Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“A Ti Gbé Ikú Mì Títí Láé”

“A Ti Gbé Ikú Mì Títí Láé”

“A Ti Gbé Ikú Mì Títí Láé”

FOJÚ inú wò ó pé àkọlé tó wà lókè yìí lo rí kà níwájú ìwé ìròyìn kan dípò àkọlé nípa ọmọdébìnrin tó para ẹ̀. Lóòótọ́, kò sí ìwé ìròyìn kankan tó tíì gbé irú ìròyìn bẹ́ẹ̀ jáde rí. Àmọ́, àkọlé tó wà lókè yìí wà nínú ìwé kan tó ti wà láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn. Bíbélì ni orúkọ ìwé náà.

Ìwé Mímọ́ ṣàlàyé ohun tí ikú jẹ́ ní kedere. Yàtọ̀ síyẹn, kì í ṣe pé Bíbélì sọ ohun tó fà á téèyàn fi ń kú nìkan ni, ó tún ṣàlàyé ipò táwọn òkú wà, ó sì fi hàn pé ìrètí wà fáwọn èèyàn wa tó ti kú. Ní paríparí rẹ̀, Bíbélì sọ nípa ìgbà kan tí a óò lè sọ pé: “A ti gbé ikú mì títí láé.”—1 Kọ́ríńtì 15:54.

Àlàyé tí Bíbélì ṣe nípa ohun tí ikú jẹ́ kò díjú rárá, ó ṣe é lọ́nà tó yéni kedere. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ ibi ni Bíbélì ti fi ikú wé ìgbà téèyàn bá “sùn,” ó tún sọ pé ńṣe làwọn tó ti kú “ń sùn nínú ikú.” (Sáàmù 13:3; 1 Tẹsalóníkà 4:13; Jòhánù 11:11-14) Bíbélì tún pe ikú ní “ọ̀tá.” (1 Kọ́ríńtì 15:26) Èyí tó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé Bíbélì jẹ́ ká lóye ohun tó mú kí ikú dà bí oorun, ìdí téèyàn fi ń kú àti bí ọ̀tá yìí yóò ṣe di ohun tí kò sí mọ́.

Kí Ló Fà Á Téèyàn Fi Ń Kú?

Ìwé àkọ́kọ́ nínú Bíbélì sọ ìtàn bí Ọlọ́run ṣe dá Ádámù, ọkùnrin àkọ́kọ́, tó sì fi í sínú Párádísè kan. (Jẹ́nẹ́sísì 2:7, 15) Lẹ́yìn tí Ọlọ́run dá Ádámù, ó fún un níṣẹ́ kan láti ṣe, ó sì tún ṣòfin kan fún un tó gbọ́dọ̀ pa mọ́. Ọlọ́run sọ fún un nípa igi kan tó wà nínú ọgbà Édẹ́nì, ó ní: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ jẹ nínú rẹ̀, nítorí ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ nínú rẹ̀, dájúdájú, ìwọ yóò kú.” a (Jẹ́nẹ́sísì 2:17) Nítorí náà, Ádámù mọ̀ pé tóun ò bá ti rú òfin yìí òun ò ní kú. Ìgbà tí kò bá pa òfin Ọlọ́run mọ́ ló máa yọrí sí ikú.

Ó bani nínú jẹ́ pé Ádámù àti Éfà, ìyàwó rẹ̀, ṣàìgbọràn. Wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ ṣe ohun tó lòdì sí ohun tí Ẹlẹ́dàá wọn fẹ́, wọ́n sì jìyà àìgbọràn wọn. Nígbà tí Ọlọ́run ń sọ ohun tó máa jẹ́ àbàjáde ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá fún wọn, ó ní: “Ekuru ni ọ́, ìwọ yóò sì padà sí ekuru.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:19) Ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá yìí ṣàkóbá fún wọn gan-an, ó sọ wọ́n di aláìpé. Ikú sì ni jíjẹ́ tí wọ́n jẹ́ aláìpé tàbí ẹlẹ́ṣẹ̀ yọrí sí fún wọn.

Gbogbo àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà, ìyẹn ìran èèyàn, wá jogún àìpé yìí, ìyẹn ẹ̀ṣẹ̀. Ńṣe ló dà bíi pé wọ́n jogún àrùn ìdílé kan. Yàtọ̀ sí pé Ádámù ò láǹfààní láti wà láàyè títí láé mọ́, ó tún kó àìpé ran àtọmọdọ́mọ rẹ̀. Gbogbo ìran èèyàn wá di ẹrú ẹ̀ṣẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Ìdí nìyẹn tí ó fi jẹ́ pé, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ti tipasẹ̀ ènìyàn kan wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.”—Róòmù 5:12.

‘Ẹ̀ṣẹ̀ Wọ Ayé’

Àìpé tàbí ẹ̀ṣẹ̀ tá a ti jogún yìí kì í ṣe ohun tá a lè fi awò amúǹkantóbi rí. “Ẹ̀ṣẹ̀” tá à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí jẹ́ àìpé tá a jogún látọ̀dọ̀ àwọn òbí wa àkọ́kọ́ tó ń jẹ́ ká ṣàṣìṣe nínú ìwà híhù tàbí nípa tẹ̀mí, ó sì ń ṣàkóbá fún ara wa. Àmọ́ ṣá o, Bíbélì fi hàn pé Ọlọ́run ti pèsè ohun tó máa mú àbùkù náà kúrò. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “Owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú, ṣùgbọ́n ẹ̀bùn tí Ọlọ́run ń fi fúnni ni ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ Kristi Jésù Olúwa wa.” (Róòmù 6:23) Nínú lẹ́tà kìíní tí Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Kọ́ríńtì, ó fi ọ̀rọ̀ ìdánilójú kan tó kà sí pàtàkì kún ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ní: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí gbogbo ènìyàn ti ń kú nínú Ádámù, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni a ó sọ gbogbo ènìyàn di ààyè nínú Kristi.”—1 Kọ́ríńtì 15:22.

Ó ṣe kedere pé Jésù Kristi kó ipa pàtàkì nínú mímú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú kúrò. Ó sọ pé òun wá sáyé láti “fi ọkàn [òun] fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Mátíù 20:28) A lè fi ohun tó ṣẹlẹ̀ náà wé ìgbà tí gbọ́mọgbọ́mọ bá jí ọmọ kan gbé, tó jẹ́ pé ó dìgbà tí ọlọ́mọ bá san iye owó kan kó tó lè rí ọmọ rẹ̀ gbà padà. Nínú ọ̀ràn tiwa, ìwàláàyè Jésù tó jẹ́ ìwàláàyè pípé ni Ọlọ́run fi gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. bÌṣe 10:39-43.

Kí Ọlọ́run lè pèsè ìràpadà náà, ó rán Jésù wá sáyé láti wá fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ. “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ . . . lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:16) Kí Kristi tó fi ẹ̀mí rẹ̀ rúbọ, ó ti kọ́kọ́ “jẹ́rìí sí òtítọ́.” (Jòhánù 18:37) Lákòókò tó sì ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù káàkiri, ó lo àwọn àǹfààní kan tó ní láti sọ ohun tí ikú jẹ́ gan-an.

“Ọmọdébìnrin Kékeré Náà . . . Ń Sùn Ni”

Ọ̀rọ̀ nípa ikú ò ṣàjèjì sí Jésù nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé. Ó máa ń dùn ún dọ́kàn nígbà táwọn tó sún mọ́ ọn bá kú, ó sì mọ̀ dájú pé àwọn èèyàn máa dá ẹ̀mí òun alára légbodò. (Mátíù 17:22, 23) Ẹ̀rí fi hàn pé ní oṣù díẹ̀ kí wọ́n tó pa Jésù, Lásárù ọ̀rẹ́ rẹ̀ ṣaláìsí. Ikú Lásárù jẹ́ ká mọ irú ojú tí Jésù fi wo ikú.

Kété tí ìròyìn nípa ikú Lásárù dé etígbọ̀ọ́ Jésù, ó sọ pé: “Lásárù ọ̀rẹ́ wa ti lọ sinmi, ṣùgbọ́n mo ń rìnrìn àjò lọ sí ibẹ̀ láti jí i kúrò lójú oorun.” Àwọn ọmọ ẹ̀yìn ń rò ó lọ́kàn pé tó bá jẹ́ pé ńṣe ni Lásárù kàn ń sinmi ni, á jẹ́ pé ó máa tó gbádùn. Ìdí nìyí tí Jésù fi là á mọ́lẹ̀ pé: “Lásárù ti kú.” (Jòhánù 11:11-14) Ó dájú pé lójú Jésù, nígbà tẹ́nì kan bá kú bíi pé ó sùn ló rí. Ó lè ṣòro fún wa láti lóye bí ikú ṣe rí, ṣùgbọ́n a mọ oorun. Bí a bá sùn wọra lóru, a kì í mọ ìgbà tí àkókò ń lọ, bẹ́ẹ̀ la kì í mọ àwọn ohun tó ń lọ láyìíká wa nítorí pé a ò mọ ohunkóhun nínú ipò tá a wà. Bí Bíbélì ṣe ṣàlàyé ipò táwọn òkú wà gan-an nìyẹn. Oníwàásù 9:5 sọ pé: “Ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá.”

Jésù tún fi ikú wé oorun nítorí pé ó ṣeé ṣe láti fi agbára Ọlọ́run jí òkú dìde. Lọ́jọ́ kan, Jésù lọ sọ́dọ̀ ìdílé kan. Ọkàn àwọn tó wà nínú ìdílé náà gbọgbẹ́ gidigidi nítorí ọmọ wọn kékeré tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kú. Jésù sọ pé: “Ọmọdébìnrin kékeré náà kò kú, ṣùgbọ́n ó ń sùn ni.” Ni Jésù bá sún mọ́ òkú ọmọdébìnrin náà, ó di ọwọ́ rẹ̀ mú, ọmọdébìnrin náà sì “dìde.” Ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé ọmọdébìnrin náà jíǹde.—Mátíù 9:24, 25.

Yàtọ̀ sí ọmọdébìnrin yìí, Jésù tún jí Lásárù ọ̀rẹ́ rẹ̀ tó kú dìde. Àmọ́ kí Jésù tó ṣe iṣẹ́ ìyanu yìí, ó kọ́kọ́ tu Màtá, ìyẹn àbúrò Lásárù nínú, ó sọ pé: “Arákùnrin rẹ yóò dìde.” Pẹ̀lú ìdánilójú, Màtá fèsì pé: “Mo mọ̀ pé yóò dìde nínú àjíǹde ní ọjọ́ ìkẹyìn.” (Jòhánù 11:23, 24) Ó dájú pé Màtá nírètí pé gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run yóò jíǹde lọ́jọ́ iwájú.

Kí ni ọ̀rọ̀ yẹn àjíǹde túmọ̀ sí gan-an? Tá a bá ní ká kàn túmọ̀ ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a tú sí “àjíǹde” (ìyẹn a·naʹsta·sis), ohun tá a máa pè é ni “dídìde dúró.” Èyí túmọ̀ sí pé kí ẹni tó ti kú padà wà láàyè. Ọ̀rọ̀ yìí lè máa ya àwọn kan lẹ́nu, ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé lẹ́yìn tí Jésù sọ pé àwọn òkú yóò gbọ́ ohùn òun, ó ní: “Kí ẹnu má yà yín sí èyí.” (Jòhánù 5:28) Àwọn àjíǹde tí Jésù ṣe nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé jẹ́ kó dá wa lójú pé òótọ́ ni ìlérí tí Bíbélì ṣe pé àwọn òkú tí Ọlọ́run fẹ́ jí dìde máa jí látinú “oorun” tí wọ́n ti ń sùn látọjọ́ pípẹ́. Ìṣípayá 20:13 sọ tẹ́lẹ̀ pé: “Òkun sì jọ̀wọ́ àwọn òkú tí ń bẹ nínú rẹ̀ lọ́wọ́, ikú àti Hédíìsì [ipò òkú] sì jọ̀wọ́ àwọn òkú tí ń bẹ nínú wọn lọ́wọ́.”

Ṣé ó wá túmọ̀ sí pé lẹ́yìn táwọn òkú bá ti jíǹde, wọ́n á tún darúgbó wọ́n á sì padà kú bíi ti Lásárù? Kì í ṣe ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn nìyẹn o. Bíbélì fi dá wa lójú pé ìgbà kan ń bọ̀ tí “ikú kì yóò . . . sí mọ́,” nígbà yẹn àwa èèyàn ò ní máa darúgbó mọ́ a ò sì ní kú mọ́.—Ìṣípayá 21:4

Ọ̀tá wa ni ikú jẹ́. Ìran èèyàn sì ni ọ̀pọ̀ ọ̀tá bẹ́ẹ̀, lára wọn ni àìsàn àti ọjọ́ ogbó tó ń pọ́n aráyé lójú. Ọlọ́run ṣèlérí pé òun yóò mú gbogbo wọn kúrò pátá, àti pé níkẹyìn òun yóò mú olórí ọ̀tá ìran èèyàn kúrò pátápátá. “Gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá ìkẹyìn, ikú ni a ó sọ di asán.”—1 Kọ́ríńtì 15:26.

Nígbà tí ìlérí yẹn bá ṣẹ, aráyé yóò gbádùn ìwàláàyè pípé, ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú kì yóò sì yọ wá lẹ́nu mọ́. Àmọ́ ní báyìí ná, kí ọkàn wa balẹ̀ pé ńṣe làwọn èèyàn wa tó ti kú ń sinmi, tí wọ́n bá sì wà lára àwọn tí Ọlọ́run máa jí dìde, wọn yóò padà wà láàyè nígbà tí àkókò bá tó.

Tá A Bá Lóye Ohun Tí Ikú Jẹ́, Ìgbésí Ayé Á Nítumọ̀ Lójú Wa

Tá a bá lóye ohun tí ikú jẹ́ àti ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sáwọn tó ti kú, ojú tá a fi ń wo ìgbésí ayé yóò yí padà. Ọmọkùnrin tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ian, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, ti lé lọ́mọ ogún ọdún nígbà tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí Bíbélì sọ nípa ikú. Ó sọ pé: “Gbogbo èrò ọkàn mi tẹ́lẹ̀ ni pé bàbá mi wà níbì kan. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé nígbà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ pé ńṣe ni bàbá mi ń sùn nínú ikú, inú mi ò dùn rárá.” Àmọ́ nígbà tí Ian ka ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé òun yóò jí àwọn tó ti kú dìde, inú rẹ̀ dùn gan-an láti mọ̀ pé òun tún lè padà rí bàbá òun. Ó rántí bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára rẹ̀, ó ní: “Ìgbà àkọ́kọ́ nìyẹn tí màá ní ìbàlẹ̀ ọkàn.” Òye tó tọ̀nà tó ní nípa ohun tí ikú jẹ́ fi ọkàn rẹ̀ balẹ̀.

Ọmọ tọkọtaya kan tórúkọ wọn ń jẹ́ Clive àti Brenda wà lára àwọn tó kú nínú jàǹbá ọkọ̀ tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú. Steven lorúkọ ọmọkùnrin náà, ọmọ ọdún mọ́kànlélógún sì ni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé tọkọtaya yìí mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa ikú, síbẹ̀ ikú òjijì tí ọmọ wọn kú yìí mú ọkàn wọn gbọgbẹ́. Kì í ṣe ẹ̀bi wọn náà, nítorí pé ọ̀tá wa ni ikú, oró rẹ̀ sì máa ń dunni wọra. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ìmọ̀ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n ti ní nípa ikú bẹ̀rẹ̀ sí mú kí wọ́n tújú ká. Ìyá ọmọ náà sọ pé: “Ìmọ̀ tá a ní nípa ikú ló mú ká ṣara gírí. Àmọ́ ṣá o, ojúmọ́ kan ò lè mọ́ ká má ronú nípa ìgbà tí Steven máa jíǹde látinú oorun àsùnwọra tó ń sùn.”

“Ikú, Ìtani Rẹ Dà?”

Ó dájú pé tá a bá lóye ipò táwọn òkú wà, a ó lè máa fi ojú tó yẹ wo ìgbésí ayé. Kò yẹ kí ọ̀rọ̀ ikú jẹ́ àdììtú fún wa. A lè máa gbádùn ìgbésí ayé wa láìjẹ́ kí jìnnìjìnnì bò wá nítorí ọ̀tá tó lè máa dẹ́rù bà wá yìí. Tá a bá fi sọ́kàn pé tá a bá tiẹ̀ kú kò túmọ̀ sí pé òpin ìgbésí ayé wa nìyẹn, èyí ò ní jẹ́ ká kàn máa gbé ìgbésí ayé fàájì, ká máa ronú pé “èèyàn lè kú nígbàkigbà.” Tá a bá mọ̀ pé ńṣe làwọn èèyàn wa tí Ọlọ́run ò ní gbàgbé ń sùn nínú ikú, wọn yóò sì jíǹde, yóò jẹ́ ìtùnú fún wa, kò sì ní jẹ́ kí ayé sú wa.

Bẹ́ẹ̀ ni o, a lè máa fi ìdánilójú wọ̀nà fún àkókò tí Jèhófà Ọlọ́run, Ẹni tó fún wa ní ìwàláàyè, yóò mú ikú kúrò pátápátá. Ayọ̀ ńlá ni yóò jẹ́ fún wa nígbà tá a bá lè béèrè pé: “Ikú, ìjagunmólú rẹ dà? Ikú, ìtani rẹ dà?”—1 Kọ́ríńtì 15:55.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ibí yìí ni Bíbélì ti kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa ikú.

b Owó ìràpadà tí Ọlọ́run san yìí ni ìwàláàyè ènìyàn pípé nítorí ohun tí Ádámù sọ nù nìyẹn. Gbogbo ìran èèyàn ló ti di ẹlẹ́sẹ̀, nítorí náà kò sí ẹ̀dá èèyàn àláìpé kankan tó lè rà wá padà. Ìdí rèé tí Ọlọ́run fi rán Ọmọ rẹ̀ wá láti ọ̀run pé kó wá rà wá padà. (Sáàmù 49:7-9) Tó o bá fẹ́ àlàyé síwájú sí i lórí kókó yìí, wo orí keje nínú ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Àìgbọràn Ádámù àti Éfà ló ṣekú pa wọ́n

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Jésù di ọmọdébìnrin tó ti kú náà lọ́wọ́ mú, ọmọ náà sì dìde

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń dúró de ìgbà táwọn èèyàn wọn tó ti kú yóò jí dìde látinú oorun, bíi ti Lásárù