Wọn Ò Lọ́kọ Wọn Ò Láya àmọ́ Ọkàn Wọn Balẹ̀ Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà
“Ọ̀dọ̀ Jèhófà Ni Ìrànlọ́wọ́ Mi Ti Wá”
Wọn Ò Lọ́kọ Wọn Ò Láya àmọ́ Ọkàn Wọn Balẹ̀ Lẹ́nu Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà
OBÌNRIN kan tó jẹ́ Kristẹni nílẹ̀ Sípéènì sọ pé: “Ayọ̀ ọ̀pọ̀ nínú wa kún rẹ́rẹ́ bá ò tiẹ̀ lọ́kọ.” Kí ló fún wọn láyọ̀ tó sì fọkàn wọn balẹ̀? Ó ní: “Ohun tó ń múnú wa dùn ni pé a bọ́ lọ́wọ́ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àníyàn, èyí sì jẹ́ ká lè túbọ̀ ráyè máa sin Jèhófà Ọlọ́run wa.”
Ọ̀rọ̀ obìnrin yìí bá ohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ nípa àwọn tí ò lọ́kọ àtàwọn tí ò láya mu. Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tọkọtaya, ó sọ ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí yìí pé: “Èmi sọ fún àwọn ènìyàn tí kò gbéyàwó àti àwọn opó pé, ó dára kí wọ́n wà, àní bí èmi ti wà.” Pọ́ọ̀lù fúnra rẹ̀ kò láya. Kí wá nìdí tó fi sọ pé á dára kéèyàn má ṣe lọ́kọ tàbí kó má ṣe láya? Ó ní àwọn tọkọtaya máa ń ní ìpínyà ọkàn, nígbà tí ẹni tí kò lọ́kọ tàbí ẹni tí kò láya máa “ń ṣàníyàn fún àwọn ohun ti Olúwa.” (1 Kọ́ríńtì 7:8, 32-34) Sísin Jèhófà ni pàtàkì ohun tó máa ń mú kí ẹni tí kò lọ́kọ tàbí ẹni tí kò láya ní ayọ̀ àti ìbàlẹ̀ ọkàn.
Àwọn Tí Ò Lọ́kọ Tàbí Tí Ò Láya Nítorí Ìdí Pàtàkì Kan
Ó ṣeé ṣe kí ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí jẹ́ nǹkan kàyéfì lójú àwọn ẹ̀yà tí kì í fọ̀rọ̀ ìgbéyàwó àti ọmọ bíbí ṣeré. Jésù Kristi tó jẹ́ àpọ́n àmọ́ tó láyọ̀ tọ́kàn rẹ̀ sì balẹ̀ sọ nǹkan àtàtà kan táwọn Kristẹni tí kò lọ́kọ tàbí tí kò láya lè máa ṣe. Ó ní: “Àwọn ìwẹ̀fà . . . wà tí wọ́n ti sọ ara wọn di ìwẹ̀fà ní tìtorí ìjọba ọ̀run. Kí ẹni tí ó bá lè wá àyè fún un wá àyè fún un.”—Mátíù 19:12.
Bó ṣe wí lóòótọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti rí i pé báwọn ò ṣe lọ́kọ tàbí báwọn ò ṣe láya jẹ́ ká wọn lè máa sin Ọlọ́run lọ láìsí ìpínyà ọkàn tó wọ́pọ̀ fáwọn tọkọtaya. (1 Kọ́ríńtì 7:35) Ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Kristẹni tí ò lọ́kọ àtàwọn tí ò láya ló ń sin Jèhófà tayọ̀tayọ̀, wọ́n sì ń rí ìdùnnú nínú ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́. a
Púpọ̀ nínú àwọn Kristẹni tí kò lọ́kọ tàbí tí kò láya mọ̀ pé kì í ṣe àwọn tọkọtaya nìkan ló ń láyọ̀, bó ṣe jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo àwọn tí kò lọ́kọ tàbí tí kò láya ni ìbànújẹ́ máa ń dorí wọn kodò. Àtàwọn tó ṣègbéyàwó o, àtàwọn tí kò ṣe o, kò sẹ́ni tí kì í ní àsìkò ayọ̀ àti àsìkò ìbànújẹ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Bá a sì ṣe ń rí àwọn tọkọtaya tí nǹkan ìbànújẹ́ dé bá náà là ń rí àwọn tí irú ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí lára àwọn tí kò lọ́kọ tàbí tí kò láya. Ohun tí Bíbélì tiẹ̀ sọ, tó sì ń ṣẹlẹ̀ lóòótọ́ ni pé ìgbéyàwó máa ń fa “ìpọ́njú nínú ẹran ara” tọkọtaya.—1 Kọ́ríńtì 7:28.
Kì Í Kúkú Ṣe Pé Wọn Ò Fẹ́ Ṣègbéyàwó
Ọ̀pọ̀ àwọn tí ò lọ́kọ tàbí láya kò fẹ́ wà bẹ́ẹ̀ o, nǹkan kan ló dá wọn dúró. Ó lè máa wù wọ́n káwọn náà lẹ́nì kejì tó máa jẹ́ olólùfẹ́ wọn tí yóò máa kẹ́ wọn, tí yóò máa gẹ̀ wọ́n. Àmọ́ àìlówólọ́wọ́ tàbí àwọn ìdíwọ́ mìíràn lè máà jẹ́ káwọn kan tíì lè lọ́kọ tàbí fẹ́yàwó. Àwọn Kristẹni kan kò tíì lọ́kọ tàbí láya nítorí pé wọ́n ti pinnu láti tẹ̀ lé ìtọ́ni Bíbélì tó sọ pé tí wọ́n bá máa ṣègbéyàwó, ó gbọ́dọ̀ jẹ́ “kìkì nínú Olúwa,” ọ̀pọ̀ nínú wọn ló sì jẹ́ àwọn arábìnrin wa ọ̀wọ́n. (1 Kọ́ríńtì 7:39) Kìkì àárín àwọn olùjọsìn Jèhófà tó ti ya ara wọn sí mímọ́ tí wọ́n sì ti ṣe ìrìbọmi ni wọ́n ti ń wá ọkọ tàbí aya.
Nígbà míì, ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn máa ń bá àwọn kan lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan nítorí àìní alábàárò tiwọn. Arábìnrin kan gbà pé ó máa ń ṣe òun bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n ó ní: “Àwa tí ò tíì ṣègbéyàwó mọ òfin Jèhófà, a ò sì fẹ́ ṣe ohunkóhun tínú rẹ̀ kò dùn sí. Lóòótọ́, ó wù wá ká ní olólùfẹ́ tiwa o, àmọ́ bó ti wù káwọn èèyàn ayé ‘máa wá èèyàn wá fún wa lemọ́lemọ́ tó,’ a ò ní fara mọ́ ọn. Kódà, a kì í bá ọkùnrin tàbí obìnrin ayé kankan ṣe wọléwọ̀de rárá.” Ó yẹ ká yin irú àwọn Kristẹni bẹ́ẹ̀ fún bí wọ́n ṣe ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì tí wọ́n sì ń para wọn mọ́ pátápátá láti lè múnú Jèhófà dùn, bó ti wù kó nira fún wọn tó.
Jèhófà Ń Ṣèrànlọ́wọ́ Gan-an
Jèhófà máa ń dúró ti gbogbo àwọn tó bá fi ìdúróṣinṣin tẹ̀ lé ìtọ́ni rẹ̀ tí wọn ò lọ fẹ́ ẹni tí kì í ṣe ìránṣẹ́ rẹ̀. Dáfídì Ọba sọ látinú ìrírí tòun fúnra rẹ̀ pé: “Ìwọ [Jèhófà] yóò hùwà lọ́nà ìdúróṣinṣin sí ẹni ìdúróṣinṣin.” (Sáàmù 18:25) Ọlọ́run sì ṣèlérí fún àwọn tó bá ń pa òfin rẹ̀ mọ́ pé: “Dájúdájú, èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà.” (Hébérù 13:5) Ó yẹ káwa náà lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà, ká máa yin àwọn Kristẹni tí ò tíì lọ́kọ tàbí láya, àti kékeré àtàgbà wọn, tí wọn ò jẹ́ ṣe ohun tó lòdì sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. A sì tún lè máa gbàdúrà pé kí Jèhófà fún wọn lókun tí wọ́n á fi lè borí ìṣòro wọn.—Àwọn Onídàájọ́ 11:30-40.
Ọ̀pọ̀ àwọn Kristẹni tí ò lọ́kọ tàbí tí ò láya ló ti rí i pé táwọn bá ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lójú méjèèjì, àwọn ń fìgbésí ayé àwọn ṣe nǹkan àtàtà nìyẹn. Àpẹẹrẹ kan ni Patricia, Kristẹni kan tí ò lọ́kọ, tọ́jọ́ orí rẹ̀ jẹ́ nǹkan bí ọdún márùnlélọ́gbọ̀n tó ń ṣe aṣáájú ọ̀nà, ìyẹn ẹni tó ń fi ọ̀pọ̀ àkókò wàásù. Ó ní: “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé onírúurú àdánwò lẹni tí ò lọ́kọ tàbí ẹni tí ò láya máa ń ní, síbẹ̀ ipò mi yìí ti fún mi láǹfààní láti ṣe aṣáájú ọ̀nà déédéé ní tèmi. Níwọ̀n bí mo ti wà ní dáńfó, mo lè lo àkókò mi bó ṣe wù mí, ìyẹn sì jẹ́ kí n túbọ̀ ráyè máa dá kẹ́kọ̀ọ́. Ó sì jẹ́ kí n túbọ̀ gbára lé Jèhófà, pàápàá nígbà ìṣòro.”
Ìlérí kan tó wà nínú Bíbélì ló mú kó lè sọ irú ohun tó sọ yìí. Ìlérí náà ni pé: “Yí ọ̀nà rẹ lọ sọ́dọ̀ Jèhófà, kí o sì gbójú lé e, òun yóò sì gbé ìgbésẹ̀.” (Sáàmù 37:5) Dájúdájú, à báà jẹ́ tọkọtaya tàbí ẹni tí kò lọ́kọ tàbí láya, gbogbo àwa tó ń sin Jèhófà tọkàntọkàn ni ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí yìí lè tù nínú kó sì fún lókun, ó sọ pé: “Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìrànlọ́wọ́ mi ti wá.”—Sáàmù 121:2.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo oṣù July àti August nínú kàlẹ́ńdà àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ọdún 2005.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 9]
“Ọkùnrin tí kò gbéyàwó ń ṣàníyàn fún àwọn ohun ti Olúwa, bí òun ṣe lè jèrè ìtẹ́wọ́gbà Olúwa.”—1 KỌ́RÍŃTÌ 7:32
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 8]
BÍ ẸNI TÍ Ò ṢÈGBÉYÀWÓ ṢE LÈ LO ÌGBÉSÍ AYÉ RẸ̀ LỌ́NÀ TÓ ṢÀǸFÀÀNÍ
Jésù tí ò gbéyàwó rárá sọ pé: “Oúnjẹ mi ni kí n ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi àti láti parí iṣẹ́ rẹ̀.”—Jòhánù 4:34.
Àwọn ọmọbìnrin Fílípì mẹ́rin tí wọn kò lọ́kọ fi ìtara ṣe iṣẹ́ ‘ìsọtẹ́lẹ̀.’—Ìṣe 21:8, 9.
Àwọn arábìnrin tí ò lọ́kọ tí wọ́n ń kéde ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ara ‘ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn obìnrin ńlá tí ń sọ ìhìn rere.’—Sáàmù 68:11.