Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Iṣẹ́ Ṣíṣe Ti Wá Dọ̀ràn

Iṣẹ́ Ṣíṣe Ti Wá Dọ̀ràn

Iṣẹ́ Ṣíṣe Ti Wá Dọ̀ràn

“Iṣẹ́ ọmọ aláṣejẹ! Kò sóhun tó ń múnú èèyàn dùn bíi kéèyàn mọ̀ pé iṣẹ́ wà láti ṣe.” —Katherine Mansfield, òǹkọ̀wé (1888-1923).

ǸJẸ́ o fara mọ́ ohun tí òǹkọ̀wé yìí sọ nípa iṣẹ́ ṣíṣe? Kí ni èrò tìrẹ nípa iṣẹ́? Ǹjẹ́ o rò pé iṣẹ́ jẹ́ ohun àṣeèṣetán téèyàn máa ń rọ́jú ṣe kí òpin ọ̀sẹ̀ alárinrin tó dé? Àbí o fẹ́ràn iṣẹ́ rẹ débi pé o ò tiẹ̀ kì í fún ara rẹ nísinmi?

Ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn tó wà láyé yìí ló jẹ́ pé iṣẹ́ ni wọ́n ń fi èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àkókò wọn ṣe. Nígbà míì, iṣẹ́ tá à ń ṣe ló máa ń pinnu ibi tí a óò gbé àti irú ìgbésí ayé tá a máa gbé. Ọ̀pọ̀ èèyàn rí i pé kò sí ìsinmi kankan fáwọn látìgbà táwọn ti di géńdé títí dìgbà táwọn fẹ̀yìn tì lẹ́nu iṣẹ́, iṣẹ́ ni ṣáá. Àwọn kan sì wà tó jẹ́ pé iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe tẹ́ wọn lọ́rùn. Ohun táwọn kan fi ń díwọ̀n bí iṣẹ́ kan ṣe jọjú tó ni owó àti iyì tó wà nídìí iṣẹ́ bẹ́ẹ̀, àwọn mìíràn sì gbà pé ńṣe làwọn tó ń ṣiṣẹ́ ń fàkókò wọn ṣòfò tàbí pé àìrí-kan-ṣèkan ló ń dààmú wọn.

Nítorí àtijẹ làwọn kan ṣe ń ṣiṣẹ́, àwọn kan sì tún wà tó jẹ́ pé ayé iṣẹ́ ni wọ́n wá; ẹnu iṣẹ́ làwọn kan kú sí, bẹ́ẹ̀ sì rèé iṣẹ́ ló ṣekú pa àwọn míì. Bí àpẹẹrẹ, àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè sọ lẹ́nu àìpẹ́ yìí pé iye àwọn tí iṣẹ́ ń dá ìrora sí lára àtàwọn tí iṣẹ́ ń pa “pọ̀ ju àpapọ̀ iye àwọn tí ogun, oògùn líle àti ọtí àmujù” ń pa lọ. Nígbà tí ìwé ìròyìn The Guardian ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ń sọ̀rọ̀ lórí kókó yìí, ó ní: “Iye àwọn tó ń kú lọ́dọọdún nítorí jàǹbá àti àìsàn tí iṣẹ́ ń fà lé ní mílíọ̀nù méjì . . . Eruku àti kẹ́míkà táwọn èèyàn ń fà símú látinú afẹ́fẹ́ àti ariwo òun ìdọ̀tí burúkú tó ń jáde látinú ẹ̀rọ máa ń fa àrùn jẹjẹrẹ, àrùn ọkàn àti àìsàn rọpárọsẹ̀.” Ohun mìíràn tó burú jáì tó tún ń wáyé nídìí iṣẹ́ lóde òní ni bí wọ́n ṣe ń kó àwọn ọmọdé ṣiṣẹ́ tó ju agbára wọn lọ àti bí wọ́n ṣe ń fipá mú àwọn èèyàn ṣiṣẹ́.

Ní àfikún sí ìyẹn, afìṣemọ̀rònú ẹ̀dá kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Steven Berglas jẹ́ ká mọ̀ pé ìgbà mìíràn wà tí iṣẹ́ máa ń dá àwọn tó ń ṣiṣẹ́ àṣekúdórógbó lágara. Ó ṣàlàyé pé òṣìṣẹ́kára tó ti dọ̀gá lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀ lè “máa bẹ̀rù, kó máa ní ìdààmú ọkàn, kí gbogbo nǹkan tojú sú u tàbí kó kárí sọ nítorí èrò pé òun ti há sídìí iṣẹ́ tí òun ń ṣe, pé kò sí ọ̀nà àbáyọ kankan fóun. Ó tiẹ̀ lè má gbádùn iṣẹ́ tó ń ṣe mọ́.”

Ìyàtọ̀ Iṣẹ́ Àṣekára àti Iṣẹ́ Àṣekúdórógbó

Nínú ayé tí ọ̀pọ̀ èèyàn ti ń lo ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkókò lẹ́nu iṣẹ́ yìí, ó dára ká mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín iṣẹ́ àṣekára àti iṣẹ́ àṣekúdórógbó. Ọ̀pọ̀ èèyàn tó ń ṣiṣẹ́ àṣekúdórógbó ka ibi iṣẹ́ sí ibi tó lè fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ nínú ayé eléwu tí kò fini lọ́kàn balẹ̀ yìí, àmọ́ ńṣe làwọn òṣìṣẹ́kára ka iṣẹ́ sí ohun pàtàkì àtohun tó lè mú kí wọ́n ṣe ojúṣe wọn. Àwọn tó ń ṣiṣẹ́ àṣekúdórógbó kì í sábà ráyè fún nǹkan mìíràn nígbèésí ayé wọn, ṣùgbọ́n àwọn òṣìṣẹ́kára mọ ìgbà tó yẹ káwọn ṣíwọ́ iṣẹ́, wọ́n mọ ìgbà tó yẹ káwọn ṣe nǹkan míì irú bíi kí wọ́n ṣèrántí àyájọ́ ìgbéyàwó wọn. Ńṣe ni iṣẹ́ máa ń pa àwọn tó ń ṣiṣẹ́ àṣekúdórógbó bí ọtí, àmọ́ tàwọn òṣìṣẹ́kára ò rí bẹ́ẹ̀.

Àwọn èèyàn òde ìwòyí ń pọ́n iṣẹ́ àṣekúdórógbó gan-an ni, ìdí nìyí tó fi ṣòro fáwọn kan láti mọ ìyàtọ̀ nínú iṣẹ́ àṣekára àti iṣẹ́ àṣekúdórógbó. Tẹlifóònù alágbèéká àti irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ kò jẹ́ kí ìyàtọ̀ wà mọ́ láàárín ìgbà téèyàn wà níbi iṣẹ́ àti ìgbà téèyàn wà nílé. Nítorí pé ìgbàkigbà àti ibikíbi lẹni tó bá ń lo àwọn nǹkan wọ̀nyẹn ti lè máa bá iṣẹ́ rẹ̀ nìṣó, àwọn kan ti fi iṣẹ́ ṣíṣe ṣe ara wọn léṣe.

Kí làwọn kan ṣe nípa irú ohun tí kò bára dé yìí? Àwọn onímọ̀ nípa ìbágbépọ̀ ẹ̀dá rí i pé àwọn tó ń ṣiṣẹ́ àṣekúdórógbó àtàwọn tí iṣẹ́ ti dá lágara ti mú ìjọsìn wọnú iṣẹ́, pé wọ́n sì ti ń da ẹ̀sìn pọ̀ mọ́ iṣẹ́. Ìwé Ìròyìn San Francisco Examiner ròyìn pé “dída ẹ̀sìn pọ̀ mọ́ iṣẹ́ ti di ohun tí wọ́n ń ṣe níbi gbogbo báyìí.”

Ìròyìn kan tí wọ́n gbé jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí sọ nípa ibì kan tó ń jẹ́ Silicon Valley lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, tí wọ́n ti máa ń ṣe àwọn nǹkan abánáṣiṣẹ́ lóríṣiríṣi. Ìròyìn náà sọ pé: “Bí àyè ibi táwọn òṣìṣẹ́ ń gbé ọkọ̀ wọn sí níbi iṣẹ́ ṣe túbọ̀ ń ṣófo nítorí pé wọ́n ń dá àwọn òṣìṣẹ́ dúró, bẹ́ẹ̀ ni àyè ìgbọ́kọ̀sí ń kún àkúnya láwọn ibi táwọn èèyàn ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́.” Ohun yòówù tí ì báà mú kó rí bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn kárí ayé ló rí i pé Bíbélì ń mú káwọn ní èrò tó yẹ nípa iṣẹ́, èyí sì ti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti mọ bó ṣe yẹ kí wọ́n máa gbé ìgbésí ayé wọn.

Báwo ni Bíbélì ṣe lè mú ká ní èrò tó yẹ nípa iṣẹ́? Ǹjẹ́ ìlànà kankan wà nínú Ìwé Mímọ́ tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti borí àwọn ìṣòro tó wà nídìí iṣẹ́ òde ìwòyí? Àpilẹ̀kọ tó kàn yóò dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.