Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀yin Èwe, Ẹ Yin Jèhófà!

Ẹ̀yin Èwe, Ẹ Yin Jèhófà!

Ẹ̀yin Èwe, Ẹ Yin Jèhófà!

“Ẹ yin Jèhófà láti ilẹ̀ ayé, . . . ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin àti ẹ̀yin wúńdíá pẹ̀lú.”—SÁÀMÙ 148:7, 12.

1, 2. (a) Kí ni ọ̀pọ̀ èwe máa ń mọ̀ pé àwọn òbí àwọn ò ní gbà wọ́n láyè láti ṣe? (b) Kí nìdí tí kò fi yẹ kí àwọn èwe bínú táwọn òbí wọn ò bá gbà wọ́n láyè láti ṣe àwọn nǹkan kan?

 ÀWỌN èwe sábà máa ń mọ ohun táwọn òbí wọn ò tíì gbà wọ́n láyè láti ṣe. Kódà, ọ̀pọ̀ nínú wọn máa ń sọ bí àwọn ṣe máa dàgbà tó kí òbí àwọn tó lè gbà wọ́n láyè láti dá sọdá títì tàbí káwọn tó lè máa fúnra wọn pinnu ìgbà táwọn yóò lọ sùn tàbí ìgbà táwọn máa tó lè wakọ̀. Nígbà mìíràn, èwe kan lè rò pé ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ohun tóun bá sọ pé òun fẹ́ ṣe ni wọn kì í gba òun láyè láti ṣe, tí wọ́n á máa sọ fóun pé, “Rárá, ó dìgbà tó o bá dàgbà.”

2 Ẹ̀yin èwe mọ̀ pé àwọn òbí yín rí i pé ó máa dára káwọ́n máà tíì gbà yín láyè láti ṣe nǹkan wọ̀nyẹn, bóyá nítorí kí ẹ má bàa fara pa. Ẹ sì mọ̀ dájú pé inú Jèhófà máa ń dùn tẹ́ ẹ bá gbọ́rọ̀ sáwọn òbí yín lẹ́nu. (Kólósè 3:20) Àmọ́ ṣé ìkálọ́wọ́kò tí àwọn òbí yín ń fún yín yìí kì í jẹ́ kẹ́ ẹ rò pé kò sí nǹkan kan tẹ́ ẹ lè dá ṣe lọ́jọ́ orí yín yìí? Ṣé gbogbo nǹkan pàtàkì náà ni wọn ò ní gbà kẹ́ ẹ ṣe àfìgbà tẹ́ ẹ bá dàgbà? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá o! Iṣẹ́ kan ń lọ lọ́wọ́ báyìí lóde òní, tó ṣe pàtàkì ju ohunkóhun mìíràn tó lè máa wù yín láti ṣe nígbà tẹ́ ẹ bá dàgbà. Ǹjẹ́ àwọn àgbà yóò gbà kí ẹ̀yin náà ṣe iṣẹ́ yìí? Bẹ́ẹ̀ ni o, kódà kì í ṣe ọ̀rọ̀ pé wọ́n á gbà tàbí wọn ò ní gbà, àní Ọlọ́run Ọ̀gá Ògo fúnra rẹ̀ ló tiẹ̀ pè yín pé kẹ́ ẹ wá ṣe é!

3. Iṣẹ́ pàtàkì wo ni Jèhófà pe àwọn èwe kí wọ́n wá ṣe, àwọn ìbéèrè wo la ó sì sọ̀rọ̀ lé lórí?

3 Iṣẹ́ wo là ń sọ? Ẹ wo ọ̀rọ̀ ẹsẹ Bíbélì tó jẹ́ àkọlé àpilẹ̀kọ wa yìí ná, ó ní: “Ẹ yin Jèhófà láti ilẹ̀ ayé, . . . ẹ̀yin ọ̀dọ́kùnrin àti ẹ̀yin wúńdíá pẹ̀lú, ẹ̀yin arúgbó pa pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀yin ọmọdékùnrin.” (Sáàmù 148:7, 12) Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn sọ àǹfààní ńláǹlà kan tẹ́ ẹ ní, ìyẹn ni pé: Ẹ lè máa yin Jèhófà. Ẹ̀yin èwe, ǹjẹ́ orí yín ń yá gágá sí iṣẹ́ yìí? Inú ọ̀pọ̀ àwọn èwe máa ń dùn láti ṣe iṣẹ́ yìí. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ lórí ìbéèrè mẹ́ta kan kẹ́ ẹ lè rí ìdí tó fi yẹ kínú yín máa dùn láti ṣe iṣẹ́ yẹn. Àkọ́kọ́, kí nìdí tó fi yẹ kẹ́ ẹ máa yin Jèhófà? Ìkejì, báwo lẹ ṣe lè máa sọ̀rọ̀ Jèhófà lọ́nà tó máa wọ àwọn èèyàn lọ́kàn? Ìkẹta, ìgbà wo ló dára kẹ́ ẹ bẹ̀rẹ̀ sí yin Jèhófà?

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kẹ́ Ẹ Máa Yin Jèhófà?

4, 5. (a) Inú agbo tó wúni lórí wo la wà gẹ́gẹ́ bí Sáàmù ìkejìdínláàádọ́jọ ṣe fi hàn? (b) Báwo làwọn ìṣẹ̀dá tí kò lè sọ̀rọ̀, tí kò sì lè ronú ṣe ń yin Jèhófà?

4 Ìdí kan pàtàkì tó fi yẹ kẹ́ ẹ máa yin Jèhófà ni pé òun ni Ẹlẹ́dàá wa. Sáàmù ìkejìdínláàádọ́jọ [148] jẹ́ ká rí kókó yìí kedere. Ẹ fọkàn yàwòrán yìí ná: Ká sọ pé ẹ wọ àárín agbo àwọn èèyàn kan tó ń kọ orin aládùn kan tó wúni lórí, inú yín máa dùn àbí kò ní dùn? Tẹ́ ẹ bá wá rí i pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ orin yẹn ńkọ́, pé orin náà ń sọ nǹkan kan tó ṣe pàtàkì, tó ń fúnni láyọ̀, tó sì ń gbéni ró, ṣé kò ní wù yín láti kọ́ orin yẹn kẹ́ ẹ sì máa bá wọn kọ ọ́? Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú wa ló máa fẹ́ ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣẹ́ ẹ rí i, irú inú agbo yẹn ni Sáàmù ìkejìdínláàádọ́jọ fi hàn pé ẹ wà, kódà ipò tiyín tiẹ̀ tún wúni lórí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Sáàmù yìí ṣàpèjúwe agbo ńláǹlà kan tí gbogbo wọn jọ ń yin Jèhófà níṣọ̀kan. Àmọ́ ṣá o, bẹ́ ẹ ṣe ń ka ọ̀rọ̀ sáàmù yìí, ẹ lè rí nǹkan kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Kí ni nǹkan yẹn?

5 Ọ̀pọ̀ lára àwọn nǹkan tí Sáàmù ìkejìdínláàádọ́jọ sọ pé ó ń yin Jèhófà ni kò lè sọ̀rọ̀, wọn ò sì lè ronú. Bí àpẹẹrẹ, a rí i kà níbẹ̀ pé oòrùn, òṣùpá, ìràwọ̀, ìrì dídì, ẹ̀fúùfù, àwọn òkè ńlá àti òkè kéékèèké ń yin Jèhófà. Báwo làwọn ẹ̀dá tí kò lẹ́mìí bẹ́ẹ̀ ṣe lè yin Jèhófà? (Sáàmù 148 Ẹsẹ 3, 8, 9) Ọ̀nà tí àwọn igi, àwọn ẹ̀dá inú òkun àti àwọn ẹranko gbà ń yin Jèhófà ni wọ́n gbà ń yìn ín. (Sáàmù 148 Ẹsẹ 7, 9, 10) Ǹjẹ́ ẹ ti rí bí oòrùn tó ń wọ̀ ṣe lẹ́wà tó tàbí bí òṣùpá àrànmọ́jú ṣe ń rọra yí lọ lójú ọ̀run tí ìràwọ̀ pọ̀ rẹpẹtẹ sí? Ǹjẹ́ ẹ ti rí ibi tí àwọn ẹranko ti ń bára wọn ṣeré tí ìyẹn sì ń pa yín lẹ́rìn-ín? Ǹjẹ́ ẹ ti rí àgbègbè ẹlẹ́wà kan tó ní àwọn nǹkan tó wú yín lórí? Tẹ́ ẹ bá ti rí àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀, ẹ ti “gbọ́” orin tí ìṣẹ̀dá ń kọ nìyẹn. Gbogbo ohun tí Jèhófà dá ló ń rán wa létí pé Jèhófà ni Ẹlẹ́dàá àti Olódùmarè, àti pé òun ló lágbára jù lọ, òun ló gbọ́n jù lọ, òun ló sì jẹ́ onífẹ̀ẹ́ jù lọ láyé àti lọ́run.—Róòmù 1:20; Ìṣípayá 4:11.

6, 7. (a) Àwọn ẹ̀dá olóye wo ni Sáàmù ìkejìdínláàádọ́jọ sọ pé ó ń yin Jèhófà? (b) Kí ló lè mú kí àwa náà bẹ̀rẹ̀ sí yin Jèhófà? Mú àpẹẹrẹ wá.

6 Sáàmù ìkejìdínláàádọ́jọ yìí sọ pé àwọn ẹ̀dá olóye náà ń yin Jèhófà pẹ̀lú. A kà á ní Sáàmù 148 ẹsẹ kejì pé àwọn “ẹgbẹ́ ọmọ ogun” Jèhófà ní ọ̀run, ìyẹn àwọn áńgẹ́lì, ń yin Ọlọ́run. Sáàmù 148 Ẹsẹ kọkànlá sọ pé kí àwọn èèyàn pàtàkì, irú bí àwọn ọba àtàwọn onídàájọ́ wá yìn ín pẹ̀lú. Bí inú àwọn áńgẹ́lì alágbára bá ń dùn láti yin Jèhófà, ǹjẹ́ ó yẹ kí ẹnikẹ́ni lára àwa ọmọ èèyàn lásán-làsàn sọ pé òun ju ẹni tó lè máa yin Ọlọ́run? Lẹ́yìn náà, Sáàmù 148 ẹsẹ kejìlá àti ìkẹtàlá wá sọ pé kí ẹ̀yin èwe wá máa yin Jèhófà bákan náà. Ǹjẹ́ inú yín ń dùn láti ṣe bẹ́ẹ̀?

7 Àpèjúwe kan rèé. Jẹ́ ká sọ pé o ní ọ̀rẹ́ kan tó mọ ohun kan ṣe gan-an, bóyá eré ìdárayá ni, tàbí àwòrán yíyà tàbí orin kíkọ, ṣé o kò ní ròyìn rẹ̀ fún ìdílé rẹ àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ yòókù? Ó dájú pé wàá ó ròyìn fún wọn. Ohun téèyàn máa ṣe náà nìyẹn téèyàn bá ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa gbogbo nǹkan tí Jèhófà ṣe. Bí àpẹẹrẹ, Sáàmù 19:1, 2 sọ pé àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run máa “ń mú kí ọ̀rọ̀ ẹnu tú jáde.” Tí àwa náà bá ń ronú lórí àwọn ohun ìyanu tí Jèhófà ti ṣe, a ò ní lè dákẹ́ ká má sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run wa fáwọn èèyàn.

8, 9. Kí nìdí tí Jèhófà fi fẹ́ ká máa yin òun?

8 Ìdí pàtàkì mìíràn tá a fi gbọ́dọ̀ máa yin Jèhófà ni pé òun fúnra rẹ̀ fẹ́ ká yin òun. Kí nìdí rẹ̀? Ṣé táwọn èèyàn ò bá yìn ín nǹkan kan máa ṣẹlẹ̀ sí i ni? Rárá o. Nígbà míì, àwa èèyàn lè fẹ́ káwọn èèyàn yìn wá ká lè mọ̀ pé à ń ṣe dáadáa, ṣùgbọ́n Jèhófà yàtọ̀ sí wa torí pé ó ga jù wá lọ gan-an. (Aísáyà 55:8) Kì í ṣiyèméjì nípa ara rẹ̀ tàbí àwọn ànímọ́ rẹ̀. (Aísáyà 45:5) Síbẹ̀ ó ń fẹ́ ká ṣì máa yin òun, inú rẹ̀ sì máa ń dùn tá a bá ń yìn ín. Kí nìdí? Ẹ wo ìdí méjì ná. Ìdí àkọ́kọ́: Ó mọ̀ pé tá a bá ń yin òun á ṣe wá láǹfààní. Nígbà tó dá wa, ó dá wa pé ká máa wá nǹkan tẹ̀mí, ìyẹn ni pé ká ní ẹ̀mí ìjọsìn. (Mátíù 5:3) Tí Jèhófà bá rí i pé à ń wọ́nà láti sin òun inú rẹ̀ máa ń dùn gẹ́gẹ́ bí inú àwọn òbí ṣe máa ń dùn tí ọmọ wọn bá ń jẹ oúnjẹ tí wọ́n mọ̀ pé ó dára.—Jòhánù 4:34.

9 Ìdí kejì: Jèhófà mọ̀ pé ó máa ṣe àwọn ẹlòmíràn láǹfààní tí wọ́n bá ń gbọ́ bí a ṣe ń yin òun. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ ọ̀rọ̀ tó tẹ̀ lé e yìí sí Tímótì tó kéré sí i lọ́jọ́ orí, ó ní: “Máa fiyè sí ara rẹ nígbà gbogbo àti sí ẹ̀kọ́ rẹ. Dúró nínú nǹkan wọ̀nyí, nítorí nípa ṣíṣe èyí, ìwọ yóò gba ara rẹ àti àwọn tí ń fetí sí ọ là.” (1 Tímótì 4:16) Láìsí àní-àní, tẹ́ ẹ bá ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà Ọlọ́run, tẹ́ ẹ̀ ń yìn ín, àwọn náà lè wá mọ Jèhófà. Irú ìmọ̀ bẹ́ẹ̀ sì lè mú kí wọ́n rí ìgbàlà ayérayé!—Jòhánù 17:3.

10. Kí nìdí tá a fi rí i pé ó pọn dandan ká máa yin Ọlọ́run?

10 Ìdí mìíràn tún wà tó fi yẹ ká máa yin Jèhófà. Ẹ rántí àpèjúwe tá a ṣe lẹ́ẹ̀kan nípa ọ̀rẹ́ yín tá a ló mọ ohun kan ṣe gan-an. Tẹ́ ẹ bá gbọ́ pé ẹnì kan parọ́ mọ́ ọn, tí wọ́n bà á lórúkọ jẹ́, ǹjẹ́ ẹ ò ní sa gbogbo ipá yín láti túbọ̀ ròyìn àwọn nǹkan dáadáa tó ti ṣe? Ṣé ẹ rí i, àwọn èèyàn ti ba Jèhófà lórúkọ jẹ́ gan-an láyé yìí. (Jòhánù 8:44; Ìṣípayá 12:9) Ìdí nìyẹn táwọn tó fẹ́ràn Jèhófà fi máa ń sọ òtítọ́ nípa rẹ̀ fáwọn èèyàn, láti lè fi tú àṣírí gbogbo irọ́ tí wọ́n ń pa mọ́ ọn. Ṣé ẹ̀yin náà yóò fẹ́ láti fi hàn pé ẹ fẹ́ràn Jèhófà pé ẹ sì dúpẹ́ oore rẹ̀? Ṣé ẹ óò fẹ́ láti fi hàn pé òun lẹ fẹ́ kó jẹ́ Alákòóso yín dípò Sátánì olórí ọ̀tá rẹ̀? Gbogbo ìwọ̀nyẹn lẹ lè ṣe tẹ́ ẹ bá ń yin Jèhófà. Ohun tó kàn báyìí ká gbé yẹ̀ wò ni bí ẹ ṣe lè máa yin Jèhófà.

Bí Àwọn Èwe Kan Ṣe Yin Jèhófà

11. Àwọn àpẹẹrẹ wo látinú Bíbélì ló fi hàn pé àwọn èwe lè yin Jèhófà lọ́nà tó máa wọ àwọn èèyàn lọ́kàn?

11 Bíbélì fi hàn pé bí àwọn ọ̀dọ́ bá ń yin Jèhófà, ọ̀rọ̀ wọn sábà máa ń wọ àwọn èèyàn lọ́kàn gan-an. Àpẹẹrẹ kan ni ti ọmọbìnrin Ísírẹ́lì kan táwọn ará Síríà mú lẹ́rú. Ó fi ìgboyà wàásù nípa Èlíṣà wòlíì Jèhófà fún ọ̀gá rẹ̀ obìnrin. Ọ̀rọ̀ tí ọmọ yìí sọ mú kí Èlíṣà ṣe iṣẹ́ ìyanu kan tó yọrí sí ìjẹ́rìí pàtàkì kan. (2 Àwọn Ọba 5:1-17) Jésù náà fi ìgboyà wàásù nígbà tó wà lọ́mọdé. Nínú gbogbo ohun tí Jésù ṣe nígbà tó wà lọ́mọdé tí wọ́n lè kọ sínú Ìwé Mímọ́, ẹyọ kan péré ni Jèhófà yàn kí wọ́n kọ, ìyẹn ni ìgbà tó wà lọ́mọ ọdún méjìlá tó ń fi ìgboyà béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ àwọn olùkọ́ tó wà nínú tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù, tí ẹnu sì yà wọ́n nítorí bó ṣe mọ àwọn ọ̀nà Jèhófà tó.—Lúùkù 2:46-49.

12, 13. (a) Kí ni Jésù ṣe nínú tẹ́ńpìlì lọ́jọ́ mélòó kan ṣáájú ikú rẹ̀, kí ni èyí sì mú kí àwọn tó wà níbẹ̀ ṣe? (b) Kí ni èrò Jésù nípa yíyìn táwọn ọmọdékùnrin kan yìn ín?

12 Nígbà tí Jésù dàgbà, ó ń ṣe ohun tó mú kí àwọn èwe yin Jèhófà pẹ̀lú. Bí àpẹẹrẹ, lọ́jọ́ mélòó kan ṣáájú kí Jésù tó kú, ó lọ sí tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù. Bíbélì sọ pé ó ṣe “àwọn ohun ìyanu” níbẹ̀. Ó lé àwọn tó sọ ibi mímọ́ yẹn di ilé àwọn ọlọ́ṣà jáde. Ó tún la ojú afọ́jú ó sì mú arọ lára dá. Ńṣe ló yẹ kí gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀, pàápàá àwọn aṣáájú ìsìn, máa fìyìn fún Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ Mèsáyà nítorí ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí. Àmọ́, wọn ò fìyìn fún wọn rárá. Àwọn tó wà níbẹ̀ yìí mọ̀ pé Ọlọ́run ló rán Jésù níṣẹ́ o, ṣùgbọ́n wọ́n ń bẹ̀rù àwọn aṣáájú ìsìn. Àwọn kan sọ̀rọ̀ tìgboyàtìgboyà ní tiwọn ṣá o. Ǹjẹ́ ẹ mọ àwọn ẹni náà? Bíbélì sọ pé: “Nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin rí àwọn ohun ìyanu tí [Jésù] ṣe àti àwọn ọmọdékùnrin tí ń ké jáde ní tẹ́ńpìlì, tí wọ́n sì ń sọ pé: ‘Gba Ọmọkùnrin Dáfídì là, ni àwa bẹ̀bẹ̀!’ ìkannú wọn ru wọ́n sì sọ fún [Jésù] pé: ‘Ìwọ ha gbọ́ ohun tí àwọn wọ̀nyí ń sọ?’”—Mátíù 21:15, 16; Jòhánù 12:42.

13 Àwọn àlùfáà wọ̀nyí rò pé Jésù yóò sọ pé kí àwọn ọmọdékùnrin tó ń yìn ín dákẹ́. Ǹjẹ́ ó sọ bẹ́ẹ̀? Rárá o! Jésù dá àwọn àlùfáà yẹn lóhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni. Ṣé ẹ kò tíì ka èyí rí pé, ‘Láti ẹnu àwọn ìkókó àti àwọn ọmọ ẹnu ọmú ni o ti mú ìyìn jáde’?” Ó dájú pé inú Jésù àti Baba rẹ̀ dùn sí ìyìn àwọn ọmọdékùnrin wọ̀nyẹn. Ohun tó yẹ kí àwọn àgbà tó wà níbẹ̀ ṣe làwọn ọmọ wọ̀nyẹn ṣe. Lọ́kàn àwọn ọmọdé tí kì í ṣe ẹlẹ́tanú wọ̀nyẹn, gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ náà ṣe kedere gan-an ni. Wọ́n rí i pé ọkùnrin yìí ń ṣe àwọn ohun ìyanu, ó ń fi ìgboyà àti ìgbàgbọ́ sọ̀rọ̀, ó sì fẹ́ràn Ọlọ́run àti àwọn èèyàn rẹ̀ dáadáa. Wọ́n mọ̀ pé òótọ́ ló sọ nígbà tó sọ pé òun ni “Ọmọkùnrin Dáfídì” tí Ọlọ́run ṣèlérí, ìyẹn ni Mèsáyà. Ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú rẹ̀ yìí ò já sí asán rárá torí pé wọ́n ní àǹfààní ńláǹlà kan, ìyẹn ni pé wọ́n mú àsọtẹ́lẹ̀ Ìwé Mímọ́ ṣẹ.—Sáàmù 8:2.

14. Àwọn ẹ̀bùn wo làwọn èwe ní tí wọ́n lè fi yin Ọlọ́run?

14 Ẹ̀kọ́ wo ni àwọn àpẹẹrẹ yìí kọ́ wa? Ẹ̀kọ́ náà ni pé táwọn èwe bá ń sọ̀rọ̀ ìyìn Jèhófà, ó máa ń wọ àwọn èèyàn lọ́kàn gan-an ni. Àwọn ọmọdé sábà máa ń rí òótọ́ kedere, lọ́nà tí kò lọ́jú pọ̀, wọ́n sì máa ń fi òótọ́ ọkàn àti ìtara sọ ìgbàgbọ́ wọn. Wọ́n tún ní ẹ̀bùn kan tí Òwe 20:29 mẹ́nu kàn nígbà tó sọ pé: “Ẹwà àwọn ọ̀dọ́kùnrin ni agbára wọn.” Dájúdájú, ẹ̀yin èwe ní okun àti agbára, ohun èlò gidi tẹ́ ẹ sì lè fi máa yin Jèhófà lèyí jẹ́. Báwo lẹ ṣe lè lo ẹ̀bùn wọ̀nyẹn lọ́nà tó dára?

Báwo Lẹ Ṣe Lè Máa Yin Jèhófà?

15. Kí ló lè mú kéèyàn dẹni tó ń sọ̀rọ̀ ìyìn Jèhófà lọ́nà tó ń wọni lọ́kàn?

15 Kéèyàn tó lè yin Ọlọ́run dáadáa, ìyìn náà gbọ́dọ̀ ti inú ọkàn wá. Ẹ kò lè sọ̀rọ̀ ìyìn Jèhófà lọ́nà tó máa wọni lọ́kàn tó bá jẹ́ pé nítorí pé àwọn kan ní kẹ́ ẹ yìn ín lẹ ṣe ń yìn ín. Ẹ rántí pé òfin tó tóbi jù lọ ni pé: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò inú rẹ.” (Mátíù 22:37) Ǹjẹ́ ẹ ti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì débi pé ẹ fúnra yín mọ Jèhófà dunjú? Tẹ́ ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ óò rí i pé ìyẹn yóò mú kẹ́ ẹ fẹ́ràn Jèhófà látọkànwá. Bẹ́ ẹ bá sì ti fẹ́ràn rẹ̀ látọkànwá ẹ óò máa yìn ín. Tẹ́ ẹ bá fẹ́ràn Jèhófà, tí ìfẹ́ yẹn sì jinlẹ̀ lọ́kàn yín, ẹ ó máa yìn ín tìtaratìtara.

16, 17. Báwo lèèyàn ṣe lè fi ìwà tó dára yin Jèhófà? Mú àpẹẹrẹ wá.

16 Wàyí o, kẹ́ ẹ tiẹ̀ tó máa ronú lórí ohun tí ẹ máa sọ, ẹ kọ́kọ́ ronú nípa irú ìwà tó yẹ kẹ́ ẹ máa hù. Ká ní pé ọ̀dọ́mọbìnrin ọmọ Ísírẹ́lì ìgbà ayé Èlíṣà yẹn máa ń hùwà àrífín ni, tó ń yájú sáwọn èèyàn tàbí tó ń parọ́, ṣé ẹ rò pé àwọn ará Síríà tó mú un lẹ́rú yóò gbọ́ ọ̀rọ̀ tó sọ nípa wòlíì Jèhófà? Kò dájú pé wọ́n á gbọ́. Bákan náà, ìgbà táwọn èèyàn bá rí i pé ẹ jẹ́ ọmọ tó ń bọ̀wọ̀ fúnni, pé ẹ jẹ́ olóòótọ́ àti ọmọ dáadáa ni ọ̀rọ̀ yín máa tó wọ̀ wọ́n lọ́kàn. (Róòmù 2:21) Ẹ wo àpẹẹrẹ kan.

17 Ọmọbìnrin kan wà lórílẹ̀-èdè Potogí, ọmọ ọdún mọ́kànlá ni. Nílé ìwé rẹ̀, wọ́n máa ń sọ fún un pé kó ṣe àwọn àjọ̀dún kan tó jẹ́ pé ó lòdì sí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ nítorí ẹ̀kọ́ Bíbélì tó ti kọ́. Àmọ́ nígbà tó lọ ṣàlàyé fún olùkọ́ rẹ̀ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, tó sọ ìdí tí òun ò fi lè bá wọn ṣe é, yẹ̀yẹ́ ni olùkọ́ rẹ̀ fi ṣe. Àìmọye ìgbà ni olùkọ́ rẹ̀ gbìyànjú láti dójú tì í, tí yóò máa fi ẹ̀sìn rẹ̀ ṣe yẹ̀yẹ́. Àmọ́, ọmọbìnrin náà ò tìtorí ìyẹn kó má bọ̀wọ̀ fún olùkọ́ rẹ̀ yìí. Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, ọmọbìnrin yìí di aṣáájú ọ̀nà, ìyẹn ẹni tó ń fi àkókò tó pọ̀ gan-an wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Lọ́jọ́ kan tí ọmọbìnrin yìí wà ní ìpàdé àgbègbè, bó ṣe ń wo àwọn tó ń ṣe ìrìbọmi ló rí ẹnì kan tó mọ̀ rí. Olùkọ́ rẹ̀ àtijọ́ yẹn ni! Lẹ́yìn tí àwọn méjèèjì dì mọ́ra, tí wọ́n kí ara wọn pẹ̀lú omijé ayọ̀, ni olùkọ́ rẹ̀ àtijọ́ yìí wá sọ fún un pé òun ò gbàgbé bó ṣe ń bọ̀wọ̀ fún òun nílé ìwé. Ẹlẹ́rìí kan ló wá wàásù fún olùkọ́ rẹ̀ tẹ́lẹ̀ yìí, olùkọ́ yìí sì mẹ́nu kan ìwà dáadáa tí ọmọbìnrin yìí ń hù nígbà tí òun jẹ́ olùkọ́ rẹ̀ nílé ìwé. Bó ṣe di pé olùkọ́ yìí bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nìyẹn o, tó sì dẹni tó tẹ́wọ́ gba ẹ̀kọ́ òtítọ́. Láìsí àní-àní, ohun pàtàkì kan tẹ́ ẹ lè fi máa yin Jèhófà ni ìwà yín!

18. Kí ni èwe kan lè ṣe tó bá ń ṣòro fún un láti bẹ̀rẹ̀ ìwàásù nípa Bíbélì àti Jèhófà Ọlọ́run?

18 Ǹjẹ́ ó máa ń ṣòro fún ọ nígbà mìíràn láti bẹ̀rẹ̀ ìwàásù nílé ìwé? Ó máa ń ṣòro fáwọn èwe mìíràn. Àmọ́, o lè ṣe ohun tó lè jẹ́ kí àwọn èèyàn máa fúnra wọn bi ọ́ ní ìbéèrè nípa ìgbàgbọ́ rẹ. Bí àpẹẹrẹ, tí ilé ìwé yín bá gbà á láyè, o ò ṣe kó àwọn ìwé wa tó ń ṣàlàyé Bíbélì dání lọ sílé ìwé, kó o máa kà wọ́n nígbà ìjáde ìjẹun tàbí láwọn ìgbà mìíràn tí wọ́n bá gbà kẹ́ ẹ máa ka irú ìwé bẹ́ẹ̀? Ìyẹn lè jẹ́ kí àwọn ọmọ ilé ìwé yín bi ọ́ nípa ohun tó ò ń kà. Tó o bá ń dá wọn lóhùn tó o sì ń sọ ohun tó o gbádùn nínú àpilẹ̀kọ kan tàbí nínú ìwé tó ò ń kà lọ́wọ́, kó o tó mọ̀ ẹ̀ẹ́ ti bá ọ̀rọ̀ lọ jìnnà. Má gbàgbé láti máa bi wọ́n ní ìbéèrè láti fi mọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Fara balẹ̀ tẹ́tí sí wọn, kó o sì sọ ohun tó o ti kọ́ nínú Bíbélì fún wọn. Ọ̀pọ̀ àwọn èwe ló ń yin Ọlọ́run nílé ìwé, gẹ́gẹ́ bí àwọn ìrírí tó wà lójú ìwé 29 ṣe fi hàn. Èyí ń fún wọn láyọ̀ gidigidi, ó sì ń mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ Jèhófà.

19. Báwo ni àwọn èwe ṣe lè túbọ̀ já fáfá nínú iṣẹ́ ìwàásù láti ilé dé ilé?

19 Ìwàásù láti ilé dé ilé ni ọ̀nà tó múná dóko jù lọ téèyàn lè fi máa yin Jèhófà. Bí o kò bá tíì bẹ̀rẹ̀ sí wàásù lóde ẹ̀rí, o ò ṣe gbìyànjú kí ìwọ náà bẹ̀rẹ̀ sí wàásù láìpẹ́? Bó o bá ti ń wàásù, ǹjẹ́ àwọn nǹkan mìíràn tún wà tó o tún lè ṣe? Bí àpẹẹrẹ, dípò tí wàá fi máa sọ ọ̀rọ̀ kan náà ní gbogbo ẹnu ọ̀nà tó o bá dé, tún wá ọ̀nà láti mọ àwọn nǹkan mìíràn tó o tún lè máa sọ. O lè sọ pé kí àwọn òbí rẹ tàbí àwọn míì tó nírìírí nínú iṣẹ́ ìwàásù ràn ọ́ lọ́wọ́ kó o lè tún mọ ọ̀nà míì tí wàá lè gbà gbọ́rọ̀ kalẹ̀ lóde ẹ̀rí. Kọ́ bó o ṣe lè mọ Bíbélì lò dáadáa àti bó o ṣe lè mọ ìpadàbẹ̀wò ṣe dáadáa tàbí bó o ṣe lè bẹ̀rẹ̀ sí báni ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (1 Tímótì 4:15) Bó o bá ṣe ń yin Jèhófà sí i ní àwọn ọ̀nà wọ̀nyẹn, bẹ́ẹ̀ ni wàá ṣe túbọ̀ já fáfá sí i, wàá sì túbọ̀ máa gbádùn iṣẹ́ ìwàásù.

Ìgbà Wo Ló Yẹ Kẹ́ Ẹ Bẹ̀rẹ̀ sí Yin Jèhófà?

20. Kí nìdí tí kò fi yẹ káwọn ọ̀dọ́ máa rò pé ọmọ kékeré ṣì làwọn pé àwọn ò tíì lè máa yin Jèhófà?

20 Nínú ìbéèrè mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tá a lá a fẹ́ sọ̀rọ̀ lé lórí, èyí tó gbẹ̀yìn yìí ló rọrùn láti dáhùn jù lọ. Ẹ wo bí Bíbélì ṣe dáhùn rẹ̀ ní tààràtà, ó ní: “Rántí Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá nísinsìnyí, ní àwọn ọjọ́ tí o wà ní ọ̀dọ́kùnrin.” (Oníwàásù 12:1) Bẹ́ẹ̀ ni o, ìsinsìnyí gan-an ló yẹ kẹ́ ẹ bẹ̀rẹ̀ sí yin Jèhófà. Àmọ́ ẹ lè máa sọ pé: “Ọmọ kékeré ṣì ni mí, mi ò tíì lè yin Jèhófà báyìí. Mi ò tíì mọ ohun tí màá sọ dáadáa. Ó yẹ kí n dàgbà sí i kí n tó bẹ̀rẹ̀.” Àwọn èwe kan náà ti rò bẹ́ẹ̀ nígbà kan rí. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jeremáyà wà ní ọ̀dọ́, ó sọ fún Jèhófà pé: “Págà, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ! Kíyè sí i, èmi kò tilẹ̀ mọ ọ̀rọ̀ sọ, nítorí pé ọmọdé lásán ni mí.” Jèhófà ní kó má bẹ̀rù rárá, pé kó sáà máa sọ̀rọ̀ òun fáwọn èèyàn. (Jeremáyà 1:6, 7) Bákan náà, kò sí ohun tó yẹ kó mú wa máa bẹ̀rù nígbà tá a bá ń yin Jèhófà. Ìdí ni pé kò sí ohunkóhun tó lè fẹ́ pa wá lára tí agbára Jèhófà kò lè ṣẹ́gun.—Sáàmù 118:6.

21, 22. Kí nìdí tí Bíbélì fi fi àwọn èwe tó ń yin Jèhófà wé ìrì tó ń sẹ̀, kí sì nìdí tí àfiwé yẹn fi dára gan-an?

21 Nítorí náà, a rọ ẹ̀yin èwe pé kẹ́ ẹ má ṣe bẹ̀rù láti máa yin Jèhófà o! Ìgbà tẹ́ ẹ ṣì wà ní èwe yìí gan-an ló dára jù kẹ́ ẹ bẹ̀rẹ̀ sí ṣe iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì ju gbogbo iṣẹ́ lọ lóde òní. Tẹ́ ẹ bá ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣe bẹ́ẹ̀ ẹ óò di ara ìdílé àgbàyanu kan tí àwọn kan lára wọn wà lọ́run tí àwọn tó kù wà láyé, ìyẹn ni ìdílé àwọn tó ń yin Jèhófà. Inú Jèhófà yóò dùn pé ẹ di ara àwọn tó wà nínú ìdílé yìí. Ẹ wo ọ̀rọ̀ tí onísáàmù náà sọ fún Jèhófà, ó ní: “Àwọn ènìyàn rẹ yóò fi tinútinú yọ̀ǹda ara wọn ní ọjọ́ ẹgbẹ́ ológun rẹ. Nínú ọlá ńlá ìjẹ́mímọ́, láti inú ilé ọlẹ̀ ọ̀yẹ̀, ìwọ ní àwùjọ rẹ ti àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n rí bí ìrì tí ń sẹ̀.”—Sáàmù 110:3.

22 Bí oòrùn àárọ̀ bá tàn sí ìrì tó sẹ̀ káàkiri ní àárọ̀ kùtùkùtù, ǹjẹ́ kì í wuni? Ìrì yìí máa ń mára tuni, wọ́n máa dán ń gbinrin, wọ́n sì sábà máa ń bolẹ̀. Bí Jèhófà ṣe ń wo ẹ̀yin èwe tẹ́ ẹ̀ ń yìn ín ní gbogbo ìgbà ní àkókò tó le koko yìí nìyẹn. Ó dájú pé bí ẹ ṣe ń yin Jèhófà ń múnú rẹ̀ dùn gan-an ni. (Òwe 27:11) Nítorí náà, ẹ̀yin èwe, ẹ sa gbogbo ipá yín láti máa yin Jèhófà!

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Kí ni àwọn ìdí pàtàkì tó fi yẹ ká máa yin Jèhófà?

• Àwọn àpẹẹrẹ wo látinú Bíbélì ló fi hàn pé àwọn èwe lè yin Jèhófà lọ́nà tó máa wọ àwọn èèyàn lọ́kàn?

• Báwo làwọn èwe ṣe lè yin Jèhófà lóde òní?

• Ìgbà wo ló yẹ kí àwọn èwe bẹ̀rẹ̀ sí yin Jèhófà, kí sì nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Bí ọ̀rẹ́ rẹ bá mọ ohun kan ṣe dáadáa, ǹjẹ́ o ò ní ròyìn rẹ̀ fún àwọn ẹlòmíràn?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Àwọn ọmọ ilé ìwé yín lè fẹ́ mọ̀ nípa ohun tó o gbà gbọ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Bí o bá fẹ́ máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù lọ́nà tó túbọ̀ dára sí i sọ pé kí àwọn Ẹlẹ́rìí tó nírìírí jù ọ́ lọ ràn ọ́ lọ́wọ́