ́n ti gbà pé ó máa fìdí rẹmi nínú ìdánwò náà. Àmọ́, ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ pé kò sí èyí tó yege nínú gbogbo àwọn tí wọ́n kọ́ ṣáájú ìdánwò náà, ṣùgbọ́n arábìnrin ọ̀dọ́ yìí yege. Bó ṣe di pé wọn ò fi í ṣe yẹ̀yẹ́ mọ́ nìyẹn. Ní báyìí, ohun táwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ń sọ fún un ni pé, “Má fi Ọlọ́run tí ò ń sìn yìí sílẹ̀ o.”

Lórílẹ̀-èdè Czech, wọ́n sọ fún ọmọbìnrin ọmọ ọdún méjìlá kan nílé ìwé pé kó kọ àròkọ kan lórí ìwé kan. Ìyá rẹ̀ wá sọ fún un pé kó kọ nǹkan lórí ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí. Nígbà tó máa bẹ̀rẹ̀ àròkọ rẹ̀, ó béèrè pé: “Kí lèrò tìẹ? Ta lẹni tó tóbi jù lọ tó tíì gbé ayé yìí rí?” Ó sọ ẹni tí Jésù jẹ́, ohun tó ṣe nígbà tó wà láyé àtàwọn ẹ̀kọ́ tó kọ́ àwọn èèyàn. Lẹ́yìn èyí ló wá sọ̀rọ̀ lórí àkòrí tó sọ pé “Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n kan Nipa Ìdáríjì.” Àròkọ rẹ̀ wú olùkọ́ rẹ̀ lórí gan-an tó fi sọ pé: “Nínú gbogbo àròkọ tó o ti ń kọ, o ò tíì kọ èyí tó dára tó èyí rí!” Nígbà tí ọmọ náà fún olùkọ́ rẹ̀ ní ẹ̀dà ìwé yìí kan, inú rẹ̀ dùn gan-an. Àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ náà sọ fún un pé kó bá àwọn náà mú tiwọn wá. Lọ́jọ́ kejì, ìwé Ọkunrin Titobilọla méjìdínlógún ni ọmọbìnrin náà fún wọn, èyí sì múnú rẹ̀ dùn gan-an.

Inú àwọn èwe bíi tàwọn tá a sọ̀rọ̀ nípa wọn yìí máa ń dùn gan-an bí wọ́n ṣe ń yin Jèhófà ní iléèwé. Kò sí àní-àní pé ó yẹ kí gbogbo wa náà jẹ́ onítara bíi tàwọn èwe wọ̀nyí.