Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Iṣẹ́ Ìwàásù Ń Tẹ̀ Síwájú Níbi Tí Ẹ̀sìn Kristẹni Ti Gbilẹ̀ Nígbà Ìjímìjí

Iṣẹ́ Ìwàásù Ń Tẹ̀ Síwájú Níbi Tí Ẹ̀sìn Kristẹni Ti Gbilẹ̀ Nígbà Ìjímìjí

Iṣẹ́ Ìwàásù Ń Tẹ̀ Síwájú Níbi Tí Ẹ̀sìn Kristẹni Ti Gbilẹ̀ Nígbà Ìjímìjí

ÍTÁLÌ jẹ́ orílẹ̀-èdè kan tí omi fẹ́rẹ̀ẹ́ yí po, ilẹ̀ rẹ̀ sì wọnú Òkun Mẹditaréníà. Nígbà kan, kò sí ibì kankan lágbàáyé tí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ orílẹ̀-èdè yìí ò kàn. Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn máa ń rọ́ lọ síbẹ̀ láti lọ wo àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀, odò àti òkè tó lẹ́wà gan-an àtàwọn iṣẹ́ ọnà tó kàmàmà, wọ́n sì máa ń lọ gbádùn àwọn oúnjẹ àjẹpọ́nnulá ibẹ̀. Orílẹ̀-èdè yìí tún jẹ́ ibi tí ẹ̀kọ́ Bíbélì ti gbilẹ̀ gan-an.

Àfàìmọ̀ kó máà jẹ́ pé ìgbà táwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe tí wọ́n di Kristẹni nígbà Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni padà wálé láti Jerúsálẹ́mù ni ẹ̀sìn Kristẹni tòótọ́ kọ́kọ́ dé ìlú Róòmù tó jẹ́ olú ìlú ìjọba tó ń ṣàkóso ayé nígbà yẹn. Nǹkan bí ọdún 59 Sànmánì Kristẹni ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù lọ sí ilẹ̀ Ítálì fún ìgbà àkọ́kọ́. Nígbà tó dé ìlú Pútéólì tó wà létí òkun, ó “rí àwọn ará” tí wọ́n jẹ́ onígbàgbọ́ níbẹ̀.—Ìṣe 2:5-11; 28:11-16.

Jésù àtàwọn àpọ́sítélì sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn kan yóò bẹ̀rẹ̀ sí kúrò nínú ẹ̀sìn Kristẹni tòótọ́ wọ́n á sì di apẹ̀yìndà, ọ̀rọ̀ wọn sì ṣẹ lóòótọ́ kó tó di ìparí ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni. Àmọ́, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tòótọ́ ń bá iṣẹ́ ìwàásù lọ ní pẹrẹu jákèjádò ayé kó tó di ìgbà tí ètò àwọn nǹkan yìí yóò dópin. Ítálì sì wà lára ibi tí wọ́n ti ń wàásù.—Mátíù 13:36-43; Ìṣe 20:29, 30; 2 Tẹsalóníkà 2:3-8; 2 Pétérù 2:1-3.

Àwọn Èèyàn Ò Mọyì Iṣẹ́ Ìwàásù Níbẹ̀rẹ̀

Lọ́dún 1891, Charles Taze Russell tó ń mú ipò iwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kárí ayé lọ sáwọn ìlú kan lórílẹ̀-èdè Ítálì fún ìgbà àkọ́kọ́. Láyé ìgbà yẹn, Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń jẹ́. Báwọn èèyàn ò ṣe kọbi ara sí iṣẹ́ ìwàásù Russell kò wú u lórí rárá, ìyẹn ló mú kó sọ pé: “A ò rí ohunkóhun nílẹ̀ Ítálì tó fún wa níṣìírí láti máa retí pé ìkórè yóò wà lórílẹ̀-èdè náà.” Nígbà ìrúwé ọdún 1910, Arákùnrin Russell tún padà sí Ítálì, ó sì sọ àsọyé kan ní gbọ̀ngàn ìṣeré kan tó wà láàárín ìlú Róòmù. Báwo ni ìpàdé ọ̀hún ṣe lọ sí? Ó sọ pé: “Bá a ṣe ronú pé ìpàdé ọ̀hún máa rí kọ́ ló ṣe rí rárá.”

Àní, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ni ìtẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ ìwàásù fi falẹ̀ nílẹ̀ Ítálì, lára ohun tó sì fa èyí ni pé ìjọba aláṣẹ oníkùmọ̀ ń ṣenúnibíni sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lákòókò yẹn, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè náà kò ju àádọ́jọ [150] lọ, ọ̀dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí wọn àtàwọn ọ̀rẹ́ wọn tó wà lórílẹ̀-èdè mìíràn ni ọ̀pọ̀ jù lọ wọn sì ti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Ìtẹ̀síwájú Tó Kàmàmà

Lẹ́yìn Ogun Àgbáyé Kejì, ètò Ọlọ́run rán àwọn míṣọ́nnárì díẹ̀ lọ sí Ítálì. Àmọ́, àwọn ìwé kan tó wà níbi tí ìjọba ń tọ́jú ìwé sí sọ pé àwọn tó wà nípò gíga nínú ẹ̀sìn Kátólíìkì sọ fún ìjọba ilẹ̀ Ítálì pé kí wọ́n lé àwọn míṣọ́nnárì ọ̀hún kúrò nílùú. Bí ìjọba ṣe fipá lé àwọn míṣọ́nnárì náà kúrò ní Ítálì nìyẹn tó fi jẹ́ pé àwọn kọ̀ọ̀kan lára wọn ló ṣẹ́ kù.

Pẹ̀lú gbogbo ìdíwọ́ yìí, ọ̀pọ̀ èèyàn nílẹ̀ Ítálì ṣì ń rọ́ lọ sí “òkè ńlá” tó dúró fún ìjọsìn Jèhófà. (Aísáyà 2:2-4) Bí àwọn Ẹlẹ́rìí ṣe ń pọ̀ sí i wúni lórí gan-an. Lọ́dún 2004, ẹgbẹ̀rún lọ́nà òjìlénígba ó dín méje àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ó lé mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n [233,527] èèyàn ló kéde ìhìn rere, tó túmọ̀ sí pé Ẹlẹ́rìí kan máa wàásù fún òjìlénígba àti mẹ́jọ [248] èèyàn kí wọ́n tó lè kárí ilẹ̀ Ítálì. Àwọn tó sì wá sí Ìrántí Ikú Kristi jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà òjìlénírínwó ó dín méje àti òjìlénígba ó lé méjì [433,242]. Ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé mọ́kàndínláàádọ́ta [3,049], àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tó dára gan-an ni wọ́n sì ti ń ṣèpàdé. Láti bí ọdún mélòó kan sẹ́yìn, àwọn kan lára àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè yìí ti ní ìtẹ̀síwájú tó hẹ̀rẹ̀ǹtẹ̀.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Ń Fi Oríṣiríṣi Èdè Wàásù

Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń wá sí Ítálì láti ilẹ̀ Áfíríkà, Éṣíà àti ìlà oòrùn Yúróòpù nítorí iṣẹ́ tàbí nítorí kí ayé wọn lè dára sí i. Àwọn mìíràn sì sá wá síbẹ̀ nítorí ààbò. Báwo làwọn Ẹlẹ́rìí ṣe lè ran ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn wọ̀nyí lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí?

Ọ̀pọ̀ lára àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà nílẹ̀ Ítálì ń kọ́ àwọn èdè ilẹ̀ òkèèrè tó ṣòroó gbọ́, irú bí èdè Albania, Amharic, Bengali, Lárúbáwá, Punjabi, Sinhala, èdè ilẹ̀ Ṣáínà àti èdè Tagalog. Bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 2001, àwọn Ẹlẹ́rìí ṣètò láti kọ́ àwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ sí àwọn èdè náà bí wọ́n ṣe lè fi wọ́n wàásù. Láti ọdún mẹ́ta sẹ́yìn, àwọn Ẹlẹ́rìí tí iye wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé ọgọ́rùn-ún méje àti mọ́kànlá [3,711] ló ti jàǹfààní látinú àwọn ètò ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà. Ètò ìdálẹ́kọ̀ọ́ mọ́kàndínlọ́gọ́rin ni wọ́n ti ṣe, èdè mẹ́tàdínlógún ni wọ́n sì ti kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà lápapọ̀. Èyí ti jẹ́ kó ṣeé ṣe láti dá àwọn ìjọ àtàwọn àwùjọ tí ń sọ èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ sílẹ̀, àti láti fún wọn níṣìírí kí wọ́n lè tẹ̀ síwájú. Ìjọ ogóje ó lé mẹ́fà [146] àti àwùjọ igba ó lé mẹ́rìnléláàádọ́rin [274] ni wọ́n ti dá sílẹ̀. Àpapọ̀ iye èdè tí àwọn ìjọ àti àwùjọ wọ̀nyí sì fi ń ṣèpàdé jẹ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n. Nípa báyìí, ọ̀pọ̀ àwọn tó fẹ́ mọ òtítọ́ ti gbọ́ ìhìn rere, wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àbájáde gbogbo ìsapá àwọn Ẹlẹ́rìí yìí dára gan-an.

Ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wàásù fún ọkùnrin kan tó ń jẹ́ George. Ọmọ ilẹ̀ Íńdíà ni, èdè Malayalam ló sì ń sọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣòro ńlá ni ọ̀rọ̀ iṣẹ́ jẹ́ fún George, tayọ̀tayọ̀ ló fi gbà pé òun yóò kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀, ọ̀rẹ́ George kan tó ń jẹ́ Gil tó ń sọ èdè Punjabi, tí òun náà wá láti ilẹ̀ Íńdíà lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Gil fi David tó ń sọ èdè Telugu han àwọn Ẹlẹ́rìí. Láìpẹ́ sígbà yẹn, David bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn ọmọ ilẹ̀ Íńdíà méjì kan tórúkọ wọn ń jẹ́ Sonny àti Shubash tí wọ́n jọ ń gbélé pẹ̀lú David náà tún bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ díẹ̀, Dalip tó ń sọ èdè Marathi tẹ àwọn Ẹlẹ́rìí láago, ó ní: “Ọ̀rẹ́ George ni mí. Ṣé ẹ lè máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?” Nígbà tó yá, Sumit tó ń sọ èdè Tamil náà tún sọ pé òun fẹ́ máa kẹ́kọ̀ọ́. Lẹ́yìn náà ni ọ̀rẹ́ George kan tún tẹ àwọn Ẹlẹ́rìí láago pé òun fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Max tí George mú wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba sọ pé òun náà fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ní báyìí, àwọn mẹ́fà làwọn Ẹlẹ́rìí ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ètò sì ń lọ lọ́wọ́ láti fi mẹ́rin kún un. Èdè Gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n fi ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n tún ń lo àwọn ìwé tó wà lédè Hindi, Malayalam, Marathi, Punjabi, Tamil, Telugu àti Urdu.

Ìhìn Rere Ń Dé Ọ̀dọ̀ Àwọn Adití Pẹ̀lú

Àwọn adití tó wà nílẹ̀ Ítálì lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́rùn-ún [90,000]. Láàárín ọdún 1970 sí 1980, àwọn Ẹlẹ́rìí bẹ̀rẹ̀ sí ṣètò bí wọ́n á ṣe kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Níbẹ̀rẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí kan tí wọ́n jẹ́ adití máa ń fi Èdè Àwọn Adití Lọ́nà Ti Ítálì kọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí bíi tiwọn tó ń fẹ́ láti ran àwọn adití lọ́wọ́. Nígbà tó yá, ọ̀pọ̀ àwọn adití bẹ̀rẹ̀ sí fetí sí ẹ̀kọ́ Bíbélì. Lónìí, àwọn adití tó lé ní egbèje [1,400] tí wọ́n ń sọ Èdè Àwọn Adití Lọ́nà Ti Ítálì ló ń lọ sípàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ìjọ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àti àwùjọ méjìléláàádọ́ta sì ń fi Èdè Àwọn Adití Lọ́nà Ti Ítálì ṣèpàdé.

Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí kọ̀ọ̀kan ló ń ṣètò bí wọ́n á ṣe wàásù fún àwọn adití. Àmọ́ lọ́dún 1978, ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílẹ̀ Ítálì bẹ̀rẹ̀ sí ṣètò àpéjọ àgbègbè fáwọn adití. Lóṣù May ọdún yẹn, wọ́n ṣèfilọ̀ pé ní àpéjọ àgbáyé tí wọ́n máa ṣe láìpẹ́ sígbà yẹn nílùú Milan wọ́n máa túmọ̀ ọ̀rọ̀ ìpàdé náà sí èdè àwọn adití. Oṣù February ọdún 1979 ni wọ́n kọ́kọ́ ṣètò àpéjọ àyíká fún àwọn adití, èyí sì jẹ́ ní Gbọ̀ngàn Àpéjọ tó wà nílùú Milan.

Látìgbà yẹn ni ẹ̀ka ọ́fíìsì ti ń ṣakitiyan láti ran àwọn adití lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa rí oúnjẹ tẹ̀mí jẹ, ọ̀nà tí wọ́n sì ń gbà ṣe èyí ni pé wọ́n ń rọ ọ̀pọ̀ àwọn akéde pé kí wọ́n sapá láti túbọ̀ mọ èdè yìí lò dáadáa. Látọdún 1995 ni ẹ̀ka ọ́fíìsì ti ń rán àwọn aṣáájú ọ̀nà àkànṣe lọ sọ́dọ̀ àwọn àwùjọ kan kí wọ́n lè kọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí tó jẹ́ adití bí wọ́n á ṣe máa wàásù àti bí wọ́n á ṣe máa ṣe ìpàdé ìjọ. Kí wọ́n lè mú káwọn tó bá wá sípàdé gbádùn rẹ̀, wọ́n gbé àwọn tẹlifíṣọ̀n ńlá tó jẹ́ ti ìgbàlódé sí Gbọ̀ngàn Àpéjọ mẹ́ta. Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n tún ṣe àwọn ìwé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sórí fídíò káwọn tí wọ́n jẹ́ adití bàa lè máa rí oúnjẹ tẹ̀mí jẹ.

Àwọn tó ń ṣàkíyèsí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí i pé wọn ò fi nǹkan tẹ̀mí wọ́n àwọn adití. Ìwé ìròyìn P@role & Segni tí Àjọ Tó Ń Bójú Tó Àwọn Adití Nílẹ̀ Ítálì tẹ̀ jáde fa ọ̀rọ̀ kan yọ nínú lẹ́tà kan tí bíṣọ́ọ̀bù Kátólíìkì kan kọ, ó ní: “Nǹkan kì í rọrùn fáwọn adití rárá nítorí pé wọ́n máa ń fẹ́ àbójútó ní gbogbo ìgbà. Bí àpẹẹrẹ, adití lè dá nìkan lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì láìsí ìnira kankan, àmọ́ ẹnì kan ní láti ṣe ìtumọ̀ fún un kó tó lè lóye gbogbo ohun tí wọ́n ń kà, ohun tí wọ́n ń sọ àti orin tí wọ́n ń kọ níbẹ̀.” Ìwé ìròyìn náà tún fi kún un pé bíṣọ́ọ̀bù náà sọ pé “ó dunni gan-an pé ṣọ́ọ̀ṣì ò tíì ṣe tán láti ran àwọn adití lọ́wọ́, ó sì tún sọ pé àwọn adití máa ń rí àbójútó tó dára tí wọ́n bá lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ju ìgbà tí wọ́n bá lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì lọ.”

Wọ́n Ń Wàásù Ìhìn Rere Fáwọn Ẹlẹ́wọ̀n

Ǹjẹ́ èèyàn lè dòmìnira nígbà téèyàn ṣì wà lẹ́wọ̀n? Bẹ́ẹ̀ ni o. Ìdí ni pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lágbára láti sọ àwọn tó bá kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ tí wọ́n sì ń fi í sílò ‘di òmìnira.’ Ohun tí Jésù ń wàásù fún “àwọn òǹdè” ni òmìnira kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti ẹ̀sìn èké. (Jòhánù 8:32; Lúùkù 4:16-19) Iṣẹ́ ìwàásù ní ọgbà ẹ̀wọ̀n ń so èso rere gan-an nílẹ̀ Ítálì. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ tó irinwó [400] gbàṣẹ lọ́dọ̀ ìjọba láti máa lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹlẹ́wọ̀n kí wọ́n lè fi ẹ̀kọ́ Ọlọ́run kọ́ wọn. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ètò ẹ̀sìn àkọ́kọ́ tí kì í ṣe ara ìjọ Kátólíìkì tó lọ sọ fún ìjọba pé àwọn fẹ́ máa wàásù fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n, tí ìjọba sì gbà wọ́n láyè kí wọ́n máa ṣe bẹ́ẹ̀.

Onírúurú ọ̀nà la lè gbà wàásù ìhìn rere, àní láwọn ọ̀nà téèyàn ò tiẹ̀ fọkàn sí pàápàá. Àwọn ẹlẹ́wọ̀n máa ń sọ fáwọn ẹlẹ́wọ̀n bíi tiwọn nípa iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe. Èyí ti mú kí àwọn kan lára àwọn ẹlẹ́wọ̀n tí wọ́n bá sọ̀rọ̀ yìí náà sọ pé àwọn fẹ́ káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sọ́dọ̀ àwọn. Nígbà míì sì rèé, àwọn tó jẹ́ aráalé ẹlẹ́wọ̀n kan tí àwọn fúnra wọn ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì máa ń rọ ẹlẹ́wọ̀n náà pé kó sọ fáwọn Ẹlẹ́rìí pé kí wọ́n wá sọ́dọ̀ òun. Àwọn kan tí wọ́n dájọ́ ẹ̀wọ̀n gbére fún nítorí ẹ̀sùn ìpànìyàn àti ìwà ọ̀daràn tó burú jáì ti ronú pìwà dà, wọ́n sì ti ṣe ìyípadà tó gadabú nígbèésí ayé wọn. Lẹ́yìn èyí, wọ́n ya ara wọn sí mímọ́ sí Jèhófà wọ́n sì ṣèrìbọmi.

Láwọn ọgbà ẹ̀wọ̀n kan, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣètò láti sọ àsọyé tó dá lórí Bíbélì, láti ṣe Ìrántí Ikú Jésù, àti láti fi àwọn fídíò táwa Ẹlẹ́rìí ṣe tó dá lórí ẹ̀kọ́ Bíbélì han àwọn ẹlẹ́wọ̀n. Ọ̀pọ̀ àwọn ẹlẹ́wọ̀n ló sì máa ń wá lọ́pọ̀ ìgbà.

Kí àwọn Ẹlẹ́rìí lè ran àwọn ẹlẹ́wọ̀n àtàwọn òṣìṣẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n lọ́wọ́, wọ́n máa ń fún wọn ní ọ̀pọ̀ ìwé ìròyìn tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tó máa ṣe àwọn ẹlẹ́wọ̀n láǹfààní. Ọ̀kan lára irú ìwé ìròyìn bẹ́ẹ̀ ni Jí! May 8, 2001, èyí tí àkọlé rẹ̀ jẹ́, “Ṣé Àwọn Ẹlẹ́wọ̀n Lè Yí Padà?” àti Jí! April 8, 2003 tí àkọlé rẹ̀ jẹ́, “Bí Ẹnì Kan Nínú Ìdílé Bá Ń Lo Oògùn Olóró—Kí Lo Lè Ṣe?” Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ẹ̀dà ìwé ìròyìn yìí ni wọ́n ti fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n. Èyí sì ti mú kí ọ̀pọ̀ àwọn ẹlẹ́wọ̀n bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kódà àwọn kan lára àwọn wọ́dà náà ti ń tẹ́tí sí ẹ̀kọ́ Bíbélì.

Àwọn aláṣẹ gbà kí ẹlẹ́wọ̀n kan tó ń jẹ́ Constantino jáde lọ́gbà ẹ̀wọ̀n kó lè lọ ṣèrìbọmi ní Gbọ̀ngàn Ìjọba kan nílùú San Remo. Ohun tí wọ́n ṣe yìí ṣàrà ọ̀tọ̀ torí pé wọn kì í sábà yọ̀ọ̀da fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n láti jáde bẹ́ẹ̀. Àwọn Ẹlẹ́rìí méjìdínlógóje [138] láti àgbègbè náà ló wá síbi ìrìbọmi rẹ̀. Inú Constantino dùn gan-an lẹ́yìn ìrìbọmi rẹ̀. Ó sọ pé: “Ìfẹ́ tí wọ́n ní sí mi wú mi lórí gan-an ni.” Ìwé ìròyìn kan lágbègbè náà gbé ọ̀rọ̀ ọ̀gá wọ́dà ọgbà ẹ̀wọ̀n tí Constantino wà jáde, ó sọ pé: “Inú wa dùn gan-an . . . láti fún ẹlẹ́wọ̀n yìí láyè. Ó yẹ ká máa ṣe àtìlẹ́yìn fún gbogbo ohun tó lè ran ẹlẹ́wọ̀n kan lọ́wọ́ láti di ẹni gidi láwùjọ àtẹni tó máa wúlò fún ara rẹ̀, tí yóò sì máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.” Inú ìyàwó Constantino àti ọmọ rẹ̀ obìnrin dùn gan-an nígbà tí wọ́n rí bí ìmọ̀ Bíbélì tó péye ṣe tún ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe, èyí ló mú kí wọ́n sọ pé: “Inú wa dùn gan-an bí ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe yí padà. Ó ti di èèyàn jẹ́jẹ́, ìfẹ́ tó ní sí wa sì ti jinlẹ̀ sí i. Àwa náà ti túbọ̀ fọkàn tán an, ó sì ti túbọ̀ níyì lójú wa.” Àwọn méjèèjì ti bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì ti ń lọ sípàdé ìjọ.

Ọkùnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sergio ń ṣẹ̀wọ̀n nítorí olè jíjà, ìdigunjalè, gbígbé oògùn olóró àti ìpànìyàn. Ọdún 2024 ni wọ́n sì sọ pé ó máa tó ṣẹ̀wọ̀n rẹ̀ tán. Lẹ́yìn tí Sergio ti kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ fún ọdún mẹ́ta, tó sì ti ṣe ọ̀pọ̀ ìyípadà nígbèésí ayé rẹ̀, ó pinnu pé òun yóò ṣèrìbọmi. Òun ni ẹlẹ́wọ̀n kẹẹ̀ẹ́dógún tó ṣèrìbọmi tó sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà lára àwọn tó wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Porto Azzurro tó wà ní erékùṣù Elba. Inú ohun ńlá kan tí wọ́n pọn omi sí lórí pápá ìṣeré ọgbà ẹ̀wọ̀n náà ló ti ṣèrìbọmi, níṣojú ọ̀pọ̀ lára àwọn ẹlẹ́wọ̀n bíi tirẹ̀.

Àwọn aláṣẹ gba Leonardo tí wọ́n sọ sẹ́wọ̀n ogún ọdún láyè láti lọ ṣèrìbọmi ní Gbọ̀ngàn Ìjọba kan nílùú Parma, èyí tó jẹ́ pé wọn kì í sábà ṣe fáwọn ẹlẹ́wọ̀n. Nígbà táwọn oníròyìn ń fọ̀rọ̀ wá Leonardo lẹ́nu wò, ó sọ pé òun fẹ́ kó yé gbogbo èèyàn pé kì í ṣe torí kí òun lè kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n ni òun ṣe fẹ́ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àmọ́ ó jẹ́ nítorí pé ó wu òun gan-an láti jọ́sìn Ọlọ́run. Leonardo sọ pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ tí mo ti dá láyé yìí kì í ṣe kékeré, àmọ́ mo ti jáwọ́ nínú gbogbo ìyẹn báyìí. Mo ti yí padà, ṣùgbọ́n kì í ṣe lọ́sàn-án kan òru kan o. Mo gbọ́dọ̀ máa sapá nígbà gbogbo láti jẹ́ olódodo.”

Ọgbà ẹ̀wọ̀n àwọn ògbólógbòó ọ̀daràn tó wà nílùú Spoleto ni ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Salvatore tí wọ́n fẹ̀sùn ìpànìyàn kan ti ń ṣẹ̀wọ̀n. Ọ̀pọ̀ àwọn tó rí i nígbà tó ń ṣèrìbọmi nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n náà ni ìrìbọmi tó ṣe náà wú lórí. Ọ̀gá wọ́dà ọgbà ẹ̀wọ̀n tí Salvatore wà sọ pé: “Ó yẹ ká kọ́wọ́ ti ohunkóhun tó bá máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti di ọmọlúwàbí láwùjọ, torí pé èyí á ṣe àwọn ẹlẹ́wọ̀n àti gbogbo aráàlú láǹfààní.” Àyípadà tí Salvatore ṣe yìí ló mú kí aya rẹ̀ àti ọmọ rẹ̀ obìnrin kan bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ẹlẹ́wọ̀n kan tí Salvatore wàásù fún ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ sí Jèhófà, ó sì ti ṣèrìbọmi.

Ilẹ̀ Ítálì wà lára ibi tí ẹ̀sìn Kristẹni ti gbèrú tó sì gbilẹ̀ nígbà ìjímìjí. (Ìṣe 2:10; Róòmù 1:7) Bákan náà, ní àkókò ìkórè tá a wà yìí, ìtẹ̀síwájú tẹ̀mí ń wáyé láwọn àgbègbè kan náà tí Pọ́ọ̀lù àtàwọn Kristẹni bíi tirẹ̀ ti wàásù ìhìn rere.—Ìṣe 23:11; 28:14-16.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 13]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

ÍTÁLÌ

Róòmù

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Gbọ̀ngàn Àpéjọ tó wà nílùú Bitonto àti ìjọ tí wọ́n ti ń sọ Èdè Àwọn Adití Lọ́nà Ti Ítálì nílùú Róòmù

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Ẹ̀kọ́ Bíbélì ń sọ àwọn ẹlẹ́wọ̀n ‘di òmìnira’

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Ìtẹ̀síwájú tẹ̀mí ṣì ń wáyé níbi tí ẹ̀sìn Kristẹni ti gbilẹ̀ nígbà ìjímìjí