Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí Àwọn Ẹlẹ́rìí Ṣe Fọwọ́ Pàtàkì Mú Bíbélì Wú Àwọn Olùkọ́ Lórí

Bí Àwọn Ẹlẹ́rìí Ṣe Fọwọ́ Pàtàkì Mú Bíbélì Wú Àwọn Olùkọ́ Lórí

Bí Àwọn Ẹlẹ́rìí Ṣe Fọwọ́ Pàtàkì Mú Bíbélì Wú Àwọn Olùkọ́ Lórí

ỌMỌ ọdún méjìdínlógún ni Marianna. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní gúúsù orílẹ̀-èdè Ítálì. Ọdún tó kẹ́yìn tó máa lò nílé ẹ̀kọ́ gíga ló wà, kì í sì í ṣe òun nìkan ni ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí tó wà nílé ẹ̀kọ́ náà.

Marianna kọ̀wé pé: “Ó ti tó ọdún mélòó kan báyìí tí díẹ̀ lára wa ti jọ ń ka ẹ̀kọ́ ojoojúmọ́ nínú ìwé Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́ lákòókò ìsinmi ọ̀sán. Ibì kan ṣoṣo tá a ti lè máa jíròrò rẹ̀ ni ọ̀ọ̀dẹ̀ kan tó sún mọ́ ọ́fíìsì táwọn tíṣà wa máa ń lò. Ariwo máa ń wà níbẹ̀. Ọ̀pọ̀ lára àwọn tíṣà wa máa ń rí wa bí wọ́n bá ń kọjá, àwọn kan sì máa ń dúró láti wo ohun tá à ń ṣe. A sábà máa ń lo àǹfààní yìí láti dáhùn àwọn ìbéèrè wọn. Kò sí ọjọ́ kan tá ò ní rí tíṣà tó máa dúró. Ọ̀pọ̀ lára wọn ló máa ń dúró láti gbọ́ bá a ṣe ń jíròrò ẹsẹ Bíbélì, wọ́n sì máa ń sọ̀rọ̀ ìwúrí nípa bí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe fọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn Ọlọ́run. Nígbà kan, igbákejì ọ̀gá àgbà tiẹ̀ ní ká wá ṣe ìjíròrò wa ní ọ́fíìsì táwọn tíṣà máa ń lò.

“Nígbà tí olùkọ́ mi rí ibi tá a ti ń ka ẹ̀kọ́ ojoojúmọ́, ó sọ fún ọ̀gá àgbá pé kó jẹ́ ká máa lo ọ̀kan lára àwọn kíláàsì ilé ẹ̀kọ́ wa níbi tí kò ti fi bẹ́ẹ̀ sí ariwo, ọ̀gá àgbà sì fọwọ́ sí i. Olùkọ́ mi yìn wá níwájú gbogbo ọmọ kíláàsì nítorí a jẹ́ àpẹẹrẹ rere. Inú gbogbo wa dùn gan-an fún àǹfààní ńláǹlà tí Jèhófà fún wa yìí.”