Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

‘Àwọn Tí Ń mú Ìhìn Rere Ohun Tí Ó Dára Jù Wá’

‘Àwọn Tí Ń mú Ìhìn Rere Ohun Tí Ó Dára Jù Wá’

‘Àwọn Tí Ń mú Ìhìn Rere Ohun Tí Ó Dára Jù Wá’

“Ẹsẹ̀ ẹni tí ń mú ìhìn rere wá mà dára rèǹtè-rente lórí àwọn òkè ńlá o . . . ẹni tí ń mú ìhìn rere ohun tí ó dára jù wá.”—AÍSÁYÀ 52:7.

1, 2. (a) Ohun ìbànújẹ́ wo ló máa ń ṣẹlẹ̀ lójoojúmọ́? (b) Báwo ni ìròyìn búburú tá a máa ń gbọ́ ní gbogbo ìgbà ṣe ń rí lára ọ̀pọ̀ èèyàn?

 ÀWỌN èèyàn jákèjádò ayé lónìí gbà pé ìròyìn burúkú làwọn ń gbọ́ ní gbogbo ìgbà. Bí wọ́n bá ṣí rédíò wọn, àwọn ìròyìn tó ń jáni láyà nípa àwọn àrùn gbẹ̀mígbẹ̀mí tí ń jà kárí ayé ni wọ́n máa ń gbọ́. Bí wọ́n bá tan tẹlifíṣọ̀n, àwòrán àwọn ọmọ tí kò róúnjẹ jẹ, tí wọ́n ti rù hangogo tí wọ́n sì ń bẹ̀bẹ̀ pé káwọn èèyàn ran àwọn lọ́wọ́ ni wọ́n máa ń rí. Irú àwọn àwòrán yìí kì í sì í kúrò lọ́kàn ẹni bọ̀rọ̀. Bí wọ́n bá gbé ìwé ìròyìn láti kà, ìròyìn bí bọ́ǹbù ṣe ya ilé lulẹ̀, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀mí àwọn tí ò mọwọ́-mẹsẹ̀ sì ṣòfò ni wọ́n máa ń rí kà.

2 Bẹ́ẹ̀ ni o, ojoojúmọ́ làwọn ohun tó jẹ́ ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ ń ṣẹlẹ̀. Ká sòótọ́, ayé yìí ń yí padà, nǹkan sì túbọ̀ ń burú sí i. (1 Kọ́ríńtì 7:31) Ìwé ìròyìn kan láti Ìwọ̀ Oòrùn ilẹ̀ Yúróòpù sọ pé nígbà míì, ńṣe ló máa ń dà bíi pé gbogbo àgbáyé “fẹ́ gbiná.” Abájọ tí ìbànújẹ́ fi ń dorí ọ̀pọ̀ èèyàn kodò! Nínú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe nípa ìròyìn orí tẹlifíṣọ̀n nílẹ̀ Amẹ́ríkà, ẹnì kan tí wọ́n fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ sọ bí ọ̀ràn náà ṣe rí lára òun, ó sì dájú pé ohun tó wà lọ́kàn ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn náà nìyẹn, ó ní: ‘Tí mo bá ti gbọ́ ìròyìn orí tẹlifíṣọ̀n tán, ṣe ni inú mi máa ń bà jẹ́. Ìròyìn búburú ni wọ́n máa ń sọ ṣáá. Gbogbo ẹ̀ tojú sú mi.’

Ìròyìn Tó Yẹ Kí Gbogbo Èèyàn Gbọ́

3. (a) Ìhìn rere wo ni Bíbélì polongo rẹ̀? (b) Kí nìdí tó o fi gbà pé ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ṣe pàtàkì?

3 Nínú ayé tí ìbànújẹ́ ń dorí ẹni kodò yìí, ǹjẹ́ a tiẹ̀ lè rí ìròyìn rere kankan? Bẹ́ẹ̀ ni, a lè rí i! Ohun ìtùnú ló jẹ́ pé Bíbélì pòkìkí ìhìn rere. Ìròyìn náà ni pé Ìjọba Ọlọ́run yóò fòpin sí àìsàn, ebi, ìwà ọ̀daràn, ogun àti gbogbo ohun tó ń fa ìnira. (Sáàmù 46:9; 72:12) Ǹjẹ́ kì í ṣe irú ìròyìn tó yẹ kí gbogbo èèyàn máa gbọ́ nìyí? Ohun táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà rò nìyẹn. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé ibi gbogbo làwọn èèyàn ti mọ̀ wá pé à ń sapá gidigidi láti máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè.—Mátíù 24:14.

4. Apá wo nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa la óò gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ yìí àti nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e?

4 Àmọ́, kí la lè ṣe láti rí i dájú pé à ń kópa pàtàkì nínú iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere yìí, kódà ní ìpínlẹ̀ táwọn èèyàn kì í ti í fi bẹ́ẹ̀ tẹ́tí sílẹ̀? (Lúùkù 8:15) Bá a bá ṣe àyẹ̀wò ṣókí nípa apá mẹ́ta pàtàkì tí iṣẹ́ ìwàásù wa pín sí, ó dájú pé èyí á ràn wá lọ́wọ́ láti máa kópa tó jọjú nínú iṣẹ́ ìwàásù. Ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò (1) ohun tó ń mú ká wàásù, tàbí ìdí tá a fi ń wàásù; (2) ohun tá à ń wàásù rẹ̀; àti (3) ọ̀nà tá a gbà ń wàásù. Bó bá jẹ́ pé èrò tó tọ̀nà la ní tá a fi ń wàásù, tá à ń jẹ́ kí ìwàásù wa ṣe kedere, tá a sì ń wàásù lọ́nà tó múná dóko, á ṣeé ṣe fún wa láti fún onírúurú èèyàn láǹfààní láti gbọ́ ìròyìn tó dára jù lọ lóde òní, ìyẹn ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. a

Ìdí Tá A Fi Ń Kópa Nínú Iṣẹ́ Ìwàásù Ìhìn Rere

5. (a) Kí ni olórí ohun tó ń mú ká kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù? (b) Kí nìdí tá a fi lè sọ pé bá a ṣe ń ṣègbọràn sí àṣẹ tí Bíbélì pa pé ká máa wàásù ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run?

5 Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ lórí apá àkọ́kọ́, ìyẹn ìdí tá a fi ń wàásù. Kí nìdí tá a fi ń wàásù ìhìn rere? Ohun kan náà tó mú kí Jésù wàásù ló ń mú káwa náà ṣe bẹ́ẹ̀. Jésù sọ pé: “Mo nífẹ̀ẹ́ Baba.” (Jòhánù 14:31; Sáàmù 40:8) Ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run ni olórí ohun tó ń mú ká lọ wàásù. (Mátíù 22:37, 38) Bíbélì jẹ́ ká mọ bí ìfẹ́ fún Ọlọ́run ṣe kan iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa, nítorí ó sọ pé: “Èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.” (1 Jòhánù 5:3; Jòhánù 14:21) Ǹjẹ́ àṣẹ tó sọ pé kéèyàn ‘lọ kó sì máa sọ àwọn ènìyàn di ọmọ ẹ̀yìn’ wà lára àwọn àṣẹ Ọlọ́run? (Mátíù 28:19) Bẹ́ẹ̀ ni, ó wà lára rẹ̀. Òótọ́ ni pé Jésù ló sọ ọ̀rọ̀ yẹn, àmọ́ àtọ̀dọ̀ Jèhófà ni ọ̀rọ̀ náà ti wá ní ti gidi. Lọ́nà wo? Jésù sọ pé: “Èmi kò ṣe nǹkan kan ní àdáṣe ti ara mi; ṣùgbọ́n gan-an gẹ́gẹ́ bí Baba ti kọ́ mi ni mo ń sọ nǹkan wọ̀nyí.” (Jòhánù 8:28; Mátíù 17:5) Nítorí náà, bí a bá ń pa àṣẹ Bíbélì tó sọ pé ká máa wàásù mọ́, ńṣe là ń tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí Jèhófà mọ pé a nífẹ̀ẹ́ òun.

6. Àwọn ọ̀nà wo ni ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run gbà ń mú ká wàásù?

6 Láfikún sí i, ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà ló ń mú ká wàásù nítorí pé a fẹ́ já irọ́ tí Sátánì ń pa mọ́ Ọlọ́run. (2 Kọ́ríńtì 4:4) Sátánì sọ pé Ọlọ́run ò lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ alákòóso. (Jẹ́nẹ́sísì 3:1-5) Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fẹ́ já irọ́ Sátánì, a sì fẹ́ sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́ níwájú gbogbo ènìyàn. (Aísáyà 43:10-12) Ìyẹn nìkan kọ́ o, a tún ń kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà nítorí pé a ti mọ àwọn ànímọ́ Jèhófà àtàwọn ọ̀nà rẹ̀. A mọ̀ pé a sún mọ́ ọn pẹ́kípẹ́kí, ó sì ń wù wá láti sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run wa fáwọn èèyàn. Ká sòótọ́, oore Jèhófà àtàwọn ọ̀nà òdodo rẹ̀ ń fún wa láyọ̀ gan-an débi pé a ò lè ṣe ká má sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà. (Sáàmù 145:7-12) Inú wa ń dùn gan-an láti máa yìn ín àti láti máa sọ̀rọ̀ nípa “ìtayọlọ́lá” rẹ̀ fún gbogbo ẹni tó bá fẹ́ gbọ́.—1 Pétérù 2:9; Aísáyà 43:21.

7. Yàtọ̀ sí ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run, kí ni ìdí pàtàkì mìíràn tá a fi ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù náà?

7 Àmọ́ o, ìdí pàtàkì mìíràn wà tó fi yẹ ká máa bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa lọ láìdáwọ́dúró. Ìdí náà ni pé tọkàntọkàn la fi fẹ́ mú ìtura bá àwọn tí ìròyìn burúkú tó pàpọ̀jù yìí ń bà lọ́kàn jẹ́ àtàwọn tó ń jìyà nítorí ìdí kan tàbí òmíràn. Bá a ṣe ń ṣiṣẹ́ yìí, Jésù là ń sapá láti fara wé. Bí àpẹẹrẹ, ẹ jẹ́ ká wo ohun tó wà nínú ìwé Máàkù orí kẹfà.

8. Kí ni àkọsílẹ̀ inú Máàkù orí kẹfà jẹ́ ká mọ̀ nípa bí ọ̀rọ̀ àwọn èèyàn ṣe rí lára Jésù?

8 Nígbà táwọn àpọ́sítélì Jésù padà dé láti ibì kan tí wọ́n ti lọ ṣiṣẹ́ ìwàásù, wọ́n ròyìn gbogbo ohun tí wọ́n ṣe àti ohun tí wọ́n fi kọ́ àwọn èèyàn níbẹ̀ fún Jésù. Jésù kíyè sí i pé ó ti rẹ àwọn àpọ́sítélì náà, ó wá sọ fún wọn pé kí wọ́n tẹ̀ lé òun láti lọ “sinmi díẹ̀.” Nítorí náà, wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi láti lọ sí ibì kan tó pa rọ́rọ́. Ṣùgbọ́n bí Jésù àtàwọn àpọ́sítélì ṣe ń kúrò níbẹ̀ làwọn èèyàn ti bẹ̀rẹ̀ sí sáré lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ etíkun náà, kò sì pẹ́ tí wọ́n fi bá wọn. Kí ni Jésù wá ṣe? Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Ó rí ogunlọ́gọ̀ ńlá, ṣùgbọ́n àánú wọ́n ṣe é, nítorí wọ́n dà bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn ní ohun púpọ̀.” (Máàkù 6:31-34) Àánú ni kò jẹ́ kí Jésù dáwọ́ wíwàásù ìhìn rere fún àwọn èèyàn dúró bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti rẹ̀ ẹ́. Dájúdájú, tọkàntọkàn ni Jésù fi fẹ̀mí ìyọ́nú hàn sí wọn.

9. Ẹ̀kọ́ wo ni àkọsílẹ̀ inú Máàkù orí kẹfà kọ́ wa nípa ohun tó ń mú ká wàásù?

9 Ẹ̀kọ́ wo ni àkọsílẹ̀ yìí kọ́ wa? Ojúṣe àwa Kristẹni ni pé ká máa wàásù ìhìn rere, ká sì máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn. A mọ̀ pé iṣẹ́ wa ni láti polongo ìhìn rere fún àwọn èèyàn, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ni pé kí “a gba gbogbo onírúurú ènìyàn là.” (1 Tímótì 2:4) Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe pé iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa jẹ́ àìgbọdọ̀máṣe nìkan la ṣe ń ṣe é, a tún ń ṣe é nítorí pé àánú àwọn èèyàn ń ṣe wá. Bá a bá ń fẹ̀mí ìyọ́nú hàn sáwọn èèyàn látọkànwá bíi ti Jésù, ọkàn wa yóò sún wa láti sa gbogbo ipá wa láti máa wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn láìdáwọ́dúró. (Mátíù 22:39) Bó bá jẹ́ ohun tó tọ́ bẹ́ẹ̀ ló ń sún wa ṣiṣẹ́ ìwàásù, a óò máa wàásù ìhìn rere náà láìdábọ̀.

Ìhìn Rere Ìjọba Ọlọ́run Là Ń Kéde

10, 11. (a) Báwo ni Aísáyà ṣe ṣàpèjúwe ìhìn rere tá à ń kéde? (b) Báwo ni Jésù ṣe mú ìhìn rere ohun tí ó dára jù wá, báwo sì làwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóde òní ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù?

10 Apá kejì nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ńkọ́, ìyẹn ohun tí à ń wàásù rẹ̀? Kí lohun tá à ń wàásù rẹ̀? Wòlíì Aísáyà ṣàpèjúwe ìhìn rere tí à ń wàásù lọ́nà tó wúni lórí, ó ní: “Ẹsẹ̀ ẹni tí ń mú ìhìn rere wá mà dára rèǹtè-rente lórí àwọn òkè ńlá o, ẹni tí ń kéde àlàáfíà fáyé gbọ́, ẹni tí ń mú ìhìn rere ohun tí ó dára jù wá, ẹni tí ń kéde ìgbàlà fáyé gbọ́, ẹni tí ń sọ fún Síónì pé: ‘Ọlọ́run rẹ ti di ọba!’”—Aísáyà 52:7.

11 Gbólóhùn tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ni “Ọlọ́run rẹ ti di ọba,” ó sì ń tọ́ka sí ìhìn tá a gbọ́dọ̀ polongo, ìyẹn ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. (Máàkù 13:10) Bákan náà, kíyè sí i pé ẹsẹ Bíbélì yìí jẹ́ ká mọ̀ pé ohun tó dáa ni ìhìn rere tá à ń kéde dá lé lórí. Aísáyà lo àwọn ọ̀rọ̀ bí “ìgbàlà,” “ìhìn rere,” “àlàáfíà,” àti “ohun tí ó dára jù.” Ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni, ìyẹn ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn ìgbà ayé Aísáyà, Jésù Kristi mú àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣẹ lọ́nà tó hàn gbangba nítorí ó fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀ nínú fífi ìtara kéde ohun tó dára jù, ìyẹn Ìjọba Ọlọ́run tí ń bọ̀. (Lúùkù 4:43) Lóde òní, pàápàá látọdún 1919, làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù nípa fífi ìtara polongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tí a ti gbé kalẹ̀ àtàwọn ìbùkún tó máa mú wá fáwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè.

12. Ipa wo ni ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ń ní lórí àwọn tó bá tẹ́wọ́ gbà á?

12 Ipa wo ni ìròyìn Ìjọba Ọlọ́run ń ní lórí àwọn tó bá tẹ́wọ́ gbà á? Ìhìn rere yìí ń mú káwọn èèyàn ní ìrètí, ó sì ń tù wọ́n nínú lóde òní, bó ṣe rí nígbà ayé Jésù. (Róòmù 12:12; 15:4) Ó ń mú káwọn tó jẹ́ ọlọ́kàn tútù máa retí ohun rere torí pé ó ń jẹ́ kí wọ́n lóye ìdí tí ìròyìn burúkú fi pọ̀ rẹpẹtẹ, ó sì ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ọ̀la ṣì ń bọ̀ wá dára. (Mátíù 6:9, 10; 2 Pétérù 3:13) Ìrètí tí ìlérí yìí máa ń fún àwọn olùbẹ̀rù Ọlọ́run ń mú kí ọkàn wọn balẹ̀ gan-an. Onísáàmù sọ pé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ “kì yóò fòyà ìhìn búburú pàápàá.”—Sáàmù 112:1, 7.

Ìhìn Rere Tí Yóò “Di Ọgbẹ́ Àwọn Oníròbìnújẹ́-Ọkàn”

13. Báwo ni wòlíì Aísáyà ṣe ṣàpèjúwe ìbùkún táwọn tó tẹ́wọ́ gba ìhìn rere náà máa kọ́kọ́ rí gbà?

13 Láfikún sí i, àwọn tó bá gba ìhìn rere yìí tún ń rí ìtùnú àti ìbùkún ojú ẹsẹ̀ gbà. Lọ́nà wo? Wòlíì Aísáyà mẹ́nu ba díẹ̀ lára àwọn ìbùkún téèyàn ń rí gbà nígbà tó sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé: “Ẹ̀mí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ń bẹ lára mi, nítorí ìdí náà pé Jèhófà ti fòróró yàn mí láti sọ ìhìn rere fún àwọn ọlọ́kàn tútù. Ó ti rán mi láti di ọgbẹ́ àwọn oníròbìnújẹ́-ọkàn, láti pòkìkí ìdásílẹ̀ lómìnira fún àwọn tí a mú ní òǹdè àti ìlajúsílẹ̀ rekete àní fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n; láti pòkìkí ọdún ìtẹ́wọ́gbà níhà ọ̀dọ̀ Jèhófà àti ọjọ́ ẹ̀san níhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wa; láti tu gbogbo àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú.”—Aísáyà 61:1, 2; Lúùkù 4:16-21.

14. (a) Kí ni gbólóhùn náà, “di ọgbẹ́ àwọn oníròbìnújẹ́-ọkàn” fi hàn pé ìhìn Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe? (b) Báwo la ṣe ń fi hàn pé ọ̀ràn àwọn oníròbìnújẹ́-ọkàn ká wa lára bó ṣe ká Jèhófà lára?

14 Gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ti sọ, Jésù yóò “di ọgbẹ́ àwọn oníròbìnújẹ́-ọkàn” nípa wíwàásù ìhìn rere fún wọn. Ẹ ò rí i pé àpèjúwe tó wọni lọ́kàn gan-an ni Aísáyà lò yìí! Ìwé atúmọ̀ èdè kan tó ń ṣàlàyé ọ̀rọ̀ Bíbélì sọ pé ọ̀rọ̀ Hébérù tá a tú sí “di” níhìn-ín ni wọ́n “sábà máa ń lò tí wọ́n bá ń sọ̀rọ̀ nípa fífi báńdéèjì ‘di’ nǹkan, nípa báyìí wọ́n ń lò ó fún ṣíṣètọ́jú àti wíwo ọgbẹ́ ẹni tó fara pa sàn.” Nọ́ọ̀sì kan lè fi báńdéèjì tàbí ohun mìíràn tí wọ́n fi ń di ọgbẹ́ wé ibi tó ń dun aláìsàn kan kí ọgbẹ́ náà lè san. Lọ́nà kan náà, nígbà tá a bá ń wàásù ìhìn Ìjọba Ọlọ́run, àwa oníwàásù tí ọ̀ràn àwọn èèyàn ń jẹ lọ́kàn máa ń fún àwọn èèyàn lókun, ìyẹn àwọn tó tẹ́tí sílẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé tí wọ́n níṣòro kan tàbí òmíràn. Bí a sì ṣe ń fún àwọn tó ní ìṣòro lókun yìí, à ń fi hàn pé ọ̀ràn àwọn èèyàn ká wa lára bó ṣe ká Jèhófà lára. (Ìsíkíẹ́lì 34:15, 16) Onísáàmù náà sọ nípa Ọlọ́run pé: “Ó ń mú àwọn oníròbìnújẹ́-ọkàn lára dá, ó sì ń di àwọn ojú ibi tí ń ro wọ́n.”—Sáàmù 147:3.

Bí Ìhìn Rere Ìjọba Náà Ṣe Ń Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́

15, 16. Àwọn àpẹẹrẹ ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn wo ló fi hàn pé ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run máa ń fún àwọn tó níṣòro lókun?

15 Onírúurú àpẹẹrẹ ohun tó ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn jẹ́ ká mọ bí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ṣe ń fún àwọn tó ní ìròbìnújẹ́-ọkàn lókun. Gbé ọ̀ràn ìyá àgbàlagbà kan tí ayé ti sú pátápátá yẹ̀ wò. Oreanna lorúkọ ìyá yìí, ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀-èdè tó wà ní Gúúsù Amẹ́ríkà ló sì ń gbé. Obìnrin kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí wá sọ́dọ̀ Oreanna, ó sì máa ń ka Bíbélì àti Iwe Itan Bibeli Mi sí i létí. b Lákọ̀ọ́kọ́, orí ibùsùn ni obìnrin tí ìbànújẹ́ ti dorí rẹ̀ kodò yìí ti máa ń gbọ́ ohun tí wọ́n ń kà sí i létí, á di ojú rẹ̀, á wá máa mí kanlẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àmọ́ nígbà tó yá, ó bẹ̀rẹ̀ sí sapá láti dìde jókòó sórí ibùsùn rẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń ka ìwé náà. Nígbà tó ṣe díẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn, ó bẹ̀rẹ̀ sí jókòó sórí àga kan tó wà ní pálọ̀, á sì máa retí ẹni tó ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tó yá, obìnrin yìí bẹ̀rẹ̀ sí wá sípàdé àwa Kristẹni ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Nítorí pé ohun tó ń gbọ́ láwọn ìpàdé yẹn wú u lórí gan-an, ó bẹ̀rẹ̀ sí fi àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ ẹnikẹ́ni tó bá kọjá níwájú ilé rẹ̀. Níkẹyìn, Oreanna ṣèrìbọmi gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ẹni ọdún mẹ́tàléláàádọ́rùn-ún [93]. Ìhìn rere Ìjọba náà ti jẹ́ kó tún wù ú láti wà láàyè.—Òwe 15:30; 16:24.

16 Kódà ìhìn rere Ìjọba náà tún máa ń fi okun fún àwọn tó mọ̀ pé àìsàn tó ń ṣe àwọn ò ní pẹ́ gbẹ̀mí àwọn. Gbé àpẹẹrẹ Maria yẹ̀ wò láti Ìwọ̀ Oòrùn ilẹ̀ Yúróòpù. Àìsàn tó lè pa èèyàn ló ń bá a fínra, ó sì ti sọ̀rètí nù pátápátá. Àsìkò tí ọkàn rẹ̀ gbọgbẹ́ gan-an làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Àmọ́, nígbà tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fún ìran èèyàn, ìgbésí ayé rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí lójú. Ó ṣèrìbọmi, ó sì ń fi ìtara ṣiṣẹ́ ìwàásù. Ní ọdún méjì tó lò kẹ́yìn ìgbésí ayé rẹ̀, ńṣe ni ìrètí àti ayọ̀ tó ní máa ń hàn ṣáá lójú rẹ̀. Nígbà tí Maria fi máa kú, ìrètí pé òun á ní àjíǹde dá a lójú hán-únhán-ún.—Róòmù 8:38, 39.

17. (a) Báwo ni ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ṣe ń ran àwọn tó tẹ́wọ́ gbà á lọ́wọ́? (b) Àwọn ọ̀nà wo ni ìwọ alára ti gbà rí i pé Jèhófà “ń gbé gbogbo àwọn tí a tẹ̀ lórí ba dìde”?

17 Àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ wọ̀nyí jẹ́ ká mọ ìrànlọ́wọ́ tí ìhìn rere Ìjọba náà lè ṣe fún àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ inú Bíbélì. Àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nítorí pé èèyàn wọn kú náà ń rí okun gbà nígbà tí wọ́n bá kẹ́kọ̀ọ́ pé àwọn òkú yóò jíǹde. (1 Tẹsalóníkà 4:13) Àwọn tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ tí wọ́n sì ń forí ṣe fọrùn ṣe nítorí àtipèsè fún ìdílé wọn ti wá dẹni iyì, wọ́n sì ti dẹni tọ́kàn rẹ̀ balẹ̀ nígbà tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà ò ní fàwọn sílẹ̀ láé bí àwọn bá jẹ́ adúróṣinṣin. (Sáàmù 37:28) Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, àwọn tí wọ́n ní ìdààmú ọkàn púpọ̀ ti wá dẹni tó ń lókun nínú, wọ́n tiẹ̀ máa ń bọ́ lọ́wọ́ àìsàn tó ń ṣe wọ́n nígbà mìíràn. (Sáàmù 40:1, 2) Dájúdájú, ní báyìí, Jèhófà “ń gbé gbogbo àwọn tí a tẹ̀ lórí ba dìde” nípasẹ̀ agbára tí Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ń fúnni. (Sáàmù 145:14) Bẹ́ẹ̀ ni o, bá a ṣe ń rí i tí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run ń tu àwọn oníròbìnújẹ́-ọkàn tó wà ní ìpínlẹ̀ wa àtàwọn tó wà nínú ìjọ wa nínú máa ń jẹ́ ká rántí ní gbogbo ìgbà pé àwa la ní ìròyìn tó dára jù lọ lónìí!—Sáàmù 51:17.

“Ìrawọ́ Ẹ̀bẹ̀ Mi sí Ọlọ́run fún Wọn”

18. Báwo ni kíkọ̀ táwọn Júù kọ ìhìn rere náà ṣe rí lára Pọ́ọ̀lù, kí sì nìdí?

18 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìhìn tá à ń wàásù rẹ̀ ni ìhìn tó dára jù lọ, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ èèyàn ni kì í tẹ́wọ́ gbà á. Báwo lèyí ṣe máa ń rí lára wa? Bó ṣe rí lára àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà ni. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló wàásù fáwọn Júù, àmọ́ èyí tó pọ̀ jù lọ lára wọn ni kò fetí sí ìhìn rere ìgbàlà tó ń sọ fún wọn. Kíkọ̀ tí wọ́n kọ̀ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù yìí bà á nínú jẹ́ gan-an. Ó sọ pé: “Mo ní ẹ̀dùn-ọkàn ńláǹlà àti ìrora tí kò dẹ́kun nínú ọkàn-àyà mi.” (Róòmù 9:2) Àánú àwọn Júù tí Pọ́ọ̀lù wàásù fún yẹn ṣe é gan-an. Ó bà á nínú jẹ́ pé wọ́n kọ̀ láti tẹ́wọ́ gba ìhìn rere náà.

19. (a) Kí nìdí tí kì í ṣe ohun ìyàlẹ́nu pé a lè ní ìrẹ̀wẹ̀sì nígbà mìíràn? (b) Kí ló ran Pọ́ọ̀lù lọ́wọ́ tó fi lè máa bá iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀ lọ?

19 Àánú àwọn èèyàn ló ń mú káwa náà máa wàásù ìhìn rere. Nítorí náà, kì í ṣe ohun àjèjì pé àwa náà lè rẹ̀wẹ̀sì nígbà tí ọ̀pọ̀ èèyàn bá kọ̀ láti gbọ́ ìhìn Ìjọba Ọlọ́run. Irú ìrẹ̀wẹ̀sì bẹ́ẹ̀ sì fi hàn pé ire tẹ̀mí àwọn tá à ń wàásù fún jẹ wá lógún gan-an. Àmọ́ ṣá o, ó yẹ ká máa rántí àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Kí ló ràn án lọ́wọ́ láti máa bá iṣẹ́ ìwàásù rẹ̀ lọ? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kíkọ̀ táwọn Júù kọ̀ láti fetí sí ìhìn rere kó ìbànújẹ́ bá a, ó sì ń dùn ún, síbẹ̀ Pọ́ọ̀lù ò tìtorí bẹ́ẹ̀ pa gbogbo àwọn Júù tì, kó sọ pé wọn ò lè gbọ́ mọ́. Ó mọ̀ pé bópẹ́ bóyá, àwọn kan ṣì wà tó máa di ọmọ ẹ̀yìn Kristi lára àwọn èèyàn náà. Ìdí nìyẹn tó fi sọ bí ọ̀rọ̀ àwọn Júù kan ṣe rí lára rẹ̀ nígbà tó kọ̀wé pé: “Ìfẹ́ rere ọkàn-àyà mi àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ mi sí Ọlọ́run fún wọn, ní tòótọ́, jẹ́ fún ìgbàlà wọn.”—Róòmù 10:1.

20, 21. (a) Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa? (b) Apá wo nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa la óò gbé yẹ̀ wò nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí?

20 Kíyè sí ohun méjì tí Pọ́ọ̀lù tẹnu mọ́. Ó wù ú pé káwọn kan rí ìgbàlà, ó sì bẹ Ọlọ́run pé kó jẹ́ kí èyí ṣeé ṣe. Àwa náà ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù lónìí. Ìfẹ́ ọkàn wa ni pé ká dé ọ̀dọ̀ ẹnikẹ́ni tó bá ní inú dídùn sí ìhìn rere. Gbogbo ìgbà la máa ń gbàdúrà sí Jèhófà pé kó jẹ́ ká lè rí irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ bá pàdé ká lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa rin ọ̀nà tí wọ́n á fi rí ìgbàlà.—Òwe 11:30; Ìsíkíẹ́lì 33:11; Jòhánù 6:44.

21 Àmọ́ ṣá o, ká tó lè sọ ìhìn Ìjọba náà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn, kì í ṣe ìdí tá a fi ń wàásù àti ohun tá à ń wàásù rẹ̀ nìkan la máa fiyè sí, a tún gbọ́dọ̀ fiyè sí ọ̀nà tá a gbà ń wàásù. Kókó yìí la óò jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àpilẹ̀kọ yìí yóò jíròrò apá méjì àkọ́kọ́. Àpilẹ̀kọ kejì yóò sì jíròrò apá kẹta.

b Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.

Ẹ̀kọ́ Wo Lo Rí Kọ́?

• Kí nìdí tá a fi ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù?

• Kí ni olórí ohun tá à ń wàásù rẹ̀?

• Ìbùkún wo làwọn tó tẹ́wọ́ gba ìhìn Ìjọba náà máa ń rí gbà?

• Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti máa bá iṣẹ́ ìwàásù wa lọ?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Ìhìn rere Ìjọba náà ń fún àwọn oníròbìnújẹ́-ọkàn lókun

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

Àdúrà ń ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìforítì nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa