Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Pèsè Ohun Tí Ìdílé Yín Nílò

Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Pèsè Ohun Tí Ìdílé Yín Nílò

Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Pèsè Ohun Tí Ìdílé Yín Nílò

“Bí ẹnì kan kò bá pèsè fún àwọn tí í ṣe tirẹ̀, . . . ó ti sẹ́ ìgbàgbọ́.”—1 TÍMÓTÌ 5:8.

1, 2. (a) Kí nìdí tó fi máa ń wúni lórí tá a bá rí ìdílé tí gbogbo wọn jọ ń wá sípàdé ìjọ? (b) Kí ni díẹ̀ lára àwọn nǹkan tí ìdílé máa ń dojú kọ kí wọ́n tó lè dé ìpàdé lásìkò?

 TÓ O bá wò yí ká inú Gbọ̀ngàn Ìjọba kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀, ó ṣeé ṣe kó o rí àwọn ọmọ tó wọṣọ tó mọ́ tí wọ́n sì múra dáadáa tí wọ́n jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn òbí wọn. Ǹjẹ́ ìfẹ́ téèyàn rí pé ó hàn nínú irú ìdílé bẹ́ẹ̀, ìyẹn bí wọ́n ṣe fẹ́ràn Jèhófà tí wọ́n sì fẹ́ràn ara wọn kì í wúni lórí? Àmọ́, èèyàn lè má tètè rántí pé irú ìdílé bẹ́ẹ̀ máa ń sapá gan-an kí wọ́n tó lè dé ìpàdé lásìkò.

2 Lọ́pọ̀ ìgbà, ńṣe ni ọwọ́ àwọn òbí máa ń dí látàárọ̀ ṣúlẹ̀. Àgàgà tó bá tún jẹ́ ọjọ́ ìpàdé, gbogbo ará ilé ló máa ń ní ọ̀pọ̀ iṣẹ́ láti ṣe. Wọ́n á se oúnjẹ, wọ́n á ṣe iṣẹ́ ilé, àwọn ọmọ á sì tún ṣe iṣẹ́ iléèwé wọn. Èjìká àwọn òbí lọ̀pọ̀ jù lọ iṣẹ́ náà sì já lé, torí àwọn ló máa rí i dájú pé kálukú wẹ̀, wọ́n jẹun, wọ́n sì tètè múra ìpàdé. Ká má gbàgbé o pé àwọn ọmọ lè dá nǹkan míì sílẹ̀ lásìkò tí kò rọgbọ rárá fún òbí. Bí àpẹẹrẹ, aṣọ ọmọ tó dàgbà jù lè fà ya níbi tó ti ń ṣeré. Oúnjẹ ọmọ tó kéré jù lè dà nù níbi tó ti ń jẹ ẹ́. Àwọn ọmọ lè bẹ̀rẹ̀ sí pariwo mọ́ra wọn. (Òwe 22:15) Kí ni nǹkan wọ̀nyí lè fà? Ó lè jẹ́ kí gbogbo ètò tí òbí ti ń ṣe bọ̀ dà rú. Síbẹ̀, irú àwọn ìdílé bẹ́ẹ̀ á ṣì ṣe gbogbo ohun tó bá gbà láti rí i pé àwọn dé Gbọ̀ngàn Ìjọba kí ìpàdé tó bẹ̀rẹ̀. Ó máa ń wúni lórí gan-an ni láti rí irú àwọn ìdílé bẹ́ẹ̀ nípàdé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, látọdún dé ọdún títí àwọn ọmọ wọn á fi dàgbà táwọn náà á máa sin Jèhófà nìṣó!

3. Kí ló jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ò fọwọ́ kékeré mú ọ̀ràn ìdílé?

3 Iṣẹ́ ẹ̀yin òbí lórí ọmọ kì í rọrùn nígbà míì, kódà ó máa ń gbomi mu, àmọ́ ó dájú pé inú Jèhófà dùn sí yín nítorí ó mọ̀ pé iṣẹ́ ribiribi lẹ̀ ń ṣe. Jèhófà ló dá ètò ìdílé sílẹ̀. Ìdí nìyẹn tí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ fi sọ pé ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni gbogbo ìdílé ti “gba orúkọ,” tó túmọ̀ sí pé òun ló dá a sílẹ̀. (Éfésù 3:14, 15) Nítorí náà, tí ẹ̀yin òbí bá ń sapá láti ṣe ojúṣe yín bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, Olúwa Ọba Aláṣẹ ayé òun ọ̀run lẹ̀ ń gbé ga. (1 Kọ́ríńtì 10:31) Iyì ńláǹlà nìyẹn sì jẹ́ fún yín, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Òun ló fi bá a mu pé ká gbé iṣẹ́ tí Jèhófà ní káwọn òbí máa ṣe yẹ̀ wò. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a ó sọ̀rọ̀ nípa báwọn òbí ṣe lè ṣe iṣẹ́ yìí nípa pípèsè ohun tí ìdílé wọn nílò. Ẹ jẹ́ ká wo ọ̀nà mẹ́ta tí Ọlọ́run ní káwọn òbí gbà máa pèsè fún ìdílé wọn.

Ẹ Pèsè Ohun Tí Ìdílé Yín Nílò Nípa Ti Ara

4. Kí ni Jèhófà sọ fáwọn òbí lórí ọ̀ràn gbígbọ́ bùkátà àwọn ọmọ?

4 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Dájúdájú, bí ẹnì kan kò bá pèsè fún àwọn tí í ṣe tirẹ̀, àti ní pàtàkì fún àwọn tí í ṣe mẹ́ńbà agbo ilé rẹ̀, ó ti sẹ́ ìgbàgbọ́, ó sì burú ju ẹni tí kò ní ìgbàgbọ́.” (1 Tímótì 5:8) Ta ni “ẹnì kan” tí Pọ́ọ̀lù sọ níbí? Olórí ìdílé ni, tó sábà máa ń jẹ́ bàbá. Àmọ́, Ọlọ́run yan iṣẹ́ pàtàkì fún obìnrin pẹ̀lú, ìyẹn ni pé kó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún ọkọ rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 2:18) Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àwọn obìnrin sábà máa ń ran ọkọ wọn lọ́wọ́ láti pèsè fún ìdílé. (Òwe 31:13, 14, 16) Lóde òní, ìdílé olóbìí kan pọ̀ gan-an. a Ọ̀pọ̀ Kristẹni tó jẹ́ òbí tó ń dá nìkan gbọ́ bùkátà ìdílé ló sì ń ṣe gudugudu méje lẹ́nu iṣẹ́ yìí. Àmọ́ ṣá, ohun tó ti dáa ni pé kí bàbá àti ìyá jọ wà pa pọ̀ nínú ìdílé, kí bàbá sì máa ṣe ojúṣe rẹ̀ bíi baba nínú ìdílé.

5, 6. (a) Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìṣòro tó máa ń dojú kọ àwọn tó ń gbìyànjú láti gbọ́ bùkátà àwọn èèyàn wọn? (b) Èrò wo ló yẹ káwọn Kristẹni tó ń gbọ́ bùkátà ìdílé ní nípa iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ kí wọ́n má bàa rẹ̀wẹ̀sì nípa ọ̀rọ̀ gbígbọ́ bùkátà ìdílé?

5 Nínú 1 Tímótì 5:8, kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé káwọn òbí pèsè fún ìdílé? Àwọn ẹsẹ tó ṣáájú àtèyí tó wà lẹ́yìn ẹsẹ yẹn jẹ́ ká mọ̀ pé ohun tí ìdílé nílò nípa ti ara ló ní lọ́kàn. Láyé òde òní, ohun tójú olórí ìdílé ń rí kó tó lè gbọ́ bùkátà ìdílé kò kéré. Ìṣòro àìríná-àìrílò pọ̀ jákèjádò ayé, bẹ́ẹ̀ làwọn iléeṣẹ́ ń dá àwọn òṣìṣẹ́ dúró, tí àwọn tí kò ríṣẹ́ ń pọ̀ sí i, tí àtigbọ́bùkátà sì túbọ̀ ń nira sí i. Kí ni ẹni tó ń gbọ́ bùkátà ìdílé lè ṣe kí ìṣòro wọ̀nyí má bàa kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá a?

6 Ó yẹ kí ẹni tó ń pèsè fún ìdílé rántí pé iṣẹ́ tí Jèhófà gbé lé òun lọ́wọ́ lòun ń ṣe. Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí Pọ́ọ̀lù láti sọ yìí fi hàn pé ẹni tó bá lè pèsè fún ìdílé rẹ̀ àmọ́ tó kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀ kò yàtọ̀ sí ẹni tó “sẹ́ ìgbàgbọ́.” Kò sì sí Kristẹni tó máa fẹ́ di irú èèyàn bẹ́ẹ̀ lójú Ọlọ́run rẹ̀. Àmọ́ o, ó dunni pé ọ̀pọ̀ èèyàn lóde òní ló ti ya “aláìní ìfẹ́ni àdánidá.” (2 Tímótì 3:1, 3) Àní àìmọye bàbá ló ti fi ojúṣe wọn sílẹ̀ láìṣe, tí wọ́n wá ń jẹ́ kí ìdílé wọn máa ráre. Àwọn ọkọ tó jẹ́ Kristẹni kò gbọ́dọ̀ ya irú ìkà èèyàn bẹ́ẹ̀ tí kì í pèsè fún àwọn tí í ṣe tirẹ̀. Àwọn Kristẹni kì í ṣe bíi tàwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ tó bá dọ̀rọ̀ ká gbọ́ bùkátà ìdílé. Àní bó bá tiẹ̀ jẹ́ iṣẹ́ táwọn èèyàn kà sí iṣẹ́ lébìrà ni wọ́n rí, wọ́n máa ń fọwọ́ pàtàkì mú un gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà kan táwọn lè gbà gbọ́ bùkátà àwọn ará ilé wọn láti lè múnú Jèhófà Ọlọ́run dùn.

7. Kí nìdí tó fi dára pé káwọn òbí ronú lórí àpẹẹrẹ tí Jésù fi lélẹ̀?

7 Bí àwọn olórí ìdílé bá ń ronú lórí àpẹẹrẹ pípé tí Jésù fi lélẹ̀, ìyẹn á ràn wọ́n lọ́wọ́. Ẹ rántí pé àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì sọ pé Jésù yóò jẹ́ “Baba Ayérayé” fún wa. (Aísáyà 9:6, 7) Níwọ̀n bí Jésù ti jẹ́ “Ádámù ìkẹyìn,” òun ló rọ́pò “Ádámù ọkùnrin àkọ́kọ́” tó sì di baba ayérayé fún gbogbo ẹni tó bá ní ìgbàgbọ́. (1 Kọ́ríńtì 15:45) Jésù jẹ́ baba tó tó baba í ṣe, kò dà bí Ádámù tó jẹ́ baba onímọtara-ẹni-nìkan tó ń gbọ́ tara ẹ̀. Bíbélì sọ ohun tí Jésù ṣe, ó ní: “Nípa èyí ni àwa fi wá mọ ìfẹ́, nítorí ẹni yẹn fi ọkàn rẹ̀ lélẹ̀ fún wa.” (1 Jòhánù 3:16) Jésù fínnú fíndọ̀ fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí àwọn èèyàn. Kódà, ó tiẹ̀ tún ń fi ire táwọn ẹlòmíràn ṣáájú tara rẹ̀ nínú àwọn ohun tí kò tó nǹkan pàápàá. Á dára gan-an kí ẹ̀yin òbí tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ tí Jésù ní.

8, 9. (a) Ẹ̀kọ́ wo làwọn òbí lè rí kọ́ lára àwọn ẹyẹ nípa bí àwọn òbí ṣe lè fi ìfẹ́ tó jinlẹ̀ pèsè fáwọn ọmọ wọn? (b) Báwo ní ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni tó jẹ́ òbí ṣe ń lo ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ?

8 Àwọn òbí lè rí ẹ̀kọ́ gidi kọ́ nípa bó ṣe yẹ kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ìdílé wọn jinlẹ̀jinlẹ̀ látinú ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fáwọn tí wọ́n jẹ́ èèyàn Ọlọ́run tí wọ́n ti ya ìyàkuyà. Ó ní: “Iye ìgbà tí mo fẹ́ láti kó àwọn ọmọ rẹ jọpọ̀ ti pọ̀ tó, ní ọ̀nà tí àgbébọ̀ adìyẹ fi ń kó àwọn òròmọdìyẹ rẹ̀ jọpọ̀ lábẹ́ àwọn ìyẹ́ apá rẹ̀!” (Mátíù 23:37) Àpẹẹrẹ bí àgbébọ̀ ṣe máa ń dáàbò bo àwọn ọmọ rẹ̀ lábẹ́ ìyẹ́ apá rẹ̀ ni Jésù ń tọ́ka sí níhìn-ín. Ká sòótọ́, ẹ̀kọ́ tó pọ̀ làwọn òbí lè rí kọ́ látinú ìṣe ìyá ẹyẹ, ìyẹn bó ṣe máa ń fara wewu nítorí àtilè dáàbò bo àwọn ọmọ rẹ̀. Ohun táwọn ẹyẹ tiẹ̀ ńṣe fáwọn ọmọ wọn lójoojúmọ́ pàápàá wúni lórí gan-an. Ṣe ni wọ́n máa ń fò lọ fò bọ̀ látàárọ̀ ṣúlẹ̀ láti lọ máa wá oúnjẹ wá. Kódà bó tiẹ̀ rẹ̀ wọ́n gan-an nígbà tí wọ́n dé, wọ́n á ṣì tiraka láti fi oúnjẹ tí wọ́n rí sẹ́nu àwọn ọmọ wọn. Bẹ́ẹ̀, bóúnjẹ yìí ṣe ń dẹ́nu wọn tàìdẹ́nu wọn ni wọ́n á tún bẹ̀rẹ̀ sí ké fún òmíràn. Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn ohun míì tí Ọlọ́run dá ló ní “ọgbọ́n àdámọ́ni” tí wọ́n ń lò bákan náà láti fi pèsè nǹkan fáwọn ọmọ wọn.—Òwe 30:24.

9 Irú ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ tó ga bẹ́ẹ̀ lẹ̀yin òbí tó jẹ́ Kristẹni kárí ayé ní. Kàkà kí àwọn ọmọ yín jìyà, ńṣe lẹ máa ń fúnra yín fara gba ìyà ọ̀hún. Pẹ̀lúpẹ̀lù, ojoojúmọ́ lẹ̀ ń ṣe ohun kan tàbí òmíràn láti pèsè àwọn ohun tí àwọn ará ilé yín nílò. Òwúrọ̀ kùtù lọ̀pọ̀ nínú yín ti ń jí sẹ́nu iṣẹ́ bó-o-jí o-jí-mi. Iṣẹ́ ribiribi lẹ̀ ń ṣe láti rí i pé ìdílé yín róúnjẹ aṣaralóore jẹ. Bẹ́ẹ̀ náà lẹ̀ ń sa gbogbo ipá yín láti rí i pé àwọn ọmọ yín wọ aṣọ tó dáa, pé wọ́n ríbi tó bójú mu gbé, pé wọ́n sì kàwé tó máa tó wọn gbọ́ bùkátà ara wọn. Bẹ́ ẹ ṣe ń sa gbogbo ipá yín nìyẹn lójoojúmọ́, látọdún dé ọdún. Ó dájú pé ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ tẹ́ ẹ ní àti bẹ́ ẹ ṣe ń ṣe ojúṣe yín láìṣàárẹ̀ ń múnú Jèhófà dùn jọjọ! (Hébérù 13:16) Àmọ́ ṣá o, ẹ má gbàgbé pé àwọn ọ̀nà kan wà tó tún ṣe pàtàkì ju èyí lọ tó yẹ kẹ́ ẹ ti máa pèsè fáwọn tí í ṣe tiyín.

Ẹ Pèsè fún Ìdílé Yín Nípa Tẹ̀mí

10, 11. Kí ni ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ fún ọmọ èèyàn láti ní, kí sì ni àwọn Kristẹni tó jẹ́ òbí ní láti kọ́kọ́ ṣe kí wọ́n tó lè pèsè nǹkan yìí fáwọn ọmọ wọn?

10 Pípèsè nǹkan tẹ̀mí fún ìdílé ṣe pàtàkì ju pípèsè ohun tí wọ́n nílò nípa tara lọ. Jésù sọ pé: “Ènìyàn kì yóò wà láàyè nípasẹ̀ oúnjẹ nìkan ṣoṣo, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo àsọjáde tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà.” (Mátíù 4:4; 5:3) Kí lẹ̀yin òbí lè ṣe kẹ́ ẹ lè máa pèsè ohun tí ìdílé yín nílò nípa tẹ̀mí?

11 Ẹsẹ Bíbélì tá a sábà máa ń tọ́ka sí jù láti fi ṣàlàyé kókó yìí ni Diutarónómì orí kẹfà, ẹsẹ karùn-ún sí ìkeje. Ẹ jọ̀wọ́ ẹ ṣí Bíbélì yín kẹ́ ẹ ka àwọn ẹsẹ yìí. Ẹ kíyè sí i pé àwọn òbí ni ibẹ̀ sọ pé kó kọ́kọ́ ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Ọlọ́run, kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà kí wọ́n sì fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ́kàn. Bẹ́ẹ̀ ni o, ẹ ní láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójú méjèèjì, ìyẹn ni pé kẹ́ ẹ máa ka Bíbélì déédéé kẹ́ ẹ sì máa ṣàṣàrò lé e lórí, kẹ́ ẹ lè mọ àwọn ọ̀nà, ìlànà àti òfin Jèhófà jinlẹ̀jinlẹ̀ kẹ́ ẹ sì tún fẹ́ràn wọn. Èyí á jẹ́ kí àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ inú Bíbélì tó fani mọ́ra kún inú ọkàn yín, tí inú yín yóò sì máa dùn pé ẹ̀ ń sin Jèhófà, tí ẹ ó máa bọ̀wọ̀ fún un tẹ́ ẹ ó sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ẹ óò dẹni tó ní ọ̀pọ̀ yanturu ohun rere tẹ́ ẹ lè gbìn sọ́kàn àwọn ọmọ yín.—Lúùkù 6:45.

12. Báwo làwọn òbí ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nígbà tó bá kan ọ̀rọ̀ gbígbin ẹ̀kọ́ Bíbélì sọ́kàn ọmọ wọn?

12 Àwọn òbí tí wọ́n jẹ́ ẹni tẹ̀mí máa ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn inú Diutarónómì 6:7, èyí tó sọ pé kí wọ́n máa “fi ìtẹnumọ́ gbin” ọ̀rọ̀ Jèhófà sínú àwọn ọmọ wọn ní gbogbo ìgbà. Láti “fi ìtẹnumọ́ gbin” nǹkan sínú èèyàn túmọ̀ sí pé ká kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ ká sì máa sọ ẹ̀kọ́ ọ̀hún lásọtúnsọ láti lè tẹ̀ ẹ́ mọ́ onítọ̀hún lọ́kàn. Jèhófà mọ̀ dáadáa pé gbogbo wa là ń fẹ́ àsọtúnsọ kí ẹ̀kọ́ tá à ń kọ́ tó lè yé wa, pàápàá àwọn ọmọdé. Ìyẹn ló mú kí Jésù máa sọ̀rọ̀ lásọtúnsọ nígbà tó ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tó ń kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ kí wọ́n má ṣe jẹ́ agbéraga àti abánidíje, ó lo onírúurú ọ̀nà láti fi sọ ìlànà yẹn lásọtúnsọ. Ó ṣàlàyé rẹ̀ fún wọn, ó ṣàpèjúwe rẹ̀, ó tún fi àpẹẹrẹ rẹ̀ hàn wọ́n. (Mátíù 18:1-4; 20:25-27; Jòhánù 13:12-15) Àmọ́ o, ní gbogbo ìgbà tí Jésù fi ń kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ kò bínú sí wọn rárá. Bákan náà, ó yẹ káwọn òbí wá ọ̀nà tí wọ́n lè máa gbà kọ́ àwọn ọmọ wọn ní àwọn ohun tá a máa ń kọ́kọ́ mọ̀ nínú ẹ̀kọ́ òtítọ́, kí wọ́n sì máa fi sùúrù sọ àwọn ìlànà Jèhófà fáwọn ọmọ wọn lásọtúnsọ títí táá fi wọ̀ wọ́n lọ́kàn, tí wọ́n á sì máa tẹ̀ lé e.

13, 14. Àwọn ìgbà wo ni àwọn òbí lè gbin ẹ̀kọ́ Bíbélì sí àwọn ọmọ wọn lọ́kàn, àwọn ìwé wo ni wọ́n sì lè lò?

13 Ìgbà ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé jẹ́ àkókò tó dára láti kọ́ àwọn ọmọ nírú ẹ̀kọ́ yìí. Ká sòótọ́, tí ìdílé bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa pọ̀ déédéé, tí wọ́n ń ṣe é tayọ̀tayọ̀ àti lọ́nà tó ń gbéni ró, ìdílé náà á dúró sán-ún nípa tẹ̀mí. Irú ìkẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ ni ìdílé àwọn Kristẹni jákèjádò ayé máa ń gbádùn. Wọ́n máa ń lo ìwé tí ètò Jèhófà pèsè, wọ́n sì máa ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́nà tó máa ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti yanjú ìṣòro wọn. Ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà wúlò gan-an láti fi ṣe èyí gẹ́gẹ́ bí ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè-Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́ ṣe wúlò. b Àmọ́ o, ìgbà ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé nìkan kọ́ ni òbí lè kọ́ ọmọ lẹ́kọ̀ọ́.

14 Diutarónómì 6:7 fi hàn pé onírúurú àkókò lẹ̀yin òbí lè bá àwọn ọmọ sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tẹ̀mí. Bóyá ẹ jọ ń rìnrìn àjò ni o, ẹ jọ ń ṣiṣẹ́ kan pọ̀ ni o, tàbí ẹ jọ ń ṣe fàájì, ẹ wọ́nà láti fún àwọn ọmọ ní ìtọ́ni nípa tẹ̀mí. Àmọ́ ṣá, kì í ṣe pé kẹ́ ẹ kúkú wá máa rọ̀jò ẹ̀kọ́ Bíbélì lé wọn lórí o. Ńṣe ni kẹ́ ẹ kàn máa jẹ́ kí ìfọ̀rọ̀wérọ̀ yín dá lórí ohun tó ń gbéni ró, tó sì jẹ mọ́ nǹkan tẹ̀mí. Bí àpẹẹrẹ, ìwé ìròyìn Jí! máa ń ní àwọn àpilẹ̀kọ tó dá lórí onírúurú ẹ̀kọ́. Irú àwọn àpilẹ̀kọ bẹ́ẹ̀ lè mú kó ṣeé ṣe fún un yín láti jọ fọ̀rọ̀ wérọ̀ lórí àwọn ẹranko tí Jèhófà dá, àwọn ibi ẹlẹ́wà tó wà káàkiri ayé, àti bí àṣà àti ìṣe àwọn ọmọ èèyàn ṣe yàtọ̀ síra lóríṣiríṣi ọ̀nà tó wúni lórí. Irú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ wọ̀nyẹn lè mú kí àwọn ọmọ túbọ̀ fẹ́ láti máa ka àwọn ìwé tí ẹrú olóòótọ́ àti olóye ń pèsè.—Mátíù 24:45-47.

15. Báwo làwọn òbí ṣe lè mú kí ọmọ wọn wo iṣẹ́ ìwàásù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ tó ń gbádùn mọ́ni tó sì ń ṣeni láǹfààní?

15 Bí ẹ bá ń bá àwọn ọmọ yín fọ̀rọ̀ wérọ̀ lórí àwọn nǹkan tó gbéni ró, ìyẹn máa jẹ́ kẹ́ ẹ lè kọ́ wọn ní ohun tẹ̀mí mìíràn tó ṣe pàtàkì. Ó yẹ kí ọmọ àwọn Kristẹni mọ bí wọ́n ṣe lè máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa ìgbàgbọ́ wọn dáadáa. Nígbà tẹ́ ẹ bá ń sọ̀rọ̀ lórí kókó kan tó wù yín nínú Ilé Ìṣọ́ tàbí Jí!, ẹ lè jẹ́ kí wọ́n mọ bí wọ́n ṣe lè lo kókó náà lóde ẹ̀rí. Bí àpẹẹrẹ, ẹ lè béèrè pé: “Ǹjẹ́ kò ní dáa gan-an káwọn èèyàn mọ̀ pé Jèhófà ló ṣe nǹkan yìí? Báwo lẹ rò pé a ṣe lè ṣàlàyé kókó yìí fẹ́nì kan kí inú rẹ̀ sì dùn sí i?” Irú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ bẹ́ẹ̀ lè mú kó máa wu àwọn ọmọ gan-an láti bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa ohun tí wọ́n ń kọ́. Nígbà táwọn ọmọ yín bá wá bá yín lọ sóde ẹ̀rí, wọ́n á rí bá a ṣe lè fi àwọn kókó bẹ́ẹ̀ báni sọ̀rọ̀ látinú àpẹẹrẹ tiyín. Wọ́n á tún lè rí i pé iṣẹ́ ìwàásù jẹ́ iṣẹ́ aláyọ̀ tó ń wúni lórí, tó sì ń gbádùn mọ́ni.—Ìṣe 20:35.

16. Ẹ̀kọ́ wo làwọn ọmọ lè rí kọ́ bí wọ́n ṣe ń gbọ́ àdúrà àwọn òbí wọn?

16 Àwọn òbí tún lè pèsè ohun tọ́mọ wọ́n nílò nípa tẹ̀mí nígbà tí wọ́n bá ń gbàdúrà. Jésù kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní àdúrà gbígbà, wọ́n sì tún jọ gbàdúrà pọ̀ lọ́pọ̀ ìgbà. (Lúùkù 11:1-13) Ẹ̀yin ẹ wo bí wọ́n á ṣe kẹ́kọ̀ọ́ tó bí wọ́n ṣe ń bá Ọmọ Ọlọ́run gan-gan gbàdúrà pọ̀! Bákan náà, ọmọ yín lè rí ẹ̀kọ́ tó pọ̀ kọ́ látinú àdúrà tiyín. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n lè tipa bẹ́ẹ̀ mọ̀ pé Jèhófà ń fẹ́ ká máa bá òun sọ̀rọ̀ fàlàlà látọkàn wa wá, ká máa sọ gbogbo àníyàn ọkàn wa fóun. Ní tòótọ́, àdúrà yín lè kọ́ ọmọ yín láwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì kan nípa tẹ̀mí. Ẹ̀kọ́ náà ni pé: Wọ́n lè ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú Baba wọn ọ̀run.—1 Pétérù 5:7.

Ẹ Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Ọmọ Yín

17, 18. (a) Báwo ni Bíbélì ṣe jẹ́ kó hàn pé ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn òbí fẹ́ràn àwọn ọmọ wọn? (b) Báwo ni àwọn bàbá ṣe lè fi hàn pé àwọn fẹ́ràn àwọn ọmọ wọn gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti ṣe?

17 Ó dájú pé àwọn ọmọ tún ń fẹ́ káwọn òbí fẹ́ràn àwọn. Bíbélì jẹ́ káwọn òbí mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì gan-an kí wọ́n ṣe èyí pẹ̀lú. Bí àpẹẹrẹ, ó rọ àwọn ọ̀dọ́bìnrin tó ti lọ́kọ pé kí wọ́n “nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn.” Ó sì fi hàn pé táwọn àgbà obìnrin bá pe orí wọn wálé, wọ́n á lè nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn. (Títù 2:4) Lóòótọ́, ohun tó bọ́gbọ́n mu ni pé kí òbí fẹ́ràn ọmọ rẹ̀. Èyí á kọ́ ọmọ náà ní bá a ṣe ń fẹ́ràn èèyàn, á sì ṣe é láǹfààní jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀. Àmọ́, béèyàn ò bá fẹ́ràn ọmọ tó bí, ìwà òmùgọ̀ gbáà ni. Ó máa ń fa ìrora ńláǹlà, ó sì fi hàn pé onítọ̀hún ò tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà, tó fi ìfẹ́ ńláǹlà hàn sí wa bó tilẹ̀ jẹ́ pé a jẹ́ aláìpé.—Sáàmù 103:8-14.

18 Jèhófà gan-an ló kọ́kọ́ fìfẹ́ hàn sí àwa ọmọ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé. Jòhánù kìíní orí kẹrin ẹsẹ ìkọkàndínlógún sọ pé, “òun ni ó kọ́kọ́ nífẹ̀ẹ́ wa.” Ẹ̀yin bàbá ní pàtàkì gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà, kẹ́ ẹ kọ́kọ́ wọ́nà láti rí i pé ìdè ìfẹ́ àárín ẹ̀yin àtọmọ yín lágbára gan-an. Bíbélì rọ àwọn baba pé kí wọ́n má ṣe máa dá àwọn ọmọ wọn lágara “kí wọ́n má bàa soríkodò.” (Kólósè 3:21) Kò sóhun tó máa ń tètè mú àwọn ọmọ kárí sọ bíi pé kí wọ́n rí i pé òbí àwọn ò fẹ́ràn àwọn tàbí pé àwọn ò já mọ́ nǹkan kan rárá lójú wọn. Á dára kí àwọn bàbá tí kì í fẹ́ sọ ọ́ jáde lẹ́nu pé àwọn fẹ́ràn ọmọ wọn rántí àpẹẹrẹ Jèhófà. Láti òkè ọ̀run ni Jèhófà ti sọ ọ́ pé òun tẹ́wọ́ gba Ọmọ òun, òun sì fẹ́ràn rẹ̀. (Mátíù 3:17; 17:5) Ìṣírí gbáà nìyẹn ní láti jẹ́ fún Jésù! Bákan náà, bí àwọn òbí bá ń sọ fáwọn ọmọ wọn látọkànwá pé àwọn fẹ́ràn wọn àti pé inú àwọn dùn sí wọn, ó máa ń mú orí àwọn ọmọ yá gágá ó sì máa ń fún wọn nígboyà.

19. Kí nìdí tí ìbáwí fi ṣe pàtàkì, ìwọ̀n wo ló sì yẹ kí àwọn Kristẹni tó jẹ́ òbí gbìyànjú láti máa ṣe é dé?

19 Àmọ́ o, ọ̀rọ̀ ẹnu nìkan kọ́ ni òbí máa fi ń fẹ́ràn ọmọ. Inú ìṣe ẹni ni ìfẹ́ tá a ní ti sábà máa ń hàn jù. Bí àwọn òbí bá ń pèsè fún ìdílé nípa tara àti tẹ̀mí, yóò hàn pé wọ́n fẹ́ràn ìdílé wọn, pàápàá tí wọ́n bá ń ṣe é lọ́nà tó fi hàn pé ìfẹ́ ló ń mú kí wọ́n ṣe é. Síwájú sí i, ọ̀nà kan táwọn òbí lè gbà fi hàn pé wọ́n fẹ́ràn ọmọ wọn ni pé kí wọ́n máa bá wọn wí. Ní tòdodo, “ẹni tí Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ni ó máa ń bá wí.” (Hébérù 12:6) Bí òbí kì í bá ń bá ọmọ wí, ńṣe ló kórìíra ọmọ rẹ̀! (Òwe 13:24) Tó bá sì di pé ká béèyàn wí Jèhófà kì í ṣe é láṣejù. Ńṣe ló ń báni wí “dé ìwọ̀n tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.” (Jeremáyà 46:28) Ní tòótọ́, kì í rọrùn fún àwọn òbí tó jẹ́ ẹ̀dá aláìpé nígbà míì láti báni wí níwọ̀ntúnwọ̀nsì. Síbẹ̀, á dáa kẹ́ ẹ máa gbìyànjú láti jẹ́ kí ìbáwí yín jẹ́ ìwọ̀n tó yẹ. Bẹ́ ẹ bá ń jẹ́ kí ọmọ mọ ìbáwí ní ìbáwí, tẹ́ ẹ sì ṣe é tìfẹ́tìfẹ́, ọmọ náà yóò wúlò tó bá dàgbà, á sì máa láyọ̀. (Òwe 22:6) Ohun tí gbogbo Kristẹni tó jẹ́ òbí sì ń fẹ́ fún ọmọ nìyẹn, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?

20. Báwo làwọn òbí ṣe lè fáwọn ọmọ wọn láǹfààní tó dára jù lọ láti “yan ìyè”?

20 Tí ẹ̀yin òbí bá ń ṣe iṣẹ́ pàtàkì tí Jèhófà gbé lé e yín lọ́wọ́, tẹ́ ẹ ń pèsè fáwọn ọmọ yín nípa tara àti nípa tẹ̀mí, tẹ́ ẹ sì nífẹ̀ẹ́ wọn, èrè ńlá lẹ máa jẹ. Ẹ ó tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ káwọn ọmọ yín láǹfààní tó dára jù lọ láti “yan ìyè” kí wọ́n lè dẹni tí yóò “máa wà láàyè nìṣó.” (Diutarónómì 30:19) Àwọn ọmọ tó bá yàn láti sin Jèhófà tí wọn ò sì yà kúrò lọ́nà ìyè bí wọ́n ṣe ń dàgbà máa ń múnú àwọn òbí wọn dùn gan-an ni. (Sáàmù 127:3-5) Ìdùnnú gbére sì ni irú ìdùnnú bẹ́ẹ̀! Àmọ́, báwo làwọn èwe ṣe lè yin Jèhófà nísinsìnyí? Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e yóò ṣàlàyé kókó yìí.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Nínú àpilẹ̀kọ yìí, àwọn ọkùnrin la ó darí ọ̀rọ̀ ẹni tó yẹ kó pèsè fún ìdílé sí. Àmọ́, àwọn ìlànà tá a máa mẹ́nu bà kan àwọn obìnrin tí wọ́n jẹ́ Kristẹni tó ń gbọ́ bùkátà ìdílé.

b Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ àwọn ìwé yìí.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Kí làwọn òbí lè ṣe láti pèsè fún àwọn ọmọ wọn nípa ti ara?

• Kí làwọn òbí lè ṣe láti pèsè fún àwọn ọmọ wọn nípa tẹ̀mí?

• Kí làwọn òbí lè ṣe láti fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Ọ̀pọ̀ ẹyẹ máa ń fò lọ fò bọ̀ láti wá oúnjẹ fáwọn ọmọ wọn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Àwọn òbí fúnra wọn gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ jẹ́ ẹni tẹ̀mí ná

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20, 21]

Onírúurú àsìkò làwọn òbí lè kọ́ ọmọ wọn nípa Ẹlẹ́dàá

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

Bí àwọn òbí bá ń fi hàn pé inú àwọn dùn sáwọn ọmọ wọn, ó máa ń mú orí àwọn ọmọ yá gágá ó sì máa ń fún wọn nígboyà