Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Philo Ará Alẹkisáńdíríà Ẹni Tó Ń Dorí Ìwé Mímọ́ Kodò

Philo Ará Alẹkisáńdíríà Ẹni Tó Ń Dorí Ìwé Mímọ́ Kodò

Philo Ará Alẹkisáńdíríà Ẹni Tó Ń Dorí Ìwé Mímọ́ Kodò

NÍ ỌDÚN 332 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Alẹkisáńdà Ńlá kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ wọ orílẹ̀-èdè Íjíbítì. Ó tẹ ìlú kan dó níbẹ̀ tó pè ní Alẹkisáńdíríà kó tó máa lọ sí ìhà ìlà oòrùn ayé bó ṣe ń jagun kiri nítorí àtidi alákòóso gbogbo ayé. Ìlú yìí wá di ojúkò àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àwọn Gíríìkì. Ní nǹkan bí ọdún 20 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, wọ́n bí aṣẹ́gun mìíràn ní ìlú yìí. Ṣùgbọ́n ohun ìjà tirẹ̀ kì í ṣe ọ̀kọ̀ tàbí idà, kàkà bẹ́ẹ̀ èrò ara rẹ̀ ló fi ń ja àjàṣẹ́gun. Orúkọ tí wọ́n ń pe ọ̀mọ̀ràn ọ̀hún ni Philo ará Alẹkisáńdíríà, wọ́n sì tún ń pè é ní Philo Judaeus torí pé Júù ni.

Lẹ́yìn tí wọ́n pa Jerúsálẹ́mù run lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn Júù fọ́n káàkiri, èyí tó mú kí ọ̀pọ̀ lára wọn lọ máa gbé ní Íjíbítì. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún lára wọn ló sì ń gbé nílùú Alẹkisáńdíríà. Ṣùgbọ́n nǹkan ò lọ déédéé láàárín àwọn Júù àtàwọn Gíríìkì tí wọ́n jọ ń gbébẹ̀. Àwọn Júù ò fẹ́ jọ́sìn àwọn ọlọ́run èké táwọn Gíríìkì ń sìn, bẹ́ẹ̀ làwọn Gíríìkì náà ń fojú tẹ́ńbẹ́lú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Philo mọ gbogbo ohun tó ń lọ láàárín àwọn méjèèjì dáadáa torí pé Júù ni òun fúnra rẹ̀, àwọn Gíríìkì ló sì kọ́ ọ níwèé. Philo gbà gbọ́ pé ẹ̀sìn àwọn Júù lẹ̀sìn tòótọ́. Àmọ́ kò ṣe bíi ti ọ̀pọ̀ èèyàn tí wọ́n ń fipá múni ṣẹ̀sìn, kàkà bẹ́ẹ̀ ẹ̀sọ̀ pẹ̀lẹ́ ló fẹ́ fi mú kí àwọn Kèfèrí mọ Ọlọ́run. Ó fẹ́ ṣe ohun tó máa mú kí wọ́n gba ẹ̀sìn àwọn Júù.

Ó Gbé Ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́ Gbòdì

Èdè Gíríìkì ni èdè àbínibí Philo, èdè náà sì ni ọ̀pọ̀ lára àwọn Júù tó wà ní Alẹkisáńdíríà ń sọ. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé Bíbélì Septuagint, ìyẹn Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tí wọ́n tú sí èdè Gíríìkì, ló gbé gbogbo ìwádìí tó ṣe kà. Nígbà tó ṣàyẹ̀wò Bíbélì Septuagint, ó gbà pé èrò èèyàn ló wà nínú rẹ̀, àti pé “ọ̀mọ̀ràn tó jáfáfá ni Mósè.”

Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún kí Philo tó dáyé, ó ṣòro fún àwọn ọ̀mọ̀ràn ilẹ̀ Gíríìsì láti gbà pé òótọ́ làwọn ìtàn nípa àwọn ọlọ́run àti abo-ọlọ́run wọn, ìyẹn àwọn òmìrán àtàwọn ẹ̀mí èṣù inú ìtàn ìwáṣẹ̀ wọn. Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí gbé ìtumọ̀ àwọn ìtàn yẹn gba ibòmíì. Ọ̀mọ̀wé kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ James Drummond, tó mọ̀ nípa ìṣẹ̀dálẹ̀ àwọn Gíríìkì ṣàlàyé bí wọ́n ṣe ṣe é, ó ní: “Ńṣe làwọn ọ̀mọ̀ràn náà máa ń wá ìtumọ̀ abẹ́nú sí àwọn ìtàn wọ̀nyẹn. Tí wọ́n bá fara balẹ̀ wo àwọn ìtàn náà, tó jọ pé kò bọ́gbọ́n mu tó sì lè mú kéèyàn máa ro ìròkurò, wọ́n á sọ pé ó ní láti jẹ́ pé àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì kan wà táwọn tó sọ ìtàn yẹn ń fẹ́ kéèyàn kọ́ látinú wọn.” Ìtándòwe ni wọ́n ka irú àwọn ìtàn bẹ́ẹ̀ sí, ojú yẹn sì ni Philo fi wo Ìwé Mímọ́.

Bí àpẹẹrẹ, wo ọ̀rọ̀ inú Jẹ́nẹ́sísì 3:213:22 nínú Bíbélì Septuagint tí Bagster ṣe, èyí tó kà pé: “Olúwa Ọlọ́run ṣe ẹ̀wù awọ fún Ádámù àti aya rẹ̀, ó sì fi wọ̀ wọ́n.” Lójú àwọn Gíríìkì, iyì àti ògo Ọlọ́run Olódùmarè pọ̀ ju kó máa ṣe aṣọ lọ. Ìyẹn ló mú kí Philo wá ìtumọ̀ abẹ́nú kan sí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn, ó ní: “Ẹ̀wù awọ náà dúró fún ara èèyàn; nítorí pé nígbà tí Ọlọ́run kọ́kọ́ ṣe agbára ìrònú, ó pè é ní Ádámù; lẹ́yìn èyí ló dá ẹ̀mí tó mú kó di alààyè, èyí tó pè ní Ìyè. Níkẹyìn ló wá ṣe ara fún un, èyí tó pè ní ẹ̀wù awọ lọ́nà àpèjúwe.” Bí Philo ṣe wá ìtumọ̀ abẹ́nú sí wíwọ̀ tí Ọlọ́run wọ Ádámù àti Éfà láṣọ nìyẹn.

Ẹ jẹ́ ká tún gbé Jẹ́nẹ́sísì 2:10-14 yẹ̀ wò. Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí sọ̀rọ̀ nípa orísun omi inú ọgbà Édẹ́nì, ó sì tún sọ àwọn odò mẹ́rin tó ń ṣàn jáde látinú ọgbà náà. Philo gbìyànjú láti wá ìtumọ̀ abẹ́nú sí àwọn ọ̀rọ̀ tí Bíbélì fi ṣàpèjúwe ọgbà Édẹ́nì yìí. Lẹ́yìn tó ti sọ̀rọ̀ nípa ilẹ̀ ọgbà Édẹ́nì náà, ó ní: “Ó ṣeé ṣe kí ìtumọ̀ abẹ́nú kan wà nínú àyọkà yìí nítorí pé ànímọ́ mẹ́rin ni odò mẹ́rin yìí dúró fún.” Ó wò ó pé odò Píṣónì dúró fún ọgbọ́n, odò Gíhónì dúró fún àròjinlẹ̀, odò Tígírísì dúró fún ìfaradà, odò Yúfírétì sì dúró fún ìdájọ́ òdodo. Bí Philo ṣe fi ìtumọ̀ abẹ́nú tó fún àyọkà yìí rọ́pò ohun tí Bíbélì sọ nípa ilẹ̀ ọgbà Édẹ́nì nìyẹn.

Philo tún wá ìtumọ̀ abẹ́nú sí ìtàn bí Ọlọ́run ṣe dá àwọn nǹkan, bí Kéènì ṣe pa Ébẹ́lì, Ìkún Omi ọjọ́ Nóà, bí Ọlọ́run ṣe da èdè àwọn èèyàn rú ní Bábélì, àti ọ̀pọ̀ òfin àti ìlànà inú Òfin Mósè. Bí àpẹẹrẹ tó wà ní ìpínrọ̀ òkè yìí ṣe fi hàn, Philo sábà máa ń gbà pé òótọ́ lohun tí ẹsẹ Bíbélì kan ń sọ, lẹ́yìn náà yóò wá wá ìtumọ̀ abẹ́nú sí i. Irú ohun tó máa ń sọ tó bá fẹ́ ṣe èyí ni pé: “Ó dà bí ẹni pé àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ní ìtumọ̀ abẹ́nú.” Nínú àwọn ìwé tí Philo kọ, ńṣe ló fi àwọn ìtumọ̀ abẹ́nú bo ọ̀rọ̀ Ìwé Mímọ́ mọ́lẹ̀, èyí sì burú gan-an.

Ta Ni Ọlọ́run?

Philo lo àkàwé kan tó lè múni ronú jinlẹ̀ láti jẹ́ kó hàn láìsí iyèméjì pé Ọlọ́run wà. Lẹ́yìn tó ti ṣàpèjúwe ilẹ̀, odò, ìràwọ̀, oòrùn àtàwọn ọ̀wọ́ rẹ̀ tí Ọlọ́run dá, ó sọ pé: “Nínú gbogbo ìṣẹ̀dá, ilẹ̀ ayé la fi ọgbọ́n àti òye tó ga jù lọ ṣe, bí ẹni pé ẹnì kan tó jẹ́ ọba ọgbọ́n àti olóye ló ṣe é. Àwọn ohun tá a fi mọ̀ pé Ọlọ́run wà nìyẹn.” Ká sòótọ́, àlàyé tó ṣe yìí bọ́gbọ́n mu.—Róòmù 1:20.

Àmọ́ nígbà tí Philo ń ṣàlàyé ẹni tí Ọlọ́run Olódùmarè jẹ́, ohun tó sọ jìnnà gan-an sí òtítọ́. Philo sọ pé Ọlọ́run “kò ní ànímọ́ pàtó kan tá a lè fi mọ̀ ọ́n,” bẹ́ẹ̀ ni “kò sẹ́ni tó lè lóye” Ọlọ́run. Philo kò fún àwọn èèyàn níṣìírí láti mọ Ọlọ́run, ohun tó ń sọ ni pé “téèyàn bá ní kí òun máa ṣèwádìí síwájú nípa Ọlọ́run, kí onítọ̀hún lè mọ ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ gan-an tàbí àwọn ànímọ́ pàtó kan tá a lè fi mọ̀ ọ́n, ìwà ẹ̀gọ̀ pátápátá ni onítọ̀hún ń hù.” Bíbélì kò sọ ohun tó jẹ mọ́ ohun tó sọ yìí rárá o, kàkà bẹ́ẹ̀ Plato tó jẹ́ ọ̀mọ̀ràn àti abọ̀rìṣà ló sọ bẹ́ẹ̀.

Philo sọ pé Ọlọ́run ò ṣeé mọ̀ rárá, ó tiẹ̀ ní èèyàn ò lè máa fi orúkọ pàtó kan pè é. Ó ní: “Nítorí náà, ó bọ́gbọ́n mu tá a bá sọ pé kò sí orúkọ pàtó kan tá a lè fún Ọlọ́run alààyè.” Irọ́ ọkùnrin yìí mà pọ̀ o!

Bíbélì jẹ́ kó yé wa gbangba pé Ọlọ́run ní orúkọ. Sáàmù 83:18 sọ pé: “Ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.” Aísáyà 42:8 sọ ohun tí Ọlọ́run fi ẹnu ara rẹ̀ sọ, ìyẹn ni pé: “Èmi ni Jèhófà. Èyí ni orúkọ mi.” Kí nìdí tí Philo tó jẹ́ Júù tó sì mọ àwọn ẹsẹ Bíbélì wọ̀nyí dáadáa ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn pé Ọlọ́run kò ní orúkọ? Ìdí ni pé kì í ṣe Ọlọ́run tòótọ́ tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ló ń ṣàpèjúwe; ọlọ́run tí kò lórúkọ, téèyàn ò sì lè mọ̀, táwọn ọ̀mọ̀ràn Gíríìkì gbà gbọ́ ló ń ṣàpèjúwe.

Kí Ni Ọkàn?

Philo kọ́ àwọn èèyàn pé ọkàn yàtọ̀ sí ara. Ó ní ara àti ọkàn ló para pọ̀ di èèyàn. Ǹjẹ́ ọkàn lè kú? Wo àlàyé tí Philo ṣe, ó ní: “Bá a ṣe wà láàyè yìí, ara wa ló wà láàyè ṣùgbọ́n ọkàn wa ti kú, a sì ti sin ín sínú ara wa, bí ẹni pé ó wà nínú sàréè. Àmọ́ bí [ara] bá kú, ìgbà yẹn gan-an ni ọkàn máa gbé ayé rẹ̀ bó ṣe yẹ, torí pé nígbà yẹn á ti kúrò nínú ara ẹ̀ṣẹ̀ tó ti di òkú níbi tí a sé e mọ́.” Lójú Philo, tá a bá sọ pé ọkàn kú èdè àpèjúwe ló jẹ́, kì í ṣe pé ó kú lóòótọ́. Ó gbà pé ọkàn ò lè kú rárá.

Àmọ́, kí ni Bíbélì fi kọ́ wa nípa ọkàn? Jẹ́nẹ́sísì 2:7 sọ pé: “Jèhófà Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣẹ̀dá ọkùnrin náà láti inú ekuru ilẹ̀, ó sì fẹ́ èémí ìyè sínú ihò imú rẹ̀, ọkùnrin náà sì wá di alààyè ọkàn.” Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwa èèyàn kò ọkàn; kàkà bẹ́ẹ̀, àwa fúnra wa gan-an ni ọkàn.

Bíbélì tún jẹ́ ká mọ̀ pé ọkàn lè kú. Ìsíkíẹ́lì 18:4 sọ pé: “Ọkàn tí ń dẹ́ṣẹ̀—òun gan-an ni yóò kú.” Àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wọ̀nyí jẹ́ kí ohun kan ṣe kedere sí wa, ìyẹn ni pé: Èèyàn kan jẹ́ ọkàn kan. Nítorí náà, béèyàn kan bá kú, ọkàn kan ti kú nìyẹn.—Jẹ́nẹ́sísì 19:19. a

Lẹ́yìn ikú Philo, àwọn Júù ò fi bẹ́ẹ̀ kọbi ara sí ẹ̀kọ́ rẹ̀. Ṣùgbọ́n, àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ń gbé ẹ̀kọ ẹ̀ gẹ̀gẹ̀. Eusebius àtàwọn olórí ìjọ mìíràn gbà gbọ́ pé Philo di Kristẹni kó tó kú. Jerome sì sọ pé ó wà lára àwọn Bàbá Ìjọ. Àwọn Júù tí ì bá tọ́jú àwọn ìwé Philo kò tọ́jú rẹ̀, àwọn Kristẹni apẹ̀yìndà ló tọ́jú rẹ̀.

Àwọn ìwé Philo jẹ́ kí ọ̀pọ̀ nǹkan yí padà nínú ìsìn Kristẹni. Ohun tó kọ ló jẹ́ káwọn tó pera wọn ní Kristẹni gba ẹ̀kọ́ kan tí kò sí nínú Ìwé Mímọ́ gbọ́, ìyẹn ẹ̀kọ́ pé ọkàn kì í kú. Bákan náà, ẹ̀kọ́ tó kọ́ àwọn èèyàn nípa Logos (tàbí, Ọ̀rọ̀) wà lára ohun tó jẹ́ káwọn oníṣọ́ọ̀ṣì gba Mẹ́talọ́kan gbọ́, ẹ̀kọ́ àwọn Kristẹni apẹ̀yìndà yìí ò sì sí nínú Bíbélì rárá.

Má Ṣe Jẹ́ Kí Ẹnikẹ́ni Tàn Ọ́ Jẹ

Ní gbogbo ìgbà tí Philo fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, ó rí i dájú pé “òun wá ìtumọ̀ abẹ́nú sí gbogbo ọ̀rọ̀ tó ṣe kedere tó wà nínú rẹ̀.” Àmọ́ nínú Diutarónómì 4:2, ohun tí Mósè sọ nípa Òfin Ọlọ́run ni pé: “Ẹ kò gbọ́dọ̀ fi kún ọ̀rọ̀ tí mo ń pa láṣẹ fún yín, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ mú kúrò lára rẹ̀, kí ẹ bàa lè pa àwọn àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run yín tí mo ń pa láṣẹ fún yín mọ́.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ohun tó dára ni Philo ní lọ́kàn, àmọ́ ọ̀pọ̀ ohun tí kì í ṣe òótọ́ tó jẹ́ ìrònú ọmọ èèyàn ló fi bo ìtọ́ni tó ṣe kedere tó wà nínú Bíbélì, ìyẹn ìwé tí Ọlọ́run mí sí, mọ́lẹ̀.

Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé: “Kì í ṣe nípa títẹ̀lé àwọn ìtàn èké àdọ́gbọ́nhùmọ̀ lọ́nà àrékendá ni àwa fi sọ yín di ojúlùmọ̀ agbára àti wíwàníhìn-ín Olúwa wa Jésù Kristi.” (2 Pétérù 1:16) Ohun tí Pétérù kọ yàtọ̀ sí ti Philo, torí pé ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an ni àpọ́sítélì yìí sọ fún ìjọ Kristẹni ìjímìjí, ẹ̀mí Ọlọ́run, ìyẹn “ẹ̀mí òtítọ́ náà” ló sì darí rẹ̀. Ẹ̀mí yìí ló ṣamọ̀nà àwọn Kristẹni ìjímìjí sínú òtítọ́ gbogbo.—Jòhánù 16:13.

Bó o bá fẹ́ láti sin Ọlọ́run tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, ohun tó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ ni ìtọ́sọ́nà tó jẹ́ òtítọ́, kì í ṣe àwọn àlàyé tó dá lórí èrò ọmọ aráyé. O gbọ́dọ̀ ní ìmọ̀ tó péye nípa Jèhófà àti ohun tó fẹ́, o sì gbọ́dọ̀ ní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ kó o tó lè kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tọkàntọkàn. Bó o bá fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wàá mọ “ìwé mímọ́, èyí tí ó lè sọ ọ́ di ọlọ́gbọ́n fún ìgbàlà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Kristi Jésù.” Wàá rí i pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè sọ ọ́ di ẹni tó “pegedé ní kíkún, tí a mú gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.”—2 Tímótì 3:15-17.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Jewish Encyclopedia ti ọdún 1910 ṣàlàyé kan nípa ọkàn, ó ní: “Ìgbàgbọ́ táwọn èèyàn ní pé ọkàn ń wà láàyè nìṣó lẹ́yìn tí ara bá ti jẹrà jẹ́ èrò àwọn ọ̀mọ̀ràn àti tàwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn, kì í sì í ṣe orí ìgbàgbọ́ tòótọ́ ni wọ́n gbé e kà. Bákan náà, kò síbi tí Ìwé Mímọ́ ti dìídì kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ yìí.”

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

ÌLÚ PHILO

Ìlú Alẹkisáńdíríà tó wà ní Íjíbítì ni Philo gbé, ibẹ̀ ló sì ti ṣiṣẹ́. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ni ìlú náà fi jẹ́ ibi tó gbajúmọ̀ torí pé ibẹ̀ ni ìwé pin sí láyé nígbà àtijọ́, àwọn ọ̀mọ̀wé sì máa ń ṣe àpérò níbẹ̀ dáadáa.

Àwọn ọ̀mọ̀wé olókìkí ni olùkọ́ tó ń kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ níwèé ní ìlú náà. Ilé ìkówèésí ìlú Alẹkisáńdíríà wá gbajúmọ̀ gan-an torí pé jákèjádò ayé ni wọ́n ti mọ̀ ọ́n. Àwọn ìwé ibẹ̀ ò lóǹkà torí pé ńṣe làwọn tó ń bójú tó ibẹ̀ máa ń gbìyànjú láti wá gbogbo ìwé tí wọ́n bá gbọ́ pé ó wà kí wọ́n lè fi síbẹ̀.

Nígbà tó yá, díẹ̀díẹ̀ ni iyì àti ògo táwọn èèyàn ń fún ìlú Alẹkisáńdíríà àti ilé ìkówèésí ńlá tó wà níbẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí lọ sílẹ̀. Àwọn olú ọba tó wà nílùú Róòmù bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun tó máa mú kí ìlú wọn gbayì ju àwọn ìlú mìíràn lọ, bí Yúróòpù ṣe wá di ojúkò àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ nìyẹn. Ọ̀rúndún keje Sànmánì Kristẹni ni ògo ìlú Alẹkisáńdíríà wọmi pátápátá nígbà táwọn tó kógun wá síbẹ̀ pa ìlú náà run. Títí di òní olónìí, ó ṣì ń dun àwọn òpìtàn pé wọ́n ba ilé ìkówèésí náà jẹ́, àní àwọn kan tiẹ̀ ń sọ pé ìfàsẹ́yìn tó kó bá ìlú yẹn pọ̀ débi pé yóò tó ẹgbẹ̀rún ọdún kí gbogbo nǹkan tó lè rí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀ níbẹ̀.

[Credit Line]

L. Chapons/Illustrirte Familien-Bibel nach der deutschen Uebersetzung Dr. Martin Luthers

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 12]

ÀWỌN KAN KA Ọ̀RỌ̀ BÍBÉLÌ SÍ ÒWE LÓDE ÒNÍ

Tí ìtàn kan bá jẹ́ òwe, ohun tí wọ́n tọ́ka sí àti ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ níbẹ̀ sábà máa ń jẹ́ àkàwé tàbí nǹkan ìṣàpẹẹrẹ. Wọ́n máa ń fi ìtàn yẹn sọ àwọn ohun kan tó jẹ́ òtítọ́ tàbí ìwà àwọn èèyàn. Àwọn ìtàn tó bá jẹ́ òwe máa ń ní àwọn ìtumọ̀ abẹ́nú kan tó ṣe pàtàkì. Lóde òní, àwọn olùkọ́ ìsìn kan ń ṣe bíi ti Philo ará Alẹkisáńdíríà, wọ́n ka ọ̀rọ̀ Bíbélì sí òwe, wọ́n wá ń wá ìtumọ̀ abẹ́nú sí ọ̀rọ̀ inú rẹ̀.

Ẹ jẹ́ ká wo ohun tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì orí kìíní sí ìkọkànlá, níbi tí ìtàn ìran èèyàn látìgbà ìṣẹ̀dá títí dìgbà tí Ọlọ́run da èdè àwọn èèyàn rú níbi ilé gogoro Bábélì wà. Nígbà tí Bíbélì The New American Bible tí àwọn Kátólíìkì ṣe ń sọ̀rọ̀ nípa apá ibí yìí nínú Bíbélì, ó sọ pé: “Kẹ́nì kan tó lè ṣàlàyé àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ wọ̀nyí lọ́nà tó máa yé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì táwọn ẹ̀kọ́ náà wà fún, onítọ̀hún ní láti fi àwọn ohun táwọn èèyàn tó ń gbé láyé ìgbà yẹn mọ̀ dájú ṣàlàyé wọn. Nítorí ìdí yìí, èèyàn ò kàn ní gba àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn bí wọ́n ṣe kọ wọ́n síbẹ̀ nítorí pé wọ́n ní ìtumọ̀ mìíràn.” Lójú tiwọn, kò yẹ ká wo ọ̀rọ̀ inú Jẹ́nẹ́sísì orí kìíní sí ìkọkànlá pé bá a ṣe kà á gan-an ló rí. Dípò ìyẹn, wọ́n gbà pé bí ẹ̀wù ṣe ń bo ara náà làwọn ọ̀rọ̀ yẹn ṣe bó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtumọ̀ mọ́lẹ̀.

Àmọ́, Jésù kọ́ àwọn èèyàn pé bí ọ̀rọ̀ ṣe rí gan-an ló ṣe wà nínú àwọn orí wọ̀nyẹn nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì. (Mátíù 19:4-6; 24:37-39) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti Pétérù náà gbà bẹ́ẹ̀. (Ìṣe 17:24-26; 2 Pétérù 2:5; 3:6, 7) Nítorí náà, àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tọkàntọkàn kì í gba àwọn àlàyé tí kò bá bá Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mu látòkèdélẹ̀.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Ilé atọ́nà ọkọ̀ òkun tó wà nílùú Alẹkisáńdíríà

[Credit Line]

Archives Charmet / Bridgeman Art Library