Wọ́n Ń Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú
Wọ́n Ń Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú
“ÀWỌN ènìyàn rẹ yóò fi tinútinú yọ̀ǹda ara wọn.” (Sáàmù 110:3) Gbólóhùn yìí ní ìtumọ̀ pàtàkì lọ́kàn àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́rìndínláàádọ́ta tí wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ yege ní kíláàsì kejìdínlọ́gọ́fà ti ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead. Kí làwọn ohun tí wọ́n ti ṣe kí wọ́n tó lè dẹni tó wá sílé ẹ̀kọ́ yìí, níbi tá a ti ń dá àwọn tó fẹ́ di míṣọ́nnárì lẹ́kọ̀ọ́ láti lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí nílẹ̀ òkèèrè? Mike àti Stacie tí wọ́n wà ní kíláàsì kejìdínlọ́gọ́fà yìí ṣàlàyé pé: “Ìpinnu tá a ṣe láti má ṣe kó ọrọ̀ jọ ló ràn wá lọ́wọ́ láti dín àwọn ohun tó lè pín ọkàn wa níyà kù, ó sì jẹ́ ká lè gbájú mọ́ àwọn nǹkan tẹ̀mí. A pinnu pé a ò ní jẹ́ kí bá a ṣe ń rọ́wọ́ mú nídìí iṣẹ́ ajé wa mú wa gbàgbé ohun tá à ń lé nípa tẹ̀mí.” Bíi ti Mike àti Stacie, tinútinú làwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó kù náà fi yọ̀ǹda ara wọn, wọ́n sì ń sìn báyìí gẹ́gẹ́ bí olùpolongo Ìjọba Ọlọ́run ní àgbègbè mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lágbàáyé.
Lọ́jọ́ Sátidé, March 12, 2005, àwọn èèyàn tó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́fà, ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ, àti mẹ́tàlélógójì [6,843] ni inú wọn ń dùn gan-an bí wọ́n ti ń tẹ́tí sí ìtòlẹ́sẹẹsẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege náà. Theodore Jaracz tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ṣe alága lọ́jọ́ náà. Lẹ́yìn tó ti kí àwọn àlejò tí wọ́n wá láti orílẹ̀-èdè méjìdínlọ́gbọ̀n ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ káàbọ̀, ó wá sọ̀rọ̀ lórí bí ẹ̀kọ́ Bíbélì ṣe ṣeyebíye tó. Olùbánisọ̀rọ̀ yìí fa ọ̀rọ̀ olùkọ́ ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ William Lyon Phelps yọ, ó sọ pé: “Gbogbo ẹni tó bá mọ Bíbélì dáadáa la lè pè ní ọ̀mọ̀wé.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀kọ́ ayé wúlò, síbẹ̀ ẹ̀kọ́ Bíbélì lọ̀gá. Ó ń jẹ́ káwọn èèyàn ní ìmọ̀ Ọlọ́run, èyí tó ń fúnni ní ìyè ayérayé. (Jòhánù 17:3) Arákùnrin Jaracz wá yin àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege náà fún bí wọ́n ṣe yọ̀ǹda ara wọn tinútinú kí wọ́n bàa lè túbọ̀ kópa gan-an nínú iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó karí ayé, èyí tó ń wáyé nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé lẹ́gbẹ̀rún lọ́nà méjìdínlọ́gọ́rùn-ún [98,000] jákèjádò ayé.
Ọ̀rọ̀ Ìṣírí Tó Bọ́ Sásìkò Fáwọn Akẹ́kọ̀ọ́yege
Lẹ́yìn ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́ tí alága sọ, arákùnrin William Samuelson wá sọ̀rọ̀ lórí kókó kan tí àkòrí rẹ̀ sọ pé: “Bẹ́ Ẹ Ṣe Lè Dà Bí Igi Ólífì Tó Gbọ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ Nílé Ọlọ́run” èyí tó gbé ka Sáàmù 52:8. Ó sọ pé a lo igi ólífì lọ́nà àpẹẹrẹ nínú Bíbélì, gẹ́gẹ́ bí ohun tó dúró fún ohun tó ń mú ọ̀pọ̀ èso jáde, ó sì tún dúró fún ẹwà àti iyì. (Jeremáyà 11:16) Olùbánisọ̀rọ̀ náà wá fi àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà wé igi ólífì ó sì sọ pé: “Jèhófà yóò kà yín sẹ́ni tó lẹ́wà àti ẹni iyì bẹ́ ẹ ti ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run tọkàntọkàn nínú iṣẹ́ míṣọ́nnárì tá a yàn yín sí.” Bó ṣe jẹ́ pé igi ólífì ní láti ta gbòǹgbò wọlẹ̀ dáadáa kó má bàa kú lásìkò ọ̀dá, bẹ́ẹ̀ náà làwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọ̀nyí gbọ́dọ̀ jẹ́ kí gbòǹgbò tẹ̀mí wọn lágbára kó bàa lè ṣeé ṣe fún wọn láti fara da ẹ̀mí ìdágunlá, àtakò, tàbí àwọn àdánwò mìíràn tó lè dojú kọ wọ́n lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn nílẹ̀ òkèèrè.—Mátíù 13:21; Kólósè 2:6, 7.
Arákùnrin John E. Barr, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn mẹ́ta tó ṣojú fún Ìgbìmọ̀ Olùdarí tó kópa nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà sọ̀rọ̀ lórí kókó tí ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé: “Ẹ̀yin Ni Iyọ̀ Ilẹ̀ Ayé.” (Mátíù 5:13) Ó sọ pé gẹ́gẹ́ bí ìyọ gidi kì í ti í jẹ́ kí oúnjẹ bà jẹ́, bẹ́ẹ̀ náà ni iṣẹ́ ìwàásù táwọn míṣọ́nnárì ń ṣe nípa Ìjọba Ọlọ́run yóò ṣe jẹ́ káwọn tó bá tẹ́tí sí i ní ìyè, ní ti pé yóò jẹ́ kí ìwà wọn dára, kò sì ní jẹ́ kí wọ́n díbàjẹ́ nípa tẹ̀mí. Lẹ́yìn náà, bí ìgbà tí bàbá bá ń bá ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀ ni Arákùnrin Barr ṣe rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege náà láti ‘wà ní àlàáfíà’ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. (Máàkù 9:50) Olùbánisọ̀rọ̀ náà gbà wọ́n níyànjú, ó ní: “Kẹ́ ẹ ní èso tẹ̀mí, kẹ́ ẹ sì rí i dájú pé ìwà yín àti ọ̀rọ̀ tó ń jáde lẹ́nu yín jẹ́ èyí tó dára nígbà gbogbo kó sì fi hàn pé ẹ̀ ń gba tàwọn ẹlòmíràn rò.”
“Jẹ́ Kí Ọkọ̀ Rẹ Léfòó Lórí Omi Jíjìn” ni àkòrí ọ̀rọ̀ arákùnrin Wallace Liverance tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì. Bí ọkọ̀ òkun tó ń rìnrìn àjò lórí omi jíjìn ṣe máa ń lọ lójú ọ̀nà tó tọ́, bẹ́ẹ̀ náà ni lílóye “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run,” ṣe máa ń ranni lọ́wọ́ láti tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Àwọn ohun ìjìnlẹ̀ náà ni àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ohun tí Ọlọ́run ṣèlérí àti bí yóò ṣe mú wọn ṣẹ. (1 Kọ́ríńtì 2:10) Bó bá jẹ́ pé inú omi tí kò jìn rárá nípa tẹ̀mí la kàn dúró sí, tá ò mọ̀ ju kìkìdá “ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ àwọn ohun àkọ́bẹ̀rẹ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ ìkéde ọlọ́wọ̀ ti Ọlọ́run,” a ò ní tẹ̀ síwájú o, kódà èyí lè sún wa lọ ṣe ohun tó máa mú kí ‘ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wa rì.’ (Hébérù 5:12, 13; 1 Tímótì 1:19) Arákùnrin Liverance wá kádìí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nípa sísọ pé: “Ẹ jẹ́ kí ‘ìjìnlẹ̀ àwọn ọrọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run’ máa gbe yín ró lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì yín.”—Róòmù 11:33.
Arákùnrin Mark Noumair tóun náà jẹ́ olùkọ́ nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì sọ̀rọ̀ lórí kókó ọ̀rọ̀ tó sọ pé, “Ṣé Wàá Tọ́jú Ogún Rẹ?” Ó ti lé lọ́gọ́ta ọdún ti ilé ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead ti ń gbayì bọ̀ tó sì lórúkọ rere nítorí ‘ọ̀pọ̀ ẹ̀rí rere’ táwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege nílé ẹ̀kọ́ náà ti jẹ́. Ogún yìí, ìyẹn orúkọ rere tí ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì ti ní, ti wá kan àwọn akẹ́kọ̀ọ́ kíláàsì kejìdínlọ́gọ́fà báyìí. Arákùnrin Noumair rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà láti máa fara wé àwọn ará Tékóà ìgbà ayé Nehemáyà kí wọ́n sì máa fi ìrẹ̀lẹ̀ fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ìjọ tí wọ́n máa dára pọ̀ mọ́ àtàwọn míṣọ́nnárì ẹgbẹ́ wọn. Ó gbà wọ́n níyànjú láti yàgò fún ìwà ìgbéraga irú èyí táwọn “ọlọ́lá ọba” tí Nehemáyà sọ̀rọ̀ nípa wọn hù, kí wọ́n sì múra tán láti máa ṣiṣẹ́ láìsí pé wọ́n ń pe àfiyèsí síra wọn tàbí kí wọ́n máa fẹ́ láti di gbajúmọ̀ láàárín àwọn arákùnrin àti arábìnrin wọn.—Nehemáyà 3:5.
Àwọn Ìrírí àti Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò Tó Lè Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́
Àkòrí apá tó kàn nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà ni, “Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ń Bá A Lọ Ní Gbígbilẹ̀.” (Ìṣe 6:7) Arákùnrin Lawrence Bowen tó jẹ́ olùkọ́ nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì ṣètò àwọn akẹ́kọ̀ọ́ láti ṣàṣefihàn àwọn ìrírí tí wọ́n ní lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù nígbà tí wọ́n wà nílé ìwé ọ̀hún. Àwọn ìrírí náà fi hàn pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ti fìtara kéde Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti pé Jèhófà bù kún ìsapá wọn gan-an.
Arákùnrin Richard Ashe fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn díẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì tí wọ́n ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó wá sílé ẹ̀kọ́ náà. Àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ jẹ́ ká túbọ̀ lóye bí ìdílé Bẹ́tẹ́lì ṣe ń ṣèrànwọ́ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́ Gílíádì kí wọ́n lè jàǹfààní gan-an nínú ẹ̀kọ́ wọn. Lẹ́yìn náà ni arákùnrin Geoffrey Jackson wá bá àwọn kan tó ti kẹ́kọ̀ọ́ yege nílé ẹ̀kọ́ Gílíádì nígbà kan rí sọ̀rọ̀. Wọ́n mẹ́nu kan ọ̀pọ̀ àǹfààní tí jíjẹ́ míṣọ́nnárì máa ń fúnni láti mú ìyìn àti ọlá bá Jèhófà. Ọ̀kan lára wọn sọ pé: “Bó o bá jẹ́ míṣọ́nnárì, gbogbo ohun tó o bá ń ṣe làwọn èèyàn á máa wò. Wọ́n á máa tẹ́tí sóhun tó o bá sọ, wọ́n á máa ṣọ́ ẹ, wọn kì í sì í gbàgbé àwọn nǹkan wọ̀nyí.” Nítorí náà, wọ́n rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà láti rí i dájú pé wọ́n ń fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀ nígbà gbogbo. Ó dájú pé ìmọ̀ràn rere yìí yóò ràn wọ́n lọ́wọ́ lọ́pọ̀lọpọ̀ lọ́jọ́ iwájú.
Arákùnrin Stephen Lett, tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí ló sọ ọ̀rọ̀ ìparí tí àkòrí rẹ̀ jẹ́, “Ẹ Jáde Lọ Gẹ́gẹ́ Bí Àwọn Tí Ń Fúnni Ní ‘Omi Ààyè.’” (Jòhánù 7:38) Ó ṣàlàyé pé láti oṣù márùn-ún sẹ́yìn làwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ti ń jàǹfààní gan-an bí wọ́n ti ń mu omi òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lámutẹ́rùn. Àmọ́ kí làwọn míṣọ́nnárì tuntun yìí yóò fi àwọn ohun tí wọ́n ti kọ́ ṣe? Arákùnrin Lett rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege náà láti fún àwọn ẹlòmíràn ní omi òtítọ́ yìí mu láìsí ìmọtara-ẹni-nìkan, káwọn ẹlòmíràn náà bàa lè dẹni tó ní “ìsun omi nínú [wọn] tí ń tú yàà sókè láti fi ìyè àìnípẹ̀kun fúnni.” (Jòhánù 4:14) Olùbánisọ̀rọ̀ náà tún wá sọ fún wọn pé: “Ẹ má ṣe gbàgbé láé láti máa fún Jèhófà tó jẹ́ ‘orísun omi ààyè’ náà ní ọlá àti ògo tó tọ́ sí i. Ẹ máa ṣe sùúrù nígbà tẹ́ ẹ bá ń kọ́ àwọn tó jáde wá látinú Bábílónì Ńlá tí ọ̀dá tẹ̀mí dá.” (Jeremáyà 2:13) Arákùnrin Lett parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nípa rírọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege náà láti máa fìtara ṣàfarawé ẹ̀mí àti ìyàwó náà kí wọ́n sì máa bá a lọ ní sísọ pé: “‘Máa bọ̀!’ Kí ẹnikẹ́ni tí òùngbẹ ń gbẹ sì máa bọ̀; kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀ gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.”—Ìṣípayá 22:17.
Arákùnrin Jaracz wá kádìí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà nípa kíka àwọn ìkíni tó wá láti ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. Lẹ́yìn náà ni ọ̀kan lára àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege ní kíláàsì yìí ka lẹ́tà ìdúpẹ́.
Ǹjẹ́ ìwọ náà gẹ́gẹ́ bí ẹnì kan lè yọ̀ǹda ara rẹ láti sìn níbi tá a ti nílò àwọn oníwàásù lójú méjèèjì? Bó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, gbé àwọn ohun tí wàá máa lé nípa tẹ̀mí ka iwájú rẹ gẹ́gẹ́ báwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege yìí ti ṣe. Wàá rí ayọ̀ àti ìfọ̀kànbalẹ̀ tó máa ń jẹ́ tẹni tó bá yọ̀ǹda ara rẹ̀ tayọ̀tayọ̀ fún iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, yálà gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì nílẹ̀ òkèèrè tàbí òjíṣẹ́ tí kò tiẹ̀ kúrò ní orílẹ̀-èdè rẹ̀.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 13]
ÌSỌFÚNNI NÍPA KÍLÁÀSÌ
Iye orílẹ̀-èdè táwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti wá: 8
Iye orílẹ̀-èdè tá a yàn wọ́n sí: 19
Iye àwọn akẹ́kọ̀ọ́: 46
Ìpíndọ́gba ọjọ́ orí wọn: 33.0
Ìpíndọ́gba ọdún tí wọ́n ti lò nínú òtítọ́: 16.5
Ìpíndọ́gba ọdún tí wọ́n ti lò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún: 12.9
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Kíláàsì Kejìdínlọ́gọ́fà Tó Kẹ́kọ̀ọ́ Yege Nílé Ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead
Nínú ìlà àwọn orúkọ tí ń bẹ nísàlẹ̀ yìí, nọ́ńbà kọ̀ọ̀kan jẹ́ láti iwájú lọ sẹ́yìn, a sì to orúkọ láti ọwọ́ òsì sí ọwọ́ ọ̀tún lórí ìlà kọ̀ọ̀kan.
(1) Brockmeyer, A.; Moloney, S.; Symonds, N.; Lopez, Y.; Howard, C. (2) Jastrzebski, T.; Brown, D.; Hernandez, H.; Malagón, I.; Jones, A.; Connell, L. (3) Howard, J.; Lareau, E.; Shams, B.; Hayes, S.; Brown, O. (4) Burrell, J.; Hammer, M.; Mayer, A.; Kim, K.; Stanley, R.; Rainey, R. (5) Jastrzebski, P.; Zilavetz, K.; Ferris, S.; Torres, B.; Torres, F. (6) Connell, J.; Hernandez, R.; Moloney, M.; Malagón, J.; Shams, R.; Hayes, J. (7) Ferris, A.; Hammer, J.; Stanley, G.; Kim, C.; Symonds, S.; Lopez, D.; Burrell, D. (8) Brockmeyer, D.; Mayer, J.; Rainey, S.; Zilavetz, S.; Jones, R.; Lareau, J.