Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ibi Ìkówèésí Àkọ́kọ́ Nílẹ̀ Rọ́ṣíà Fi Hàn Kedere Pé Òótọ́ Lọ̀rọ̀ Bíbélì

Ibi Ìkówèésí Àkọ́kọ́ Nílẹ̀ Rọ́ṣíà Fi Hàn Kedere Pé Òótọ́ Lọ̀rọ̀ Bíbélì

Ibi Ìkówèésí Àkọ́kọ́ Nílẹ̀ Rọ́ṣíà Fi Hàn Kedere Pé Òótọ́ Lọ̀rọ̀ Bíbélì

ÀWỌN ọ̀mọ̀wé méjì kan ń wá àwọn ìwé Bíbélì àfọwọ́kọ ìgbàanì lójú méjèèjì. Olúkúlùkù wọn gba ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lọ sínú aṣálẹ̀ láti lọ wá gbogbo ihò inú àpáta, wọ́n lọ sílé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé tó wà ní àdádó àtàwọn ilé àtijọ́ tó wà ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè. Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, ọwọ́ wọn kanra ní ibi ìkówèésí àkọ́kọ́ nílẹ̀ Rọ́ṣíà, níbi tí wọ́n kó àwọn ìwé Bíbélì ìgbàanì tó ṣe pàtàkì jù lọ lágbàáyé tí wọ́n ṣàwárí sí. Ta ni àwọn ọkùnrin yìí? Báwo sì làwọn ohun tí wọ́n ṣàwárí ṣe dé orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà?

Àwọn Ìwé Bíbélì Àfọwọ́kọ Ìgbàanì Fìdí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Múlẹ̀

Ká tó lè mọ̀ nípa ọ̀kan lára àwọn ọ̀mọ̀wé yìí, a ní láti mọ àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ ní nǹkan bí igba ọdún sẹ́yìn tó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo àwọn tó wà nílẹ̀ Yúróòpù ló ṣáà fẹ́ di ọ̀jọ̀gbọ́n. Àsìkò yìí ni ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ tẹ̀ síwájú táwọn èèyàn sì túbọ̀ ń ṣe ohun tó máa gbé ògo ilẹ̀ wọn yọ. Èyí ló mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa kọminú sí ohun táwọn èèyàn ti gbà gbọ́ látọjọ́ pípẹ́. Àwọn tó ń ṣe lámèyítọ́ ọ̀rọ̀ Bíbélì àti ìtumọ̀ rẹ̀ wá ń wá oríṣiríṣi ọ̀nà tí wọ́n lè gbà jin ọ̀rọ̀ Bíbélì lẹ́sẹ̀. Kódà, àwọn ọ̀mọ̀wé ń sọ ọ́ pé kò dájú pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ inú Bíbélì.

Àwọn kan tí wọ́n gbà tinútinú pé ọ̀rọ̀ Bíbélì ṣeé gbára lé wò ó pé táwọn bá lè ṣàwárí àwọn ìwé Bíbélì ìgbàanì tí wọ́n fọwọ́ kọ, èyí tí wọn kò tíì rí lákòókò náà, àwọn èèyàn á gbà láìsí iyèméjì pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣeé gbára lé. Wọ́n ní táwọn bá lè rí àwọn ìwé Bíbélì àfọwọ́kọ tí ọjọ́ rẹ̀ pẹ́ ju tàwọn tó wà lọ́wọ́ lásìkò ìgbà yẹn lọ, wọ́n á jẹ́ ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro pé òótọ́ lọ̀rọ̀ Bíbélì, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọjọ́ ti pẹ́ táwọn èèyàn ti ń wá oríṣiríṣi ọ̀nà látọjọ́ pípẹ́ láti pa Bíbélì run tàbí láti gbé ìtumọ̀ rẹ̀ gbòdì. Èyí nìkan kọ́ o, wọ́n tún lè jẹ́ káwọn èèyàn rí àwọn ibì kọ̀ọ̀kan táwọn àṣìṣe ti yọ́ wọnú Bíbélì.

Ilẹ̀ Jámánì làwọn èèyàn ti ń bára wọn jiyàn lọ́nà tó gbóná jù lórí bí ọ̀rọ̀ inú Bíbélì ṣe jẹ́ òótọ́ sí. Lórílẹ̀-èdè náà, ọ̀jọ̀gbọ́n kan tí kò tíì dàgbà púpọ̀ fi yunifásítì tó wà sílẹ̀, ó sì rìnrìn àjò pàtàkì kan tó jẹ́ kó ṣàwárí àwọn ìwé Bíbélì ìgbàanì tó ṣe pàtàkì jù lọ láyé. Konstantin von Tischendorf lorúkọ ọ̀jọ̀gbọ́n tó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ náà. Ọ̀jọ̀gbọ́n yìí ò fara mọ́ àṣà ṣíṣe lámèyítọ́ ọ̀rọ̀ Bíbélì, èyí tó jẹ́ kó lè fi hàn gbangba-gbàǹgbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ Bíbélì. Nígbà tó kọ́kọ́ lọ sí aṣálẹ̀ Sínáì lọ́dún 1844, àwọn ohun tó rí mú bọ̀ pọ̀ ju ohun tó lálàá pé òun lè rí lọ. Nínú ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé kan tó lọ, ńṣe ló kàn ní kí òun yọjú wo inú apẹ̀rẹ̀ kan tí wọ́n ń kó ìdọ̀tí sí ló bá rí ohun kan níbẹ̀ tó jọ ọ́ lójú gidigidi. Ohun tó rí náà ni àwọn ìwé Bíbélì Septuagint, ìyẹn Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tí wọ́n tú sí èdè Gíríìkì, èyí sì ni Bíbélì àfọwọ́kọ tí ọjọ́ rẹ̀ pẹ́ jù lọ tí wọ́n tíì ṣàwárí lágbàáyé lásìkò yẹn!

Inú Tischendorf dùn gan-an nígbà tó rí àwọn ìwé Bíbélì tí wọ́n fọwọ́ kọ sórí awọ náà, ló bá kó mẹ́tàlélógójì lọ lára wọn. Ó dá a lójú pé àwọn ìwé náà ṣì kù síbẹ̀, àmọ́ nígbà tó máa fi padà wá lọ́dún 1853, ẹyọ kan ṣoṣo ló rí. Ibo làwọn tó kù wà? Nígbà tí kò sówó mọ́ lọ́wọ́ Tischendorf, ó lọ bá ọlọ́rọ̀ kan tó lè ràn án lọ́wọ́, ó sì pinnu láti tún kúrò lórílẹ̀-èdè rẹ̀ láti lọ wá àwọn ìwé Bíbélì àfọwọ́kọ ọlọ́jọ́ pípẹ́ sí i. Àmọ́, kó tó lọ sí ìrìn àjò yìí, ó kọ́kọ́ lọ bá ọba ilẹ̀ Rọ́ṣíà fún ìtìlẹ́yìn.

Inú Ọba Ilẹ̀ Rọ́ṣíà Dùn sí Akitiyan Tischendorf

Ó dájú pé Tischendorf á ti máa ṣàníyàn nítorí kò mọ̀ bóyá àwọn ará ilẹ̀ Rọ́ṣíà á tẹ́wọ́ gba òun tàbí wọn ò ní tẹ́wọ́ gba òun. Ìdí ni pé ẹ̀ṣìn Kristẹni tó ń ṣe yàtọ̀ sí tàwọn ará Rọ́ṣíà tó jẹ́ pé Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Rọ́ṣíà ni ọ̀pọ̀ lára àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè wọn tó tóbi gan-an yẹn ń lọ. Àmọ́, ó dára tó jẹ́ pé àkókò tí ilẹ̀ Rọ́ṣíà ń ṣe àyípadà sí àwọn ìlànà wọn ló lọ. Báwọn èèyàn ilẹ̀ Rọ́ṣíà ṣe túbọ̀ ń mọyì ẹ̀kọ́ ló mú kí Ọbabìnrin Catherine Kejì kọ́ Ibi Ìkówèésí Aláyélúwà Ti Ìlú St. Petersburg lọ́dún 1795. Níwọ̀n bí ibi ìkówèésí yìí ti jẹ́ àkọ́kọ́ irú rẹ̀ lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà, ó jẹ́ kí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn láǹfààní láti rí ọ̀pọ̀ ìwé kà.

Lóòótọ́ làwọn èèyàn gbà pé Ibi Ìkówèésí Aláyélúwà yìí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ibi ìkówèésí tó dára jù lọ nílẹ̀ Yúróòpù, síbẹ̀ ohun kan kù díẹ̀ káàtó níbẹ̀. Ohun náà ni pé lẹ́yìn àádọ́ta ọdún tí wọ́n ti ń lò ó, kìkì ìwé Bíbélì àfọwọ́kọ mẹ́fà lédè Hébérù ló wà níbẹ̀. Tá a bá sì ní ká fi ojú báwọn èèyàn ilẹ̀ Rọ́ṣíà ṣe túbọ̀ ń fọwọ́ pàtàkì mú ẹ̀kọ́ nípa èdè àti ìtumọ̀ Bíbélì wò ó, ẹyọ ìwé Bíbélì mẹ́fà yìí kéré jọjọ. Ọbabìnrin Catherine Kejì rán àwọn ọ̀mọ̀wé lọ sáwọn yunifásítì kan tó wà nílẹ̀ Yúróòpù láti lọ kọ́ èdè Hébérù. Lẹ́yìn táwọn ọ̀mọ̀wé náà padà dé, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àwọn èèyàn ní èdè Hébérù láwọn ilé ẹ̀kọ́ṣẹ́ àlùfáà pàtàkì-pàtàkì tó jẹ́ ti Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì Ilẹ̀ Rọ́ṣíà. Yàtọ̀ síyẹn, fún ìgbà àkọ́kọ́, àwọn ọ̀mọ̀wé ilẹ̀ Rọ́ṣíà bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìtúmọ̀ Bíbélì lọ́nà tó péye látinú èdè Hébérù ìgbàanì sí èdè Rọ́ṣíà. Àmọ́, wọn ò rówó láti máa fi ṣe é lọ, bẹ́ẹ̀ làwọn olórí ìjọ tí kò nífẹ̀ẹ́ sí ohun tí wọ́n ń ṣe náà ń gbógun tì wọ́n. Pẹ̀lú gbogbo akitiyan àwọn ọ̀mọ̀wé yìí, àwọn tó fẹ́ ní ìmọ̀ Bíbélì kò tíì bẹ̀rẹ̀ sí ní ojúlówó òye àwọn nǹkan tẹ̀mí.

Alexander Kejì tó jẹ́ ọba ilẹ̀ Rọ́ṣíà mọyì akitiyan tí Tischendorf ń ṣe, èyí ló mú kó fi owó ràn án lọ́wọ́. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan ń jowú Tischendorf wọ́n sì ń fínná mọ́ ọn, ó kó àwọn ẹ̀dà tó kù lára ìwé Bíbélì Septuagint padà bọ̀ láti ilẹ̀ Sínáì. a Nígbà tó yá, wọ́n wá ń pe àwọn ìwé náà ni Ìwé Bíbélì Àfọwọ́kọ Ti Ilẹ̀ Sínáì (Codex Sinaiticus), ó sì wà lára àwọn ìwé Bíbélì àfọwọ́kọ tó lọ́jọ́ lórí jù lọ tó ṣì wà báyìí. Nígbà tí Tischendorf padà dé ìlú St. Petersburg, ó yára lọ bá ọba Rọ́ṣíà ní Ààfin Ìgbà Òtútù Aláyélúwà. Ó sọ fún ọba náà pé kó ṣonígbọ̀wọ́ “ọ̀kan lára àwọn iṣẹ́ tó kàmàmà jù lọ nínú ṣíṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé àti kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀,” ìyẹn ni títẹ ẹ̀dà ìwé àfọwọ́kọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ rí náà jáde, èyí tí wọ́n wá fi sí Ibi Ìkówèésí Aláyélúwà nígbà tó yá. Tinútinú ni ọba náà fi gbà láti ṣèrànwọ́ fún Tischendorf, inú ọ̀jọ̀gbọ́n náà sì dùn gan-an sí èyí. Ó kọ̀wé lẹ́yìn náà pé: “Ọlọ́run pèsè Ìwé Bíbélì Àfọwọ́kọ Ti Ilẹ̀ Sínáì ní àkókò tiwa kó lè tànmọ́lẹ̀ sí ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ gan-an, rírí tá a sì rí ẹ̀dà ojúlówó yìí jẹ́ ká lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé òtítọ́ lọ̀rọ̀ Bíbélì.”

Àwọn Ìwé Bíbélì Pàtàkì Tí Wọ́n Kó Wá Láti Àgbègbè Crimea

Níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí, a sọ pé ọ̀mọ̀wé kan náà wà tó ń wá àwọn ìwé Bíbélì tí wọ́n fọwọ́ kọ. Ta ni onítọ̀hún? Ní ọdún díẹ̀ kí Tischendorf tó padà sí ilẹ̀ Rọ́ṣíà, wọ́n kó àwọn ìwé Bíbélì àfọwọ́kọ kan ránṣẹ́ sí Ibi Ìkówèésí Aláyélúwà. Àwọn ìwé náà pọ̀ débi pé ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún ọba Rọ́ṣíà nígbà tó rí wọn, gbogbo àgbègbè ilẹ̀ Yúróòpù làwọn ọ̀mọ̀wé sì ti wá síbẹ̀ láti wá wò ó. Ohun tí wọ́n rí jọ wọ́n lójú gidigidi. Àwọn ìwé Bíbélì àfọwọ́kọ àtàwọn nǹkan mìíràn lóríṣiríṣi tí wọ́n rí níbẹ̀ pọ̀ gan-an. Onírúurú ìwé tí iye wọn tó egbèjìlá ó lé méjìlá [2,412] ló wà níbẹ̀, lára wọn sì ni àwọn ìwé Bíbélì àfọwọ́kọ àti àkájọ ìwé tí iye wọn jẹ́ ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún ó lé márùndínlọ́gọ́rin [975]. Àwọn ìwé Bíbélì àfọwọ́kọ márùndínláàádọ́ta tí wọ́n ti ṣe jáde ṣáájú ọ̀rúndún kẹwàá tún wà lára àkójọ náà. Iṣẹ́ kékeré kọ́ ni iṣẹ́ yìí, àmọ́ ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé Abraham Firkovich, ọ̀mọ̀wé kan tó jẹ́ ara àwọn Karaite tó ti lé lẹ́ni àádọ́rin ọdún lásìkò náà ló nìkan ṣàwárí gbogbo ìwé Bíbélì àfọwọ́kọ yìí! Àmọ́, àwọn wo làwọn Karaite? b

Ó wu ọba Rọ́ṣíà láti mọ àwọn Karaite. Ilẹ̀ Rọ́ṣíà ti gba àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn mọ́ ilẹ̀ rẹ̀, èyí sì jẹ́ kí àwọn ẹ̀yà tuntun wà nílẹ̀ Rọ́ṣíà. Àwọn èèyàn kan tí wọ́n jọ ẹ̀yà Júù àmọ́ tí àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wọn jọ tàwọn ará Turkey tí èdè wọn sì jọ èdè Tatar ló ń gbé ní àgbègbè Crimea ẹlẹ́wà tó wà ní etí Òkun Dúdú. Àwọn Karaite wọ̀nyí tọpasẹ̀ ìran wọn lọ sọ́dọ̀ àwọn Júù tí àwọn ará Bábílónì kó nígbèkùn lẹ́yìn tí wọ́n pa Jerúsálẹ́mù run ní ọdún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Ṣùgbọ́n o, àwọn Karaite yàtọ̀ sáwọn olùkọ́ ẹ̀sìn Júù torí pé àwọn ò tẹ̀ lé Talmud rárá, ohun tó jẹ wọ́n lógún jù ni kíka Ìwé Mímọ́. Ó wu àwọn Karaite tó wà lágbègbè Crimea láti fi ẹ̀rí han ọba Rọ́ṣíà pé àwọn yàtọ̀ pátápátá sáwọn olùkọ́ ẹ̀sìn Júù torí pé èyí á jẹ́ kí ọba náà lè máa fojú tó dára wò wọ́n. Wọ́n wò ó pé tí àwọn bá lè fi àwọn ìwé Bíbélì àfọwọ́kọ ìgbàanì táwọn Karaite ti kó jọ han ọba, yóò lè gbà gbọ́ dájú pé ọ̀dọ̀ àwọn Júù tó wá sí àgbègbè Crimea lẹ́yìn táwọn ará Bábílónì kó wọn nígbèkùn làwọn ti ṣẹ̀ wá.

Nígbà tí Firkovich máa bẹ̀rẹ̀ sí wá àwọn ìwé àkọsílẹ̀ àti ìwé Bíbélì àfọwọ́kọ ìgbàanì kiri, ó kọ́kọ́ lọ sí àwọn ilé tí wọ́n kọ́ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè ní àgbègbè Chufut-Kale. Nígbà kan rí, inú àwọn ilé kó-kò-kó tí wọ́n fi òkúta tí wọ́n gbẹ́ látinú àpáta kọ́ yìí ni ìrandíran àwọn Karaite ń gbé, ibẹ̀ ni wọ́n sì ti ń ṣe ìjọsìn wọn. Àwọn Karaite ò ba àwọn ẹ̀dà ìwé tó ti gbó tí orúkọ Jèhófà wà nínú wọn jẹ́, torí pé wọ́n ka ìyẹn sí títàbùkù sí ohun mímọ́. Ńṣe ni wọ́n rọra tọ́jú àwọn ìwé Bíbélì tí wọ́n fọwọ́ kọ sórí awọ náà sínú ilé ìkẹ́rùsí kékeré kan tí wọ́n ń pè ní genizah, èyí tó túmọ̀ sí “ibi ìpamọ́” lédè Hébérù. Àwọn Karaite kì í sábà fọwọ́ kan àwọn ìwé awọ yìí torí pé wọ́n bọ̀wọ̀ fún orúkọ Ọlọ́run gidigidi.

Firkovich fi ẹ̀sọ̀ pẹ̀lẹ́ wá inú àwọn ibi tí wọ́n ń kó ẹrù sí náà bó tilẹ̀ jẹ́ pé eruku àìmọye ọdún ti bo gbogbo ibẹ̀. Níbì kan ó rí ìwé Bíbélì àfọwọ́kọ kan tó wá di ohun táwọn èèyàn mọ̀ bí ẹni mọwó kan tí wọ́n ṣe ní ọdún 916 Sànmánì Kristẹni. Orúkọ tí wọ́n pè é ni Ìwé Bíbélì Àfọwọ́kọ Tí Ìlú Petersburg Tí Àwọn Wòlíì Tó Bẹ̀rẹ̀ Láti Aísáyà dé Málákì, ó sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tó lọ́jọ́ lórí jù lọ tó ṣì wà báyìí.

Firkovich gbìyànjú láti kó ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ìwé Bíbélì àfọwọ́kọ jọ, nígbà tó sì di ọdún 1859 ó pinnu láti kó àwọn tó ṣàwárí lọ sí Ibi Ìkówèésí Aláyélúwà. Lọ́dún 1862, owó gegere ni Alexander Kejì fi ra àwọn àkájọ ìwé tí wọ́n kó sí ibi ìkówèésí náà. Iye tó san nígbà yẹn jẹ́ ẹgbẹ̀rún lọ́nà márùnlélọ́gọ́fà [125,000] rúbù (owó ilẹ̀ Rọ́ṣíà). Nígbà yẹn sì rèé, gbogbo owó tí wọ́n ń ná sórí ibi ìkówèésí náà lọ́dún kò ju ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá owó rúbù lọ! Lára àwọn ìwé Bíbélì àfọwọ́kọ tó wà níbẹ̀ ni ọ̀kan tó gbayì gan-an tí wọ́n ń pè ní Ìwé Bíbélì Àfọwọ́kọ Tí Ìlú Leningrad [Leningrad Codex (B 19A)]. Ọdún 1008 ni wọ́n ṣe é, òun sì ni odindi ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tí ọjọ́ rẹ̀ pẹ́ jù lọ lágbàáyé. Nígbà tí ọ̀mọ̀wé kan ń sọ̀rọ̀ lórí ìwé yìí, ó ní “àfàìmọ̀ kó máà jẹ́ pé òun ni ìwé Bíbélì àfọwọ́kọ tó ṣe pàtàkì jù lọ, torí pé ó fìdí ohun tó wà nínú ọ̀pọ̀ lára àwọn ẹ̀dá Bíbélì òde òní tó wà lédè Hébérù tí wọ́n fara balẹ̀ ṣe múlẹ̀.” (Wo àpótí tó wà lójú ìwé yìí.) Lọ́dún 1862 yẹn kan náà ni wọ́n tẹ Ìwé Bíbélì Àfọwọ́kọ Ti Ilẹ̀ Sínáì tí Tischendorf ṣàwárí jáde, àwọn èèyàn sì gba tiẹ̀ jákèjádò ayé.

Ìlàlóye Tẹ̀mí Lóde Òní

Ibi ìkówèésí tí wọ́n ń pè ní Ibi Ìkówèésí Ìjọba Rọ́ṣíà nísinsìnyí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ibi tí àwọn ìwé Bíbélì àfọwọ́kọ ìgbàanì pọ̀ sí jù lọ lágbàáyé. c Ẹ̀ẹ̀méje ni wọ́n ti yí orúkọ ibi ìkówèésí náà padà láàárín igba ọdún, gbogbo orúkọ tí wọ́n ń pè é ló sì máa ń gbé ìtàn ilẹ̀ Rọ́ṣíà yọ. Orúkọ kan tó gbajúmọ̀ tí wọ́n ti fi pè é rí ni Ibi Ìkówèésí Saltykov-Shchedrin (The State Saltykov-Shchedrin Public Library). Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn rògbòdìyàn ọ̀rúndún ogún ṣàkóbá fún ibi ìkówèésí náà, kò sóhun tó ṣe àwọn ìwé Bíbélì àfọwọ́kọ ibẹ̀ nígbà tí wọ́n já ogun àgbáyé méjèèjì àti nígbà táwọn ọ̀tá kógun ti ìlú Leningrad. Báwo la wá ṣe lè jàǹfààní látinú àwọn ìwé Bíbélì àfọwọ́kọ wọ̀nyẹn?

Àwọn ìwé Bíbélì àfọwọ́kọ ìgbàanì ni wọ́n gbé ọ̀pọ̀ àwọn ìtumọ̀ Bíbélì òde òní tó ṣeé gbára lé kà. Wọ́n ń jẹ́ káwọn tó dìídì fẹ́ mọ òtítọ́ rí ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́ tó péye kà. Lílò tí àwọn olùtumọ̀ lo àwọn Ìwé Bíbélì Àfọwọ́kọ Ti Ilẹ̀ Sínáì àti Ìwé Bíbélì Àfọwọ́kọ Tí Ìlú Leningrad mú kí iṣẹ́ ìtumọ̀ Bíbélì Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun dára gan-an. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe Bíbélì yìí, ọdún 1961 la sì tẹ̀ ẹ́ jáde lódindi lédè Gẹ̀ẹ́sì. Bí àpẹẹrẹ, inú Ìwé Bíbélì Àfọwọ́kọ Tí Ìlú Leningrad ni wọ́n ti túmọ̀ Bíbélì Biblia Hebraica Stuttgartensia àti Bíbélì Biblia Hebraica tí Kittel ṣe, Bíbélì méjèèjì sì làwọn Ìgbìmọ̀ Tó Túmọ̀ Bíbélì Ayé Tuntun lò. Àwọn Bíbélì wọ̀nyí lo lẹ́tà mẹ́rin tó dúró fórúkọ Ọlọ́run nígbà ẹgbẹ̀rún mẹ́fà, ẹgbẹ̀rin ó lé méjìdínlọ́gbọ̀n [6,828] gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Bíbélì ti ìpilẹ̀ṣẹ̀.

Ìwọ̀nba díẹ̀ lára àwọn tó ń ka Bíbélì lónìí ló mọyì ibi ìkówèésí tó wà nílùú St. Petersburg àtàwọn ìwé Bíbélì àfọwọ́kọ inú rẹ̀. Àwọn ìwé Bíbélì àfọwọ́kọ kan tiẹ̀ wà tó jẹ́ pé orúkọ ìlú náà tẹ́lẹ̀, ìyẹn Leningrad, ni wọ́n fi ń pè wọ́n. Síbẹ̀, Jèhófà tó ni Bíbélì ló yẹ ká fún ní ọpẹ́ tó ga jù lọ torí pé ó ń fún wa ní ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí. Abájọ tí onísáàmù náà fi fi ìtara ọkàn gbàdúrà pé: “Rán ìmọ́lẹ̀ rẹ àti òtítọ́ rẹ jáde. Kí ìwọ̀nyí máa ṣamọ̀nà mi.”—Sáàmù 43:3.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ó tún kó gbogbo ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì tí wọ́n ṣe ní ọ̀rúndún kẹrin Sànmánì Kristẹni wá.

b Bó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa àwọn Karaite, wo àpilẹ̀kọ náà “Àwọn Karaite àti Bí Wọ́n Ṣe Wá Òtítọ́ Kiri,” nínú Ilé-Ìṣọ́nà July 15, 1995.

c Ọ̀pọ̀ lára àwọn àkájọ ìwé tí wọ́n para pọ̀ jẹ́ Ìwé Bíbélì Àfọwọ́kọ Ti Ilẹ̀ Sínáì làwọn ará Rọ́ṣíà tà sí Ibi Ìkóhun-Ìṣẹ̀ǹbáyé-Sí Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Kìkì àwọn àjákù nìkan ló wà ní Ibi Ìkówèésí Ìjọba Rọ́ṣíà.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 13]

ÀWỌN ÈÈYÀN MỌ ORÚKỌ ỌLỌ́RUN WỌ́N SÌ Ń LÒ Ó

Jèhófà lo ọgbọ́n rẹ̀ láti rí i dájú pé Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ wà títí di òní olónìí. Iṣẹ́ àṣekára táwọn tó da Bíbélì kọ ti ń ṣe láti àìmọye ọdún sẹ́yìn wà lára ohun tó jẹ́ ká lè rí Bíbélì lónìí. Àwọn tó fara balẹ̀ ṣiṣẹ́ jù làwọn Masorete, ìyẹn àwọn akọ̀wé Hébérù amọṣẹ́dunjú tí wọ́n ṣiṣẹ́ láti ọ̀rúndún kẹfà títí dé ọ̀rúndún ìkẹwàá Sànmánì Kristẹni. Èdè Hébérù ayé àtijọ́ tí wọ́n ń kọ sílẹ̀ kì í ní fáwẹ́ẹ̀lì nínú. Bí ọdún ti ń gorí ọdún, àìsí fáwẹ́ẹ̀lì láàárín èdè Hébérù yìí mú kó túbọ̀ rọrùn láti gbàgbé bí wọ́n ṣe ń pe ọ̀rọ̀ nígbà tí èdè Árámáíkì rọ́pò Hébérù. Àwọn Masorete ló wá dá ọgbọ́n kan kí èyí má bàa ṣẹlẹ̀. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí fi àmì sí ibi tí fáwẹ́ẹ̀lì máa wà láàárín ọ̀rọ̀ inú Bíbélì káwọn òǹkàwé lè mọ ọ̀nà tó tọ́ láti gbà pe àwọn ọ̀rọ̀ Hébérù.

Ó dára gan-an pé àwọn àmì táwọn Masorete fi síbi tí fáwẹ́ẹ̀lì máa wà láàárín ọ̀rọ̀ inú Ìwé Bíbélì Àfọwọ́kọ Ti Ìlú Leningrad jẹ́ káwọn èèyàn mọ bí wọ́n ṣe lè pe lẹ́tà mẹ́rin tó dúró fórúkọ Ọlọ́run. Báwọn èèyàn ṣe ń pè é ni Yehwah’, Yehwih’, àti Yeho·wah’. “Jèhófà” ni ọ̀nà tí ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn gbà ń pe orúkọ yìí báyìí. Àwọn tó kọ Bíbélì àtàwọn ẹlòmíràn láyé àtijọ́ mọ orúkọ Ọlọ́run dáadáa. Lónìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn ló mọ orúkọ Ọlọ́run tí wọ́n sì ń lò ó torí wọ́n mọ̀ pé ‘Jèhófà nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.’—Sáàmù 83:18.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Yàrá ìwé Bíbélì àfọwọ́kọ ní Ibi Ìkówèésí Ìjọba Rọ́ṣíà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Ọbabìnrin Catherine Kejì

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Konstantin von Tischendorf (àárín) àti Alexander Kejì, ọba ilẹ̀ Rọ́ṣíà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Abraham Firkovich

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 10]

Àwọn àwòrán méjèèjì: Ibi Ìkówèésí Ìjọba Rọ́ṣíà nílùú St. Petersburg

[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 11]

Catherine Kejì: Ibi Ìkówèésí Ìjọba Rọ́ṣíà nílùú St. Petersburg; Alexander Kejì: Látinú ìwé Spamers Illustrierte Weltgeschichte, Leipzig, 1898