Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

‘Wọ́n Ṣe Inúnibíni sí Riet Nítorí Ìgbàgbọ́ Rẹ̀’

‘Wọ́n Ṣe Inúnibíni sí Riet Nítorí Ìgbàgbọ́ Rẹ̀’

‘Wọ́n Ṣe Inúnibíni sí Riet Nítorí Ìgbàgbọ́ Rẹ̀’

NÍ ÌLÚ Cernobbio ní àríwá orílẹ̀-èdè Ítálì, wọ́n ṣe ibì kan sínú ọgbà ìtura kan ní ìrántí àwọn tí wọ́n fi ẹ̀tọ́ wọn dù. Wọ́n gbé àmì ẹ̀yẹ kan sí ọgbà náà ní ìrántí Narciso Riet. Ọmọ orílẹ̀-èdè Ítálì làwọn òbí Riet, àmọ́ orílẹ̀-èdè Jámánì ni wọ́n bí i sí, àárín ọdún 1930 sí 1939 ló sì di ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ìjọba fojú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà han èèmọ̀ nígbà ìjọba Hitler nítorí pé wọn ò gbé Hitler ga ju Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́.

Nígbà tí Riet rí i pé àwọn ọlọ́pàá Gestapo ti mọ̀ pé òun ń kó ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ lọ sáwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, ó sá lọ sílùú Cernobbio. Nígbà tó débẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbẹ̀ sọ fún un pé kó máa túmọ̀ Ilé Ìṣọ́ sí èdè Ítálì, kó sì máa kó o lọ fáwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n ń gbé nítòsí ibẹ̀. Bó ṣe ń lọ tó ń bọ̀ làwọn ọlọ́pàá ń rí. Lọ́jọ́ kan, ọlọ́pàá SS kan àtàwọn ọlọ́pàá tó wà lábẹ́ rẹ̀ já wọ ilé Riet, wọ́n sì mú un. Wọ́n gba Bíbélì méjì àti lẹ́tà bíi mélòó kan lọ́wọ́ rẹ̀, àwọn nǹkan tí wọ́n sì rí nìyẹn tí wọ́n fi pè é ní ọ̀daràn. Àbẹ́ẹ̀rí nǹkan! Wọ́n dá Riet padà sí Jámánì, wọ́n sì sọ ọ́ sínú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ tó wà nílùú Dachau kó tó di pé wọ́n wá pa á nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì ń parí lọ. Ohun tó wà lára àmì ẹ̀yẹ tí wọ́n gbé sílùú Cernobbio ni pé ‘wọ́n ṣe inúnibíni sí Riet nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀.’

Ìṣírí ńlá ni ìgbàgbọ́ Narciso Riet àti ti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí tí ìjọba Násì ṣe inúnibíni sí jẹ́ fáwa Kristẹni tí ń bẹ lóde òní nítorí pé àpẹẹrẹ wọn lè ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ adúróṣinṣin sí Jèhófà, Ẹnì kan ṣoṣo tó yẹ ká máa jọ́sìn láyé àti lọ́run. (Ìṣípayá 4:11) Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí a ti ṣe inúnibíni sí nítorí òdodo.” Ọlọ́run ò ní gbàgbé wọn, yóò sì bù kún wọn nítorí pé wọ́n fi ìgboyà ṣe ìfẹ́ rẹ̀.—Mátíù 5:10; Hébérù 6:10.