Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ibo Lo Ti Lè Rí Ẹ̀kọ́ Òtítọ́?

Ibo Lo Ti Lè Rí Ẹ̀kọ́ Òtítọ́?

Ibo Lo Ti Lè Rí Ẹ̀kọ́ Òtítọ́?

NÍ ILẸ̀ Tibet, ọkùnrin kan ń fọwọ́ yí agolo kan tí wọ́n ki igi bọ̀ láàárín. Onírúurú àdúrà tí wọ́n kọ síwèé kéékèèké ló wà nínú agolo náà. Ọkùnrin náà gbà gbọ́ pé gbogbo àdúrà inú agolo náà lòun ń gbà níye ìgbà tóun bá yí i. Ní orílẹ̀-èdè Íńdíà, wọ́n ya yàrá kan sọ́tọ̀ nínú ilé ńlá kan fún ààtò àdúrà tí wọ́n ń pè ní puja nínú ẹ̀sìn Híńdù. Nígbà ààtò náà, wọ́n máa ń fi tùràrí, òdòdó àtàwọn nǹkan mìíràn bẹ́ẹ̀ rúbọ sí onírúurú òòṣà akọ àti abo. Ní ilẹ̀ Ítálì tó wà ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún kìlómítà sí ilẹ̀ Íńdíà, obìnrin kan kúnlẹ̀ síwájú ère Màríà ìyá Jésù tó wà nínú ṣọ́ọ̀ṣì aláràbarà kan, ó mú ìlẹ̀kẹ̀ àdúrà dání, ó ń gbàdúrà.

Ẹ̀sìn ń kó ipa pàtàkì gan-an nígbèésí ayé àwọn èèyàn, bí ìwọ alára ṣe lè mọ̀. Ìwé Àwọn Ẹ̀sìn Ayé—Bí A Ṣe Lè Mọ Àwọn Ẹ̀sìn Tòótọ́ (Gẹ̀ẹ́sì) sọ pé: “Àtayébáyé ni ẹ̀sìn ti ń kó ipa pàtàkì láwùjọ kárí ayé.” Nínú ìwé Ọlọ́run—Ìtàn Ṣókí Nípa Rẹ̀ (Gẹ̀ẹ́sì) tí John Bowker kọ, ó sọ pé: “Kò sí àwùjọ ẹ̀dá kankan tí ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run kò ti kó ipa kan tàbí òmíràn. Wọ́n sábà máa ń kà á sí alákòóso àgbáyé àti Ẹlẹ́dàá. Kódà ọ̀rọ̀ kò yàtọ̀ láwọn ilẹ̀ tó jẹ́ pé àwọn èèyàn ò ka ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn sí rárá.”

Ipa kékeré kọ́ ni ẹ̀sìn ń kó nínú ìgbésí ayé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn nínú ayé. Ǹjẹ́ èyí ò fi hàn gbangba pé ẹ̀sìn ṣe pàtàkì fọ́mọ èèyàn, pé kálukú ló ń wọ́nà láti ṣe é lọ́nà kan tàbí òmíràn? Dókítà Carl G. Jung tó jẹ́ gbajúgbajà afìṣemọ̀rònú ẹ̀dá sọ nínú ìwé rẹ̀ Ohun Téèyàn Ò Mọ̀ Nípa Ara Rẹ̀ (Gẹ̀ẹ́sì) pé ó ṣe pàtàkì kéèyàn máa sin agbára gíga jù kan, àti pé “láti ọjọ́ táláyé ti dáyé lọmọ aráyé ti rí i pé ó ṣe pàtàkì káwọn jọ́sìn agbára gíga jù náà.”

Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn ò gbà pé Ọlọ́run wà, wọn ò sì nífẹ̀ẹ́ sọ́rọ̀ ẹ̀sìn rárá. Ohun tó sì ń fà á táwọn kan fi ń ṣiyèméjì pé bóyá ni Ọlọ́run wà, tó sì tún mú káwọn mìíràn máa sọ pé kò sí Ọlọ́run ni pé ẹ̀sìn tí wọ́n mọ̀ kò pèsè ohun tí wọ́n nílò nípa tẹ̀mí. Ìwé atúmọ̀ èdè kan túmọ̀ ẹ̀sìn sí “fífi gbogbo ọkàn tẹ̀ lé ìlànà kan; fífi inú funfun tàbí ìṣòtítọ́ ṣe nǹkan kan déédéé; kéèyàn máa ṣe nǹkan kan lójú méjèèjì; kéèyàn fẹ́ràn nǹkan kan débi pé kò lè ṣàìṣe é tàbí kí nǹkan kan gbà èèyàn lọ́kàn pátápátá.” Tá a bá sì wá tibi ìtumọ̀ yìí wò ó, a jẹ́ pé kò sẹ́ni tí kì í ṣe ẹ̀sìn lọ́nà kan tàbí òmíràn láyé yìí nìyẹn, títí kan àwọn tí kò gbà pé Ọlọ́run wà pàápàá.

Látayébáyé ni nǹkan tẹ̀mí ti ń jẹ ọmọ aráyé lọ́kàn. Ìdí nìyí tí wọ́n fi ń dáwọ́ lé onírúurú ìsìn. Bí oríṣiríṣi ẹ̀kọ́ ìsìn tó yàtọ̀ síra ṣe kún ayé nìyẹn. Bí àpẹẹrẹ, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ẹ̀sìn ló gbà pé agbára kan wà tó ga ju ohun gbogbo lọ, àmọ́ wọn ò fohùn ṣọ̀kan nípa ohun tí agbára náà jẹ́ tàbí ẹni tí í ṣe. Ọ̀pọ̀ jù lọ ẹ̀sìn ayé ló ń kọ́ni pé ìgbàlà tàbí ìsọni-dòmìnira ṣe pàtàkì. Ṣùgbọ́n ẹ̀kọ́ wọn nípa ìgbàlà yìí àti béèyàn ṣe lè rí i yàtọ̀ síra. Bí onírúurú ẹ̀kọ́ ìsìn ṣe wá pọ̀ lọ jàra yìí, báwo lèèyàn ṣe máa dá àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tínú Ọlọ́run dùn sí mọ̀ yàtọ̀?