Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìhìn Rere Fún Àwọn Èèyàn Gbogbo Orílẹ̀-èdè

Ìhìn Rere Fún Àwọn Èèyàn Gbogbo Orílẹ̀-èdè

Ìhìn Rere Fún Àwọn Èèyàn Gbogbo Orílẹ̀-èdè

“Ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi . . . títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.”—ÌṢE 1:8.

1. Bá a ṣe ń fi Bíbélì kọ́ni, kí ló yẹ ká máa kíyè sí, kí sì nìdí?

 OHUN táwọn olùkọ́ tó dáńgájíá máa sọ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ nìkan kọ́ ni wọ́n máa ń rò, wọ́n tún máa ń ronú nípa ọ̀nà tí wọ́n á gbà sọ ọ́. Ohun tí àwa tá à ń fi òtítọ́ Bíbélì kọ́ni máa ń ṣe náà nìyẹn. Bá a ṣe ń ronú nípa ohun tá à ń wàásù rẹ̀ náà là ń ronú nípa àwọn ọ̀nà tá a máa gbà sọ ọ́. Ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tá à ń polongo kò yí padà, àmọ́ a máa ń yí ọ̀nà tá a gbà ń sọ ọ́ padà. Kí nìdí tá a fi ń ṣe bẹ́ẹ̀? Nítorí ká lè bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn sọ̀rọ̀ ni.

2. Tá a bá ń jẹ́ kí ọ̀nà tá a gbà ń wàásù bá ipò àwọn èèyàn mu, ta là ń fara wé?

2 Tá a bá ń yíwọ́ padà nínú ọ̀nà tá a gbà ń wàásù, a jẹ́ pé à ń fara wé àwọn tó jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run láyé ọjọ́hun nìyẹn. Gbé àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù yẹ̀ wò. Ó sọ pé: “Fún àwọn Júù mo dà bí Júù . . . Fún àwọn tí wọ́n wà láìní òfin mo dà bí aláìní òfin . . . Fún àwọn aláìlera mo di aláìlera, kí n lè jèrè àwọn aláìlera. Mo ti di ohun gbogbo fún ènìyàn gbogbo, kí n lè rí i dájú pé mo gba àwọn kan là.” (1 Kọ́ríńtì 9:19-23) Pọ́ọ̀lù ṣàṣeyọrí tó pọ̀ nígbà tó mú ẹ̀kọ́ tó ń kọ́ àwọn èèyàn bá ipò wọn mu. Àwa náà yóò ṣàṣeyọrí bíi tirẹ̀ tá a bá ń fi sùúrù mú kí ọ̀nà tá a gbà ń bá ẹnì kọ̀ọ̀kan sọ̀rọ̀ bá ipò onítọ̀hún mu.

Dé “Òpin Ilẹ̀ Ayé”

3. (a) Iṣẹ́ bàǹtàbanta wo ló já lé wa léjìká nínu iṣẹ́ ìwàásù wa? (b) Báwo ni ọ̀rọ̀ inú Aísáyà 45:22 ṣe ń nímùúṣẹ lóde òní?

3 Iṣẹ́ bàǹtàbanta tó já lé àwọn tó ń wàásù ìhìn rere náà léjìká ni pé wọ́n ní láti wàásù ní ilẹ̀ tó gbòòrò, ìyẹn “gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.” (Mátíù 24:14) Ní ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ti ṣiṣẹ́ kára láti polongo ìhìn rere yìí ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ láfikún sí àwọn ilẹ̀ tá a ti mú ìhìn rere náà dé tẹ́lẹ̀. Kí ni àbájáde rẹ̀? Àwọn ibi tá a ti ń wàásù ti gbòòrò gan-an kárí ayé lọ́nà tó kàmà mà. Níbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún, ilẹ̀ díẹ̀ làwọn Ẹlẹ́rìí ti ń wàásù, àmọ́ lóde òní, ilẹ̀ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń fi ìtara wàásù ti di igba ó lé márùndínlógójì [235]! Dájúdájú, a ti polongo ìhìn rere Ìjọba náà títí dé “òpin ilẹ̀ ayé.”—Aísáyà 45:22.

4, 5. (a) Àwọn wo ló ti kópa tó pọ̀ gan-an nínú pípolongo ìhìn rere náà? (b) Kí làwọn ẹ̀ka iléeṣẹ́ kan sọ nípa àwọn tó ti ilẹ̀ òkèèrè wá sìn ní ìpínlẹ̀ táwọn ẹ̀ka náà ń bójú tó?

4 Kí ló mú káwọn ilẹ̀ tá a ti ń wàásù náà pọ̀ tó bẹ́ẹ̀? Ọ̀pọ̀ nǹkan ló jẹ́ kó rí bẹ́ẹ̀. Àwọn míṣọ́nnárì tó gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ ní ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead àtàwọn bí ọ̀kẹ́ kan [20,000] arákùnrin tó kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ lẹ́nu àìpẹ́ yìí ti ṣe bẹbẹ. Ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí tí wọ́n ti fi owó ara wọn rìnrìn àjò lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù Ìjọba náà gan-an ti ṣe bẹbẹ pẹ̀lú. Àwọn Kristẹni tí wọ́n ní irú ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ bẹ́ẹ̀ ti kópa tó pọ̀ gan-an nínú iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba náà jákèjádò ayé. Ọkùnrin wà lára wọn, obìnrin náà wà níbẹ̀, lọ́mọdé lágbà, títí kan àwọn tí kò gbéyàwó àtàwọn tó gbéyàwó pàápàá. (Sáàmù 110:3; Róòmù 10:18) A mọrírì ohun tí wọ́n ṣe yìí gan-an ni. Gbọ́ ohun táwọn ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa bíi mélòó kan kọ nípa àwọn tó ń ti ilẹ̀ òkèèrè wá sìn láwọn ibi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù gan-an ní ìpínlẹ̀ táwọn ẹ̀ka náà ń bójú tó.

5 “Àwọn Ẹlẹ́rìí tó jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n yìí ló ń mú ipò iwájú nínú wíwàásù láwọn àgbègbè tó jẹ́ àdádó, àwọn ló ń ṣèrànwọ́ láti dá àwọn ìjọ tuntun sílẹ̀, tí wọ́n sì ń jẹ́ káwọn arákùnrin àti arábìnrin tó wà níbẹ̀ dàgbà nípa tẹ̀mí.” (Orílẹ̀-èdè Ecuador) “Bí ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tó ń sìn níhìn-ín bá lọ, ipò tẹ̀mí àwọn ìjọ tó wà níbi kò ní lágbára mọ́. Ìbùkún ńlá ni wíwà tí wọ́n wà pẹ̀lú wa jẹ́.” (Orílẹ̀-èdè Dominican Republic) “Àwọn arábìnrin ló pọ̀ jù nínú ọ̀pọ̀ àwọn ìjọ wa, wọ́n tiẹ̀ máa ń tó ìpín méje nínú mẹ́wàá àwọn ará nígbà míì. (Sáàmù 68:11) Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn arábìnrin wọ̀nyí ló jẹ́ ẹni tuntun nínú òtítọ́, àmọ́ àwọn arábìnrin tí ò lọ́kọ tí wọ́n jẹ́ aṣáájú ọ̀nà tó wá láti àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ti ṣèrànwọ́ gan-an nípa kíkọ́ àwọn ẹni tuntun wọ̀nyẹn bá a ṣe ń wàásù. Ẹ̀bùn gidi làwọn arábìnrin tó wá láti ilẹ̀ òkèèrè yìí jẹ́ fún wa!” (Orílẹ̀-èdè kan ní Ìlà Oòrùn ilẹ̀ Yúróòpù) Ǹjẹ́ ìwọ náà tiẹ̀ ti ronú nípa sísìn ní orílẹ̀-èdè mìíràn? aÌṣe 16:9, 10.

“Ọkùnrin Mẹ́wàá Láti Inú Gbogbo Èdè”

6. Báwo ni Sekaráyà 8:23 ṣe tọ́ka sí ìṣòro wíwàásù fáwọn èèyàn tó ń sọ onírúurú èdè lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa?

6 Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èdè táwọn èèyàn ń sọ lórí ilẹ̀ ayé tún jẹ́ ìṣòro mìíràn táwọn oníwàásù ní láti kojú. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé: “Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ wọnnì pé ọkùnrin mẹ́wàá láti inú gbogbo èdè àwọn orílẹ̀-èdè yóò dì í mú, bẹ́ẹ̀ ni, ní ti tòótọ́, wọn yóò di ibi gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ ọkùnrin kan tí ó jẹ́ Júù mú, pé: ‘Àwa yóò bá yín lọ, nítorí a ti gbọ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín.’” (Sekaráyà 8:23) Nínú ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ yìí lóde òní, ogunlọ́gọ̀ ńlá tí àsọtẹ́lẹ̀ nípa wọn wà nínú Ìṣípayá 7:9 làwọn ọkùnrin mẹ́wàá náà dúró fún. Àmọ́, ẹ kíyè sí i pé gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ Sekaráyà yìí ti fi hàn, kì í ṣe pé “ọkùnrin mẹ́wàá” yẹn yóò jáde wá látinú gbogbo orílẹ̀-èdè nìkan ni, wọ́n á tún wá “láti inú gbogbo èdè àwọn orílẹ̀-èdè.” Ǹjẹ́ a ti rí ìmúṣẹ kókó pàtàkì yìí nínú àsọtẹ́lẹ̀ náà? Dájúdájú, bẹ́ẹ̀ ni.

7. Àwọn ìsọfúnni wo ló fi hàn pé a ti ń wàásù ìhìn rere náà fáwọn èèyàn tó wá “láti inú gbogbo èdè”?

7 Ẹ jẹ́ ká ṣe àwọn àyẹ̀wò díẹ̀ ná. Ní àádọ́ta ọdún sẹ́yìn, àádọ́rùn-ún [90] èdè la fi ń tẹ àwọn ìwé wa. Lónìí, iye yẹn ti lé ní irínwó èdè. “Ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ti ṣe gbogbo ohun tó yẹ ní ṣíṣe láti pèsè àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ láwọn èdè kan táwọn tó ń sọ wọ́n ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀. (Mátíù 24:45) Bí àpẹẹrẹ, àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti wà báyìí lédè Greenlandic (tí ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínláàádọ́ta [47,000] èèyàn péré ń sọ), ó tún wà lédè Palauan (tí ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún èèyàn péré ń sọ), àti èdè Yapese (táwọn èèyàn tó ń sọ̀ ọ́ kò tó ẹgbẹ̀rún méje).

“Ilẹ̀kùn Ńlá” Tí Ń Ṣamọ̀nà sí Àwọn Àǹfààní Tuntun

8, 9. Àwọn nǹkan wo ló ń ṣẹlẹ̀ tó mú kí “ilẹ̀kùn ńlá” ṣí sílẹ̀ fún wa, kí sì ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí ti ṣe nípa rẹ̀?

8 Àmọ́ lóde òní, ó lè má pọn dandan pé ká lọ sílẹ̀ òkèèrè ká tó lè wàásù ìhìn rere náà fáwọn èèyàn tó wá látinú gbogbo èdè. Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn tó ń ṣí wọnú àwọn orílẹ̀-èdè tí nǹkan ti rọ̀ ṣọ̀mù àtàwọn tó ń sá lọ síbẹ̀ nítorí ogun tàbí àwọn ìṣòro mìíràn ti mú káwọn àgbègbè táwọn èèyàn ti ń sọ onírúurú èdè pọ̀ láwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyẹn. Bí àpẹẹrẹ, nílùú Paris, nílẹ̀ Faransé, nǹkan bí ọgọ́rùn-ún èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ń sọ níbẹ̀. Nílùú Toronto, lórílẹ̀-èdè Kánádà, iye èdè tí wọ́n ń sọ níbẹ̀ jẹ́ márùnlélọ́gọ́fà [125]; nílùú London sì rèé, nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ohun tó lé ní ọ̀ọ́dúnrún [300] èdè ilẹ̀ òkèèrè ni wọ́n ń sọ! Báwọn èèyàn tó wá láti àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn ṣe wà ní ìpínlẹ̀ tí ọ̀pọ̀ ìjọ ti ń wàásù báyìí ti mú kí “ilẹ̀kùn ńlá” ṣí sílẹ̀, èyí tó máa jẹ́ kí ọ̀pọ̀ àǹfààní wà láti wàásù ìhìn rere fún àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè.—1 Kọ́ríńtì 16:9.

9 Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí ló ń kọ́ èdè mìíràn kí wọ́n lè sọ ìhìn rere náà fún àwọn èèyàn tó wá látinú gbogbo orílẹ̀-èdè. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn rárá fún ọ̀pọ̀ jù lọ wọn; síbẹ̀ wàhálà wọn ò já sásán nítorí ayọ̀ tí wọ́n ń rí nínú ẹ̀kọ́ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí wọ́n ń kọ́ àwọn tó ṣí wá láti ilẹ̀ òkèèrè àtàwọn tí ogun tàbí àwọn ìṣòro mìíràn lé wá sí orílẹ̀-èdè wọn. Ní ọdún kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí, nǹkan bí ìdá ogójì nínú ìdá ọgọ́rùn-ún àwọn èèyàn tó ṣèrìbọmi láwọn àpéjọ àgbègbè tó wáyé ní Ìwọ Oòrùn ilẹ̀ Yúróòpù ló jẹ́ àwọn ará orílẹ̀-èdè mìíràn.

10. Àwọn ọ̀nà wo lo ti gbà lo ìwé kékeré náà, Good News for People of All Nations? (Wo àpótí “Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Kékeré Good News for People of All Nations,” ní ojú ìwé 26.)

10 Lóòótọ́, èyí tó pọ̀ jù lọ lára wa ni kò láǹfààní láti kọ́ èdè ilẹ̀ òkèèrè. Síbẹ̀ náà, a ṣì lè ran àwọn tó ń ṣí wá sí orílẹ̀-èdè wa lọ́wọ́ nípa lílo ìwé pẹlẹbẹ tuntun tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ mú jáde yẹn lọ́nà tó dára. Ìwé pẹlẹbẹ náà ni Good News for People of All Nations, b èyí tó ní àwọn ọ̀rọ̀ tó fani mọ́ra látinú Bíbélì nínú tí wọ́n kọ ní ọ̀pọ̀ èdè tó yàtọ̀ síra. (Jòhánù 4:37) Ǹjẹ́ o máa ń lo ìwé kékeré yìí nígbà tó o bá wà lóde ẹ̀rí?

Bí Àwọn Èèyàn Ò Bá Fẹ́ Gbọ́

11. Àwọn ìṣòro mìíràn wo la tún ń dojú kọ láwọn ìpínlẹ̀ kan?

11 Bí ipa tí Sátánì ń kó lórí ilẹ̀ ayé ṣe túbọ̀ ń pọ̀ sí i, ìṣòro mìíràn tún wà tá a máa ń bá pàdé látìgbàdégbà, ìṣòro náà ni pé àwọn èèyàn tí ò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ìhìn rere náà wà láwọn ìpínlẹ̀ kan. Ká sòótọ́, èyí ò yà wá lẹ́nu, níwọ̀n bí Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀ pé irú nǹkan bẹ́ẹ̀ yóò wáyé. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa àkókò tiwa yìí, ó ní: “Ìfẹ́ ọ̀pọ̀ jù lọ yóò di tútù.” (Mátíù 24:12) Láìsí àní-àní, ọ̀pọ̀ èèyàn ni ò fi bẹ́ẹ̀ nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run mọ́, wọn ò sì fi bẹ́ẹ̀ ka ọ̀rọ̀ inú Bíbélì sí mọ́. (2 Pétérù 3:3, 4) Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé àwọn tó ń di ọmọ ẹ̀yìn tuntun fún Kristi ò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ rárá láwọn apá ibì kan láyé. Àmọ́, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé akitiyan àwọn Kristẹni arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ọ̀wọ́n tí wọ́n ń fi ìṣòtítọ́ wàásù nírú àwọn ìpínlẹ̀ táwọn èèyàn ò ti fẹ́ gbọ́ bẹ́ẹ̀ já sásán o. (Hébérù 6:10) Kí nìdí? Gbé ohun tó tẹ̀ lé e yìí yẹ̀ wò.

12. Kí nídìí méjì tá a fi ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù wa?

12 Ìhìn Rere Mátíù tẹnu mọ́ ohun méjì pàtàkì tí iṣẹ́ ìwàásù wa dá lé lórí. Ọ̀kan ni pé ká “sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.” (Mátíù 28:19) Èkejì ni pé ìhìn rere Ìjọba náà jẹ́ “ẹ̀rí.” (Mátíù 24:14) Àwọn ohun méjèèjì yìí ṣe pàtàkì, àmọ́ èyí tó kẹ́yìn yẹn ló ṣe pàtàkì jù lọ. Kí nìdí?

13, 14. (a) Èwo ló jẹ́ apá pàtàkì tó ṣe jù lọ lára àwọn ohun tí Kristi sọ pé ó máa jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín òun? (b) Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn, àgàgà tá a bá ń wàásù láwọn ìpínlẹ̀ táwọn èèyàn ò ti fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ wa?

13 Mátíù tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó kọ Bíbélì sọ pé àwọn àpọ́sítélì bi Jésù pé: “Kí ni yóò sì jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín rẹ àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan?” (Mátíù 24:3) Jésù fèsì pé èyí tó jẹ́ apá tó ṣe pàtàkì jù lọ lára gbogbo ohun tó máa jẹ́ àmì náà ni iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé. Ṣé ọ̀rọ̀ nípa sísọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn ló ń sọ? Rárá o. Ó sọ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.” (Mátíù 24:14) Jésù tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà fúnra rẹ̀ jẹ́ apá pàtàkì lára àmì náà.

14 Nítorí náà, bá a ṣe ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, à ń rántí pé bá ò tiẹ̀ fi gbogbo ìgbà láǹfààní láti sọni di ọmọ ẹ̀yìn, síbẹ̀ a ń kẹ́sẹ járí nínú jíjẹ́ “ẹ̀rí.” Láìfi ojú táwọn èèyàn fi ń wo iṣẹ́ ìwàásù wa pè, wọ́n ṣáà mọ ohun tá à ń ṣe, a sì tipa bẹ́ẹ̀ ń kópa nínú mímú àsọtẹ́lẹ̀ Jésù ṣẹ. (Aísáyà 52:7; Ìṣípayá 14:6, 7) Jordy, ọmọ kékeré kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí ní Ìwọ̀ Oòrùn ilẹ̀ Yúróòpù sọ pé: “Mímọ̀ tí mo mọ̀ pé Jèhófà ń lò mí láti kópa nínú mímú àsọtẹ́lẹ̀ inú Mátíù 24:14 ṣẹ ń múnú mi dùn gan-an ni.” (2 Kọ́ríńtì 2:15-17) Ó dájú pé bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára ìwọ náà nìyẹn.

Táwọn Èèyàn Bá Ń Ṣàtakò sí Iṣẹ́ Ìwàásù Wa

15. (a) Kí ni Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀? (b) Kí ló ń ràn wá lọ́wọ́ láti wàásù láìfi àtakò pè?

15 Àtakò tún jẹ́ ìṣòro mìíràn tó dojú kọ iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba náà. Jésù ti sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ pé: “Ẹ ó sì jẹ́ ẹni ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ní tìtorí orúkọ mi.” (Mátíù 24:9) Bíi tàwọn Kristẹni ìjímìjí, àwọn èèyàn kórìíra àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ti òde òní náà, wọ́n ń ṣe àtakò sí wọn, wọ́n sì ń ṣe inúnibíni sí wọn pẹ̀lú. (Ìṣe 5:17, 18, 40; 2 Tímótì 3:12; Ìṣípayá 12:12, 17) Ìjọba tiẹ̀ fòfin dè wọ́n lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí láwọn orílẹ̀-èdè kan. Síbẹ̀, àwọn Kristẹni tó wà láwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyẹn ń bá iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba náà lọ nítorí pé wọ́n fẹ́ ṣègbọràn sí Ọlọ́run. (Ámósì 3:8; Ìṣe 5:29; 1 Pétérù 2:21) Kí ló ran àwọn Ẹlẹ́rìí wọ̀nyẹn àti gbogbo Ẹlẹ́rìí yòókù kárí ayé lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀? Jèhófà ló ń fún wọn lágbára nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀.—Sekaráyà 4:6; Éfésù 3:16; 2 Tímótì 4:17.

16. Báwo ni Jésù ṣe fi hàn pé iṣẹ́ ìwàásù àti ẹ̀mí Ọlọ́run wọnú ara wọn gan-an?

16 Jésù mẹ́nu kan ọ̀nà tí ẹ̀mí Ọlọ́run àti iṣẹ́ ìwàásù gbà wọnú ara wọn gan-an nígbà tó sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ ó gba agbára nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bá bà lé yín, ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi . . . títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.” (Ìṣe 1:8; Ìṣípayá 22:17) Bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ṣe sọ pé àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣe máa ṣẹlẹ̀ tẹ̀ léra gbàfiyèsí gan-an. Lákọ̀ọ́kọ́, àwọn ọmọ ẹ̀yìn gba ẹ̀mí mímọ́, ẹ̀yìn ìyẹn ni wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù kárí ayé. Ìtìlẹ́yìn ẹ̀mí Ọlọ́run nìkan ló lè jẹ́ kí wọ́n ní okun tí wọ́n á fi ní ìfaradà láti máa jẹ́ “ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.” (Mátíù 24:13, 14; Aísáyà 61:1, 2) Abájọ tí Jésù fi pe ẹ̀mí mímọ́ ní “olùrànlọ́wọ́.” (Jòhánù 15:26) Ó sọ pé ẹ̀mí Ọlọ́run ló máa kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun tó sì máa ṣamọ̀nà wọn.—Jòhánù 14:16, 26; 16:13.

17. Báwo ni ẹ̀mí mímọ́ ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ nígbà tá a bá dojú kọ àtakò gbígbóná janjan?

17 Àwọn ọ̀nà wo ni ẹ̀mí Ọlọ́run gbà ń ràn wá lọ́wọ́ lónìí nígbà tá a bá dojú kọ inúnibíni líle koko lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere náà? Ẹ̀mí Ọlọ́run máa ń fún wa lókun, ó sì máa ń gbéjà ko àwọn tó ń ṣenúnibíni sí wa. Bí àpẹẹrẹ, wo ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó wáyé nínú ìgbésí ayé Ọba Sọ́ọ̀lù.

Ẹ̀mí Ọlọ́run Gbéjà Ko Sọ́ọ̀lù

18. (a) Ìyípadà búburú wo ló dé bá Sọ́ọ̀lù? (b) Ọ̀nà wo ni Sọ́ọ̀lù gbà ṣe inúnibíni sí Dáfídì?

18 Sọ́ọ̀lù ni ọba tó kọ́kọ́ jẹ lórí Ísírẹ́lì. Ọmọlúàbí ni nígbà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jọba, àmọ́ nígbà tó yá ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣàìgbọràn sí Jèhófà. (1 Sámúẹ́lì 10:1, 24; 11:14, 15; 15:17-23) Nítorí èyí, ẹ̀mí Ọlọ́run ò ràn án lọ́wọ́ mọ́. Inú wá bẹ̀rẹ̀ sí í bí Sọ́ọ̀lù gan-an ó sì fẹ́ pa Dáfídì tí wọ́n ti fi òróró yàn láti di ọba tó máa jẹ tẹ̀ lé e, àmọ́ ẹ̀mí Ọlọ́run ti bẹ̀rẹ̀ sí ran Dáfídì lọ́wọ́ lákòókò náà. (1 Sámúẹ́lì 16:1, 13, 14) Sọ́ọ̀lù rò pé Dáfídì máa rọrùn fún òun láti mú. Ó ṣe tán, háàpù lásán ló wà lọ́wọ́ Dáfídì, ọ̀kọ̀ ló sì wà lọ́wọ́ Sọ́ọ̀lù. Lọ́jọ́ kan, bí Dáfídì ṣe ń fi háàpù rẹ̀ kọrin lọ́wọ́, “Sọ́ọ̀lù . . .ju ọ̀kọ̀ náà, ó sì wí pé: ‘Èmi yóò gún Dáfídì àní mọ́ ògiri!’ ṣùgbọ́n Dáfídì yí sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan kúrò níwájú rẹ̀, lẹ́ẹ̀mejì.” (1 Sámúẹ́lì 18:10, 11) Lẹ́yìn náà, Sọ́ọ̀lù fetí sí Jónátánì ọmọ rẹ̀ tó jẹ́ ọ̀rẹ́ Dáfídì, ó sì búra pé: “Bí Jèhófà ti ń bẹ, a kì yóò fi ikú pa [Dáfídì].” Àmọ́, nígbà tó ṣe díẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn, Sọ́ọ̀lù tún “wá ọ̀nà láti fi ọ̀kọ̀ gún Dáfídì mọ́ ògiri.” Ṣùgbọ́n Dáfídì “yẹ̀ sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan kúrò níwájú Sọ́ọ̀lù, tí ó fi sọ ọ̀kọ̀ náà wọnú ògiri.” Ni Dáfídì bá sá lọ, àmọ́ Sọ́ọ̀lù ń wá a kiri. Àkókò ìdààmú yẹn gan-an ni ẹ̀mí Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí gbéjà ko Sọ́ọ̀lù. Lọ́nà wo?—1 Sámúẹ́lì 19:6, 10.

19. Báwo ni ẹ̀mí Ọlọ́run ṣe dáàbò bo Dáfídì?

19 Dáfídì sá lọ sọ́dọ̀ wòlíì Sámúẹ́lì, àmọ́ Sọ́ọ̀lù ní káwọn ìránṣẹ́ òun lọ mú Dáfídì wá. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n dé ibi tí Dáfídì sá pamọ́ sí, “ẹ̀mí Ọlọ́run sì wá bà lé àwọn ońṣẹ́ Sọ́ọ̀lù, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí hùwà bí wòlíì.” Ẹ̀mí Ọlọ́run kápá wọn débi pé wọ́n gbàgbé ohun tí wọ́n wá ṣe níbẹ̀ pátápátá. Àmọ́, ìgbà méjì lẹ́yìn ìyẹn ni Sọ́ọ̀lù tún rán àwọn èèyàn pé kí wọ́n lọ mú Dáfídì wá, ohun kan náà ló sì ṣẹlẹ̀ nígbà méjèèjì ọ̀hún. Nígbà tó yá, Ọba Sọ́ọ̀lù fúnra rẹ̀ lọ bá Dáfídì, àmọ́ Sọ́ọ̀lù alára ò lè kojú ẹ̀mí Ọlọ́run. Àní, ẹ̀mí mímọ́ kò jẹ́ kó lè ṣe ohunkóhun “ní gbogbo ọjọ́ yẹn àti ní gbogbo òru yẹn” tí Dáfídì fi rọ́nà sá lọ mọ́ ọn lọ́wọ́ pátápátá.—1 Sámúẹ́lì 19:20-24.

20. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú bí Sọ́ọ̀lù ṣe ṣenúnibíni sí Dáfídì?

20 Ìtàn Sọ́ọ̀lù òun Dáfídì yìí kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ kan tó ń fúnni lókun, ẹ̀kọ́ náà ni pé: Àwọn tó ń ṣàtakò sáwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run kò lè kẹ́sẹ járí bí ẹ̀mí Ọlọ́run bá gbéjà kò wọ́n. (Sáàmù 46:11; 125:2) Jèhófà ti sọ pé Dáfídì máa di ọba lórí Ísírẹ́lì. Kò sẹ́ni tó lè yí ìyẹn padà. Jèhófà ti pinnu pé ‘a ó wàásù ìhìn rere ìjọba’ náà ní àkókò tiwa yìí. Kò sẹ́ni tó lè ní kíyẹn náà máà wáyé.—Ìṣe 5:40, 42.

21. (a) Kí làwọn alátakò kan máa ń ṣe lóde òní? (b) Ìdánilójú wo la ní?

21 Àwọn kan tó jẹ́ olórí ìsìn àtàwọn òṣèlú máa ń lo irọ́ láti dí wa lọ́wọ́, kódà wọ́n máa ń lù wá nígbà míì. Àmọ́, bí Jèhófà ṣe dáàbò bo Dáfídì nípa tẹ̀mí ni yóò ṣe dáàbò bo àwọn èèyàn Rẹ̀ lóde òní pẹ̀lú. (Málákì 3:6) Nítorí ìdí èyí, àwa náà lè fi ìgbọ́kànlé sọ ohun tí Dáfídì sọ pé: “Ọlọ́run ni mo gbẹ́kẹ̀ lé, àyà kì yóò fò mí. Kí ni ará ayé lè fi mí ṣe?” (Sáàmù 56:11; 121:1-8; Róòmù 8:31) Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, ẹ jẹ́ ká máa fara da gbogbo ìṣòro tó bá yọjú bá a ṣe ń ṣe iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́ pé ká máa wàásù ìhìn rere Ìjọba náà fún àwọn èèyàn gbogbo orílẹ̀-èdè.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo àpótí ‘Inú Wọn Dùn Gan-an,’ ní ojú ìwé 22.

b Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Kí nìdí tó fi yẹ ká máa yí àwọn ọ̀nà tá a gbà ń wàásù padà?

• “Ilẹ̀kùn ńlá” tó ṣamọ̀nà sí àwọn àǹfààní tuntun wo ló ti wà ní ṣíṣí sílẹ̀?

• Kí ni iṣẹ́ ìwàásù wa ti jẹ́ kó ṣeé ṣe, kódà láwọn ìpínlẹ̀ táwọn èèyàn ò ti ń fi bẹ́ẹ̀ tẹ́tí sílẹ̀?

• Kí nìdí tí kò fi sí alátakò kankan tó lè dá iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba náà dúró?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 22]

Inú Wọn Dùn Gan-an

Ohun tá a lè sọ nípa ìdílé kan tó ṣí kúrò ní Sípéènì tí wọ́n lọ sí Bolivia ni pé: “Inú wọn dùn, wọ́n sì ń gbádùn iṣẹ́ ìsìn wọn sí Jèhófà.” Ọmọkùnrin kan nínú ìdílé náà ló kọ́kọ́ lọ síbẹ̀ láti lọ ṣèrànwọ́ fún àwùjọ kan tó wà ní àdádó náà. Ayọ̀ tó rí níbẹ̀ wú àwọn òbí rẹ̀ lórí débi pé kíá ni gbogbo ìdílé náà títí kan àwọn ọmọkùnrin wọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí wọ́n jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlá sí ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n lọ ń sìn níbẹ̀. Mẹ́ta lára àwọn ọmọkùnrin náà ti di aṣáájú ọ̀nà báyìí, èyí tó sì kọ́kọ́ lọ síbẹ̀ lára wọn ti kẹ́kọ̀ọ́ yege ni Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ lẹ́nu àìpẹ́ yìí.

Angelica tó jẹ́ ẹni ọgbọ̀n ọdún láti Kánádà, tó ń sìn ní apá Ìlà Oòrùn ilẹ̀ Yúróòpù, sọ pé: “Àwọn ìṣòro téèyàn máa ń kojú kì í ṣe kékeré, àmọ́ inú mi ń dùn bí mo ṣe ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. Ohun tó tún máa ń wú mi lórí jù ni àwọn ọ̀rọ̀ ìmoore tó máa ń jáde lẹ́nu àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà níbẹ̀, tí wọ́n máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ mi pé mo ṣé, tí mo wá ran àwọn lọ́wọ́.”

Àwọn arábìnrin méjì kan tí wọ́n jẹ́ tẹ̀gbọ́n tàbúrò tí wọ́n sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ọmọ ọgbọ̀n ọdún láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, tí wọ́n sì ń sìn ní orílẹ̀-èdè Dominican Republic, sọ pé: “Àwọn àṣà ìbílẹ̀ ibi tá a ti ń sìn pọ̀ gan-an, èèyàn sì gbọ́dọ̀ mọ̀ wọ́n. Àmọ́ a ń lo ìfaradà nínú iṣẹ́ ìsìn wa, kódà méje lára àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló ti ń wá sípàdé báyìí.” Àwọn arábìnrin méjì yìí ló jẹ́ kí wọ́n ṣètò pé kí wọ́n dá àwùjọ kan sílẹ̀ tó jẹ́ tàwọn akéde Ìjọba Ọlọ́run ní ìlú kan tí kò ní ìjọ.

Laura, arábìnrin kan tó ti ń lọ sẹ́ni ọgbọ̀n ọdún ti ń sìn nílẹ̀ òkèèrè láti ohun tó lé ní ọdún mẹ́rin báyìí. Ó sọ pé: “Mo mọ̀ọ́mọ̀ ń gbé ìgbésí ayé mẹ̀kúnnù. Èyí sì ran àwọn akéde lọ́wọ́ láti rí i pé gbígbé ìgbésí ayé ohun-moní-tomi kì í ṣe ọ̀ràn pé èèyàn ò rówó fi lògbà, kàkà bẹ́ẹ̀ ohun téèyàn pinnu láti ṣe ni, ó sì fi hàn pé onítọ̀hún mọ nǹkan tó ń ṣe. Bí mo ṣe láǹfààní láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, àgàgà àwọn ọ̀dọ́, ti jẹ́ kí n máa láyọ̀, ìyẹn ò sì jẹ́ kí n máa ro ìnira tó wà nínú kéèyàn máa sìn nílẹ̀ òkèèrè. Mi ò ní fi iṣẹ́ ìsìn mi níbi sílẹ̀ nítorí ohunkóhun mìíràn láyé yìí, màá si wà níbi yìí níwọ̀n ìgbà tí Jèhófà bá ti gbà mí láyè láti ṣe bẹ́ẹ̀.”

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Àwọn Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Kékeré Good News for People of All Nations

Ìwé kékeré náà, Good News for People of All Nations ní ìsọfúnni olójú ewé kan nínú, èyí tá a kọ ní nǹkan bí èdè méjìléláàádọ́rùn-ún [92] ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Bí ìgbà tẹ́ni méjì bá jọ ń sọ̀rọ̀ la ṣe kọ ìsọfúnni náà. Nítorí ìdí èyí, nígbà tí ẹni tó ò ń wàásù fún bá ń ka ohun tó wà níbẹ̀, ńṣe ló máa dà bíi pé ìwọ gan-an lò ń bá a sọ̀rọ̀.

Bó o bá ṣí ìwé kékeré yìí, wàá rí àwòrán àwọn orílẹ̀-èdè tó wà láyé nínú èèpo ẹ̀yìn rẹ̀. Lo àwòrán náà láti fi bẹ̀rẹ̀ ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ẹni tó o fẹ́ wàásù fún. O lè tọ́ka sí orílẹ̀-èdè tó ò ń gbé, kó o sì jẹ kó mọ̀ pé wàá fẹ́ láti mọ ibi tó ti wá. Lọ́nà yẹn, wàá lè fún un níṣìírí láti sọ̀rọ̀, wàá sì mú kí ara tù ú, kẹ́ ẹ lè jọ sọ̀rọ̀ bí ọ̀rẹ́.

Ọ̀rọ̀ ìṣáájú nínú ìwé kékeré yìí sọ ohun bíi mélòó kan tá a lè ṣe ká bàa lè ṣèrànwọ́ tó yẹ fáwọn tó ń sọ èdè tá ò gbọ́. Jọ̀wọ́, fara balẹ̀ kà wọ́n, kó o sì rí i pé ò ń lò wọ́n dáadáa.

Kì í ṣe pé a to àwọn èdè tó wà nínú ìwé yìí síbi tá a kọ kókó ẹ̀kọ́ inú rẹ̀ sí nìkan ni, àmọ́ a tún kọ àwọn àmì tó dúró fún èdè kọ̀ọ̀kan sẹ́gbẹ̀ẹ́ èdè náà. Èyí á ràn ọ́ lọ́wọ́ gan-an láti mọ àwọn àmì tá a máa ń lò fún àwọn èdè tá a fi tẹ àwọn ìwé ìléwọ́ wa àtàwọn ìtẹ̀jáde mìíràn tó wà ní onírúurú èdè.

[Àwòrán]

Ǹjẹ́ o máa ń lo ìwé kékeré yìí nígbà tó o bá wà lóde ẹ̀rí?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Àwọn ìwé tá a fi ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti wà ní èdè tó lé ní irinwó báyìí

GÁNÀ

PHILIPPINES

LAPLAND (SWEDEN)

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24, 25]

Ǹjẹ́ o lè lọ sìn níbi tí wọ́n ti nílò àwọn olùpòkìkí Ìjọba náà gan-an

ECUADOR

DOMINICAN REPUBLIC