Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bíbélì Ọba Àgbà Ìwé Tó Wúlò Gan-an

Bíbélì Ọba Àgbà Ìwé Tó Wúlò Gan-an

Bíbélì Ọba Àgbà Ìwé Tó Wúlò Gan-an

NÍ NǸKAN bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] ọdún sẹ́yìn, ọkọ̀ òkun kan gbéra láti orílẹ̀-èdè Sípéènì lọ sí orílẹ̀-èdè Ítálì. Ẹrù tó ṣeyebíye gan-an ni wọ́n kó sínú ọkọ̀ òkun náà, ìyẹn àwọn ẹ̀dà Bíbélì Elédè Púpọ̀ ti Complutensian tí wọ́n tẹ̀ láàárín ọdún 1514 sí 1517. Bí ọkọ̀ òkun náà ṣe ń lọ ni ìjì líle kan bẹ̀rẹ̀ sí jà. Àwọn tó wà nínú ọkọ̀ náà sapá gidigidi kí ọkọ̀ náà má bàa rì, àmọ́ pàbó ni gbogbo akitiyan wọn já sí. Ọkọ̀ náà rì tòun ti gbogbo ẹrù iyebíye tó wà nínú rẹ̀.

Àjálù yìí ló mú káwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí wá bí wọ́n á ṣe rí Bíbélì Elédè Púpọ̀ mìíràn. Níkẹyìn, àgbà òǹtẹ̀wé nì tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Christophe Plantin sọ pé òun yóò tẹ àwọn ẹ̀dà tuntun mìíràn. Àmọ́, ó ń wá ọlọ́rọ̀ kan tí yóò fi owó ṣètìlẹ́yìn fún un kó lè ṣe iṣẹ́ bàǹtàbanta yìí, ìdí nìyẹn tó fi lọ bá ọba ilẹ̀ Sípéènì, ìyẹn Philip Kejì, pé kó ṣonígbọ̀wọ́ iṣẹ́ tóun fẹ́ ṣe náà. Kí ọba yìí tó gbà láti ṣonígbọ̀wọ́ rẹ̀, ó kọ́kọ́ kàn sáwọn ọ̀mọ̀wé ilẹ̀ Sípéènì irú bí gbajúgbajà ọ̀mọ̀wé kan tó kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Benito Arias Montano. Ọ̀mọ̀wé yìí sọ fún Philip Ọba pé: “Kábíyèsí, yàtọ̀ sí pé iṣẹ́ Ọlọ́run niṣẹ́ títẹ Bíbélì yìí àti pé yóò ṣe àwọn ará ìjọ láǹfààní, yóò gbé orúkọ yín ga, yóò sì gbé yín níyì gan-an láàárín àwọn èèyàn.”

Philip Ọba mọ̀ pé táwọn bá tún Bíbélì Elédè Púpọ̀ ti Complutensian tẹ̀ jáde, yóò jẹ́ ìtẹ̀síwájú ńlá kan fún wọn, ìdí nìyẹn tó fi kọ́wọ́ ti Plantin tọkàntọkàn. Ọba náà gbé iṣẹ́ bàǹtàbanta kan fún Arias Montano, ìyẹn ni pé kó ṣàtúnṣe tó bá yẹ sí Bíbélì náà. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, wọ́n wá ń pe Bíbélì náà ní Bíbélì Ọba tàbí Bíbélì Elédè Púpọ̀ ti Antwerp. a

Philip nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ títẹ Bíbélì Elédè Púpọ̀ yìí gan-an débi pé ó sọ fáwọn tó ń ṣiṣẹ́ lórí rẹ̀ pé kí wọ́n máa fi gbogbo abala tí wọ́n bá ti ṣiṣẹ́ lé lórí ránṣẹ́ sóun kóun lè kà á kóun sì ṣàtúnṣe tó bá yẹ sí i. Plantin ò fi gbogbo ara fara mọ́ ohun tí Philip Ọba sọ yìí nítorí àkókò tó máa gbà láti fi àwọn abala náà ránṣẹ́ láti ìlú Antwerp sí ilẹ̀ Sípéènì, kí ọba tó wá kà á kó sì ṣàtúnṣe sí i, kó tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá dá a padà sọ́dọ̀ wọn. Níkẹyìn, kìkì abala tí wọ́n kọ́kọ́ tẹ̀ jáde ló tẹ Philip lọ́wọ́, ó sì ṣeé ṣe kó rí ojú ewé mélòó kan sí i lára èyí tí wọ́n tẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn. Lákòókò náà, Montano ń bá iṣẹ́ lọ lórí kíka Bíbélì náà àti ṣíṣe àtúnṣe sí i. Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n mẹ́ta nílùú Louvain àti ọmọ Plantin obìnrin ló ràn án lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ náà.

Ọkùnrin Kan Tó Nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Ọkàn Arias Montano balẹ̀ láàárín àwọn ọ̀mọ̀wé tó wà nílùú Antwerp. Ó jẹ́ ẹnì kan tó máa ń gba èrò ẹlòmíì mọ́ tirẹ̀, ìdí nìyẹn tí Plantin fi fẹ́ràn rẹ̀ gan-an, àwọn méjèèjì sì dọ̀rẹ́ jálẹ̀ ìgbésí ayé wọn. Kì í ṣe jíjẹ́ tí Montano jẹ́ ọ̀mọ̀wé nìkan ló mú kó ta yọ, ó tún ta yọ nítorí ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tó ní fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. b Nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́, ó wù ú láti tètè parí ẹ̀kọ́ rẹ̀ kó bàa lè fi ìyókù ìgbésí ayé rẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ nìkan.

Arias Montano gbà gbọ́ pé téèyàn bá fẹ́ ṣe ìtumọ̀ Bíbélì, bó ṣe wà gẹ́lẹ́ nínú èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ lèèyàn gbọ́dọ̀ túmọ̀ rẹ̀. Ó gbìyànjú láti túmọ̀ Bíbélì bó ṣe wà gan-an nínú Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀, èyí sì jẹ́ káwọn èèyàn rí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kà bó ṣe wà látìbẹ̀rẹ̀. Montano tẹ̀ lé èrò Erasmus tó ń sọ fáwọn ọ̀mọ̀wé pé ‘látinú Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀ ni kí wọ́n ti máa wàásù nípa Kristi.’ Ó ti pẹ́ gan-an tí ìtumọ̀ Bíbélì ní èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ ti ṣókùnkùn sáwọn èèyàn nítorí ó ṣòro fún wọn láti lóye Bíbélì Látìn.

Bí Wọ́n Ṣe Ṣe Bíbélì Náà

Arias Montano lọ gba gbogbo àwọn ìwé Bíbélì àfọwọ́kọ tí Alfonso de Zamora kó jọ tó sì ṣe àtúnṣe sí láti fi ṣe Bíbélì Elédè Púpọ̀ ti Complutensian. Àwọn ìwé Bíbélì àfọwọ́kọ náà sì ni Montano fi ṣe Bíbélì Ọba. c

Ohun tí àwọn tó ṣe Bíbélì Ọba jáde ní lọ́kàn níbẹ̀rẹ̀ ni pé kí Bíbélì náà jẹ́ àtúntẹ̀ tí wọ́n á fi rọ́pò Bíbélì Elédè Púpọ̀ ti Complutensian, àmọ́ wọ́n ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan sí i tó mú kó ju àtúntẹ̀ lásán lọ. Wọ́n fi Bíbélì Septuagint ní èdè Hébérù àti ti Gíríìkì tó wà nínú Bíbélì Complutensian sínú rẹ̀, yàtọ̀ síyẹn, wọ́n fi Ìwé Mímọ́ tó wà láwọn èdè míì sínú rẹ̀, wọ́n sì tún fi àfikún ẹ̀yìn ìwé tó ní àlàyé rẹpẹtẹ kún un. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, gbogbo ìdìpọ̀ Bíbélì Elédè Púpọ̀ tuntun yìí jẹ́ mẹ́jọ. Ọdún márùn-ún gbáko ló gbà wọ́n láti tẹ Bíbélì náà, bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1568 sí ọdún 1572. Ọdún tó gbà wọ́n yìí kéré jọjọ tá a bá ní ká wo adúrú iṣẹ́ tí wọ́n ṣe sínú rẹ̀. Níkẹyìn, wọ́n tẹ ẹ̀dà tó tó ẹgbẹ̀rún kan ó lé igba àti mẹ́tàlá [1,213].

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì Elédè Púpọ̀ ti Complutensian tí wọ́n ṣe lọ́dún 1517 jẹ́ “ohun àmúyangàn tó bá dọ̀rọ̀ iṣẹ́ ọnà ìwé títẹ̀,” Bíbélì Elédè Púpọ̀ ti Antwerp tún gbayì jùyẹn lọ nítorí bó ṣe dára tó àti bí àwọn ohun tó wà nínú rẹ̀ ṣe pọ̀ tó. Ìtẹ̀síwájú lèyí jẹ́ nínú ìtàn ìwé títẹ̀, àti ní pàtàkì nínú ṣíṣe ẹ̀dà Bíbélì tó péye fún iṣẹ́ ìtumọ̀ Bíbélì.

Àwọn Ọ̀tá Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Gbógun

Kò yani lẹ́nu pé láìpẹ́ láìjìnnà, àwọn tí kò fẹ́ kí wọ́n ṣe ìtumọ̀ Bíbélì tó péye bẹ̀rẹ̀ sí gbógun ti àwọn tó ṣe é. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Póòpù fọwọ́ sí i pé kí Arias Montano ṣe Bíbélì Antwerp yìí, tí Montano sì jẹ́ ọ̀mọ̀wé kan táwọn èèyàn gba tiẹ̀, síbẹ̀ àwọn alátakò ṣì gbé e lọ sílé ẹjọ́ tí ìjọ Kátólíìkì gbé kalẹ̀ láti gbógun ti àdámọ̀. Àwọn alátakò wọ̀nyí sọ pé Bíbélì tí Montano ṣe ń fi hàn pé Bíbélì Látìn tí Santes Pagninus ṣẹ̀ṣẹ̀ tún ṣe, tó jẹ́ ìtumọ̀ látinú àwọn ìwé Bíbélì èdè Hébérù àti Gíríìkì ti ìpilẹ̀ṣẹ̀ péye ju ìtumọ̀ Vulgate, èyí tí wọ́n túmọ̀ ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ṣáájú ìyẹn. Wọ́n tún fẹ̀sùn kan Montano pé ó lọ wo àwọn èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ nítorí pé ó fẹ́ ṣe ìtumọ̀ Bíbélì tó péye. Àdámọ̀ ni wọ́n ka ohun tó ṣe yẹn sí.

Ilé ẹjọ́ náà tiẹ̀ sọ pé “bí Ọba ṣe ṣonígbọ̀wọ́ fún títẹ Bíbélì náà kò buyì kún un.” Wọ́n ní ó dun àwọn pé Montano ò ka Bíbélì Vulgate tí wọ́n fọwọ́ sí kún. Láìka gbogbo ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Montano sí, ìgbìmọ̀ náà ò rí ẹ̀rí tó tó láti dá Montano lẹ́bi tàbí láti gbẹ́sẹ̀ lé Bíbélì Elédè Púpọ̀ tó ṣe. Níkẹyìn, Bíbélì Ọba náà wá di ohun tí gbogbo èèyàn gba tiẹ̀, wọ́n sì ń lò ó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ yunifásítì.

Ó Wúlò Gan-an Nínú Iṣẹ́ Ìtumọ̀ Bíbélì

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe gbogbo èèyàn làwọn tó ṣe Bíbélì Antwerp ṣe é fún níbẹ̀rẹ̀, kò pẹ́ tí Bíbélì náà fi di ìwé tó wúlò gan-an fáwọn tó ń túmọ̀ Bíbélì. Bí Bíbélì Elédè Púpọ̀ ti Complutensian ṣe wúlò gan-an ni Bíbélì Antwerp náà ṣe wúlò nítorí pé wọ́n lò ó nígbà tí wọ́n ń tún àwọn ìwé Bíbélì tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó nígbà náà ṣe. Ó tún ran àwọn atúmọ̀ èdè lọ́wọ́ láti túbọ̀ lóye àwọn èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀. Àwọn tó túmọ̀ Bíbélì sí onírúurú èdè pàtàkì nílẹ̀ Yúróòpù jàǹfààní látinú rẹ̀ pẹ̀lú. Bí àpẹẹrẹ, ìwé The Cambridge History of the Bible ròyìn pé Bíbélì Antwerp làwọn tó túmọ̀ Bíbélì ọba Jémíìsì (King James Version) tó gbajúmọ̀ tí wọ́n ṣe lọ́dún 1611 lò láti fi túmọ̀ àwọn èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀. Bíbélì Ọba yìí tún ṣèrànwọ́ gan-an nígbà tí wọ́n fẹ́ ṣe Bíbélì Elédè Púpọ̀ méjì tí wọ́n tẹ̀ jáde ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ọdún sẹ́yìn.—Wo àpótí tí àkọlé rẹ̀ jẹ́ “Àwọn Bíbélì Elédè Púpọ̀.”

Ọkàn lára ọ̀pọ̀ àǹfààní tó wà nínú Bíbélì Elédè Púpọ̀ ti Antwerp ni pé ó jẹ́ káwọn ọ̀mọ̀wé ilẹ̀ Yúróòpù rí Ìwé Mímọ́ Lédè Gíríìkì tí wọ́n túmọ̀ sí èdè Síríákì fúngbà àkọ́kọ́. Wọ́n fi ìtumọ̀ ti Síríákì sẹ́gbẹ̀ẹ́ ti Látìn tí wọ́n túmọ̀ ní olówuuru. Ìtumọ̀ ti Síríákì tí wọ́n fi kún un yìí dára gan-an ni nítorí pé ó wà lára àwọn ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì tó wà pẹ́ jù lọ. Ọ̀rúndún karùn-ún Sànmánì Kristẹni ni wọ́n ṣe Bíbélì èdè Síríákì yìí, àwọn ìwé Bíbélì àfọwọ́kọ tó ti wà láti ọ̀rúndún kejì Sànmánì Kristẹni ni wọ́n lò láti túmọ̀ rẹ̀. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The International Standard Bible Encyclopedia sọ pé “gbogbo èèyàn ló mọ̀ pé ìtumọ̀ Bíbélì [Síríákì] Peshitta dára gan-an fún ṣíṣe àgbéyẹ̀wò ọ̀rọ̀ inú Bíbélì. Ó wà lára ìtumọ̀ tó pẹ́ jù lọ tó sì ṣe pàtàkì jù lọ tí wọ́n fi ń jẹ́rìí sí àwọn àṣà ayé ìgbàanì.”

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹ̀dà Bíbélì Elédè Púpọ̀ ti Complutensian rì sínú òkun, ilé ẹjọ́ tó ń gbógun ti àdámọ̀ nílẹ̀ Sípéènì sì gbógun kí wọ́n má lè tẹ òmíràn tí wọ́n ṣe àtúnṣe sí tó sì tóbi ju ti tẹ́lẹ̀ lọ jáde, síbẹ̀ gbogbo èyí ò dá iṣẹ́ títẹ Bíbélì Ọba tó rọ́pò rẹ̀ jáde lọ́dún 1572 dúró. Ìtàn bí wọ́n ṣe ṣe Bíbélì Elédè Púpọ̀ tí wọ́n tẹ̀ nílùú Antwerp jẹ́ ká mọ akitiyan táwọn ọkùnrin olóòótọ́ ṣe láti fìdí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run múlẹ̀.

Yálà àwọn ọkùnrin tó fi tọkàntọkàn ṣiṣẹ́ yìí mọ̀ bẹ́ẹ̀ ni o tàbí wọn ò mọ̀, iṣẹ́ ribiribi tí wọ́n ṣe fi hàn pé òótọ́ ni àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà. Ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọdún sẹ́yìn, wòlíì náà sọ pé: “Koríko tútù ti gbẹ dànù, ìtànná ti rọ; ṣùgbọ́n ní ti ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa, yóò wà fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Aísáyà 40:8.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ìdí tí wọ́n fi ń pe Bíbélì náà ní Bíbélì Ọba ni pé Philip Ọba ló ṣonígbọ̀wọ́ rẹ̀, wọ́n sì ń pè é ní Bíbélì Elédè Púpọ̀ ti Antwerp nítorí pé ìlú Antwerp tó jẹ́ ara Ilẹ̀ Ọba Sípéènì nígbà yẹn ni wọ́n ti tẹ̀ ẹ́.

b Ó gbọ́ èdè Lárúbáwá, Gíríìkì, Hébérù, Látìn, àti èdè Síríákì dáadáa, ìyẹn àwọn èdè márùn-ún pàtàkì tó wà nínú Bíbélì Elédè Púpọ̀ náà. Montano tún gbóná nínú ìmọ̀ nípa ìwalẹ̀pìtàn, ìmọ̀ ìṣègùn, ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àti ẹ̀kọ́ nípa Ọlọ́run. Ìmọ̀ nípa gbogbo nǹkan wọ̀nyí ló sì lò nígbà tó ń ṣe àfikún ẹ̀yìn ìwé sí Bíbélì Elédè Púpọ̀ náà.

c Tó o bá fẹ́ ka àlàyé nípa bí Bíbélì Elédè Púpọ̀ ti Complutensian ṣe ṣe pàtàkì tó, wo Ilé Ìṣọ́, April 15, 2004.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 13]

“Ní ti ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa, yóò wà fún àkókò tí ó lọ kánrin”

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

ÀWỌN BÍBÉLÌ ELÉDÈ PÚPỌ̀

Ọ̀mọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Sípéènì tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Federico Pérez Castro sọ pé “Bíbélì Elédè Púpọ̀ ni Bíbélì tí onírúurú èdè wà nínú rẹ̀. Àmọ́, ohun tí Bíbélì Elédè Púpọ̀ túmọ̀ sí níbẹ̀rẹ̀ ni pé àwọn èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ ni wọ́n fi kọ àwọn ìwé Bíbélì tó wà nínú rẹ̀. Tá a bá sì wá fojú ìtumọ̀ yìí wò ó, á jẹ́ pé iye Bíbélì Elédè Púpọ̀ tí ń bẹ kò pọ̀.”

1. Bíbélì Elédè Púpọ̀ ti Complutensian (1514 sí 1517). Kádínà Cisneros ló ṣonígbọ̀wọ́ Bíbélì yìí, ìlú Alcalá de Henares, lórílẹ̀-èdè Sípéènì ni wọ́n sì ti tẹ̀ ẹ́. Ìdìpọ̀ mẹ́fà ni wọ́n ṣe Bíbélì náà sí, èdè mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ sì làwọn ìwé Bíbélì tó wà nínú rẹ̀. Àwọn èdè náà ni: Hébérù, Gíríìkì, Árámáíkì àti Látìn. Látinú Bíbélì yìí làwọn atúmọ̀ èdè ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún ti túmọ̀ Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù àti ti Árámáíkì.

2. Bíbélì Elédè Púpọ̀ ti Antwerp (1568 sí 1572). Benito Arias Montano ló ṣe àtúnṣe sí Bíbélì yìí nígbà tí wọ́n ń ṣe é. Láfikún sí àwọn ìwé inú Bíbélì Elédè Púpọ̀ ti Complutensian tí wọ́n fi sínú rẹ̀, wọ́n tún fi Ìwé Mímọ́ lédè Gíríìkì tó jẹ́ ìtumọ̀ ti Síríákì Peshitta àti Bíbélì Árámáíkì tí Jonathan ṣe kún un. Wọ́n fi ìwé Bíbélì lédè Hébérù tí Jacob ben Hayyim ṣe ṣàtúnṣe sí ìwé Bíbélì lédè Hébérù tó wà nínú rẹ̀, èyí tó jẹ́ pé wọ́n fi àmì ibi tí fáwẹ̀lì máa wà láàárín ọ̀rọ̀ àti àmì pípe ọ̀rọ̀ sí. Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù yìí wá di ìtumọ̀ tó péye táwọn atúmọ̀ Bíbélì gbára lé láti ṣe ìtumọ̀ wọn.

3. Bíbélì Elédè Púpọ̀ ti Paris (1629 sí 1645). Agbẹjọ́rò ọmọ ilẹ̀ Faransé kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Guy Michel le Jay ló ṣonígbọ̀wọ́ Bíbélì yìí. Bíbélì Elédè Púpọ̀ ti Antwerp kó ipa pàtàkì nínú ṣíṣe Bíbélì yìí, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìwé Bíbélì ti àwọn ará Samáríà àti ti èdè Lárúbáwá wà nínú rẹ̀.

4. Bíbélì Elédè Púpọ̀ ti London (1655 sí 1657). Brian Walton ló ṣe àtúnṣe sí Bíbélì yìí, Bíbélì Elédè Púpọ̀ ti Antwerp ló sì fi ṣe ìtumọ̀ inú rẹ̀. Àwọn ìtumọ̀ Bíbélì ayé àtijọ́ tó jẹ́ ti èdè Etiópíà àti ti Páṣíà wà nínú rẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìtumọ̀ Bíbélì wọ̀nyí ò mú kí ọ̀rọ̀ Bíbélì náà ṣe kedere tó bẹ́ẹ̀ jù bẹ́ẹ̀ lọ.

[Àwọn Credit Line]

Ọ̀rọ̀ tó wà lábẹ́ àkọlé àpótí àti Bíbélì Elédè Púpọ̀ ti Antwerp (méjì tó wà nísàlẹ̀): Biblioteca Histórica. Universidad Complutense de Madrid; Bíbélì Elédè Púpọ̀ ti Antwerp (lókè): Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda Museum Plantin-Moretus/Stedelijk Prentenkabinet Antwerpen; Bíbélì Elédè Púpọ̀ ti London: Látinú ìwé The Walton Polyglot Bible, Ìdìpọ̀ Kẹta, 1655 sí 1657

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Philip Kejì, ọba ilẹ̀ Sípéènì

[Credit Line]

Philip Kejì: Biblioteca Nacional, Madrid

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Arias Montano rèé

[Credit Line]

Montano: Biblioteca Histórica. Universidad Complutense de Madrid

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Àwọn ẹ̀rọ̀ ìtẹ̀wé tí wọ́n fi tẹ Bíbélì náà nìyí nílùú Antwerp, lórílẹ̀-èdè Belgium

[Credit Line]

Ẹ̀rọ ìtẹ̀wé: Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda Museum Plantin-Moretus/Stedelijk Prentenkabinet Antwerpen

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Òsì: Christophe Plantin àti ojú ìwé tá a kọ àkọlé Bíbélì Elédè Púpọ̀ ti Antwerp sí

[Credit Line]

Ojú ìwé tá a kọ àkọlé ìwé sí àti Plantin: Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda Museum Plantin-Moretus/Stedelijk Prentenkabinet Antwerpen

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Òkè: Ẹ́kísódù orí 15 ní òpó ìlà mẹ́rin

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 9]

Ojú ìwé tá a kọ àkọlé ìwé sí àti Plantin: Nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda Museum Plantin-Moretus/Stedelijk Prentenkabinet Antwerpen

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 13]

Biblioteca Histórica. Universidad Complutense de Madrid