Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Aburú Tí Ikú Ń Fà

Aburú Tí Ikú Ń Fà

Aburú Tí Ikú Ń Fà

“ỌMỌ ỌDÚN MẸ́FÀ PARA Ẹ̀.” Àkọlé tó ń bani nínú jẹ́ yìí ló wà níwájú ìwé ìròyìn kan tó ròyìn nípa bí ọmọbìnrin kékeré kan tó ń jẹ́ Jackie ṣe kú ikú gbígbóná. Kò tíì pẹ́ púpọ̀ tí àìsàn kògbóògùn kan pa ìyá ọmọ náà tí ọmọ yìí fi lọ para ẹ̀. Kó tó di pé Jackie lọ mọ̀ọ́mọ̀ kó sẹ́nu rélùwéè, ó sọ fáwọn èèyàn rẹ̀ pé òun ‘fẹ́ di áńgẹ́lì àti pé òun fẹ́ lọ bá ìyá òun níbi tó wà.’

Ọmọkùnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ian wà lọ́mọ ọdún méjìdínlógún nígbà tó lọ bẹ àlùfáà ìjọ rẹ̀ pé kó sọ ìdí tí àrùn jẹjẹrẹ fi pa bàbá òun fóun. Àlùfáà náà sọ fún un pé èèyàn rere tí bàbá Ian jẹ́ ló mú kí Ọlọ́run mú un lọ sọ́run. Lẹ́yìn tí Ian gbọ́ àlàyé yìí, ó pinnu pé òun ò ní kẹ́kọ̀ọ́ kankan nípa Ọlọ́run tó ń hu irú ìwà ìkà bẹ́ẹ̀. Nígbà tí Ian sì wá wò ó pé ó dà bíi pé ìgbésí ayé ò nítumọ̀, ló bá bẹ̀rẹ̀ sí jayé kiri. Ìyẹn ló mú kó máa mutí nímukúmu, kó máa lo oògùn olóró, kó sì máa ṣèṣekúṣe. Bí ìgbésí ayé Ian ṣe bẹ̀rẹ̀ sí bà jẹ́ nìyẹn.

“Àwọn Alààyè Mọ̀ Pé Àwọn Yóò Kú”

Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ méjì tó ń bani nínú jẹ́ yìí jẹ́ ká rí i pé ikú èèyàn ẹni lè sọni dìdàkudà, páàpáà tí ikú ọ̀hún bá lọ jẹ́ ikú òjijì. Lóòótọ́, gbogbo wa la mọ̀ pé òótọ́ lohun tí Bíbélì sọ pé: “Àwọn alààyè mọ̀ pé àwọn yóò kú.” (Oníwàásù 9:5) Àmọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn ni kì í fẹ́ ronú pé àwọn lè kú nígbàkigbà. Ìwọ náà ńkọ́? Ọ̀pọ̀ nǹkan là ń ṣe tó ń gba àkókò wa, tó sì ń gbà wá lọ́kàn débi pé a lè má máa ronú nípa ikú, èyí tó lè dé nígbàkigbà.

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The World Book Encyclopedia sọ pé: “Ọ̀pọ̀ èèyàn lẹ̀rù ikú ń bà, wọn kì í sì í fẹ́ ronú nípa rẹ̀.” Àmọ́, nígbà tí jàǹbá kan bá ṣẹlẹ̀ tàbí tí àìsàn burúkú kan bá ṣe wá, a lè bẹ̀rẹ̀ sí ronú nípa ikú. Tàbí kẹ̀, ikú ọ̀rẹ́ wa kan tàbí mọ̀lẹ́bí wa kan lè rán wa létí pé kò sẹ́ni tó bọ́ lọ́wọ́ ikú.

Síbẹ̀, àwọn abánikẹ́dùn sábà máa ń sọ níbi ìsìnkú pé, “Ẹní kú ti kú, a ò rọ́gbọ́n dá sí i.” Bó sì ṣe rí nìyẹn lóòótọ́. Kì í pẹ́ lọ títí tí àgbà fi máa ń dé, téèyàn á sì darúgbó. Téèyàn bá sì ti darúgbó, ikú ń sún mọ́ nìyẹn. Gbogbo ìgbà ni ìsìnkú ń wáyé, ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ wa láti ọjọ́ pípẹ́ ni ikú máa ń mú lọ. Ìbéèrè tí ọ̀pọ̀ àwọn àgbàlagbà sábà máa ń bi ara wọn ni pé, “Ìgbà wo ni ikú máa yí kàn mí?”

Àdììtú Ńlá

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo wa la mọ̀ pé ikú dájú fọ́mọ èèyàn, àdììtú ńlá lóhun tó ń ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn téèyàn bá kú jẹ́. Bí àlàyé àwọn èèyàn nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ikú ò ṣe bára mu lè mú káwọn oníyèmejì ka gbogbo àlàyé wọn sí bí ìgbà téèyàn kàn ń dara ẹ̀ láàmú lórí ohun tí ò lè mọ̀. Àwọn tó jẹ́ pé bí nǹkan bá ṣe rí ni wọ́n ṣe máa ń gbà á lè máa sọ pé “èèyàn ò kúkú ní tún ayé wá,” nítorí náà, kéèyàn jayé orí ẹ̀ dáadáa.

Àmọ́ ṣá o, àwọn kan ò gbà pé ikú lòpin ohun gbogbo. Síbẹ̀, wọn ò mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn téèyàn bá kú. Àwọn kan gbà pé lẹ́yìn téèyàn bá kú, ọ̀run rere ló ń lọ, èrò àwọn míì sì ni pé àwọn tó ti kú máa ń tún ayé wá, bóyá kí wọ́n wá gẹ́gẹ́ bí èèyàn míì.

Àwọn tí èèyàn wọn ṣaláìsí sábà máa ń bi ara wọn pé, “Ibo làwọn tó ti kú wà?” Ní ọdún mélòó kan sẹ́yìn, ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù kan ń lọ síbi tí wọ́n ti fẹ́ lọ gbá bọ́ọ̀lù. Bí wọ́n ṣe ń lọ ni ọkọ̀ ńlá kan ṣàdédé kọ lu bọ́ọ̀sì tí wọ́n wà nínú rẹ̀, ni bọ́ọ̀sì náà bá tàkìtì. Márùn-ún lára àwọn agbábọ́ọ̀lù náà ló kú. Látọjọ́ tí jàǹbá náà ti ṣẹlẹ̀, obìnrin kan tí ọmọ rẹ̀ ọkùnrin wà lára àwọn tó kú nínú jàǹbá ọkọ̀ náà kò tíì gbádùn. Obìnrin náà ò yéé ronú nípa ibi tó ṣeé ṣe kí ọmọ rẹ̀ wà. Gbogbo ìgbà ló sì máa ń lọ síbi ibojì ọmọ náà, táá dúró síbẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí, táá sì máa sọ̀rọ̀ sókè bó ṣe ń bá ọmọ náà sọ̀rọ̀. Bó ṣe dun obìnrin náà tó, ó ní: “Mi ò gbà pé kò sóhun tó ń ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn tẹ́nì kan bá kú, àmọ́ nǹkan ọ̀hún ò dá mi lójú.”

Ó ṣe kedere pé èrò tá a bá ní nípa ikú lè ní ipa lórí ìgbésí ayé wa nísinsìnyí. Nítorí ohun táwọn èèyàn máa ń ṣe nígbà tẹ́nì kan bá kú, ọ̀pọ̀ ìbéèrè ló ti jẹ yọ. Wo bó o ṣe lè dáhùn wọn. Ǹjẹ́ ó yẹ ká pa ọ̀rọ̀ ikú tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan ká wá gbájú mọ́ ìwàláàyè nìkan? Ǹjẹ́ ó yẹ ká sọ ìgbésí ayé wa dìdàkudà nítorí èrò pé ikú lè mú wa lọ nígbàkigbà? Ǹjẹ́ ó yẹ kí ẹnì kan téèyàn rẹ̀ kú máa ṣe kàyéfì nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí èèyàn rẹ̀ tó ti kú? Ṣé ohun téèyàn ò lè lóye rárá ni ikú jẹ́?