Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Iṣẹ́ Ṣíṣe Ìbùkún Ni Tàbí Ègún?

Iṣẹ́ Ṣíṣe Ìbùkún Ni Tàbí Ègún?

Iṣẹ́ Ṣíṣe Ìbùkún Ni Tàbí Ègún?

“Fún ènìyàn, kò sí ohun tí ó sàn ju pé kí ó . . . rí ohun rere nítorí iṣẹ́ àṣekára rẹ̀.”—Oníwàásù 2:24.

NÍNÚ àwọn òṣìṣẹ́ tí wọ́n fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò láìpẹ́ yìí, ìdámẹ́ta wọn sọ pé ó máa ń rẹ àwọn tẹnutẹnu lẹ́yìn táwọn bá tibi iṣẹ́ dé. Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ò ṣàjèjì nínú ayé yìí táwọn èèyàn ti ń ṣe wàhálà púpọ̀ gan-an lẹ́nu iṣẹ́; wọ́n máa ń ṣe àfikún iṣẹ́, wọ́n sì máa ń kó ọ̀pọ̀ iṣẹ́ lọ sílé láti ṣe. Síbẹ̀ náà, àwọn ọ̀gá wọn kì í sábà yìn wọ́n.

Ní báyìí tó jẹ́ pé ẹ̀rọ ló ń béèyàn ṣe àwọn nǹkan jáde lọ́pọ̀ rẹpẹtẹ, ọ̀pọ̀ òṣìṣẹ́ ló ti gbà pé àwọn ò fi bẹ́ẹ̀ wúlò mọ́. Àwọn èèyàn kì í fi bẹ́ẹ̀ lo ọpọlọ wọn mọ́ láti fi ṣiṣẹ́. Èyí ti wá ṣàkóbá fún ẹ̀mí táwọn èèyàn ní sí iṣẹ́. Àwọn òṣìṣẹ́ ò fẹ́ máa fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ mọ́. Ó sì ṣeé ṣe kó má fi bẹ́ẹ̀ yá àwọn èèyàn lára mọ́ láti sa gbogbo ipá wọn nídìí iṣẹ́. Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè mú kéèyàn má fẹ́ràn iṣẹ́ ṣíṣe mọ́, bóyá kó tiẹ̀ mú kéèyàn kórìíra iṣẹ́ rẹ̀ pàápàá.

Ó Yẹ Ká Kíyè Sí Ẹ̀mí Tá A Ní sí Iṣẹ́

Òótọ́ ni pé kì í ṣe gbogbo ìgbà lèèyàn lè yí ipò tó wà padà. Àmọ́, ǹjẹ́ o ò gbà pé a lè ṣe nǹkan kan nípa ẹ̀mí tá a ní sí iṣẹ́? Tí àwọn tó ní èrò òdì nípa iṣẹ́ bá ti kéèràn ràn ọ́, á dára kó o gbé èrò Ọlọ́run àtàwọn ìlànà rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí yẹ̀ wò. (Oníwàásù 5:18) Ọ̀pọ̀ èèyàn tó ti gbé wọn yẹ̀ wò rí i pé ṣíṣe táwọn ṣe bẹ́ẹ̀ ti jẹ́ káwọn ní ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn nínú iṣẹ́ àwọn.

Ọlọ́run ni Òṣìṣẹ́ tó ga jù lọ. Ọlọ́run jẹ́ òṣìṣẹ́. Ó ṣeé ṣe ká má tíì ronú lọ sápá ibẹ̀ yẹn rí, àmọ́ bí Ọlọ́run ṣe kọ́kọ́ ṣàlàyé ara rẹ̀ nínú Bíbélì nìyẹn. Ohun tó bẹ̀rẹ̀ Jẹ́nẹ́sísì ni pé Jèhófà dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 1:1) Wo onírúurú iṣẹ́ tí Ọlọ́run ṣe nígbà tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìṣẹ̀dá. Ó ṣètò àwọn nǹkan létòlétò, ó ṣe iṣẹ́ ọnà, ó ṣiṣẹ́ kọ́lékọ́lé, iṣẹ́ onímọ̀ ẹ̀rọ, iṣẹ́ onímọ̀ kẹ́míkà, iṣẹ́ onímọ̀ ohun alààyè, iṣẹ́ onímọ̀ ẹranko, iṣẹ́ onímọ̀ èdè púpọ̀, àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.—Òwe 8:12, 22-31.

Báwo ni iṣẹ́ tí Ọlọ́run ṣe ṣe rí? Bíbélì sọ pé ó “dára,” ó tún sọ pé “ó dára gan-an.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:4, 31) Kò sí àní-àní pé àwọn ohun tí Ọlọ́run dá ń “polongo ògo Ọlọ́run,” ó sì yẹ kí àwa náà máa fi ògo fún un!—Sáàmù 19:1; 148:1.

Àmọ́ o, Ọlọ́run ò ṣíwọ́ iṣẹ́ lẹ́yìn tó dá ọ̀run àti ilẹ̀ ayé àtàwọn ẹ̀dá èèyàn àkọ́kọ́. Jésù Kristi, Ọmọ Jèhófà sọ pé: “Baba mi ti ń bá a nìṣó ní ṣíṣiṣẹ́ títí di ìsinsìnyí.” (Jòhánù 5:17) Òótọ́ ni, Jèhófà ò dáwọ́ iṣẹ́ dúró nítorí ó ń pèsè fáwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀, ó ń tọ́jú wọn, ó sì ń dáàbò bo àwọn tó ń fi tọkàntọkàn sìn ín. (Nehemáyà 9:6; Sáàmù 36:6; 145:15, 16) Ó tiẹ̀ ń lo àwọn èèyàn, ìyẹn àwọn “alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run,” láti bá a ṣe àwọn iṣẹ́ kan.—1 Kọ́ríńtì 3:9.

Ìbùkún ni iṣẹ́ jẹ́. Ǹjẹ́ Bíbélì ò sọ pé ègún ni iṣẹ́ jẹ́? Ó lè jọ bíi pé ohun tí Jẹ́nẹ́sísì 3:17-19 ń sọ ni pé ńṣe ni Ọlọ́run fún Ádámù àti Éfà níṣẹ́ ńlá ṣe láti fi fìyà jẹ wọ́n nítorí àìgbọràn wọn. Nígbà tí Ọlọ́run ń gégùn-ún fáwọn ẹ̀dá èèyàn àkọ́kọ́ náà, ó sọ fún Ádámù pé: “Inú òógùn ojú rẹ ni ìwọ yóò ti máa jẹ oúnjẹ títí tí ìwọ yóò fi padà sí ilẹ̀.” Ṣé ọ̀rọ̀ yẹn wá túmọ̀ sí pé èèyàn ò lè rí èrè kankan nídìí iṣẹ́ láé ni?

Rárá o. Dípò ìyẹn, ńṣe ni ọgbà Édẹ́nì tó dà bíi Párádísè kò ní lè gbòòrò lákòókò yẹn nítorí ìwà àìṣòótọ́ Ádámù àti Éfà. Ọlọ́run fi ilẹ̀ bú, ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé kéèyàn tó lè mú oúnjẹ jáde látinú ilẹ̀, èèyàn ní láti ṣiṣẹ́ àṣelàágùn.—Róòmù 8:20, 21.

Bíbélì ò sọ pé ègún ni iṣẹ́ ṣíṣe jẹ́, dípò ìyẹn, ohun tó sọ ni pé iṣẹ́ jẹ́ ẹ̀bùn kan tó yẹ ká fọwọ́ pàtàkì mú. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ níbẹ̀rẹ̀, òṣìṣẹ́kára ni Ọlọ́run fúnra rẹ̀. Jèhófà dá èèyàn ní àwòrán rẹ̀, ó sì fún wọn ní agbára àti àṣẹ láti mójú tó àwọn nǹkan abẹ̀mí tó dá sórí ilẹ̀ ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26, 28; 2:15) Ọlọ́run ti fún wọn ní iṣẹ́ yìí kó tó sọ ohun tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì orí kẹta ẹsẹ ìkọkàndínlógún. Ká ní pé ègún ni iṣẹ́ jẹ́ ni, Jèhófà ì bá má ti gba àwa èèyàn níyànjú pé ká máa ṣe é. Nóà àti ìdílé rẹ̀ ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ṣáájú Ìkún Omi àti lẹ́yìn Ìkún Omi. Nígbà ayé àwọn Kristẹni, wọ́n gba àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù náà nímọ̀ràn pé kí wọ́n máa ṣiṣẹ́.—1 Tẹsalóníkà 4:11.

Síbẹ̀ náà, gbogbo wa la mọ̀ pé àwọn iṣẹ́ tó wà láyé ìsinsìnyí máa ń kó ìnira báni. Másùnmáwo, jàǹbá, àárẹ̀, ìjákulẹ̀, ìbánidíje, ẹ̀tàn àti èrú wà lára “ẹ̀gún àti òṣùṣú” tó wà nídìí iṣẹ́ ṣíṣe. Ṣùgbọ́n iṣẹ́ fúnra rẹ̀ kì í ṣe ègún. Nínú Oníwàásù 3:13, ẹ̀bùn tó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ni Bíbélì pe iṣẹ́ àtàwọn àǹfààní tá à ń jẹ látinú iṣẹ́ ṣíṣe.—Wo àpótí tó ní àkọlé náà “Ohun Tá A Lè Ṣe Bí Iṣẹ́ Bá Ń Mú Ká Ṣàníyàn.”

O lè fi iṣẹ́ ọwọ́ rẹ yin Ọlọ́run. Àwọn èèyàn máa ń mọyì iṣẹ́ tó bá jẹ́ ojúlówó tó sì dára. Ọ̀kan lára ohun tí Bíbélì sọ nípa iṣẹ́ ni pé ó yẹ kí iṣẹ́ wa jẹ́ ojúlówó. Ojúlówó ni gbogbo iṣẹ́ tí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ máa ń ṣe. Ọlọ́run ti fún wa ní ẹ̀bùn àti agbára, ó sì fẹ́ ká lo ẹ̀bùn àti agbára yìí láti fi ṣe ohun tó dára. Bí àpẹẹrẹ, nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ayé ọjọ́un fẹ́ kọ́ àgọ́ ìjọsìn, Jèhófà fún àwọn èèyàn bíi Bẹ́sálẹ́lì àti Òhólíábù ní ọgbọ́n, òye àti ìmọ̀ kí wọ́n lè ṣe àwọn iṣẹ́ ọnà kan àtàwọn iṣẹ́ pàtàkì mìíràn. (Ẹ́kísódù 31:1-11) Èyí fi hàn pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ wọn, títí kan bí iṣẹ́ ọnà àti ẹwà rẹ̀ yóò ṣe rí àtàwọn nǹkan míì tó jẹ mọ́ iṣẹ́ náà.

Èyí jẹ́ ká rí i pé ó ṣe pàtàkì ká máa lo òye tá a bá ní dáadáa ká sì lẹ́mìí iṣẹ́ ṣíṣe. Ó sì tún jẹ́ ká rí i pé ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni òye tá a ní àti ẹ̀mí iṣẹ́ ṣíṣe jẹ́ láwọn ọ̀nà kan, kò sì yẹ ká fọwọ́ yẹpẹrẹ mú un. Ìdí nìyí tí Bíbélì fi gba àwa Kristẹni níyànjú pé ká máa ṣe iṣẹ́ wa bí ẹni pé Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ń yẹ̀ ẹ́ wò, ó ní: “Ohun yòówù tí ẹ bá ń ṣe, ẹ fi tọkàntọkàn ṣe é bí ẹni pé fún Jèhófà, kì í sì í ṣe fún ènìyàn.” (Kólósè 3:23) Bíbélì fi hàn pé àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run gbọ́dọ̀ máa ṣe iṣẹ́ tó jọjú tó sì dára, ṣíṣe tí wọ́n bá sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ yóò mú kí ìhìn rere tí wọ́n ń wàásù túbọ̀ fa àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ àtàwọn míì mọ́ra.—Wo àpótí tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ “Máa Tẹ̀ Lé Àwọn Ìlànà Bíbélì Níbi Iṣẹ́.”

Nítorí náà, á dára ká bi ara wa pé, ǹjẹ́ à ń ṣiṣẹ́ tó pójú owó, ǹjẹ́ a sì ń tẹpá mọ́ṣẹ́? Ǹjẹ́ inú Ọlọ́run dùn sí ohun tá à ń ṣe? Ǹjẹ́ ọ̀nà tá a gbà ń ṣe iṣẹ́ wa tẹ́ wa lọ́rùn délẹ̀délẹ̀? Tí kò bá rí bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká ṣàtúnṣe.—Òwe 10:4; 22:29.

Má ṣe jẹ́ kí iṣẹ́ rẹ pa ìjọsìn Ọlọ́run lára. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó dára kéèyàn jẹ́ òṣìṣẹ́kára, síbẹ̀ ohun kan wà tó máa jẹ́ ká lè nítẹ̀ẹ́lọ́rùn nídìí iṣẹ́ wa àti nínú ayé wa. Ohun náà ni ìjọsìn Ọlọ́run. Sólómọ́nì Ọba tó jẹ́ òṣìṣẹ́kára, tó ní ọrọ̀ tó sì tún jẹ gbogbo ìgbádùn ayé yìí sọ ní paríparí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, kí o sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. Nítorí èyí ni gbogbo iṣẹ́ àìgbọ́dọ̀máṣe ti ènìyàn.”—Oníwàásù 12:13.

Ọ̀rọ̀ yẹn fi hàn kedere pé a ò gbọ́dọ̀ gbàgbé ìfẹ́ Ọlọ́run nínú gbogbo ohun tá a bá dáwọ́ lé. Ǹjẹ́ à ń ṣe nǹkan bí Ọlọ́run ṣe fẹ́, àbí òdìkejì rẹ̀ là ń ṣe? Ǹjẹ́ à ń gbìyànjú láti ṣe ohun tí inú Ọlọ́run máa dùn sí àbí ìfẹ́ ara wa là ń ṣe? Téèyàn ò bá ṣèfẹ́ Ọlọ́run, bópẹ́bóyá ìgbésí ayé onítọ̀hún ò ní lójú, kò ní nítumọ̀, onítọ̀hún ò sì ní láyọ̀.

Steven Berglas sọ pé kí àwọn lọ́gàálọ́gàá tí iṣẹ́ ṣíṣe ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dá lágara ‘wá ohun tó gbayì kan tí wọ́n fẹ́ràn láti máa ṣe kí wọ́n sì fi nǹkan náà kún ohun tí wọ́n ń ṣe nígbèésí ayé.’ Kò sí ohun tó gbayì téèyàn lè máa ṣe tá a lè fi wé jíjọ́sìn Ẹni tó fún wa láwọn ẹ̀bùn àti agbára tá a fi ń ṣe ohun tó jọjú. Tá a bá ń ṣe iṣẹ́ tí inú Ẹlẹ́dàá wa dùn sí, agara ò ní dá wa láé. Ńṣe ni iṣẹ́ tí Jèhófà gbé lé Jésù lọ́wọ́ dà bí oúnjẹ aṣaralóore, tó gbádùn mọ́ ọn. (Jòhánù 4:34; 5:36) Ẹ má sì gbàgbé pé Ọlọ́run tó jẹ́ Òṣìṣẹ́ tó ga jù lọ ń pè wá pé ká jẹ́ “alábàáṣiṣẹ́pọ̀” pẹ̀lú òun.—1 Kọ́ríńtì 3:9.

Tá a bá ń jọ́sìn Ọlọ́run tá a sì ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, a ó lè máa ṣe iṣẹ́ wa àti ojúṣe wa lọ́nà tó dára. Bí ìdààmú àti wàhálà ibi iṣẹ́ ṣe pọ̀, tí iṣẹ́ sì máa ń pọ̀ láti ṣe, ìgbàgbọ́ tó jinlẹ̀ àti ìjọsìn Ọlọ́run tá à ń ṣe yóò máa fún wa lókun bá a ṣe ń sapá láti jẹ́ òṣìṣẹ́ tàbí ọ̀gá tó dára. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn nǹkan tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé burúkú yìí tún lè jẹ́ ká rí apá ibi tó ti yẹ ká mú ìgbàgbọ́ wa lágbára sí i.—1 Kọ́ríńtì 16:13, 14.

Ìgbà Tí Iṣẹ́ Yóò Jẹ́ Ìbùkún

Àwọn tó ń sapá gidigidi láti sin Ọlọ́run nísinsìnyí lè máa fojú sọ́nà fún ìgbà tí Ọlọ́run yóò sọ ayé yìí di Párádísè bó ṣe wà níbẹ̀rẹ̀, iṣẹ́ tó jọjú la ó sì máa ṣe ní gbogbo ayé nígbà yẹn. Aísáyà, wòlíì Jèhófà, sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí ìgbésí ayé yóò ṣe rí lákòókò náà, ó ní: “Dájúdájú, wọn yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn; dájúdájú, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì máa jẹ èso wọn. Wọn kì yóò kọ́lé fún ẹlòmíràn gbé; wọn kì yóò gbìn fún ẹlòmíràn jẹ. . . . Iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn ni àwọn àyànfẹ́ mi yóò sì lò dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.”—Aísáyà 65:21-23.

Ìbùkún ńlá gbáà ni iṣẹ́ yóò jẹ́ nígbà náà! Bó o ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ ohun tí ìfẹ́ Ọlọ́run jẹ́, tó o sì ń fi àwọn ohun tó ò ń kọ́ ṣèwà hù, àdúrà wa ni pé kí o wà lára àwọn tí Jèhófà yóò bù kún, kí o sì “rí ohun rere nítorí gbogbo iṣẹ́ àṣekára [rẹ].”—Oníwàásù 3:13.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 8]

Ọlọ́run ni Òṣìṣẹ́ tó ga jù lọ: Jẹ́nẹ́sísì 1:1, 4, 31; Jòhánù 5:17

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 8]

Ìbùkún ni iṣẹ́ jẹ́: Jẹ́nẹ́sísì 1:28; 2:15; 1 Tẹsalóníkà 4:11

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 8]

O lè fi iṣẹ́ ọwọ́ rẹ yin Ọlọ́run: Ẹ́kísódù 31:1-11; Kólósè 3:23

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 8]

Má ṣe jẹ́ kí iṣẹ́ rẹ pa ìjọsìn Ọlọ́run lára: Oníwàásù 12:13; 1 Kọ́ríńtì 3:9

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

OHUN TÁ A LÈ ṢE BÍ IṢẸ́ BÁ Ń MÚ KÁ ṢÀNÍYÀN

Àwọn oníṣègùn sọ pé àníyàn ṣíṣe wà lára ìṣòro téèyàn máa ń rí níbi iṣẹ́. Ó lè fa ọgbẹ́ inú àti àárẹ̀ ọkàn, kódà ó tiẹ̀ lè mú kéèyàn gbẹ̀mí ara ẹ̀. Àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè Japan máa ń pe àníyàn tí iṣẹ́ ń fà ní karoshi, tó túmọ̀ sí “ikú tí iṣẹ́ àṣekúdórógbó ń fà.”

Ọ̀pọ̀ nǹkan tó jẹ mọ́ iṣẹ́ ló máa ń fa àníyàn. Bí àpẹẹrẹ, ẹnì kan lè bẹ̀rẹ̀ sí ṣàníyàn bí àkókò tó fi ń ṣiṣẹ́ bá yí padà tàbí tí ipò nǹkan bá yí padà níbi iṣẹ́, bí àárín òun àtàwọn ọ̀gá rẹ̀ kò bá gún régé, bí ohun tó ń ṣe níbi iṣẹ́ bá yí padà tàbí tó pààrọ̀ iṣẹ́, bó bá fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́ tàbí tí wọ́n dá a dúró níbi iṣẹ́. Nígbà tí irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ bá wáyé, ńṣe làwọn kan máa ń wáṣẹ́ síbòmíràn tàbí kí wọ́n tiẹ̀ kó kúrò ládùúgbò ibi tí wọ́n ń gbé nítorí kí wọ́n bàa lè bọ́ lọ́wọ́ àníyàn. Àwọn ẹlòmíràn ti rí i pé báwọn ṣe ń sá fún àníyàn lọ́nà kan làwọn tún ń korí bọ àníyàn lápá ibòmíràn nínú ìgbésí ayé wọn, èyí sì sábà máa ń jẹ́ nínú ìdílé. Àwọn kan ò tiẹ̀ mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe, gbogbo nǹkan tojú sú wọn, wọ́n sì ti ro ara wọn pin.

Àwọn Kristẹni ní ohun tó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti borí àníyàn tí iṣẹ́ ń fà. Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìlànà ló wà nínú Bíbélì tó lè ràn wá lọ́wọ́ nígbà ìṣòro. Àwọn ìlànà náà lè ṣe wá láǹfààní nípa tẹ̀mí, wọ́n sì tún lè jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè ní ìbàlẹ̀ ọkàn. Bí àpẹẹrẹ, Jésù sọ pé: “Ẹ má ṣàníyàn láé nípa ọ̀la, nítorí ọ̀la yóò ní àwọn àníyàn tirẹ̀. Búburú ti ọjọ́ kọ̀ọ̀kan tó fún un.” Ìmọ̀ràn tí Jésù ń fún wa nínú ẹsẹ yẹn ni pé, ìṣòro tòní ni ká máa wá bá a ṣe máa yanjú, ká má ṣe ṣàníyàn nítorí ọ̀la. Tá a bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí, a ò ní máa fẹ ìṣòro wa lójú ju bó ṣe yẹ lọ, èyí ò sì ní jẹ́ kí àníyàn ṣíṣe bò wá mọ́lẹ̀.—Mátíù 6:25-34.

Ó ṣe pàtàkì pé káwọn Kristẹni gbára lé Ọlọ́run, kí wọ́n má ṣe gbára lé ara wọn. Tí ìṣòro wa bá fẹ́ ju agbára wa lọ, Ọlọ́run lè fún wa ní ayọ̀ àti ìbàlẹ̀ ọkàn, ó sì lè fún wa ní ọgbọ́n tá a lè fi bójú tó ìṣòro wa. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ máa bá a lọ ní gbígba agbára nínú Olúwa àti nínú agbára ńlá okun rẹ̀.”—Éfésù 6:10; Fílípì 4:7.

Paríparí rẹ̀, ìgbà mìíràn wà tí àníyàn ṣíṣe pàápàá lè so èso rere. Àdánwò lè mú ká ké pe Jèhófà, ká máa gbàdúrà pé kó ràn wá lọ́wọ́, ká sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ̀. Àdánwò tún lè mú ká ní àwọn ànímọ́ Kristẹni mìíràn ká sì ní okun láti fara da àwọn ìṣòro wa. Pọ́ọ̀lù gbà wá níyànjú pé: “Ẹ jẹ́ kí a máa yọ ayọ̀ ńláǹlà nígbà tí a bá wà nínú ìpọ́njú, níwọ̀n bí a ti mọ̀ pé ìpọ́njú ń mú ìfaradà wá; ìfaradà, ní tirẹ̀, ipò ìtẹ́wọ́gbà; ipò ìtẹ́wọ́gbà, ní tirẹ̀, ìrètí.”—Róòmù 5:3, 4.

Gbogbo èyí fi hàn pé àníyàn lè mú kéèyàn tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí dípò kó mú kéèyàn ro ara rẹ̀ pin tàbí kéèyàn banú jẹ́.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

MÁA TẸ̀ LÉ ÀWỌN ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ NÍBI IṢẸ́

Ìwà àti ìṣesí Kristẹni kan níbi iṣẹ́ lè mú káwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ àtàwọn míì fẹ́ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Bíbélì. Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí Títù, ó gba àwọn òṣìṣẹ́ níyànjú pé kí wọ́n “wà ní ìtẹríba fún àwọn [ọ̀gá] wọn nínú ohun gbogbo, kí wọ́n sì tẹ́ wọn lọ́rùn dáadáa, láìgbó wọn lẹ́nu, kí wọ́n má jalè, ṣùgbọ́n kí wọ́n máa fi ìṣòtítọ́délẹ̀ rere hàn ní kíkún, kí wọ́n bàa lè ṣe ẹ̀kọ́ Olùgbàlà wa, Ọlọ́run, lọ́ṣọ̀ọ́ nínú ohun gbogbo.”—Títù 2:9, 10.

Bí àpẹẹrẹ, wo lẹ́tà tí ọkùnrin oníṣòwò kan kọ ránṣẹ́ sí orílé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó ní: “Ìdí tí mo fi kọ lẹ́tà yìí ni pé, mo fẹ́ kẹ́ ẹ gbà mí láyè láti gba Ẹlẹ́rìí Jèhófà síbi iṣẹ́ mi. Àwọn ni mo fẹ́ gbà síṣẹ́ nítorí mo mọ̀ dájú pé wọn kì í ṣèrú, olóòótọ́ èèyàn ni wọ́n, wọ́n ṣe é fọkàn tán, wọn kì í sì í rẹ́ni jẹ. Ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan ni mo fọkàn tán. Ẹ jọ̀ọ́, ẹ bá mi ṣe é kó lè bọ́ sí i.”

Obìnrin kan tó jẹ́ Kristẹni tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kyle ń ṣiṣẹ́ ní ilé ìwé àdáni kan gẹ́gẹ́ bí olùgbàlejò. Èdè àìyedè tó wáyé láàárín òun àti obìnrin kan níbi iṣẹ́ wọn mú kí obìnrin náà bẹ̀rẹ̀ sí ṣépè fún Kyle níṣojú àwọn ọmọ ilé ìwé. Kyle sọ pé: “Mo gbìyànjú láti kó ara mi níjàánu kí n má bàa kó ẹ̀gàn bá orúkọ Jèhófà. Odindi ọjọ́ márùn-ún ni Kyle fi ronú lórí bí òun ṣe lè fi ìlànà Bíbélì yanjú ọ̀rọ̀ náà. Ó rántí ìlànà inú Róòmù 12:18 tó sọ pé: “Bí ó bá ṣeé ṣe, níwọ̀n bí ó bá ti jẹ́ pé ọwọ́ yín ni ó wà, ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn.” Kyle fi kọ̀ǹpútà kọ lẹ́tà sí obìnrin ará ibi iṣẹ́ rẹ̀ yìí láti fi tọrọ àforíjì nítorí èdè àìyedè tó wáyé náà. Kyle tún sọ fún un nínú lẹ́tà náà pé òun fẹ́ rí i lẹ́yìn iṣẹ́ kí wọ́n lè jọ yanjú ọ̀rọ̀ náà. Nígbà tí wọ́n ríra tí wọ́n sì yanjú ọ̀rọ̀ náà, inú obìnrin náà rọlẹ̀, ó sì lóun gbédìí fún Kyle nítorí ọgbọ́n tó fi bá òun sọ̀rọ̀. Ó sọ fún Kyle pé: “Mo mọ̀ pé ẹ̀sìn tó ò ń ṣe ló mú kó o lè ṣe ohun tó o ṣe yìí.” Obìnrin náà wá gbá a mọ́ra, lẹ́yìn náà kálukú wọn lọ sílé. Kí lohun tí Kyle wá sọ lẹ́yìn tí ọ̀rọ̀ yìí yanjú? Ó ní: “Ẹni bá tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì ò lè kọsẹ̀ láé.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4, 5]

Ọ̀pọ̀ òṣìṣẹ́ gbà pé àwọn ò fi bẹ́ẹ̀ wúlò mọ́

[Credit Line]

Japan Information Center, Consulate General of Japan in NY

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 8]

Ilé Ayé: Fọ́tò NASA