Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Èèyàn Ń Wá Bí Wọ́n Ṣe Máa Ní Ìbàlẹ̀ Ọkàn

Àwọn Èèyàn Ń Wá Bí Wọ́n Ṣe Máa Ní Ìbàlẹ̀ Ọkàn

Àwọn Èèyàn Ń Wá Bí Wọ́n Ṣe Máa Ní Ìbàlẹ̀ Ọkàn

BAÁLÉ ilé tó láyọ̀ gan-an ni Albert. Ó bí ọmọ méjì tó ń múnú rẹ̀ dùn. Àmọ́, ó mọ̀ pé ohun kan ṣì wà tóun ò tíì ní. Nígbà kan tó wáṣẹ́ títí tí kò rí, ó lọ wọ ẹgbẹ́ òṣèlú, ó sì fara mọ́ èrò ìjọba àjùmọ̀ní. Kódà ó di akínkanjú nínú Ẹgbẹ́ Ìṣèlú Kọ́múníìsì tó wà ládùúgbò rẹ̀.

Àmọ́ ṣá o, láìpẹ́ láìjìnnà, ìjọba Kọ́múníìsì já Albert kulẹ̀. Bó ṣe pa ìṣèlú tì nìyẹn tó sì gbájú mọ́ títọ́jú ìdílé rẹ̀. Bí ìdílé rẹ̀ ṣe máa láyọ̀ lohun tó wá jẹ ẹ́ lógún jù lọ. Síbẹ̀ náà, Albert mọ̀ pé ohun kan ṣì wà tóun ò tíì ní. Kò tíì ní ìbàlẹ̀ ọkàn.

Kì í ṣe Albert nìkan ni irú nǹkan báyìí ń ṣẹlẹ̀ sí. Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ti dán oríṣiríṣi nǹkan wò, irú bí èròǹgbà ìṣèlú, èrò àwọn ọ̀mọ̀ràn, àti ẹ̀sìn kí wọ́n lè gbé ìgbésí ayé tó nítumọ̀. Ẹgbẹ́ ọ̀dọ́ kan tó dìde nílẹ̀ Yúróòpù àti Amẹ́ríkà láwọn ọdún 1960 jẹ́ ẹgbẹ́ tó ń ta ko ìlànà ìwà rere àti àjọṣe ẹgbẹ́-òun-ọ̀gbà. Àwọn èèyàn ń wá ayọ̀ àti ohun tí ìgbésí ayé túmọ̀ sí, àmọ́ àwọn ọ̀dọ́ gan-an ló ń wá a jù lọ, ìdí nìyẹn tí wọ́n fi ń lo oògùn olóró, tí wọ́n sì lọ ń gba àmọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn tó pe ara wọn ní baba ìsàlẹ̀ ẹgbẹ́ tó dìde nílẹ̀ Yúróòpù àti Amẹ́ríkà yìí. Síbẹ̀síbẹ̀, ẹgbẹ́ náà kò lè fún wọn ní ojúlówó ayọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ló mú káwọn tó ń lo oògùn olóró àtàwọn ọ̀dọ́ oníṣekúṣe pọ̀ sí i, ìyẹn sì mú kí àwùjọ òde òní túbọ̀ wá bà jẹ́ bàlùmọ̀.

Látọjọ́ tó ti pẹ́ làwọn èèyàn ti ń sapá láti ní ọrọ̀, agbára, tàbí ẹ̀kọ́ ìwé kí wọ́n lè láyọ̀. Àwọn ohun wọ̀nyí ti yọrí sí ìjákulẹ̀. Jésù sọ pé: “Nígbà tí ẹnì kan bá tilẹ̀ ní ọ̀pọ̀ yanturu pàápàá, ìwàláàyè rẹ̀ kò wá láti inú àwọn ohun tí ó ní.” (Lúùkù 12:15) Bẹ́ẹ̀ ni o, ìbànújẹ́ ni lílépa ọ̀rọ̀ sábà máa ń mú wá. Bíbélì sọ pé: “Àwọn tí ó pinnu láti di ọlọ́rọ̀ máa ń ṣubú sínú ìdẹwò àti ìdẹkùn àti ọ̀pọ̀ ìfẹ́-ọkàn tí í ṣe ti òpònú, tí ó sì ń ṣeni lọ́ṣẹ́, èyí tí ń ri ènìyàn sínú ìparun àti ègbé. Nítorí ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò onírúurú ohun aṣeniléṣe gbogbo, àti nípa nínàgà fún ìfẹ́ yìí, . . . àwọn kan . . . ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora gún ara wọn káàkiri.”—1 Tímótì 6:9, 10.

Báwo wá ni ẹnì kan ṣe lè ní ìbàlẹ̀ ọkàn kó sì gbé ìgbésí ayé tó nítumọ̀? Ṣé ọ̀rọ̀ ká máa dán oríṣiríṣi nǹkan tá a rò pé ó lè fini lọ́kàn balẹ̀ wò ni, bí ìgbà téèyàn ń tafà sí ohun tí kò rí dáadáa nínú òkùnkùn? A dúpẹ́ pé ọ̀ràn kò rí bẹ́ẹ̀, ọ̀nà tá a lè gbé e gbà wà. Gẹ́gẹ́ bá a ṣe máa rí i nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí, àtúnṣe náà yóò wá látinú bíbójú tó ohun kan tó ṣe pàtàkì gan-an tó jẹ́ pé ọmọ aráyé nìkan la dá a mọ́.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Ṣé lílépa ọrọ̀, agbára tàbí ẹ̀kọ́ ìwé lè mú ọ ní ìbàlẹ̀ ọkàn?