Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Ẹlẹ́sìn Menno Fẹ́ Mọ Ohun Tí Bíbélì Kọ́ni

Àwọn Ẹlẹ́sìn Menno Fẹ́ Mọ Ohun Tí Bíbélì Kọ́ni

Àwọn Ẹlẹ́sìn Menno Fẹ́ Mọ Ohun Tí Bíbélì Kọ́ni

BÁWỌN míṣọ́nnárì kan tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n ń sìn lórílẹ̀-èdè Bolivia ṣe yọjú síta látojú fèrèsé ilé kékeré tí wọ́n ń gbé lówùúrọ̀ ọjọ́ kan ní oṣù November ọdún 2000, ni wọ́n rí àwọn ọkùnrin àtàwọn obìnrin kan lẹ́nu géètì ilé wọn, tí wọ́n múra ṣákálá, tára wọn ò sì balẹ̀. Nígbà táwọn míṣọ́nnárì náà ṣí géètì, ohun táwọn àlejò náà kọ́kọ́ sọ ni pé: “A fẹ́ mọ òtítọ́ látinú Bíbélì.” Ẹlẹ́sìn Menno ni wọ́n. Àwọn ọkùnrin wọ aṣọ àwọ̀kanlẹ̀, àwọn obìnrin sì wọ aṣọ àwọ̀lékè aláwọ̀ dúdú tí wọ́n ń pè ní épúrọ́ọ̀nù lórí aṣọ wọn, èdè ìbílẹ̀ ilẹ̀ Jámánì kan ni wọ́n ń sọ. Ó hàn lójú wọn pé ẹ̀rù ń bà wọ́n. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń wobí-wọ̀hún láti mọ̀ bóyá àwọn kan ń tẹ̀ lé àwọn lẹ́yìn. Síbẹ̀, bí wọ́n ti ń gun àtẹ̀gùn wọnú ilé náà lọ ni ọ̀kan lára àwọn ọ̀dọ́kùnrin náà ń sọ pé, “Èmi fẹ́ mọ àwọn tó ń lo orúkọ Ọlọ́run ní tèmi.”

Lẹ́yìn tí wọ́n wọlé tí wọ́n sì fún wọn ní nǹkan ìpanu díẹ̀, ara wọn bẹ̀rẹ̀ sí wálẹ̀. Ọ̀nà jíjìn ni wọ́n ti wá, ní ibùdó àwọn àgbẹ̀ kan tó wà ní àdádó. Ọdún mẹ́fà ni wọ́n ti fi gba ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ níbẹ̀ nípasẹ̀ ìfìwéránṣẹ́. Wọ́n wá béèrè ìbéèrè kan, wọ́n ní: “A rí i kà pé Párádísè máa wà lórí ilẹ̀ ayé, ṣé òótọ́ ni?” Àwọn Ẹlẹ́rìí náà sì fi ìdáhùn hàn wọ́n nínú Bíbélì. (Aísáyà 11:9; Lúùkù 23:43; 2 Pétérù 3:7, 13; Ìṣípayá 21:3, 4) Ọ̀kan lára àwọn àgbẹ̀ náà sọ fáwọn tó kù pé: “Ẹ ò rí i báyìí! Òótọ́ ni. Párádísè máa wà lórí ilẹ̀ ayé.” Bẹ́ẹ̀ láwọn tó kù ń sọ pé: “Ó dà bíi pé a ti rí òtítọ́ o.”

Àwọn wo tiẹ̀ ni ẹlẹ́sìn Menno yìí? Kí ni wọ́n gbà gbọ́? Ká tó lè rí ìdáhùn, a gbọ́dọ̀ gbé ohun kan tó ṣẹlẹ̀ ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún yẹ̀ wò?

Àwọn Wo Ni Àwọn Ẹlẹ́sìn Menno?

Ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún, iṣẹ́ ìtumọ̀ Bíbélì àti títẹ̀ ẹ́ ní èdè tọ́pọ̀ èèyàn ń sọ nílẹ̀ Yúróòpù tẹ̀ síwájú gan-an, nítorí èyí àwọn èèyàn tún bẹ̀rẹ̀ sí nífẹ̀ẹ́ sí kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọ̀gbẹ́ni Martin Luther àtàwọn mìíràn tó jẹ́ Alátùn-únṣe Ìsìn pa púpọ̀ nínú ẹ̀kọ́ Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì tì. Síbẹ̀, àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tó ya kúrò lára ẹ̀sìn Kátólíìkì yìí ṣì fara mọ́ ọ̀pọ̀ àṣà tí kò bá Bíbélì mu. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ jù lọ wọn gbà pé wọ́n gbọ́dọ̀ ṣèrìbọmi fún ọmọ ọwọ́ tí wọ́n bá ṣẹ̀ṣẹ̀ bí kó lè di ara ìjọ. Àmọ́ àwọn kan tí wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láti mọ òtítọ́ rí i pé àfi téèyàn bá fúnra rẹ̀ ṣe ìpinnu tó gbé karí ìmọ̀ ló tó lè ṣèrìbọmi kó sì di ara ìjọ Kristẹni. (Mátíù 28:19, 20) Làwọn oníwàásù tó fara mọ́ ìgbàgbọ́ yìí tí wọ́n sì nítara bá bẹ̀rẹ̀ sí lọ sáwọn ìlú àti ìletò, wọ́n ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọ́n sì ń ṣèrìbọmi fáwọn àgbàlagbà. Àwọn èèyàn wá ń pè wọ́n ní Ánábatíìsì, tó túmọ̀ sí “àwọn atúnnibatisí.”

Ọkùnrin kan wà tó ń jẹ́ Menno Simons, ó gbà pé àwọn Ánábatíìsì lè ran òun lọ́wọ́ láti mọ òtítọ́. Àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì lọkùnrin yìí lábúlé kan tó ń jẹ́ Witmarsum, ní àríwá ilẹ̀ Netherlands. Nígbà tó di ọdún 1536, ó yọwọ́yọsẹ̀ nínú ìjọ Kátólíìkì, wọ́n sì ń wá a kiri láti mú un. Lọ́dún 1542, Olú Ọba Ilẹ̀ Róòmù Mímọ́, ìyẹn Charles Karùn-ún, kó ọgọ́rùn-ún owó ilẹ̀ Netherlands sílẹ̀ bí ẹ̀bùn fún ẹnikẹ́ni tó bá lè jẹ́ kí wọ́n rí Menno mú. Síbẹ̀, Menno ń kó àwọn Ánábatiísì tó bá rí jọ, ó sì ń sọ wọ́n di ìjọ. Kò pẹ́ tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ sí pe òun àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní ẹlẹ́sìn Menno.

Àwọn Ẹlẹ́sìn Menno Ti Òde Òní

Nígbà tó yá, inúnibíni mú kí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ẹlẹ́sìn Menno sá láti Ìwọ̀ Oòrùn Yúróòpù lọ sáwọn orílẹ̀-èdè Àríwá Amẹ́ríkà. Láwọn ibi tí wọ́n sá lọ yìí, wọ́n láǹfààní láti máa wá òtítọ́ nìṣó, ó sì ṣeé ṣe fún wọn láti mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn tẹ́wọ́ gba ìsìn wọn. Àmọ́ ìtara wọn láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti láti wàásù fáwọn èèyàn kò dà bíi táwọn aṣáájú wọn. Ọ̀pọ̀ jù lọ wọn ló gba àwọn ẹ̀kọ́ tí kò bá Bíbélì mu gbọ́, irú bí ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan, ẹ̀kọ́ pé ọkàn èèyàn kì í kú, àti iná ọ̀run àpáàdì. (Oníwàásù 9:5; Ìsíkíẹ́lì 18:4; Máàkù 12:29) Lónìí, ètò ìlera àti iṣẹ́ afẹ́nifẹ́re làwọn míṣọ́nnárì ẹlẹ́sìn Menno ń gbájú mọ́ jù, dípò iṣẹ́ ìwàásù.

Nǹkan bíi mílíọ̀nù kan àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọ̀ọ́dúnrún [1,300,000] niye tí wọ́n fojú bù pé àwọn ẹlẹ́sìn Menno tó báyìí, wọ́n sì ń gbé lórílẹ̀-èdè márùnlélọ́gọ́ta. Síbẹ̀ àwọn ẹlẹ́sìn Menno ọjọ́ òní ń ráhùn pé kò sí ìṣọ̀kan láàárín àwọn bí Menno Simons náà ṣe ráhùn lọ́pọ̀ ọ̀rúndún sẹ́yìn. Nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, èrò wọn ò ṣọ̀kan nípa wàhálà tó ń lọ nínú ayé lásìkò yẹn, èyí sì fa ìpínyà ńlá. Ọ̀pọ̀ àwọn tó wà láwọn orílẹ̀-èdè Àríwá Amẹ́ríkà kọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológun nítorí ohun tí Bíbélì sọ. Àmọ́ ìwé kan tó ṣàlàyé nípa ìtàn àwọn ẹlẹ́sìn Menno, An Introduction to Mennonite History, sọ pé: “Nígbà tó fi máa di ọdún 1914, àwọn ọmọ ìjọ Menno ní Ìlà Oòrùn ilẹ̀ Yúróòpù ti ń lọ́wọ́ síṣẹ́ ológun.” Lọ́nà kan ṣá, àwọn àwùjọ ẹlẹ́sìn Menno kan ti ń gbé ìgbésí ayé ọ̀làjú táwọn èèyàn ń gbé lónìí. Àmọ́, ìkọ́ làwọn kan ṣì fi ń mú aṣọ wọn pọ̀ dípò bọ́tìnnì, wọ́n sì gbà pé kò yẹ káwọn ọkùnrin máa fá irùngbọ̀n.

Àwọn àwùjọ ẹlẹ́sìn Menno kan tó ti pinnu láti má ṣe ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú àwọn èèyàn òde òní ti ṣí lọ sáwọn àgbègbè kan táwọn ìjọba ìbílẹ̀ gbà wọ́n láyè láti máa gbé láìsí pé ẹnikẹ́ni ń yọ wọ́n lẹ́nu. Bí àpẹẹrẹ, lórílẹ̀-èdè Bolivia, wọ́n fojú bù ú pé nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjìdínlógójì [38,000] ẹlẹ́sìn Menno ló ń gbé lọ́pọ̀ àwọn ibùdó tó jìnnà sílùú, òfin tó sì ń darí ìwà ibùdó kọ̀ọ̀kan yàtọ̀ sí ti òmíràn. Láwọn ibùdó kan, wọn ò gbọ́dọ̀ ní mọ́tò àfi ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ tẹ́ṣin ń fà. Wọn ò sì gbọ́dọ̀ ní rédíò tàbí tẹlifíṣọ̀n láwọn ibùdó kan tàbí kí wọ́n gbọ́ orin. Èèwọ̀ tiẹ̀ ni fáwọn kan láti kọ́ èdè orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń gbé. Ọ̀kan lára àwọn tó ń gbé láwọn ibùdó náà sọ pé: “Káwọn oníwàásù bàa lè ráyè máa darí wa, wọn kì í jẹ́ ká kọ́ èdè Spanish.” Ọ̀pọ̀ nínú àwọn èèyàn yìí lara ń ni tẹ́rù sì ń bà pé wọ́n lè lọ lé àwọn kúrò láwùjọ náà. Ìbẹ̀rù ńlá sì lèyí fún ẹnì kan tí kò tíì gbé àárín àwọn èèyàn mìíràn rí.

Bí A Ṣe Gbin Irúgbìn Òtítọ́ Sáàárín Wọn

Bí ipò nǹkan ṣe rí nìyẹn lákòókò tí àgbẹ̀ kan tó jẹ́ ẹlẹ́sìn Menno tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Johann rí ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ nílé aládùúgbò rẹ̀ kan. Orílẹ̀-èdè Kánádà ni ìdílé Johann tí ṣí lọ sílẹ̀ Mẹ́síkò kí wọ́n tó tún ṣí lọ sílẹ̀ Bolivia. Àmọ́ ó pẹ́ tó ti ń wu Johann pé kóun rí ìrànwọ́ láti lóye ìmọ̀ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì. Ló bá ní kí wọ́n yá òun ní ìwé ìròyìn náà.

Nígbà tí Johann wá ta irè oko rẹ̀ láàárín ìlú lẹ́yìn náà, ó lọ bá Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó ń fi ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ lọ àwọn èèyàn nínú ọjà náà. Arábìnrin náà darí rẹ̀ sí míṣọ́nnárì kan tó ń sọ èdè Jámánì, kò sì pẹ́ tí Johann fi bẹ̀rẹ̀ sí rí Ilé Ìṣọ́ gbà lédè Jámánì nípasẹ̀ ìfìwéránṣẹ́. Ó máa ń fara balẹ̀ ka ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan, lẹ́yìn náà ni ìwé ìròyìn náà yóò wá máa ti ọwọ́ ìdílé kan dé òmíràn níbùdó náà títí tá á fi gbó. Nígbà míì, àwọn ìdílé wọ̀nyí á pàdé pọ̀ wọ́n á sì máa kẹ́kọ̀ọ́ ohun tó wà nínú rẹ̀ títí dọ̀gànjọ́ òru, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n á máa wo gbogbo ẹsẹ Bíbélì tó wà níbẹ̀. Ó wá dá Johann lójú pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ní láti jẹ́ àwọn tó ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n sì wà níṣọ̀kan kárí ayé. Kó tó kú, ó sọ fún ìyàwó àtàwọn ọmọ rẹ̀ pé: “Ẹ gbọ́dọ̀ máa ka Ilé Ìṣọ́ déédéé. Yóò ràn yín lọ́wọ́ láti lóye Bíbélì.”

Àwọn kan nínú ìdílé Johann bẹ̀rẹ̀ sí bá àwọn aládùúgbò wọn sọ̀rọ̀ nípa nǹkan ti wọ́n ń kọ́ nínú Bíbélì. Wọ́n ní: “Ọlọ́run ò ní pa ayé yìí run. Kàkà bẹ́ẹ̀, yóò sọ ọ́ di Párádísè. Ọlọ́run kì í dá èèyàn lóró nínú ọ̀run àpáàdì.” Kò pẹ́ tóhun tí wọ́n ń bá àwọn èèyàn sọ yìí fi détígbọ̀ọ́ àwọn oníwàásù ní ṣọ́ọ̀ṣì, bí wọ́n ṣe wá halẹ̀ mọ́ ìdílé Johann nìyẹn pé tí wọn ò bá jáwọ́, àwọn á lé wọn kúrò ní ṣọ́ọ̀ṣì. Nígbà tí ìdílé náà ń sọ̀rọ̀ nípa wàhálà táwọn alàgbà ìjọ Menno ń fún wọn, ni ọ̀dọ́kùnrin kan bá dìde sọ̀rọ̀. Ó ní: “Mi ò ṣáà mọ ìdí tá a fi ń ṣàròyé nípa àwọn alàgbà ṣọ́ọ̀ṣì wa. Gbogbo wa ti mọ ìsìn tòótọ́, a ò sì ṣe nǹkan kan nípa rẹ̀.” Bàbá ọ̀dọ́kùnrin yìí ronú lórí ọ̀rọ̀ yìí gan-an. Kò sì pẹ́ lẹ́yìn èyí làwọn mẹ́wàá nínú ìdílé náà rin ìrìn-àjò bòókẹ́lẹ́ láti wá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí, wọ́n sì bára wọn nílé àwọn míṣọ́nnárì náà bá a ṣe sọ níbẹ̀rẹ̀.

Lọ́jọ́ kejì, àwọn míṣọ́nnárì náà lọ sọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ wọn tuntun yìí níbùdó wọn. Ọkọ̀ wọn nìkan ṣoṣo ló wà lójú ọ̀nà náà. Bí wọ́n ti rọra ń wakọ̀ kọjá lára àwọn kẹ̀kẹ́ tí ẹṣin ń fà, bẹ́ẹ̀ làwọn àtàwọn ará ibẹ̀ jọ ń wora wọn tìyanutìyanu. Láìpẹ́, wọ́n jókòó nídìí tábìlì kan pẹ̀lú àwọn mẹ́wàá tó jẹ́ ẹlẹ́sìn Menno ìdílé méjì sì làwọn mẹ́wẹ̀ẹ̀wá náà.

Lọ́jọ́ yẹn, wákàtí mẹ́rin ni wọ́n fi kẹ́kọ̀ọ́ orí àkọ́kọ́ nínú ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun. a Àwọn àgbẹ̀ náà ti wá àwọn ẹsẹ Bíbélì mìíràn tó bá ìpínrọ̀ kọ̀ọ̀kan mu sílẹ̀ wọ́n sì fẹ́ mọ̀ bóyá àlàyé àwọn lórí àwọn ẹsẹ náà tọ̀nà. Lẹ́yìn ìbéèrè kọ̀ọ̀kan, àwọn àgbẹ̀ náà ò ní tètè fèsì, wọ́n á kọ́kọ́ fi èdè ìbílẹ̀ Jámánì kan bára wọn sọ̀rọ̀ kẹ́ni tó jẹ́ agbẹnusọ wọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá fi èdè Spanish dáhùn fún gbogbo wọn. Ọjọ́ tí wọn ò lè gbàgbé lọjọ́ náà. Àmọ́ wàhálà ti ń rú lábẹ́lẹ̀. Wọn ò ní pẹ́ rí àdánwò bí Menno náà ṣe rí i nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí wá ọ̀nà láti mọ òtítọ́ nínú Bíbélì lọ́gọ́rùn-ún márùn-ún ọdún sẹ́yìn.

Wọ́n Rí Àdánwò Nítorí Òtítọ́

Ọjọ́ díẹ̀ lẹ́yìn náà làwọn alàgbà ṣọ́ọ̀ṣì wá sọ́dọ̀ ìdílé Johann tí wọ́n sì fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yìí níkìlọ̀. Wọ́n ní: “A gbọ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wá sọ́dọ̀ yín. Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí wọ́n padà wá mọ́, tẹ́ ò bá sì kó àwọn ìwé wọn fún wa ká dáná sun wọ́n, ńṣe la máa lé yín kúrò ní ṣọ́ọ̀ṣì.” Ẹ̀ẹ̀kan péré làwọn Ẹlẹ́rìí náà ṣì kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú wọn, nítorí náà, ìṣòro ńlá gbáà lèyí jẹ́ fún wọn.

Ni olórí ìdílé kan bá fèsì pé: “A ò lè ṣe ohun tẹ́ ẹ sọ yẹn. Ẹ̀kọ́ Bíbélì ni wọ́n wá ń kọ́ wa.” Kí làwọn alàgbà náà ṣe? Wọ́n ní ìjọ ò ní bá àwọn ìdílé náà da nǹkan pọ̀ mọ́ nítorí pé wọ́n ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì! Ìyà ńlá lèyí sì fi jẹ wọ́n. Iléeṣẹ́ tó ń bá wọn fi mílíìkì ṣe wàràkàṣì kò gbé mílíìkì ọ̀kan lára àwọn ìdílé náà nígbà tó ń kọjá lọ, ọ̀nà kan ṣoṣo tí wọ́n sì fi ń rówó ná ni wọ́n dí yìí. Wọ́n lé olórí ìdílé kan kúrò lẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀. Wọn ò ta ọjà fún ọ̀kan lára wọn ní ṣọ́ọ̀bù tí wọ́n ti ń ta nǹkan ní ibùdó náà, wọ́n sì lé ọmọbìnrin rẹ̀ tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́wàá kúrò níléèwé. Àwọn ará àdúgbò yí ilé kan ká láti mú ìyàwó ọ̀kan lára àwọn ọ̀dọ́kùnrin tó wà níbẹ̀ lọ, wọ́n láwọn ò ní jẹ́ kó bá ọkọ́ rẹ̀ tí wọn ò fẹ́ bá da nǹkan pọ̀ gbé mọ́. Síbẹ̀, àwọn ìdílé tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yìí kò juwọ́ sílẹ̀ bí wọ́n ti ń wá ọ̀nà láti mọ òtítọ́.

Àwọn míṣọ́nnárì náà ń wakọ̀ lọ sọ́nà jíjìn yìí lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti lọ darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà. Ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí sì fún àwọn ìdílé náà lókun gan-an! Kẹ̀kẹ́ tẹ́ṣin ń fà làwọn kan fi máa ń rìnrìn àjò wákàtí méjì wá síbi ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Ẹnu kọ̀ròyìn lọ́jọ́ táwọn ìdílé náà kọ́kọ́ sọ pé kí ọ̀kan lára àwọn míṣọ́nnárì náà gbàdúrà. Láwọn ibùdó náà, àwọn ẹlẹ́sìn Menno kì í gbàdúrà sókè rárá, nítorí náà wọn ò gbọ́ kẹ́nì kan gbàdúrà fún wọn rí. Ńṣe lomi ń bọ́ lójú àwọn ọkùnrin náà. Ǹjẹ́ o lè fojú inú wo bí ara wọn ti wà lọ́nà tó láti gbọ́ orin nígbà táwọn míṣọ́nnárì náà gbé rédíò tó ń lo kásẹ́ẹ̀tì wá? Wọn ò fàyè gba orin rí níbùdó wọn. Inú wọn dùn gan-an nígbà tí wọ́n gbọ́ bí Àwọn Orin Atunilára ti Ìjọba Ọlọ́run náà ṣe dùn tó, débi pé wọ́n pinnu láti máa kọ àwọn orin náà lẹ́yìn ìkẹ́kọ̀ọ́ kọ̀ọ̀kan! Àmọ́ o, ọgbọ́n wo ni wọ́n fẹ́ ta sí ìṣòro tó ṣẹ̀ṣẹ̀ yọjú yìí?

Wọ́n Rí Ẹgbẹ́ Ará Tó Nífẹ̀ẹ́

Níwọ̀n báwọn aládùúgbò kò ti bá àwọn ìdílé yìí da nǹkan pọ̀ mọ́, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣe wàràkàṣì tiwọn. Àwọn míṣọ́nnárì náà bá wọn wá àwọn tí yóò máa rà á. Ẹlẹ́rìí kan tó ti ń sin Jèhófà fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún lórílẹ̀-èdè kan ní Àríwá Amẹ́ríkà tó sì jẹ́ pé ọ̀kan lára ibùdó àwọn ẹlẹ́sìn Menno ní Gúúsù Amẹ́ríkà ló ti dàgbà gbọ́ nípa ìṣòro àwọn ìdílé wọ̀nyí. Ó fẹ́ láti ṣèrànwọ́. Àárín ọ̀sẹ̀ kan péré ló wọkọ̀ òfuurufú lọ sílẹ̀ Bolivia láti lọ bẹ̀ wọ́n wò. Yàtọ̀ sí pé ó fún wọn níṣìírí gan-an nípa tẹ̀mí, ó tún ra ọkọ̀ akẹ́rù ńlá fún wọn láti lè máa wọ̀ ọ́ lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba kí wọ́n sì tún máa fi kó irè oko wọn lọ sọ́jà.

Ọ̀kan lára wọn sọ ohun tójú wọn rí, ó ní: “Nǹkan nira fún wa gan-an lẹ́yìn tí wọ́n ní káwọn aládùúgbò má bá wa da nǹkan pọ̀ mọ́. Pẹ̀lú ìbànújẹ́ la máa ń lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba àmọ́ tayọ̀tayọ̀ la máa ń padà sílé.” Ká sòótọ́, àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ládùúgbò náà ṣe bẹbẹ, wọ́n ràn wọ́n lọ́wọ́ gan-an. Àwọn kan kọ́ èdè Jámánì, àwọn Ẹlẹ́rìí kan tó ń sọ èdè Jámánì sì ti ilẹ̀ Yúróòpù wá sílẹ̀ Bolivia láti wá máa bá wọn dárí ìpàdé Kristẹni lédè Jámánì. Kò pẹ́ rárá tí mẹ́rìnlá lára àwọn ẹlẹ́sìn Menno náà fi bẹ̀rẹ̀ sí wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run fáwọn ẹlòmíràn.

Ní October 12, ọdún 2001, láìtíì pé ọdún kan táwọn Ánabatíìsì yẹn kọ́kọ́ wá sílé àwọn míṣọ́nnárì, mọ́kànlá lára wọn tún ìrìbọmi wọn ṣe, àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, ó jẹ́ àmì pé wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà. Látìgbà náà, àwọn mìíràn tún ti ṣèrìbọmi. Ọ̀kan lára wọn sọ lẹ́yìn náà pé: “Bí ẹrú tó dòmìnira la jẹ́ látìgbà tá a ti bẹ̀rẹ̀ sí mọ òtítọ́ nínú Bíbélì.” Òmíràn sọ pé: “Ọ̀pọ̀ àwọn ẹlẹ́sìn Menno ló ń ṣàròyé pé kò sífẹ̀ẹ́ láàárín àwọn. Àmọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń bìkítà nípa ara wọn. Ọkàn mi balẹ̀ bí mo ṣe wà láàárín wọn.” Bí ìwọ náà bá ń wá ọ̀nà láti túbọ̀ lóye ìmọ̀ òtítọ́ látinú Bíbélì, o lè rí ìṣòro. Àmọ́ bó o bá bẹ Jèhófà pé kó ràn ọ́ lọ́wọ́, tó o sì ní ìgbàgbọ́ àti ìgboyà bíi tàwọn ìdílé yìí, ìwọ náà á ṣàṣeyọrí wàá sì láyọ̀.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é jáde.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Inú wọn dùn nígbà tí wọ́n rí àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lédè Jámánì gbà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò gbà wọ́n láyè tẹ́lẹ̀ láti kọrin, gbogbo ìgbà tí wọ́n bá ti parí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn ni wọ́n máa ń kọrin báyìí