Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Látiwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ayé ọjọ́un, kí ni ìmọ́lẹ̀ àgbàyanu tí wọ́n sábà máa ń pè ní Ṣèkínà tó máa ń wà ní Ibi Mímọ́ Jù Lọ nínú àgọ́ ìjọsìn àti nínú tẹ́ńpìlì dúró fún?

Jèhófà jẹ́ baba onífẹ̀ẹ́ tí ń dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀. Ó jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí ẹ̀rí tó hàn gbangba pé òun wà láàárín wọn. Ọ̀kan lára àwọn ẹ̀rí náà ni àwọsánmà tó mọ́lẹ̀ yòò tó máa ń wà níbi ìjọsìn rẹ̀.

Ìmọ́lẹ̀ tó mọ́lẹ̀ yòò náà fi hàn pé Jèhófà wà pẹ̀lú wọn bí wọn ò tilẹ̀ lè rí i. Inú Ibi Mímọ́ Jù Lọ ni ìmọ́lẹ̀ náà máa ń wà nínú àgọ́ ìjọsìn àti nínú tẹ́ńpìlì tí Sólómọ́nì kọ́ lẹ́yìn náà. Ìmọ́lẹ̀ àgbàyanu yẹn kò túmọ̀ sí pé Jèhófà wà níbẹ̀ ní ti gidi. Kò sí ilé èyíkéyìí táwa ẹ̀dá èèyàn kọ́ tó lè gba Ọlọ́run. (2 Kíróníkà 6:18; Ìṣe 17:24) Ìmọ́lẹ̀ tí Ọlọ́run mú kó tàn nínú ibi ìjọsìn rẹ̀ yìí yóò mú kó dá àlùfáà àgbà lójú pé Jèhófà wà pẹ̀lú orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Àlùfáà náà yóò wá mú kó dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lójú pé Jèhófà wà pẹ̀lú wọn láti dáàbò bò wọ́n àti láti pèsè ohun tí wọ́n fẹ́ fún wọn.

Lẹ́yìn àkókò tí wọ́n kọ Bíbélì, ohun tí wọ́n ń pe ìmọ́lẹ̀ yìí lédè Árámáíkì ni Ṣèkínà, ọ̀rọ̀ yìí sì túmọ̀ sí “èyí tó ń gbé” tàbí “ibi gbígbé.” Kò sí ọ̀rọ̀ yìí nínú Bíbélì rárá àmọ́ ó wà nínú àwọn Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tí wọ́n tú sí èdè Árámáíkì, èyí tí wọ́n tún ń pè ní Targum.

Nígbà tí Jèhófà ń fún Mósè ní ìtọ́ni nípa bó ṣe máa kọ́ àgọ́ ìjọsìn, ó sọ fún un pé: “Kí o . . . gbé ìbòrí náà lé Àpótí náà, inú Àpótí náà ni ìwọ yóò sì fi gbólóhùn ẹ̀rí tí èmi yóò fún ọ sí. Èmi yóò sì pàdé rẹ níbẹ̀, èmi yóò sì bá ọ sọ̀rọ̀ láti orí ìbòrí náà, láti àárín àwọn kérúbù méjì tí ó wà lórí àpótí . . . náà.” (Ẹ́kísódù 25:21, 22) Àpótí tí ẹsẹ Bíbélì yìí ń sọ jẹ́ àpótí kan tí wọ́n fi wúrà ṣe tó wà ní Ibi Mímọ́ Jù Lọ. Àwọn kérúbù méjì tí a fi wúrà ṣe wà lórí ohun tí wọ́n fi bo Àpótí Májẹ̀mú náà.

Ibo ni Jèhófà ti máa sọ̀rọ̀? A lè rí ìdáhùn nínú ohun tó sọ fún Mósè, ó ní: “Nínú àwọsánmà ni èmi yóò fara hàn lórí ìbòrí náà.” (Léfítíkù 16:2) Àwọsánmà yìí máa ń wà lórí Àpótí mímọ́ láàárín àwọn kérúbù méjì tí wọ́n fi wúrà ṣe náà. Bíbélì ò sọ bí àwọsánmà náà ṣe ga tó tàbí bó ṣe jìnnà sí orí àwọn kérúbù náà tó.

Àwọsánmà tó ń tàn yòò náà ló máa ń jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ wà nínú Ibi Mímọ́ Jù Lọ. Kódà, òun nìkan ni ìmọ́lẹ̀ tó ń tàn síbẹ̀. Ìmọ́lẹ̀ náà ni àlùfáà àgbà fi ń ríran tó bá wọ yàrá inú lọ́hùn-ún nínú àgọ́ náà ní Ọjọ́ Ètùtù. Èyí fi hàn pé iwájú Jèhófà ló dúró sí.

Ǹjẹ́ ìmọ́lẹ̀ àgbàyanu yìí ṣe pàtàkì lọ́nà èyíkéyìí fún àwọn Kristẹni? Nínú ìran kan tí àpọ́sítélì Jòhánù rí, ó rí ìlú kan níbi tí “òru kì yóò sí.” Jerúsálẹ́mù Tuntun ni ìlú náà, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí Ọlọ́run jí dìde kí wọ́n lè bá Jésù jọba ni wọ́n sì para pọ̀ jẹ́ Jerúsálẹ́mù Tuntun yìí. Kì í ṣe oòrùn tàbí òṣùpá ló ń tànmọ́lẹ̀ sí ìlú ìṣàpẹẹrẹ yìí. Ògo Jèhófà Ọlọ́run ló ń tàn sórí rẹ̀ ní tààràtà, gẹ́gẹ́ bí àwọsánmà Ṣèkínà ṣe ń tànmọ́lẹ̀ sí Ibi Mímọ́ Jù Lọ. Ìyẹn nìkan kọ́ o, Jésù Kristi, Ọ̀dọ́ Àgùntàn ni “ìmọ́lẹ̀” ìlú náà. Ìlú ìṣàpẹẹrẹ yìí sì wá ń tan ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí sórí àwọn èèyàn tá a ti rà padà látinú gbogbo orílẹ̀-èdè láti fi tọ́ wọn sọ́nà, ó sì ń ṣojú rere sí wọn.—Ìṣípayá 21:22-25.

Ó yẹ kí ọ̀pọ̀ yanturu ìbùkún táwọn tó ń jọ́sìn Jèhófà ń rí gbà yìí fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀ pé Jèhófà ni Olùṣọ́ Àgùntàn tó ń dáàbò bò wọ́n àti pé òun ni Baba wọn onífẹ̀ẹ́.