Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

‘Aláyọ̀ Ni Àwọn Tí Ohun Tẹ̀mí Ń Jẹ Lọ́kàn’

‘Aláyọ̀ Ni Àwọn Tí Ohun Tẹ̀mí Ń Jẹ Lọ́kàn’

‘Aláyọ̀ Ni Àwọn Tí Ohun Tẹ̀mí Ń Jẹ Lọ́kàn’

NÍGBÀ táwọn ẹyẹ bá jí lówùúrọ̀, wọ́n sábà máa ń ké ṣíoṣío fúngbà díẹ̀, lẹ́yìn náà wọ́n á fò lọ láti wá oúnjẹ kiri. Tó bá dalẹ́, wọ́n á padà sínú ìtẹ́ wọn, wọ́n á sì tún ké ṣíoṣío fúngbà díẹ̀ sí i, tó bá yá, wọ́n á sùn lọ. Láwọn ìgbà kan láàárín ọdún, akọ máa ń gùn abo, wọ́n á yé ẹyin, wọ́n á sì pamọ. Ìlànà yìí gẹ́lẹ́ làwọn ẹranko mìíràn ń tẹ̀ lé.

Àmọ́, àwa èèyàn yàtọ̀. Lóòótọ́ lá máa ń jẹun, tá à ń sùn, tá a sì ń bímọ, ṣùgbọ́n kìkì àwọn nǹkan wọ̀nyẹn kò fún ọ̀pọ̀ jù lọ wa láyọ̀. A fẹ́ mọ ohun tá a wà láyé fún. À ń wá bí ayé wa ṣe máa nítumọ̀. A tún fẹ́ mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Àwọn ohun tá a nífẹ̀ẹ́ sí yìí jẹ́ ká mọ̀ pé àwa ẹ̀dá èèyàn ní ànímọ́ kan tó yàtọ̀, ìyẹn ni pé a máa ń fẹ́ láti jọ́sìn.

Ọlọ́run Dá Wa Ní Àwòrán Ara Rẹ̀

Bíbélì ṣàlàyé ìdí tí ọ̀rọ̀ ìjọsìn fi máa ń jẹ àwọn èèyàn lọ́kàn, ó sọ pé: “Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí dá ènìyàn ní àwòrán rẹ̀, àwòrán Ọlọ́run ni ó dá a; akọ àti abo ni ó dá wọn.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:27) Dídá tá a dá wa ní “àwòrán Ọlọ́run” túmọ̀ sí pé a ní àwọn ànímọ́ kan tí Ọlọ́run ní bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé ti kó àbàwọ́n bá wa. (Róòmù 5:12) Bí àpẹẹrẹ, a lè ṣe àwọn nǹkan jáde. A tún ní ọgbọ́n dé ìwọ̀n àyè kan, a mọ ohun tó bẹ́tọ̀ọ́ mu, a sì lè fi ìfẹ́ tó jinlẹ̀ hàn sáwọn ẹlòmíràn. Síwájú sí i, a tún lè ronú nípa ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn, ká sì múra sílẹ̀ de ohun tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú.—Òwe 4:7; Oníwàásù 3:1, 11; Míkà 6:8; Jòhánù13:34; 1 Jòhánù 4:8.

Bó ṣe máa ń wù wá láti jọ́sìn Ọlọ́run ló jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run ti dá ànímọ́ yìí mọ́ wa. A ò lè rí ayọ̀ gidi tó máa wà títí lọ àyàfi tá a bá ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá wa. Jésù sọ pé, “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn, níwọ̀n bí ìjọba ọ̀run ti jẹ́ tiwọn.” (Mátíù 5:3) Àmọ́ ṣá o, a ní láti rí i dájú pé a wá nǹkan ṣe sí àìní tẹ̀mí náà, òtítọ́ tẹ̀mí ló sì lè ràn wá lọ́wọ́, ìyẹn òtítọ́ nípa Ọlọ́run, nípa àwọn ìlànà rẹ̀, àti nípa ohun tó fẹ́ ṣe fún aráyé. Ibo la ti lè rí òtítọ́ nípa Ọlọ́run yìí? Inú Bíbélì ni.

“Òtítọ́ Ni Ọ̀rọ̀ Rẹ”

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo.” (2 Tímótì 3:16) Ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù yẹn bá ti Jésù mu, èyí tó gbà nínú àdúrà sí Ọlọ́run pé: “Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.” Lónìí, Bíbélì Mímọ́ ni Ọ̀rọ̀ yẹn, ó sì bọ́gbọ́n mu pé ká máa ṣàyẹ̀wò bóyá ìgbàgbọ́ wa àti ọ̀nà tá à gbà ń gbé ìgbésí ayé wa bá ìlànà Bíbélì mu.—Jòhánù 17:17.

Tá a bá ń ṣàyẹ̀wò nípa bí ohun tá a gbà gbọ́ ṣe bá ohun tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mu, ńṣe là ń fara wé àwọn ará Bèróà ayé ìgbàanì, tí wọ́n wádìí láti rí i dájú pé ohun tí Pọ́ọ̀lù fi kọ́ wọn bá Ìwé Mímọ́ mu. Dípò kí Lúùkù ṣàríwísí àwọn ará Bèróà, ńṣe ló yìn wọ́n nítorí ìwà wọn. Ó kọ̀wé pé, wọ́n “gba ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú ìháragàgà ńláǹlà nínú èrò inú, tí wọ́n ń fẹ̀sọ̀ ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́ ní ti pé bóyá bẹ́ẹ̀ ni nǹkan wọ̀nyí rí.” (Ìṣe 17:11) Nítorí pé onírúurú ẹ̀kọ́ làwọn ìsìn fi ń kọ́ni lónìí, tó sì jẹ́ pé nǹkan ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ń sọ nípa ìwà tó yẹ kéèyàn máa hù, ó ṣe pàtàkì pé ká tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn ará Bèróà tí wọ́n jẹ́ ọlọ́kàn rere.

Ọ̀nà mìíràn tá a lè fi mọyì ohun tẹ̀mí ni pé ká wo bó ṣe ń yí ayé àwọn èèyàn padà sí rere. (Mátíù 7:17) Bí àpẹẹrẹ, téèyàn bá ń ṣe ohun tí Bíbélì wí, á jẹ́ kéèyàn di ọkọ rere, bàbá rere, aya rere, tàbí ìyá rere, á sì tipa bẹ́ẹ̀ fi kun ayọ̀ ìdílé, yóò sì túbọ̀ mú kéèyàn ní ìbàlẹ̀ ọkàn. Jésù sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń pa á mọ́.”—Lúùkù 11:28.

Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí mú wa rántí ọ̀rọ̀ tí Bàbá rẹ̀ ọ̀run sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì pé: “Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, Ẹni tí ń mú kí o tọ ọ̀nà tí ó yẹ kí o máa rìn. Ì bá ṣe pé ìwọ yóò fetí sí àwọn àṣẹ mi ní tòótọ́! Nígbà náà, àlàáfíà rẹ ì bá dà bí odò, òdodo rẹ ì bá sì dà bí ìgbì òkun.” (Aísáyà 48:17, 18) Dájúdájú irú ọ̀rọ̀ tó fani mọ́ra báyìí ní láti jẹ́ ìwúrí fún gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ inú rere àti òdodo!

Àwọn Kan Fẹ́ Kí Wọ́n Máa “Rìn Wọ́n Ní Etí”

Ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé Aísáyà yìí ni Ọlọ́run fi pàrọwà fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì nítorí pé ìsìn èké ti ṣì wọ́n lọ́nà. (Sáàmù 106:35-40) Àwa náà gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ká má ṣe gba irọ́ gbọ́. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa àwọn kan tó pe ara wọn ní Kristẹni, ó ní: “Nítorí sáà àkókò kan yóò wà, tí wọn kò ní gba ẹ̀kọ́ afúnni-nílera, ṣùgbọ́n, ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́-ọkàn ti ara wọn, wọn yóò kó àwọn olùkọ́ jọ fún ara wọn láti máa rìn wọ́n ní etí; wọn yóò sì yí etí wọn kúrò nínú òtítọ́.”—2 Tímótì 4:3, 4.

Àwọn aṣáájú ìsìn máa ń rin àwọn èèyàn létí nítorí pé wọ́n fàyè gba ìfẹ́ ọkàn tí kò tọ́, irú bí ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹni tí kì í ṣe ọkọ tàbí aya ẹni, ìbálòpọ̀ láàárín ẹ̀yà kan-náà àti ìmutípara. Bíbélì sọ kedere pé àwọn tó fọwọ́ sí irú ohun bẹ́ẹ̀ àtàwọn tó ń ṣe wọn “kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.”—1 Kọ́ríńtì 6:9, 10; Róòmù 1:24-32.

Láìsí àní-àní, ó gba ìgboyà kéèyàn tó lè gbé ìgbésí ayé tó bá ìlànà Bíbélì mu, àgàgà tí wọ́n bá ń fi wá ṣe yẹ̀yẹ́. Àmọ́ ó ṣeé ṣe. Àwọn èèyàn kan wà lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ti fìgbà kan rí jẹ́ ẹni tó ń lo oògùn olóró, ọ̀mùtípara, alágbèrè, ọmọ ìta, olè àti òpùrọ́. Síbẹ̀, wọ́n jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wọ̀ wọ́n lọ́kàn, ẹ̀mí mímọ́ sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti yí ìgbésí ayé wọn padà kí wọ́n lè “máa rìn lọ́nà tí ó yẹ Jèhófà.” (Kólósè 1:9, 10; 1 Kọ́ríńtì 6:11) Nítorí pé wọ́n ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run, wọ́n tún ní ìbàlẹ̀ ọkàn, wọ́n sì tún ní ìrètí gidi pé ọjọ́ ọ̀la á dára, gẹ́gẹ́ bí a óò ṣe rí i.

Ohun Tí Ìjọba Ọlọ́run Yóò Ṣe

Ìjọba Ọlọ́run ló máa mú ohun tí Bíbélì sọ ṣẹ pé àwọn èèyàn tó jẹ́ onígbọràn yóò ní àlàáfíà títí ayé. Jésù sọ nínú àdúrà àwòfiṣàpẹẹrẹ tó gbà, ó ní: “Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” (Matthew 6:10) Bẹ́ẹ̀ ni, kìkì Ìjọba Ọlọ́run ló lè mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run di ṣíṣe lórí ilẹ̀ ayé. Nítorí kí ni? Nítorí pé Ìjọba ọ̀run tí Jésù Kristi máa ṣàkóso ni Ọlọ́run máa lò láti fi hàn pé òun, Jèhófà, ni ọba aláṣẹ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé pátá.—Sáàmù 2:7-12; Dáníẹ́lì 7:13, 14.

Nítorí pé Jésù Kristi ni Ọba Ìjọba ọ̀run yẹn, yóò dá àwọn ẹ̀dá èèyàn tó bá ṣègbọràn sílẹ̀ kúrò nínú gbogbo ìgbèkùn, títí kan ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù àti ohun tí ẹ̀ṣẹ̀ náà fà, ìyẹn àìsàn àti ikú. Ìṣípayá 21:3, 4 sọ pé: “Wò ó! “Àgọ́ Ọlọ́run wà pẹ̀lú aráyé . . . [Jèhófà Ọlọ́run] yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.”

Àlàáfíà tó máa wà títí lọ yóò kárí ayé. Kí nìdí tó fi lè dá wa lójú gan-an? Ìdí tó fi lè dá wa lójú wà nínú Aísáyà 11:9 tó sọ pé: “Wọn [àwọn ọmọ abẹ́ Ìjọba náà] kì yóò ṣe ìpalára èyíkéyìí, bẹ́ẹ̀ ni wọn kì yóò fa ìparun èyíkéyìí ní gbogbo òkè ńlá mímọ́ mi; nítorí pé, ṣe ni ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo òkun.” Bẹ́ẹ̀ ni o, gbogbo àwọn tó ń gbé lórí ilẹ̀ ayé yóò ní ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run, wọ́n á sì máa ṣègbọràn sí i. Ǹjẹ́ èyí kò mu inú rẹ dùn? Tí ìdáhùn rẹ bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, ìsinsìnyí ló yẹ kó o bẹ̀rẹ̀ sí gba “ìmọ̀ Jèhófà” tó ṣeyebíye.

Ṣé Wàá Fetí sí Ìhìn Rere Ìjọba Náà?

Ọlọ́run yóò tipasẹ̀ Ìjọba rẹ̀ tún gbogbo ohun tí Èṣù ti bà jẹ́ ṣe yóò sì kọ́ àwọn èèyàn ní ọ̀nà òdodo Rẹ̀. Abájọ tí gbogbo ẹ̀kọ́ tí Jésù fi ń kọ́ni ṣe dá lórí Ìjọba yẹn. Jésù sọ pé: “Èmi gbọ́dọ̀ polongo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run fún àwọn ìlú ńlá mìíràn pẹ̀lú, nítorí pé tìtorí èyí ni a ṣe rán mi jáde.” (Lúùkù 4:43) Kristi pàṣẹ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn láti lọ sọ ìhìn rere kan náà yẹn fún àwọn èèyàn. (Mátíù 28:19, 20) Ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” (Mátíù 24:14) Òpin yẹn ti sún mọ́lé gan-an. Ẹ ò rí i pé ó ṣe pàtàkì gan-an pé káwọn olóòótọ́ ọkàn fetí sí ìhìn rere tó ń gbẹ̀mí là yìí!

Albert tá a sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú gbọ́ ìhìn rere nípa Ìjọba Ọlọ́run nígbà tí ìyàwó rẹ̀ àti ọmọ rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lákọ̀ọ́kọ́, Albert ń ṣiyè méjì. Àní, ó tiẹ̀ sọ pé kí àlùfáà àdúgbò òun wá sọ́dọ̀ aya àti ọmọ òun kó bàa lè járọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí. Àmọ́ àlùfáà náà kò fẹ́ dá sí ọ̀ràn náà. Nítorí náà Albert pinnu pé òun á tiẹ̀ fetí sí ohun tí wọ́n ń jíròrò látinú Bíbélì kóun lè já irọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí. Lẹ́yìn tó ti jókòó síbi ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lẹ́ẹ̀kan, ló bá bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́, ó sì fẹ́ mọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan sí i. Ó wá ṣàlàyé ohun tó mú kí ìwà òun yí padà. Ó sọ pé: “Ohun tí mo ti ń wá tipẹ́ nìyí.”

Lẹ́yìn-ọ̀-rẹ́yìn, Albert bẹ̀rẹ̀ sí rí ohun tó ń fẹ́ nípa tẹ̀mí, kò sì kábàámọ̀ rẹ̀. Òtítọ́ inú Bíbélì fún un ní ohun tó ti ń wá ní gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀. Ohun tó sì ń wá náà ni àtúnṣe sí ìwà ìrẹ́nijẹ àti ìwà ìbàjẹ́ tó gbòde kan àti ìrètí pé ọjọ́ iwájú á dára. Òtítọ́ inú Bíbélì fún un ní ìbàlẹ̀ ọkàn. Ǹjẹ́ ò ń rí oúnjẹ tẹ̀mí jẹ tó? O ò ṣe fi àkókò díẹ̀ ka àwọn ìbéèrè tá a tò sínú àpótí tó wà lójú ìwé 6? Bó o bá fẹ́ àlàyé sí i, inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà á dùn láti ràn ọ́ lọ́wọ́.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

ǸJẸ́ Ò Ń RÍ OÚNJẸ TẸ̀MÍ JẸ TÓ?

Ǹjẹ́ oúnjẹ tẹ̀mí tó ò ń jẹ́ ń tẹ́ ọ lọ́rùn? A fẹ́ kó o ka àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí, kó o sì dáhùn àwọn èyí tó o mọ̀ níbẹ̀.

□ Ta ni Ọlọ́run, kí sì ni orúkọ rẹ̀?

□ Ta ni Jésù Kristi? Kí nìdí tó fi kú? Báwo ni ikú rẹ̀ ṣe lè ṣe ọ́ láǹfààní?

□ Ǹjẹ́ Èṣù wà? Tó bá wà, ibo ló ti wá?

□ Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sáwọn èèyàn tó kú?

□ Kí ni Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe fún ilẹ̀ ayé àti fún aráyé?

□ Kí ni Ìjọba Ọlọ́run?

□ Kí ni ìlànà Ọlọ́run nípa ìwà tó yẹ ká máa hù?

□ Ipa wo ni Ọlọ́run fẹ́ kí ọkọ àti aya máa kó nínú ìdílé? Àwọn ìlànà Bíbélì wo ló ń mú kí ayọ̀ ìdílé pọ̀ sí i?

Bí o kò bá mọ ìdáhùn sí èyíkéyìí lára àwọn ìbéèrè wọ̀nyí, o lè béèrè fún ẹ̀dà kan ìwé pẹlẹbẹ náà Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la tẹ̀ ẹ́ jáde, ó sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rùn-ún mẹ́ta èdè tá a fi tẹ̀ ẹ́. Ìwé pẹlẹbẹ yìí sọ̀rọ̀ lórí kókó pàtàkì mẹ́rìndínlógún látinú Bíbélì, ó sì dáhùn gbogbo ìbéèrè tó wà lókè yìí níbàámu pẹ̀lú Ìwé Mímọ́.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Ẹ̀dá èèyàn máa ń fẹ́ láti jọ́sìn, wọn ò dá bí ẹranko

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

“Wọn yóò kó àwọn olùkọ́ jọ fún ara wọn láti máa rìn wọ́n ní etí.”—2 Tímótì 4:3

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ìjọba Mèsáyà látọwọ́ Ọlọ́run ni yóò mú àlàáfíà tó máa wà títí lọ wá