Ẹ̀kọ́ Òtítọ́ Tínú Ọlọ́run Dùn Sí
Ẹ̀kọ́ Òtítọ́ Tínú Ọlọ́run Dùn Sí
KÍ ỌMỌ aráyé tó lè mọ ẹ̀kọ́ òtítọ́ tínú Ọlọ́run dùn sí, Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ní láti sọ èrò ọkàn rẹ̀ fún wọn. Ó sì ní láti jẹ́ kí gbogbo èèyàn láǹfààní láti mọ ohun tó bá sọ. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, báwo lọmọ aráyé ṣe lè mọ ẹ̀kọ́, ìsìn àti ìwà tínú Ọlọ́run dùn sí? Ǹjẹ́ Ọlọ́run pèsè irú ìsọfúnni bẹ́ẹ̀? Tó bá pèsè rẹ̀, ṣé ó kàn fẹnu sọ ọ́ ni àbí ó wà lákọsílẹ̀?
Ǹjẹ́ a lè rí èyíkéyìí lára àwa ọmọ èèyàn ọlọ́jọ́ kúkúrú tó lè bá gbogbo èèyàn sọ̀rọ̀ káríkárí, kí onítọ̀hún sì jẹ́ ẹni tí Ọlọ́run yóò máa gbẹnu rẹ̀ bá aráyé sọ̀rọ̀? Rárá o. Àmọ́ tí Ọlọ́run bá kọ èrò rẹ̀ sínú ìwé, gbogbo ìran ènìyàn á lè rí i kà. Nítorí náà, yóò dára kó jẹ́ pé inú ìwé kan ni ohun tí Ọlọ́run ṣí payá fún wa máa wà, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Lára àwọn ìwé àtayébáyé tí wọ́n kọ ọ́ sínú rẹ̀ pé Ọlọ́run mí sí i ni Bíbélì. Òǹkọ̀wé Bíbélì kan sọ pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo.” (2 Tímótì 3:16) Ẹ jẹ́ ká yẹ Bíbélì ọ̀hún wò bóyá a óò rí àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ nínú rẹ̀.
Ìgbà Wo Ni Bíbélì Ti Wà?
Bíbélì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìwé tó lọ́jọ́ lórí jù lọ nínú àwọn ìwé pàtàkì tó jẹ́ ìwé ẹ̀sìn. Ó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àtààbọ̀ [3,500] ọdún sẹ́yìn tí wọ́n ti kọ apá àkọ́kọ́ lára rẹ̀. Ọdún 98 Sànmánì Kristẹni ni wọ́n kọ ọ́ parí pátápátá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó tó ogójì èèyàn tó kọ Bíbélì, tí kíkọ rẹ̀ sì gba ẹgbẹ̀jọ [1,600] ọdún, síbẹ̀ kò sí èyí tó ta kora nínú gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ látòkè délẹ̀. Ìdí tó sì fi rí bẹ́ẹ̀ ni pé Ọlọ́run ló ni Bíbélì.
Bíbélì ni ìwé tó wà káàkiri ayé jù lọ, òun ni wọ́n sì tú sí èdè tó pọ̀ jù lọ. Lọ́dọọdún, ó lé ní ọgọ́ta mílíọ̀nù odindi Bíbélì tàbí apá kan rẹ̀ tó ń tẹ àwọn èèyàn lọ́wọ́. Ó ti ju ẹgbẹ̀rún méjì àti ọ̀ọ́dúnrún [2,300] èdè tàbí ẹ̀ka èdè tí wọ́n ti túmọ̀ odindi Bíbélì tàbí apá kan rẹ̀ sí. Ó lé ní
èèyàn mẹ́sàn-án nínú mẹ́wàá tí odindi Bíbélì tàbí apá kan rẹ̀ wà ní èdè àbínibí wọn. Kò síbi tí ìwé yìí kò tíì dé láyé, láìka orílẹ̀-èdè, ẹ̀yà tàbí ìran yòówù kó jẹ́.Báwo Ni Wọ́n Ṣe To Ìwé Inú Bíbélì?
Tó o bá ní Bíbélì, o ò ṣe ṣí i kó o wo bí wọ́n ṣe to àwọn ìwé inú rẹ̀? a Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ṣí Bíbélì rẹ sí ojú ìwé tí wọ́n to orúkọ gbogbo ìwé inú rẹ̀ àti ojú ìwé tí wọ́n wà sí. Nínú ọ̀pọ̀ jù lọ Bíbélì, apá ìbẹ̀rẹ̀ ló máa ń wà. Wàá rí i pé ìwé kéékèèké tó lórúkọ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n tò pa pọ̀ tó di ìwé ńlá tá à ń pè ní Bíbélì. Jẹ́nẹ́sísì nìwé àkọ́kọ́ níbẹ̀, ìwé Ìṣípayá tàbí Ìfihàn ló sì gbẹ̀yìn. Apá méjì ni wọ́n pín àwọn ìwé inú Bíbélì sí. Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ni wọ́n ń pe ìwé mọ́kàndínlógójì [39] àkọ́kọ́, nítorí pé èdè Hébérù ni wọ́n fi kọ ọ̀pọ̀ jù lọ wọn. Ìwé mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n [27] tó gbẹ̀yìn, tí wọ́n fi èdè Gíríìkì kọ ni wọ́n ń pè ní Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì. Àwọn míì máa ń pe apá méjèèjì yìí ní Májẹ̀mú Láéláé àti Májẹ̀mú Tuntun.
Àwọn ìwé inú Bíbélì ní orí àti ẹsẹ, kó bàa lè rọrùn fúnni láti rí ibi téèyàn fẹ́ kà. Nínú ìwé ìròyìn yìí, tá a bá tọ́ka sí ẹsẹ Bíbélì kan, nọ́ńbà tó tẹ̀ lé orúkọ ìwé Bíbélì náà ni orí, nọ́ńbà tó sì tẹ̀ lé èyí ni ẹsẹ rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá rí “2 Tímótì 3:16,” ohun tó túmọ̀ sí ni ìwé Tímótì kejì, orí kẹta ẹsẹ kẹrìndínlógún. Wò ó bóyá wàá lè wá ẹsẹ yìí rí nínú Bíbélì.
Ǹjẹ́ o ò rí i pé téèyàn bá fẹ́ mọ Bíbélì dáadáa, ohun tó ti dáa jù ni pé kéèyàn máa kà á déédéé? Àwọn kan ti rí i pé Ìwé Mímọ́ lédè Gíríìkì ló dára káwọn kọ́kọ́ kà, ìyẹn ni wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ láti ìwé Mátíù. Tó o bá ń ka orí Bíbélì mẹ́ta sí márùn-ún lójúmọ́, wàá ka gbogbo Bíbélì tán lọ́dún kan. Ṣùgbọ́n, báwo ló ṣe lè dá ọ lójú pé lóòótọ́ ni Ọlọ́run mí sí àwọn ohun tó ò ń kà nínú Bíbélì?
Ǹjẹ́ O Lè Gba Bíbélì Gbọ́?
Ǹjẹ́ kò yẹ kí ìwé tí Ọlọ́run mí sí tó sì pèsè fún gbogbo èèyàn ní ìmọ̀ràn nípa bá a ṣe lè gbé ìgbésí ayé, kí ìmọ̀ràn náà sì wúlò títí lọ gbére? Ọ̀rọ̀ inú Bíbélì jẹ́ ọ̀rọ̀ ẹni tó mọ ẹ̀dá èèyàn tinú tòde, gbogbo ìran èèyàn látìrandíran ló sì kàn. Bí àwọn ìlànà inú rẹ̀ ṣe wúlò gan-an láyé ìgbà tí wọ́n kọ ọ́ náà ló ṣì ṣe wúlò lóde òní. Ẹ̀rí èyí hàn kedere nínú àsọyé pàtàkì kan tí Jésù Kristi tó dá ẹ̀sìn Kristẹni sílẹ̀ sọ. Àsọyé yìí wà nínú Mátíù orí karùn-ún sí ìkeje. Àsọyé rẹ̀ yìí tí wọ́n ń pè ní Ìwàásù Orí Òkè jẹ́ ka mọ bá a ṣe lè rí ayọ̀ tòótọ́, bá a ṣe lè yanjú aáwọ̀, bá a ṣe lè gbàdúrà, irú ojú tó yẹ ká máa fi wo àwọn nǹkan tara, àti ọpọ̀ nǹkan míì. Àsọyé yìí àtàwọn ọ̀rọ̀ yòókù nínú Bíbélì sọ ohun tó yẹ ká ṣe fún wa kedere àti ohun tí kò yẹ ká ṣe tá a bá fẹ́ rí ojú rere Ọlọ́run kí ayé wa sì dára.
Ìdí míì tó fi yẹ kó o gba Bíbélì gbọ́ ni pé níbi tí Bíbélì, ìwé tí wọ́n kọ nígbà láéláé yìí ti sọ̀rọ̀ nípa ohun tó jẹ mọ́ sáyẹ́ǹsì, bó ṣe sọ ọ́ gẹ́lẹ́ náà ló rí. Bí àpẹẹrẹ, láyé àtijọ́ tí ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn gbà pé ojú ilẹ̀ ayé tẹ́ pẹrẹsẹ ni Bíbélì ti sọ bí ayé ṣe rí, tó pè é ní “òbìrìkìtì ilẹ̀ ayé.” b (Aísáyà 40:22) Ní èyí tó sì lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] ọdún ṣáájú kí onímọ̀ sáyẹ́ǹsì olókìkí nì, Alàgbà Isaac Newton, tó ṣàlàyé pé agbára òòfà ló gbé ayé, oòrùn, òṣùpá àtàwọn ìràwọ̀ dúró lójú òfuurufú láìsí ohunkóhun tí wọ́n so mọ́, ni Bíbélì ti sọ pé “ilẹ̀ ayé rọ̀ sórí òfo.” (Jóòbù 26:7) Tún wo bí Bíbélì ṣe lo èdè ewì láti fi ṣàlàyé bí omi orí ilẹ̀ ayé ṣe ń lọ yípo-yípo. Ní ohun tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] ọdún sẹ́yìn, ni Bíbélì sọ ọ́ pé: “Odò gbogbo ni nṣan sinu òkun ṣugbọn òkun kò kún nibi ti awọn odò ti nṣan wa, nibẹ ni wọn si tun pada lọ.” (Oníwàásù 1:7, Bibeli Yoruba Atọ́ka) Ó dájú nígbà náà pé Ẹlẹ́dàá ọ̀run òun ayé ni Ẹni tó ni Bíbélì.
Bí ìtàn inú Bíbélì ṣe jóòótọ́ délẹ̀délẹ̀ tún jẹ́ ẹ̀rí tó fi hàn pé Ọlọ́run mí sí i. Àwọn ìtàn tó wà lákọọ́lẹ̀ nínú Bíbélì kì í ṣe àròsọ rárá. Bíbélì sọ ìgbà tí wọ́n ṣẹlẹ̀ gan-gan, àwọn èèyàn tó ṣẹlẹ̀ sí àti ibi tí wọ́n ti ṣẹlẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, Lúùkù 3:1 sọ ọ́ gbangba pé ìṣẹ̀lẹ̀ kan wáyé “ní ọdún kẹẹ̀ẹ́dógún ìgbà ìjọba Tìbéríù Késárì, nígbà tí Pọ́ńtíù Pílátù jẹ́ gómìnà Jùdíà, tí Hẹ́rọ́dù sì jẹ́ olùṣàkóso àgbègbè Gálílì.”
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣẹ́gun àwọn alákòóso àtohun dáradára tí wọ́n ṣe nìkan làwọn òpìtàn ayé àtijọ́ sábà máa ń kọ sílẹ̀, àwọn tó kọ Bíbélì ò fi nǹkan kan bò ní tiwọn, títí kan àṣìṣe tàwọn fúnra wọn pàápàá. Bí àpẹẹrẹ, Dáfídì ọba Ísírẹ́lì jẹ́wọ́ pé: “Mo ti ṣẹ̀ gidigidi nínú ohun tí mo ti ṣe. . . . Mo ti hùwà òmùgọ̀ gan-an.” Bí wọ́n sì ṣe kọ ọ́ sínú Bíbélì gẹ́lẹ́ nìyẹn. (2 Sámúẹ́lì 24:10) Mósè tó jẹ́ òǹkọ̀wé Bíbélì pàápàá kọ ìtàn nípa ìgbà tí ohun kan ṣẹlẹ̀ tí òun alára kò ṣe ohun tó fi hàn pé ó gbára lé Ọlọ́run tòótọ́.—Númérì 20:12.
Nǹkan mìíràn tún wà tó fi hàn pé Ọlọ́run mí sí Bíbélì. Òun ni pé ó máa ń sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ ìtàn bí ìṣẹ̀lẹ̀ kan ṣe máa rí kó tó ṣẹlẹ̀, á sì ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ láìtàsé. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Jésù Kristi wà lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tá à ń wí yìí. Bí àpẹẹrẹ, ní èyí tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin [700] ọdún ṣáájú kí wọ́n tó bí Jésù ni Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ti sọ tẹ́lẹ̀ pé ìlú “Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ti Jùdíà” ni wọ́n ti máa bí Ẹni tí Ọlọ́run ṣèlérí rẹ̀ yìí, ó sì rí bẹ́ẹ̀.—Mátíù 2:1-6; Míkà 5:2.
Tún wo àpẹẹrẹ mìíràn. Nínú Tímótì kejì, orí kẹta, ẹsẹ kìíní sí ìkarùn-ún, Bíbélì sọ pé: “Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò yóò wà níhìn-ín. Nítorí àwọn ènìyàn yóò jẹ́ olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni-lójú, onírera, asọ̀rọ̀ òdì, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, afinihàn, olùwarùnkì, awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga, olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run, àwọn tí wọ́n ní ìrísí fífọkànsin Ọlọ́run ṣùgbọ́n tí wọ́n já sí èké ní ti agbára rẹ̀.” Irú ìwà wọ̀nyí wọ́pọ̀ láàárín àwọn èèyàn òde òní, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Kẹ́ ẹ sì wá wò ó o, ọdún 65 Sànmánì Kristẹni, èyí tó ti ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀wá [1,900] ọdún sẹ́yìn, ni wọ́n ti kọ ọ́ sílẹ̀!
Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
Bó o bá ka Bíbélì, wàá rí i pé ògidì ọgbọ́n ló ń kọ́ni. Ó dáhùn àwọn ìbéèrè bíi: Ta ni Ọlọ́run? Ǹjẹ́ Èṣù wà lóòótọ́? Ta ni Jésù Kristi? Kí nìdí tọ́mọ èèyàn fi ń jìyà? Kí ló ń ṣẹlẹ̀ síni nígbà téèyàn bá kú? Tó o bá bi àwọn èèyàn ní ìbéèrè wọ̀nyí, ohùn wọn ò lè ṣọ̀kan nítorí bí ẹ̀sìn àti àṣà ìbílẹ̀ wọn ṣe yàtọ̀ síra ni ìdáhùn wọn ṣe máa yàtọ̀ tó. Ṣùgbọ́n Bíbélì sọ òtítọ́ nípa kókó wọ̀nyí àtàwọn kókó mìíràn. Bákan náà, kò sí ìtọ́sọ́nà tó dáa tó ti Bíbélì lórí ọ̀ràn bó ṣe yẹ ká máa hùwà àtohun tó yẹ ká máa ṣe sí ọmọnìkejì wa àtàwọn aláṣẹ. c
Kí ni Bíbélì sọ nípa ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe nípa ilẹ̀ ayé àtohun tó máa ṣe fún aráyé? Ìlérí tó wà nínú rẹ̀ ni pé: “Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹni burúkú kì yóò sì sí mọ́ . . . Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.” (Sáàmù 37:10, 11) “Ọlọ́run fúnra rẹ̀ yóò sì wà pẹ̀lú [aráyé]. Yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ.” (Ìṣípayá 21:3, 4) “Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”—Sáàmù 37:29.
Bíbélì tún sọ tẹ́lẹ̀ pé ogun, ìwà ipá, ìwà ọ̀daràn àti ìwà ibi yóò dópin láìpẹ́. Àìsàn, ọjọ́ ogbó àti ikú kò sì ní sí mọ́. Ayé yóò di Párádísè téèyàn yóò ti máa wà láàyè títí láé. Ìyẹn á ti lọ wà jù! Gbogbo èyí jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ọmọ aráyé gan-an ni!
Kí Ló Yẹ Kó O Ṣe?
Ẹ̀bùn àtàtà tí Ẹlẹ́dàá fi jíǹkí wa ni Bíbélì jẹ́. Ọwọ́ wo ló wá yẹ ká fi mú un? Ọkùnrin kan tó d Bákan náà ni ọ̀jọ̀gbọ́n kan ní yunifásítì kan lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà rí i pé á dára kóun kọ́kọ́ ka ìwé táwọn èèyàn ní lọ́wọ́ jù lọ yìí wò kóun tó sọ ohunkóhun nípa rẹ̀.
jẹ́ ẹlẹ́sìn Híńdù sọ pé kí ohun kan tí Ọlọ́run ṣí payá tó lè ṣe gbogbo ìran èèyàn pátá láǹfààní, ó yẹ kó ti tẹ aráyé lọ́wọ́ látìgbà ìjímìjí. Nígbà tí ọkùnrin yìí wá rí i pé apá kan lára Bíbélì ti wà tipẹ́tipẹ́ ṣáájú èyí tó lọ́jọ́ lórí jù lọ lára àwọn ìwé ẹ̀sìn Híńdú, ìyẹn Veda, ó pinnu láti ka Bíbélì kó lè mọ ohun tó wà nínú rẹ̀.Tó o bá ń ka Bíbélì tó o sì ń fi ohun tó sọ sílò, yóò ṣe ọ́ láǹfààní gan-an. Bíbélì sọ pé: “Aláyọ̀ ni ènìyàn tí . . . inú dídùn rẹ̀ wà nínú òfin Jèhófà, [tó] sì ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ka òfin rẹ̀ tọ̀sán-tòru. Dájúdájú, òun yóò dà bí igi tí a gbìn sẹ́bàá àwọn ìṣàn omi, tí ń pèsè èso tirẹ̀ ní àsìkò rẹ̀ èyí tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ eléwé kì í sì í rọ, gbogbo nǹkan tí ó bá ń ṣe ni yóò sì máa kẹ́sẹ járí.” e (Sáàmù 1:1-3) Tó o bá ń ka Bíbélì tó o sì ń ṣàṣàrò lórí ohun tó sọ, yóò mú ọ láyọ̀ torí pé wàá máa rí àwọn ohun tẹ̀mí tó ṣe pàtàkì gbà. (Mátíù 5:3) Bíbélì yóò jẹ́ kó o mọ bó o ṣe lè gbé ìgbé ayé tó dára àti bó o ṣe lè máa fara da ìṣòro. Láìsí àní-àní, “èrè ńlá wà nínú pípa [àwọn òfin Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì] mọ́.” (Sáàmù 19:11) Ìyẹn nìkan kọ́ o, tó o bá gba àwọn ìlérí Ọlọ́run gbọ́, yóò ṣe ọ́ láǹfààní nísinsìnyí, yóò sì jẹ́ kí ọkàn rẹ balẹ̀ pé ọ̀la ṣì ń bọ̀ wá dára.
Bíbélì rọ̀ wá pé: “Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ jòjòló tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí, ẹ ní ìyánhànhàn fún wàrà aláìlábùlà tí ó jẹ́ ti ọ̀rọ̀ náà.” (1 Pétérù 2:2) Wàrà ṣe pàtàkì gan-an fáwọn ọmọ jòjòló, wọn kì í sì í sinmi àfi bí wọ́n bá rí i mu. Bákan náà ni ìmọ̀ Ọlọ́run ṣe ṣe pàtàkì gan-an fún wa. Nítorí náà, ‘máa yán hànhàn’ fún Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ìyẹn ni pé kó o jẹ́ kó máa wù ọ́ kà nígbà gbogbo. Inú Bíbélì la ti lè rí ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó tọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá o. Rí i pé ò ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ déédéé. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lágbègbè rẹ yóò sì dùn láti ràn ọ́ lọ́wọ́ kí òye ohun tó ò ń kà lè túbọ̀ yé ọ. A rọ̀ ọ́ pé kó o kàn sí wọn. O sì lè kọ̀wé sí àwọn tó tẹ ìwé ìròyìn yìí.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti fún ọ ní Bíbélì tó ò bá ní.
b Ọ̀rọ̀ Hébérù tá a tú sí “òbìrìkìtì” nínú Aísáyà 40:22 tún ṣe é tú sí “róbótó.” Àwọn ìtumọ̀ Bíbélì kan túmọ̀ ọ̀rọ̀ Hébérù yìí sí “òbìrí ayé” (Bibeli Yoruba Atọ́ka) tàbí “ayé róbótó.”—Bíbélì Moffatt.
c A ṣàlàyé kókó wọ̀nyí nínú ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.
d Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] ọdún sẹ́yìn ni wọ́n sọ pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kọ orin ìsìn àwọn Híńdù tí wọ́n ń pè ní Veda, tí wọ́n sì ń gbà á látẹnu dẹ́nu látìgbà náà. P. K. Saratkumar sọ nínú ìwé rẹ̀, A History of India (Ìtan Íńdíà), pé: “Ọ̀rúndún kẹrìnlá [ìyẹn nǹkan bí ẹgbẹ̀ta ọdún sẹ́yìn] ni wọ́n tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ orin Veda sínú ìwé.”
e Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run tó ni Bíbélì. A lè rí orúkọ yìí nínú Sáàmù 83:18 nínú ọ̀pọ̀ Bíbélì.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
‘Máa yán hànhàn’ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 5]
Fọ́to NASA