“Ó Parí O”
“Ó Parí O”
LỌ́DÚN 2002, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ìpàdé àgbègbè kan nílùú Mbandaka, lórílẹ̀-èdè Kóńgò. Nígbà tí wọ́n mú Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun jáde lédè Lingala ní ìpàdé agbègbè náà, àwọn tó wà nípàdé náà fò sókè tayọ̀tayọ̀, omi sì ń bọ́ lójú àwọn kan. Lẹ́yìn náà, àwọn èèyàn rọ́ lọ sórí pèpéle láti túbọ̀ wo Bíbélì tuntun náà dáadáa, wọ́n sì ń pariwo pé: “Basuki, Basambwe,” èyí tó túmọ̀ sí: “Ó parí o! Ojú tì wọ́n!”
Kí ló mú kínú àwọn èèyàn náà dùn tó báyìí, kí sì ni ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ yẹn? Láwọn apá ibì kan nílùú Mbandaka, kò ṣeé ṣe fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láti rí Bíbélì èdè Lingala rà. Kì nìdí? Nítorí pé àwọn ṣọ́ọ̀ṣì kì í ta Bíbélì náà fáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni. Àwọn Ẹlẹ́rìí ní láti rán ẹlòmíràn tí kì í ṣe ara wọn láti bá wọn rà á. Ní báyìí, inú wọn dùn jọjọ nítorí pé àwọn ṣọ́ọ̀ṣì ò lè fi Bíbélì dù wọ́n mọ́.
Kì í ṣe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan ni Bíbélì tuntun yìí yóò ṣe láǹfààní, àwọn aráàlú pàápàá yóò jàǹfààní rẹ̀. Ọkùnrin kan tó tẹ́tí sí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìpàdé náà nínú ilé rẹ̀ látorí ẹ̀rọ gbohùngbohùn tó wà níbi ìpàdé náà kọ̀wé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lẹ́tà tó kọ náà kà pé: “Inú mi dùn gan-an sí Bíbélì tẹ́ ẹ mú jáde yìí. Ọ̀pọ̀ nǹkan ni yóò jẹ́ ká túbọ̀ mọ̀. Èmi kì í ṣe ọ̀kan lára ẹ̀yin Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àmọ́ ara mi ti wà lọ́nà báyìí láti rí Bíbélì tẹ́ ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe yìí gbà.”
Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lódindi ti wà báyìí ní mẹ́tàlélọ́gbọ̀n èdè, Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì sì wà ní èdè mọ́kàndínlógún mìíràn. Èdè Lingala wà lára àwọn èdè wọ̀nyí. O ò ṣe béèrè lọ́wọ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bó o ṣe lè rí ẹ̀dà kan Bíbélì tí kò lẹ́gbẹ́ yìí gbà?